Welcome, Guest: Register On Nairaland / LOGIN! / Trending / Recent / New
Stats: 3,148,882 members, 7,802,850 topics. Date: Friday, 19 April 2024 at 11:15 PM

New Yoruba Movie: AYE MI - Culture - Nairaland

Nairaland Forum / Nairaland / General / Culture / New Yoruba Movie: AYE MI (3240 Views)

New Yoruba Nation Coming Soon, Says Ooni / New Yoruba Nation Coming Soon, Says Ooni / New Yoruba Nation Coming Soon, Says Ooni (2) (3) (4)

(1) (Reply)

New Yoruba Movie: AYE MI by obaede: 11:41pm On Aug 05, 2014
[center]AYE MI lati Owo Bose Alubarika[/center][b][/b]
Orisiirisii aditu ogbon lati ri ni owo awon onimo agbaye, onise alakada ati awon onwoye nipa igbe aye awon eniyan lawujo. Lara iru akiyesi ogbon naa ni wi pe opolo ti Edumare fun eda eniyan kii baje raurau- ki i ba je ise aye tabi afowofa ara eni. A ri apeere eyi nipa wi pe ko si bi were se ya digbolugi to, to ba ri moto ti n bo n se ni o sare yago lona. Abala kan ninu opolo won si n sise lati se akiyesi ewu tabi ijamba.

Bibeli naa salaye orisii were kan eleyii to bugije koja apejuwe. Iboji ni were naa n gbe; o si maa n fi okuta ya ara re lopolopo igba. Sugbon lojo kan o ri Jesu, opolo si so fun wi pe Jesu lori. Awon onimo bibeli (Theologist) si je ko ye wa wi pe oseese ki okunrin naa ti gbo nipa Jesu ri nibi kan idi ni yii to fi sare too Omo Maria wa fun igbala.


E maa ro wi pe ki lo fa surutu repete? 'Oga oniroyin e fitan sile, koko la fe gbo.'

O daa, ko buru, mo ti fe e debi ti mo n lo. Sugbon sa, e ma gbagbe wi pe mo n so nipa aditu ogbon eleyii ti awon onwoye se akiyesi re ninu iseda eniyan lawujo.

E tun gbo eleyii...

Nigba lailai, awon agbalagba Yoruba aye atijo gba wi pe laakaye to je baba ogbon a maa ya inu awon omode (tabi awon odo) sun leekookan tayo ohun ti agbalagba le ri kojo fun odindi ogorun odun. Idi ni yii won fi n pa owe wi pe omode gbon, agba gbon ni won fi da United Kingdom. Ha! E ma binu, Ile Ife ni mo fe wi. Omode gbon, agba gbon la fi da ile Ife.

Leyin igba ti mo ti salaye ero okan mi. E je ka pada sori afihan fiimu wa fun osu yii, eleyii ti won pe akole re ni AYE MI lati owo Bose Oladimeji (Alubarika). Ojo ori ko ni ohunkohun se pelu ogbon ori. Eni wu Edumare ni oba mi oke n fun ni laakaye yanturu. Bi eniyan ba buru to si daju bi alujannu ti won pe ni Sani Abacha tabi Idi Amin ti ilu Uganda, bi eni naa ba wo Omo Orukan ti Adebayo Salami se, dandan ni ko yomi loju. Bee, omode ni Bayo lodun to fi ogbon ori gbe itan naa kale. Muyiwa Ademola ti salaye ri wi pe fiimu ORI ti gbogbo aye n pariwo, okan ninu awon itan ti oun ti ko nigba ti oun wa ni ile iwe girama ni.

Mo ti pinnu wi pe mi o ni so ohunkohun nipa fiimu AYE MI to ti gori igba. Enikeni ti e ba ti ri, e bere lowo won wi pe se won ti wo fiimu naa. Ohun ti won ba ti wi ni kee tele. Bi o tile je wi pe Bose Alubarika ti se awon fiimu kan saaju, sugbon itan Aye Mi ti wa lowo re tipetipe eleyii to se Afeez Eniola ni kayeefi lojo ti Bose Alubarika mu akosile itan naa jade sita. Muyiwa Ademola ri agbekale itan naa lo fi gba lati kopa ninu re. Awon agba osere yii gbimopo, won si gba wi pe ki Bayo Tijani dari ere naa latari iriri ati awon aseyori to ti ni lori awon fiimu onirawo meje bi ti Aye Mi to ti dari seyin.

Ibo ni Bose Alubarika ti ri ogbon ko iru itan yii?

Eni to beere oro lo fe idi re gbo. Eni to fe ori ahun ati ese ahun, dandan ni ko ra odindin ahun. Bayo Tijani lodari fiimu tuntun yii, Afeez Eniola ni alamojuto. Lara awon osere fiimu naa ni Bimbo Akintola ati Doris Simeon sugbon maa royin ki e kiyesi Arike Akinyanju pupo. Alubarika ti wo ise owo Bose Oladimeji ni. Almaroof se n kiri aye. Alubarika ko ni won ninu ise wa. Amin.

http://www.olayemioniroyin.com/2014/08/iriri-aye-ati-ogbon-ninu-fiimu-tuntun.html

Re: New Yoruba Movie: AYE MI by 2prexios: 1:30pm On Aug 06, 2014
Eku iyanju lori ero ikanni yi,

Bi o tile ti je wipe nko kundun lati maa wo sinima tobe ju bee lo, mo se sadankata fun ise opolo ti e lo lati fi ewa ede agbede-gbeyo gbe erongba yin lori sinima yin kale lati fi ise opolo ti e ti se naa han fun mutumuwa. O dara lati ni asiko fun idaraya ati ituraka pelu awon ebi laarin kan tabi omiran, Nitori naa, mo gb'osuba fun yin.

Igbagbo mi ni wipe bi aba ns'akitiyan lori sinima pelu ewa ede wa, ko nii rorubn ki ise ati asa wa pare leyinwa ola. Eleyi a je "moriwu" fun awon ti won nfe ki asa ati ise wa ni idagbasoke ni sanmoni taa wa bayi.

Lai dena penu, emi naa yoo nife si sinima naa lati wo, bolouwa bafe.

Eseun l'opolopo.
Re: New Yoruba Movie: AYE MI by 2prexios: 1:30pm On Aug 06, 2014
Eku iyanju lori ero ikanni yi,

Bi o tile ti je wipe nko kundun lati maa wo sinima tobe ju bee lo, mo se sadankata fun ise opolo ti e lo lati fi ewa ede agbede-gbeyo gbe erongba yin lori sinima yin kale lati fi ise opolo ti e ti se naa han fun mutumuwa. O dara lati ni asiko fun idaraya ati ituraka pelu awon ebi laarin kan tabi omiran, Nitori naa, mo gb'osuba fun yin.

Igbagbo mi ni wipe bi aba ns'akitiyan lori sinima pelu ewa ede wa, ko nii rorubn ki ise ati asa wa pare leyinwa ola. Eleyi a je "moriwu" fun awon ti won nfe ki asa ati ise wa ni idagbasoke ni sanmoni taa wa bayi. Lai dena penu, emi naa yoo nife si sinima naa lati wo, bolouwa bafe.

Eseun l'opolopo.

(1) (Reply)

Umu Obiligbo – KENE CHUKWU / Linguistic Evidence Supports Yoruba Migration From Egypt Thesis / Secondary Royal Titles In Yorubaland

(Go Up)

Sections: politics (1) business autos (1) jobs (1) career education (1) romance computers phones travel sports fashion health
religion celebs tv-movies music-radio literature webmasters programming techmarket

Links: (1) (2) (3) (4) (5) (6) (7) (8) (9) (10)

Nairaland - Copyright © 2005 - 2024 Oluwaseun Osewa. All rights reserved. See How To Advertise. 19
Disclaimer: Every Nairaland member is solely responsible for anything that he/she posts or uploads on Nairaland.