Welcome, Guest: Register On Nairaland / LOGIN! / Trending / Recent / New
Stats: 3,150,233 members, 7,807,776 topics. Date: Wednesday, 24 April 2024 at 07:01 PM

.. - Culture (76) - Nairaland

Nairaland Forum / Nairaland / General / Culture / .. (1827058 Views)

"We The Ewe People Of Ghana Are The Same As Yoruba"- Yewe2011.ewe Guy From Ghana / How Do U Spell (weed) In Yoruba, Is It Igbo? Or Egbo? / Yoruba Idioms: Owe Yoruba, Itunmo Re Ati Lilo Re (2) (3) (4)

(1) (2) (3) ... (73) (74) (75) (76) (77) (78) (79) ... (99) (Reply) (Go Down)

Re: .. by estateallen: 2:39am On May 06, 2016
Ara iwaju iba o!!! ejor shey a le jo ewe ogun papo lori electric cooker?
Re: .. by jophins(m): 10:43am On May 06, 2016
Ifankaleluya no ki yin sir eku ishe E jowo no Send mail kan si yin ejowo sir E dakun mon reti esi Ayo.
Re: .. by jophins(m): 10:47am On May 06, 2016
@estateallen o funny die sugbon emi naa to she iru e ri daada sugbon Orun at I efi ma gba inu ile koda gan o tun ya sugbon e je ji a she bi ti awon Baba wa tin manshe ki o ba ri bitin ri ka ma fi aye Olaju bo lo Aroo eledu tabi Stove tabi Igi
Re: .. by sanjayzaman(m): 10:18pm On May 06, 2016
walexy30:


E SE PUPO
se ale lo ebu yii fun opo eniyan abi ori Kan Loma loo toba je ori Kan Loma loo se ekan Lao lo gbogbo ebu yii tan abi diedie ni ao ma lo ese pupo olohun atunbo ma ran yin lowo ewe ATI egbo yio ma je?
Re: .. by Ifankaleluya: 10:57pm On May 07, 2016
flightz:
ekalee o. eku eto. pls, I want to destroy d destiny of the oloribu that stole my phone, pls e shanu mi. thanks

E se suuru baba..!

1 Like

Re: .. by Ifankaleluya: 10:58pm On May 07, 2016
jophins:
Ifankaleluya no ki yin sir eku ishe E jowo no Send mail kan si yin ejowo sir E dakun mon reti esi Ayo.

E dakun kin ni e-mail yin yen na?
Re: .. by Ifankaleluya: 11:04pm On May 07, 2016
OGUN KI A MA BA LU MAGUN

Panumo, ewe seyo, ao lo papo mo oko-atare kan, ao fi sin gbere yika isale ikun wa.

Aboru, Aboye, Abo-sise.

2 Likes

Re: .. by Ifankaleluya: 11:11pm On May 07, 2016
AJEGUN ABALAYE

Owo-osi elegbede, ewe-ina pupa, ewe-esisi, odidi atare kan, etu ibon. Owo-osi elegbede yi ni ao koko jo papo mo awon ewe-ida yoku, ti o ba jo tan ti a so kale, ao wa je ko tutu, ao wa da etu-ibon yen si, ao lo po dada, ao fi sin gbere yi orun owo mejeji ka, ao po iyoku mo ose, ao ma fi fo owo.

Ela-boru, Ela-boye, Ela-bosise.

2 Likes

Re: .. by zenith329: 8:04am On May 08, 2016
[quote author=Ifankaleluya post=45414089]OGUN KI A MA BA LU MAGUN

Panumo, ewe seyo, ao lo papo mo oko-atare kan, ao fi sin gbere yika isale ikun wa.
Baba ifankehaleluya, e ma binu, se ewe sayo le fe ko?
Re: .. by Lero70: 12:47pm On May 08, 2016
Ifankaleluya:
OGUN KI A MA BA LU MAGUN

Panumo, ewe seyo, ao lo papo mo oko-atare kan, ao fi sin gbere yika isale ikun wa.

Aboru, Aboye, Abo-sise.
,
baba awo Ifankaleluya, edakun orisi panumo meji lowa, panumo abo ni abi panumo abafe? Eseepupo ewe amaaje o.

2 Likes 1 Share

Re: .. by consato009: 10:52pm On May 08, 2016
E joo baba efun nise yi tan nitori mo need e gan ni, gbogbo Awon babalawo timo ma nlo sodore tiwon ba dafa lo tiwon dafa bo won ani ogun Awon agbalagba ni kinma tera mo lati loo, e tori olorun efi iseyi saanu mi...
Re: .. by Faiga84: 8:10am On May 09, 2016
Nil
Re: .. by Ifankaleluya: 7:18pm On May 09, 2016
Lero70:

,
baba awo Ifankaleluya, edakun orisi panumo meji lowa, panumo abo ni abi panumo abafe? Eseepupo ewe amaaje o.

Panumo Abo ni baba..!

1 Like

Re: .. by Ifankaleluya: 7:23pm On May 09, 2016
consato009:
E joo baba efun nise yi tan nitori mo need e gan ni, gbogbo Awon babalawo timo ma nlo sodore tiwon ba dafa lo tiwon dafa bo won ani ogun Awon agbalagba ni kinma tera mo lati loo, e tori olorun efi iseyi saanu mi, 08062090143.........or shoyinkaismail@gmail.com




Se eti se awon etutu ti won ni ki e se?

Ati wipe, se awon babalawo yen o se ifa awon agbalagba fun yin ni?

Ifa awon agbalagba po dada, melo ni e se?....sugbon ko ba wu mi lati mo ODU-IFA e da last.
Re: .. by fbabs(m): 9:01am On May 10, 2016
Ifankaleluya:

Boya ki e kan si wa lori e-mail yi.....ifankaleluya@gmail.com
ki a so labe aso!
e seun baba mo ti ri owo yin. E pe fun wa mo ti kan si yin pada
Re: .. by estateallen: 10:21pm On May 10, 2016
Ejor shey mo le ri eni to nbo wa si ilu oyinbo (UK) laipe ni bibayi ? Ese o
Re: .. by Ifankaleluya: 10:23pm On May 11, 2016
Ifa ni;
Tipa-tipa ni Babalawo fi fewure bo-ifa
Agbe eeti ni maro
Aluko kii ti ni ibu kosun
Odidere kii ti ni ibu tepo
Ojulumo e je ki ahun o sun gbe
Alo, alo, alo ese lori alabahun jafa
Ora loni kin ma rahun owo
Ihoho-dodo lagbado roko
To ba dajodun a do nigba ire gbogbo
Sinkinminni mi de
Afaimoni ko ni mora
Iyere-osun loni ki ire-aje temi o ma sun na
Eji-ogbe, a gbe la ni ko gbe mi.
Eledumare ko ni je ki gbogbo wa o rahun ire gbogbo. Ase!
Aboru, Aboye, Abo-sise..!

1 Like

Re: .. by auggswell: 12:08am On May 12, 2016
[quote author=Legendbaba1 post=44872377]BABA KEPE EJO WO TI ENIYAN BANI AYISAN Staphylococcus KINI ENIYAN LELO FUN ARUN YI MAY U LIVE LONG AMIN [



aarun buruku ni staph, oogun wa ti e ma lo amo yi o gba yin ni time, at leas OSU meta, o wa le kuro Lara yin laarin OSU kan oo amo OSU meta ni ki e ma fi okan le. toripe e le lo se test ki won ni won o ri nlankan ti o de si wa nibe. aasi ma fa aisan orisirisi si yin lara. torina Bi e ba se n lo oogun ni e o ma se ayewo leekan tabi emeji losu
Re: .. by Ifankaleluya: 9:14pm On May 12, 2016
Ifa ni;
Bikun ba jẹ loju oloko,
Eku ẹ sagada lẹhin ebe
A difa fun Ogbe eyi ti o gbe apo iwa ko Iwori ọmọ iya rẹ lọrun.
O ni ọjọ ta a ri Iwori la rahun aje mọ.
A rira, mama jẹ ki a rahun a rira.
Ojọ ta ri Iwori la rahun owo mọ.
Ojo ta ri Iwori la rahun ire gbogbo mo. A rira, Ifa mama je ki a rahun, a rira.
Eledumare ko ni je ki a rahun ire-gbogbo nile aye...Ase!

1 Like

Re: .. by Ifankaleluya: 5:57pm On May 13, 2016
Ifa ni;
Aronipin(re re re re) eniyan ni funni lagbondo adie je,
A dia fun Orunmila
Baba n fomije sungbere aya
Won ni o sa ki imonle ebo elenini ni ko se,
O gbebo nbe o si sebo,
Nje elenini ile e wa gba,
Eyin aronipin eniyan, e wa gba,
Odere ile yi e wa gba,
Asake ile yi e wa gba,
Iya kere ile yi e wa gba,
Eyin aronipin eniyan e wa gba.
Gbogbo ota to ni ti e ko ba de ile oun e o ni se rere,
Pelu ogo-olorun, lowo yin ni won ti mo wa gba. To abala esu.
Aboru, Aboye, Abo-sise.

1 Like

Re: .. by shogzy12: 6:32pm On May 13, 2016
Bi e ba fe dara po mo wa lori whatsapp, e fi number yin ranse si e-mail yi binaryteck@gmail.com, ao fi yin sori whasapp wa. Ao da whatsapp group sile fun awon ibeere sugbon eni to ba fe ibeere lori asiri, yio kan si wa ni idakonko.(private).
Re: .. by shogzy12: 6:38pm On May 13, 2016
E jo sir (gmail) te fun wa o lo lati aro ni mo ti gbiyanju lati add re, e Jo boya ke ranmilowo ke add mi, aolamide25@gmail.com e seun gan sir modupe
Re: .. by misspricy(f): 9:59am On May 14, 2016
orunmila76:
Ara iwaju IBA!

Oogun Eyonu to daju

igbo die(Indian hemp),Irun Abe obirin die,aa lo po,aa daa sinu lofinda ti a BA feran.

Lilo re: pipara Ni aaro Monday.

Ofo re: Ojo ti omode BA mu igbo Ni igbo npaa,ojo ti agbalagba BA mu igbo Ni npaa,tomode tagba lo feran obo.
. E jowo sir, se body cream ni lofinda abi perfume.
Re: .. by wale259(m): 10:56pm On May 14, 2016
Amin Ase baba mi ifankaleluya.
Ifankaleluya:
Ifa ni;

Aronipin(re re re re) eniyan ni funni lagbondo adie je,

A dia fun Orunmila

Baba n fomije sungbere aya

Won ni o sa ki imonle ebo elenini ni ko se,

O gbebo nbe o si sebo,

Nje elenini ile e wa gba,

Eyin aronipin eniyan, e wa gba,

Odere ile yi e wa gba,

Asake ile yi e wa gba,

Iya kere ile yi e wa gba,

Eyin aronipin eniyan e wa gba.

Gbogbo ota to ni ti e ko ba de ile oun e o ni se rere,

Pelu ogo-olorun, lowo yin ni won ti mo wa gba. To abala esu.

Aboru, Aboye, Abo-sise.
Re: .. by ALIUDAVID: 11:04pm On May 14, 2016
Ifankaleluya:
Ifa ni;

Bikun ba jẹ loju oloko,

Eku ẹ sagada lẹhin ebe

A difa fun Ogbe eyi ti o gbe apo iwa ko Iwori ọmọ iya rẹ lọrun.

O ni ọjọ ta a ri Iwori la rahun aje mọ.

A rira, mama jẹ ki a rahun a rira.

Ojọ ta ri Iwori la rahun owo mọ.

Ojo ta ri Iwori la rahun ire gbogbo mo.
A rira, Ifa mama je ki a rahun, a rira.

Eledumare ko ni je ki a rahun ire-gbogbo nile aye...Ase!

Baba ifakaleluya moti send mail si email yin ma ma reti esi yin email mi ni yii (aliudavidodunayo@gmail.com) eseun
iba agbagba, iba eyin to laye.
Re: .. by ademotech: 2:55am On May 15, 2016
eejo molala pe moru irin mosi sokale SI ebute kini itun mo re
Re: .. by Tevez83839: 7:45am On May 15, 2016
Edakun eyin babawa
monife arabinrin kan ni mosi fee fe sile sugbon oni ohun ko le femi edakun mo mo oruko re ati ti baba re .ko ki se omo timo le fun ni afunje .,sugbon iru ise wo nimole sasi
Re: .. by Hadeyeancah(m): 12:26pm On May 15, 2016
Ara iwaju iba o!!!

E Jo sir, kini awon agba npe ni ogun asiri owo ati ogun asiri bibo.

Iyato wo lo wa larin won ati wi pe kinni implications ati disadvantages won..
E se sir, ewe a ma je ooo
Re: .. by fbabs(m): 1:57pm On May 15, 2016
misspricy:
. E jowo sir, se body cream ni lofinda abi perfume.

lofinda = perfume , body cream = ipara
Re: .. by Ifankaleluya: 2:28pm On May 15, 2016
Tevez83839:
Edakun eyin babawa
monife arabinrin kan ni mosi fee fe sile sugbon oni ohun ko le femi edakun mo mo oruko re ati ti baba re .ko ki se omo timo le fun ni afunje .,sugbon iru ise wo nimole sasi

Imonran temi ni wipe ki e koko lo wadi boya iyawo yin ni na. Lotito Ife se fi agbara wa, sugbon ko dara to nitori ojo-iwaju.

1 Like

Re: .. by Ifankaleluya: 2:37pm On May 15, 2016
Hadeyeancah:
Ara iwaju iba o!!!

E Jo sir, kini awon agba npe ni ogun asiri owo ati ogun asiri bibo.

Iyato wo lo wa larin won ati wi pe kinni implications ati disadvantages won..
E se sir, ewe a ma je ooo

Iyato wa dara-dara larin awon nkan ti e daruko yen. Ati wipe orisi-risi re lo wa.
Asiri-Owo da bi Ako-Osole, Nigbati a si le pe Asiri-bibo ni Awure.

Nipa disadvantages won, Awon nkan ti won ba fi se ni yio so iru alebu to wa nibe. Kiiise. Gbogbo iru-ogun bayen na ni o ni alebu, o wa lowo Babalawo ti o ba se fun yin. Idi niyi to fi je wipe eniyan o kan le sa dede ma se awon ogun kan to ka ninu iwe kan, bi kose. Ko to awon to ni imo(knowledge) nipa Ogun lo.

1 Like

Re: .. by Ifankaleluya: 3:00pm On May 15, 2016
IFA NI,

Iji ti mo ji mo ba agbe lori igbago

Iji ti mo ji mo ba akalamagbo lori imo

Iji ti mo ji mo ba toro momo lori ope

Toro gege ni iya orunmile nje

Awon olode e mo le binu igun-nu-gun lai-lai

Olorisa kii binu sefun-sefun

Enikan kii binu akan lodo

Aigbori odo pete odo

Aigbaja ka gbimonran ika laja

Enikan kii gun iyan koko ko pode ilu jo

Ojiji enikan ke di mo ni

Ifa o to gege, ma je ki omo araye o le binu mi.

Aboru, Aboye, Abo-sise.

2 Likes

(1) (2) (3) ... (73) (74) (75) (76) (77) (78) (79) ... (99) (Reply)

Viewing this topic: 1 guest(s)

(Go Up)

Sections: politics (1) business autos (1) jobs (1) career education (1) romance computers phones travel sports fashion health
religion celebs tv-movies music-radio literature webmasters programming techmarket

Links: (1) (2) (3) (4) (5) (6) (7) (8) (9) (10)

Nairaland - Copyright © 2005 - 2024 Oluwaseun Osewa. All rights reserved. See How To Advertise. 71
Disclaimer: Every Nairaland member is solely responsible for anything that he/she posts or uploads on Nairaland.