If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here!

A Member? Please Login  
type your username and password to login
Date: July 26, 2008, 02:36 AM
223724 members and 127043 Topics
Latest Member: TAIWO PETE
Nairaland [Nigerian Forum] Home Help Search Who is currently online? Login Register
Nairaland Forum  |  General Discussion  |  Culture  |  If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here!
Pages: (1) ... (3) (4) (5) (6) (7) (8) (9) (10) (11) (12) (13) (14) (15) ... (141) Go Down Send this topic Notify of replies
Author Topic: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here!  (Read 31816 views)
segoye2 (m)
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here!
« #256 on: May 24, 2007, 11:59 PM »

Odara la ti ma ko iwe ni ede wa,  ati ojo ti mo bere si ni ko ede yoruba yi,  mo tin gbona ninu ee daa daa, bee mi oti loo 5 minutes ri ni ile yoruba ni ayemi,  but don't try me,  nitori language student ni mi.
minute (f)
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here!
« #257 on: May 25, 2007, 12:01 AM »

kini gbogbo nti @richlaw type soke yen? iyalenu loje funmi wipe mi ole ka.
richylaw (m)
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here!
« #258 on: May 25, 2007, 12:02 AM »

Penfold

A kii se babalawo ni idile ti wa o. Ewa ede ni mo karamasiki!
segoye2 (m)
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here!
« #259 on: May 25, 2007, 12:03 AM »

Babalawo, jeka soro ti ofe ba mi so yen lori msn ,  ibi ti obo ba wa, e mi a wa ri ni oni,  e je ka loo sa,  e ku ise agbara na
minute (f)
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here!
« #260 on: May 25, 2007, 12:03 AM »

now oye mi wayii.on pofo right? ebi e ko,aini se se lofa.
richylaw (m)
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here!
« #261 on: May 25, 2007, 12:04 AM »

Quote from: minute on May 25, 2007, 12:01 AM
kini gbogbo nti @richlaw type soke yen? iyalenu loje funmi wipe mi ole ka.

 Grin Grin Grin Grin O jo ti larubawa abi ti igbira, kaa leyo kookan yio ye o!
richylaw (m)
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here!
« #262 on: May 25, 2007, 12:06 AM »

Segoye, awon eke babalawo bi i haywhy ko le yi , richylaw lo pada de o, ti iwo ba fe ba mi soro o le e pade mi lori oju iwe ayarabi asa ate ka iseabe@yahoo.com
Nite Angel (m)
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here!
« #263 on: May 25, 2007, 12:07 AM »

Richylaw,
Ki l'on mu ni Glasgow. Awon ogboju babalawo nwa e o.

E ranti lati ko awon omo yin ni ede yi o, bi be ko, ogun odun si igba ta wa yi be bere iru okun bayi e ni r'eiye,
segoye2 (m)
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here!
« #264 on: May 25, 2007, 12:10 AM »

ha ha ahaha Mo san bu so sile ni shala shala,  si oro si Nite Angel n so.

Babalawo tuntun,  ese sir, bawo lese le ran mi lowo oooo,  ani, e so fun mi sir. e sa mo ohun ti mo n wa, ki ni etu tu ooo?
richylaw (m)
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here!
« #265 on: May 25, 2007, 12:13 AM »

Quote from: minute on May 25, 2007, 12:03 AM
now oye mi wayii.on pofo right? ebi e ko,aini se se lofa.

ki lode ti o wa n ri mi fin, igba  wo ni mo wa di alaini ise si o bayi? dakun je ki a fi ala si ori ile o. Gbogbo ni a ni ise, ayo ede la nyo ni bi o.
Quote from: Nite Angel on May 25, 2007, 12:07 AM
Richylaw,
Ki l'on mu ni Glasgow. Awon ogboju babalawo nwa e o.

E ranti lati ko awon omo yin ni ede yi o, bi be ko, ogun odun si igba ta wa yi be bere iru okun bayi e ni r'eiye,

Arabintin Angeli abiye fo  lowo ale
O didan ki omo temi gbo ede abinibi mi o. Glasgow ti mo wa yi, ise aje lo gbe omo re igberi okun o. O si didan kin kere dele. Ajo ki dun kodidere ma re Iwo, Odi dandan  ki aja o pada ja. Mo ja ewe mose awo ki n to wa o, nitorina won ko lee see ma a wa mi.
richylaw (m)
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here!
« #266 on: May 25, 2007, 12:16 AM »

segoye, emi ki ise babalawo titun, eniti o ti n se ogun re lati igba iwase wa ni o. Nje iwo ti se awon etutu ti mo ni ki o lo se ni aso rock , tabi iwaju ile iya charlie, tabi ile funfun ni amerika?
minute (f)
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here!
« #267 on: May 25, 2007, 12:18 AM »

okay okay donot be pissed okay? mabinu o sogbo?
ayo ede len"yo? odun mi pe mio leso yoruba bio sen so yen,oju den timi pe ibadan nimotiwa,can u imagine?
omobadan ti yoruba odanmoran lenue?
richylaw (m)
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here!
« #268 on: May 25, 2007, 12:23 AM »

Quote from: minute on May 25, 2007, 12:18 AM
okay okay donot be pissed okay? mabinu o sogbo?
ayo ede len"yo? odun mi pe mio leso yoruba bio sen so yen,oju den timi pe ibadan nimotiwa,can u imagine?
omobadan ti yoruba odanmoran lenue?

ha a  Minute (iseju) ara ile ti wa ja o.Omo ibadan ni iya ti o bi mi lomo. (Ki oluwa ki o fi orun kee)
It's good you do appreciate your cultural heritage and indigenous source ride on babe.

ibadan mesi ogo
Ibadan maja maja
omo ajigun ja lehin olohun
omo afi kara hun fori mu
Oluyole , oloke kan obanta
oloke giriwo obanta

minute bi o ba n fe oluko ti o gbona jingiri ninu ede mo le e ma a ko o lori ero ayara bi asa o LOL
Nite Angel (m)
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here!
« #269 on: May 25, 2007, 12:37 AM »

Awo Richylaw,
Be ba so'lu Minute bo se gbona yi a jo rau rau. E ma ni lati f'omi la ni o, bi o je be ede ko le ma ko o
minute (f)
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here!
« #270 on: May 25, 2007, 12:40 AM »

lol. se omoye iseju tio gbami lati kaa nkan tio type yen shaa?

inu mi adun timo ba le ri eniti ama ko mi,tio bati ni si nkan mi leyin e, tori wipe erin e yen Undecided Undecided Undecided

but mio bad sha? mon try right?

richylaw (m)
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here!
« #271 on: May 25, 2007, 12:43 AM »

Quote from: Nite Angel on May 25, 2007, 12:37 AM
Awo Richylaw,
Be ba so'lu Minute bo se gbona yi a jo rau rau. E ma ni lati f'omi la ni o, bi o je be ede ko le ma ko o

Omo awo Angeli abiye fo owo alale
O ku u la a kaye , aye kan o ni ri o gbese o. Emi na ti n ro be e.

Egbo na eyin ara nairaland arakunrin ti o pe ara re ni SATAN ni oju ewe kerin ijiroro yi nko. Eru ba , o ti siyan la i duro gbobe. Omo ole Grin Grin Grin Grin Grin
richylaw (m)
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here!
« #272 on: May 25, 2007, 12:50 AM »

Quote from: minute on May 25, 2007, 12:40 AM
lol. se omoye iseju tio gbami lati kaa nkan tio type yen shaa?

inu mi adun timo ba le ri eniti ama ko mi,tio bati ni si nkan mi leyin e, tori wipe erin e yen Undecided Undecided Undecided

but mio bad sha? mon try right?

Omidan iseju, emi ki se adagba  ma la be o, mo mo wipe eru n ba o ni wipe ki babablawo ma da enu ife ko e Grin, sugbon emi ko ni  ti igba kan bo ikan ninu o. Sebi ori ero ayara bi asa ni o ti ma gba eko,bawo  ni n kan miran se fe yo lehin re, eyi ma tun ko mi lomi nu o. O da mi loju wipe ti a ba n sunkun a ma riran sha. Bi o ba feran ede re ti o si fe ko si ko iwe simi lori  iseabe@yahoo.com
minute (f)
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here!
« #273 on: May 25, 2007, 01:00 AM »

eru tani onbami?

lord you are so good.

emiko ni ti igba kan bokan nini-
eyi matun kan mi lomi nu o,i love your choice of words dude!

sofunmi ibo logbe dagba?
Nite Angel (m)
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here!
« #274 on: May 25, 2007, 01:07 AM »

Gb'omo fo'mu, gb'omu fo'mo. Oju alejo lati je gbese ehin e lati san. A ni si lori ero ayara bi asa yen o, sugbon iroyin eko na a kan wa,  Omo le'we ka'we e. Oluko gbiyanju koo ko daa daa. E maa ya'se
obo_nyunmi (f)
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here!
« #275 on: May 25, 2007, 01:10 AM »

ki le ri so o.
minute (f)
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here!
« #276 on: May 25, 2007, 01:20 AM »

obo nyunmi? lol *sighs*
 what a name!
 i"d better run along now.
odabo o gbogbo eyin ara ile. Smiley Smiley Smiley
 
hmmm@ richylaw, she ogbadun shaa?
richylaw (m)
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here!
« #277 on: May 25, 2007, 01:24 AM »

Quote from: minute on May 25, 2007, 01:00 AM
eru tani onbami?

lord you are so good.

emiko ni ti igba kan bokan nini-
eyi matun kan mi lomi nu o,i love your choice of words dude!

sofunmi ibo logbe dagba?
omidan iseju, awon agba bo won ni "ti han ti han o beyin, beyin ba se meji ,ko fo egungun ki o si funfun
Oju awo(plate) temi , lawo fi n gbobe.
A bi mi si orilede Naijira, mo si ka eko alakobere , girama ati iwe giga apakini ni orile ede naijiria. Ma je ki imo yoruba mi tan o je, awon obi mi mejeeji ko tile kawe ni orile ede naijiria rara , Ilu eko ni mo dagba si ni eti erekusu. Omo ajebota si ni awon kan a ma pe mi. Emi ti o si n ka oro mi yi ko le e ko ede yoruba tabi so daadaa titi ti mo fi bere girama , eyi ti ise F.G.C, Ilu oba ni mo si ti gba iwe eri eko giga apa keji ninu imo ise ayaworan ile ati agbekale re (architecture) . Nitorina ibi ti a gbe dagba ko ni yio fi ona ati gbo ede han.Mo fi da o loju wipe bi yoruba mi se ri ni ede oyinbo mi si ri pelu.
richylaw (m)
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here!
« #278 on: May 25, 2007, 01:36 AM »

Minute
hmmm@ richylaw, she ogbadun shaa?

Mo wa pa, mo si duro digbidigbi. LOL
smile4kenn (m)
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here!
« #279 on: May 25, 2007, 06:16 AM »

Awon omo yoruba. Omo Uche ni mi. Mo ki ooooooh. Eku Nairaland.   

Yoruba ni mo so ni asia.  Mo ki OOOO

Omo nna   
mishoo (m)
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here!
« #280 on: May 25, 2007, 07:27 AM »

Ekaro ninu ile yi oo!! E ee jire bi? Ejo e bami wa @richylaw  lo o. Omo na gbona !! Amon enu agba ni obi ti ndun haun!! E so be fun !! E ni ko se iba fun agba ko to ma ba agba jeun oo. Awon ofo to pa si oju iwe keje yen ti po ju ojo ori re lo.
  Huh Huh Abi omo awo ni ise ni?? Huh Huh
mishoo (m)
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here!
« #281 on: May 25, 2007, 07:29 AM »

Quote from: smile4kenn on May 25, 2007, 06:16 AM
Awon omo yoruba. Omo Uche ni mi. Mo ki ooooooh. Eku Nairaland.

Yoruba ni mo so ni asia. Mo ki OOOO

Omo nna
omo ibo, kaabo. Aje okuta ma mumi !! pele !1 se o fe kako e ni ede ni abi kilo wa wa oo??? Cool Cool Cool
PrincessM (f)
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here!
« #282 on: May 25, 2007, 08:58 AM »

orisirisi!
candy (f)
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here!
« #283 on: May 25, 2007, 09:29 AM »

orisirisi aborisirisi! Kini n kan gan an to n sele ni bi? se ka kan maa so yoruba to ba wa senu wa ni abi o ni nkan ti a n soro le lori? e laa yemi o,alejo ni mi. Huh
richylaw (m)
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here!
« #284 on: May 25, 2007, 09:31 AM »

Quote from: mishoo on May 25, 2007, 07:27 AM
Ekaro ninu ile yi oo!! E ee jire bi? Ejo e bami wa @richylaw lo o. Omo na gbona !! Amon enu agba ni obi ti ndun haun!! E so be fun !! E ni ko se iba fun agba ko to ma ba agba jeun oo. Awon ofo to pa si oju iwe keje yen ti po ju ojo ori re lo.
 Huh Huh Abi omo awo ni ise ni?? Huh Huh

Leekan si fun anfani ohun ti iwo fe ri.

Iba akoda o
iba aseda
iba origun mereerin agbaye
to fidi sole ti o ro.
Iba awon to tiwa ki n to ma be.
ewure ile o juba o di eran amuso
aguntan ile o juba , o di eran amusin
mo  juba eni iwaju loni o
e ma je ko hun mi.
ASE WA!

Alagba Mishoo,
E ku ojumo o ara o le bi?  Mo si ki yin lee kan si, si ori ijiroro yi. Mo fe ki e mo wipe ayaju si agba ki i to agba. E mi ki i se omo oodua ti ko mo eto (obligations) o. Awon agba ti fa mi mo ra, efo odu temi ki i si se aimo fun oloko. Emi ki i se ayaju si ara iwaju o. Mo ti fi owo fun awon agba, won ko mi bi a se n fowo , mo fowo mi mo tan ni mo ba ta kete ti mo si n ba agba je o.
(Awon ofo to pa si oju iwe keje yen ti po ju ojo ori re lo) Nje e ti le mo  ojo ori mi ni,
Mo fe ki e mo wipe ojo ori ko lagba rara , a tete de be si ko ni atete dara fun o.Eni to ba yara logun gbe.
Laise ani ani o dabi eni wipe mo ti yan na na gbogbo ikilo tabi ibeere yin fun yin. Bi e ba si tunn pada sehin die lati ka gbogbo oun ti mo ti ko sehin ninu okun ijiroro yi , e o ri daju wipe ko si oro iyaju kankan, tabi isokuso , tabi oro alufansa o, eyin ni ki e kago ki e to wo ile o .

Nitorina mo ti di eegun  ile loni o
Emi ki i se eni a  n gba loju
Mo ti di  afin ile loni , emi ki i se eni an ti laya,
Arigini aringini , aringinigini woja loruko a n pe,  Grin Grin Grin

Do not be afraid , our God is real
richylaw (m)
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here!
« #285 on: May 25, 2007, 09:40 AM »

Posted by: candy  

orisirisi aborisirisi! Kini n kan gan an to n sele ni bi? se ka kan maa so yoruba to ba wa senu wa ni abi o ni nkan ti a n soro le lori? e laa yemi o,alejo ni mi.  

Arabinrin Adun (Candy)

Bi awon akegbe mi yio ba gbami laaye lati je agbenuso lori okun ijiroro yi,     Mo fe fi asiko yi kiyin  ku abo si ori eto  o. Ewa ede ati asa ibile wa ni ohun ti a ngbe laruge ni ogbun okun ijiroro ti eleyi. Bi o ti le je wipe opo ti ko "orisirisi" gege bii iwo na ti se ri,sugbon emi yio fe ki o mo wipe gbogbo edo fini ohun gbogbo ti o n sele ni duniyan ni a le jiroro ni pa re ni ibi yi. O bere lati ori ere idaraya, irohin , Oselu, imoran fun loko laya ni ede abinibi wa ati bebe lo.E tu ra ka lati da si oro na  If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here!
ronnie-slimz (f)
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here!
« #286 on: May 25, 2007, 11:09 AM »

nigbawo ni e bere thread yi ti emi omo nipa re Huh sugbon sa ohun gbogbo nsisefun rere. . eku ile eyin omo ile karo ojire, esi ku dede iwoyi oo. . se dada nimo bayin? Grin Grin
haywhy (m)
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here!
« #287 on: May 25, 2007, 11:22 AM »

Richy law, mo n gbadun awon ikaramasiki to lamilaaka ti o se si oke yen, Ko ni bu o lapa ooooooo! Yoo si ma ju oo se!

Richy law ooooooo
Itun lo ni ki won fi oun rere tun e she
Ifa loni ki won fi oun rere fa e wo
Abeere loni ki won fi oun rere beere re wo
Tigi tope ni ishe anu afomo
Omo araye o ma she anu ee
Awon araye aje ki ori tire she oooo
 Igbo Kwenu ! Kwenu Kwezo Nu ! Join Us If You Proud To Be An Igbo Guy/lady  Page 2
Pages: (1) ... (3) (4) (5) (6) (7) (8) (9) (10) (11) (12) (13) (14) (15) ... (141) Go Up Send Topic to Friend by E-mail Reply 
Google
 
Web www.nairaland.com
Sections: TV/Movies (2) Music/Radio (2) Celebrities Jobs (2) Career Romance Books Politics Sports Fashion Travel
Health Schooling Religion General(2) Business Webmaster Programming Computers Phones Cars & Trucks

Links: Page1 Page2 Page3 Page4 Page5 Page6 Page7 Page8 Page9 Page10

Nairaland is owned by Oluwaseun Osewa
Nairaland Forum | Powered by SMF 1.0.12.
© 2001-2005, Lewis Media. All Rights Reserved.