If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here!

A Member? Please Login  
type your username and password to login
Date: July 24, 2008, 07:34 AM
223036 members and 126524 Topics
Latest Member: DwergoFew
Nairaland [Nigerian Forum] Home Help Search Who is currently online? Login Register
Nairaland Forum  |  General Discussion  |  Culture  |  If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here!
Pages: (1) ... (117) (118) (119) (120) (121) (122) (123) (124) (125) (126) (127) (128) (129) ... (141) Go Down Send this topic Notify of replies
Author Topic: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here!  (Read 31655 views)
mafolayomi (f)
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here!
« #3904 on: December 31, 2007, 01:48 PM »

Aku odun oooooooooo gbogbo wa, ase yi se eemi toko taya tomotomo bi ewa ooooooooooo, awa tia se odun yi ni ao se eemi pelu ara lile oooooooooo
richylaw (m)
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here!
« #3905 on: January 03, 2008, 12:44 PM »

ADURA ODUN TUNTUN 2008
(Singing)
Oun ti mo wi aaro a ro mo, hen a hen /2x
Ka l’owo l’owo
Ka kole mole
Hen a hen ,

Mo ki kekere ile o
Mo ki eyin agba popo  ti n be ninu imo oro
Mo ki ologbon ti n mu ogbon se ohun ogbon
Mo ki onimo to n mu imo se ohun imo
Mo ki ara iwa ti n lo geregere ti o ni f’ese ko
Mo ki ero eyin ti n bo ginigini ti o si ni d’eni awa ti
Mo ki gbogbo oloye (the wise) ti a jo la odun to koja ja
Ani mo ki gbogbo eniyan loke erupe ti a jo ri odun titun
Ninu odun yi a o ni ta wo na o
A o ni taraka o
Ile o ni gbona mo wa o
Ona o ni na wa
Ka ro wo s’aye
A o ni je eegun gbehin eran o
Odun ayo , odun idunu
Odun owo, odun omo
Omoge to n w’oko ari , odomokunrin to n w’aya a ri o
Awon to ti ni ko ni fi oju sunkun o
Iwaju lopa ebiti n re si o
Ilu yi o ni daru o
Nairaland o ni di ohun igbagbe o
Orile ede Naijiria a gun rege o
Omori igba kii ri idi joko
Gbogbo ojelu , alaparutu, afarannu ba ohun to dun je, eletekete, onisekuse,ole, abinu eni
Ati gbogbo oniyangi to fe d‘oju ti elepo, ati elepo paapaa to fe d’oju ti alala
Awon alale a se won m’ose fun gbogbo wa ninu odun yi o.
ASEEEEEEEE!!!!
Segoye o ku ojo meta, lo ba di firifiri, a dara ki n gba nomba ibanisoro  re wayi o nitori wipe eni ti a o fe ni ile re njinna
Dr Ferlie, mo ri bi o se n se aayun mi,sugbon bi a ba mu ipin kuro loju, a ma n fi han oju ni o, gbogbo ohun ti o n wi kiri laarin ilu ni mo kuku n gbo , sugbon ninu re o mo wipe otito kan ko si ni be. Baale o gba iyawo oloye kankan o, Desorlah n be,Oloye Segoye na n be o, Baale Richylaw  o si lo si ewon rara o.Mo wa ni alaafia ara mi l’aafin o. Koko lara ota n le, bi a ba pe a o mu oni ola la n mu o.
Tafari , Disguy, Ikamefa, Mishoo,Iya aje ati ojiji re ‘Wunmi! , Nana,Minutes, Omoge ati gbogbo oju titun ti n be ni lu mo ki yin o.
B’ojo  ba yo a kari aye , a la kanle ni t’osumare , oto logo orun , oto logo  osupa o. Aye o ni ri Irawo wa ju si omi o
ASEEEEEEE!!!   
Richylaw
Baale Yoruba Thread
segoye2 (m)
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here!
« #3906 on: January 03, 2008, 06:42 PM »

Eku odun tuntun yi ooo. Ire wa ninu odun yi yio wa wa ri oooo,

baale eseun wa ooo, ma ma fi ero ibani soro mi sowo siyin ni owuro ola.

CHEERS for 2008
DIAMONDAY (m)
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here!
« #3907 on: January 04, 2008, 03:03 PM »

eyi ga lagaju, awon omodey wonyi,  won o ti e le rara,  elomiran a si so ede abinibi re bi eni wipe ayalo ede lon so,  nigbati opolopo ninu yin ko le so ede abinibi re, bawo ni WAEC shey ma fun ni English, eleyi ti o je ede elede,  awon oloyinbo ani Son Chipa Mother n carry,  eyi ti o tumo si pe,  omo to ba ship ni iya re ngbe,  e gbiyanju lati mo eyi ti o se koko ninu ede abinibi yin,

ire oooo
replenish (f)
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here!
« #3908 on: January 05, 2008, 04:38 PM »

a ku odun titun o, odun ayo ni odun yi ma je fun gbogbo wa o
Mustay (m)
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here!
« #3909 on: January 05, 2008, 11:33 PM »

o pe ti mo de tiredi yi o Cool
proxies (m)
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here!
« #3910 on: January 09, 2008, 06:22 PM »

O ga fun gbogbo yin o. se yoruba naa le n so be nipe e ya were ba yi,  ko yami lenu fun yin o. ai nise se lo n damu gbogbo yin, e ma lo wa se se
supercunt (m)
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here!
« #3911 on: January 09, 2008, 07:32 PM »

E ku ewu odun o,odun a ya obo abo fun wa o Grin
top_kin (m)
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here!
« #3912 on: January 09, 2008, 07:55 PM »

Mi o de tiredi yi rii o. E le yi akoko ti mo ma de'biyi. Eyin eyan mi bawo ni o?

Odun yi a tura ko ni le koko mo wa o
Ohu ti a ba wa la ma ri o
Olorun a pa wa mo titi di odun to tun bo o. Amin, amin, amin lo'ruko Jesu. Amin!!!  Grin
Dis Guy
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here!
« #3913 on: January 10, 2008, 01:59 AM »

talo fe shey party, awa egbe nairalandi ka mu asho ebi
fun party ni ijebu ode  Cheesy
supercunt (m)
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here!
« #3914 on: January 15, 2008, 05:51 PM »

ole o fe ka dawo aso ko gbewa lowo salo Grin Grin
e wo eyin fellow nairalanders emi ni ki e dawo aso ebi yin fun o,its just #25,000=00 for five yards,eyin okunrin ma ra fila #2000=00 while tawon obirin ma san #3000=00 naira fun gele ati ipele won
meanwhile mo ki gbogbo wa pe a ku odun o,
odun yi a ya obo abo fun wa o Grin Grin
tosinadeda (m)
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here!
« #3915 on: January 16, 2008, 12:38 AM »

AWON OSOMO GBOMO TIA
AWON OSOMO GBOMO GBIN
TO BA WUNMI MO LE GBA TOKYO LO OOOO
TO BA WUNMI MO FE LO JAMAICA  OOOOOOOO
tosinadeda (m)
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here!
« #3916 on: January 16, 2008, 12:42 AM »

OTI SU MI FUN ORO NAIJA YI O, INA A NI, OMI KO SI, ISE OSE SE.
KI GAN GAN LANI TA FE LO DA NI NAIJA?
EHN
BABA LO TUN LO NAAA IYAWO OMO RE LEGBA!!!!!!!!!!! SE E LE IMAGINE KI BABA BI 80 MA NAAA IYAWO OMO RE LEGBA?
EMI O SO WIPI OBASANJO NI O, MO KAN NI BABA NI, KI E MA LO KOBA MI, TORI MO GBO PE OLOOGUN NI BABA YEN,NPE OGBBOLOGBO NI
trukoments (m)
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here!
« #3917 on: January 16, 2008, 02:23 PM »

e o jii re bi eyin omo kaaro o'jiire,mo ki yin t'eso t'eso,mo ki yin t'ologun t'ologun,emi ni t'emi ni t'iyin ademola:akiti gbon won se bi obo o gbon,obo gbon t'inu obo l'obo n se, afa'i bawonja won n binu ija ilara ko tan boroboro.emi naa ni forosikun bi agba,agba o si nilu ilu baje baale ile ku ile d'ahoro.
afefe ire a felu wa o,ase!
Dr Ferlie (m)
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here!
« #3918 on: February 05, 2008, 05:16 PM »

eyin omo oodua, this thread must not die. ki lo de? baale e ku ijo meta oooooooooo Grin Grin Grin
stranger26 (f)
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here!
« #3919 on: February 06, 2008, 03:47 PM »

Gbogbo eyin omo yoruba mo ki yin o. Se dada ni gbogbo yin wa o? Mo hope pe mo ba yin ni alafiya ati irorun.
Edakun e ma fi yoruba mi se yeye o, mon gbiyanju lati ko ni. Ni oto, ede mi ni sugbon ko si awon yoruba pupo ni univasiti ti mo wa. nitori na mo tin gbagbe gbogbo yoruba ti mo gbo. Iyen o gbudo sele, nitori na mo hope lati wa ma so yoruba ni ibibai kin mafi gbagbe.

Odabo eyin eyan mi.
Dr Ferlie (m)
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here!
« #3920 on: February 06, 2008, 08:07 PM »

kaabo, stranger26. o ku igbiyanju. gbogbo ilu wa ni alaafia. baale ni kin ma ki e oooooooooo.
gege bi omo oodua ko ye ki a gbagbe asa ile wa.
lekansi kaabo si ilu wa Cheesy
stranger26 (f)
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here!
« #3921 on: February 07, 2008, 06:35 AM »

Eseun, dokita. edakun tani baale ilu wa yi? Emabinu pe mi o mo nkankan ni pa awon oloye ilu yi.
Bawo ni e se yan baale ati awon ijoye? Se awon omo idile kan ni won mo je ipo ni abi democracy le se?
Edakun e se alaye o.

Kiko yoruba le gan o! Eku ise gbogbo eyin ti en ri ko.
Dr Ferlie (m)
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here!
« #3922 on: February 07, 2008, 09:25 AM »

Quote from: stranger26 on February 07, 2008, 06:35 AM
Eseun, dokita. edakun tani baale ilu wa yi? Emabinu pe mi o mo nkankan ni pa awon oloye ilu yi.
Bawo ni e se yan baale ati awon ijoye? Se awon omo idile kan ni won mo je ipo ni abi democracy le se?
Edakun e se alaye o.

Kiko yoruba le gan o! Eku ise gbogbo eyin ti en ri ko.

E kaabo lekan si. Oruko Baale ilu wa ni Alagba Richylaw, idile won ni kan ni o le je baale ni ilu wa.
A si ni awon oloye ti o poo, ninu won ni alagba segeoye, debosky, iyalaje ikamefa, ati beebee lo.
Ti baale ba pada si aafin, ao jolo ki won, won a si fi yin han fun gbogbo ilu.
 Cheesy Cheesy
 
FunmyKemmy (f)
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here!
« #3923 on: February 07, 2008, 12:34 PM »

E ku atijo gbogbo yin oooooooooooooooooooooo.
Dr Ferlie (m)
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here!
« #3924 on: February 07, 2008, 03:19 PM »

Quote from: FunmyKemmy on February 07, 2008, 12:34 PM
E ku atijo gbogbo yin oooooooooooooooooooooo.

e pele arabinrin funmykemmy. se daadaa ni?
segoye2 (m)
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here!
« #3925 on: February 10, 2008, 04:52 PM »

Baale, Eseun Wa ooo,  Koda Inu mi dunpe e wa ni alafia. Egbon mi lo fun ise abe orun (neck surgery) lo fa ti mi o fi wa si ori threadi yi. Koda, opelope olorun ati ati lehin Aya mi.

Eyin alejo ninu ilu wa, e kabo ooo,  niwon igba ti o ti je wipe ewa bawa yo ni ori threadi yi, ayo eyin ni ko ni baje ooo, ogo olorun yio ma wa yin ri. Gbogbo awon ari Ogo, Ba Ogo je koni ni agbara lori Ogo wa ooo. Amin.

Baale, e fun mi ni addressi yin lori alantakun kin bale so ero abani soro mi sinu re.

Mo nife gbogbo yin ooooo,

Emi ni tiyin tooto,

Oloye Segoye2 ati Desorlah
Abo ba Jiro of Nairaland.
fellybabe (f)
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here!
« #3926 on: February 10, 2008, 11:56 PM »

 Eku atijo, se dada ni? se alafia le wa, gbogbo ile nko o?



fellybabe  oluwaseun omo ti a fi oja aran pon lon ki yin oooooooooooooooooooo
ayanjide (m)
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here!
« #3927 on: February 11, 2008, 09:47 AM »

e ku ojumo, e ku ojumo. Aa jii re bi? o je ohun ayo fun mi lati mo wipe okun yi ko i tii parun. Gbogbo omo yoruba, e kuu ko le da ti gbogbo wa n ba kiri
ODUA A GBEWA O. RICHYLAW, eniyan mi atata, o pe ti mo ri n kan ka lat'odo yin o. Kaa si n kan bi? BOLORUNFEMI, ara o le bi? okan mi n saferii yin o. o wun mi lati ka akosile yin lori okun yi sugbon mi o rii. Oba edumare aa so agbara d'otun o
stranger26 (f)
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here!
« #3928 on: February 14, 2008, 04:04 PM »

Eku ijo meta eyin eyan mi. Awon Yoruba ma won ni Nairaland yi o. Ibo ni gbogbo won wa ti won o le wa ko oro diye si inu okun yi? Abi ko si awon Yoruba pupo ni ibibai ni? Ibo ni gbogbo won sa pa mo si?

Mo kan ni kin ki yin ni o. E toju ara yin (is that how you say "take care"?)
Fileki (f)
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here!
« #3929 on: February 15, 2008, 05:02 PM »

Sranger 26, o gbiyanju. . . sugbon lojo miran o le so wipe: e se jeje o.
eyin temi , a ku odun ayajo ololufe ana o. e je ki ife ti ko ni etan ninu ki o ma bawa gbe o.
ati wipe e wa o, se ko si oye ni inu ilu wa yi mon ni? emi fe je oye o, looto ilesanmi dun joye lo amo mo fe wa lara awon amulu t'oro ilu wa yi, mo fe dije fun ipo oye '' iyalode'' ti ilu wa yi.  e se, lekan si, a ku ayajo odun ololufe o.

e se jeje.

ire o
Dr Ferlie (m)
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here!
« #3930 on: February 15, 2008, 08:51 PM »

Quote from: Fileki on February 15, 2008, 05:02 PM
Sranger 26, o gbiyanju. . . sugbon lojo miran o le so wipe: e se jeje o.
 eyin temi , a ku odun ayajo ololufe ana o. e je ki ife ti ko ni etan ninu ki o ma bawa gbe o.
ati wipe e wa o, se ko si oye ni inu ilu wa yi mon ni? emi fe je oye o, looto ilesanmi dun joye lo amo mo fe wa lara awon amulu t'oro ilu wa yi, mo fe dije fun ipo oye '' iyalode'' ti ilu wa yi. e se, lekan si, a ku ayajo odun ololufe o.

e se jeje.

ire o

Arabinrin Fileki,

a ku odun ayajo ololufe ti o koja ni ana. ti odun to nbo a bawa laye o. ase.
nipa ti oro oye ilu wa yi, ipo iyalode ko ti si sile.
sugbon gege bi ASIWAJU ilu yii, ma ba baale soro lori oro oye re.

Ise ati awon molebi nko?  se daadaa ni won wa.

 
babs787 (m)
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here!
« #3931 on: February 16, 2008, 02:38 PM »

E ku ise eyin eniyan mi o, Se alaafia ni gbogbo yin wa. E ku ijo meta o. Olorun yio ma pa alo ati abo yin mo.

Emi ko tete mo wipe iru nkan bayi nlo ni ibi yio. Olorun yio ma wa pelu yin bi e  se fe maa gbe ede wa laruge o.

O dabo o
Dr Ferlie (m)
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here!
« #3932 on: February 16, 2008, 07:44 PM »

Quote from: babs787 on February 16, 2008, 02:38 PM
E ku ise eyin eniyan mi o, Se alaafia ni gbogbo yin wa. E ku ijo meta o. Olorun yio ma pa alo ati abo yin mo.

Emi ko tete mo wipe iru nkan bayi nlo ni ibi yio. Olorun yio ma wa pelu yin bi e se fe maa gbe ede wa laruge o.

O dabo o

kaabo si ilu awa omo yoruba. oodua a gbe o o.

 
top_kin (m)
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here!
« #3933 on: February 18, 2008, 03:21 PM »

E'nle ni bee o!  Grin
richylaw (m)
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here!
« #3934 on: February 18, 2008, 04:05 PM »

Ara ile se ba o ni de , a n bo o
Ire taa ko lona lo je a pe.

Mo ki kekere ile o
Mo ki gbogbo agbagba beleje o, Gbogbo odo-langba ode iwoyi mo ki yin o
Omidan ilu mo ki yin o
Adelebo ilu, mo ki yin o
Mojesin ilu moki yin o
borokini ilu , mo ki yin o
Mekunnu ilu, mo ki yin o
Mo ki gbogbo eso
mo ki gbogbo ologun
mo ki gbogbo oloye,
mo ki oselu
mo ki ojelu

Ki akoda aye  je ko ma ju wa a se o, a o ni ta wo na o, a o si ni taraka o. Nibi won ba  gbe n lu ilu ayo, ese wa o ni ko ijo nibe o.
Gudugudu l’oba  awon omele, wonsi-wonsi l’oba awon sekere, Ilu kan bayi ti o ba ni saworo kii se ilu rara. Okun Yoruba a ma layo ni o. Ilu o ni t u mo wa lori o. Ase.
Dr Ferlie , Asiwaju Okun Oro Yoruba ti Ile Nairaland, e ku a mu le dani o. Inu mi dun si akitiyan re o, wa a ma ri ba ti se o Ase, (ran mi leti o ye ki n le ba o wa isare ile lona Ogun gege bii ebun ranpe lati owo bale o),
Laisi ani-ani Stranger 26 ti n fi ara mo ile lehin ti Dr Ferlie ti yanana asa ati ise awa ti Okun oro Yoruba ti Nairaland fun.
Ayanjide, ore mi pataki Pataki, bi gbogbo nairaland ba rin ninu mi won o ni kose nitori re. O ku ayesi mi lojo ibi mi  ti o koja, ipe re jo mi loju , o bu iyi kun  mi, o si tun  se apehan oriki ti ORE nje. A o pe fun ara wa o, ire bayi na ni a o ma ba ara wa se.
Segoye, abobajiro mi , se eku n dun bi eku o, se eye na si n dun bi eye. Ki Eledua ki o ba wa fun egbon re ni alaafia ti o peye o. O tobi gigigidi ni owo mi o , a o si ni te lowo  ara. Adiresi ayara bi asa mi n be loju ewe idanimo mi (profile), Inu mi yio si dun lati ri iwe re o.
Gbogbo oju titun, Stranger26,Fileki ati awon bebe lo, aaya ti bee le o fe sare o, e gbaradi fun ekunrere ede abinibi baba nla baba wa ti ko ni amulumola Kankan ninu, inu eyin na yio si dun wipe e darapo mowa.
Kanakan ti na omo re o desin , ija nbo , ija ko i de, sebi awifunni koto dani iyen gangan lagba ijakadi.
Awodi Baale lo re ye, won sebi eye ti ku, o sewo a kii gba abata lowo akiti, a kii gba ile baba eni lowo eni
Ope o ku o, e wo moriwo ope to n tu turu yeye turu yeye lorun ope
IRE. IRE KABITI

Richylaw
Baale Okun Oro Yoruba
richylaw (m)
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here!
« #3935 on: February 18, 2008, 04:07 PM »

Quote from: top_kin on February 18, 2008, 03:21 PM
E'nle ni bee o! Grin
E ku abo si ori eto yi o, Baale Richylaw  lo se yin ni pele pele o
 Igbo Kwenu ! Kwenu Kwezo Nu ! Join Us If You Proud To Be An Igbo Guy/lady  Page 2
Pages: (1) ... (117) (118) (119) (120) (121) (122) (123) (124) (125) (126) (127) (128) (129) ... (141) Go Up Send Topic to Friend by E-mail Reply 
Google
 
Web www.nairaland.com
Sections: TV/Movies (2) Music/Radio (2) Celebrities Jobs (2) Career Romance Books Politics Sports Fashion Travel
Health Schooling Religion General(2) Business Webmaster Programming Computers Phones Cars & Trucks

Links: Page1 Page2 Page3 Page4 Page5 Page6 Page7 Page8 Page9 Page10

Nairaland is owned by Oluwaseun Osewa
Nairaland Forum | Powered by SMF 1.0.12.
© 2001-2005, Lewis Media. All Rights Reserved.