Welcome, Guest: Register On Nairaland / LOGIN! / Trending / Recent / New
Stats: 3,148,898 members, 7,802,892 topics. Date: Saturday, 20 April 2024 at 02:02 AM

Yoruba Homosapiens History Written By My Grandfather - Religion (2) - Nairaland

Nairaland Forum / Nairaland / General / Religion / Yoruba Homosapiens History Written By My Grandfather (2860 Views)

Book Of Light: Great War Between Homosapiens And Anakhims Of 20fts / Lifecreation Api: Programming Human Species & HomoSapiens Kill Switch- End Time / My Grandfather Was A Native Doctor: Is The Generational Curse Phenomenon True? (2) (3) (4)

(1) (2) (Reply) (Go Down)

Re: Yoruba Homosapiens History Written By My Grandfather by MysteryFinder: 2:29pm On Sep 22, 2020
My phone was having fault, I just fixed it yesterday.

2 Likes

Re: Yoruba Homosapiens History Written By My Grandfather by MysteryFinder: 2:29pm On Sep 22, 2020
ORI KEFA
Nígbànáà ni Odùduwà, Òrìsànlá ati Yemoja gbà láti so àwon omo ìkókó méta náà ní orúko. Won si so oruko ikini ni Olokun. Ekeji ni won si so ni Olosa. Won si so eketa ni Oba. Awon oruko wonyin ni won so won gege bi awon oruko ti orisirisi omi nje.
Nigbana Yeye Aye fohun wipe, "Eyin ara ilu Ile-Ifesi, ilu ogbon, ilu imo ati oye. Ilu owo ti a ti n se ara eni losusu owo. E maa se rere nitori wipe ore lo pe. Ika ko suwon. Iwapele ni n soni di eniyan eye. E fohun ati imo sokun ki e fowo sanya se oun gbogbo."
"Ti enikeni ninu yin ba ko ijamba, e ma se daa da oun nikan. Sugbon ki e gbaruku ti i, ki e si se itoju re. E no sigbo ki e ka eso repete fun ojo iwaju. Sise ole ko dara, ka sun ka maa fa lala ki i se iwuwasi omo Oduduwa."
"Iwa imele ki i se iwa akinkanju. E ma se se ole. E gbera ki e ko eso jo, gbogbo eyin akesojo. E gbera ki e se ode, gbogbo eyin asode. Eyin afowo tu koriko, e ma se gbeyin."
"Eyin ti e n fi ojojumo ronu bi e o se se awari ohun tuntun, e ma se imele. Eyin ti e n gbe koto, e ma sun. Eyin ti e si n wa ewe ati egbo fun iwosan awon alaisan, e ma gbeyin."
"Emi ni n mbe ninu ilè? Awon oun meremere ni mbe ninu ile. Oogun ara yin si ni e le fi wa won jade. Kini mbe loju lofurufu? Afefe alaafia, imole ati imo ni mbe loju ofurufu. Ologbon ni n se iwadi ohun gbogbo."
"Emi ni mbe ninu ibu? Emi ni n be ninu ibu. Emi Yeye Aye ti fi ibu se ibugbe ninu aye lailai. Mo ti fi oun abemi se ara ati iru mi."
"Aye n mi, emi si ni eemi aye. Oun abemi ni aye, emi si ni ogbodu emi aye. E kora jo, e faperete. E gbo oun ti emi aye n wi bi owiwi."
"Kíni ìdí tí ìyàtò nínú awo se n fa ááwò nínú ayé? Kini idi ti araye se n gbe iró ró ko òdodo sílè? Asiri aye n bo wa tu, sugbon o di ìgbà tí igba lona egberun le ni ogorin to tun le ni igba mewa to tun le ni odun die."
"E ma mikan, e ma foya, nitori wipe oun ti mo wi yi ko le ye enikeni ninu yin, nitori wipe iriri aye se se bere ni. E o i si ti bere ounka iseju aya, iseju, wakati, ojo, osu ati odun nihin."
"Nitorina, oun ti mo n so bayi ko le ye yin. Sugbon n o la a ye Oduduwa toju ba koju, ti a ba ti fi oro jomi toro oro nikoko."
"Nipa omo bibi, mo fi Osun se ayíngbàdo omo bibi fun yin. Agbado ki n sé egungun ayíngbàdo kankan. Nitorina, omo kankan ko ni ku siwaju Osun agbèbi ile Yoruba titi ti Iwo yio fi re ìwàlè àsà."
"Ede Yoruba ti mo n fo yi se ajoji si opolopo eyin ara ile, sugbon o ye awon ara oke yékéyéké. Nitorina, e ma a ko ede yi lati owo awon ara oke, ki e si ma a fi ko awon omo yin."
"Esi o! Ki ni eyi? Ee ti je? Irufe awon omo Yoruba wo leyi ti won ko gbo pa, ti won ko gbo po ninu ede Yoruba? Amo won n gbe oruko Yoruba kari?"
"Ki lo fa yanponyanrin yi? Asiko awon wo niyi? Asiko ti asa ati ede Yoruba n di oun afiseyin bi eegun se n fiso?"
16. Nigba ti Yeye Aye so eyi, awon ara oke pe e si ikoko, won si pon oke lo. Won si so wipe, "Yeye Aye, emi lo de?"
17. Bayii ni Yeye Aye se so wipe, "Emi mi rin irinajo lo si igba ojo iwaju ti o jina rere, oun ti mo si mu no irinajo niyi. Lori ile ti ede Yoruba ti Iwo Oduduwa n fi tosan, toru ko awon ara ile yi, ede ajoji ni yio joba lokan, lahon ati lenu awon omo Yoruba nigbanaa."
Nigba ti Oduduwa gbo eyi, o ta kebe, o si so wipe, "Ka ma ri, iya wa. Ko je je be." Iya si fi erin bonu wipe, "Ko se e yi pada. Oun ti yio sele yio sele"
"Itan iseda aye ti Iwo fi asiko re ronu jinle so fun awon wonyin, nigbana ni yio di alo lasanlasan loju won. Won yio si fi alo lasanlasan ti ile ajoji se itan iseda aye tiwon.
Won yio bowo fun awon orisa oke ti ile ajoji kaka ki won bowo fun awon orisa oke ti ile Yoruba. Won yio yi Itan Olorun Eledumare ti Iwo so fun won pada, won yio si ma a pe Olorun Eledumare ni oruko awon orisa ile ajoji.
Won a ma foribale fun awon orisa ile ajoji nigba ti won yio lero wipe Olorun Eledumare ti Iwo n ko won no awon n foribale fun.
Nigba ti Oduduwa gbo eyi, o figbe ta wipe, " Ki wa ni ona abayo bayii? Ki ni ka se lati gbegi dina oun ti yio sele yi?"
Yeye Aye wipe, "Ko si oun ti iwo le se lati je ki iriri naa ma wa si imuse. Oun ti yio sele ni mo ri, ki n se oun ti o fe sele ti a le gbegi dina ati sele re."
"Amo to ba je wipe oun ti o fe sele ti won si gbegi dina sisele re ni iwo fe gbo, n'o so fun o."
Nigbati Oduduwa beere oun ti o fe sele, sugbon ti won gbegi dina sisele re, Yeye Aye so wipe, "Gege bi mo ti so fun iwo tele, ki i se eyin alawo dudu nikan ni e m be ni orile aye. Awon alawo ti o fara jo funfun ati pupa naa mbe laye."
"Awon eyi naa ko Itan iseda aye tiwon, won si fi ara won jin fun awon Itan naa. Won a ma gbe asa ile won gege bi eyin oju won. Won a si maa se awari ati aridaju oun gbogbo lati fi oun ti n se otito mule."
"Nigba ti asiko Oye Nla si de, awon wonyi fi awon oun ti a n pe ni eewo ti si egbe kan, won si n se awari orisirisi imo. Sugbon awa eniyan dudu fi eewo se ferese idina si imo tuntun."
"O si te wa lorun lati ma a fi eewo se idiwo si nini imo tuntun. Nigbose awon ti won fi asiko to dangajia si sise awari lasiko Oye Nla yi wa lati inu ilu won wa, won si bere si i se akoso awon ile alawo dudu."
"Ede, ironu ati asa ile awon eniyan dudu si yi pada di ti awon eniyan naa. Awon oun wonyi ni emi mi ri gege bi oun ti o fe sele lojo iwaju. E da eewo sile niwonba, bibeko, awon eewo yi ni yio je idiwo si idagbasoke ile yin."

1 Like

Re: Yoruba Homosapiens History Written By My Grandfather by MysteryFinder: 6:02am On Oct 14, 2020
Ori Keje
Laipe ojo, Oduduwa to Yemoja lo, oun si ba a ni ajosepo. Awon eniyan ile naa tesiwaju Latin ma a ba ara won ni ajosepo, amo ko si omo bibi repete laarin won nitori wipe awon ti n di ogbo. Abo meji ni o si bi omo laarin awon ara petele. Ikini bi abo, ekeji si bi ako.
Osun ko bi omo kankan sibe, amo Yemoja tun fi inu se oyun. Oun si bi omo kan ti a si so oruko re ni Erinle. Nigbanaa ni awon ara ile-ife-si se ayeye isomoloruko. Won si so oruko omo naa ni Erinle. Won si pin awon eso ti won ti n ko jopo fun igba pipe laarin ara won.
Leyin igba ti Yemoja ti bimo, Sopona bere ijangbon laarin awon eniyan ile-Ife-si. Oun si ko jale lati ma a fi ewe ati egbo se iwosan. Bayii ni Yeye Aye se to lo, o si so wipe, "Sopona o, Baba Ilu, baba Aye, olu omo ilu ile-Ife-si, eni aponle, eni iyi. Eni ti a gbodo ma a gbe oruko re laruge. Emi lo de ti Iwo ko fe fi ebun Mirofa ti n be ninu re se iwosan fun awon ara ilu re?"
Bayii ni Sopona fohun wipe, "Yeye Aye, eni ti n mi eemi gbogbo aye, emi mo wipe mo wa latoke wa pelu ebun wiwo awon alaisan san. Sugbon awon eniyan oke n fi oju di mi. Won ko fi mi han gege bi i alagbara laarin won. Won n kan oje mi sile da iyanrin bo o. Nje iwo Yeye Aye le so otito fun mi bi?"
Yeye Aye mi ori wipe oun yio so otito. Bayii ni Sopona se so wipe, "So fun mi, ninu eni ti o n so itan ati eni ti o n se iwosan, ewo ni o ye ki a pe ni alagbara julo?"
Bayii ni Yeye Aye wipe, "Olusotan ni awon araye ma a n ri gege bi alagbara julo nitori wipe oro ati ase ti o n ti enu jade ni nipon bi awo erin. Ati wipe iro inu itan a ma a dun gbo ju otito lo. Awon oun ti ko sele a si maa dabi otito leti awon agbotan. Olusotan kan le so nipa bi oun se ni agbara ati wo egberun eniyan san, sugbon ka se e han ni nikan ni ko ni."
"Itan oun ti ko sele a ma a joba lokan awon olugbotan fun
egbeegerun odun. Sugbon eni ti o se iwosan lai ni itan yio di eni igbagbe. Eni ti ko se iwosan kankan le fi oro enu je ki awon olugbotan re ro wipe oun ti se egberun iwosan nigba ti eni ti o fi tosan toru se iwosan le di eni igbagbe nitori oun ko ni ebun isotan."
Nigba ti Sopona gbo eyi, oun pinu lati ma se iwosan kankan mo ni ilu Ile-Ife-si nitori wipe Oduduwa olusotan ni okan gbogbo awon omo ilu n fa si gege bi adari ati alagbara julo. Bayii ni Sopona se rin kuro ni ilu Ile-Ife-si.
Ko pe, ko jina, leyin ti Sopona ti rin kuro ni ilu Ile-Ife-si, arun kan kolu Ile-Ife-si. O si mu ki won se aare. Nigba naa ni won bere si aferi Sopona i se. Odidere si so wipe, bawo ni awa se gba ki Sopona fi ilu sile? Awa ti gbo korin kese, a ko si ni iminu lati ma a wa a kaakiri inu igbe."
Bayii ni Yeye Aye se so wipe, "Sise iwosan ki i se ise enikan soso. Ti enikeni ba si ko lati fi ebun Mirofa ti oun ni se omo ara aye loso, awon miran yio dipo re. Bi enikeni ba ko lati se oun ti o wa ni ikawo re lati de aye lorun, imole Mirofa yio tan si elomiran. Oun yio si wa ona abayo. Nitorina, e ta giri ki e si ronu jinle lati wa oun ti e o fi se iwosan.
Nigba naa ni awon eniyan ilu naa bere si i orisirisi nkan danwo. Won lo oje ara igi danwo. Won korin. Won jijo. Won fi erupe kun ara. Won si sa okuta jo lati wa iwosan fun aare ti o n se won.
Oruko awon eniyan ako petele ti o wa ni Ile-Ife-si ni nigbana ni Akesan, Demurin, Akano, Gbara ati Odedaje. Oruko awon abo naa si ni Oyiboyi, Awero, Amope, Aramide, Iyoosa, Jadesiyi, Perosi ati Mefun.
Oruko awon omo ti a bi si Ile-Ife-si nigbana si n je Olokun, Olosa, Oba, Erinle ti i se awon omo Yemoja, nigba ti Yewa je omo Oyiboyi, Oya si je omo Awero.
Gbara ni o fi erupe ati okuta kekeke wo arun naa san. Oun fi erupe kun ara awon ti o n se aisan, ara won si da laipe ojo. Ko si si enikeni ti o padanu emi re ni Ile-Ife-si.
Nigba ti won fi oro to Yeye Aye leti, oun so wipe, "Gbogbo oun ti n be laye lo ni ipa ati agbara lati se oun kan tabi ekeji. Sugbon mimo oun ti won ni ipa lati se ni oun isoro. Awon ti n se awari oun gbogbo nikan ni won yio si se aseyori ti o joju julo."
"Okuta ni ise tire, bee si ni omi okun ati osa. Iyo ni ise tire, bee si ni afefe ati oniruuru eso. Ewe orisirisi ni ise otooto ti won n se. Be si ni imi eniyan ati ti eranko. Oun gbogbo ti n be laye ni o ni ipa lati se oun kan tabi omiran. Awon ti o se fe awari i se ni won yio di adari aye."

1 Like

Re: Yoruba Homosapiens History Written By My Grandfather by Proanalyst(m): 11:20am On Nov 23, 2020
Bro, @mysteryfinder

Kindly update this thread. I have been refreshing for several weeks.

Thanks.
Re: Yoruba Homosapiens History Written By My Grandfather by MysteryFinder: 4:42am On Nov 24, 2020
Proanalyst:
Bro, @mysteryfinder

Kindly update this thread. I have been refreshing for several weeks.

Thanks.

Thank you sir.
Re: Yoruba Homosapiens History Written By My Grandfather by MysteryFinder: 5:59am On Nov 24, 2020
Ori Kejo
Nigbose, Yeye Aye bere si itan aye to ti re koja i so fun awon eniyan oke. Oun si so fun won wipe, "Aye kan ti wa siwaju eyi ti eyin n ni iriri re nisisiyin. Oorun, osupa, oorun, irawo ati awon oun ti n be ni ofurufu ni awon eda igba naa ti se iwadi won lofintoto ti won si ti mo oun ti o parapo lati di awon oun wonyi.
"Emi ti gbe ninu omi gege bi emi inu omi teletele ri. Mo ti fi iru eja se iru ninu omi osa. Awon orisa igba naa ti jagun segun. Won ti fa gbonmi-si-omi-o-to lori aye fun igba pipe ki won to fi aye sile lo nigba naa. Iseda igba naa fi aaye gba awon iriri meremere ti o foju jo idan pipa, sugbon ni aye ti a wa yi, opolopo oun ti iseda fi aaye gba ni a ti gbe de to bee ge ti o fi je wipe opolopo oun ti yio maa sele nile aye yio je oun ti ara dipo ti emi."
"Sugbon oun ti ara ti araye o ba i ti se awadi finifini yio fi oju jo ti oun emi titi igba ti awon ti o ni imo to ye koro yio tan imole si won."
Nigbana ni Yemoja beere lowo Yeye Aye bi awon se le fi iru eja se iru ki awon le fi wa ninu omi fun igba pipe. Bayii ni Yeye Aye mu eja nla meji ninu osa. Won si ge ori won kuro. Won si fi se aso wo. Yeye Aye si bu iyo pupo sinu eja naa ki o ma ba jera.
Oun ati Yemoja si gbe ara eja wo bi aso. Won a si ma a luwe pelu ara eja naa ninu odo.
Nigba ti awon mejeji si n fi ara eja luwe ni ojo kan, Yemoja beere wipe, "Nje Iwo ti ko awon abo ilu ibomiran ni ogbon wiwo ara eja bi aso bayii?" Yeye Aye si so wipe, "Ilu yi je ilu kejidinlogun ti mo n ko ni etan yi. Kiyesi, awon ti won ko ni imo ijinle nipa bi a se se eyi yio ka a kun oun emi dipo oun ara ati etan ti i se.
Nigba ti Yemoja ba ti wo iru eja naa, awon eniyan a maa to wa si eba odo lati maa bo o. Won a si ma dari adura won fun un. Awon ko si mo bi iru eja naa ti je.
Ko pe, ko jina, Sopona wo inu ilu Ile-Ife-si wa pelu awon olutele meta. Oun si fi ara pamo sinu okuta lati maa fi se ibugbe, sugbon awon olutele re darapo mo awon ara Ile-Ife-si. Won si gba won ni towo tese. Oruko awon olutele naa a si ma je Bulejo, Atijo ati Odole. Ako si ni gbogbo won i se.
Sopona si ti ko won bi won se n fi ewe ati egbo se iwosan. O si ti ko won bi won se le se majele ati oniruuru oun ti o le fa aisan si ago ara.
Awon wonyi si ba awon ara Ile-Ife-si da ore. Won si po majele fun won je. Nigba ti awon ti o je majele naa si wa ni okaka iku, Gbara sa okuta jo lati fi se iwosan, sugbon won ko san.
Nigbana ni Odedaje ka eso eyìn, o si fun won je. Won si bi majele naa sile. Won si ye.
Bayii ni Oduduwa pa a lase wipe ki won gbe awon ajoji naa de. Sugbon awon ti fi ese fe.

1 Like 1 Share

Re: Yoruba Homosapiens History Written By My Grandfather by God2man2again(m): 7:35am On Nov 24, 2020
I see
Re: Yoruba Homosapiens History Written By My Grandfather by MysteryFinder: 12:44am On Nov 26, 2020
Ori Kesan
Ko pe, ko jina, awon ajoji mefa wo inu ilu Ile-Ife-si wa. Sopono ati awon emewa re si ni won lo pade won.
Won si gbin ikoro sinu awon eniyan naa. Awon eniyan mefa naa si dara po mo won. Sopono si ko won ni oke aimoye ika sise. O si so fun won wipe, eyin emewa mi, emi nilo eje omo ikoko.
Nitori wipe eje naa ni yio mu wa pada si odo bi a ti ri tele nigbati a koko kale si orile aye. Bayii ni awon eniyan naa se gba a gbo. Won si lo lati lo wa omo ikoko lati ji gbe ninu ilu Ile-Ife-si.
Nigbati won de tosi aba yeye kan ti n se Awero, won bere si i gbo igbe omo ikoko kan. Bayii ni awon meta se wole, won si ba Awero toun tomo re. Won si gba omo lenu omo Awero ti oruko re a ma je Oya. Won si gbe Awero de towo tese. Bayii ni won se gbe Oya digbadigba lo si eba odo kan ti Sopono ati awon emewa re yoku n farasin si. Won si ta eje omo naa sile. Won si mu eje naa pelu erongba wipe awon yio pada di odo. Won si ju oku omo naa sinu odo naa. Odo naa si di kikida eje.
Nigba ti Akano lo si aba Awero lati be e wo, oun ba Awero ninu irora ati ninu ide. Oun si tu u sile. Awero ko si le fohun, nitori iriri ti oun ti ri. Sugbon oun toka fun Akano ibi ti awon eni ibi naa gbe omo re gba lo. Bayii ni Awero se lo fi to Demurin ore re timotimo leti. Awon si bere si i se ofintoto. Laipe laijina, awon de idi odo naa, won si ri bi eti odo naa se pupa yo yo.
Nigbose, won fi oju ba oku omo ikoko naa ti won ti ya welewele. O si je iyalenu nla fun won wipe oun buburu bi eyi le sele.
Nigbana ni won fi oro naa to Oduduwa ati Orisanla leti. Awon si sokale lori oke ti won fi se ibugbe. Won si wa si eba odo naa pelu Yeye Aye ati Yemoja, sugbon Osun ko ba won rin nitori oun ni omo repete lati se itoju, nitori wipe gbogbo awon ti o ti bimo ninu ilu naa, ayafi Awero ni won gbe omo won fun Osun to. Won si n gbe pelu Osun ninu aba re.
Nigba ti Yeye Aye ti ronu jinle, o so wipe, 'Dajudaju, ise owo Sopona ati awon emewa re ni a ri nihin. O da mi loju wipe Sopona n fi ara sin si koro ilu fenfe yi. Nitorinaa, e ma se sun fonfon titi ti e yio fi se awari oun ati awon emewa Odo'
Bayii ni Yeye Aye se parowa fun Awero ti o n sofo omo re. Eyi si ni iku kini ti o jeyo ni ilu Ile-Ife-si.
Re: Yoruba Homosapiens History Written By My Grandfather by MysteryFinder: 2:40am On Dec 01, 2020
Ori Kewa
Nigba ti Yeye Aye ti lo odun kan ati osu kan ni ilu Ile-Ife-si, oun gbero lati koju si Arewa. Yemoja si mu amoran wa wipe oun yio tele e. Nigbana ni Oduduwa ranse pe gbogbo ara ilu wipe ki won pejo si eba odo Osun.
Nigba ti gbogbo ese ti pe jo, Oduduwa fi to won leti wipe asiko ati dagbere fun ilu Ile-Ife-si ti to fun Yeye Aye. Ati wipe Yemoja ti gbero lati ba a lo. Bayii ni awon ara ile Yoruba se bere si i sokun kikoro, won si n wa omije mu bi emu.
Won si fi orin bo enu wipe, "Yeye omo, yeye eja, ma se gbagbe awa nibi kibi ti iwo ba doriko. Ma ta ipako si wa titi laye. Ma a boju weyin lekan n kan nitori wipe digbi ni awa wa leyin re. Awa ko le ba e lo no ti ara, sugbon awa n sin e lo ni ti emi."
"Yemoja olori ti n se olori awon eja inu ibu. Iwo ti o to eja i da bora bi aso. Iwo ti n la ibu ja lasiko kekere. Iwo ti agbami okun ko le ro yo. Iwo ti omi n teriba fun. Ma se gbagbe awa."
"Je ki ojo ro, fi omi ranse si wa ki awon omi okun wa ma se gbe. Fun wa ni opolopo eja ki awon omi wa si ma san lai ni idaduro. Dahun awon ofo wa nigbakugba ti a ba nilo ohunkohun lati owo re."
Nigba ti won ti kewi nipa Yemoja tan, won bere si Yeye Aye ki. Won si so wipe, "Yeye Aye o, apata rapata ti o fidi kale sorile aye. Eni ti n lo kaakakiri agbaye lati fi ogbon kun ogbon ati lati fi imo kun imo fun awon eniyan adarihurun. Yeye Aye o, lilo ti iwo n lo, ma se fi eyi se arimo fun wa. Bi iwo ko ba tile ni wa ni ti ara mo, fi emi re ranse si wa, ki o ma so wa ki o si ma a da abo bo wa."
"Gba wa lowo awon eni ibi ti won n wa emi lati da legbodo. Ki iku ma pa wa, ki arun ma se wa. Ki a gbo korin kese, ki a to korin kese. Ki ibi di ire, ki ona wa si de wa lorun. Igbakugba ti a ba n pa ofo loruko iwo yeye, je ki ofo wa o ma a gba. Ofo la o ma pa, awa ko ni sofo omo mo. Je ki iku Oya se arimo laarin awon omo ikoko. Yeye o, je ki ilu Ile-Ife-si fe ju bi o ti wa yi lo. Ki o fe wonu okun, ki o fe wonu osa. Ki o fe soke, ki o fe sodo. Je ki a ma a bi si i ki a si ma a re si i."
"Nigba ti awon ara ilu Ile-Ife-si ti soro repete kale, Yeye Aye ati Yemoja mura lati lo. Won si gbe awon ara eja nla meji ko ejika. Yemoja si da owo le Yeye Osun lori, o si so wipe, ki Olorun eleduwa je ki ise omo tito ro e lorun bi ogede. Omo kankan ko ni towo re ku ni rewe rewe. Iwo yio ma gbebi fun awon omo ati awon omo omo ilu yi, ko si ni si omo kan ti yio ti owo re so emi re nu."
"Ise gbigbebifunni yio si ma a dun mo e bi eni n fi iye adiye rin eti. Bi adiye funfun se da iye funfun bora, be gege ni iwo yio da aso funfun bora. Efun ni iwo yio je ni ile Yoruba. Funfun lai ni abawon ni igbebi re yio je. Eje pupa ki yio ta ba efun re titi laye."
"Boju to awon omo mi ti i se ibeta; Olokun ti i se Tayewo, Olosa ti i se Ekehinde ati Oba ti i se Idowu. To won titi ti won yio fi di odo. Ko won ki won ma se se imele. Ko won bi a ti n se bi akin. Ko won ni ila oorun ati ni iwo orun. Ko won gege bi omo bibi inu re. To won de ipo awon omo ti a le mu yangan lawujo. Je ki won mo bi won yio se wa ni irepo. Ki won se ara won ni osusu igi. Ki won gbo po, ki won to po."
Leyin ti won ti so oro tan, Yemoja ati Yeye Aye kehin si ilu Ile-Ife-si, won si n rin lo pelu ara eja ti won gbe dani, pelu erongba lati wo awon awo naa nigbakugba ti awon ba ti de ese odo ti o wu won lati luwe ninu re.
Nigbose, won kan ese odo kan ni ona jinjin rere si olu ilu Ile-Ife-si leyin ojo mejila ti awon ti n rin. Won si gbe awon eja naa wo bi aso. Won si be sodo lati luwe lo.

1 Like

Re: Yoruba Homosapiens History Written By My Grandfather by Nobody: 11:05am On Jan 13, 2021
Interesting thread.
Re: Yoruba Homosapiens History Written By My Grandfather by josh123(m): 8:08pm On Jan 13, 2021
pls continue
Re: Yoruba Homosapiens History Written By My Grandfather by SisterFire(f): 8:43pm On Jan 13, 2021
Crazy christians are coming to say u are possessed by Astarte demons,


But never worry the Antichrist ( workers of nature/humanity) are ending christianity

Proudly ANTICHRIST

1 Like 1 Share

Re: Yoruba Homosapiens History Written By My Grandfather by Proanalyst(m): 7:53pm On Mar 15, 2021
Sir, Mysteryfinder,



We have been waiting for your update.
Re: Yoruba Homosapiens History Written By My Grandfather by Omogaia: 9:04am On Oct 24, 2021
Proanalyst:
Sir, Mysteryfinder,



We have been waiting for your update.

I have been waiting for your update for so long , you have no idea what this means to me , I refresh daily to see if you have updated your post..I am also from Igbajo but never been there before , I have heard great things about our ancestors that makes me so proud to belong to such a lineage ..looking forward to reading from you , it’s literally like a time travel for me ..
Re: Yoruba Homosapiens History Written By My Grandfather by A001: 11:11am On Oct 30, 2021
Why this guy just disappear from Nairaland since January?

(1) (2) (Reply)

Only Satan Shall Set You Free. What's Satan? / How To Celebrate Christmas / Jesus Is The Son Of:

(Go Up)

Sections: politics (1) business autos (1) jobs (1) career education (1) romance computers phones travel sports fashion health
religion celebs tv-movies music-radio literature webmasters programming techmarket

Links: (1) (2) (3) (4) (5) (6) (7) (8) (9) (10)

Nairaland - Copyright © 2005 - 2024 Oluwaseun Osewa. All rights reserved. See How To Advertise. 93
Disclaimer: Every Nairaland member is solely responsible for anything that he/she posts or uploads on Nairaland.