Obaede's Posts
Nairaland Forum › Obaede's Profile › Obaede's Posts
|
Ase! |
Awon Omo Egbe PDP Ti Ipinle Rivers Ti Da Yeye Rotimi Amaechi Sile Pelu Bo Se Padanu Ipo Igbakeji Buhari www.olayemioniroyin.com Awon omo egbe PDP ti Ipinle Rivers ti ko leta "O Ku Ori Ire" ranse si Gomina Ipinle naa, Rotimi Amaechi eleyii ti won fi n se yeye pelu bi ipo igbakeji Buhari se bo mo lowo. Won ni pelu gbogbo lalakukufefe re, lori looser naa ni oro re pada jasi. Gege bi atejade won se so, "aimoye owo Ipinle naa ni Amaechi n na yafunyafun lati wa oju ire awon agbaagba egbe APC tori ki won le gbe ipo igbakeji Buhari fun un. Sugbon ori ti won ti ko iya mo latorun loro re, ko ni sa lai ma jeya naa." Won tun fi kun wi pe a se ori Amaechi kosi nibe rara, enu lasan lo ni bi ajakara. " Elenu yiyo bi ila, a fi igba to pada lana". Sugbon ninu iroyin mii to jade, ohun ti a gbo ni wi pe oseese ki won wa ipo to ni kimi kan fun Rotimi Amaechi ninu ijoba Buhari leyin to ba wole. Ipo ti won si n foju sun naa ni akowe agba patapata fun ijoba apapo iyen ti Buhari ba le se bee gbori wo Aso Rock l'Abuja. Ninu iroyin mii: Awon omo irapada (RCCG) ti bere si ni fi adura ran Paito Yemi Osinbajo lowo pelu bi Olorun Emi Mimo se n sin lo si ibi giga. Bi won se n korin Hallelujay ti won dunnu bee ni won ran Paito leti ise pataki ti awon omo Nigeria fe ki won se leyin ti won ba wonu ogo lo. Ninu Iroyin mii: Nje e ti gbo wi pe Musiliu Obanikoro ti gbe Jimi Agbaje lo si ile ejo to gaju lo latari ibo abele to waye eleyii ti Agbaje jawe olubori. Obanikoro so wi pe ojoro ni ibo to kede Agbaje gege bi olubori. Nibayii ile ejo to gaju ni ilu Abuja ti ranse pe egbe PDP ati INEC lati wa so ohun ti won ri lobe ti won fi waru sowo ni ile ejo lojo ketalelogun osu kejila odun yii (Dec 23). Bakan naa, ile ejo ti pase wi pe egbe PDP Ipinle Eko ko gbodo gbe igbese kankan lori idibo to waye tele ayafi ti ile ejo ba yanju gbogbo oro naa patapata. E tun gba iroyin kekere yii kun tile: Akolawole Olootu, ogbontarigi sorosoro ni ile Adulawo ti ki Taye Currency to je okan pataki ninu awon omo olorin fuji to fi ilu Ibadan se ibujoko ku orire ayajo ojo ibi re to ko lonii [17-12-14]. Igba odun, odun kan ni! Nje e ti gbo? Awon Boko Haram ti gbe Fidio tuntun kan jade bayii nibi ti Shekau ti n leri wi pe oun yoo seku pa Emir ti ilu Kano. Shekau to je olori awon Boko Haram so wi pe enu Emir ti gbooro ju, awon si ti setan lati ko logbon gidigidi. http://www.olayemioniroyin.com/2014/12/awon-omo-egbe-pdp-ti-ipinle-rivers-ti.html http://www.facebook.com/photo.php?fbid=747607288658490&set=gm.889504514434192&type=1&relevant_count=1
|
Sometimes, I wonder how some topic made it to the Nairaland's front page. |
I just pray that one day, Americans (and the world) will be struggling to get visa into our dear country. What u called funny might not be really funny to some people. I just hope that things get better here in Naija so the number of applicants will be reduced. God bless America too, no easy to build a strong country. |
Odun kini mi ni ile eko giga je akoko ti mi o le gbagbe laelae. Gbogbo ara ni mo fi sise alakada nitori wi pe ore mi o pe meji. Mi o mo ibi kankan ju yara ikawe ati ibi mo n sun lo. Igba to ya ni mo joba, faaji womi lewu, die lo ku ko ba se akoba fun eko mi. Laaarin akoko odun kinni mi, mo koja ni eka ti won ti n ko nipa Eto Ogbin. Lara patako ikede won, nisale patako naa, ohun ti won ko sibe ni yii “Agriculture is Life”. Ki lo de ti Ise Iroyin ko se wa nibi ti won ko eto ogbin si? Se pe ohun to se pataki ju ise iroyin lo tun wa ni? Ki n ti mo ki n dake ara mi jeje, mo n finu ro bi mo se le jawon niro nipa akole won. Mo ranti wi pe omokunrin kan wa ti mo pade nigba ti mo n se akitiyan igbawole mi si ile iwe giga. O so fun wi pe eka ti won ti n ko nipa Eto Ogbin ni oun wa. Mo si ranti oruko re, Ibrahim Otubela lo pe oruko re fun mi. Mo wa kan, mo si wa ri. Awari ni obirin n wa nnkan obe. Ibrahim se alaye fun mi wi pe ti ko ba si ounje fun awon eniyan lati je senu, koni si ohun taa ma pe ni iran eniyan, nitori gbogbo eniyan yoo ti ku. O ni imo nipa eto ogbin si n se awari ogbon bi ounje yoo se de ikun iran omoniyan. Igba ti Ibrahim yoo fi pari oro re mi o le fesi mo, nitori oro re mu opolo pupo dani. Asiwere nikan lo si le tako pupo ninu nnkan to menu ba. Mo dara mi lebi lati wa ba Ibrahim. Igba to soro re tan. O ki owo mejeeji re sapo. O yi eyin pada si mi bi igba ti ponmo yira pada ninu obe ata. O si n yan lo bi igba ti Boy Alinco ba wa lori itage. Igba to ya lo tun tiro apa re mejeeji soke, o gaaru apa soke bi sisi Eko. O boju weyin rerin iyangi si mi. O ya wo kona kan, mi o si ri mo. Akurete ti de ba ise iroyin eleyii to mu pupo ninu awon koko ti ise iroyin dale di ohun igbagbe. Eleyii si sele latari imele (laziness) awon oniroyin, ainimo to kun nipa ohun ti ise iroyin dale ati iwa ibaje jegudujera to je orisa kan pataki ti gbogbo wa n bo ni ile Adulawo. E je ka wo pataki ise Iroyin: Gege bi Alufa Femi Emmanuel ti ijo Living Springs Chapel se so, “Nikete ti eda eniyan ba ti duro lati maa wa imo tuntun, igba naa ni irufe eniyan bee ti bere si ni dipeta (ki nnkan bere si ni baje)”. Ko si iye imo ti eniyan le ni lagbari, ti ko ba wa imo tuntun moo ko le tesiwaju. Idi niyi ti awon Yoruba fi ni aa pe gbon ni enikan kii pe go. Ati wi pe bi oni se ri ola ko ri bee lo mu baba alawo maa difa ojoojumo. Ise Iroyin je ohun ti n se afikun tabi atunse imo yala nigba ti awon eniyan awujo n ko eko lowo tabi leyin eko won ni ile iwe. Ise Iroyin je agbara tabi igi leyin ogba ti yoo maa gbe awon eniyan ro ninu imo ati iriri ogbon to n lo layika won leyin eko ile iwe onisabuke tabi ikose-owo. Gege bi apeere, aimoye awon ise iwadii ogbon ni awon onise alakada ti se seyin eleyii to ti duro gege bi imo fun igba pipe. Sugbon bi ojo se n gori ojo ni isele tuntun sele lagbaye eleyii to n so pupo awon imo bee di ohun ti o wulo mo. Akitiyan awon oniroyin si maa mu awon onise alakada jigiri lati lo tun Ifa won da leyin abajade ise iwadii awon oniroyin nipa isele tuntun to so ogbon ana di omugo oni. Lopo igba, awon onise iroyin yoo ti pari ise ko to te awon onise alakada lowo nitori wi pe oju won tole-toko. Gege bi apeere, ka so wi pe orisii kokoro kan ti enikankan ko mo ri tele ti bere si ni yo awon agbe lenu eleyii to n se akoba fun ere oko won ni awon ilu okeere kan, ka so wi pe China. Eleyii ti orisii kokoro naa ko ti di mimo fun awon onimo onise alakada ni ilu mii. Akitiyan ati ilakaka ise iwadii awon oniroyin le je ka mo ohun to sokunfa kokoro buruku naa ati ona abayo eleyii ti o pada jasi iroyin ko to wa di wi pe awon kan yoo tun bere si ni gbeyewo gege bi ise iwadii tuntun ni ilu mii fun aridaju imo ati itesiwaju ogbon tuntun. Alaye mi ko da lori ariyanjiyan, koko oro mi ko si da lori wi pe Ise Iroyin se pataki ju imo nipa Eto Ogbin lo gege bi Ibrahim se fi ye mi. Ohun ti mi o ni anfaani lati so fun Ibrahim ni pataki ati iwulo ise iroyin lawujo ati bi ise iroyin se jinle to. Opolopo kudiekudie lo ti de ba ise iroyin ni ile Adulawo latari imele awon oniroyin, aini imo to kun nipa ohun ti ise iroyin dale ati iwa jegudujera awon eniyan dudu. Eleyii si mu ki awon oniroyin so agbara won nu lati igba pipe seyin. Kini Ise Iroyin Gan-an? Mo ti se iwadii lorisirisi lati mo ero awon ojogbon ati awon onilaakaye nipa ojulowo ise iroyin ati ohun ti ise iroyin dale. Gege bi akosile American Press Instistute, awon gba wi pe ise iroyin dale sise akojopo awon isele fun ikede. “Journalism is the activity of gathering, assessing, creating, and presenting news and information. It is also the product of these activities.” Omowe Anthony Curtis lati Ifafiti Carolina ni eka ti won ti n ko nipa Igbohunsafefe ati Ise Iroyin naa fi idi alaye tie naa mule: “Journalism is the practice of investigating and reporting events, issues and trend to the mass audiences of print, broadcast and online media such as newspaper, magazines and books radio and television stations and networks, and blogs and social and mobile media.” Robert Niles ti gba orisirisi ami eye gege bi oniroyin ori ero ayelukara, mo si ro wi pe oro to ba so ko ye ki eniyan le ko danu rara nitori ojo tipe ti omo obo ti fi ori igi sele. Ohun ti Baba naa wi ni yii: “Journalism is form of writing that tells people about things that really happened, but that they might not have known about already. People who write journalism are called “journalist”. They might work at newspapers, magazines, websites or TV or radio stations.” Bi o tile je wi pe pupo ninu awon alaye won lo kesejari ti awon eniyan si tewo gba nipa ohun ti ise iroyin dale lori. Sugbon ko si eyi to ba ero mi lo. Agbekale Dr Anthony Curtis yaayi pupo, sugbon alaye naa ko kun to. Ma gbiyanju ki n so ohun ti ise iroyin tunmo si gege bi ero mi ati iriri mi ki n to wako alaye mi gunle patapata. Sugbon kii eegun mi to ma jo siwaju, e je n duro nibi lati se afihan awon Oniroyin ti won ti doosa ajiki nipase ojulowo ise iroyin to kunfofo bi ataare to n ti owo won jade. Irufe awon eniyan yii ti kuro ni ipele oniroyin lasan, won ti di onwoye agbaye nipa igbe aye eda lawujo. Yato si ise iwadii, agbekale alaye to se koko si igbe aye eda eniyan, iroyin irinkerindo nipa awon orileede agbaye, lara ohun to mu eto Opral Winfrey di gbajugbaja kaakiri agbaye ko tayo orisii ogbon ayinike ise iroyin igbohun safefe to n lo. Eleyii to je wi pe pupo awon onworan re kii le yira pada titi arabirin naa yoo fi pari eto re lori afefe. Orisii ogbon yii ni awon oluko wa n pe ni ikonilokanro (suspense) ninu litireso. Kosi bi babalawo se lekenka to nibikibi lagbaye, Araba Ifayemi Eleebubon loga nla, to ba jo bi iro eni e ba ri ke e bi. Ojogbon Wande Abimbola si ni Oosa rabata ti won fi ori bale fun to ba dibi ojulowo imo nipa orunmila baba Ifa. Oniroyin le ni oruko nla pelu okiki, sugbon abaje iwadii fi ye wa wi pe Larry King ni ilu Amerika ni sorosoro ori afefe to laponle julo nigbogbo orileede agbaye. Sugbon ninu okan mi, mo ti pinnu pe lojo kan maa foju kan Christiane Amanpoul. Maa si fila fun ori ade, ma si beri fun akoni obirin bi okunrin ninu ise iroyin to danto. E maa fi oniroyin we oniroyin, oloju akosemose to mose akin to yanranti bi Amanpoul. Oloju onisegun to le fe abirun niyawo. Oluko ti o ko akurari ni takada loju lasan o wopo. E maa je n tan yin, oniroyin kan ju oniroyin kan lo. Oga ni kaun lawujo okuta. Oga niyo lawujo erupe. Ojo ti Yasser Arafat, Bashorun Gaa ilu Palestine gbenakari, Christiane Amanpoul sokale. E ma f’amala dudu we iyan Ekiti laelae. Oloju oniroyin to le soro dasaka loju ogun ida ati bajinatu. Eyi to lagbekale ko lakinkanju bee akinkanju nise iroyin to fakiki pelu agbekale to kun fun ogbon ti n tu gbogbo alaye to ta koko. Ki ni ohun pataki to so awon oniroyin doosa ajiki? Abi ki n so wi pe ki lo mu awon oniroyin kan pegede ju awon oniroyin mii lo? Lakoko na, ise iroyin rekoja ikede gege bi ero opolopo awon eniyan. Bi awon oniroyin tile n kede isele awujo si eti ara ilu, a je wi pe ikede isele je bi okan ninu ogorun ninu ohun ti ise iroyin gun le ni. http://www.olayemioniroyin.com/2014/10/igbe-aye-wale-dada-gege-bi-oniroyin.html E je ka se agbeyewo alaye kekere yii: Pelu anfaani awon ero iwiregbe to wa lori ayelukara bi Facebook, Twitter, Instagram, BBM ati bee bee lo, nibi ti awon eniyan orisirisi ti maa n kede isele ayika won, isele inu ile won, awon mii tile maa n kede awon isele ti n sele ninu igbe aye won ati oun ti won ro lokan. Ti ise iroyin ba je ikede isele, nje a le gba wi pe oniroyin ni gbogbo awon eniyan ti a se apeere won soke yii je? Kini Ise Iroyin sise je gan-an? Ise Iroyin ni akojopo eroja ti ko leja-n-bakan ninu nipase itopinpin ati iwadii ijinle eleyii to da lori isele awujo lati fi kede isele, se alaye ohun to ruju, idanileko, ikilo, atunse, tabi idanilaraya fun awon eniyan awujo laikuna ninu ofin igbekale ise iroyin sise. Niwon igba ti oniroyin ko ba ti ni oye nipa ohun ti ise iroyin dale, ni o soro fun iru oniroyin bee lati kogo ja. Yato si ojulowo imo nipa ise iroyin tabi igbohunsafefe; Oniroyin gbodo ni oye nipa asa ati ise awon eniyan awujo ti won n tewo gba abajade ise oniroyin tabi ti koko iroyin naa dale lori. Oniroyin gbodo mo nipa awon eniyan awujo; gbedeke imo ori won, ero okan tabi irori won, ohun ti won n reti lati odo oniroyin, iha to seese ki won ko si orisii abajade tabi agbekale iroyin kan nipato. Oniroyin gbodo mo nipa igba ati akoko to n lo lowo eleyii ni yoo ran-an lowo lati le se agbekale ise iroyin ni ona ti o fi ba igba mu. Yato si wi pe oniroyin n sise pelu awujo, oniroyin tun sise ‘laaarin’ awujo. Eyi lo fi je dandan gbon fun ojulowo oniroyin lati ni imo gbogboogbo nipa ohun to gbe awujo ro bi eto eko, eto oro aje, ere idaraya, oselu, isejoba, amuludun, eto ilera, eto isuna owo, eto ogbin, ibasepo awujo pelu orileede agbaye, ofin ati eto idajo abbl. Ti mo ba ni ki n maa ka awon abuda ojulowo oniroyin, oseese ko gba mi ni opolopo akoko eleyii ti gbogbo re si se koko. Ise iroyin jin pupo bee lo si fe feregede bi owo aso. Eyi lo fa ti awon oniroyin fi yan abala ise iroyin kan nipato fun ise iwadii to jinle. Sugbon fun ojulowo oniroyin, dandan lo je lati ni gbogbo abuda ise oniroyin nitori gbogbo re wonu ara won ni. Yato si awon sawo-sogberi oniroyin, a wa le gba wi pe asaaju (leader) to pegede ni ojulowo oniroyin to gbamuse lawujo igbe aye awon eniyan. Eni to feebo nile ana dandan ni ko tu u. http://www.olayemioniroyin.com/2014/10/igbe-aye-wale-dada-gege-bi-oniroyin.html Awon wo ni Sawo-Sogberi? Gege bi Ojogbon Akinwumi Isola se so ninu alaye re. Kofeso so wi pe awon Sawo-Sogberi ni orisi awon eniyan kan ti won maa n sebi awo loju awon eniyan ti ko mo ohunkohun sugbon lojo ti won ba pade ojulowo awo gidi (akosemose), iru won yoo pada di ogberi. E yi tun mo si wi pe ayederu ni won. E ri wi pe mo se apeere oniroyin gege bi asaaju tabi eni to le di ipo asaaju mu. A le gba wi pe bee naa lori nipase Imo, Iriri igbe aye awon eniyan ati ibasepo oniroyin pelu awon eniyan awujo lenu ise won. Tani asaaju? Asaaju kii se eniyan ti n lo niwaju ti awon eniyan to ku n tele leyin. Asaaju kii se eniyan to wa ni ipo agbara lati dari awon eniyan to ku leyin. Asaaju kii se orisii eniyan ti awon kan n bo bi oosa. Taa wa ni asaaju? Asaaju ni eniyan to n lo niwaju lati pese ona fun awon to n bo leyin lati ri ona to dara gba koja. Asaaju ni eni to n tiraka lati mo ohun ti opolopo awon eniyan ko mo pelu ero ati fi orisii imo bee se iranlowo fun awujo. Asaaju ni eni to mo ona lati je ki ifokanbale pada si aarin ilu ni akoko ti awujo wa ninu hilahilo tabi aibale okan. Asaaju ni eni to n lakaka lati je ki awon eniyan awujo bo sinu ominira kuro ninu iponju ati ipayinkeke. Asaaju ni akinkanju to duro lori ododo ati igbagbo nipa ojo ola rere awon eniyan. Asaaju je eni ti ki beru ohunkohun; awon kan so wi pe ohun ni won pe ni igboya. Asaaju ni eni o n lo anfaani to ni, yala dukia tabi imo fun idagbasoke awujo tabi ilu re. Asaaju ni eni to fi ara re sile lati je ohun (voice) fun opolopo ti won ko lenu lati soro lawujo. Awon nnkan ti awon oniroyin agbaye bi Larry King, Opral Winfrey ati Christianah Ammanpol mu mo ise opolo ni yii ti won fi di eni aponle ti gbogbo awon alagbara aye fi n ye won wo bi ifa to ba dibi oro iselu (mi o so wi pe oselu) tabi eto ilu. O seese ko je wi pe awon nnkan yii ni awon Ojogbon ro papo nipa akitiyan Adewale Dada lawujo ti won fi fi oye Dokita da lola. Eyi si wa lara nnkan ti itan ko ni gbagba laelae ninu ise iroyin igbohunsafefe ile Naijeria ati ile adulawo lapapo. Igba ti ilu wa ninu rukerudo, Adewale Dada dide lati ponlogo alaafia. Igba ti awon omo ale tabuku ile Naijeria, Adewale Dada dide lati maa bu ola fun un. Igba ti awon eniyan so ireti nu, Adewale Dada se afihan agbara igbagbo ati ireti. Igba ti awon eniyan karibonu, Adewale Dada lo ebun re toni lati ko ibanuje awon eniyan danu sinu okun pupa. Igba ti awon ojelu te eto omoniyan mole, Adewale Dada duro lori ododo lai foya. Igba ti awon odo ile yii se bi o ti tan, Adewale Dada se idasile The Good Intiative lati ran awon alaini lowo. Akinkanju, olotito, asaaju rere, ore mekunnu ni Adewale Alao omo Dada je. Eyi ni die lara apileko ti awon Ojongba ka si eti gbogbo aye ko to di wi pe won wo aso oye fun Wale Dada, leyin eyi ni won gbe Sabuke oye Dokita le lowo ni ilu Ibadan. Gongo so! “Akosile isele tuntun ti wonu iwe itan laaarin awon ojogbon onise alakada lonii. Ohun gbogbo ni eniyan le kowo ra, eniyan ko le fi owo ra oye Dokita iru eyi. Awon eniyan awujo dabi osere ori itage loju ti wa, a si n se akiyesi ipa ati akitiyan enikookan nipa idagbasoke awujo wa. A n se eyi lati se koriya, idalola ati imoore.” Ise iroyin je ise akinkanju ati ise ilu- ifi ara eni jin fun ise ilu. Oniroyin to ba ni oye nipa ohun ti ise iroyin gunle, to si tele awon ilana to ro mo o nipa nini awon abuda to ye ki ojulowo oniroyin ni, a le pe iru oniroyin bee ni asaaju gidi lawujo. Olayemi Oniroyin ibi ti maa ti duro ni yii. Ti mo ba wo aso funfun emi kii sunmo elepo rara. Emi ko ni tori atije ki n da oju oro ru bi onilu Onibode Lalupon. Atenuje lo pa Sule Igbira. Oju kokoro lo pa Baba Wande to fi tale oosa. Emi ko ni tori oni ki n ba ojo ola ilu mi je. Awon kan an pa lekun, awon kan fe ko wo danu sugbon titi lai ni i maa gbe laruge; ilu mi, aye mi, Nigeria ilu olokiki nla. Ki Oluwa ki o bu kun un. Amin. http://www.olayemioniroyin.com/2014/10/igbe-aye-wale-dada-gege-bi-oniroyin.html
|
NFF and CAF are just being selfish in their individual move toward this matter. Heaven will not come down if CAF cancel AFCON for this year. The lives of people should be the first in all their plan not their profit. Awon oloshe |
saintneo:It seems u don't understand politics. Fasola is a performer but its popularity does not go beyond SW. GMB na Pillar in the North. The hausas are ready to follow him anyday and this has nothing to do with his achievement. |
ratiken:. But Boko Haram and ISIS are not muslim. Am a christian but I strongly believe those guys are not muslim. If we always base our decision on sentiment or nepotism, we can't move forward as nation. I believe so much in Fasola, I just need to check Buhari again. |
ilugunboy:u make sense. |
www.olayemioniroyin.com I blog in African Language (Yoruba). And my blog is about News update. Olayemi Oniroyin |
Awon Yoruba ni bi onirefin ko ba fingba mo, eyi to ti fin ko le parun laelae. Okan lara awon gbajugbaja ewi akosori ile iwe alakobere nigba kan ri ni yii, eleyii ti opolopo awon agbalagba aye ode oni ka ninu iwe Alawiye ti won koko te jade lodun 1943. Nje eyin si ranti bi? Ise l'ogun ise Mura s'ise ore mi Ise la fi n'deni giga Bi a ko ba reni feyin ti Bi ole la'nri Bi a ko ba reni gbekele A tera mo'se eni Iya re le lowo lowo Baba re le lesin lekan Bi o ba gbo'ju lewon O te tan ni mo so fun o Ohun ti a ko ba ji'ya fun Se kii le pe lowo Ohun ti a ba fara sise fun Nii pe lowo eni Apa lara Egunpa niyekan B'aye ba n'fe o loni Bi o ba lowo lowo Aye a ma fe o lola Tabi ki o wa ni'po atata Aye a ma ye o si terinterin Je k'o de'ni tin rago Aye a ma yinmu si o Eko si'nso ni d'oga Mura ki o ko dara dara Bi o si r'opo eniyan Ti won f'eko s'erin rinrin Dakun ma f'ara we won Iya n'bo fun'omo ti ko gbon Ekun n'be fun'omo to nsa kiri Ma f'owuro sere ore mi Mura si'se ojo'nlo. www.olayemioniroyin.com/2014/09/ewi-ise-loogun-ise-jf-odunjo.html?m=1 |
|
Ale ana ki i n to sun, orin Bob Marley ni mo n gbo. Opolopo awon orin Bob Marley lo kun fun ogbon ati ijinle ede. Odun 1945 ni won bi Robert Nesta Marley ti gbogbo eniyan mo si Bob Marley ni Saint Ann to wa ni ilu Jamaica. Igba to pe omo odun merindinlogoji (36), ni odun 1981 lo gba ilu Amerika de ajule orun. Bi Bob Marley ko tile si laye mo, okiki awon orin to ti ko ko je ki oruko re pare. Die lara ohun ti Bob Marley wi ninu awon orin re ni yii: "You can fool some people sometimes, you can't fool all the people all the time." "O le mu opo awon eniyan lobo fun awon igba kan, o ko le mu gbogbo eniyan lobo ni gbogbo igba." Bi eniyan ba le were titi ti were oun sare lo lai boju weyin, ti were ba de bi ti ona ti pin dandan ni ko yiju pada. Bi ilu Nigeria se ni ola to, ti eniyan kookan ni orileede Nigeria ba ni oko ayokele meta lagbala ko ti i poju. Sibesibe awon eniyan ko beere oko ayokele, aadota (50) naira ti won oo fi woko ni ko si lowo elomii. Owo iresi ogorun naira (100), ewa aadota (50) naira, ounje osan-an lai seran, ati piowota omi inu ora oni naira marun-un (N5) ni omo ogbon odun (30yrs) wa ti o fi jeun ti ko si lapo re. Agba to ji ti ko ba ooko ji, o ti ku won o ti gbe sin ni. Awon eniyan ko beere oun to po rara, won ko tile gbero ati ko ile alarinrin bi eyi ti nbe ni Gwarimpa, Lekki tabi eyi ti won ko si Bodija n’Ibadan. Ohun ti won fe ni ibi ti won oo maa gbe ori won le to ba di lasaale. Ori ti n fo awon odo ile yii, ohun to fa ori fifo ko si ye mi. Boya nipa iroyin owo bilionu aimoye ti n poora lojoojumo ti won n gbo seti tabi ise ti won ko rise ti won n wa kiri ti kosi nibi kankan lo fa efori tuulu. Sugbon ori n fo won gidi gan-an, owo iya won ni won si ti lo n gba owo fensiiki ti won lo lati dekun ori fifo abaadi. Sibesibe ori fifo o lo. Ko si eni rere nibikibi. Yemi Elebuubon ti ni ‘Eeyan won, araye eniyan soro’. Eni afeyinti bi o ba ye wiwiniiwi. Eni a gboju okun le ko si jeni agba. Igi taa ba feyinti ka maa je igbadun, gbogbo ara lo fi segun. Eni o ye ko feni loju ti fata senu. Sebi igi taa tori re jiya, o ye ko le dana fun ni ya. Gbogbo awon olori wa pata ni odale, asise nla gbaa ni ominira taa gba lowo ijoba Biritiko je. . Kini anfaani ominira ti ara tun ni gbogbo mekunnu? Kini anfaani orogbo na? A pa ko lawe, a fi senu o tun koro bi jogbo. A tun ni ka figi re dana, won ni eewo ni enikan ki i figi orogbo dana. Orisa boo le gbemi fimi le bi mo ti wa. Bi ebiti ko ba peku o ye o le feyin feleyin. Bi eniyan ko si le jawe lori asewele a ki i ko tori re kuro. http://www.olayemioniroyin.com/2014/09/se-gbogbo-wa-lobo-langido-ni.html Awon oba alaye ati ijoye ilu to ye ki won maa gba eto ilu lowo awon ijoba fun ara ilu ni won ti tori ijekuje so ori ade di yeyenatu. Enu to ba ti je dodo ko ni le sododo. Agbalagba to ba si so agbado modi, dandan ni ko di alawada adie. Agba ti o farabale ni i fara gbegba. Mo nife orileede mi pupo gan-an, teni-n-teni, takisa n taatan. Omo eni ko ni sedi bebere ka wa fi ileke sidi omo elomii laelae. Ibi ori dani si laagbe. Sugbon odaju, eniibi, ika, ole, jaguda, gbewiri, olosa, barao, tiifu, wobia, alanikanjopon, onijekuje, ajeun-omo-nu-oyun, oloorun, onidoti, obun, olodo, akurari, olopo dudu, keferi alainiberu Olorun, apaayan ni gbogbo awon olori wa pata. E je ka yopin loju ka fihan oju. E wo ni ki omo maa jale ka maa lomo n fewo. Baa wi aa ku, baa si wi orun la n lo. Baa sooto ba o sooto, o di dandan ki eye oko o fo lo. Ojo ti mo gbo itan Tunde Fasasi (oruko re gidi ko ni yii), mo dupe lowo Olorun. Ti oloju kan ba ri eni ti o loju rara yoo sope fun Oluwa oba. Itan aroso ko, Isele to sele gidi ni. Odun karun-un re e ti Tunde ti n wase leyin to jade ile iwe. Igba ti o rise se lo lo ra aga ati tabili segbe titi lati maa fi se ise teliwaya. O n ta kaadi ipe, eni to ba fe se eloelo ni gba muri kookan (N20) lowo won fun iseju kan ti won ba lo lori ila. Owo pensan baba Tunde ni won to papo mo owo ti iya Tunde ba pa nibi worobo ti fi n saje. Ireti won ni wi pe ti won ba fori ti titi, ti Tunde ba jade iwe yoo le ran aburo re lowo. Sebi ti okete ba dagba tan, omu omo re ni i mu. Ati wi pe tita riro laa kola, to ba jina ni i doge. Adun ni i gbeyin ewuro. Leyin okunkun birimu, imole lo kan. Sugbon riro ni teniyan, sise ni t'Oluwa oba. Se awa le so wi pe Oluwa oba ni ko je ki Tunde rise se, rara o. Amukun eru re wo, oni oke le n wo e o wole. Baba Tunde saisan, awon ijoba o sanwo pensan kia, lojo kan ni Ogbeni Olarewaju Gbadamosi dake ti ko si ji mo. Ibi kan ni aburo Tunde obirin n gbe l'Abuja, won ni kojo omo odo tabi kabani sise ile ni i se nibi to wa loke oya. Ki i se wi pe o wu bee. Bi o ba r'adan, eniyan le fi oobe sebo. http://www.olayemioniroyin.com/2014/09/se-gbogbo-wa-lobo-langido-ni.html Ko saa ma fi joko sile lasan ni. Iya o jeun, baba o jeun, won o tun sanwo ile. Bi eniyan ba n sare ki oju ma tini, ti oju ba ti tini are ka maa ku lo kan. Iduro o si, ibeere o si feni to gbodo mi. Igba to gbo iku baba re ni Morenike fi n pada bo nile. Se e mo awon olopa alaso dudu ti won maa tewo gba muri kookan ni masose? Awon ni won da oko ti Morenike wa ninu re duro. Awako ni i ba won lagidi ni won ni olopa ba yinbon. Olorun nikan lo ye bi ota ibon naa serin to fi ba Morenika lapa. Morenike o ku sugbon apa naa ko wulo fun-un mo. Ko le pada si oke oya mo, joojumo ni won si n lo si osibitu lo gbatoju. Joojumo ni apa naa n ro Morenike. Awon kan tile ni boya aye ti toju bo egbo apa re ni ti ko fi jina lati ojo ti won ti n toju re. Oko iya Tunde ti ku, ise iya Tunde si ti doloogbe lowo bukata repete, joojumo ni Morenike n jerora. Gbogbo ebi lo ti salo fun won tori bukata. Kaluku lo kun un ru tie kiri. Temi gan-an tomi leru, e ma di kun-un. Oju titi ni Tunde si wa nibi to ti n gba muri kookan lowo eni ba fe se eloelo. Owo ti Tunde n pa ko to o jeun ka to wa so ebi to fi sile. Mo mo omo gomina to ti je nigba kan ri to je wi pe gbogbo opin ose ni maa gbe baalu lo silu London lati lo wo boolu Premiasiipu ilu Oba, aa si pada wale lojo Aje. Ti o ba n lo, obirin meji ni i ko dani pelu awon ore re bi meta. Bakan naa ni mo ti ri aburo gomina kan ri to so wi pe oun o fi owo baye asobode ile itura kan je niseju mi korokoro nigba ti asobode naa so fun wi pe won kii to sibi ti n to si (aburo gomina naa ti mu oti yo nigba naa). Esi ti aburo gomina naa fun ni wi pe, “ maa fi owo ba ti e je”. E dakun, kilagbe ki le ju? Bakan naa, mo ni ore kan to ti ni anfaani lati lo si awon ilu okeere bi meta tabi ju bee lo. Omo eniyan pataki ni. Awon Yoruba sibo, won ni ola abata ni i modo san, ola baba omo ni i mu omo yan fanda. Ore mi yi ti ni anfaani lati wo inu ile ijoba apapo l’Abuja - Aso Rock naa ri. Ojo kan lo so iriri re fun mi. O ni iru aye ti won je ninu ile ijoba apapo to wa l’Abuja, o ni oun ko ri iru aye bee nibikibi ni gbogbo ilu okeere ti oun ti de ri. O salaye die fun mi, emi gan-an yanu ni. Eni i sise wa ninu oorun, eni gbowo wa nibooji. E je ki n tun pada sori oro Bob Marley Akoni igbaani, "You can fool some people sometimes, you can't fool all the people all the time." "O le mu opo awon eniyan lobo fun awon igba kan, o ko le mu gbogbo eniyan lobo ni gbogbo igba." Aifoonu eleyii ti won fi asan goolu gidi se n won ha ni saara lojo ti omo Aare n se igbeyawo alarinrin fun gbogbo alejo. Ilu Okeere bi meta ni oko ati iyawo tun fo de nikete ti ayeye igbeyawo won kase nile lati lo se onimuunu pelu opolopo owo dollar. Aimoye omo mekunnu ni won n ku lojoojumo loke oya, nigba ti awon kan tile sonu ti a ko ri won mo. Akosile die ninu opolopo awon owo ti won ti ji ko pamo si ilu okeere nigba kan tele ni yii. Sampu lasan ni mo fi eyi se, eyi ti won ko pamo loteyii tun goboi. Se e ranti $9.3M ti won ri ni South Africa. Sebi eyi ti asiri tu lagbo, aimoye taa gbo nko? Omo Aare to se igbeyawo ni yii saaju ko to lo si ile oko. Aimoye moto ni fi n se faaji, o si feran ko maa ko oruko inagije re si awon oko re gbogbo gege bi nomba. Awon kan tile so wi pe kii se omo bibi inu re gan-an wi pe o gbato lo wa so domo. Iya n je opolopo awon eniyan o, eni ba ri ounje ojumo je ko dupe lowo Oluwa. Eniyan to wa ni alaafia ko mo ohun ti oju awon eniyan to wa ni osibitu n ri. Awon osibitu wa ko yato si ile iku, eni ori ba koyo ni i pada wale ti won ba lo. To ba je iro ni mo pa, kilode ti awon olori wa ki i se lo sibe (awon oba gan-an kii ya be). Awon olopolo dudu ko ni won se yahoo-yahoo o, boya ti won ba ri ohun gidi fi opolo won se boya won ko ba jawo ninu ise ibi. Kosi omo ti o mowe, okun inu la fi n gbe tode. Ti omobirin ba ji ti n fidi re se sadaka kiri, e je ka ronu ka to fun iru obi omo bee lepe. Se ise asewo je ise ti eniyan mu yangan ni? Opo alagbara lo ti dole (laziness). Opolopo ologbon ni won ti domugo. Aimoye oku ni won rin ni titi bi alaaye sugbon oku ni won. Mo nireti wi pe Nigeria yoo dun lojo kan. Mo si gbagbo wi pe abiku yoo di abiye. Sugbon e ba mi jise Bob Marley fun won. E so dorin titi yoo fi ko si won leti: "You can fool some people sometimes, you can't fool all the people all the time." "O le mu opo awon eniyan lobo fun awon igba kan, o ko le mu gbogbo eniyan lobo ni gbogbo igba." Olayemi Olatilewa ni oruko mi. Mo si feran orileede mi bi emi mi. Idi Pataki ti mo fi wa ni lati wa ki yin ku odun ominira. Mo ro yin ki e mu okan le gidi pelu igbagbo to jinle. O ni le koro, sugbon adun ni i gbeyin ewuro. Leyin okunkun imole nbo. Bi ekun pe dale ayo n bo lowuro. Kosi ohun to le ti kii ro. O di gba kan na! http://www.olayemioniroyin.com/2014/09/se-gbogbo-wa-lobo-langido-ni.html
|
[center]AYE MI lati Owo Bose Alubarika[/center][b][/b] Orisiirisii aditu ogbon lati ri ni owo awon onimo agbaye, onise alakada ati awon onwoye nipa igbe aye awon eniyan lawujo. Lara iru akiyesi ogbon naa ni wi pe opolo ti Edumare fun eda eniyan kii baje raurau- ki i ba je ise aye tabi afowofa ara eni. A ri apeere eyi nipa wi pe ko si bi were se ya digbolugi to, to ba ri moto ti n bo n se ni o sare yago lona. Abala kan ninu opolo won si n sise lati se akiyesi ewu tabi ijamba. Bibeli naa salaye orisii were kan eleyii to bugije koja apejuwe. Iboji ni were naa n gbe; o si maa n fi okuta ya ara re lopolopo igba. Sugbon lojo kan o ri Jesu, opolo si so fun wi pe Jesu lori. Awon onimo bibeli (Theologist) si je ko ye wa wi pe oseese ki okunrin naa ti gbo nipa Jesu ri nibi kan idi ni yii to fi sare too Omo Maria wa fun igbala. E maa ro wi pe ki lo fa surutu repete? 'Oga oniroyin e fitan sile, koko la fe gbo.' O daa, ko buru, mo ti fe e debi ti mo n lo. Sugbon sa, e ma gbagbe wi pe mo n so nipa aditu ogbon eleyii ti awon onwoye se akiyesi re ninu iseda eniyan lawujo. E tun gbo eleyii... Nigba lailai, awon agbalagba Yoruba aye atijo gba wi pe laakaye to je baba ogbon a maa ya inu awon omode (tabi awon odo) sun leekookan tayo ohun ti agbalagba le ri kojo fun odindi ogorun odun. Idi ni yii won fi n pa owe wi pe omode gbon, agba gbon ni won fi da United Kingdom. Ha! E ma binu, Ile Ife ni mo fe wi. Omode gbon, agba gbon la fi da ile Ife. Leyin igba ti mo ti salaye ero okan mi. E je ka pada sori afihan fiimu wa fun osu yii, eleyii ti won pe akole re ni AYE MI lati owo Bose Oladimeji (Alubarika). Ojo ori ko ni ohunkohun se pelu ogbon ori. Eni wu Edumare ni oba mi oke n fun ni laakaye yanturu. Bi eniyan ba buru to si daju bi alujannu ti won pe ni Sani Abacha tabi Idi Amin ti ilu Uganda, bi eni naa ba wo Omo Orukan ti Adebayo Salami se, dandan ni ko yomi loju. Bee, omode ni Bayo lodun to fi ogbon ori gbe itan naa kale. Muyiwa Ademola ti salaye ri wi pe fiimu ORI ti gbogbo aye n pariwo, okan ninu awon itan ti oun ti ko nigba ti oun wa ni ile iwe girama ni. Mo ti pinnu wi pe mi o ni so ohunkohun nipa fiimu AYE MI to ti gori igba. Enikeni ti e ba ti ri, e bere lowo won wi pe se won ti wo fiimu naa. Ohun ti won ba ti wi ni kee tele. Bi o tile je wi pe Bose Alubarika ti se awon fiimu kan saaju, sugbon itan Aye Mi ti wa lowo re tipetipe eleyii to se Afeez Eniola ni kayeefi lojo ti Bose Alubarika mu akosile itan naa jade sita. Muyiwa Ademola ri agbekale itan naa lo fi gba lati kopa ninu re. Awon agba osere yii gbimopo, won si gba wi pe ki Bayo Tijani dari ere naa latari iriri ati awon aseyori to ti ni lori awon fiimu onirawo meje bi ti Aye Mi to ti dari seyin. Ibo ni Bose Alubarika ti ri ogbon ko iru itan yii? Eni to beere oro lo fe idi re gbo. Eni to fe ori ahun ati ese ahun, dandan ni ko ra odindin ahun. Bayo Tijani lodari fiimu tuntun yii, Afeez Eniola ni alamojuto. Lara awon osere fiimu naa ni Bimbo Akintola ati Doris Simeon sugbon maa royin ki e kiyesi Arike Akinyanju pupo. Alubarika ti wo ise owo Bose Oladimeji ni. Almaroof se n kiri aye. Alubarika ko ni won ninu ise wa. Amin. http://www.olayemioniroyin.com/2014/08/iriri-aye-ati-ogbon-ninu-fiimu-tuntun.html
|
I had worked in that call center close to two years. so, I know exactly what happened on your line base on your information. Firstly, when your subscription hits expiring time and date, whatever data you have on your account will be cleared. So when that happens, auto renew ought to be effected once you have sufficient balance with your auto renew service active ( some deactivate autorenew at their first subscription). If u have deactivated ur autorenew, ur subscription will not be renewed; forget about the message u got when your subscriptions was about to finish where u were told of ur subscription would be renewed with sufficient balance. If u are sure that u did not deactivate the autorenew service, then I can conclude that u experienced network error as result of inactive operation of one the system applications. if that is the case, the fault is from the network. On Airtel Network, if u don't have bb subscription on ur line, ur line will be functioning but u will be billed from ur main account at faster burn rate. and this is what i perceived to be ur experience. STOP CALLING THE CALL CENTRE, THEY CAN SOLVE YOUR KIND OF ISSUE AND THEY WILL NOT TELL THEY CAN'T. First of all, call centre does not have the access to refund ya money. Also, those ones that were logging your complaints were not too experienced. because people they are transferring your issue to will not refund either in as much they find out that the money was not dropped or cleared by the network, it was charges for internet service that was going on on you line after ur bb expiration. I will only advise you to visit airtel shop. But if u will really take my real advice, I will say Forget and move on. Probability of getting ur money back is one over ten. I have seen many things that i can say here, but i know table will turn one day. Those one you think that will help u on this are friends with them. |
Please, how can upgrade bbm on techno P9? |
Agbeyewo Awon Ede Tuntun Ati Ise A-bani-loyun Ni Ilu India Ko si idi kankan ti a fi le so wi pe awon oluko wa ko gbiyanju to, bi o tile je wi pe eto eko Naijeria pofo bi iyo to da sinu erupe ile. Awon Yoruba si bo, won ni ika to ba se ni oba n ge. Ti omo eni ba si pegede ki lo buru ninu ka ko oropotoyun baba awon ileke sidi iru omo bee. Ni iwon igba ti o ba ti je wi pe ti oju ba ti n sepin a fi n han oju ni, ki lo wa buru ninu ka gbe ade fun esin funfun to mu ori dele? Ki lo ‘baadi’ ninu ka dupe lowo babalawo to koni n’Ifa ori ire? E je ka ki tisa to komo niwe to ye omo yekeyeke, nitori tisa to ya olodo ko le fi ogbon ro omo lara bi aso. Eko to je ojulowo to gba arogun tabi arojinle ise opolo ti n soni doosa ojiji, agbekale atotonu to ridi joko bi igi araba nla pelu ise iwadii to duro soke tente bi Olumo ti ko re jabo, igbelaruge ogbon atinuda eleyii to tayo takada lasan, ogangan ibi ti ogbon ti domugo ti omugo tun yira pada dogbon lowo onise alakada ti n yooru gbigbona. Olayemi, ko si igba ti mi o ni pada si Ifafiti. Nibi ti Ifa fi ogbon ti si, ogangan ibi awon onise alakada ti gbe n se ogbon bi igba adelebo n se egusi pelu irorun. http://olayemioniroyin..com/2013/11/agbeyewo-awon-ede-tuntun-ati-ise-bani.html Bi o tile je wi pe kini kan pere lo ba Ajao je, apa re gun bi opo ina monamona, itan re si ri gbonda bi omorogun amala. Eto isakoso Naijeria ti je ki akurete de ba eto eko ile wa. Ohun to ye ko je koko ti wa ni koko lori, ibadi aran oge to ye ko je ohun iwuri ti di yeyenatu. Sibesibe, kini mo le je gbagbe kilaasi Imo Eda Ede mi? Nibi ti awon onimo ti gbe n fi iwadii tako ara awon pelu akawe to moyan lori. Awon kan ni n se ni a da ede mo wa, iwadii awon onimo mii tun so wi pe igba ti a de ile aye ni a ko ede, gbogbo won pata ni abere iwadii won si lokun nidi. Eleyii to nira fun wa lati ko ifa enikeni danu ninu won. Lopolopo igba lo je wi pe kilaasi maa n pari nipa yiyi omugo pada si ogbon tabi ohun ti a ti gba gege bi ogbon yoo si di eru akitan nipa agbeyewo awon ‘Oga Nla’ ninu ijinle ise opolo to daduro bi okiti ogan. Kini Imo Eda Ede? Lede kukuru, imo Eda Ede(Linguistics) je orisii imo kan ti n se ofintoto bi ede se wa saye, tabi bi ase da ede. Gege bi agbekale awon onimo Linguistiiki se so, opolopo won gba wi pe ohun elemi tabi abemi ni ede je, eleyii to je wi pe gbogbo igba lo n dagba sii. Eleyii si wa lara ohun ti o mu orisii imo naa gun gbon-onna bi owo aso. Joojumo ni ede n dagba awon ede tuntun si n jeyo bi igbe aye iran omoniyan se n tesiwaju. Idi ni yii ti a fi ni awon ede atijo ati ede tuntun. Orisii ede tuntun yii le je agbelero, ayalo ede lati inu ede mii, tabi awon ede ti olaju fi le wa lowo latari igba to de ba wa. Nikete ti ede tuntun ba ti jewo tabi ti isele tuntun ba ti waye yala ni eka Imo Sayensi tabi Imo Ero, ojuse awon onimo Eda Ede (nibayii, mo ti n so nipa awon onimo eda ede Yoruba nipato)ni lati se atunse si ede ki iru emi ede bee le tesiwaju (se e ranti wi pe mo ni ohun elemi ni ede je?). Awon onimo ede Yoruba si n gbiyanju, sebi okunrin ti n sun rara fun okunrin ni, ise ako nla ni iru won n se. Gbogbo igba ti awon ede tuntun bee ba si ti n jeyo lagbaye, paapa ju lo leka Imo Ero ati Eto Ilera ni atunse maa n de ba awon Ede Iperi (Metalanguage) wa fun atunse ilo ede to peye. Nibayi, ohun kan ti gbajugbaja ni ilu India. Ohun to gbajugba naa ni asa A-bani-bi-omo. Eyi ni wi pe toko-taya le gbe ise oyun nini ati omo bibi fun obiriin ajoji. Leyin ti won ba bi omo naa tan toko-taya yoo gba omo won pada lori adehun si ni, eleyii ti opolopo re si maa n da lori owo. Opolopo awon eniyan kaakiri agbaye ni won n ti n lo si ilu india la ti lo gbe ise oyun nini fun awon obirin ti won fi n se ise sise ni ilu India. Pupo ninu awon onibara awon obirin yii ni won je awon okunrin meji ti won n fe ara won laye ode oni gege bi toko-taya. Nipase olaju ati idagbasoke ti o ti de ba Eto Ilera ati Imo Isegun Oyinbo, awon dokita le gba ato okunrin ati obirin ki won si ko sinu obirin ajoji ti iru ato bee yoo si pada doyun ati omo. Iru igbese bayii ni won pe ni ‘Surrogacy’. Surrogacy ati opolopo orisiirisii awon oro tuntun mii ninu ede geesi lo ti di egungun eja si awon ojogbon lorun nipa wi pe iru oro wo la le fi ropo re ninu ede Yoruba. Olayemi Oniroyin, bi o tile je wi pe mi o ni pe danu duro na, sugbon o hun to daju ni wi pe alaye mi si n bo leyin bi eegun nla ti n dun yunmuyunmu bi olu-igbo. Amo kini kan lo da mi loju saka, niwon igba ti ede kan ba ti duro lati dagba soke tabi lati gbooro nipa bi awon ede yoku lagbaye se n tesiwaju nipase olaju, iru ede bee ki pe wole bi Sango oko Oya. E ku ikale. http://olayemioniroyin..com/2013/11/agbeyewo-awon-ede-tuntun-ati-ise-bani.html
|
Please, If you get sms from MEDPRO GLOBAL RESOURCES,161 Ikorodu rd beside Lanre Shittu motors Onipanu B/S calling for aptitude test or interview, do not attend. Those people are scammers, after wasting all your day with meaningless long lecture they we ask you to pay 9k to get a job. This how how they get people; They will use different organization name and email add to advertise vacancy . And their requirement always be any course of study so that they can get large number of people. After they have gotten your contact, they will now send sms to u with their original name calling u for interview. please, do not let them waste you time they don't have any job. I don't understand why you should tell a graduate to pay money to get a job that is not visible. |
Please, If you get sms from MEDPRO GLOBAL RESOURCES,161 Ikorodu rd beside Lanre Shittu motors Onipanu B/S calling for aptitude test or interview, do not attend. Those people are scammers, after wasting all your day with meaningless long lecture they we ask you to pay 9k to get a job. This how how they get people; They will use different organization name and email add to advertise vacancy . And their requirement always be any course of study so that they can get large number of people. After they have gotten your contact, they will now send sms to u with their original name calling u for interview. please, do not let them waste you time they don't have any job. I don't understand why you should tell a graduate to pay money to get a job that is not visible. |
Please, If you get sms from MEDPRO GLOBAL RESOURCES,161 Ikorodu rd beside Lanre Shittu motors Onipanu B/S calling for aptitude test or interview, do not attend. Those people are scammers, after wasting all your day with meaningless long lecture they we ask you to pay 9k to get a job. This how how they get people; They will use different organization name and email add to advertise vacancy . And their requirement always be any course of study so that they can get large number of people. After they have gotten your contact, they will now send sms to u with their original name calling u for interview. please, do not let them waste you time they don't have any job. I don't understand why you should tell a graduate to pay money to get a job that is not visible. |
Please, If you get sms from MEDPRO GLOBAL RESOURCES,161 Ikorodu rd beside Lanre Shittu motors Onipanu B/S calling for aptitude test or interview, do not attend. Those people are scammers, after wasting all your day with meaningless long lecture they we ask you to pay 9k to get a job. This how how they get people; They will use different organization name and email add to advertise vacancy . And their requirement always be any course of study so that they can get large number of people. After they have gotten your contact, they will now send sms to u with their original name calling u for interview. please, do not let them waste you time they don't have any job. I don't understand why you should tell a graduate to pay money to get a job that is not visible. |