Welcome, Guest: Register On Nairaland / LOGIN! / Trending / Recent / New
Stats: 3,165,725 members, 7,862,319 topics. Date: Sunday, 16 June 2024 at 01:49 PM

.. - Culture (72) - Nairaland

Nairaland Forum / Nairaland / General / Culture / .. (1834188 Views)

"We The Ewe People Of Ghana Are The Same As Yoruba"- Yewe2011.ewe Guy From Ghana / How Do U Spell (weed) In Yoruba, Is It Igbo? Or Egbo? / Yoruba Idioms: Owe Yoruba, Itunmo Re Ati Lilo Re (2) (3) (4)

(1) (2) (3) ... (69) (70) (71) (72) (73) (74) (75) ... (99) (Reply) (Go Down)

Re: .. by Ifankaleluya: 4:03pm On Apr 10, 2016
Ifatoki16:
Baba Ifankaleluya,eku atunse ati agbaale wa lori ikanni yi.Ejoo emi Ifatoki16 bere fun imule awon aje ti won fi nfi ami igba si aya wa tie fi sita ti ko pe.mo bere ni ori email yin,sugbon e ko dami lohun lati igba na.tabi e nbinu simi ni.email mi ni eyi llcatz@yahoo.com

e-mail po ti mo n fo esi si ni. E ma ti binu, n o da esi pada laipe.
Re: .. by Ifatoki16: 4:16pm On Apr 10, 2016
Baba mi agbalagba Ifankaleluya,e ma pe mo ba yin loye mope yin loruko,oruko la fi npoba alade.mo ti fi nomba ero ipe mi sori ibere mi tie ba fe ka soro labe aso. o nbe ninu o ku sikun.gbogbo nkan ko ni a le ma bere ni gbangba.Orunmila a gbe yin oo.
Re: .. by wale259(m): 9:42am On Apr 11, 2016
E jo sir,se a ni mu owo(money) yen kuro ninu igba yen ti a fi ma ko ose le Oga lori.[quote author=fxopen post=44432917][/quote]
Re: .. by Tevez83839: 6:44pm On Apr 11, 2016
Healthfirst/kadunasouth .
Edakun oogun wo ni mo le ri mo inu shop ki customer le maa wa .miota ..oorun la n sun..emi ati awon omo ise mi..mo fe ki shop mi dabi oja .
Re: .. by Tevez83839: 10:02pm On Apr 11, 2016
Dis is my number
Re: .. by Tevez83839: 10:03pm On Apr 11, 2016
Ibaoooooo
Dis is my number 08162736520 whatsapp me pls....kaadunasouth or healthfirst adebayoyusuff41@gmail.com
Re: .. by horlakunmy: 8:15am On Apr 12, 2016
Are u sure that u
Re: .. by adeten: 1:28pm On Apr 12, 2016
08050500178,add me to group and whatsapp please
Re: .. by Nobody: 4:01pm On Apr 12, 2016
Ifankaleluya:

e-mail po ti mo n fo esi si ni. E ma ti binu, n o da esi pada laipe.
baami, mi ti kan si yin lori e-mail yin nipa esi lilo ogun yen fun ojo die oo
Re: .. by Ifankaleluya: 7:20pm On Apr 12, 2016
Oyeku-ka

Ifa ni;

Eke(do mi) ni Olorisa to ni iru oun ko si

Ti nyowo aso-funfun lala

Dia fun Asise(do do re)

Eyi ti segbon Orisa

Nijo ti n tikole orun bowa ile aye ebo won ni kose

O gb'ebo nibe o si sebo

O gb'atuka esu o si tu

Egun(mi mi) kan kii seni

Orisa(do do do) kan kii le loro(mi do)

Asise nikan lo le loro

Lo ju gbogbo ebo lo

Mo gbadura wipe ki Eledumare o fi oju fo Asise ti Onikaluku wa ti se to da aye wa ru. Ase!

Aboru, Aboye, Abosise!

1 Like

Re: .. by Ifankaleluya: 7:22pm On Apr 12, 2016
WiLdFLame:

baami, mi ti kan si yin lori e-mail yin nipa esi lilo ogun yen fun ojo die oo

Mo ti ri e-mail yen....sugbon boya ka soro labe aso ti mo ba ti raye.
Re: .. by Ifankaleluya: 7:30pm On Apr 12, 2016
wale259:
E jo sir,se a ni mu owo(money) yen kuro ninu igba yen ti a fi ma ko ose le Oga lori.

@wale259, thank you so much 4 wht you sent to appreciate all wht you av got 4rm m. May GOD continued to bless you!

A ko ni mu owo yen kuro nibe rara, a ma fi Oga yen lo owo yen lori ni a fi ma gbe ose yen le mole.

2 Likes

Re: .. by Ifankaleluya: 7:39pm On Apr 12, 2016
[quote author=Tevez83839 post=44546648]Edakun shop yen fee die .e koo fun mi boya mo le see. Tabi ejowo e add me 08162736520.EDAKUN OJA KO WA[/quote

Kiise oun gbogbo lo je mo Ogun sise..! E se koko lo se iwadi oun to fa idiwo ki e to ma wa ogun kiri?
Ati wipe iru ise ti e n se yen o pon dan-dan pe ki e ri nkan mo shop yin. Nko mo igbagbo yin ninu ogun ririmo shop. Ko pon dan-dan ki e waste owo yin lati fi se Ogun ti ko ni sise...! Sugbon ti o ba sa wu yin lati ri nkan mo shop yin, e kan si mi lori e-mail.

1 Like

Re: .. by Nobody: 7:40pm On Apr 12, 2016
Ifankaleluya:

Mo ti ri e-mail yen....sugbon boya ka soro labe aso ti mo ba ti raye.
e se baami!
Re: .. by marv006: 8:06pm On Apr 12, 2016
OBARA IKA

Kowe awo aye, ogbigbi awo isalu orun. Bi kowe awo aye ba ke awon agbagba aye a ma gba ode orun lo, bi ogbigbi awo isalu orun bake awon omo wewe orun a ma bo wa saye, ese oba akaye, ese oba akaja, ni won sa'agede fun orunmila nigba awon ota rogba yika, ifa ni to ba sebi temi -omo- bani, emi o segun ota, emi o reyin odi, iba se oso/aje/emere etc ni nba sa simi ni, ewe owo ni yio ma wo awon ota mi losorun, eru ni yio ma ru ibi won to won lo, bi igbin ba fa ikarahun re atele, obaraka bami ran awon ota mi lo sorun.

EWE IFA: ewe owo wewe, eru awonka, igbin kan. Ao jo won po pelu igbin na tikarahun re. Ao wa ni ihoho, ao te ebu na ni obara ika ni ilele lori cement lenu ona yara wa, ao pe igede na si,ao ka owo wa seyin lori ikunle, ao la pelu ahon wa. ao ta epo si oju ilele ti ati la ebu na. Ise yi wa fun eni ti o ba ni ota pupo. Ekan losu laoma la.

IBA ELEDUMARE OBA TO BA LORI OUN GBOGBO, IBA RE ORI MI, IBA EYIN AFINJU EYE TI NJE LORU TI IDAGIRI KI DA LONA, IBA GBOGBO AWO TI O WA LORI PAGE YIO. ABORU ABOYE ABOSISE O.

1 Like

Re: .. by marv006: 8:49pm On Apr 12, 2016
Not real
Re: .. by marv006: 9:15pm On Apr 12, 2016
IFA NI:

IFA NLA NLA LA FI GBAFA NLA N LA,
OGUN NLA NLA LAA FIGBA OGUN NLA,
EGBASERE LAA FI TANRAN SERE,
IGBA TA BARI SERE MO, EMI LA FI TANRAN EGBA RE,
ADIFA FUN OLOKUN NIJO ERI GBOGBO NBA SOTA,
OSE BOWO FUN OLOKUN, OLOKUN LAGBA OMI,
ERI GBOGBO EBOWO FUN OLOKUN,
OLOKUN LAGBA OMI.

1 Like

Re: .. by marv006: 9:26pm On Apr 12, 2016
IFA NI:

BI IGI BA DA, IGI AYERI, BI ENIYAN BAKU,
AKU ENIYAN SASASA NILE, BI ENI ORI ENI BAKU,
ENI ILELE ASIDI ENI ORI ENI, ADIAFUN ARABA PATAKI,
EYI TI YIO KEYIN IGI OKO............
Re: .. by wale259(m): 2:11pm On Apr 13, 2016
E se mo dupe sir
Ifankaleluya:


@wale259, thank you so much 4 wht you sent to appreciate all wht you av got 4rm m. May GOD continued to bless you!

A ko ni mu owo yen kuro nibe rara, a ma fi Oga yen lo owo yen lori ni a fi ma gbe ose yen le mole.
Re: .. by marv006: 6:30pm On Apr 13, 2016
ORUNMILA NI TALOTALASAN BA ROKUN,
WONI ORI NIKAN LO TALASAN BAROKUN,
AKAPO EJUESI, EDAWO OBUN KEDASOROMI.
MAPO ELERE, MONBA OTUN, BOLAJOKO,
OKINKIN TI TO MERIN FON, O NI TA LODA ORI
NIKAN TOTALASAN BAROKUN. ORI NIKAN NI NGBENI,
TI NBA LOWO LOWO, LOWO ORI NI, TI NBA FE AYA,
LOWO ORI NI, TI NBA BIMO, LOWO ORI NI,
TI NBA NIRE GBOGBO, LOWO ORI NI, ORI NI N O MA ROFUN,
ORI MIO, ORI MI ATETE NIRAN, ATETE GBENI KO OSA,
KO SI OSA TI N DANI GBE LEYIN ORI, ORI MI PELE O.
BI BABALAWO/OLOSA/ONISANGO BAKU, WAN KO ORISA RE SONU,
TI ENIYAN BAKU KOSI ENI TI WON GE ORI RE LE,
WON SINI PELU ORI NI, ORI MI PELE O, ATETE NIRAN,
ATETE GBENI KOOSA, KO SI OSA TI NGBENI LEYIN ORI.
Re: .. by marv006: 6:47pm On Apr 13, 2016
ORUNMILA NI ODI EDUN, MONI ODI EDUN.
ORUMILA NI ODI EDUN OKAN, MONI ODI EDUN OKAN,
ONI TI EGBE ENI BA NBA LOWO TABA LOWO,
ORI ENI LAA NKEPE, ONI TI EGBE ENI BA NSE OUN RERE,
TI ABA RI OUN RERE SE ORI ENI NA LAA NKEPE,
NJE ORI MIO O, WA SE ELEGBE LEYIN MI O,
IGBA IGBA NI OROGBO NSO LOKO, IGBA NI OBI NSO LOKO,
IGBA NI ATARE NSO LOKO. AJE KO WOLE TOMIWA,
OOGUN, AISAN, AITOEGBE,IKORIRA ETC KO POORA,
TI EFUN BA WONU OSUN APOORA, KI GBOGBO WHALA MI O POORA, AAWISE NI TI IFA, AFOSE NI TI ORUNMILA,
ABA TI ALAGEMO BA DA NI ORISA OKE NGBA, KAN KAN NI
EWE INA NJO, WARA WARA NI OMODE NBO OKO ESISI,
ILE OGBA ONA OGBA NI TI ARAGBA, GBOGBO EYI MO WI, KI ARO O RO MO.
Re: .. by marv006: 8:05am On Apr 14, 2016
OSEFU

Bi ori osunwon, ogbon inu ni keito,
Omi nbe nile olokun, okun olori omi,
Omi nbe nile olosa osa ibikeji,
Ogbon nbe ninu akoda, akoda ti nko gbogbo aye nifa,
Oro nbe ninu aseda, aseda ti nko gbogbo agba ni imoran,
Ogbon nbe ninu orunmila amayegun, odudu ti ndu ori emere
atunritikosunwon se,
A daa fun awonkomoosekomoowa ti nfi ojoojumo kegbe ori aisunwon, pe oba eleda ti se awon ni ibi,
.............................komonosekomonowa to ko ifa,
Ori re sunwon nigbeyin ni.
Re: .. by marv006: 8:12am On Apr 14, 2016
AJEGUN AWON BABA NLA WA RE OOO

Ika arin eranko ti a npe ni eero/inaki, ati oko atare kan ni ao jo po ti ao fi sin gbere yika orun owo wa, wa si arin ika wa ti oga julo.

FUN AWON TI OGUN KI JE LARA WON

Ao gun ewe eyin olobe pelu awo inaki die mon ose ao ma fi we.

1 Like

Re: .. by Lero70: 8:32pm On Apr 14, 2016
marv006:
Ibo lajari laja ngbo, adifa fun Osa nla Oserimogbo
ti yio bimo meji lojo, obi osan, obi oru, emi - lobi siketa won
Oso se se se ko le pa osan beni ko di osan lowo, aje se se se ko le pa osan beni ko le di osan lowo, oso sesese ko le pa oru
aje sesese ko le pa oru, gbogbo alagbara aye sesese won ko le pa osan beni won ko le pa oru. Nigbati won ko ti le pa osan ati oru ti won ko sile di osan ati oru lowo, moni won koni le pa emi-omo- naa. eni ti oba ni oun pa mi tabi to loun o mo dina momi
Apadari ni won pa oka, apalado ni won pa ere, apa gbe sonu ni won pa opolo, ikukiku ni ki oni toun o ku, awon ajogun orun ni kiwon bami dari onitoun si ode orun, nitori ooro gangan, ibere gangan ni won beri aja s'ogun, ooro gangan ibere gangan ni ki awon ajogun orun bami dari ountoun si ode oru, ki eni na ori ija ogun, ki ogun o bami mu oni toun lo si ode orun, ki ona mi ogun rege ni ile aye mi.

EWE IFA: Ao ge die kuro ni orun aja ti won ti be si ogun, ori oka, ori ere, opolo toku lojo. Ao teni EEPA-ODU / ORANGUN MEJI.
NOTICE: Eni keni toba lo ise yi ti gbe esu mi nu oo, iru eni be yio soro saasi, koda onisegun toba teri si, orun awo.

You can thank me later...
ejowo alagba efunwa ni ise yi tan, nitori mo sakiyesi pe oseese ki eroja yi siku, tobasijepe otitan, ekoso bi asemaasee ati bi asemaaloo funwa. Orunmila yio gbeyino

1 Like

Re: .. by marv006: 10:46pm On Apr 14, 2016
OSE-IRETE ( OSE BI IRETE SI ILE AJE)

IFA O DI ALAJUBARAKA, EMI O DI ALAJUBARAKA,
BI ABA LO JUBARAKA KIO JUBARAKA, OBI OLOTOORO,
OBI OLOTEERE, OBI ONAWOFUNMIRIN, ONAWOFUNMIRIN
LO BI AJE, AJE LO BI ENIYAN, AJE DI ORE OLOKUN,
ENIYAN DI ORE IRADA,
OSE KIO SAREGEGE LO RE MU AJE WA FUN MI NI ILE OLOKUN,
IRETE KIO SAREGEGE RE IRADA LORE MU ENIYAN WA FUNMI,
APE KIO MAJE KI IRE MI PE KIOTODE, EJINRIN KIOMAJE KI
IRE MI RIN JINA KIOTODE, BI ABA GBALEGBA'NA,
AATAN LA NKORIRE SI, IRE GBOGBO KO WA BA MI NI JEBUTU,
IRE GBOGBO KO MO DARI SODO MI.

EWE IFA: ewe ape, ewe ejinrin, yerupe atan to gba igba ese, omi okun, ose, osun pupa not osun buke o, eje eyele funfun meji; okan fun ose okan fun irete, ara ogiri yara wa ni ao pari ise yi si o. Aini di gberee nu o, ifa awon baba nlawa niyio o, eyi ti alefi okete ti nse eran ifa na gbe ebo re wa.

1 Like

Re: .. by marv006: 11:56pm On Apr 14, 2016
IFA NLA KAN RE O( OSO)

EWE IFA: eran ifaa(okete) aaye, ewe akiriboto, aso waji, aso odo egungun pupa, egun erin, egun efon, eku eda, eja aro, ikoride, iye agbe, iye aluko, epo ose, epo odan , igi asorin, imi ojo, ataare ati .......,

IFA: Osemi so mo te idaro bo enu, emi kowaye to poburukoso(3x)
aye awagbo, aye awato, ayeawa se oun re re le oun rere ni ile aye ti mo wa. Won bi mi kini mo ndu, moni igbe aye rere ni mo ndu ti mo du titi wo gbaja ola, won bimi ni gbaja ola pe kini mo nwa, moni mofela, mofe lowo pupo, mofe bimo laye, mofe kole monle, mofese gbogbo oun rere ti egbe mi nse, won bimi se moti tee, moni moti tee, won bimi nigbati ti mo te tori kini mose tee, moni tori awon iyami osoronga, won bi mi pe nibo ni mo ti tee, moni mote ni tese lakokote kato te oju opon, moni mote ni gbaja ola, moni mo te loja iyee, moni mote niso adie, moni mo te ni wonran nibi ojumo ti ntimo wasaye, moni mo te ni oke igeti nile agbonmiregun, moni mote ni owo ire, moni mote ni sonso ori ako. Wontunbimi pe awon tani olugbenide ati olutunisile, moni eleda ni olugbenide ati olutunisile, won tun bimi pe awon tani olugbenide ati olutunisile, moni awon aje iya mi osoronga ni olugbenide ati olutunisile, wontun bimi pe tani eni dudu ati eni pupa, moni emi ko mo eni dudu ati eni pupa o, woni awon eni dudu ati eni pupa ni awon ajana jo omo, tiwon ma n fi owo won aluse fitilekun ola mo omo eniyan, eyi to jepe won yio fi owo won se kokoro fi silekun ola temi funmi ni kiakia, nigbana ni won ni ki nma lo si KARAKATADINLOGUN, nigbati mode be mo ba awon enia DUDU BI ASO WAJI, MO BA AWON PUPA RORO BI ODODO ASO EGUN,MOBA AWON ASOMU SOMU TI NMO SO OWO(HAND) OMO ARAYE MO IGI, MOBA AWON OSOYO SOO, AWON TI WON MA NJE ERAN LENU MAKUNA, MOBA AWON ADURO SEGE LORI ODO IGUNYAN FUN ORO, MOBA AWON SOKO DOMO, MOBA AWON SOKO DEJE, KANAKANA SOJU WASO WASO, gbogbo won tun bi mi pe se moti tee, moni moti tee, nigba na ni woni odi dandan ki awon o ko simi lapo kinmari oun mu sowo kale aye kiri, woni kin ma losi okakan gangan, woni nibeni mati pade ola temi, ni mo ba nlo nigbati mode agbede meji ona mo ba awon IYAKAN IYAKAN, MOBA AWON IYA LOLOGBAJA TI WON JOKO REMUREMU LABE IGI OSE, mo kiwon ni iki irele fun enitobajunilo, won bimi pe kini mo nwa, moni awon gangan ni mo nwa ti mo tun wa eyonu yin ati idunu yin si ise ati oun gbogbo ti mo ba nse, woni nitorikini mose nwa eyonu ati idunu awon, moni lati ojo ti mo ti gbonju saye timoti nri eni dudu ati eni pupa eyin ko ti fi oju rere yin wo mi,.......TO BE CONTINUED..
Re: .. by marv006: 1:18am On Apr 15, 2016
Atanpako ku re lese,
gbogbo ara ojo rin pee,
bi ababa pe oku ni popo,
alaye ni n daun,
adi'fun Jewesun
ti nse akanbi Eledumare agotun,
olomo ateni ola, legele f'ori sagbeji,
nigbati onbe nigbatemu omoaraye,
ebo ni won nio se,
ero po, ero ofa...
........

......Ifa loso be.
Re: .. by hussainhassan011: 4:34pm On Apr 15, 2016
Ekuse sir,Oluwa awa pelu yin
Re: .. by marv006: 4:51pm On Apr 15, 2016
ASINA KEKE KAN NI O

ORI OKETE
EGBO TUDE
ERU ALAMO
EWE EJINRIN ATI
EWE EWURO.

ao jo, aolo, aoteni OTURA-OGBE.
ao fi eje eyele po, ao su si ona meta,
aofi REGAL lofunjo meta.
Re: .. by omoalade144(m): 6:39pm On Apr 15, 2016
Moki gbogbo ile o.Ejoo se baba Heltfirst kosi nile ni

(1) (2) (3) ... (69) (70) (71) (72) (73) (74) (75) ... (99) (Reply)

(Go Up)

Sections: politics (1) business autos (1) jobs (1) career education (1) romance computers phones travel sports fashion health
religion celebs tv-movies music-radio literature webmasters programming techmarket

Links: (1) (2) (3) (4) (5) (6) (7) (8) (9) (10)

Nairaland - Copyright © 2005 - 2024 Oluwaseun Osewa. All rights reserved. See How To Advertise. 46
Disclaimer: Every Nairaland member is solely responsible for anything that he/she posts or uploads on Nairaland.