Welcome, Guest: Register On Nairaland / LOGIN! / Trending / Recent / New
Stats: 3,151,466 members, 7,812,426 topics. Date: Monday, 29 April 2024 at 01:12 PM

Itan Ilorin Laderin - Culture - Nairaland

Nairaland Forum / Nairaland / General / Culture / Itan Ilorin Laderin (5744 Views)

Awon Itan Wo Ni E Ranti Nigba Kekere Yin??? / Itan Yoruba / Itan Eye Odidere (2) (3) (4)

(1) (Reply) (Go Down)

Itan Ilorin Laderin by gawab: 2:18pm On May 16, 2015
Oju mi ti ri to ninu itan eti mi si ti gbo to ninu iwadi ijinle debi pe eru ohun to le sele lehin ti awa ti a nbe laye ni saa yi ba lo tan nba mi nitori a nso nipa itan awon eni ana bawo ni Itan yio se so nipa ti wa gan.
Loni awuyewuye po lori ilu Ilorin Looto ni itan Ilorin ko fi be ru'ju sugbon ase ilu ti bo lowo awon omo onile to si je pe Iran ajeji lo nje Emir nibe loni, sugbon mo fe ka mo pe lara ilu ti itan won je ogbé okàn fun awon opitan ni ilu Ilorin wa.

LADERIN LO TE ILU ILORIN

Awon opitan gba pe omo bibi Oyo Alafin ni Laderin sugbon ironu mi pin yeleyele lori itumo Laderin yala Oladerin ti won pa ìró je ti yio wa je Ola-dode-erin ti o ba je Oladodeerin ni a je pe omo ola ni Laderin ni Ilu Oyo sugbon to ba je pe Laderin ti o tun lo ba bayi ni Ola-di-erin iyen nipe ola di erin Yorùbá mo nso oruko eniyan mo eranko tabi igi ati odo lati le saponle eniyan tabi idile kan, to ba je oladierin ni omo ola ni loyo ti won si juwe ola awon dabi ti erin nitori Yorùbá a ma ni erin nsola ninu igbo nitori ohun ni eranko to tobi ju.
Laderin je ode ati akoni sugbon kiise eso nitori omo ola Òyó ni kiise abuku ka ni awon omo Oba Òyó nse ode tabi awon omo Oyo Mesi nitori kosi eni ti ki da oko nile Yoruba yala idile Oba ko ba je Akeyo (Prince of Oyo) be sini anfani wa fun won lati se ode nitori won mo nse owo lati ilu kan si ekeji tabi si awon orilede iru eyi ti Aole se lo ilu Apomu lorilede Owu si Ife saaju ko to di Oba.
Yoruba ni eni ti yio pa erin ko to ju egbe eyi yio je ka mo pe ki se ode lasan ni yio pa erin ogbologbo ode ni, lara ogbologbo yi ni Laderin wa, ohun oju ode ri ni iju won ki dele wi nitori won mo npé ninu igbe ode, ninu igbe ode yi na ni won tun mo npago si lati le mo ko nkan isura si ati lati mo sun pelu awon ode tun mo npade nibe ti eyi yio si je ki awon ode mo iyeju awon ode akoni to wa sode ni agbegbe na.
Iwadi je ka mo pe ibi ti Laderin pago si yi ni okuta kan wa to ti mo nlo ada, obe ati ida re ti won fi irin se ti awon ode to nwa sodo re na mo nlo ada won nibe, awon ode na ipago tiwon nitori ahehe ni won nko a ko le so boya ibe ni Laderin ba oluta yi tabi oun lo yi wa ibe sugbon okuta yi gbajumo larin awon ode latari pe o mo nlo irin won mu dada, a nlo lo irin lodo Laderin lo di Ilorin tabi ka ni esi ibere pe kini o nfi okuta to wa niwaju ago ode re se to si dahun pe ilorin ni lo mu oruko Ilorin waye okuta ti Laderin nfi irin lo lo nje Ilorin.
Diedie awon ode npo si ninu igbe ode iwa ooto ati akoni Laderin je ki awon ode mo wari fun ti opo awon to si wa ra eran igbe ati èyà ara erin si njoko de lasiko to ba se ode lo nigbati o kiyesi eyi o pago to je ile elewe bi meta si ki awon eniyan le mo ri aye sun papa oju ona ero ni ago Laderin wa nikehin opo awon ode ko ago won sile won si lo ipago tuntun si odo Laderin, niwon igba to je omo Ola ni Loyo kosi ewu fun lati pago tabi so ago ode di abà nitori ola ni nse be ni.
Kere kere awon eniyan bere si po ni aba Laderin be ni aba di abule ti abule si di Ileto, Lasiko ti Laderin fi ndabira awon obi re wa ni Oyo inu Òyó na won si ku ti won si sin won si lehin iku awon obi re opinu lati so Ilorin di ile o si gba ase lowo Alafin pelu adehun sisan isakole, Laderin ni Bale Ilorin akoko emi re gun dada ko to ku sugbon Ileto ti ile ibe ko ju bi ogun pere lo fi Ilorin si ile ewe sini pelu.
Yara loka apa keji, keta ati ikerin ni www.itanyoruba.com
Re: Itan Ilorin Laderin by simplymade(m): 2:19pm On May 16, 2015
Ewo tun leleyi bayi
Re: Itan Ilorin Laderin by Rilwayne001: 2:20pm On May 16, 2015
Mo npada bo wa ka ita yi.
Re: Itan Ilorin Laderin by Nobody: 6:17pm On May 17, 2015
Mo mo wipe abule Oyo ni Ilorin sugbon Laderin yi ni mi o ti gbo ri.

Itan to dara ni; e fun wa ni apakeji. Wa yi, mo nlo si linki ti e fun wa lati ka a gbadun.

(1) (Reply)

Attah Of Igala Didn’t Invoke Thunder On Fulani Herdsmen – Palace Source / Lagos Belongs To Awori, The Bini Met Them There- Akintoye / How Horn Of Africans Are Trying To Steal African Culture

(Go Up)

Sections: politics (1) business autos (1) jobs (1) career education (1) romance computers phones travel sports fashion health
religion celebs tv-movies music-radio literature webmasters programming techmarket

Links: (1) (2) (3) (4) (5) (6) (7) (8) (9) (10)

Nairaland - Copyright © 2005 - 2024 Oluwaseun Osewa. All rights reserved. See How To Advertise. 21
Disclaimer: Every Nairaland member is solely responsible for anything that he/she posts or uploads on Nairaland.