Welcome, Guest: Register On Nairaland / LOGIN! / Trending / Recent / New
Stats: 3,152,747 members, 7,817,061 topics. Date: Saturday, 04 May 2024 at 02:17 AM

Ibadan Omo Ajorosun: Ohun To Ye Ke E Mo Nipa Ilu Ibadan - Culture - Nairaland

Nairaland Forum / Nairaland / General / Culture / Ibadan Omo Ajorosun: Ohun To Ye Ke E Mo Nipa Ilu Ibadan (2831 Views)

Oro Nipa Osole Owo Nla / Awon Olorin Naijiria O Ni Agbekale Ohun To Yato - Paul Play Dairo / Ibadan Omo Ajorosun: Ohun To Ye Ke E Mo Nipa Ilu Ibadan (2) (3) (4)

(1) (Reply)

Ibadan Omo Ajorosun: Ohun To Ye Ke E Mo Nipa Ilu Ibadan by OlayemiOniroyin(m): 6:58pm On Aug 28, 2015
Leyin awuyewuye to ro mo ipapoda Oba Sijuwade
Olubuse II, Ooni ti Ile-Ife ati bi awon oloye se tako
iroyin to jade nipa bi baba se goke aja, won ti pada
so wi pe lotito ni Oba to wa ni ipo keta ninu awon oba to lowo ati ola ju ni ile Afirika ti lo ba awon babanla re.

Ni odun 2014 ni magasiini agbaye Forbes se atejade
awon Oba ile adulawo marun-un ti won lowo ju lo.

Bi won se to lori ila ni yii:
1. King Mohammed VI, Morocco
2. Oba Obateru Akinrutan, UgboLand, Nigeria
3. Oba Okunade Sijuwade, Ile-Ife, Nigeria
4. King Mswati III, Swaziland
5. Otumfuo Osei Tutu II, Ashanti, Ghana

Lonii, Oba Okunade Sijuwade o si mo, ki lo fe sele si
awon ola ati dukia oba ti a bi ni ojo kinni osu kinni,
odun 1930?

Iroyin to koko jade fi ye wa wi pe ojo kejidinlogbon
osu keje odun 2015 ni Alayeluwa Oba Okunade
Sijuwade gbese ni ile iwosan to wa ni ilu London leyin aisan ranpe.

Bi o ba je wi pe ilu Nigeria ni baba dake si, o seese ki iroyin yii ma lu sita saaju igba ti awon oloye kede
ipapoda oba naa.

Ayafi ti a ba n tan ara wa je, iroyin to jade saaju ikede yii mu edun okan deba awon asaaju isese Ile-Ife ati ile Yoruba lapapo. Eyi lo fa bi awon oloye se n binu ti won si n kanra mo awon oniroyin.

Gege bi Oba to wa ni ipo keta ninu awon oba to lowo ju lo ni ile Afirika, kini Oba Okunade Sijuwade ti se lati mu eto ilera gberu ni Ile-Ife tabi Naijeria lapapo?

Pupo ninu awon olori/oloselu wa naa lo feran lati lo
maa gba itoju ni oke-okun laibikita fun awon ile
iwosan wa gbogbo.


Ti a ba yo Ile iwe Ifafiti ti Obafemi Awolowo to je ti
ijoba apapo to wa ni Ile-Ife kuro, kini ohun
idagbasoke ti a tun le naka si to wa ni Ile-Ife? Iru igbe aye wo ni awon odo n gbe? Iru ipo wo ni awon
wa? Eto wo lo wa fun awon omo wewe? Se
igbelaruge asa ati isese nikan lo se pataki julo ninu
igbesi aye eda laibikita fun igbe aye awon mekunnu?


Ti a ba n so nipa owo, ola, iyi, agbara, okiki ati ipo, eyi to poju ni Edua fi fun omo Adelekan. Sugbon ibeere mi ni wi pe, nje awon nnkan yii fara han ni Ile-Ife to je orirun Yoruba? Sebi awon Yoruba nibi ta ba pe lori, enikan ki fi ibe tele.

Kini ni awon oyinbo ni ni awon ile iwosan oke okun ti awa naa ko le ni? Iwadii tile fi ye wa wi pe pupo ninu awon dokita alawo dudu ti won sise ni ilu Amerika ni opolopo won je awon omo Nigeria. Ani awon olopolo pipe sugbon ko si ohun elo to munadoko.


Oba Okunade Sijuwade ko si mo lonii, Alayeluwa ti
gbe aafin re lo salakeji, oba to je leyin Adesoji

Aderemi ti deni idaro, omobibi inu Yeyelori Emilia
Ifasesin Sijuwade si ti deni agbe gege, ko si ni wu mi
ki n si awon iwe iranti eleyii to se afihan awon asise
tabi tabuku Oba gidi.

Boya tori wi pe Ooni ti sise ri gege bi Oniroyin
akoroyin fun ile ise iroyin The Nigerian Tribune lo je
ki n fe daso ro lara. Sebi won ni awo kii se ibaje awo. Eewo orisa!


Mi o ni so ipa ti Baba Tokunbo ko nipa June 12 ati bi
iya ojosi se je Mosuudi 'Emuke' Abiola lajegbe? Mi o
ni menu ba asise oko Olori Monisola. Mi o ni menu
ba bi Asoju Oodua se koyin si omo Yoruba nitori
owo. Awon alaye yii wa lodo ikun mi sugbon mi o ni
dale awo ise iroyin laelae.

Mi o ni salaye bi Ibrahim Babangida se ri ona wo
ojubo Oduduwa Atewonro. Mi o ni so nipa eni to gbe Oye Adimu, okan ninu awon oye pataki ni ile Yoruba fun Atiku Abubakar nitori owo.

Mo ti pinnu wi pe mi o ni so iye owo dollar ti Oga Jonathan gbe lo saafin baba Adedotun lati ra awon oba ile Yoruba pa raurau. Awon asiri wonyii ni mo ti pinnu wi pe mi o ni tu; mo si se ileri wi pe mi o ni se bee.

Se ija to wa laaarin Ooni ati Alaafin tile pari patapata abi ife oju lasan ni won ba ara won se?

Kini awon agba mejeeji jo n du mo ara won lowo? Akoba wo leyii se fun awon omo Yoruba?

Olayemi Oniroyin, bi eniyan lami lofun mi o ni soro.
Mo ti tilekun enu mi bi enu bode ewon. Mo si ti ko
gege-ikowe mi logbon ohun ti mi o fe ko ko faraye ri.

Mi o ni so gbogbo ohun ti mo mo nipa oko Olori
Ladun Sijuwade; eyi ti mo mo nipa olowo ori Dalapo
ni mo si ti faso bo mole patapata.

Bi eniyan ba fe mo bi baba Gbade Sijuwade se pataki to, ilu London ni ke e ti lo beere wo lowo oba
Elisabeeti, oba alaso funfun.

Sugbon lonii, Oba Okunade Sijuwade o si mo. Bi won fi egberun odun kun ojo ori baba, ojo kan o jokan ti
oba o pada waja naa ni.

Iku o pa eni a n pe, iku o pa eni ti n peni. Eni o waye ti o ni ku kan ko si, sebi gbogbo wa la o fi ile aye yii sile lojo kan.

Iku ti pa darodaro aso aro ko si lode mo.
Iku ti pa akosun, aye o rosun para.
Iku pa lekeleke, efun o si mo laye.
Oba Sijuwade ti se bee gborun lo, sangbafo!
Mo ki gbogbo ara Ife ooye lagbo, wi pe won ku
aseyinde oba Sijuwade.

Sebi eyin lomo olodo kan
oteere. Eyi lomo olodo kan otaara.
Odo to san wereke, to san wereke
To dehinkunle oshinle to dabata
To dehinkunle adelawe to dokun
Onikee ko gbodo bu mu
Ababaja won ko gbodo buwe

Ogedegede onisoboro ni yio mu omi do naa gbe
Soboro mi wumi, eje ki ibi dandan maa ba alabe
Won kii duro ki wa nIfe ooni,won kii bere ki wa nIfe
ooye

Ko ga, ko bere laa ki wa nIfe oodaye
Bi won ko si ki wa nIfe, won kii to abere
Oju bintin la fi n wo ni
Emi wa ki oba nIfe,mo lo akun
Oba nii lo sese efun
Adimula,won a ni apalado
Bante gbooro, ni mufe wumi
Segi owo ati tese,
Kafari apakan ka dapakan si
Yeepa orisa, aso funfun
Oun nii mu Ile olufe wumi
Apadari eni,apalado eniyan
Ebo ojoojumo,nii mu ile won su nii lo
Awa lomo oni fitila rebete
Ina ko nii ku nibe tosan toru
Ibe ni baba wa gbe n ka owo eyo
Awa lomo onilu kan, ilu kan
Ti won n fawo ekun se
Aketepe eti erin ni won fi nse osan re
Onikeke ko gbodo jo
Ababaja ko gbodo yese
Kikida onisoboro ni yio jo ilu naa ya
Ogun ko see da gbe
Baba taani ko mo wipe irin ti po lagbede
Oun ti o ba mu alagbede, ko ni mu eni to n fin ina.

www.olayemioniroyin.com/2015/08/ibadan-omo-ajorosun-ohun-to-ye-ke-e-mo.html?utm_source=twitterfeed&utm_medium=twitter&m=1
Re: Ibadan Omo Ajorosun: Ohun To Ye Ke E Mo Nipa Ilu Ibadan by Nobody: 6:59pm On Aug 28, 2015
grin

(1) (Reply)

Yoruba Tone Marker - Online Tool For Typing Tone Marked Yoruba Content / Meet The Longest Reigning Traditional Ruler In Africa! / Please Please Please Translate This Yoruba For Me !!!!

(Go Up)

Sections: politics (1) business autos (1) jobs (1) career education (1) romance computers phones travel sports fashion health
religion celebs tv-movies music-radio literature webmasters programming techmarket

Links: (1) (2) (3) (4) (5) (6) (7) (8) (9) (10)

Nairaland - Copyright © 2005 - 2024 Oluwaseun Osewa. All rights reserved. See How To Advertise. 27
Disclaimer: Every Nairaland member is solely responsible for anything that he/she posts or uploads on Nairaland.