Welcome, Guest: Register On Nairaland / LOGIN! / Trending / Recent / New
Stats: 3,153,204 members, 7,818,692 topics. Date: Sunday, 05 May 2024 at 09:52 PM

Ewi Yoruba - Literature - Nairaland

Nairaland Forum / Entertainment / Literature / Ewi Yoruba (4319 Views)

(2) (3) (4)

(1) (Reply)

Ewi Yoruba by fatigs88: 4:05pm On Nov 22, 2015
AGBA BI OMODE
- Ayoola omo Fadeyi

Agba bi omode

Bi e ri eni to fi opa tele

To soro omugo

Omode ni

Agba kii soro omugo

Bi e wa ri abirun funfun lori

To n fi ewu ori se bi ajunilo

To n fi ese janle kiri ladugbo

Omode ni

Pelu suru lagba fi n lo



Omode bi agba

Bi e ri eniyan to soro atata lenu

Oro ologbon, onilaakaye

Bose omode loju yin

Agba ni

Bi e ri abirun dudu lori

To soro atata

Agba ni



Ooto ni

Owo to fun agba

A bere terin pelu opa

A fi akamu je moinmoin sun

Agba onirun funfun lori



Ooto ni

Ohun agba ri nikale

Bomode garun lori ile oni-peteesi

Ko to be kori i

Agba ojo ori wa

Agba onilaakaye n be



Seri awon agba olojo ori

Awon ni won n mu emu takiti kiri ilu

Awon ni ko le tole won gunrege

Agbere o fi won sile nigba kankan

Gbogbo ise ibi, owo won lo kun mo

Bi a ba dagba, a yee ogun ja

Ko ni ti won

Won a so agbado modi, adie a si maa le won kiri



Wan tu tiri ko lafi n mo agba

O le se pataki niha ibi kan

Kii se gbogbo ibi

Bomode olojo ori bafe dagba onilaakaye

O to, ki o bowo fun agba olojo ori

O to, ki o bowo fun agba onilaakaye



Won a pe aadorin odun

Won a tun maa le omoomo won kiri ladugbo

Fun fife ko, agbere ponbele ni

Won a ni omoataye nile

Iya a je iyawo atomo

Owo ko lo tan nile

Tabi ise lo safeku

Oti ati burandi lo n dara

Oti ti poju oka won lo

Ohun laso fi n pon mo won lara



Eyin agba, e se bi agba

E huwa agba

Ki e le baa ko awon omo yin jen pepepe

Enu agba lobi n gbosi

Ki awon omode, ma tete mo iyi yin



Tani ko fe dagba tooto?

Tani ko fe dagba onilaakaye?

Agba to mo ojuse

Ki n ma dagba iranu, agba iya

Ki n ma dagba osi, agba bi omode

Mo seba agba

Mo juba agba.


---------------------------------
#AyF™
©2015
Re: Ewi Yoruba by fatigs88: 12:50pm On Dec 07, 2015
OGILINTI
- Ayoola omo Fadeyi

Ogilinti de, afefe tutu de
Orun an lodun, ooru mu
Ojo ro lodun, otutu mu
Ogilinti n dara, ategun tutu je

Orun to ran nibere odun
Lomu kii aso gbe labe ooru
Oye to n ja nipari odun
Lomu ki aso gbe labe otutu

Ninu ogilinti, ina ya jo
Ninu oye, aso ya gbe
Ninu ogilinti, ara ya tutu
Ninu oye, tii gbona ya mu

Okugbe rise se lasiko
Ogilinti loku ti yoo paro mo
Akekoo ti o le we l'owuri kutukutu
Oye yoo ran lowo d'oba

Bi ikoko r'oye, inu ikoko a dun sinkin
Oye kii mu ikoko
Bi agba r'oye, agba a fojuro
Aleyin laya ni oye n se lose

Inu oye ni gbogbo ile ti n tutu bi yinyin
Gbogbo ile wa di ile oluwere
Ti a n ba ni tutututu
Omi odo ti wole towo wa lona afefe yeye

Adin agbon rise se
Bi ko se ete, a se oju
Ete gbigbe, oju funfun balau
E ba mi gbe adin olororo ki n rihun fi para

Bi afefe fe, afefe tutu
Bi orun ran, orun tutu
Bi osupa tan, osupa tutu
Bi irawo yo, irawo tutu

Ogilinti gbe kata de
Gbogbo ilu lo n fimu
Eni mumu tutu ninu ogilinti se'rare pa
O digba omi tutu dekun ko to mo 'ki lo n se le'

Eyin agbe, e rora fina s'oko papa lasiko ogilinti
Oko papa a maa jo, a jo rohin rohin
Eyin dereba, e tee jeje lori popo
Ara n kan ategun, ara n kan betiro

E ba mi m'aso idabora ki oye ma baa gbe mi lo
Eruku Osodi kun'le kun'ko
Eruku Osodi kun'ko kun'le
Oye ogilinti, ogilinti oye

#AyF™
©2015
Re: Ewi Yoruba by fatigs88: 9:36am On Dec 14, 2015
fatigs88:

OGILINTI - Ayoola omo Fadeyi
Ogilinti de, afefe tutu de Orun an lodun, ooru mu Ojo ro lodun, otutu mu Ogilinti n dara, ategun tutu je
Orun to ran nibere odun Lomu kii aso gbe labe ooru Oye to n ja nipari odun Lomu ki aso gbe labe otutu
Ninu ogilinti, ina ya jo Ninu oye, aso ya gbe Ninu ogilinti, ara ya tutu Ninu oye, tii gbona ya mu
Okugbe rise se lasiko Ogilinti loku ti yoo paro mo Akekoo ti o le we l'owuri kutukutu Oye yoo ran lowo d'oba
Bi ikoko r'oye, inu ikoko a dun sinkin Oye kii mu ikoko Bi agba r'oye, agba a fojuro Aleyin laya ni oye n se lose
Inu oye ni gbogbo ile ti n tutu bi yinyin Gbogbo ile wa di ile oluwere Ti a n ba ni tutututu Omi odo ti wole towo wa lona afefe yeye
Adin agbon rise se Bi ko se ete, a se oju Ete gbigbe, oju funfun balau E ba mi gbe adin olororo ki n rihun fi para
Bi afefe fe, afefe tutu Bi orun ran, orun tutu Bi osupa tan, osupa tutu Bi irawo yo, irawo tutu
Ogilinti gbe kata de Gbogbo ilu lo n fimu Eni mumu tutu ninu ogilinti se'rare pa O digba omi tutu dekun ko to mo 'ki lo n se le'
Eyin agbe, e rora fina s'oko papa lasiko ogilinti Oko papa a maa jo, a jo rohin rohin Eyin dereba, e tee jeje lori popo Ara n kan ategun, ara n kan betiro
E ba mi m'aso idabora ki oye ma baa gbe mi lo Eruku Osodi kun'le kun'ko Eruku Osodi kun'ko kun'le Oye ogilinti, ogilinti oye
#AyF™ ©2015

Ki ogilinti odun yii tuwa lara, t'eru t'omo.

(1) (Reply)

Grace, The House Girl Asanwa Baby (A Short Romantic Story) / 48 Laws Of Power By Robert Greene. / My Landlady, Her Daughters And A Tenant (18+) Episode 15

(Go Up)

Sections: politics (1) business autos (1) jobs (1) career education (1) romance computers phones travel sports fashion health
religion celebs tv-movies music-radio literature webmasters programming techmarket

Links: (1) (2) (3) (4) (5) (6) (7) (8) (9) (10)

Nairaland - Copyright © 2005 - 2024 Oluwaseun Osewa. All rights reserved. See How To Advertise. 17
Disclaimer: Every Nairaland member is solely responsible for anything that he/she posts or uploads on Nairaland.