Welcome, Guest: Register On Nairaland / LOGIN! / Trending / Recent / New
Stats: 3,151,108 members, 7,811,121 topics. Date: Sunday, 28 April 2024 at 12:35 AM

Moraye Mosa Faye - Culture - Nairaland

Nairaland Forum / Nairaland / General / Culture / Moraye Mosa Faye (202 Views)

(2) (3) (4)

(1) (Reply)

Moraye Mosa Faye by absoluteSuccess: 11:03am On Oct 09, 2023
Eni ba mose okunkun,
Komase da osupa loro,
Eniba mo buburu daniloro,
Koranti pe ika nbowa konika.

Adabi ja o joogun,
Eni buburu e gbeje,
Osika tan tesemorin,
Ojokan, ewe yin asunko.

Nko tete mo pe erin o denu
Ope koto yemi pe enibi nrobi,
Bii kasun kama ji l'afemojumo,
Lonse ninu edoforo Osonu-Osika.

Ojumo moni saye tan inu tun bi won,
Won worun haun bi eniti ko nii kumo,
Won ni Talonje adaniwaye ninu ogbon Ori?
Won ni tal'Eleduwa to too beere wipe etiseyi?

Won go bii go koko,
Won se b'awon gbon.
Asiwere naa loun gbon,
Sibe ko mo imoran igbah.

Howu, enibi, awaye wa sebi,
Kilayo re ninu ko mukoro ba kowa?
Kilere re ninu pe dandan taidan iwoni?
Eni melo lo ti siju aanu wo lati jo to ti daye?

Edatorofo ika fomolakeji,
Omo Ila keji eni bii eni lori,
Bope boya omo re aje nibe,
Asegbe kan kosi e je lo gbeje.

Ori rii yin nile koto fun wa se,
Abinu eni o le pa kadara da laye,
Eyin l'omo adiye nto agbebo adiye,
Eyin no ni eyin abinu eni yoo ma wosi.

Gbogbo ogbon aburu yin ti dofo,
Oku kee maa fi ogboju se eyitoku,
Ase Alaanu n l'olodumare adaniwaye,
Oba tii gbani kato ko sofin amokunseka.

Ota ran alami simi,
Inu won ndun pe eleyi alo,
Agunfon won retireti, Erin goke Alo.
Owadi olowe, itakun to ni kerin ma goke Alo.

1 Like

Re: Moraye Mosa Faye by absoluteSuccess: 11:19am On Oct 09, 2023
Bi mo ba ji, make pori,
Koje ki ojo oni o sanmi,
Ko pamimo lowo osika,
Ko gbe rere komi lona.

Ko ranmi l'owo,
Ninu igbokegbodo mi,
Ki mma lalase ntojeun,
Kotamayomi laye timowa.

Oluwa modupe oregbogbo,
Eyin lese odidere loore, Aro,
Eyin naa lese aluko loore osun,
Ekosai se lekeleke ni ore ikefun.

Agbe setan, o lahun aro,
Aluko naa se, o lahun osun,
Lekele se tan, oun naa lahun efun,
Oluwa E seun tee se ogo oro ninu ayemi.

Eoje kaye o pa kadara mida saida,
Won petepero pe kowo kowo
Nitori to ba wo kiwon le ho,
Amosa, Alaurabi o sebi.
Re: Moraye Mosa Faye by absoluteSuccess: 11:51am On Oct 09, 2023
Oluwa dara, Oluwa seun,
Oluwa dunsin, ibale okan ni,
Eni ba sope iroko nloun yo bo,
Oluwere igbo duro gboin ninu oko.

Ase Ori lababo ka forisa sile,
Edaeni laba yan laayo ni koko-ibaba,
Nitori akii bori so ko nani l'owo,
Akii ro lokan kota 'o gbelemo.

Amo oun taa b'aro leti ore,
Nijo ti ore ba sein wa dota nko?
Odiwipe oro obo mo lenu alayo meji,
Ori, somi lowo oredota at'otadore eniyan.

Eleduwa, oba ateni legelege fori sapeji Omi,
Adake dajo, Oba tongbo oun ti eda nrolero,
Abeti lu kara bi ajere, eleti i gbaroye nibaba,
Ope kabiti nimomu to yin wa ninu iyaraero.

Bojumo, afefe lele won a maa seweoko yayo,
Boring ran, efufu lele asi segi oko gerugeru,
Baa woke, Ofurufu lo salalu bi ola Eleduwa,
Opin Awamaridi, tan'to tu aditu Olodumare?

Ng o ma se asaro ninu imo Re,
Ng o maa gbe O ga ninu oye too funmi,
Ng o maa s'ogo ninu ebun agboye Oro,
Ng o si maa ji kio sa bi ogun.

Bimo ba pe Eleduwa A je,
Oun loseda mi latinu eran ara,
Alamo to mo mi latinu ato denu ato,
Kabiesi Aseyiowu tii je Olodumare.

(1) (Reply)

Ikpakachin: The Guardians Of The River In Igala Culture / Rivers Community, Ogu Initiate Young Virgins Into Womanhood / Most Nigerians Are On Foreign Opium Drugs

(Go Up)

Sections: politics (1) business autos (1) jobs (1) career education (1) romance computers phones travel sports fashion health
religion celebs tv-movies music-radio literature webmasters programming techmarket

Links: (1) (2) (3) (4) (5) (6) (7) (8) (9) (10)

Nairaland - Copyright © 2005 - 2024 Oluwaseun Osewa. All rights reserved. See How To Advertise. 29
Disclaimer: Every Nairaland member is solely responsible for anything that he/she posts or uploads on Nairaland.