Welcome, Guest: Register On Nairaland / LOGIN! / Trending / Recent / New
Stats: 3,151,180 members, 7,811,452 topics. Date: Sunday, 28 April 2024 at 11:53 AM

Yoruba: Ede Tii koni Ni'mo Bi Iyekan Eni - Culture - Nairaland

Nairaland Forum / Nairaland / General / Culture / Yoruba: Ede Tii koni Ni'mo Bi Iyekan Eni (475 Views)

Ogun Ti Afi Ma Nde Ipo Nla Tabi Di Eni Pataki Lawujo / Ogun Ti Akoba Fe Ki Okunrin Tabi Obinrin Loju Miran Leyin Eni / ENI O LE SE BI ALABARU L'OYINGBO, KO LE SE BI ADEGBORO L'OJA OBA. a short story (2) (3) (4)

(1) (Reply) (Go Down)

Yoruba: Ede Tii koni Ni'mo Bi Iyekan Eni by absoluteSuccess: 3:49pm On Oct 24, 2023
Ninu orisirisi ede ti eleda da, okan ninu awon ede to rewa ju lawujo omo eniyan ni ede Yoruba je. E ma fowo ro seyin.

Ti a ba gbo ede naa lagboye, ti a si gbo daada, odamiloju saka wipe ao ri ainiye oye maa mu lati inu ede naa jade loorekoore.

Bi otilewu ki o ri, e mase je ka gbagbe ede Yoruba, ede abinibi wa. Ewà po ninu ede naa, osi kun fun ogbon, imo ati oye.

Opo igba, nko ni ekunrere awon asiri oro iwadi ti mo nse. Sugbon mo ni igbagbo pe ede Yoruba, kiibati. Ti mo ba saa ti ri aridaju meji tabi meta to fidi iwadi naa mule, moti ni ipinnu.

Fun apere, lori akole ti mo ti nso nipa owonrin, bawo lotiseese kinwipe owonrin tunmo si o won rin, nigbati awon babanla wa ti fi edidi ifa di oro naa seyin "owongogo"?

Sugbon asiri oro naa ni wipe ti a ba ntu oro naa si yebeyebe, gbogbo itupale to ba seese lagbodo yewo finnin-finnin laik'eyokan. Idi ni wipe, kosi itunmo kankan t'o n bawa s'ota ninu ede Yoruba, af'aimo l'oku.

Nitori naa, taa ba wa wo ìjoré ege oro ayebaye ti a pe ni owonrin yi, aori wipe owon ati rin la lo po. Kiwa ni ajosepo to dan moran ninu ege oro meji wonyi ti ilopo silebu yi fi waye?

Kato le ni aridaju lori ipinnu wa, a ni lati wa ibi ti eri to ri bakanna ninu ede Yoruba nibomiran, to je wipe o han gbangba pe oun ti a nwi ni ede naa nwi nibomiran laisi aniani.

Leyin eyi, eyitoku kere. Bo ba to asiko kan, imole a tun tan si eri miran fun itesiwaju iwadi wa.
Re: Yoruba: Ede Tii koni Ni'mo Bi Iyekan Eni by absoluteSuccess: 4:17pm On Oct 24, 2023
Fun apere, eje ki a tun wo saakun oro yi.

Gaza

Ninu imo ifa, ese ifa je ainiye. Awon Baba wa pe won ni omo odu. Oju tabi akori ifa kookan ni won pe ni oju Odu. Nitori naa, bi ati ni oju Odu ni ati ni omo odu.

Yato si eleyi, oju Odu merindinlogun ni ase lati ba arawon dapo ni okookan, eleyi tunmo si 16x16. A le pe aditu yi ni isori keji eka imo Ifa ninu eto imo ibile Yoruba.

Awon onimo ifa a maa pe aditu yi ni amulu Odu. Fun apere, ti Ose ba lo pelu Otua, oun ti eleyi maa bi ni osetura. Ti Irete ba si lo po pelu Ogbe, a di Ogberete.

Amo oun ti o semi ni kayefi ni bi ewa ede kanna yi ti bi Oyeku Gasa. Gege bi akole mi oke yi ti lo. Ninu Oyeku Gasa, Oyeku ati Osa ti mi si ara won.

Sebi Oyeku lo ro mo Osa, kilo bi Gasa ninu eyi? Asiri ede naa ni wipe nigbati iwa se, awon babanla wa mo ibi ti a pe ni Gasa tabi Gaza lojo oni. Etikun ni lati ayebaye.

Laini aniani, osa tunmo si alagbalugbu omi, nigbati lilo kan Osa ninu Ifa, won mu oun to jo ti Osa jade. Onimo ijinle lawon Awo igbaani ti won nseda oro akole ti Ifa kookan nje.

Baafe baako, sebi abani mule ibudo ni awon Awo aye joun, "adia fun Oba Ado, ejigbara ileke, tii lo ree b'awon mule ibudo, won nio kaki mole o jare, ebo ni ki o se".

Nje eyin omo ode oni nka oro Ifa yi bi? Kini eyin nrubo tiyin le lori? E wa, ka ro àròjinlè, kii se'ewo. Ese Ifa naa te siwaju "O gbo riru ebo, o ru, o gberu atukesu o tuu, o gbo tiharara, ebo ha fun un."

Aseyinwa aseyinbo, aseyori ni Baba fi pari ise imule ti awon ati awon emewa won fi sise se, iku funwon ni owo won lati se ise ti Eleduwa yan fun won, Baba si pada wa dupe. Egbo bi Ifa ti wi:

"O lanu koto, orin awo lo bo si lenu. Ese tio na, ijo faa. Oni "awa donile, aoku mo, awa dopitan ile"..."

Kiise ibiyi nikan latile ri apere mimu ile ibudo ninu ifa, laiwawawi, a npe ara wa ni ore imule nitori awon babanla wa je ore imule, elegbejegbe wedowedo tii wa ile ibudo rere ka etikun.

Oloye ni oye a maa ye. Kiise lasan ni won fi nsowipe "Omo Alado Moro", fun idi eyi, eyin omo egbe onimo buburu, eonibiire, elo sinmin agbaja.

Ifa karele, omo eranko siiri tii yode loko. Omo foofo tii fo didun l'Egun.
Re: Yoruba: Ede Tii koni Ni'mo Bi Iyekan Eni by absoluteSuccess: 10:38am On Oct 25, 2023
Ninu Ifa, Osa ti o duro gege bi akole kan ninu awon oju Odu mere'rindinlogun, je oro onitunmo ipelenipele. Osa ti Ifa, gege bi ati nse enu pe se regi pelu Osa Eleye. Aigbofa laa woke, Ifa kan ko si ni para.

Osa tunmo si isansa, o tunmo si eni ti o sa kuro ni ilu abinibi re to lo si eyin odi ilu lati lo fi iru ibi òún se ibudo, boya latari wipe ijoba tuntun tabi ote dide lodi si oluwa re ni ibiti won ti fori onitoun sole si.

Ninu itan Yoruba nigba Iwase, Osun ni a mo pe o sa lati ibikan bo si ibikan. Eyi lo bi gbolohun oro oriki to sakawe Osun gege bii "oroki asala". Dajudaju, ni asiko kan ni igba aye re, Osun sa asala fun emi ara re.

Ipo yi lo bi osa, eniti o fi ile re sile nibba isoro pelu ijoba tuntun. Eleyi ko sai wopo lasiko ti awon babanla wa lo isemi. Gbogbo agbara wa lowo awon Oba ati awon omoba.

Sugbon nigbati lilo kan Osa pelu Oyeku, awon babanla wa yi ede naa pada, won fi aderopo ede se eso fun oun ti won fe so. Nitori naa, Gasa yato gedegbe si osa.

Ki ale ni aridaju ede, itori wipe ilu kan to ni Osa ti a so npe ni Gasa wa ninu iriri awon babanla wa ni won se seda Gasa lati ropo Osa. Fun idiwon, Ose ati Otua lo bi osetura.

Sibe, osetura je oro kan, o tunmo si Ose itura. Nipa adape yi, asiri itunmo Otua gangan ko tile pamo mo. Otua tunmo si o tu ra. Iparoje konsonanti "r" gbeyin farahan.
Re: Yoruba: Ede Tii koni Ni'mo Bi Iyekan Eni by absoluteSuccess: 1:04pm On Oct 26, 2023
Yoruba bo wonni ala kii bomo leru ko male ro. Ti Osa ba je ti Eleye, tani Eleye gan ninu itan Yoruba?

Eleye kii se ajogun.

E ma soko lasa, eye iyaami ni. Iyaami agba, Ajibola Abeni Olotu Ife, eye rere tii waje fawo. Asa je eye to ni agbara, ko beru iku, beeni ko kin nrin ni bebe, ibi giga lo maa ngbero.

Iwa yi gan ni iyaami agba ni, nitori naa ni won fi fi eye idi sakawe tabi apejuwe iru eyan ti iyaami agba je. Ajibola je okan ninu oriki iyaami agba, Ajibola Abeni, ore yeye o.

Ogbologbo aje ni iyaami agba je. Leti awon ogberi, aje je enibi. Sugbon aje ti itan Yoruba nigba Iwase ntoka si je akinkanju obinrin, atoofise ogun ran.

Dajudaju, o maa ni ota pupo. Bee gele lori. Ninu isota yi ni ati mu aje jade, ninu re naa lati mu eye aje jade. Amo bi a ba wo saakun ede, ti a ba gbe eye segbe aje, mejeeji a di eye-aje.

Taa ba wa too lona Ifa bi tisaaju, eye aje a tunmo si "eye tii je ka". Adape eyi a tunmo si eye ti jeka, ayunlo ayunbo, ailagboye ati iberu a seinbo so eleyi di eye aje ati ika. Jije ka ni ese ti Ajibola Abeni se awon ero nigba Iwase. Besini, ise Ori ran an lonse.

"Aje" ni kootu o jireh ni awon oyinbo pe ni angeli. Rara, kiise wipe mo ngbiyanju lati so ibi di rere, kamari. Amosa, mo ngbiyanju lati je ki eyin naa se iwadi titi yin. Kamaa fi ojo gbogbo maa gbe ninu aimo pelu iberu nitori itan atayebaye wa to sokunkun siwa.

A (eleyi tunmo si eniti) je (idahun si ti o nise pelu irinkerindo: lakotan, eniti o nise pelu lilo ati bibo tabi jije kaakiri, bi aje ti je lowo oloko oju omi) Aje je iranse, gege bii angeli ti se tunmo si iranse.

E dide, eje ka wa itan wa lawari, kama baa ku sinu okunkun. Itan aimodaju nii soni di eru esin, ti eniyan fii binu esin tabi binu awon tii se esin. E gbe esin si apa kan, e gbe itan si apa kan, ninu imo ni itan wa.

Oun tii be l'eyin ofa, o ju oje lo. Awon eniyan mi segbe nitori won ko ni imo.
Re: Yoruba: Ede Tii koni Ni'mo Bi Iyekan Eni by absoluteSuccess: 9:57am On Jan 21
Laipe yi, ni ojo abameta to re koja (odij'esan l'eni), mo raye lati ka iwe Baba Ojogbon D.O. Fagunwa. Eyi ti mo ka ninu iwe won ni 'ireke Onibudo". Ise Iwuri gidi ni baba se, won fi itan tun aye opolopo se ni ile kootu o jiireh. Won sun, sugbon ise won si nfohun.

Oun ti mo mu jade ninu oju iwe kan ninu iwe na ni ibiti won ti daruko ojo didi. Mi o mo 'ipe mo maa ko nkankan nipa e bayi, mii ba ti ko page ti mo ti ri oro naa sile. Laisi ani ani, ni ile Yoruba, yinyin ni yinyin nje, o yato gedegbe si ojo didi.

O dabi eni wipe ewa Ifepade ni baba nsakawe ni ikorita naa, bi eyin Ifepade ti ri nigbati o rerin muse si Ireke Onibudo ni ilu Alupayida, nibiti ogbeni naa ti salabapade ejo iberu to nyo ilu naa l'enu, ti o si ran ilu naa lowo lati segun abami eda naa.

kinni mo fe fayo?

Ojo didi tunmo si snow. Baba ko se akitiyan kankan lati salaye nkan wonyi. O seese ki awon Yoruba igbaani mo nipa nkan bee ti o fi ro won lorun lati lo akanlo ede yi ninu iwe kiko fun awon ti nkan bee ko si ninu iriri won, gege bi olugbe ile olooru.

Oloye eniyan ni irandiran awon baba wa, won si je owa. Eleyi tunmo si awon ti won mo nipa bi a tii se iwadi oun koun toba sokunkun si won tabi ile kile to wa ni orere. Idi niyi ti oriki Awori fi so wipe, "omo oyinbo f'oju orun s'orere, eye oko f'oju orun s'ona"

Ninu oriki Eletu Iwase ni eleyi ti jeyo. Dajudaju, awon babanla wa ti fi igbakan lo isemi ni ile tii ojo didi, to funfun bi egbon owu ti maa nro bi ojo. Iwadi wa nte siwaju, otun lojo nyo.

Aku isinmi oni.
Re: Yoruba: Ede Tii koni Ni'mo Bi Iyekan Eni by absoluteSuccess: 11:46am On Jan 27
Awon owe kan wa ninu ede Yoruba ti o ye ka sa lesa fun irusoke ati ireti eda laye. Awon gboloun to san okan ninu aare tabi ainireti. Awon oro tii funni ni erongba rere ninu aropin. Akoko ninu won so wipe, "ori kii buru buru ko kogun odun, leyin okunkun biri biri imole a tan". Ki Olodumare dele fun baba wa Hubert Ogunde, won lo eleyi ninu okan ninu awon ere won to laami laka, ti akole re nje Yoruba r'onu.

Bi otile je wipe ko seese ka fidi ero akoko inu ipin oro yi mule, boya ninu eto isuna owo tabi iwa eda, amo sa, ti eniyan ba fi iru ero bayi se edidi aye oluwa re ninu isoro, o daju wipe aye oluwa 'e a nireti atunbotan rere a si pada wa di teni, dandan. Eni t'o npa owe bee ki maa ise ole! Dajudaju, onitoun kun fun igbiyanju kan tabi omiran, o si nfi okan te siwaju, boya l'eyin opo ijakule.

Looto ni, ori kii buru buru ko ka ogun odun, leyin okunkun biribiri, imole a tan. Ti ti akoko ko ba seese, ti ikeyin ko see da duro. Bi o ba wu ori ti o buru lati ka ogun odun, a ka ogun odun: amo ti "okunkun biri biri" ni agbedo! Bi ojumo tii mo nile aye gele, nni oye tii la peregede kari ibi gbogbo. Ti a ko ba ti ri t'ojo se ko mala, dandan ni kori to pe nile ko dire. Ori mi apere, ori mi apesin, ire ni mo wun, ire ni moyan ire ni mo he.

Owe miran bii tie ni ti iran meta kiitosi. Otito ni, idi ni wipe koseese ki eni meta ninu idile kan soso jo maa lo saa kanna laini si eni ti yoo yi nkan pada laarin won. Iran meta le duro fun omo-iyabi-bababi meta tabi iran kinni si iran keta ninu ebi kan. Ko seese ki ise ati osi diran nile kootu o jire, bo pe boya, okan ninu awon ara naa a jija gbara won ninu ise ati osi dandan.

Asiri ola ti o daju ni ki eniyan ni oun kan tabi omiran ti ndi iwulo fun ogoro omo eniyan, bi a ba ti ni eyi, ati segi ola na, o daju. Eyi dara lati wa, idi niyi ti awon baba wa fi maa nso wipe a n wowo lo, a pade iyi lona. Nse lo ye ka pada sile, tori baaba lowo o'un tan, iyi lao fi ra. Lati pinnisin ni oro yi ti ni itunmo to yato gedegbe ni eti mi gege bi omo-anibi-niran.

Iyi yato si iwulo. Iwulo a maa yi pada, sugbon i yi a maa wa sibe titi lae. Iwulo a funni l'owo, anfaani a fuuni niyi, iyi kii yi pada, ola a maa silo nile eni. O dara lati wa iyi kun iyi. Iyi soro lati ri, sugbon ti o ba di teni, taa si mo bi ati nlo iyi, a maa je titi aye. Kolojo oni je ki aye wa niyi ko si ni eye l'ojo gbo. Ami ase E'dumare. E je n maa wa f'eyi selo.

Oku ni 'bon ro.

(1) (Reply)

Fumigation Promo / Pidgin Help / I Have A Hermes Bracelet Replica.

(Go Up)

Sections: politics (1) business autos (1) jobs (1) career education (1) romance computers phones travel sports fashion health
religion celebs tv-movies music-radio literature webmasters programming techmarket

Links: (1) (2) (3) (4) (5) (6) (7) (8) (9) (10)

Nairaland - Copyright © 2005 - 2024 Oluwaseun Osewa. All rights reserved. See How To Advertise. 44
Disclaimer: Every Nairaland member is solely responsible for anything that he/she posts or uploads on Nairaland.