Welcome, Guest: Register On Nairaland / LOGIN! / Trending / Recent / New
Stats: 3,165,375 members, 7,861,034 topics. Date: Friday, 14 June 2024 at 09:37 PM

.. - Culture (41) - Nairaland

Nairaland Forum / Nairaland / General / Culture / .. (1834046 Views)

"We The Ewe People Of Ghana Are The Same As Yoruba"- Yewe2011.ewe Guy From Ghana / How Do U Spell (weed) In Yoruba, Is It Igbo? Or Egbo? / Yoruba Idioms: Owe Yoruba, Itunmo Re Ati Lilo Re (2) (3) (4)

(1) (2) (3) ... (38) (39) (40) (41) (42) (43) (44) ... (99) (Reply) (Go Down)

Re: .. by Nobody: 11:41pm On Dec 10, 2015
systembayo:
ejo egba mi ooo eyin awo e fun mi ni Ogun ti Ori abami ban fo yan edakun e sanu mi ooooooo

Efori abami bi ti bawo?
Re: .. by omoalade144(m): 3:28pm On Dec 11, 2015
Ejoo gbogbo awo moni ibere pataki kan ti mofe bi eyin awo.Ti eyan ba pe odu ifa irete lati oju orun wa si oju aye, kini eleyi tumo si o!!, gbogbo eyin majeo baje lori ikanni yi?
Re: .. by moziza: 8:59pm On Dec 11, 2015
E ku ale o eyin awo. E jowo e ran mi lowo o.Emere ni iyawo mi, osi tun ni oko orun. Nko ni ilosiwaju lori ise mi, ati jeun gan o di wahala. Mo gbiyanju ati le jade sugban pabo lonja si. E jowo eni to ba lagbara a ti tumi sile ko ran mi lowo o. Oodua agbe wo.
Re: .. by Shomar: 9:05pm On Dec 11, 2015
healthFirst:


Opolopo Awure lo ti wa lori abala yi sugbon te ba fe awon Aworo Nla tabi Afaro Nla, e kan si wa lori e-mail.
E Seun Baba. Amo mio ni e-mail yin lowo.
Re: .. by Oluokunoluwole: 10:54pm On Dec 11, 2015
healthFirst:


Beeni...won yio ma di oko re lowo, won le fa aisan si lara...o tun seese ki iru okunrin bee ma le se deede gege bi okunrin lodo iyawo re. wahala nla ni. ki iru eni be mura gidi ni o.
baba kini iru eni bee lese aburu o ni kan yin
Re: .. by Nobody: 11:23pm On Dec 11, 2015
moziza:
E ku ale o eyin awo. E jowo e ran mi lowo o.Emere ni iyawo mi, osi tun ni oko orun. Nko ni ilosiwaju lori ise mi, ati jeun gan o di wahala. Mo gbiyanju ati le jade sugban pabo lonja si. E jowo eni to ba lagbara a ti tumi sile ko ran mi lowo o. Oodua agbe wo.

E kan si mi lori e-mail. Enikan kii soro Okuku ninu Imole beeni enikan kii soro Imole ninu Okuku

1 Like

Re: .. by Nobody: 11:24pm On Dec 11, 2015
Shomar:
E Seun Baba. Amo mio ni e-mail yin lowo.

E lo wo oju iwe kini.
Re: .. by Nobody: 11:25pm On Dec 11, 2015
omoalade144:
Ejoo gbogbo awo moni ibere pataki kan ti mofe bi eyin awo.Ti eyan ba pe odu ifa irete lati oju orun wa si oju aye, kini eleyi tumo si o!!, gbogbo eyin majeo baje lori ikanni yi?

E to Babalawo lo ki won ba yin ki Odu Irete...ki e si se ohun ti e ba gbo nibe.
Re: .. by Nobody: 11:33pm On Dec 11, 2015
x

2 Likes

Re: .. by Nobody: 2:14pm On Dec 12, 2015
x

1 Like 1 Share

Re: .. by Nobody: 2:28pm On Dec 12, 2015
x

1 Like

Re: .. by Oluokunoluwole: 2:46pm On Dec 12, 2015
healthFirst:
113

ATUWÓ
Ewe Ódan,
Ewe Tude
Egbo Tude,
Ao gun Awon ewe yi papo mo osé dudu ao ma we pelu agbo ré ni agogo mewa ale 10pm.. ao té aso funfun silé; ori é ni a ma duro si ti aofi wé tan....
Agboré;
Ewe Iyalode pupa ati funfun, Ewe ajeobale, Ewe akoko ao se lagbo ao ma fi wé ose okeyi.. ni alalé nio
se aso eyokan naa lao ma te sile ni abi eyokan fun ojo kan atipe se ti abawe ose naa tan la o ma lo mu aso naa kuro ni,ojo melo ni a o fi we agbo naa,ejowo e se alaye re fun wa.agba yin adale

2 Likes

Re: .. by Nobody: 2:54pm On Dec 12, 2015
Oluokunoluwole:
se aso eyokan naa lao ma te sile ni abi eyokan fun ojo kan atipe se ti abawe ose naa tan la o ma lo mu aso naa kuro ni,ojo melo ni a o fi we agbo naa,ejowo e se alaye re fun wa.agba yin adale

Gege bi e ba se ri alaye oogun ni ke tele, oogun yi ko ni ojo melo la n fi lo, idi niyen ti a ko fi ko wipe oye ojo ti e ma fi lo. Aso ff te ba ti lo lojo kini na le lo titi ti eo fi we ose na tan.

1 Like

Re: .. by Hybrid01: 5:53pm On Dec 12, 2015
e n le sir.e ko dahun I were mi no pg39.egbon mi o le ba iyawo e se fun bi odun merin.oko re ki I le bee won ti bimo kan tele.a ma le nita sa o.kini a le se si?
Re: .. by Ifadamilola30: 9:10pm On Dec 12, 2015
healthFirst:
109

IMULE FUN EYONU AYE
Okete OOoye kan, ao ge ori re ati iru re, ao ko ifun re jade, ao jo pelu odindi atare kan. Ao sun iyoku ara re, ao ge si 16, ao wa bo lori ina, ti o ba jina die, ohun ni ao fi gbe ipese ni aago kan oru. Ao fi ebu ti a jo yen die si, eyi to ku yen, ao fi schinap lo lekan na ti a ba ti gbe ipese yen ti a ti wole ni ao to lo.

Agba yin a dale baba, e dakun se a ma fi iyo se eran yen??

2 Likes 1 Share

Re: .. by Nobody: 11:40pm On Dec 12, 2015
Hybrid01:
e n le sir.e ko dahun I were mi no pg39.egbon mi o le ba iyawo e se fun bi odun merin.oko re ki I le bee won ti bimo kan tele.a ma le nita sa o.kini a le se si?

Sebi mo ti dahun ibeere yin ninu e-mail te send. Abi eyin ko lo send e-mail ni? to ba je wipe e-mail yin ko niyen, e kan si mi lori e-mail.
Re: .. by Nobody: 11:41pm On Dec 12, 2015
Ifadamilola30:


Agba yin a dale baba, e dakun se a ma fi iyo se eran yen??

Se won daruko iyo ninu alaye yen ni?
Re: .. by Bostilo: 12:42am On Dec 13, 2015
E kale sir o. E jowo kini mole lo fun enitojewipe oti loma nfi gbogbo ojo aye re mu. E jowo egbami o egbon mi kotoju iyawo ati awon omo e. Oti lonfi gbogbo ojo aye won mu. Please help
Me o.
Re: .. by yemzino: 2:24am On Dec 13, 2015
[quote author=healthFirst post=40951316]

Baba eku ise takuntakun Eledumare amafun yin se o agbo ti yin ATI ebi yin o, Baba oogun ki ikan omokunrin matete wa ti aba sekan pelu obirin, e se sir

1 Like

Re: .. by Nobody: 11:11am On Dec 13, 2015
[quote author=yemzino post=40952739][/quote]

E wo ori abala yi fun oogun Idakole...sugbon to ba je wipe o ti pe lara, ke kan si mi lori e-mail

1 Like

Re: .. by Nobody: 11:12am On Dec 13, 2015
x

1 Like

Re: .. by Hybrid01: 12:11pm On Dec 13, 2015
healthFirst:


Sebi mo ti dahun ibeere yin ninu e-mail te send. Abi eyin ko lo send e-mail ni? to ba je wipe e-mail yin ko niyen, e kan si mi lori e-mail.
mi o ri sir.e ba mi send e si: duperola74@gmail.com

1 Like

Re: .. by jamiu3209(m): 1:07pm On Dec 13, 2015
healthFirst:
114
OOGUN ATIKE TI OKUNRIN FI N FERAN OBINRIN
Obinrin na yio mu orogbo kan si abe re moju, a o gba ni ojo keji, a o gun orogbo na pelu epo bodunbawo ti o wo sile funrare ati ifo ejo die, a o lo kunna dada, a o po mo atike, obirin na yio ma ku si oju re.

E jowo Baba kin lo nje EPO BODUNBAWO ati IFO EJO, nje ale rira lodo awon alagbo.....E seun On ama je o

1 Like

Re: .. by Nobody: 1:50pm On Dec 13, 2015
Hybrid01:
mi o ri sir.e ba mi send e si: duperola74@gmail.com

E send e-mail si binaryteck@gmail.com
Re: .. by Nobody: 1:50pm On Dec 13, 2015
jamiu3209:


E jowo Baba kin lo nje EPO BODUNBAWO ati IFO EJO, nje ale rira lodo awon alagbo.....E seun On ama je o

E beere lowo awon Elewe Omo

1 Like

Re: .. by OlanikeAsaolu(f): 5:37pm On Dec 13, 2015
Ejowo, mo nilo ogun isoye to daju, ejowo eranmi lowo
Re: .. by Nobody: 5:54pm On Dec 13, 2015
healthFirst:
hello, this thread is for lovers of nature when it comes to health and other areas of our lives. This thread is also strictly for the Yorubas and those who can read and understand as the language here is going to be pure Yoruba and no translation will be allowed. Reason is that we are going to be revealing some Yoruba secret knowledge of the application of leaves and roots and we intend to preserve and guard these wisdom of our ancestors.

Please do not ask further question regarding my reason to keep this as a Yoruba affairs, it's my choice...but if you refused to respect this, I shall only dignify you with silence.

Aye wa fun o lati beere fun iru Oogun to ba fe sugbon ao ma ko awon orisirisi Oogun sita. Awon Oogun fun itoju aisan, akoya, ati awon Oogun fun isora/isori, awure, aworo, ati beebe lo. Sugbon kii se gbogbo Oogun ni a le fi sita lofe, awon eyi to ba ni agbara gan ni ao so wipe ki e kan siwa lori apo ifiwe ranse wa binaryteck@gmail.com fun ekun rere alaye.

E le dara po mo wa lori whatsapp pelu ero ibanisoro yi...08148398067...e fi gbogbo ibeere yin ranse, ao da yin lohun

Bi a ba ri inkan ti ko ye wa, e je ki a beere ibeere pelu alaye, ao si gbiyanju lati se alaye lekun rere.

Gbogbo Oogun ti a ba ko sita la ti dan wo, to de ni idaniloju wipe yio se ise ti a ba ran.

Too, mo seba awon agbalagba awo ile aye, mo seba awon awo ode orun, mo seba awon Iya mi abeni...e juba o se o.

Iba, iba, iba

Akoda iba

Aseda iba

Ile ogere a foko yeri

Alapo Iku

Olona ola, iba

Esu odara, iba

Irunmale olukotun

Igba imale olukosin

Iba gbogbo yin o

Ero osaju, ero eyin, iba

Adase ni ni wun omode

Iba ki wun ni o

Eyin to ni aye

E je sise mi o san mi

Emi lomo agba

E je owo a maa je fun mi o

Ada ki nmu, ki o ge eku idi e

Omo eni ki nburu,

Ki a gbe fun ekun pa je

E dari jimi, ki e fi owo mi wo mi

Emi lomo aie fepo we

Osoronga opiki elese osun

Ajefun jedo

Oriri aye

Ebo aye ni a ru o

Osoronga ni nba ni gbele aye

Aje ni npa eni

Osoronga gbigbe ni o gbe mi o

Aje ma pa mi lomo
Lomi ki o somo mi

Iya mi agba opiki elese osun

A woni maye

A woni loju re orun

Eje lepo ekuru won

Iya-mi aye elekuru pupa foo

O gberita jagun

O gbe origi ke kanran kanran

Fori jimi bi mo ba se

Fi owo re wo mi

Na ke kanran wonu ile mi

Iya-mogun alara

Bi igun jebo

Aje gbe ni nje

Bi akala jebo

Aje gbe ni nje

Gbogbo eyi a ba se

Asegben ni e je o je

Iya-agba alapo iku

Olokiki oru

Ki nfo o fara pa

Onile origi ki njebo

Ki ebo naa ma gun rege

A agba ki nfi abo bo eni

Ki Omo ara aye ma ri ami won Lara eni

A jefun jedo

Ki nje tire tan

Ki o ma fio na han eni

Iya mi toto aye

Fio na han mi

Bi o ba gbe ori igi ke

Ma ke ao mi

Bi o gbe orita ke

Ma ke pa mi

Kike ni ki o fi ike re ke mi

Omidan eleye oloju owiwi

A ri eni ko to pe eni

Omoran ologbon

Linmo riro ati w ri eda

Alapo iku olona ola

Iku ti nba nro nile mi

Re danu,Opiri eleye moran bi afefe

Arun ti nba nro nile mi

Ro danu

Iya-mi omoran eleye

A pani ma yoda

A mubo ti nbe laye mi

Re danu o

Eyin ti o ni aye

E fa mi mora

Aje eleye e fa mi mora o
.

1 Like

Re: .. by Nobody: 5:59pm On Dec 13, 2015
HsLBroker:
Iba agba, agba oni tan lo ri ile ode aye.

Ki Iba Se. E seun.
Re: .. by Nobody: 6:04pm On Dec 13, 2015
OlanikeAsaolu:
Ejowo, mo nilo ogun isoye to daju, ejowo eranmi lowo

E wo ori itakun yi ...Isoye ti wa lara awon oogun ta fi sita.
Re: .. by jamiu3209(m): 6:30pm On Dec 13, 2015
healthFirst:

E beere lowo awon Elewe Omo
E Seun Baba ewe ama je
Re: .. by omoalade144(m): 7:37pm On Dec 13, 2015
Hunnnn...Ase bao ni akan agba bi ewe laari.Bi omode o ba mo ewe ti kosi mo owe afi kori awon agba ki won to sonan.
Too! adupee lowo eyin
agbagba lori ikanni yi
fun itoni sonan lori
ohun gbogbo,
nipa ewe ati egbo,ELEDUMARE yio
ma gbo adura wa,ao si ni seru aye lagbara OLORUN ELEDUMARE
ati loruko orunmila alagbawi wa ase.
Re: .. by Nobody: 7:45pm On Dec 13, 2015
omoalade144:
Hunnnn...Ase bao ni akan agba bi ewe laari.Bi omode o ba mo ewe ti kosi mo owe afi kori awon agba ki won to sonan.
Too! adupee lowo eyin
agbagba lori ikanni yi
fun itoni sonan lori
nipa ewe ati egbo,ELEDUMARE yio
ma gbo adura wa,ao si ni seru aye lagbara OLORUN ELEDUMARE
ati loruko orunmila alagbawi wa ase.

Ase Wa. Ajagunmole Awo Ode Orun ko gbe ohun yin re orun...ko je be. Eyi Ewi Aye ba ti wi, ohun legba Orun n gba.

(1) (2) (3) ... (38) (39) (40) (41) (42) (43) (44) ... (99) (Reply)

(Go Up)

Sections: politics (1) business autos (1) jobs (1) career education (1) romance computers phones travel sports fashion health
religion celebs tv-movies music-radio literature webmasters programming techmarket

Links: (1) (2) (3) (4) (5) (6) (7) (8) (9) (10)

Nairaland - Copyright © 2005 - 2024 Oluwaseun Osewa. All rights reserved. See How To Advertise. 58
Disclaimer: Every Nairaland member is solely responsible for anything that he/she posts or uploads on Nairaland.