Welcome, Guest: Register On Nairaland / LOGIN! / Trending / Recent / NewStats: 3,195,053 members, 7,956,934 topics. Date: Monday, 23 September 2024 at 11:00 PM |
Nairaland Forum / Nairaland / General / Religion / Share Your Best Hymns (42918 Views)
Post Your Favourite Christian Hymns / I Need Deeper Life Bible -gospel Hymns CD / Post Yoruba Christian Hymns Here (2) (3) (4)
(1) (2) (3) ... (9) (10) (11) (12) (13) (Reply) (Go Down)
Re: Share Your Best Hymns by obasolape(f): 4:09am On Oct 26, 2022 |
C.M.S. 563, S.O. ED D7s (FE 135) "Iwo ki ise eru mo, Iwo di arole Olorun nipase Kristi" - Gal. 4:7 1. EWE ti Oba orun, Korin didun be ti nlo Korin ‘yin Olugbala Ologo ‘nu ise Re. Egbe: A nlo ‘le sodo Olorun Lona t'awon Baba rin Nwon si nyo: nisisiyi Ayo won l'awa o ri. 2. A nlo sodo Olorun Lona t'awon Baba rin Nwon si nyo: nisisiyi, Ayo won l'awa o ri. Egbe: A nlo ‘le sodo... 3. Korin agbo kekere E o simi n'ite Re, ‘ Bit'a pese 'joko nyin Ibe si n'ijoba nyin. Egbe: A nlo ‘le sodo... 4. W'Oke, omo imole Ilu Sion wa lokan Ibe n‘ile wa titi; Ibe l'ao r'Oluwa. Egbe: A nlo ‘le sodo... 5. Kerubu, tesiwaju Serafu, ma jafara Kristi Omo Baba nwi Pe laifoiya ka ma lo. Egbe: A nlo ‘le sodo... 6. Jesu, a nlo l'ase Re, A ko‘hun gbogbo sile lwo ma j‘ amona wa, A o si ma ba o lo. Egbe: A nlo ‘le sodo... 7. A f’ogo fun Baba wa, A f'ogo fun Omo Re; Ogo ni f’Emi Mimo, Mu wa de ‘le ayo na. Egbe: A nlo ‘le sodo Olorun Lona t'awon Baba rin Nwon si nyo: nisisiyi Ayo won l'awa o ri. Amen 1 Like |
Re: Share Your Best Hymns by obasolape(f): 4:27am On Oct 26, 2022 |
Ninu irin ajo mi, beni mo nkorin Mo n toka si kalfari, N’ibi eje na Idanwo lode ninu, l’ota gbe dide Jesu lo nto mi lo, isegun daju Egbe: A! mo fe ri Jesu kin ma w’oju re, Ki nma korin titi nipa ore re Ni ilu ogo ni ki ngbohun soke Pe mo bo, ija tan, mo de ile mi. Stanza 2 Ninu ise isin mi, b’okunkun basu Un o tubo sunmo Jesu, y’o tan imole Esu le gb’ogun ti mi, kin le sa pada Jesu lo nto mi lo, ko se’wu fun mi. Egbe: A! mo fe ri Jesu kin ma w’oju re, Ki nma korin titi nipa ore re Ni ilu ogo ni ki ngbohun soke Pe mo bo, ija tan, mo de ile mi. Stanza 3 Bi mo tile bo sinu afonifoji Imole itoni Re, Yio Mole simi Yio na owo re simi, Yio gbe mi soke Un o ma tesiwaju, b’o ti nto mi lo Egbe: A! mo fe ri Jesu kin ma w’oju re, Ki nma korin titi nipa ore re Ni ilu ogo ni ki ngbohun soke Pe mo bo, ija tan, mo de ile mi. Stanza 4. Nigbati iji aye yi ba yi lu mi Mo ni abo t’o daju, labe apa re Y’o ma f’owo re to mi titi de opin Ore ododo ni, A! mo ti f’e to. Egbe: A! mo fe ri Jesu kin ma w’oju re, Ki nma korin titi nipa ore re Ni ilu ogo ni ki ngbohun soke Pe mo bo, ija tan, mo de ile mi. 1 Like |
Re: Share Your Best Hymns by obasolape(f): 4:32am On Oct 28, 2022 |
OGO NI F'ORUKỌ OLUWA 1. Jesu ala-bu-kun a-wa yin ọ A kò kiki 'fẹ́ oore rẹ Alagbara, ẹni mímọ Ogo nla ni f'orukọ rẹ Chrs.. Óòoo...........ogo. Óòoo.........ogo Ogo ni f'orukọ~Oluwa Óòoo...........ogo. Óòoo.........ogo Ogo ni f'orukọ rẹ 2. Olurapada nla, oluwa wa Imọlẹ ọjọ ~ayeraye Jẹ k'awọn mimọ ni gbogbo aye Kọrin iyin ailopin rẹ 3. Lat'ori itẹ ogo ti ọ́run S'ori agbelebu itiju E'n tó kù, to ra wa pada Ki ẹlẹṣe ba tun le ye 4. Sọkalẹ wa, ọba àìkú Wa gba' jọba ogo re Wa ma jọ́ba, titi lailai Ki gbogbo 'jọba jẹ tirẹ 1 Like |
Re: Share Your Best Hymns by obasolape(f): 12:43am On Nov 01, 2022 |
Blessed Assurance Oda mi loju, mo ni Jesu! Itowo adun oorun l’eyi je! Mo di ajogun igbala nla, Eje Re we mi, a tun mi bi. Egbe: Ngo so itan na, ngo korin na, Ngo yin Olugbala mi titi; Ngo so itan na, ngo korin na, Ngo yin Olugbala mi titi. Ngo teriba fun tayotayo, Mo le ri iran ogo bibo Re; Angeli nmu ihin didun wa Ti ife at’anu Re si mi. Egbe: Ngo teriba fun, ngo simi le Mo di ti Jesu, Mo d’eni ’bukun, Ngo ma sora, ngo si gbadura, Ki ore Re ma fi mi sile. Egbe: Amin. |
Re: Share Your Best Hymns by obasolape(f): 4:05pm On Nov 01, 2022 |
ONIBU ORE HYMN LYRICS Verse 1 Oluwa orun on aye Wo Niyin atope ye fun Bawo la ba ti fe o to Onibu ore Verse 2 Orun ti nran atefefe Gbogbo eweko nso fe re Wo lo nmu irugbin dara Onibu ore Verse 3 Fun ara lile wa gbogbo fun gbogbo ibukun aye Awa yin o, a si dupe a onibu ore Verse 4 O ko du wa li omo re o fi fun aye ese wa o si f'ebun gbogbo pelu onibu ore Verse 5 O fun wa l'Eni Mimo re Emi iye atagbara O rojo ekun ibukun re Le wa lori Verse 6 Fun idariji ese wa, ati fun ireti orun Ki lohun ta fin fun o O je isura ti taye Onibu ore Verse 7 Owo ti anna, ofo ni Sugbon eyi tafin fun o O je isura ti taye Onibu ore Verse 8 Ohun ta bun o Oluwa Wo o an le pada fun wa Layo la ta o lore Onibu ore Verse 9 Ni odo re lati san wa olorun olodumare Je ka le ba O gbe titi Onibu ore |
Re: Share Your Best Hymns by obasolape(f): 2:40pm On Jan 26, 2023 |
1. Mo nduro lori ileri Krist' Oba Eniti a o ma yin titi laelae Ogo f‘Olorun, emi yo ma korin Mo nduro lori ileri Re. Emi nduro...... (Mo nduro de ‘leri, Mo nduro de ‘leri) Emi nduro lori ileri Oluwa Emi nduro...... (Mo nduro de ‘leri, Mo nduro de ‘leri) Emi nduro lori ileri Re. 2. Mo nduro le ileri ti ko le ye Gbati iji 'yemeji at‘ eru ba de Nipa Oro Re li emi yo segun Mo nduro lori ileri Re, 3. Ileri Re la mi loju lati ri Iwenumo pipe ninu eje Re Ileri Re so okan mi d‘om'nira Mo nduro lori ileri Re. 4. Mo nduro le ileri Krist' Oluwa Ife lo fi so mi po mo ara Re Nipa oro Re mo nsegun lojojo Mo nduro lori ileri Re Amin. |
Re: Share Your Best Hymns by obasolape(f): 5:53am On Feb 25, 2023 |
B’o ti dun lati gba Jesu Bi iwo ba gbagbo, iwo o ri ogo Olorun. Jn. 11:40 1. B’o ti dun lati gba Jesu Gbo gegebi oro Re; K’a simi lor’ ileri Re, Sa gbagbo l’Oluwa wi Jesu, Jesu, emi gbagbo, Mo gbekele n’gbagbogbo, Jesu, Jesu, Alabukun Ki nle gbekele O si. 2. B’o ti dun lati gba Jesu, K’a gb’eje ‘wenumo Re Igbagbo ni ki a fi bo Sin ‘eje wenumo na. 3. B’o ti dun lati gba Jesu, Ki nk’ara ese sile, Ki ngb’ayo, iye, isimi Lati odo Jesu mi. 4. Mo yo mo gbeke mi le O, Jesu mi, Alabukun; Mo mo pe O wa pelu mi, Ntoju mi titi dopin. Amin. Tis so sweet to trust in Jesus If thou wouldest believe, thou shouldest see the glory of God. John.11:40 1. 'Tis so sweet to trust in Jesus, Just to take Him at His word: Just to rest upon His promise: Just to know, 'Thus saith the Lord. Jesus, Jesus, how I trust Him! How I've proved Him o'er and o'er Jesus, Jesus, precious Jesus! O for grace to trust Him more! 2. O how sweet to trust in Jesus, Just to trust His cleansing blood; Just in simple faith to plunge me 'Neath the healing, cleansing flood! 3. Yes, ‘tis sweet to trust in Jesus, Just from sin and self to cease; Just from Jesus simply taking Life and rest, and joy and peace. 4. I'm so glad I learn'd to trust Thee Precious Jesus, Saviour, Friend; And I know that Thou art with me, Wilt be with me to the end. Amen. |
Re: Share Your Best Hymns by obasolape(f): 5:58am On Feb 25, 2023 |
Nigba igbi aiye ba dide si o, T' okan re baje pe gbogbo nkan segbe, Siro ibukun re, ka won lokokan, Enu y'o ya o fun nkan t' Oluwa t'se. Refrain Ro 'bukun re ka won lokokan, Ro ohun t' Olorun se fun o; Ro 'bukun re, ka won lokokan, Ro 'bukun re, ri nkan t' Olorun ti se. Eru aniyan ha ti n pa okan re? Agbelebu ti 'wo nru ha si wuwo? Siro ibukun re le 'yemeji lo, Iwo y'o si korin b' ojo ti nkoja. Nigbat' ini elomi kun o loju, Ranti Krist n 'oro aimoye fun o, Siro ibukun re t' owo ko le ra, At' ere re lorun, ile re l' oke Beni larin ija b' o ti wu ko ri, Mase ba okan je mo p' Olorun mbe, Siro ibukun re, Angeli y'o wa, Fun ranwo on 'tunu d'opin ajo re. Source: YBH #658 When upon life’s billows you are tempest tossed, When you are discouraged, thinking all is lost, Count your many blessings name them one by one, And it will surprise you what the Lord hath done. Refrain: Count your blessings, name them one by one; Count your blessings, see what God hath done; Count your blessings, name them one by one, And it will surprise you what the Lord hath done. Are you ever burdened with a load of care? Does the cross seem heavy you are called to bear? Count your many blessings, every doubt will fly, And you will be singing as the days go by. When you look at others with their lands and gold, Think that Christ has promised you His wealth untold. Count your many blessings, money cannot buy Your reward in heaven, nor your Lord on high. So amid the conflict, whether great or small, Do not be discouraged, God is over all; Count your many blessings, angels will attend, Help and comfort give you to your journey’s end. |
Re: Share Your Best Hymns by obasolape(f): 2:34pm On Mar 02, 2023 |
11. Recessional Hymn Akokun 22 “B’o ba ni Jesu k’o dimu” B’o ba ni Jesu k’o dimu, K’o si toro imuduro, Jesu, Oluwa mi, Mu mi duro dopin. Mu mi duro, mu mi duro, Mu mi duro dopin, Jesu, Oluwa mi, Mu mi duro dopin. Ninu ofi-ola aiye, Pelu danwo arotele, Jesu, Oluwa mi, Mu mi duro dopin. Nigba ‘banuje ile B’a d’ori okan mi kodo; Jesu, Oluwa mi, Mu mi duro dopin. Nigba wahal’ aiye l’otun Idanwo Esu li osi, Jesu, Oluwa mi, Mu mi duro dopin. Nigba Esu gbe mi soke, T’o fe k’emi k’o teriba, Jesu, Oluwa mi, Mu mi duro dopin. Nigbat’ o ku emi nikan, Ti ko si alabaro mo; Jesu, Oluwa mi, Mu mi duro dopin. |
Re: Share Your Best Hymns by obasolape(f): 9:56am On Mar 11, 2023 |
1 Nigbati ‘gbi aye yi ba nyi lu o, To si dabi enipe gbogbo re pin, Ka ibukun re, siro won l‘okokan, Ise Oluwa yo je ‘yanu fun o Ka ‘bukun re, ka won l‘okokan, Ka ‘bukun re, wo ‘se Olorun; Ka ‘bukun re, ka won l‘okokan, Ka ‘bukun re, wa ri ‘se t‘Olorun se. Eru aniyan ha nwo ‘kan re l‘orun! Ise t‘a pe o si ha soro fun O; Ka ‘bukun re, ‘yemeji yo si fo lo, Orin iyin ni yo si gb‘enu re kan. 3 ‘Gbat‘ o ba nwo awon oloro aye, Ronu oro ti Jesu ti se leri; Ka ibukun re, owo ko le ra won, Ere re l‘orun ati ‘le re l‘oke. 4 Ninu gbogbo ayidayida aye, Mase foya, Olorun tobi julo; Ka ‘bukun re, awon angel‘ yo to o Won yo si ran o lowo titi d‘opin. Amin. |
Re: Share Your Best Hymns by obasolape(f): 4:48pm On Mar 20, 2023 |
11. Recessional Hymn Akokun 22 “B’o ba ni Jesu k’o dimu” B’o ba ni Jesu k’o dimu, K’o si toro imuduro, Jesu, Oluwa mi, Mu mi duro dopin. Mu mi duro, mu mi duro, Mu mi duro dopin, Jesu, Oluwa mi, Mu mi duro dopin. Ninu ofi-ola aiye, Pelu danwo arotele, Jesu, Oluwa mi, Mu mi duro dopin. Nigba ‘banuje ile B’a d’ori okan mi kodo; Jesu, Oluwa mi, Mu mi duro dopin. Nigba wahal’ aiye l’otun Idanwo Esu li osi, Jesu, Oluwa mi, Mu mi duro dopin. Nigba Esu gbe mi soke, T’o fe k’emi k’o teriba, Jesu, Oluwa mi, Mu mi duro dopin. Nigbat’ o ku emi nikan, Ti ko si alabaro mo; Jesu, Oluwa mi, Mu mi duro dopin. |
Re: Share Your Best Hymns by obasolape(f): 1:13pm On Mar 22, 2023 |
Ninu irin ajo mi, beni mo nkorin Mo n toka si kalfari, N’ibi eje na Idanwo lode ninu, l’ota gbe dide Jesu lo nto mi lo, isegun daju Egbe: A! mo fe ri Jesu kin ma w’oju re, Ki nma korin titi nipa ore re Ni ilu ogo ni ki ngbohun soke Pe mo bo, ija tan, mo de ile mi. Stanza 2 Ninu ise isin mi, b’okunkun basu Un o tubo sunmo Jesu, y’o tan imole Esu le gb’ogun ti mi, kin le sa pada Jesu lo nto mi lo, ko se’wu fun mi. Egbe: A! mo fe ri Jesu kin ma w’oju re, Ki nma korin titi nipa ore re Ni ilu ogo ni ki ngbohun soke Pe mo bo, ija tan, mo de ile mi. Stanza 3 Bi mo tile bo sinu afonifoji Imole itoni Re, Yio Mole simi Yio na owo re simi, Yio gbe mi soke Un o ma tesiwaju, b’o ti nto mi lo Egbe: A! mo fe ri Jesu kin ma w’oju re, Ki nma korin titi nipa ore re Ni ilu ogo ni ki ngbohun soke Pe mo bo, ija tan, mo de ile mi. Stanza 4. Nigbati iji aye yi ba yi lu mi Mo ni abo t’o daju, labe apa re Y’o ma f’owo re to mi titi de opin Ore ododo ni, A! mo ti f’e to. Egbe: A! mo fe ri Jesu kin ma w’oju re, Ki nma korin titi nipa ore re Ni ilu ogo ni ki ngbohun soke Pe mo bo, ija tan, mo de ile mi. |
Re: Share Your Best Hymns by obasolape(f): 8:55pm On Mar 27, 2023 |
Bi Krist ti da okan mi nde Aye mi ti dabi orun Larin 'banuje at' aro Ayo ni lati mo jesu Chorus: Halleluya Ayo l'o je Pe mo ti ri 'dariji gba Ibikibi ti mo ba wa Ko s'ewu Jesu wa nibe Mo ti ro pe orun jinna Sugbon nigba ti Jesu de L'orun ti de 'nu okan mi Nibe ni yo'o si wa titi Nibo l'a ko le gbe l'aiye L'or'oke tabi petele L'ahere tabi agbala Ko s'ewu Jesu wa nibe |
Re: Share Your Best Hymns by obasolape(f): 3:24am On Mar 28, 2023 |
1. GBO-GB’ ogo iyin ola, Fun O oludande, S’ Eni t’ awon omode Ko Hosanna didun! ‘Wo l’ Oba Israeli, Om’ Alade Dafidi, T’ O wa l’ Oko Oluwa, Oba olubukun. Gbogb’ ogo iyin ola Fun O, Oludande, S’ Eni t’ awon omode Ko Hosanna didun! 2. Egbe awon maleka, Nyin O l’ oke giga; Awa at’ eda gbogbo Si dapo gberin na. 3. Awon Hebru lo, saju, Pelu imo ope, Iyin, adura, at’ orin, L’ a mu wa ‘waju Re. 4. Si O saju iya Re, Nwon korin iyin won; ‘Wo t’a gbega nisiyi, L’ a nkorin iyin si. 5. ‘Wo gba orin iyin won: Gb’ adura t’a mu wa, ‘Wo ti nyo s’ ohun rere, Oba wa Olore. |
Re: Share Your Best Hymns by obasolape(f): 4:43am On Apr 08, 2023 |
1. Jesu mimo Ore airi Oluranlowo alaini N'nu ayida aiye, ko mi K'emi le romo O. 2.Ki nsa n‘idapo mimo yi, Gba ohun t‘O fe ugo kun bi? B‘okan mi b‘eka ajara Ba sa le ro mo O. 3. Are ti m'okan mi pupo Sugbon o wa r'ibi simi T'ori t'o room O 4. B'aiye d'ofo mo mi loju Ba gba ore at'ara lo Ni Suri ati laibohun L'emi o romo O 5 ‘Gba t‘o k‘emi nikan soso, Larin idamu aye yi, Mo gb‘ohun ife jeje na Wipe, “Sa ro mo Mi 6 B‘are ba fe mu igbagbo, T‘ireti ba si fe saki, Ko si ewu fun okan na Ti o ba ro mo O. 7 Won ko beru ‘rumi aye Nitori ‘Wo wa nitosi; Won ko si gbon b‘iku ba de ‘Tori won ro mo O. 8 Ire sa ni l‘ohun gbogbo, Ko s‘eni le daya fo mi ‘Gba mo fi O s‘Olugbala, Ti mo si ro mo O. |
Re: Share Your Best Hymns by obasolape(f): 1:19pm On Apr 17, 2023 |
TOLUWA NILE ATEKUN RE T'Oluwa Nile at'ekun re Aye at'ekun 'nu re O fi idi re sole lor'okun At I lori isan omi Egbe Gbe ori yin soke, eyin ilekun Ka gbe yin soke K'Oba Ogo wole wa Tani yo gori oke yi lo? Ori oke Oluwa Tani yo duro niwaju Re? Niwaju Oluwa wa Eni ti o ni owo mimo To so ni aya funfun Ti ko gb' okan re soke s'asan Ti ko si bura etan Awa ni iran ti nsaferi Re Saferi Re Oluwa Awa yo si ri ibukun gba Lowo Olorun Jakob A! Tani Oba awon oba Ti'se Oba Ogo yi? Oluwa awon omo Ogun Oun naa l'Oba ogo 1 Like |
Re: Share Your Best Hymns by obasolape(f): 9:42am On Apr 18, 2023 |
1. Bukun 'le wa at'ebi wa, at'ara wa/2ce Ibukun orun, iranwo, Re, Ibukun orun ko fi kari awa, K'O fi fun wa o, l'aye l'orun o, Baba orun 2. Tu wa lara, Alagbara, se 'toju wa/2ce Itunu Re, alafia Re, Ike Re, K'O fi toju wa, ye, Awa mbe O o, gbo adura wa, Oba Ogo. 3. Baba fun wa l'Emi mimo at'agbara/2ce Iranse orun, ebun lat'orun Itunu Baba, k'o wonu okan wa, K'o gbe 'nu wa o, k'o fun wa l'ayo, Oba Orun. 4. Awa f'iyin at'ope fun Baba l'orun/2ce Iyin fun 'ranwo, ope fun anu, Ayo fun 'dasi ti a nri lojojo, Ope fun O o, a tun juba Re, Baba awa. Amin 1 Like |
Re: Share Your Best Hymns by obasolape(f): 3:55pm On Nov 13, 2023 |
SOFTLY AND TENDERLY (In Yoruba) Gbo bi Oluwa ti npe lohun jeje O nkesi o, at 'emi Wo! O nfi suru duro lenu ona Nduro de t'emi tire ÈGBÈ: Wa 'le... wa 'le.... Enyin t'are mu, wa le Tifetife li Olugbala nkigbe O npe elese wa 'le DOH is A flat m : - .r :d :d :t, :d |r :d :l, :l, :s, : -|| d :d :d :m : - .r :d |r : - : - : - : - : -|| m : - .r :d :d :t, :d |r :d :l, :l, :s, : -|| d :d :f :m : - .d :r |d : - : - : - : -|| REFRAIN s, |r : - : - : - : - :m |d : - :r :m : - : -|| r :r :r :m.m : - :fe |s : - :fe :f : - : -|| m : - .r :d :d :t, :d |r :d :l, :l, :s, : -|| d.d : - :f :m.d : - :r |d : - : - : - : -|| (Copied). |
Re: Share Your Best Hymns by obasolape(f): 3:56pm On Nov 13, 2023 |
CCC. HYMN 575 1.Oluwa mafi mi se gbagbe Ranti mi toba de'joba Re Nibi igbala ohun ayo gbe wa Nibi igbala ayeraye 2 Oluwa to loke to nile Ohun lolorun to laye Bo tiwu kile aiye dun to A o faye sile nigbakan. 3 Nigba Maria bi Jesu Awon amoye wa Gbogbo won foribale fun Won si tun ta jesu loore. Amin. |
Re: Share Your Best Hymns by Blackman101: 4:34pm On Nov 13, 2023 |
We have heard the joyful sound: Jesus saves! Jesus saves! Spread the tidings all around: Jesus saves! Jesus saves! Bear the news to every land, Climb the steeps and cross the waves; Onward!—’tis our Lord’s command; Jesus saves! Jesus saves! 2 Waft it on the rolling tide, Jesus saves, Jesus saves; Tell to sinners far and wide, Jesus saves, Jesus saves; Sing, ye islands of the sea, Echo back, ye ocean caves; Earth shall keep her jubilee, Jesus saves, Jesus saves. 3 Sing above the battle’s strife, Jesus saves, Jesus saves; By His death and endless life, Jesus saves, Jesus saves; Sing it softly thru the gloom, When the heart for mercy craves, Sing in triumph o’er the tomb, Jesus saves, Jesus saves. 4 Give the winds a mighty voice, Jesus saves, Jesus saves; Let the nations now rejoice. Jesus saves, Jesus saves; Shout salvation full and free, Highest hills and deepest caves, This our song of victory, Jesus saves, Jesus saves. |
Re: Share Your Best Hymns by obasolape(f): 2:58am On Nov 16, 2023 |
SI O OLUTUNU ORUN 1. Si o Olutunu Orun Fun ore at’agbara Re A nko, Aleluya 2. Si O, ife eni t’Owa Ninu Majemu Olorun A nko, Aleluya 3. Si O agbara Eni ti O nwe ni mo, t’o nwo ni san A nko, Aleluya 4. Si O, Oluko at’ore Amona wa toto d’opin A nko, Aleluya. 5. Si O, Eniti Kristi ran Ade on gbogbo ebun re A nko, Aleluya. Amin. |
Re: Share Your Best Hymns by obasolape(f): 4:54am On Nov 19, 2023 |
CCC. HYMN 575 1.Oluwa mafi mi se gbagbe Ranti mi toba de'joba Re Nibi igbala ohun ayo gbe wa Nibi igbala ayeraye 2 Oluwa to loke to nile Ohun lolorun to laye Bo tiwu kile aiye dun to A o faye sile nigbakan. 3 Nigba Maria bi Jesu Awon amoye wa Gbogbo won foribale fun Won si tun ta jesu loore. Amin. |
Re: Share Your Best Hymns by obasolape(f): 5:55am On Nov 21, 2023 |
Oluwa ran mi ni’se, Aleluya! Iwọ ni un o jẹ iṣẹ na fún; A kọ sínú ọrọ Rẹ, Aleluya! P’ẹni t’o ba wo Jesu y’o ye. Egbe: Wo k’o ye, Arakurin Wo Jesu ki o sí ye A kọ sínú ọrọ Rẹ, Aleluya! P’ẹni t’o ba wo Jesu y’o ye. A rán mi ni’se ayọ, Aleluya! Un ọ j’iṣẹ na fún ọ ọrẹ mi; Iṣẹ lat’oke wa ni Aleluyah! Jésù sọ, mo mọ pé otọ ni. Egbe: Wo k’o ye, Arakurin Wo Jesu ki o sí ye A kọ sínú ọrọ Rẹ, Aleluya! P’ẹni t’o ba wo Jesu y’o ye. A n’ọwọ iye sí ọ, Aleluya! Ao fi’ye ailopin fún ọ; T’o ba wo Jesu nikan, Aleluya! Wòó, On nìkan l’o le gbala. Egbe: Wo k’o ye, Arakurin Wo Jesu ki o sí ye A kọ sínú ọrọ Rẹ, Aleluya! P’ẹni t’o ba wo Jesu y’o ye. Amin. |
Re: Share Your Best Hymns by obasolape(f): 5:56am On Nov 21, 2023 |
OLORI IJO T'ORUN Olori ijo t' orun, L' ayo l' a wole fun O; K' o to de, ijo t' aiye, Y'o ma korin bi t' orun, A gbe okan wa s' oke, N' ireti t' o n' ibukun; Awa kigbe, awa f' iyin F' Olorun igbala wa. Bi a wa ninu 'ponju, T' a nkoja ninu ina, Orin ife l' awa o ko. Ti o mu wa sunmo O; Awa sape, a si yo, Ninu ojurere Re Ile t' o so wa di Tire, Y'o pa wa mo titi lai. Iwo mu awon enia Re Koja isan idanwo; A ki o beru wahala, 'Tori O wa nitosi, Aiye, ese at' Esu, Kojuja si wa lasan, L' agbara Re, a o segun, A o si ko 'rin Mose. Awa f' igbagbo r' ogo, T' O nfe lati fi wa si, A kegan ere aiye, Ti a fi siwaju wa, Bi O ba si ka wa ye, Awa pelu Stefen t'o ku Y'o ri O bi o ti duro Lati pe wa lo s' orun. |
Re: Share Your Best Hymns by obasolape(f): 6:00am On Nov 21, 2023 |
FUN MI NI IWA PELE Fun mi n' iwa pele, Okan tutu; Ifarabale bi T' Oluwa mi; Irele on suru At' opo oiyonu, Ninu ohun gbogbo Ki njo Jesu. Fun mi n' itelorun N' ipo k' ipo; Ko le re 'le ju yi T' a bi Jesu. Fun mi n' itunu Re. At'iranlowo Re Ninu ohun gbogbo Ki njo Jesu. Fun mi ni itara S' ipa Tire; Aniyan at' ife S' ohun t' orun; Fun mi n' iwa mimo, Ikorira ese, Ninu ohun gbogbo Ki njo Jesu. Fun mi ni igbagbo At' ireti; Fun mi l' ayo 'gbala Ninu Jesu; F' emi iye fun mi, Fun mi l' ade ogo, 'Gbati mo ba jinde Ki njo Jesu. |
Re: Share Your Best Hymns by obasolape(f): 6:47am On Nov 21, 2023 |
Oluwa ran mi ni’se, Aleluya! Iwọ ni un o jẹ iṣẹ na fún; A kọ sínú ọrọ Rẹ, Aleluya! P’ẹni t’o ba wo Jesu y’o ye. Egbe: Wo k’o ye, Arakurin Wo Jesu ki o sí ye A kọ sínú ọrọ Rẹ, Aleluya! P’ẹni t’o ba wo Jesu y’o ye. A rán mi ni’se ayọ, Aleluya! Un ọ j’iṣẹ na fún ọ ọrẹ mi; Iṣẹ lat’oke wa ni Aleluyah! Jésù sọ, mo mọ pé otọ ni. Egbe: Wo k’o ye, Arakurin Wo Jesu ki o sí ye A kọ sínú ọrọ Rẹ, Aleluya! P’ẹni t’o ba wo Jesu y’o ye. A n’ọwọ iye sí ọ, Aleluya! Ao fi’ye ailopin fún ọ; T’o ba wo Jesu nikan, Aleluya! Wòó, On nìkan l’o le gbala. Egbe: Wo k’o ye, Arakurin Wo Jesu ki o sí ye A kọ sínú ọrọ Rẹ, Aleluya! P’ẹni t’o ba wo Jesu y’o ye. Amin. |
Re: Share Your Best Hymns by obasolape(f): 9:14pm On Nov 26, 2023 |
AO sise ! ao sise! Om’ -Olorun ni wa, Jek’ a tele ona ti Oluwa wa to; K’ a f’ imoran Re so agbara wa d’ otun, K’ a fi gbogbo okun wa sise t’ a o se. Egbe: Foriti ! Foriti ! Foriti ! Foriti ! K’ a reti, k’ a s’ ona Titi Oluwa yio fi de. Ao sise ! ao sise ! bo awon t’ ebi npa, Ko awon alare lo s’ orisun iye ! Ninu agbalebu l’ awa o ma s’ ogo, Nigbat’ a ba nkede pe, ” Ofe n’ igbala,” Egbe: Ao sise ! ao sise ! gbogbo wa ni yio se, Ijoba okunkun at’iro yio fo, Ao si gbe oruko Jehofah leke, won, Ninu orin iyin wa pe, “Ofe n’ igbala,” Egbe: Ao sise ! ao sise ! I’ agbara Oluwa, Agbada at’ ade yio si je ere wa; Ile awon oloto yio si je ti wa, Gbogbo wa o jo ho pe, “Ofe n’ igbala,” Egbe: Amin. 1 Like |
Re: Share Your Best Hymns by obasolape(f): 4:55am On Nov 30, 2023 |
1. BABA to da orun meje Ati ‘le meje pelu Aiye lo se ekedogun lyin ni f’oruko Re. Egbe: Ijinle loro na Awamaridi si ni, Ijinle loro na Awamaridi si ni. 2. Orun, Osupa, Irawo Awon ni ‘mole aiye Okuta Oniyebiye Awon ni ‘mole ‘sale. Egbe: Ijinle loro na... 3. Abo Oluwa Onike L’awa Egbe bora mo Ko s‘ohun ‘bi to le se wa Lagbara Metalokan. Egbe: Ijinle loro na... 4. Eni loyun a bimo la Agan a t’owo b‘osun Olomo ko ni padanu Iku ko ri wa gbe se. Egbe: Ijinle loro na... 5. Ko s’eniti nri ‘di okun A ki nri ‘di olosa Baba to da orun on aiye Ma je k’aiye r’idi mi. Egbe: Ijinle loro na... 6. Awon Agbara Emi meje Ta fi wo HOLY MICHAEL To si fi segun Lusifa Lojo ogun Olorun. Egbe: Ijinle loro na... 7. Baba, Omo, Emi Mimo Metalokan to gunwa Jowo ko gbo adura wa, Larin Egbe Serafu. Egbe: Ijinle loro na Awamaridi si ni, Ijinle loro na Awamaridi si ni. Amin |
Re: Share Your Best Hymns by obasolape(f): 11:27am On Mar 15 |
BI mo ti ri – laisawawi, Sugbon nitori eje Re, B’O si ti pe mi pe ki nwa – Olugbala, mo de. Bi mo ti ri – laiduro pe, Mo fe k’okan mi mo toto, Sodo Re t’o le we mi mo. Olugbala, mo de. Bi mo ti ri -b’o tile je Ija l’ode, ija ninu; Eru l’ode, eru ninu – Olugbala, mo de. Bi mo ti ri -osi, are, Mo si nwa imularada; Iwo l’o le s’awotan mi – Olugbala, mo de. Bi mo ti ri -‘wo o gba mi, ‘wo o gba mi t’owo t’ese ‘Tori mo gba ‘leri Re gbo – Olugbala, mo de. Bi mo ti ri – ife Tire L’ o sele mi patapata; Mo di Tire, Tire nikan – Olugbala, mo de. Amin. |
Re: Share Your Best Hymns by obasolape(f): 4:30am On Mar 17 |
Jesu, a fe pade, Lojo Re mimo yi; A si yite Re ka, Lojo Re mimo yi: 'Wo Ore wa orun, Adura wa n bo wa, Boju wo emi wa Lojo Re mimo yi. A ko gbodo lora, Lojo Re mimo yi Li eru a kunle Lojo Re mimo yi; Ma taro ise wa, K'Iwo ko si ko wa, Ka sin O bo ti ye Lojo Re mimo yi A teti soro Re Lojo Re mimo yi; Bukun oro ta gbo, Lojo Re mimo yi; Ba wa lo 'gbat'a lo, Fore igbala Re Si aya wa gbogbo, Lojo Re mimo yi. Amin. |
Re: Share Your Best Hymns by obasolape(f): 4:24am On Mar 22 |
Are mu O, okan re poruru? So o fun Jesu: Ibanuje dipo ayo fun o? So o fun Jesu nikan. Egbe: So o fun Jesu; so o fun Jesu Oun lore ti yoo mo Ko tun sore Ati'yekan bi Re So o fun Jesu nikan Asun-dakun omije lo nsun bi? So o fun Jesu, so o fun Jesu, O l'ese to farasin f'eniyan So o fun Jesu nikan Egbe: 'Banuje teri okan re ba bi? So o fun Jesu, so o fun Jesu O ha nsaniyan ojo ola bi? So o fun Jesu nikan Egbe: Ironu iku mu o damu bi? So o fun Jesu, so o fun Jesu Okan re nfe ijoba Jesu bi! So o fun Jesu nikan Egbe: Amin. |
Re: Share Your Best Hymns by obasolape(f): 4:24am On Mar 24 |
Hosanna s'omo Dafidi Hosanna, e korin Olubukun l'Eniti mbo L'oruko Oluwa. Hosanna s'omo Dafidi L'egbe Angeli nke Gbogbo eda jumo gberin Hosanna s'Oba wa Hosanna awon Heberu Ja imo ope s'ona Hosanna e mu ebun wa Fi tun ona Re se. T'agba t'ewe nke Hosanna Ki ijiya Re to de Loni a si nko Hosanna B'O ti njoba loke B'O ti gba'yin won nigbanaa Jo gba ebe wa yi Lorun k'a le ba Angeli korin Hosanna s'Oba wa. Amin. |
(1) (2) (3) ... (9) (10) (11) (12) (13) (Reply)
"Woman Gives Birth To A Lizard In Port-Harcourt" - Facebook User Claims (Pics) / This Female Nigerian Anglican Priest Will Officiate Wedding Of Gay Bisi Alimi / ''Thunder Uproots Fuel Tanks After Land Battle Btw Pastor And Businesman''. PICS
(Go Up)
Sections: politics (1) business autos (1) jobs (1) career education (1) romance computers phones travel sports fashion health religion celebs tv-movies music-radio literature webmasters programming techmarket Links: (1) (2) (3) (4) (5) (6) (7) (8) (9) (10) Nairaland - Copyright © 2005 - 2024 Oluwaseun Osewa. All rights reserved. See How To Advertise. 85 |