Welcome, Guest: Register On Nairaland / LOGIN! / Trending / Recent / New
Stats: 3,151,738 members, 7,813,424 topics. Date: Tuesday, 30 April 2024 at 12:11 PM

.. - Culture (59) - Nairaland

Nairaland Forum / Nairaland / General / Culture / .. (1828142 Views)

"We The Ewe People Of Ghana Are The Same As Yoruba"- Yewe2011.ewe Guy From Ghana / How Do U Spell (weed) In Yoruba, Is It Igbo? Or Egbo? / Yoruba Idioms: Owe Yoruba, Itunmo Re Ati Lilo Re (2) (3) (4)

(1) (2) (3) ... (56) (57) (58) (59) (60) (61) (62) ... (99) (Reply) (Go Down)

Re: .. by Ifankaleluya: 6:13pm On Feb 28, 2016
ONILEIFA:
[AGADAGODO TI KIIJE KENU ENU ENIYAN KO

Iye igun, iye agbe, ...Ekan si mi ..., etu ibon die[not original one], atare odindin kan, ao jo po, ao waabu sinu efe owu. ao fi owu dudu ati funfun we. ao waa so mo agadagodo.
*OFORE*
Moda ofa meta mo mu ikan mofita igun, igun ni enu won koni gun, modafa meta mo mu ...efi number sile fun iyoku....., modafa meta mo mu ikan mofita agbe lenu, agbe loni odi igbo rere, etu loni kiwon tuka.


WONYI NI ONIRURU ORUKO TI NWON FI NPE AWON ODU OWO ENRINDILOGUN¤
1. OKANRAN
2. EJIOKO
3. OGUNDA
4. IROSUN
5. OGBESE
6. OBARA
7. ODI
8. EJIOGBE
9. OTURA
10. OFUN
11. Owonrin
12. Ejila Sebora
13. Odu pariwo
14. Oyeku
15. Igara
16. Adakete



Aye wa fun ibere tabi so unkan ti oba ru yin ni oju.

Nibo lo ti ri gbogbo awon odu-ifa iro re yi okunrin yi? Haaaaaaa.....erin re pa mi.

1 Like

Re: .. by Nobody: 6:17pm On Feb 28, 2016
healthFirst:

DIDA IRAWO PADA
_Ao han surat
kaosara 9 fun okunrin iyere bii ideri rub ipara aolu igbin kan nidi aogbe omi re sinu hantu ao ge igbin yen si 16 aose leponiyo odi jije
Ose re _
igbin kan aalomu dudu eepo obo gigun pomo ose ..eemeji lao maa fiwe lose kan

Baba healthfirst eejo wo mo nidi alaye ranpe die si lori ise yi : Ki la ma fi iyere yen se ?, elekeji se a ma yo ikarahun igbin ka to ge si 16 ?

2 Likes

Re: .. by ONILEIFA: 7:03pm On Feb 28, 2016
[quote author=Ifankaleluya post=43334982][/quote]


Eyi owun e wi mi o ni lo lati ba yin jiyan rara to ri wipe eyin ni aroni lale odo
Re: .. by ONILEIFA: 7:05pm On Feb 28, 2016
Ìbà o, Obatala, Oba taasa,
Oba patapata lode Iranje,
Ìbà Iranje’le Iba Iranje oko,
Ìbà Ifon-Osun,
Ìbà Igbin, Iba Igbin-Oosa,
Ìbà Alágemo-téérekangé,
Je a gbo Je a to;
Ìbà Abamoda omo Oosa-Agbowujin,
Mo daba ire aje, ire aya/oko, ire omo, ire gbogbo,
Aba ti Alagemo bada lOosa-Oke n gba,
Ìbà Gunyan gunyan ile Ido,
Ìbà rokaroka obinrin Ibadan,
Ìbà Aje tii n somo Olu-Ibini,
Ìbà Okun tii n somo Ode-Irada,
Ìbà Orò, òròpòtò pómùpómù,
Tobi ‘mo léweléwe ti kan kan o sofun,
Ìbà Osanyin –mògbòráyè, To gba opa lowo olókùnrùn sanu.
Aye mo juba é jé ki o ju mi sé

2 Likes

Re: .. by ONILEIFA: 7:34pm On Feb 28, 2016
Ifankaleluya:


Nibo lo ti ri gbogbo awon odu-ifa iro re yi okunrin yi? Haaaaaaa.....erin re pa mi.

[quote author=Ifankaleluya post=43334982][/quote]


BABA IFAKALELUYA EJO WO KI NI MO RA NI IGBA YIN ONIKON KO JABELE KALUKU N SE TI RE O DAMI LOJU GBAN GBA PE ODU IFA YEN NI OGBE IRETE TI AN PE NI OGBE ATE TI KO BA RI BE E FI TI YIN SI TA KA RI EDA TO NWO SE OKUNKUN KO MA SE DO SUPA LORO.

Re: .. by keyguy59(m): 8:07pm On Feb 28, 2016
Baba healthfirst se e ri.......awon ti won pe a wa ni copy and past.....afi suru........e mi o jin yan..sugbon eni ti won ma gba lo ma po ju.......emi......keyguy mi o je fi ogun mi si le fun enikeni.....aya fi ti ba ma....se copy and past......fun won....
Re: .. by Ifankaleluya: 10:55pm On Feb 28, 2016
ONILEIFA:



Eyi owun e wi mi o ni lo lati ba yin jiyan rara to ri wipe eyin ni aroni lale odo





arunkunrin o le bami jiyan tori onijibiti ni ooooo. Nibo loti ri gbogbo odu-ifa iro re yen? Dakun nje o ti e mo odu to bi o gan? Pelepele re ooo...ko ye ki e mo fi oruko babalawo gba awon eniyan,ti o ba wu o lo ona miran.
Re: .. by Ifankaleluya: 11:08pm On Feb 28, 2016
ONILEIFA:





BABA IFAKALELUYA EJO WO KI NI MO RA NI IGBA YIN ONIKON KO JABELE KALUKU N SE TI RE O DAMI LOJU GBAN GBA PE ODU IFA YEN NI OGBE IRETE TI AN PE NI OGBE ATE TI KO BA RI BE E FI TI YIN SI TA KA RI EDA TO NWO SE OKUNKUN KO MA SE DO SUPA LORO.


Ogbeni..ko wu mi lati da o lohun oro re tori mo ti se ipinnu lati ma so oro lori thread yi mo,sugbon mi o ni la oju mi sile ki o ma fi ifa paro fun awon eniyan. Emi o kin n se baba-alariwo, babalawo ni emi,fun idi eyi mo ni lati fo esi si oro re.
LO BA BABALAWO RE PE IFA IRE-N-TEGBE LOPE FUN O NI OGBE-ATE. ONIJIBITI NI OOO,INU-IWE ALAWIYE LO TI WO,O KIN NSE BABALAWO.

ifa ni ogbe wa te ki ara o ro won,eni wa iwakuwa,a ri irikuri lodifa fun apon to sai laya nile to n toro omo lowo-orisa.
Arakunrin se pele-pele,mo ri ibinu awon awo. Ma wa iwakuwa loruko awon babalawo!
Dakun ki ese ifa kan ninu ogbe-ate to so yen gan?
Re: .. by Ifankaleluya: 11:13pm On Feb 28, 2016
ONILEIFA:
Ìbà o, Obatala, Oba taasa, Oba patapata lode Iranje, Ìbà Iranje’le Iba Iranje oko, Ìbà Ifon-Osun, Ìbà Igbin, Iba Igbin-Oosa, Ìbà Alágemo-téérekangé, Je a gbo Je a to; Ìbà Abamoda omo Oosa-Agbowujin, Mo daba ire aje, ire aya/oko, ire omo, ire gbogbo, Aba ti Alagemo bada lOosa-Oke n gba, Ìbà Gunyan gunyan ile Ido, Ìbà rokaroka obinrin Ibadan, Ìbà Aje tii n somo Olu-Ibini, Ìbà Okun tii n somo Ode-Irada, Ìbà Orò, òròpòtò pómùpómù, Tobi ‘mo léweléwe ti kan kan o sofun, Ìbà Osanyin –mògbòráyè, To gba opa lowo olókùnrùn sanu. Aye mo juba é jé ki o ju mi sé
Dake enu re joorr...Iba iro re wo? Ifon-osun ko....Ifon-oyo ni. Onijibiti..!
Re: .. by Ifankaleluya: 11:23pm On Feb 28, 2016
ONILEIFA:
#1

EBO AYE TODAJU*
Eyin meje,
Odidi Okete,
Orogbo meje,
Eyin Open meje,
Oti ati epo,
Awo sobi kan,
Ao fi Ifa osa meji koru,
Otan.


#2
OOgun Atepa
ESE pepeye mejeeji, ao pelu odidi atare kan, ao wafi sin ESE mejeeji yika.

#3

Owo(respect) fun ole:-
Igi Abo, ao fi nu idi, ao fi aso funfun di ni ikobere, ao wafiko ibi ti aba nso.
Ole koni wo ibi ile ti aba fiko laelae.
NB:- (for vengeance) Atun leefi gba esan, eni to fe fi GBA esan korimi

gbe enu re dake joorr...iwo mo ohun ti won npe ni aye?igi-abo re wo lo fi n nu idi? Din-dinrin,dakun bawo lo se fi ifa osa-meji ko ebo ru jare?
ONIJIBITI!
Re: .. by Naturewonders: 11:31pm On Feb 28, 2016
Hymn...Oludasile ku agba,won de ku opolopo suruu.emi kii se awo,sugbon ni gba ti mo ri ohun ti awon ti won pe ara won ni babalawo post nse ni erin kan pami ni.Se efe ba ti awon eyan je ni.mo ro awon ogberi ,ogun ti healthfirst oba fi owo si ,ko ma se dawole ti won ba nife arawon.iro se wa dun lenu eyin oni jibiti bi oyin bai.oro baba sese nye mi ni.baba edakun ema wo ran tori oruko yin.won ti fe ba eto yi jeo.esun pupo
Re: .. by Nobody: 6:01am On Feb 29, 2016
.

1 Like

Re: .. by Nobody: 6:14am On Feb 29, 2016
keyguy59:
Baba healthfirst se e ri.......awon ti won pe a wa ni copy and past.....afi suru........e mi o jin yan..sugbon eni ti won ma gba lo ma po ju.......emi......keyguy mi o je fi ogun mi si le fun enikeni.....aya fi ti ba ma....se copy and past......fun won....

Ejabure...mr keyguy59. ejowo e fun mi ni email yin?
Re: .. by ONILEIFA: 9:00am On Feb 29, 2016
Ifankaleluya:


gbe enu re dake joorr...iwo mo ohun ti won npe ni aye?igi-abo re wo lo fi n nu idi? Din-dinrin,dakun bawo lo se fi ifa osa-meji ko ebo ru jare?
ONIJIBITI!


Ara lon ta ee onijibiti agba.
Re: .. by Nobody: 9:40am On Feb 29, 2016
Ogbeni Ifankaleluya ati OnileIfa, ki keke pa mo yin lenu, eyin obileje awo eke. ki le ri ninu obe te fi waro owo bayi? A gbe eto yi sita lati ran awon ti aye n fiya je lowo ati lati gba won sile lowo eyin Awo eke gbogbo. lehin gbogbo ikilo ta kin yin, e tun wa n paro orisirisi. Mo fe fi dayin loju, teo ba dawo ibi duro, eo gba Esu lalejo laipe. Egbinrin ote loro yin, ba se n pa kan nikan n ru jade. E ki owo omo yin sinu aso ni kiakia te ba fe ka fi Epe ranse si yin.

Ikilo leekan si fun gbogbo awon ti won fe se ogun kan tabi meji lori ikanni yi; yato si oogun ti mo fi sita ati awon eyi ti ogbeni kadunasouth fi sita, iro funfun ni gbogbo eyi to ku. E kiyesara o! Bi enikeni ba ko eti didi si awon ikilo wonyi, o ku si lowo ati Eleda re o. oogun eke ma n ba kadara eeyan je lehin igba ti won ba fi owo yin sofo. Ao ni ri ogun agbana lati owo awon Awo eke o!.

3 Likes

Re: .. by Oluokunoluwole: 11:20am On Feb 29, 2016
Ifankaleluya:
IFA-ISOYE

ODIDI OROGBO KAN, ODIDI ATAARE KAN, OBI-ABATA OLOJU MERIN KAN, EJA-ABORI KAN, EWE-ONIYEMIYE,EWE-EERAN ATI EWE ATORI. AO GUN PAPO TI YIO KUN NA DADA BI AGUNMU,AO WA TE NI ODU-IFA OLOGBON-MEJI,AO WA PE IFA RE SI

IFA RE: sabe lawo sade, asa lawo asagede,arara abori patoki awo ile orunmila, lodifa fun orunmila nigba ti baba nsawo ti ko ni iye ninu, ifa ni to ba bi ise tohun(to ba se bi ise temi lagbaja omo lagbaja ba ni. Ni e ma lo larin yen) ba ni, ifa ni iye-orogbo kiiku mo orogbo ninu ka je ko ma le koro,iye obi kiiku mo obi ninu ka so ko ma le yan,iye ataare kiiku mo ataare ninu ka je ko mo le ta ni lenu, eyi ti mo jaja gbagbe eja loni ko ja simi ninu,eeran loni kin ma ranti, atori loni ko to nikun mi worowo,ipanan merindinlogun ni ewe-oniyemiye ma n ni,gbogbo ara ni fi so. Ologbon-meji fun mi ni iye temi kin gbon sara-sara. AO MA FI MU EKO-TUN DIE-DIE.
NOTE
mo fi ifa yi sile fun iwulo awon eniyan ni. Ti iwo ti o n ta iwe ba ko sori iwe-re,lagbara lowo eledumare wa ri ija awon eleye. Mo fi odu-mererindinlogun bura.

FUN IMONRAN TABI OHUNKOHUN, E KAN SI WA LARI ifankaleluya@gmail.com
Ela boru, Ela boye, Ela bo sise.
eku ise opolo eledua a ran yin lowo,ti eba ni orisi isoye miran ebawa fi sita
Re: .. by ONILEIFA: 12:21pm On Feb 29, 2016
healthFirst:
Ogbeni Ifankaleluya ati OnileIfa, ki keke pa mo yin lenu, eyin obileje awo eke. ki le ri ninu obe te fi waro owo bayi? A gbe eto yi sita lati ran awon ti aye n fiya je lowo ati lati gba won sile lowo eyin Awo eke gbogbo. lehin gbogbo ikilo ta kin yin, e tun wa n paro orisirisi. Mo fe fi dayin loju, teo ba dawo ibi duro, eo gba Esu lalejo laipe. Egbinrin ote loro yin, ba se n pa kan nikan n ru jade. E ki owo omo yin sinu aso ni kiakia te ba fe ka fi Epe ranse si yin.

Ikilo leekan si fun gbogbo awon ti won fe se ogun kan tabi meji lori ikanni yi; yato si oogun ti mo fi sita ati awon eyi ti ogbeni kadunasouth fi sita, iro funfun ni gbogbo eyi to ku. E kiyesara o! Bi enikeni ba ko eti didi si awon ikilo wonyi, o ku si lowo ati Eleda re o. oogun eke ma n ba kadara eeyan je lehin igba ti won ba fi owo yin sofo. Ao ni ri ogun agbana lati owo awon Awo eke o!.

Baba Ema binu ogbeni Ifankaleluya lo ni a mo ju lara... ologun eke ti on pe ra re ni aroni lati eni lo mi ko ni fi ise sita lai gba ase lowo yin

1 Like

Re: .. by Nobody: 3:19pm On Feb 29, 2016
ONILEIFA:


Baba Ema binu ogbeni Ifankaleluya lo ni a mo ju lara... ologun eke ti on pe ra re ni aroni lati eni lo mi ko ni fi ise sita lai gba ase lowo yin

Ifa a gbe yin fun esi te fun mi. Mio kuku binu sugbon ko le da na mo gbiyanju. Ko si eni kan to le so wipe oun mon gbogbo inkan tan sugbon ta ba ri ayederu, o ye ki a mon wipe ayederu ni.

Eni tio ba ti fe ko ara re nijanu lori ikilo ti mo fi sita, ko lo da ikanni tire sile. ki won ma se ba ibi je fun mi ati fun gbogbo awon ti won se ogun lori ikanni yi.

E seun leekan si, ogbeni OnileIfa.
Re: .. by akingbemi(m): 3:36pm On Feb 29, 2016
healthFirst:


OGUN IKIYA FUN ENI TI AYA RE N JA-
Oko sango, a o fi sinu ina. Ti o ba gbona daada a o ju sinu epo pupa die. To ba tutu, a o yo ninu epo yen. A a wa da epo yen sinu ekuru ti a ti fo, ao po mo, a. A wa je e.

Sugbon Ikilo kan wa...Bi Oogun yi ba wa lara wa, Oogun Egbe ko ni sise nitoripe bi aya wa ko ba ja nigbati ohun eru ba sele, Oogun Egbe ko ni sise.
ejo kini oko sango
Re: .. by akingbemi(m): 3:42pm On Feb 29, 2016
[quote author=Jadonjack post=32751371]

Ejoor, seh eleyi ni agbara re kopo abi fun igba wo ni eleyi lee siseh di?[/quote
ejo kin I itumo eleyi to ko lu rara
Re: .. by Nobody: 5:23pm On Feb 29, 2016
akingbemi:
ejo kini oko sango

Edun Aara/Sango

2 Likes

Re: .. by tundeologo: 6:18pm On Feb 29, 2016
Suuru baba iwa
Suuru loba awure
Eni toba ni suuru-ohun gbogbo loni.

Emi koi tii Dan ise kan wo ri toje ti ori ikanni yii
Sugbon igba kugba ni mo man ko eko gidi lori ikanni naa
Nipa eto ilana iwosan Yoruba ni ka soni
Abi ti ona iyanu ti yoruba n GBA toju emi(spiritual.....)

Moti fi igbakan je alatako si ijinle agbara ti olohun fun Yoruba ri
Sugbon Lehin opolopo experience pelu research
Mori otito dimu sinsin lai pa esin mi Lara

Eko ni mo maan ko ni ojoojumo lori ikanni yi
Mo si mo wi pe opolopo naa wa bee
Mo tun ti wa ko eko tuntun lat'ara baba healthfirst

Baba, oluwa atubo je ki e le maa se suuru
Bi eniyan yio ba te, bi eda yio ba kan abuku,
Suuru ni yio koko sonu lowo oluwa re

Baba,e o ni te o, eo ni kan abuku ati gbogbo wa naa
Gbogbo wa na ao ni te, ao sini subu , ao ni so ire owo wa nu
E je ki gbogbo wa naa maa ni suuru daada
Kasi mo tori Ohun ti aoje, ba ti eni eleni je,
Ka ma ko idamu ba omolakeji
Ka ma da wahala si won l'agbada
Ranti wipe, "bi iwo ko bale pa eniyan lerin,
Ko ni eto ki o paa lekun o"
Bi ogun ba jelo, ogbon a jebo
A tubo maa dara fun wani o(ase edumare)

2 Likes 1 Share

Re: .. by Nobody: 9:55pm On Feb 29, 2016
Ifa A gbe Yin O!

tundeologo:
Suuru baba iwa
Suuru loba awure
Eni toba ni suuru-ohun gbogbo loni.

Emi koi tii Dan ise kan wo ri toje ti ori ikanni yii
Sugbon igba kugba ni mo man ko eko gidi lori ikanni naa
Nipa eto ilana iwosan Yoruba ni ka soni
Abi ti ona iyanu ti yoruba n GBA toju emi(spiritual.....)

Moti fi igbakan je alatako si ijinle agbara ti olohun fun Yoruba ri
Sugbon Lehin opolopo experience pelu research
Mori otito dimu sinsin lai pa esin mi Lara

Eko ni mo maan ko ni ojoojumo lori ikanni yi
Mo si mo wi pe opolopo naa wa bee
Mo tun ti wa ko eko tuntun lat'ara baba healthfirst

Baba, oluwa atubo je ki e le maa se suuru
Bi eniyan yio ba te, bi eda yio ba kan abuku,
Suuru ni yio koko sonu lowo oluwa re

Baba,e o ni te o, eo ni kan abuku ati gbogbo wa naa
Gbogbo wa na ao ni te, ao sini subu , ao ni so ire owo wa nu
E je ki gbogbo wa naa maa ni suuru daada
Kasi mo tori Ohun ti aoje, ba ti eni eleni je,
Ka ma ko idamu ba omolakeji
Ka ma da wahala si won l'agbada
Ranti wipe, "bi iwo ko bale pa eniyan lerin,
Ko ni eto ki o paa lekun o"
Bi ogun ba jelo, ogbon a jebo
A tubo maa dara fun wani o(ase edumare)

1 Like

Re: .. by akingbemi(m): 10:48pm On Feb 29, 2016
healthFirst:


OGUN IKIYA FUN ENI TI AYA RE N JA-
Oko sango, a o fi sinu ina. Ti o ba gbona daada a o ju sinu epo pupa die. To ba tutu, a o yo ninu epo yen. A a wa da epo yen sinu ekuru ti a ti fo, ao po mo, a. A wa je e.

Sugbon Ikilo kan wa...Bi Oogun yi ba wa lara wa, Oogun Egbe ko ni sise nitoripe bi aya wa ko ba ja nigbati ohun eru ba sele, Oogun Egbe ko ni sise.
ejo mio no bi won tin Jo Ogun sir
Re: .. by akingbemi(m): 6:37am On Mar 01, 2016
Ousmaf:

ejoo sir se odindi OLONGBO abi ori re lao lo fun osole nla yen abi bao?
ejo Baba mio more big won Tin Jo Ogun esaye e fun mi sir
Re: .. by akingbemi(m): 6:38am On Mar 01, 2016
Ousmaf:

ejoo sir se odindi OLONGBO abi ori re lao lo fun osole nla yen abi bao?
ejo Baba mio mo bi won Tin Jo Ogun esaye e fun mi sir
Re: .. by scholes0(m): 6:58am On Mar 01, 2016
healthFirst:


Edun Aara/Sango

Se oun ni awon elede geesi ma n pe ni "fulgurite"? Okuta ti o maa n wa ni ibi ti monamona bá ti ba ilè?

Re: .. by Zalam5: 3:35pm On Mar 01, 2016
healthFirst:
hello, this thread is for lovers of nature when it comes to health and other areas of our lives. This thread is also strictly for the Yorubas and those who can read and understand as the language here is going to be pure Yoruba and no translation will be allowed. Reason is that we are going to be revealing some Yoruba secret knowledge of the application of leaves and roots and we intend to preserve and guard these wisdom of our ancestors.

Please do not ask further question regarding my reason to keep this as a Yoruba affairs, it's my choice...but if you refused to respect this, I shall only dignify you with silence.

Aye wa fun o lati beere fun iru Oogun to ba fe sugbon ao ma ko awon orisirisi Oogun sita. Awon Oogun fun itoju aisan, akoya, ati awon Oogun fun isora/isori, awure, aworo, ati beebe lo. Sugbon kii se gbogbo Oogun ni a le fi sita lofe, awon eyi to ba ni agbara gan ni ao so wipe ki e kan siwa lori apo ifiwe ranse wa binaryteck@gmail.com fun ekun rere alaye.

E le dara po mo wa lori whatsapp pelu ero ibanisoro yi...08148398067...e fi gbogbo ibeere yin ranse, ao da yin lohun

Bi a ba ri inkan ti ko ye wa, e je ki a beere ibeere pelu alaye, ao si gbiyanju lati se alaye lekun rere.

Gbogbo Oogun ti a ba ko sita la ti dan wo, to de ni idaniloju wipe yio se ise ti a ba ran.


Iwe iwulo ewe, egbo ati eranko ti wa fun tita bayi pelu owo kekere. Die ninu awon oogun to wa ninu iwe na niwonyi: 1. Oogun arobi nla, 2. Agbelepota, ebe agba to daju, 3, eyonu nla, 4. Osole tutu, 5. Ayeta, 6. Okigbe ada, 5. Oki igo, 6. Ki ota ma le yin wa lorun, 7, isuju, 8. Bi omo ba dabu sinu alaboyun, 9. Ki alaboyun bimo pelu irorun lai se ise abe, 10. Bi inkan osu obinrin o ba se deede, 11. Afeeri to daju, 12. Oruka aluwo oni yepe, 13. Asubusere, 14. Oogun arun ito sugar, 15. Oogun arun ogbe inu, 17. Oogun arun ogun oru, 18. Olubasiri, 19 awure nla ti a n pe ni fayegbami, 19. Oogun apesin, 20. Oogun afaro nla, 21. Oogun fun awon omo yahoo. 22. Oogun ohunmo, 23. Oogun ariran, 24. Oogun isoye. 25, oogun jedojedo. 26. Oogun roparose, 27. Oogun ajidewe. 28. Oogun awoka/eje dudu, 29. Oogun obinrin ti o n yan ale, 30. Oogun afose, 31. Awise, 32. Agadagodo nla, 33. Aforan to lagbara, 34. Orikosungbo/egbe, 35 ipese awon agba 36. Oogun idakole, 37. Oogun fun ato okunrin ti ko le di omo, 38. Oogun afato ti kii fi tete re okunrin lori obinrin, 39. Oogun fun igbega lenu ise. 40. Oogun fun oju rere lati odo gbogbo eniyan .....ati beebelo...awon orisirisi oogun to wa ninu iwe na le ni 500. Gbogbo re si je ojulowo oogun. Bi e ba fe ipin ninu iwe yi, e kan si wa fun account number ti e ma san owo si. Iwe yio te yin lowo ni ojo keta te ba ti san owo. E seun o, isese a gbe wa o! Ase.

Iwe yi ti wa ni tita nile Eko bayi ni Iju_ishaga.




Too, mo seba awon agbalagba awo ile aye, mo seba awon awo ode orun, mo seba awon Iya mi abeni...e juba o se o.

Iba, iba, iba

Akoda iba

Aseda iba

Ile ogere a foko yeri

Alapo Iku

Olona ola, iba

Esu odara, iba

Irunmale olukotun

Igba imale olukosin

Iba gbogbo yin o

Ero osaju, ero eyin, iba

Adase ni ni wun omode

Iba ki wun ni o

Eyin to ni aye

E je sise mi o san mi

Emi lomo agba

E je owo a maa je fun mi o

Ada ki nmu, ki o ge eku idi e

Omo eni ki nburu,

Ki a gbe fun ekun pa je

E dari jimi, ki e fi owo mi wo mi

Emi lomo aie fepo we

Osoronga opiki elese osun

Ajefun jedo

Oriri aye

Ebo aye ni a ru o

Osoronga ni nba ni gbele aye

Aje ni npa eni

Osoronga gbigbe ni o gbe mi o

Aje ma pa mi lomo
Lomi ki o somo mi

Iya mi agba opiki elese osun

A woni maye

A woni loju re orun

Eje lepo ekuru won

Iya-mi aye elekuru pupa foo

O gberita jagun

O gbe origi ke kanran kanran

Fori jimi bi mo ba se

Fi owo re wo mi

Na ke kanran wonu ile mi

Iya-mogun alara

Bi igun jebo

Aje gbe ni nje

Bi akala jebo

Aje gbe ni nje

Gbogbo eyi a ba se

Asegben ni e je o je

Iya-agba alapo iku

Olokiki oru


Ki nfo o fara pa

Onile origi ki njebo

Ki ebo naa ma gun rege

A agba ki nfi abo bo eni

Ki Omo ara aye ma ri ami won Lara eni

A jefun jedo

Ki nje tire tan

Ki o ma fio na han eni

Iya mi toto aye

Fio na han mi

Bi o ba gbe ori igi ke

Ma ke ao mi

Bi o gbe orita ke

Ma ke pa mi

Kike ni ki o fi ike re ke mi

Omidan eleye oloju owiwi

A ri eni ko to pe eni

Omoran ologbon

Linmo riro ati w ri eda

Alapo iku olona ola

Iku ti nba nro nile mi

Re danu,Opiri eleye moran bi afefe

Arun ti nba nro nile mi

Ro danu

Iya-mi omoran eleye

A pani ma yoda

A mubo ti nbe laye mi

Re danu o

Eyin ti o ni aye

E fa mi mora

Aje eleye e fa mi mora o
Subgon number Te fisita wipe kadarapo moyin Lori what's app yen o ti wa active Lori what's appeal
Ko is number yen ni what's app now
Why ?
Re: .. by 08101646045atwp(m): 9:54pm On Mar 01, 2016
hmm! okan wa dunmi fun awon ogberi ni thread yii sha, nitori awo ni awo amaje, sugbo ogberi loma nri nkan ti koto nkan ti afelatimo ju oni nkan, ode tun dun mi fun gan eni ti oni abalayi, nitori kosi bi ase fese ebolo ti koni run igbe, tori awon eyan toje alapa leti si nbo wa, ki Olorun fun wa lagbara lati kapa won atanni ni suuru'o. Ojogbon wa H.F. Olorun amakoyi'o. Tori awon towa nile ti won'o soro safefe, won po ju eyin ti ewa lori ategun lo, sugbon onikaluku lonsa fun oruko, tori oruko rere san ju wura ohun fadaka lo. AJUWASE'O
Re: .. by ONILEIFA: 9:58pm On Mar 01, 2016
¤HAPPY NEW MONTH GREAT FANS¤
<OSA-OLOYAN>
! !!
! !
!! !
! !
Bi ara eni ba n laje, bao ba laje,
oju amaa yan ni.
Bi ara eni ba n kole, bao ba koo,
Oju amaa yan ni.
Bi ara eni ba n laya bao ba ni,
Oju amaa yan ni.
Bi ara eni ba sere gbogbo bao ba seekan, oju amaa yan ni.
Adiafun Osa oloyan,
Ekun ire gbogbo niisun.
Ebo niwon nio see,
O rubo tan, ire wole re wa.
Nje kini Oloyan gbewa fawo?
Jingbinjigbin ileke, ola nla loloyan gbewa fawo,
Jingbinjingbin ileke.
Kini Oloyan je lere o?
Jingbinjingbin Ileke, Ere nla loloyan je,
Jingbinjingbin ileke.
Gbogbo ohun to n dun awa FANS egbe yi lokan ni Olodumare aa see fun o(ase).
Aa je ere ninu osu tuntun yi o,
Gbogbo ire ti egbe awa FANS page yi nse lawa naa amaa bawon gbele aye se.
OLODUMARE KO NII SE AWA FANS PAGE YI LASINNIWAYE O(ASE).
Wishing you a joyful MONTH!!!.
Re: .. by 08101646045atwp(m): 10:08pm On Mar 01, 2016
AGO'onile'o, fun eyin ti enbere ibeere nipa osu, tabi ti nta nso'oye,
opolopo ntaso koseyin akose jaye, dida ara eni mo, iwadi nipa eto igbe aye wa, boba wa laye
bi okoba da arare mo inira amawa ni igba kokan, tojepe bi oba se oogun gan
koni sise, sugbon aje, oso, emere lama ndi lelori, bi akose jaye ba ndani laamun
bi eyi tojepe eyan si aye wa ni, tori bore waju pabo ni, bore yin pabo ni, atotun atosi bi alai monse ni
bi oro bari bai, owo Ori lati nbeere, tori ori eni lawure eni, ogun loni ojo iponju
kafola fori tolojo gbogbo. fun iwo ti obafe lati wo akose jaye re onilati kansi awon ojogbon ni abalayi tabi ki ofi ojo ibi re ranse. ajuwase'o

(1) (2) (3) ... (56) (57) (58) (59) (60) (61) (62) ... (99) (Reply)

(Go Up)

Sections: politics (1) business autos (1) jobs (1) career education (1) romance computers phones travel sports fashion health
religion celebs tv-movies music-radio literature webmasters programming techmarket

Links: (1) (2) (3) (4) (5) (6) (7) (8) (9) (10)

Nairaland - Copyright © 2005 - 2024 Oluwaseun Osewa. All rights reserved. See How To Advertise. 81
Disclaimer: Every Nairaland member is solely responsible for anything that he/she posts or uploads on Nairaland.