Welcome, Guest: Register On Nairaland / LOGIN! / Trending / Recent / New
Stats: 3,150,608 members, 7,809,225 topics. Date: Friday, 26 April 2024 at 06:01 AM

Ogun Awon Bàba Wa - Culture (3) - Nairaland

Nairaland Forum / Nairaland / General / Culture / Ogun Awon Bàba Wa (326020 Views)

Asiri Aiye Siwa Lowo Awon Agba Woli / Asiri Ijinle Awon Woli Lailai / Asiri Ogun Awon Baba Wa (2) (3) (4)

(1) (2) (3) (4) (5) (6) (7) (8) (9) (Reply) (Go Down)

Re: Ogun Awon Bàba Wa by ALIUDAVID: 10:43am On Dec 29, 2015
Ago onile Baba wa ayomikun ati eyin agbagba lori itakun yi, ejo ti e ba ni atupa aye(lantern) ejo efun wa, aye ko ni pa atupa wa ase... Iba eyin to laye iba agbagba..

1 Like 1 Share

Re: Ogun Awon Bàba Wa by Naturewonders: 10:58am On Dec 29, 2015
ayokomi1010:
OGUN TAFI WE ISE OSI DANU
Ao toju odidi ori etu kan,iye agbe meta,iye aluko meta,ikode meta,iye lekeleke meta,iye akala meta,iye igun meta,iye awodi meta,ao Jo po pelu atare odidi kan,ao po Mo ose,ao kosinu igba olomori,ao te ifa osa meji si lori,ao ma fi we,ao bere si ri se,iba eyin agba o.
Ejo baba se etu elese merin ni abi eye awo ti won pe ni eye etu.eseun pupo

3 Likes

Re: Ogun Awon Bàba Wa by Snowealth: 2:10pm On Dec 29, 2015
ayokomi1010:
OGUN ONMO NLA
odidi eye karo kan,ori olongbo kan,egungun eye akala die,eja ojiji kan,odidi imo ope kan,odidi atare kan,ikode meta,ao jopo gbere kan si igbayawa,iyoku Ogede omini pupa la o mafi koje,kosi oun kan ti o sokunkun siwa koda won a tunma kowa ni OGUN loju orun pelu.odaju iba eledumare o
E ku ise takuntakun Baba, oluwa a ma ran yin lowo. E jowo, onmo yii, se ti onmo oju orun ni tabi ti iriran ti eniyan fi n mo ohun to ti sele ri, ati ohun to tun nbo wa sele lola? E seun , modupe, odun a ba wa layo.

2 Likes

Re: Ogun Awon Bàba Wa by pappykay0428(m): 2:27pm On Dec 29, 2015
ayokomi1010:
OGun AJEGUN.
ao toju oga aye kan,ao fi ako Okuta ge iru oga na ni aye,ao lo pelu omo atare mesan,ao fi si gbere yipo owo mejeji. o daju.
E jowo se ajegun mi ttunwa leyin eleyi ti o si sise daada,

1 Like

Re: Ogun Awon Bàba Wa by ayokomi1010(m): 4:58am On Dec 31, 2015
ori eye Awo ni ti a tun peni etu

1 Like

Re: Ogun Awon Bàba Wa by ayokomi1010(m): 4:59am On Dec 31, 2015
beni ajegun Miran wa
Re: Ogun Awon Bàba Wa by ALIUDAVID: 7:56am On Dec 31, 2015
Baba wa ayomikun ati eyin agbagba lori itakun yi, ejo ti e ba ni atupa aye(lantern) ejo efun wa, aye ko ni pa atupa wa ase... Iba eyin to laye iba agbagba..
Re: Ogun Awon Bàba Wa by Ousmaf(m): 9:24am On Dec 31, 2015
Agoo nile, ejoo efun wa ni Ogun ti eni to sese pari eko re to nwa ise yio fi ri ise to lalubarika, eseun adua wa a man gba pelu ase Edumare.
Re: Ogun Awon Bàba Wa by Nobody: 3:32pm On Jan 02, 2016
ayokomi1010:
OGUN ONMO NLA
odidi eye karo kan,ori olongbo kan,egungun eye akala die,eja ojiji kan,odidi imo ope kan,odidi atare kan,ikode meta,ao jopo gbere kan si igbayawa,iyoku Ogede omini pupa la o mafi koje,kosi oun kan ti o sokunkun siwa koda won a tunma kowa ni OGUN loju orun pelu.odaju iba eledumare o
MO NILO IRANLOWO YIN O E jowo, se oogun yi le sise fun lotto jije? Ati wi pe onmo wo le tun mo ti eroja ko ju nnkan meji tabi meta lo? E o ni subu daanu o.

1 Like

Re: Ogun Awon Bàba Wa by Makapounse(m): 7:19am On Jan 03, 2016
ayokomi1010:
e karo,aku ojumo rere o, Awon baba wa Ni iwure yi dara pupo Lati ma lo ni owuro kutu papa julo OJO aje, Ao bu OMI tutu sinu igba kan tabi Awo,ao te ejiogbe si ori omi na,ao wa wure yisi,lehin na la o mu die nibe ao da iyoku sile ni enu ona ile wa ao fi ese alafia te mole bo sita,Iwure:-) OMI sepesepe nise OMI alaketu,agbara gbururu nise OMI ete ife,o dara fun eyin aja eyin aja funfun nini,o dara fun OMI iyirisi OMI iyirisi ntan yiriyiri,nje o ori wa di ori Ade loni o,orun wa di orun ileke ola,ESE wa di ESE bata ola loni,nitoripe ojukan ti oka Ba joko si lohunje oka lo Ba oka,ojukan ti ere jokosi ni ohunje ere ba ere,ojumo Ki Mo Ki adariwurun ma bere OMI,ejiogbe o sebi odu mererindilogun ni se erusin fun ejiogbe,Ki won wa fi oun rere sin mi loni o,kiri aje se ohun rere.Ase ase ase . ! kabiyesi eledumare oba ajiki o,aiye toto akamora iba o,ire ni mase nitemi Omo obasayero,mi o Ni se ika,sugbon bi aye bawa so ire di ibi ipade di ohun o.
se ibi ipade di ohun,abi ibi ase ase ase ni iwure yi ti pari ?
Re: Ogun Awon Bàba Wa by Makapounse(m): 7:25am On Jan 03, 2016
ayokomi1010:
OGUN ONMO NLA
odidi eye karo kan,ori olongbo kan,egungun eye akala die,eja ojiji kan,odidi imo ope kan,odidi atare kan,ikode meta,ao jopo gbere kan si igbayawa,iyoku Ogede omini pupa la o mafi koje,kosi oun kan ti o sokunkun siwa koda won a tunma kowa ni OGUN loju orun pelu.odaju iba eledumare o
se o le sise fun baba ijebu lotto
Re: Ogun Awon Bàba Wa by Naturewonders: 6:32am On Jan 04, 2016
[quote author=ayokomi1010 post=41504908]ori eye Awo ni ti a tun peni etu[/quote.)Eseun pupo baba.Aku odun yi,emi wa ase pupo re lase eledumare.Yio ma ju yin se
Re: Ogun Awon Bàba Wa by orunmila76(m): 10:07am On Jan 04, 2016
Oogun Eyonu to daju

Eyin adiye sise kan, iyo die.aa da iyo yen sinu plate ,waa te Odu iwori meji si,waa fi eyin adiye naa lee Lori, waa gbe sinu orun di 12pm,waa lo gbe kuro ninu orun by 12pm,waa Bo ara e si ihoho ,waa gbadura,waa Bo eyin naa wa fi kan iyo naa,waa je eyin naa lodidi. Waa da iyo naa sinu omi fun wiwe.

4 Likes 1 Share

Re: Ogun Awon Bàba Wa by ayokomi1010(m): 6:36am On Jan 06, 2016
E karo gbogbo ile, A de ku aseku odun,odun a yabo fun wa o,Amin ase edumare, E jo ohun ti o je keri owo mi lori ikanni lati bi ojo meta nipe moni adua kan ti mo mase ni ipari odun si odun titun ohun lo fa,sugbon moti de pada bayi,ati pe se ogberi lo po lori ikanni yi ni tori enikan pere ni mori ti o sese fi Ogun ti e si ori ikanni yi lehin mi,se bi ani kajo yara wa logbon ni,enikeni lo le fi ogun si ori ikanni yi,sati je olododo,olodunmare abawa se o

1 Like 1 Share

Re: Ogun Awon Bàba Wa by ayokomi1010(m): 6:56am On Jan 06, 2016
OGUN EYONU TI A MALO LO SI ODE TAFI GBA IYIN NI BE
ao fi epo pupa te ejiogbe si atelewo alafia,ao tun fi omi na te pelu iyo isebe,ao wa pe ohun yi si ao wa la,ao fi owo iyoku sa ori,kama lo sode na ao gba iyin nibe, ohun re:amo roro loruko ti won pe iwo epo,amayegun loruko ti won pe iwo omi,amuludun loruko ti won pe iwo iyo,omi kiti laye o,ejiogbe kiti lawujo ifa,ki emi lagbaja omo lagbaja gba iyin nibi gbogbo loni o.
ejiogbe
! !
! !
! !
! !
ogun yi dara gan ni o asegbayin la o ma se o ni ojojumo aye wa ao ni te lase edunmare

2 Likes

Re: Ogun Awon Bàba Wa by ayokomi1010(m): 7:00am On Jan 06, 2016
OGUN EYONU FUN KI WON MA FERAN WA
ao toju ori ti afise obe,ao wa pa eje ako alangba kan le lori,ao po papo,ao ma fira ori idodo wa,o daju

4 Likes

Re: Ogun Awon Bàba Wa by ayokomi1010(m): 7:34am On Jan 08, 2016
OGUN FUN OBINRIN TI OKO RE KORIRA
ao toju eyele kan ao pa eje re sinu Oyin ao ropo ki Obinrin mafi pa oju ara re ti won bafe Joni ajoseopo pelu oko re

3 Likes 1 Share

Re: Ogun Awon Bàba Wa by ALIUDAVID: 9:56pm On Jan 11, 2016
EYONU AWON AGBA ATI APAMOWO OWO..
Ikoide meta,
Alanbere meta,
Odidin atare meta,
Ao jo won po, ao fi sin gbere yii orun owo wa mejeeji, ao po eyi ti o ku mo ose dudu ao ma fi we...

OGUN ATUDE TODAJU...
Ewe tude,
Egbo tude,
Odindin atare,
Ao jo po, ao lo kuna dada ao ma fi epo pupa lo.

Iba eyin agbagba iba eyin to laye..

3 Likes

Re: Ogun Awon Bàba Wa by ADEWALE7777: 12:29am On Jan 12, 2016
Eku ise takuntakun lori ikanni yii oo...eledua a tunbo ma fun yin se e jowo e fi ogun oko lile si ori ikani yii fun wa...e jowo e ran mi lowo baba
Re: Ogun Awon Bàba Wa by ALIUDAVID: 8:40am On Jan 12, 2016
ayokomi1010:
OGUN OSOLE OWO TO MA SISE KIAKIA
odidi ejo kan,kibase gbigbe tabi tutu,Awo lili tolori,ipe ore 21,odidi atare kan, ao jo po,ao mafi fo eko tutu Mu,ninu omori Igba ti koridi joko.odaju saka lase olodunmare
'..
baba se osole yii ko le pawa lara tabi omo wa tabi ebi wa, se ko de tuni ewo... ese ise se agbewa. igba eyin agbagba.

2 Likes

Re: Ogun Awon Bàba Wa by hibee4uall(m): 12:35am On Jan 15, 2016
ayokomi1010:
OSOLE OWO NLA
ao toju odidi okete kan ,opolopo ewe ewuro,tagiri odidi kan,Gbogbo owo tane,odidi atare kan,ao jo po ,ao mafi eyin adie ibile je lekan lojumo

Iba agba o, baba ewe a maa je oo
edakun se ao se eyin yen ni tabi ao fi din ebu yen.
Edakun e fun wa ni atude to daju.

1 Like

Re: Ogun Awon Bàba Wa by ayokomi1010(m): 4:04pm On Jan 18, 2016
IYONU ASINA EBE AWON AGBA ATUDE
Ao toju abo adiie olopipi,totobi ,ao wa wa opolopo imi gbigbe,ao gun ninu ile ni ihoho,lai ni si ohunkankan Lara wa,ao ta epo pupa yipo Odo ti a fi gun,ao si ma ta epo pupa diedie si inu re bi ase gun,titi ao fi gun kunna dada,ao wa po mo opolopo ose,ako sinu ikoko tuntun,ao mawe ni ago mejila si ago kan oru,kankan titun kokan ni ojo kokan,o daju.

2 Likes

Re: Ogun Awon Bàba Wa by Baba2015: 7:14pm On Jan 18, 2016
esun baba ooo

bawo ni ase leri afan awon iwe yin ni offa kwara state
Re: Ogun Awon Bàba Wa by hibee4uall(m): 8:04am On Jan 20, 2016
ayokomi1010:
OGUN OSOLE YAN
ao ma bu diedie la o mawa se eyin adie ibile kan lojumo,ti a ba tise eyin tojina tan ao bo epo re,ao mawa Fi eyin yan ba etu-ogun tajo yan je,be lase malo o

awon to laye a maa fun yin se baba.
Edakun ti eniyan ba nfi oju ko jankariwo kini eniyan lese si

1 Like 1 Share

Re: Ogun Awon Bàba Wa by ayokomi1010(m): 6:43pm On Jan 27, 2016
OSOLE OWO
Okan maalu ti ko wo omi,omudun ewe akoko 101,pati omonigedegede,epo jebo,ao lo awon ewe yi,ao ge okan maalu yan si 16,ao se pelu epo iyo,ati ata ijosi,ti o ba tutu,ao da sinu Awo funfun,ao wo aso to dara,ao joko si aye to dara,ao pe Ohun re si,ao wa je obe na,
Ohunre:- igbe nla ni eran nla ke,e ma GBE owo nla wa fun mi,enikan kiridi omonigedegede o,ki e wa Fi owo nla bemi nise loni. ao ma je obe na diedie fun ojo merin tabi marun,osise gan ni o

2 Likes

Re: Ogun Awon Bàba Wa by ojukoro: 8:39pm On Jan 27, 2016
Ogun Isoye.Ewe oniyemiye,eye awoko,iwe newspaper ti ko ni aworan pupo, Igbo die, ao jo po, ao ma bu diedie si oyin igan.lila ni idaji.o da gaaaaaaa

2 Likes 1 Share

Re: Ogun Awon Bàba Wa by Sobandemojisola: 1:04pm On Jan 30, 2016
E
Re: Ogun Awon Bàba Wa by ALIUDAVID: 10:05pm On Feb 01, 2016
Ekale gbogbo ile ejo eni ti o ba ni ogun arobi todaju ko ju sita fun afani gbogbo wa... Iba agbagba iba eyin to laye..
Re: Ogun Awon Bàba Wa by admolfemx(m): 8:44am On Feb 14, 2016
ayokomi1010:
OGUN IWOSAN AYE
ewe ela,ewe alupayida odidi atare kan, ao jo po ao da sinu omori isaasun ao wa ko oruka irin si,ao wa da epo pupa si ao ro po, ao wa fa Ogun yan si enu akuko adie,ni emeta,ao ma fi oruka ni si lenu ni okokan yio ma gbemi,ti o bawa di OJO keje ao pa adie na,ao lainure ao Ba awon oruka na,ao ko ao ma fun eniti Asian ba nse yio fi bowo re,aisan re yio San ni OJO na ase eledunmare ni,iba eyin agba o aiye mojuba o,mowole mo pa igbunmo o,mofori bale fun gbogbo ajunilo.
Baba kie pe funwa ho, akoko iberemi niwipe ki ara alaisan na batiya tan se alegba orukana kuro lowore,elekeji adiye ohun se aleje abi ama junu ni, iberemi keta nipe e jo baba iru ogun woni alelo fun inurirun,tabi ki inu makanyan tabi ki inu eniyan ma gbona fun okunrin,e se pupo sir.

1 Like

Re: Ogun Awon Bàba Wa by marv006: 1:26am On Feb 21, 2016
ayokomi1010:
OGUN EBE AWON AGBA
obi pupa kan,funfun kan,ewe ata ijosi,ao gun Mo ose ao mawe.
(²) igbin kan,odu ori ewe ahunekun,epo obo,ao gun dada ao fi ose po ao ko sinu aso funfun,wiwe ni odaju

Iba Eyin agba o. Se ao fi aso funfun ti a ko ose ko si oke ni, abi a le fi si ibi to ba wuwa.
Re: Ogun Awon Bàba Wa by 08101646045atwp(m): 2:20pm On Feb 24, 2016
ago'onile'o, fun eyin ti enbere ibeere nipa osu, tabi ti nta nso'oye,
opolopo ntaso koseyin akose jaye, dida ara eni mo, iwadi nipa eto igbe aye wa, boba wa laye
bi okoba da arare mo inira amawa ni igba kokan, tojepe bi oba se oogun gan
koni sise, sugbon aje, oso, emere lama ndi lelori, bi akose jaye ba ndani laamun
bi eyi tojepe eyan si aye wa ni, tori bore waju pabo ni, bore yin pabo ni, atotun atosi bi alai monse ni
bi oro bari bai, owo Ori lati nbeere, tori ori eni lawure eni, ogun loni ojo iponju
kafola fori tolojo gbogbo. fun iwo ti obafe lati wo akose jaye re onilati fi ojo ibi re ranse. ajuwase'o

1 Like

(1) (2) (3) (4) (5) (6) (7) (8) (9) (Reply)

Meet The Most Beautiful People On Earth- The Fulanis / Post Pictures Of Traditional Weddings. / If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here!

(Go Up)

Sections: politics (1) business autos (1) jobs (1) career education (1) romance computers phones travel sports fashion health
religion celebs tv-movies music-radio literature webmasters programming techmarket

Links: (1) (2) (3) (4) (5) (6) (7) (8) (9) (10)

Nairaland - Copyright © 2005 - 2024 Oluwaseun Osewa. All rights reserved. See How To Advertise. 41
Disclaimer: Every Nairaland member is solely responsible for anything that he/she posts or uploads on Nairaland.