Welcome, Guest: Register On Nairaland / LOGIN! / Trending / Recent / New
Stats: 3,161,441 members, 7,846,804 topics. Date: Saturday, 01 June 2024 at 12:53 AM

If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! - Culture (107) - Nairaland

Nairaland Forum / Nairaland / General / Culture / If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! (377209 Views)

If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here. Everybody Is Invited! / If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! / Do You Speak Yoruba? (2) (3) (4)

(1) (2) (3) ... (104) (105) (106) (107) (108) (109) (110) ... (167) (Go Down)

Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by mishoo(m): 2:46pm On Aug 23, 2007
SUGBON BO SE YE KI O RI NI

REMI RERE MI DOREDO
REMI RERE MI DOREDO
REMI DODODODO
MI REMI DO MIMI
REMI RERE MI DOREDO
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 3:07pm On Aug 23, 2007
ayanjide:

RICHY, omo ogbomosho gan ni mo je ni oyo st8
ise ilu lilu si ni ise awon baba nlaa mi
sugbon ai f'oju f'okan si lo je ko yi mi
legbiri. ki olorun ki o ran mi lowo

Ogbomoso, ajilete, ogbomojugun
omo oreposuyi
nibi won gbe n jeka ki won to mu eko yangan.

Ara e lara e , okun sokoto. Ko ti pe ju fun o, wa woroko se ada ki o je ki oruko re ba ise owo re lo.


Mishoo, mi o mo bi o se n pe ami yen jade , sugbon ti o ba je wipe bi gongo yio se pee jade ni, be ni ami ti mo yan le lori yio se ri lowo onilu, se iwadi re daadaa.
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by mishoo(m): 3:12pm On Aug 23, 2007
richylaw:

Mishoo, mi o mo bi o se n pe ami yen jade , sugbon ti o ba je wipe bi gongo yio se pee jade ni, be ni ami ti mo yan le lori yio se ri lowo onilu, se iwadi re daadaa.

ENU AGBA NI OBI TI N DUN "HAUN" . Mo ti gbo, mo si gba pelu !!
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by tafari(m): 3:31pm On Aug 23, 2007
Baale, Mishoo ati gbogbo ilu, mo ki yin o.
se ariya nlo ni yerewu
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by mishoo(m): 3:36pm On Aug 23, 2007
Tafari, se daada lo de. Kaabo !!
Se oko o je epo oo !!
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by tafari(m): 3:40pm On Aug 23, 2007
Mishoo, mo wa pa o! bawo ni ise? iyawo ati omo nko?
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 3:49pm On Aug 23, 2007
Alagba Tafari, e kaa bo si ori eto yi.
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by ayanjide(m): 3:54pm On Aug 23, 2007
tafari, kaabo o
oode o daa bi

richy richy, o see mo dupe
kee pe baba o
nje o lee ran mi lowo pelu
oriki ILE IFE
MO NI LO O RE FUN KANKAN NI KANMO N KOBO
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by tafari(m): 3:56pm On Aug 23, 2007
Baale, ori idobale ni mo wa o? se ara o le bi? awon olori ni aafin nko?
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by mishoo(m): 4:15pm On Aug 23, 2007
Baale n reju lowo !!

grin grin grin
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by ayanjide(m): 4:36pm On Aug 23, 2007
ENU AGBA NI OBI TI N DUN "HAUN" . Mo ti gbo, mo si gba pelu !!

iru owe ti o fee pa yi pin si ona meji
ENU AGBA NI OBI TI N GBO
tabi
ENU ONI KAN LA A TI N GBO PON-UN

misho darijimi to ba dabi ayonuso o
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by mishoo(m): 4:54pm On Aug 23, 2007
Ayanjide, owe ti mo fe pa na ni mo pa. Omode o le mo obi je to awon agba ti won ti pe ni idi obi jije. NMitori na ni owe yi.

Enu agba ni obi ti n dun 'haun'.
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 4:59pm On Aug 23, 2007
O se o jare, lotito ni mo n re ju, even though it's ironical , you can imagine what it may look like working with this  oyinbos

Oriki Olufe niyi ni soki, o gun gbonanagbonana sugbon jeki ki a mu ni iwonba.

Ife o daye, ibi oju ti n mo wa
akoraye akeji omo
oju mi yeso, ojurabesa
A i duro ki won n'Ife Oni
bi o ba duro ki won nife ooni , eru ni baba won n mu ni se
a i bere kin won n'ife lembebe
bi o ba bere ki won n'ife lembebe ebo ni baba won n fini se
Bi mo ba tori oni keke ku, e pe ku arewa lopogo
bi mo ba tori onisomboro ku , e pe ku arewa lo pogo
Emi o ni tori oni perense ku , abila logido
erukeru abi lala lenu
aso funfun ni mu le yin wu mi duro si
Ori a fa kodoro nii  mule baba won su mi loo.


kii dun po , soki lobe oge grin
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by mishoo(m): 5:16pm On Aug 23, 2007
E ku ogbon, e ku laakaye !!
A bu di ni todo, Eni kan i bu omi ko loju, enikan i bu osa ko lami. Ogbon yin o ni gbe oo!!
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 5:23pm On Aug 23, 2007
Ase o, opolo ti e na o ni joba - sterile ( put mi:do on it)
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by mishoo(m): 6:01pm On Aug 23, 2007
Ase o. Opolo tire naa (k)o ni jobaa (without iparoje)

Dore re. rerere dore mido do mi midomi
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by ayanjide(m): 6:03pm On Aug 23, 2007
richy, o see pupo, mo gbadun oriki naa
sugbon mo ni idojuko die ninu itumo
awon oro die ninu e
awon oro bii :

AKORAYE AKEJI OMO-1st to see d world, d 1 dat second a child

OJU MI YESO, OJU RABESA- beauty adorns my face, my face ran away from(avoids)knife

LEMBEBE- wots d meanin

BI O BA TORI ONI KEKE KU E PE KU AREWA LO POGO- if i die cos of a bicycle owner, say it is d death of a beautiful 1 dat kills GLORY

PERENSE- wots d meanin

e ma ni wahala mi po o , e o ko wa je pe, e o ri un amufiboju ati amusagba
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by lalaboi(m): 7:04pm On Aug 23, 2007
talo wa nile?
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 7:30pm On Aug 23, 2007
ayanjide:

richy, o see pupo, mo gbadun oriki naa
sugbon mo ni idojuko die ninu itumo
awon oro die ninu e
awon oro bii :

AKORAYE AKEJI OMO-1st to see d world, d 1 that second a child

OJU MI YESO, OJU RABESA- beauty adorns my face, my face ran away from(avoids)knife

LEMBEBE- wots d meanin ASODUN EDE NI LEMBEBE JE LATI SE ATENUMO IPO TI IFE DURO SI LAARIN AWON ILU YORUBA TI O KU
BI O BA TORI ONI KEKE KU E PE KU AREWA LO POGO- if i die because of a bicycle owner, say it is d death of a beautiful 1 that kills GLORY. THIS IS KEKE (ami:is 'mimi')and not 'keke'-bicycle. KEKE IS REGARDED AS ONE OF THE MOST BEAUTIFYING FACIAL ADORNMENT ( SCARIFICATION!) OTHERWISE KNOWN AS TRIBAL MARK. NOTE THAT SOMBORO IS ALSO ANOTHER TYPE.THIS ARE TYPICAL OF OMO OLUFE.

Yoruba pa owe: Tita riro laa kola , to ba doju tan a di oge.
it is believed that tribal marks makes you more beautiful grin

PERENSE- wots d meanin[b]. PERENSE IS A FACIAL SCARIFICATION USED AS MARKS ON SLAVES[/b]

e ma ni wahala mi po o , e o ko wa je pe, e o ri un amufiboju ati amusagba

The first two phrases are right by your translation

[s]if you truely need it , give me your number , I will call you and recite it for you.[/s]
ODUA A GBE WA O
Ko ju be lo.
IRE
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by ayanjide(m): 7:21am On Aug 24, 2007
ojumo oni mo, ojo ayo lo mo emi
se alaafia ni lagboole yi
mo f'ope f'eledumare fun anfaani
ojo tuntun ti o fi jinki aye mi loni

se mo ba eeyan ninu abule yi

Richy, o see pupo
mo rii bi anfani nla rapata lati gbo OHUN ENU
re, nitori idi eyi, nko nii kuna lati fun o ni nomba
gegele isoro alagbekaa mi
laipe yoo kan o lara
O SEE FUN EKO TO MOYANLORI
ATI ANFAANI TI KO SEE F'OWORA
IPO AGBA LA N BAGBA
AGBA KAN KII SE LANGBA LANGBA
AGBAA RE O NII DI YEPERE.
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by sweetberry(f): 7:28am On Aug 24, 2007
e ku ise o eyin omo yoruba
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by mashaun(m): 7:37am On Aug 24, 2007
Taa gan ni Baale ladugbo yii,se o da oluware loju pe ohun to baale je.se baale naa kiise eko tabi eegun.ki a to le fi yan joye nilu yii, onitohun gbodo we ko yan kainkain,ani koda nito.
ABI mo it wi (OYO ohun IBADAN lolede o)
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by replenish(f): 9:40am On Aug 24, 2007
Abi o, emi na ti nwo wipe ta lo f'oba je, ti eyan kan awa ma pe ara re ni baale.

emi kan fe mo eni to fi je baale ati wipe kini ikan to gbe se pato.

mo ki gbogbo omo oduduwa, eku miliki esi ku yotomi.

o'dua a gbe wa o

ase wa ni t'ireke
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 9:45am On Aug 24, 2007
Ayanjide mo ti ri owo re, a o soro laipe. Ki Oba Oke ki o ma gba opolo ati ohun lenu eni kooka wa.
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by mishoo(m): 10:00am On Aug 24, 2007
E ku ikale lagbala ooo. Ara o le bi??
Adupe fun ojo eti omiran. A ye wa kale oo
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 10:26am On Aug 24, 2007
IBEERE MEJE PERE!

1. Nibo ni akere wa nigba ti opolo n gba ara re lowo elegusi?
2. Nibo ni eera wa nigba ti ikan n mo ile nla, to tun hu iye lapa di esunsun?
3. Okin joba eye, Ogongo je baba eye, Owiwi je amoye lawujo eye, awoko joba orin nipekun oke lawujo abiye fo. Nibo ni ega ati eliri wa nigba ti
   gbogbo awon wonyi  n yan ase laayo?
4. Nigba ti olokun n se ogun okiki nibo ni gbogbo awon odo pepepe wa?
5. Nibo ni iran okobo wa , nibi olomokunrin ti n ku aya e mole lori eni?
6. Nibo ni akiriboto lo lojo gbogbo alabe aye  n fi ti won se omo?
7. Yerepe gbara e la loko, gbogbo igi oko wa n pa ariwo enu, e ba mi bere lowo won wipe nibo ni won wa , nigba ti ewe ajonilara n sebo igbara la?


Ewuro ti dagba igi , eso wewe igi kerejee e faaye owo sile
Tafojudi ko, tete sonbo si ko.
Bo nigba ba se pe igba re , laa ba pe.
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by replenish(f): 10:54am On Aug 24, 2007
ta wa gan ni ewuro, ta l'eso weewe

ati pe awon wo ni onigba.

idahun si ibere mi ni mo fe o jare
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 11:07am On Aug 24, 2007
replenish:

ta wa gan ni ewuro, ta l'eso weewe

ati pe awon wo ni onigba.

idahun si ibere mi ni mo fe o jare

Erofo ni oro, bi a ba fi papa lu a ma ta ba ni, eni oro ta ba ni ko fi oye gbe, ki o si ye ara re wo.
Bi Oba oke se n be , ti orun o si jabo, emi RICHYLAW NI BAALE OKUN YORUBA YII
Niwon igba ti emi ko si yaju si ara iwaju o di dandan ko ju mi se.
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by replenish(f): 12:02pm On Aug 24, 2007
oro peesi je, oro di e
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by mishoo(m): 12:06pm On Aug 24, 2007
Replenish, kaabo si abule yi.
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by replenish(f): 1:15pm On Aug 24, 2007
o seun jare mishoo

se dada lo wa, se alafia ni mo ba e.
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by lalaboi(m): 1:34pm On Aug 24, 2007
ki enikan ko orin fun wa na

(1) (2) (3) ... (104) (105) (106) (107) (108) (109) (110) ... (167)

Pictures Of Nigeria Traditional Attire / Igbo Names & Their Meanings / Igbo Kwenu ! Kwenu Kwezo Nu ! Join Us If You Proud To Be An Igbo Guy/lady

(Go Up)

Sections: politics (1) business autos (1) jobs (1) career education (1) romance computers phones travel sports fashion health
religion celebs tv-movies music-radio literature webmasters programming techmarket

Links: (1) (2) (3) (4) (5) (6) (7) (8) (9) (10)

Nairaland - Copyright © 2005 - 2024 Oluwaseun Osewa. All rights reserved. See How To Advertise. 35
Disclaimer: Every Nairaland member is solely responsible for anything that he/she posts or uploads on Nairaland.