Welcome, Guest: Register On Nairaland / LOGIN! / Trending / Recent / New
Stats: 3,162,693 members, 7,851,376 topics. Date: Wednesday, 05 June 2024 at 06:03 PM

If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! - Culture (124) - Nairaland

Nairaland Forum / Nairaland / General / Culture / If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! (377442 Views)

If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here. Everybody Is Invited! / If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! / Do You Speak Yoruba? (2) (3) (4)

(1) (2) (3) ... (121) (122) (123) (124) (125) (126) (127) ... (167) (Go Down)

Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by DrFerlie(m): 6:57pm On Feb 18, 2008
Baale Richylaw,

Ki ade pe lori, ki bata pe ni ese. igba odun, bi odun kan ni o .

Inu mi dun ti mo bayin pade ni aafin ni oni.

E ku ise ilu. oodua a gbe gbogbo wa ooooooooo. cheesy cheesy
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by OpeLovely(f): 11:05am On Feb 19, 2008
Gbogbo eyan mi, iyan ra o!
Eku joko o!
Eku osise o!
Ese jeje o!

Ke ma soro kiso lori Komputer. Ka je ka se nkan to da.
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 1:40pm On Feb 19, 2008
Ojumo to mo wa loni , ojumo owo ni o
Ojumo alaafia ati aiku baale oro
Bi ojo ba yo a kari aye, alakanle bayi ni ti osumare
enikan kii fi owo b'oju ojo ko ma yo
enikan kii f'owo b'ogo orun ko ma ran
Irawo gbogbo wa o ni ku o
Ki a ma ri ba ti se o
ki a ma rona gbegba o
Lola awon onile a o ni d'obu o
Idere loni ki awon adeni ma le ri wa de mo le o
Okakatirika ko ni je ki aye ka wa ribiti o
Akun sinu ni tegbin, a kun sikun ni teera
Eti ayan ki gbo igbe , eti eera ki gbo ibosi
Awa la o ma leke ota wa o. ASE

Libational Prayers from the Palace of Baale of Yoruba Thread
Richylaw
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 1:52pm On Feb 19, 2008
Dr Ferlie, se oju ojo so ire loni o,okiki re o ni di ibaje o
Segoye, aworerin eledumare, aridinu loju iyawo, o o ni pose, o ni fojusunkun o
Tafari nko, e ba mi so fun wipe o jina simi o, ki lode?  Agbala owo re, ko ni hu koriko aini ati osi o
Ayanjide, ore Oba, ahere ni kehin oko, akitan ni yio kehin ile, iwo lo ma bori gbogbo ota ati abinu eni o
Desorlah, aya oloye, e ku itoju baale o.Isale lowo atoroje n wa, o ma fun ni ni o, o ni i toro laye o
Disguy, bi opolo se n yan niwaju elegusi ni o ma yan fanda loju awon elenini eniyan
Minute nko? Iyalode Ikamefa ni bo lo wa?
mukina2,haywhy,nana olufidu, nite angel,omoge, omogenaija, thiefofheart, debosky
gbogbo olori ire ti n be n'ilu yi e ba mi gbaruku ti akitiyan kii Kaaro-o-jiire o le gboro si,

Odua a gbe wa o

Baale Richylaw
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by metodman(m): 2:03pm On Feb 19, 2008
se thredi yi ti ku ni??
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 3:45pm On Feb 19, 2008
Ko ku rara, oke o hun ni ko je ki a ri ti ibi, a o se odun ilu wa laipe , iwo yio si ri gbogbo awon eni atijo ni ori okun yi!
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by Nobody: 12:30pm On Feb 20, 2008
Ekaasan gbogbo omo yoruba lori thread yi. she e wapa?
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by metodman(m): 1:41pm On Feb 20, 2008
a wapa, iwon nko? se gbo gbo nkan lo si dara dara ?
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by Ferlie1(m): 1:42pm On Feb 20, 2008
lamidebaby:

Ekaasan gbogbo omo yoruba lori thread yi. she e wapa?

arabinrin lamide, e kaabo si ilu wa yi o. inu mi dun pupo lati ri yin ni ibi yi.
se alaafia ni awon molebi wa o? cheesy
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by Fileki(f): 4:13pm On Feb 20, 2008
Baale, emi ki se oju titun ni ilu yi o. o kan ti pe die ti mo ti de ori okun yi o, o si ye ki e toro gafaara fun afoju di kekere yi. amon sa ka bi o ko si. se alafia le wa, se ara le. e jowo mo fe mon awon olori baale ilu wa yi, nitori, apon le ko si fun Baale ti ko ni olori. E ma si mi gbo o, emi ko ni ife si ipo olori o, sugbon mo fe mon pupo nipa ilu wa yi. gege bi omo ilu wa tooto, kara o le o.

e ma gbagbe mo nife si oye ni ilu wa yi o, oye *iyalode* ni mo fe je.
o digba.
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by mishooo(m): 4:45pm On Feb 20, 2008
Se okun yi si wa laaye??
O ma se ooo. sad sad sad
Agba o si mo, ilu baje. Baale ile ku, ile dahoro.
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by DrFerlie(m): 5:42pm On Feb 20, 2008
Fileki:

Baale, emi ki se oju titun ni ilu yi o. o kan ti pe die ti mo ti de ori okun yi o, o si ye ki e toro gafaara fun afoju di kekere yi. amon sa ka bi o ko si. se alafia le wa, se ara le. e jowo mo fe mon awon olori baale ilu wa yi, nitori, apon le ko si fun Baale ti ko ni olori. E ma si mi gbo o, emi ko ni ife si ipo olori o, sugbon mo fe mon pupo nipa ilu wa yi. gege bi omo ilu wa tooto, kara o le o.

e ma gbagbe mo nife si oye ni ilu wa yi o, oye *iyalode* ni mo fe je.
o digba.

gege bi ikan pataki lara awon ara ilu yii, mo pa ni ase ki arabinrin fileki di olori baale richylaw cool

arabinrin fileki, baale ti gbe ese le e o. grin grin grin
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by DrFerlie(m): 5:43pm On Feb 20, 2008
mishooo:

Se okun yi si wa laaye??
O ma se ooo. sad sad sad
Agba o si mo, ilu baje. Baale ile ku, ile dahoro.

arakunrin mishooo, e kaabo si ilu wa. se daadaa ni e de?
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 6:19pm On Feb 20, 2008
To o bi a se pe a waye ri na laa ri,

Fileki,  sebi omode gbon agba gbon la fi da ile ife, ogbon ologbon ni ko si je ki a pe agba ni were. Ko si afojudi ninu oro yi rara. Mo tooro aforiji fun aifiyesi ati afoju foda ipo re laarin ilu yi o. Mo ki o ku abo ni ekan si o.

Asiwaju Dr Ferlie , bi o ba  wo saakun oro yi daradara, Fileki kan beere awon Olori ni, ko so wipe ohun fe di okan, a mo sa o fe je oye iyalode,  Ikamefa si n be laye ara re, a o le si lese pada.
Oye kan soso ti o wa nile nisisiyi fun obinrin ni , ' Yeye Oge Amogbonjoye of Nairaland' iyen tun nko.

Fileeki, won ni ohun ti n dun ni ni i po loro eni, okan mi n so fun mi wipe aafin mi n wu o gbe, sugbon o lee joye ilu  ki o tun di olori o, ' a pe laye , oju mi o ni ribi, okan loo fowo mu ninu re' -iyen owe awon agba.

Awon igbimo ilu n fun o laye lati lo ro wo daadaa ki o si fi owo di ikan mu ninu mejeeji- sugbon laisi ani-ani, Oba ti gbese le o wayi titi ti awon igbimo yio fi pari ipade lori re, Mukina2 ti gba iyawo na nu. Oloye Ferlie e ba wa pari eto bi yio se de afin ni ojo-ro
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by DrFerlie(m): 6:56pm On Feb 20, 2008
richylaw:

To o bi a se pe a waye ri na laa ri,

Fileki, sebi omode gbon agba gbon la fi da ile ife, ogbon ologbon ni ko si je ki a pe agba ni were. Ko si afojudi ninu oro yi rara. Mo tooro aforiji fun aifiyesi ati afoju foda ipo re laarin ilu yi o. Mo ki o ku abo ni ekan si o.

Asiwaju Dr Ferlie , bi o ba wo saakun oro yi daradara, Fileki kan beere awon Olori ni, ko so wipe ohun fe di okan, a mo sa o fe je oye iyalode, Ikamefa si n be laye ara re, a o le si lese pada.
Oye kan soso ti o wa nile nisisiyi fun obinrin ni , ' Yeye Oge Amogbonjoye of Nairaland' iyen tun nko.

Fileeki, won ni ohun ti n dun ni ni i po loro eni, okan mi n so fun mi wipe aafin mi n wu o gbe, sugbon o lee joye ilu ki o tun di olori o, ' a pe laye , oju mi o ni ribi, okan loo fowo mu ninu re' -iyen owe awon agba.

Awon igbimo ilu n fun o laye lati lo ro wo daadaa ki o si fi owo di ikan mu ninu mejeeji- sugbon laisi ani-ani, Oba ti gbese le o wayi titi ti awon igbimo yio fi pari ipade lori re, Mukina2 ti gba iyawo na nu. Oloye Ferlie e ba wa pari eto bi yio se de afin ni ojo-ro

Baale,

Ki ade pe lori oooooooooooooooooo.

Gege bi eti momi, iti ogede lasan ni oro fileki, koda gbogbo eto tito lati so di olori yin.
Mo ti se ipade pelu awon obi(parent) fileki, won si ti faa towo tese le yin lowo.

Olori Fileki, okunrin abiro, obirin abiye o, igba yin atuwa lara ninu ilu yii. grin grin
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by Fileki(f): 8:04pm On Feb 20, 2008
t'oba l'ase, t'aa ni mi lati so wipe n ko fe ipo to ni iye l'ori bii ti ipo Olori?
e se o, ilu yi ko ni b'aje. inu mi dungan an ni. e je ki n mon awon olori ti mo ba l'aafin

k'oba pe
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by Nobody: 8:59am On Feb 21, 2008
F erlie:

arabinrin lamide, e kaabo si ilu wa yi o. inu mi dun pupo lati ri yin ni ibi yi.
se alaafia ni awon molebi wa o? cheesy
Alaafia ni o. mo fe mo, shey eyin ni afobaje ni ilu yi ni abi oba gangan. Then shey ipo Erelu shi wa available? kide ni prerequisite (sorry, mii mo yoruba e) ati ni ipo yi?
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by DrFerlie(m): 9:51am On Feb 21, 2008
lamidebaby:

Alaafia ni o. mo fe mo, shey eyin ni afobaje ni ilu yi ni abi oba gangan. Then shey ipo Erelu shi wa available? kide ni prerequisite (sorry, mii mo yoruba e) ati ni ipo yi?

omidan lamide, a ku ojumo o. ASIWAJU ilu yoruba lasan ni mi o. Baale richylaw ni oba ilu wa.
sugbon ma ba baale soro nipa oro oye yin.

Si Baale, Omidan lamide nife si oye erelu ilu wa, bawo ni e se ri si

Iwadi nipa omidan lamide fiye wa wipe eniyan pataki ati olooto ni won.
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 11:36am On Feb 21, 2008
Fileeki, O ku abo si afin o,

Arude arude
aponjinijini a le nu ma ro
loruko ti a npe ibaka
A le fonfo dori omi mu
ni oruko ti a npe iwo oju oro
Idandan awo molubi
E ba mi se Olori Fileeki ni majomajo o
E ba mi gba si afin iwase ni belejebeleje
Omo were laa ba lagbo ogede
Igba ewe lewe iyeye o
Inu a gbe oyun dani o
E hin a gbomo pon
A logbo n'igba n lo ope
ASE

singing: Ta lo so pe ru eyi o ye ni/2x
Fileeki d'aya Kabiesi
Ta lo so pe ru eyi o ye ni.

Arabinrin Lamide, inu mi dun si ilosiwaju ilu wa yi ti o je o loogun, o o ni pare maye lara o. Iwaju bayi lopa ebiti re yi o ma re si.
Oye Erelu je oye ti o lagbara pupo, orisirisi idanwo ni a si ma n gbeyewo lara awon ti o ba to si. Mo si nu , mo si ikun awo enu ni. Nje o le yanana ohun ti o ro wipe awon erelu ma n je laarin ilu. Ki tile ni ise won, Nje eyin ti ni oko bi?, omo melo ni e ti bii
Asiwaju Ferlie , E je ki fileeki fun yin ni idahun si ibeere wonwonyi, ki a le jiroro lori re ni tanmo-oko
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by Fileki(f): 5:29pm On Feb 21, 2008
smiley Kaabiesi o! E seun, mo dupe k'e pe. Olowo ori mi, e dakun mo fe mon awon olori ti mo ba l'aafin ki n le ma ye won si bi o se to.
mo fe mu amoran wa, wi pe ki arabinrin Lamide so fun wa awon iwa amuye ti Erelu gbodo ni. . , Dr Felie e seun ana, Kabiesi ounje yin ti se tan, k'eepe o
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by DrFerlie(m): 5:50pm On Feb 21, 2008
Olori Fileki, baale nko? se daadaa ni o. Niwoyi amodun ibeta ni oooo. Ase grin
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by Fileki(f): 5:59pm On Feb 21, 2008
ase o
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 6:27pm On Feb 21, 2008
E gba mi o, Baale ti ni bi omo to le l'aadota e tun wa n soro ibeta, n je agbara fileeki ka bayi.

Mukina2 je okan ninu awon Olori, sugbon awon marun toku ko yoju si awon ara ilu. Se eyin na kuku mo wipe iyawo ti oko feran loko lo n gbe.
Ko da Mukina2 gan ko fi igba kan gbe aafin, iya n yo wa lo n se, Nitorina , Ile ni ile re o fileeki,Iwo nikan ni o wa pelu mi laafin bayi , laisi ani-ani iwo na ni olori ti yio ma ba mi se wole-wode o.
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by Fileki(f): 7:12pm On Feb 21, 2008
Kabieesi, eyi ni wipe emi nikan ni Olori l'aafin? inu mi dun fun eyi. k'epe
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by bisibaby(f): 7:19pm On Feb 21, 2008
oga fun gbogbo eyin omo yoruba yi ohhhhhhhhhh

ekan so yoruba bi pe en so egun lenu ni sha

eti e le rara. gobe ni yoruba ti e nso lenu ohhhhh

ekan fi enu pale niwaju yoruba ni sha



oodua a gbe gbogbo wa ohhhhhhhhhhhhhh


omo yoruba ronu ohh!!!!!!
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by DrFerlie(m): 8:47pm On Feb 21, 2008
bisibaby:

oga fun gbogbo eyin omo yoruba yi ohhhhhhhhhh

ekan so yoruba bi pe en so egun lenu ni sha

eti e le rara. gobe ni yoruba ti e nso lenu ohhhhh

ekan fi enu pale niwaju yoruba ni sha



oodua a gbe gbogbo wa ohhhhhhhhhhhhhh


omo yoruba ronu ohh!!!!!!

arabinrin bisi., e kaabo si ilu wa. mo ki yin ni oruko baale richylaw ati olori fileki richylaw.
ilu wa atuyin lara oooooooooooooooo.
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by Nobody: 1:10pm On Feb 22, 2008
richylaw:

Arabinrin Lamide, inu mi dun si ilosiwaju ilu wa yi ti o je o loogun, o o ni pare maye lara o. Iwaju bayi lopa ebiti re yi o ma re si.
Amin

richylaw:

Oye Erelu je oye ti o lagbara pupo, orisirisi idanwo ni a si ma n gbeyewo lara awon ti o ba to si. Mo si nu , mo si ikun awo enu ni. Nje o le yanana ohun ti o ro wipe awon erelu ma n je laarin ilu. Ki tile ni ise won
embarassed Kabiyesi o, e fiye mi.

richylaw:

Nje eyin ti ni oko bi?, omo melo ni e ti bii
Rara o, afesona nikan ni moshi ni, mio de tii bimo rara.
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by metodman(m): 2:26pm On Feb 22, 2008
TI KABIYESI BA WA PALASE KI E FIN AFESONA YIN SILE NKO? (WAT IF THE KING ORDERS YOU TO LEAVE YOUR BOYFRIEND/FIANCEE)
BABA BA LORI OHUN GBOGBO NI ABI BE KO DOKITA ?
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 3:02pm On Feb 22, 2008
metodman:

TI KABIYESI BA WA PALASE KI E FIN AFESONA YIN SILE NKO? (WAT IF THE KING ORDERS YOU TO LEAVE YOUR BOYFRIEND/FIANCEE)
BABA BA LORI OHUN GBOGBO NI ABI BE KO DOKITA ?
Agbedo , ki a ma ri, baale o tile ni fe fi ori oka ho imu o.
Gege bi orin baba Orlando

Oro ni yo so ra re/2x
E je ki Lamide lo m'oko
Oro ni yoo so rare.


Baale Richylaw ko ni lowo tabi gbe si eyin iwa irenije tabi iloni lowo gba. E sa je ki Lamide ma da bi edun ko si ma ro bi owe

Olori Fileeki, sa maa yo si mi loorun, iwo lo nigba yi , aafin laafin re. Ojuretete afin gbere oge da oko laya, ibadi aran, egbin ogbegbe adara tan ko to d'aya oba , o tun wa d'aya oba tan o tun n peleke si. Maa rin , maa yan Oko re loni le

Lamide ti o ba di owo ale ti mo ba ti pada de aafin n o fun o ni gbogbo esi si awon ibeere re, mo wa ni ipade loba loba lowo nisisiyi.
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by metodman(m): 3:06pm On Feb 22, 2008
[[color=#006600]color=#000099]Baba mo ni ki n gbo oro lenu yin ni ooooo, epele sir. Baba awa amulu dun duro o. Mo ti so fun KSA ki o ma palemo tori baba ti ni Olori, a n reti ibeta ti dokita so. BABA E MA DISAPOINTI WA OOO![/color][/color]
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by desorlah(f): 3:13pm On Feb 22, 2008
Hello! grin
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by metodman(m): 3:14pm On Feb 22, 2008
aunti desorlah, se e wapa ?

(1) (2) (3) ... (121) (122) (123) (124) (125) (126) (127) ... (167)

Pictures Of Nigeria Traditional Attire / Igbo Names & Their Meanings / Igbo Kwenu ! Kwenu Kwezo Nu ! Join Us If You Proud To Be An Igbo Guy/lady

(Go Up)

Sections: politics (1) business autos (1) jobs (1) career education (1) romance computers phones travel sports fashion health
religion celebs tv-movies music-radio literature webmasters programming techmarket

Links: (1) (2) (3) (4) (5) (6) (7) (8) (9) (10)

Nairaland - Copyright © 2005 - 2024 Oluwaseun Osewa. All rights reserved. See How To Advertise. 61
Disclaimer: Every Nairaland member is solely responsible for anything that he/she posts or uploads on Nairaland.