Welcome, Guest: Register On Nairaland / LOGIN! / Trending / Recent / New
Stats: 3,160,141 members, 7,842,281 topics. Date: Tuesday, 28 May 2024 at 04:01 AM

Ìrìnkèrindò Iṣẹ́ Wíwá Ọ̀gbẹ́ni Adébáyọ̀. - Literature - Nairaland

Nairaland Forum / Entertainment / Literature / Ìrìnkèrindò Iṣẹ́ Wíwá Ọ̀gbẹ́ni Adébáyọ̀. (240 Views)

SYNW Explains The Reasons Behind Celebrating Posthumous Birthdays Of Departed Ni / English Students, How Do You Say “shey You Dey Whine Me Ni” In Correct English? / Ewi Ni Mo Gbadun Ju Lati Ma Ko - Olujide Jacob Olúmofe (2) (3) (4)

(1) (Reply)

Ìrìnkèrindò Iṣẹ́ Wíwá Ọ̀gbẹ́ni Adébáyọ̀. by JOJUADE(m): 12:36pm On Jul 28, 2022
Àláàmù ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ mi lo jí mi ni dédé aago mẹ́fa aárọ̀ yìí. Mo sáré dìde, mo wólẹ̀ láti gbàdúrà, kíá, mo ti bọ́ sínú balùwẹ̀, gẹ́gẹ́bí ọmọ Ọkùnrin tó dùn ń wò, mo ta mọ́ra, mo gbé fáìlì kiridésíàsì mi, mo tún yẹ ara mi wò lẹ́ẹ̀kan si kí n tó bọ́ s'ójú ọ̀nà.

Mo dé ilé iṣẹ́ tí mo kọ ìwé ìwásẹ́ sí, mo kọ orúkọ mi si ibi tí àwọn tó wá se ìfọ̀rọ̀wánilẹ́niwò fún isẹ́ kọ orúkọ wọn sí. Àtẹ̀jísẹ́ ìyá mi ló kọ́kọ́ wọlé s'órí èrọ́ ìbánisọ̀rọ̀ mi bí mo se tan èrọ náà. Lẹ́yìn tí mo ka gbogbo ádùrá tí ìyá mi ṣe fún mi tan, ni mo tún rí ọ̀rọ̀ ìtùnú àti ádùrá tí olólùfẹ́ mi Àbẹ̀kẹ́ tẹ̀ ránṣẹ́ sí mi, mo rẹ́ẹ̀rin músẹ́, ọkàn mi tutù, ayọ̀ mí sì kún.

"Arákùnrin Adébáyọ̀ Adégoríọlá !!!" Akọ̀wé ilé iṣẹ́ náà ló ń pe orúkọ mi láti orí ìjòkó rẹ̀ níwájú ilé ìgbàlèjò ilé iṣẹ́ náà, "èmi re", mo dáa lóhún, "ẹ̀yin lọkàn, ẹ wọlé sí ófìsì tí ó wà ní apá òtún yín".

Ọmọ Obìnrin tí ọjọ́ orí i rẹ̀ kò ju ọdún mẹ́rìndínlógójì lọ ni mo rí tó jòkó sórí àga nínú ófìsì ọgá àgbà ilé iṣẹ́ náà, "ẹ jòkó", mo se bó ti wí. "Mo ti wo àwọn kiridésíàsì yín, mo rí pé o yege nínú èkọ́ rẹ, kódà, o pegedé, ṣùgbọ́n, iwe tí o kà ju isẹ́ tí a fẹ́ gbàyàn sí lọ", "Mo mọ̀ bẹ́ẹ̀ mà", mo dáa lóhún, "kílódé tí o wá kọ ìwé láti gba isẹ́ yìí" ?? "Kí n lè máa rí ọwọ́ mú lọ s'ẹ́nu ni Mà".

"Ọ̀rọ̀ rẹ kúkú yé mi", ọ̀gá ilé iṣẹ́ náà fèsì. "Ó da náà, hun ó fùn ń ọ ní'sẹ́ yìí tí o bá ti lè dá májẹ̀mú pé wàá ṣe kini kan fún mi", mo dáa lóhùn, "kíni kíni ọ̀hún "

© 'Kunle JONISE.

(1) (Reply)

The Circumcision (continued) / Tempting The Devil - Feather's Stories / 2 Part Of Your Book That Wows Your Reader.

(Go Up)

Sections: politics (1) business autos (1) jobs (1) career education (1) romance computers phones travel sports fashion health
religion celebs tv-movies music-radio literature webmasters programming techmarket

Links: (1) (2) (3) (4) (5) (6) (7) (8) (9) (10)

Nairaland - Copyright © 2005 - 2024 Oluwaseun Osewa. All rights reserved. See How To Advertise. 8
Disclaimer: Every Nairaland member is solely responsible for anything that he/she posts or uploads on Nairaland.