Welcome, Guest: Register On Nairaland / LOGIN! / Trending / Recent / New
Stats: 3,151,050 members, 7,810,909 topics. Date: Saturday, 27 April 2024 at 06:12 PM

Afopinna Ati Fitila - Culture - Nairaland

Nairaland Forum / Nairaland / General / Culture / Afopinna Ati Fitila (324 Views)

Afose Ati Olugbohun Todaju / Ogun Stroke Ati Diabetes / Ogun Ti Afi Ngbe Aye Ni Irorun Ati Ogun Korikosun To Gbona Gan (2) (3) (4)

(1) (Reply) (Go Down)

Afopinna Ati Fitila by absoluteSuccess: 11:07am On Oct 13, 2023
Lati ayebaye, bi eniyan ba tan fitila, fitila naa a tanna, a fi imole ina naa yi ara re ka. Eleyi ko ni yi pada lati igba de igba, titi laelae. Akii tan fitila tabi atupa ninu imole, nitori imole oorun nibaba.

Ninu okunkun lati nilo imole, laisi aroye pupo, ayé iba wa sibe ninu okunkun birimu-birimu ti itansan oorun ko ba to lati tan imole roro sinu aye bi a ti maa nri pelu oju wa ati imolara ooru ni osoosan lojo gbogbo, pataki julo nile adulawo. Boya bi Aurora lasan ni imole orun iba tije.

Sá, oromi dori 'o dori, odori fitila ati afopinna. Gbogbo wa lamo wipe lojoun ana, fitila tabi atupa lafii riran tabi rinna lookun. Amo wipe fitila, oun la fii riran oru. Sugbon ninu okunkun ati ni gbangba walia, imole kii pe ku. Nitori naa, ti a ba gbe imole sita, nibiti koti ni ku lamaa nfe gbe imole si.

A maa nfe je ki imole bosi koro. Itori ategun lase maa nse eyi. Ategun je okan ninu awon ota ti imole ni. Bee sini imole nilo ategun lati jo, nitori ti a ba to pinpin oun gbogbo ninu imo ijinle, ao ri wipe, bi a ba de imole mole, ti ko ri ategun oxygen ti an mi simu, oun naa yoo ku nikeyin.

Imole naa ni emi tire, tabi oun ti a le pe ni agbara. Oun si ni ina. Awon baba wa pe agbara naa ni ase: Ayinla omo wura ni "ase ina nina fiijo". Bi a ba kii taara, aoni, "ina omo orara, ina pupa belege, ina o moju enio nii". Benni, pupa ni ina fitila, a maa fe legelege to ba wa ni ibiti o roo lorun lopo ti kosi ni inira.

Amo, ota Ina ko mo niwon: omi, ategun ati awon oun abemi miran wa to korira ina tabi imole. Boya ke ka wipe imole maa nfawon mora nitori imole lodi si iriri won. Ninu awon oun abemi wonyi ni ati ri oun ti Yoruba npe ni afopinna.

1 Like

Re: Afopinna Ati Fitila by absoluteSuccess: 12:02pm On Oct 13, 2023
Eje ka jumo wo ewa ede Yoruba yi. Ina lo bi imole. Abi bee ko? Imole ti ko nilo ina ni awon oloyinbo npe ni "self-sufficient light" eleyi tunmo si ina to nti ikalara ara re jo. Eleyi ko nilo epo. A le ba akawe yi pade ninu bibeli mimo tabi ninu ijinle ohun enu Ifa.

Bibeli: Mose go si ibikan leba oko lati mo bi o ti seese ki ina maa jo ooko, ki ooko naa masi se jona. Kiní òún see ni kayefi, o go lati ri aridaju.

Ifa Olokun: Awon agbagba Yoruba a maa ki Ifa ni, "Ifa Olokun asorodayo, eleri ipin, omo ina j'oko ma j'erun". Ina to joko ti ko si run ko lo ara ewe lati jo rara, o kan wule ntan lara ewe oko nì ni.

Ogangan ibi ti mo nlo gan ni wipe, jijo ni ina maa njo: eke oro ti a nii lo gan ni ijo, nje bi atii jo ha ni ounkoun lati se pelu bi ina tii jo bi? Awa naa le se agbeyewo oro naa lowo arawa. Osekose, eti saa lafii gbeyawo oro. Eleyi a ranwa lowo: Sunny Omo Alade pari oro, oni:

Ikunle l'adura biwon to nwi,
Aiduro nijo, ibere nise.

Lakotan, aiduro nijo. Ai~wa ni ojukan fun igbakan laiyisepada gan-an ni ijo. Bee gan ni ina tii jo. A maa fe legelege, asi maa fi ase ara re ran ara owu to ba duro le lori lati ran, osi di igba ti ororo tabi owu to wa lara oun to duro le lori ba jò tan di eeru ki oun naa to ku.

Jíjó~ase Ina ti ina fii jo belebele.
Jíjò~rirun tabi didinku òóró ati epo ara oun ti ina bá bà lé.

Jijo tunmo si wipe oun ti a nlo maa tan ati wipe ninu Osuwon, idinku ti mba oun naa bi lilo ti kan~an. Laifi ti ewa ede se, aori wipe isewo~lo ede Yoruba ti ko dabi nkan leti wa yi kun fun ero to se regi pelu ogbon, imo ati oye. Anso eyi nitori ojo mii ojo ire. Mo nbo.

1 Like

Re: Afopinna Ati Fitila by absoluteSuccess: 9:04am On Oct 14, 2023
Taa ba wo atejade oke yi, nje ko jo wipe arojinle lo bi ege kookan silebu to so ede Yoruba ro bi? Loju temi, beeni, nko mo ti elomiran. Fun apere, sebi oro ina ati imole lanso, kini to monamona ninu eyi?

Monamona ni imole ojiji tonwa to si tun nlo, tabi to ko mona loju sanma leekan, ti ko si farahan mo. Eyi wopo lasiko ti ojo ba ngbiyanju lati ro, oun ti imo ijinle so wipe oun se okunfa eleyi ni owo eya ti irufe ategun otun ati osi to nwo ni Ofurufu fi kolu ara won.

Ti ategun otun ba ni igbara lile, ti ti osi ni igbara sodi, ti awon mejeeji ba ro pade ara won ni eseogbeji loju sanma, sapatakara ni ara maa san, arabambi a foun ninu ojo. Eni to ba ya akin le wo sanma kori bi ategun naa se ro gbanu ara won, eje ki Oluwa re o ki Eleduwa.

Imole ti o tan lasiko yi ni "agbara" ti akolu kogba otun ati osi efuufu abara meji naa bi. Lati inu ikolu igbara otun ati t'osi ni imole ojiji to di monamona naa ti wa. Onikaluku oun ti Eleduwa da ni o ni igbara to ngbe inu ara won, bi o tile wu ki won kere to. Ibaaje oun to kere ku de ori koun, ibaasi se ategun.

Oni bi atii ki monamona l'eyo, ao wipe: "monamona soju orun geru." Ema je ka gbagbe wipe monamona to s'oju orun geru yi naa ni Thomas Edison, pelu iranlowo ogbontarigi onimo ijinle sayensi ti oruko re nje Steinmetz so di ina monamona ni nkan bi ogofa odun die seyin.

Won pe eleyun ni "clandestine electric light bulb" tabi ina ti a fi pamo sinu igo fun imole lati inu elentiriki. Ajosepo wa laarin elentiriki oju orun pelu ina inu igo yi: awon ojogbon meta to mo idi eeta lori bi eleyi seese ni ogbeni Tesla, Thomas Edison ati Steinmetz.

Parakoyi onisowo ni Thomas Edison je, o si je okunrin kan to ni aseyori olokan o jokan to laami laka kaakiri gbogbo agbaye, omo bibi Ile Amerika ni. Oun mo nipa bi elentiriki se le di lilo lati orisun si ibode ti ao ti lo Ina na (AC). Sugbon eleyi ko sai ni abawon tie.

Amo Tesla mo nipa idabu elentiriki (DC). Kamaa fa oro gun, olowo lo lowo. Edison gba Tesla gege bi osise re, oyinbo p'ogbon po, won si fi se ina monamona fun gbogbo omo aye ati adarihunrun. Eba mi fi Obey die si ni ikorita yi, eje ka jumo ronu latinu isalu oro:

Ijo wo lami abo, eyin eyan mi, lowo rikisi pelu ote, tembelekun?

Iwa ika ko pe ara mi, ema danwo, iwa ika ko pe ara mi, rara ko da.

1 Like

Re: Afopinna Ati Fitila by absoluteSuccess: 8:11am On Oct 19, 2023
Igbara ti mo menu ba kiise eyi to tunmo si igbara oke tabi igbara odo ni ipinle Ondo o, oun ti mo ntunmo nibe yen ni ìgbara, "electron", gbogbo wa lani igbara to ngbara wa koja loore~koore.

Eleyi lo bi agbara. Kii se okun ni mo nso, rara. Agbara ni oun ti o ngbe ara wa, tobee ti ko soro fun okan wa lati so funwa pe oya dide fu, ki a si dide, oun to gbe wa dide gan~ni a gbe ara tabi agbara. Nje ti ko ba si agbara, se o seese ki a da ara gbe bi?

Tikobasi Agbara, kolesi Ase.
Iyen a maa je ti Ajibola Alabi.
Re: Afopinna Ati Fitila by absoluteSuccess: 7:40pm On Oct 19, 2023
Looto ni, ti ko ba si Agbara, kolesi Ase. Agbara lo maa nfi ase mule. Eni ti ko lagbara lori eni, isoro gbe pe ki oluwa re pase funni.

Yato si eyi, ti okan ba saare, botilewu ki enyan gbiyanju to, aare okan maa di agbara lowo lati ruwa soke se oun ti a feran lati se.

Nidi eyi, agbara ni isaaju, ase ni atunbotan ife, ofin tabi iyanju agbara to daju. Agbara ni Ipilese aseyori. Ti ko ba si agbara, kolesi ase.

1 Like

(1) (Reply)

Personal Forex Trainer / House Of Elvira : Designers Of African/foreign Wears & Beauty Experts / Suggestions Needed On How People (esp Nigerians) Can Utilize Their Free Time

(Go Up)

Sections: politics (1) business autos (1) jobs (1) career education (1) romance computers phones travel sports fashion health
religion celebs tv-movies music-radio literature webmasters programming techmarket

Links: (1) (2) (3) (4) (5) (6) (7) (8) (9) (10)

Nairaland - Copyright © 2005 - 2024 Oluwaseun Osewa. All rights reserved. See How To Advertise. 31
Disclaimer: Every Nairaland member is solely responsible for anything that he/she posts or uploads on Nairaland.