Oluspicy's Posts
Nairaland Forum › Oluspicy's Profile › Oluspicy's Posts
1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 (of 36 pages)
austineovbi:Thanks. |
86. A kì í ta eyín lójú ẹni tí ebi ńpa. Translation Do not pick your teeth in the presence of a hungry person. Morals Be courteous, considerate and tactful; be sensitive to the effect of your choices on others. |
85. Tí a bá fẹ́ ṣe akin ká ṣe akin, tí a bá fẹ́ ṣe ojo ká ṣe ojo, ìṣakinṣojo kò yẹ ọmọ èèyàn. Translation If you want to be bold, be bold; if you want to be timid, by all means, be timid; to be bold and timid suits no one. Morals No vacillation; no duplicity: don't play both sides; be true. |
84. Bí èkúté bá fara balẹ̀, á jẹ nínú owó ológbò. Translation If the rat can be reasonably calm (and patient), it would eat out of the cat's wealth. Moral With patience, virtually nothing is impossible. |
83. Gbogbo ọ̀rọ̀ ló lésì, ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo ọ̀rọ̀ là ńf'èsì sí. Translation There is always an appropriate response to every statement, but it's not every statement that one responds to. Morals Be focused; don't be distracted: not all issues deserve your attention: don't major on minors. |
82. Orí igi tó wọ́, làá wà, táà rí èyí tó tọ́. Translation It's while on the crooked tree that one will find the proper one. Morals Where we are; quite often, is a stepping stone to where we'd like to be: don't despise where you are. |
81. Ohun tó ṣe igúnnugún tó fi pá lórí, tó ṣe àkàlàmàgbò tó fi yọ gẹ̀gẹ̀ lọ́rùn, tó bá ṣe àgbò bọ̀lọ̀jọ̀, á ti fa ìwo ẹ̀ tú. Translation If what balded the vulture and gave the crow goiter had befallen the full-grown ram, it'd have lost its horns. Morals Be tolerant; people are different |
80. A kì í kánjú tu olú ọrán; igba a rẹ̀ kò tó ó sè lọ́bẹ̀. Translation The oran mushroom is not to be harvested in haste; two hundred pieces of it are not sufficient for (a pot of) soup. Morals Handle complex issues calmly and methodically; hurried actions are prone to errors. |
79. Ọlọ́run ò fẹ́ irọ́; ọmọ èyàn ò fẹ́ òdodo; bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ ò pé mẹ́ta. Translation God hates lies; man hates truths; yet there is no third option in a discourse. Morals Better to stick with the truth, even when there are no easy options. |
FuglyGurl:Weldon Dr. Bọlọrunduro, you a very nice man, but didn't know it will be like this. Well, you've made your choice. |
78. A kì í gbọ́ kúkù òjò da omi agbada nù. Translation Never pour away the water (you have) in the trough, simply because you heard the rumbling of the cloud. Morals Don't be presumptuous; never jump the gun; it's never wise to count one's chicks before they are hatched. |
77. A kì í gba àkàtà lọ́wọ́ akítì; a kì í gba ilé baba ọmọ lọ́wọ́ ọmọ. Translation No one can stop monkeys from squatting; no one should deprive a child of his or her patrimony. Morals Be fair; deprive no one of what is rightly his or hers. |
76. Wọ́n fi ẹ́ ṣe ẹẹ̀kẹrin ìlú, ò ńbínú, ṣé ẹ̀yin mẹ́rin lẹ̀ wà ní ìlú ni? Translation You were displeased when designated the fourth (to the throne) in a town; are there only four of you in the town? Moral Lack of contentment can be self-limiting. |
75. Tí ẹyin adìyẹ ò bá fọ́, oromọadìyẹ ò leè wáyé. Translation If the chicken's (incubated) egg did not crack, the chick could not have been hatched. Moral Adversity may well be a stepping stone; keep hope alive. |
74. Bí inú bá bí baba tó bá gbé ọmọ rẹ̀ jù sí inú èèrùn, bí inú rẹ̀ bá rọ̀, inú èèrùn lè má rọ̀. Translation If a father gets so angry as to throw his child into a raid of army ants, by the time he calms down, the ants may not be. Moral Handle anger with caution; avoid rash decisions. |
73. Ọjọ́ tí orí bá ti kúrò lára ejò ló di okùn lásán. Translation The day the head leaves the body is when the snake becomes a mere rope. Morals Leadership is ever crucial to a body or team: at the very least, it gives life, points in a clear direction and harnesses strengths effectively. |
72. Ọdẹ-afifìlà-perin ọjọ́ kan n'iyì i rẹ̀ ẹ́ mọ; tó bá ti di ọjọ́ kejì, ó ti di olóògùn ìkà. Translation A hunter who killed an elephant with a mere cap, would be honoured for just one day; the next, he would be denigrated as a wicked sorcerer. Moral Success can elicit both awe and envy. |
71. Ti asín yé asín kó tó ṣẹnu gbọọrọ; ti ọ̀kùn yé ọ̀kùn kó tó fi igba ẹsẹ̀ rìn. Translation The moonrat has its reasons for having a long mouth; the millipede has its reasons for moving with hundreds of legs. Moral People have their reasons: give them the benefit of the doubt. |
70. Adìyẹ ńjẹ yangan, ó ńmu omi ó ńgbé ókúta mì, ó tún ńsunkún àìléyín; ṣé òbúkọ tó léyín ńjẹ irin ni? Translation Hens eat corns, drink water, and swallow stones, yet lament lacking teeth; do goats, with teeth, chew pieces of iron (with theirs)? Moral Contentment is it; greed breeds stress. |
69. Ojú tí kò rí yànná yànná iná, yẹ̀rẹ̀ yẹ̀rẹ̀ oòrùn, kì í rí yìndìn yindin idẹ. Translation A pair of eyes that won't endure the fiery flames of fire and the searing glare of the sun, cannot enjoy the glittering beauty of brass. Morals No pain, no gain; no guts, no glory. |
68. Tí ẹyẹ kò bá fín ẹyẹ níràn, ojú ọ̀run tó ẹyẹ ẹ́ fò láì fara kanra. Translation If a bird won't seek the ill of another, the sky is wide enough for all to fly without colliding. Moral Live and let live: the world is endowed enough for all. |
67. Òṣìkà ì bá là, á ba ìlú jẹ́. Translation Were a wicked fellow to be wealthy, he would wreck the town. Morals The prosperity of a wicked person is a risk to everyone. |
66. Sísan ló san ọsàn, lọmọ aráyé fi la ọ̀nà nínú igbó lọ báa nínú oko. Translation The orange is simply favoured, which is why people created a path in the bush to get to it in the farm. Morals Destiny, sometimes, makes the difference; when one is favoured, things simply work right. Do you agree with this? |
65. Kànnìké tìtorí oókan bẹ́ wọ ìgbẹ́; ó ní ibi tó bọ́ sí ni kò tẹ́ òun lọ́rùn. Translation Kannike jumped into the forest in search of his lost one cowrie (money); he insisted that he wasn't satisfied with where it dropped. Morals Be efficient: don't waste needless resources over trifles. |
64. Àì fi nǹkan pe nǹkan ló ńba nǹkan án jẹ́. Translation Lack of regard for something is why it is easily abused. Morals Whatever we value seldom suffer neglect nor is it easily exposed to abuse. |
63. Ìṣín wò ó; ìkòrò wò ó; ohun tí a bá jìjọ wò, gígún ni í gún. Translation Let the fingerlings consider it (an issue); let all the big fishes assess it too; whatever we all join hands to assess, typically gets thoroughly defined. Morals All points of view are crucial; discount and dismiss no one. |
62. Ọ̀rọ̀ ò dun ọmọ ẹṣin; a mú ìyá a rẹ̀ so, ó ńjẹ oko kiri. Translation The colt has no shame; it's mother mare is tethered down, yet it goes about foraging. Morals Prioritise: Handle first things, first; don't major on minors. |
61. Báa gún iyán, táa ro ọkà fún kòfẹ́kògbà, kò ní fẹ́, kò ní gbà, náà ni. Translation Even if one pounds yam and prepares yam flour meal for a difficult fellow, he'll yet remain difficult. Morals Regardless of what you do or say, a difficult fellow can't but be irrational; do your best and move on. |
60. Obìnrin kì í dàgbà jù lọ́wọ́ ọkọ rẹ̀; bí eyín bá ku méjì lẹ́nu ìyá, ọmọge ni lójú baba. Translation A woman is never too old to her husband; even if she's lost all her teeth, a maiden she remains to her man. Morals Love is it; with love, other concerns pale. |
59. Ọ̀pọ̀ ló fẹ́ láàpa láì lápá, bí èèyàn ò sì lápá, kò leè láàpa. Translation Many want to make a mark without effort, yet without effort, no marks can be made. Morals Nothing ventured, nothing gained; diligence pays. |
58. Bí irọ́ bá lọ lógún ọdún, ọjọ́ kan ṣoṣo ni òótọ́ máa bá a. Translation Even, if a lie has gone for twenty years, the truth will catch up with it in just one day. Morals Regardless of how long, the truth always prevails; dishonesty does not pay: it always disappoints. |
57. Tẹ̀tẹ̀ tí kò bá fẹ́ tẹ́ l'áwùjọ ẹ̀fọ́, á yẹ'ra fún àwọn ewékéwé. Translation The spinach that won't be dishonoured in the gathering of vegetables will steer clear of strange leaves. Morals Association matters: we are defined, nay made or marred, by the company we keep. |