Family / Re: Connect With Someone Born On The Same Month & Day You Were Born! by wale259(m): 5:02am On Jun 13, 2016 |
July 27 |
Culture / Re: .. by wale259(m): 2:19pm On Jun 07, 2016 |
Amin Ase! E seun lopolopo....baba modupe,iru eniyan bi tiyin opo,ifa a ma je yin nigba gbogbo.Ase!!! Ifankaleluya:
Thank you very much for the gift you sent this morning bro, GOD bless you real good. Amen!
E seun modupe, owo yin o ni kan isale apo, e o ni wa owo ti
Nile aye yin.
Ifa ni;
Ajikore, Arinkore, oji-kutukutu ko okun ola(wealth) lowo
Ajikore loruko ti a pe ifa
Arinkore loruko ti a pe esu-odara
Oji-kutukutu ko okun ola lowo loruko ti a pe eyin iyami eleye
Eyin meteta ni kin ni mo pe yin fun
Mo ni nitori okun-ola ti e ko lowo ni
Ki e ko fun wale259
To ba se bi ise ti wale259 ba ni
E ni yio la laye
Afaila ojo, bi ojo ba la ki wale259 o la
Eewo, aje ki pe aje ti fi ri taje se
Sawerepepe ni ko ma pe ohun rere fun wa
Ogunda-bede oooo, wa lo re ma jale owo nla nla fun wale259. Ase oo! 1 Like |
Culture / Re: .. by wale259(m): 10:35pm On Jun 06, 2016 |
Ase bami Agbalagba! Ifankaleluya: Ifa ti a da fun OKE-ITASE 2016/2017 ni OBARA lotun
IRETE lowo osi, awon babalawo pe papo, won pe ni Obara-rete.
Ifa ni;
Abere nii fi toju- timu sise
A difa fun Foribale koo rire
Ebo ni won ni ko se
O si gbebo nbe o rubo
Awa wa foribale a o ku mo
Obara- rete , Ori gbo ke!
IFA ori mi re oooo
Mo foribale mo rire
Ifa o jire loni oooo.
Mo gbadura wipe ori gbogbo wa ni yio gbare lodun yi oooo
Aboru, Aboye, Abo-sise! |
Culture / Re: .. by wale259(m): 9:55pm On Jun 02, 2016 |
Ase!!! Ifankaleluya: IFa ni
Akere finu sogbon
Ni oruko ti an pe ifa iran Ija gidigidi ko kan agba
Eniti olorun ba pe ni agba
Baba la ma pe
Adifa fun osetura ti o ma ti kere
Gba agba lowo olodunmerinlogun
Ebo won ni kose
Ogbe'bo nbe o si sebo
Ko pe, ko jinna
Ka wa bani ni jebutu ire
Ijebutu ire la ba ni lese oba-orisa.
Mo toro fun gbogbo wa losu titun yi, ti won ba gba ire ni ile ti won gba ni ita, odo gbogbo wa ni won o dari re si. Ase!!!
Aboru, Aboye, Abo-sise. |
Culture / Re: .. by wale259(m): 3:58pm On May 27, 2016 |
Baba,Ako Langba abi Abo? Ifankaleluya: AWURE OJA TITA ATI FUN ENI TI WA ISE
Ori--Langba, Oyin die, Omi-Omu, Ewe sawerepepe, Ewe-
afomo ajade, ao gun won po mo ose, ao ko sinu igba-
olomori, omi-omu yen ni ao fi po ose yen oo.
Ao te ose yen ni eji-ogbe, ao ma fi we.
Aboru, Aboye, Abo-sise! |
Culture / Re: .. by wale259(m): 9:01pm On May 15, 2016 |
Ifa o to gege,ma je ki omo araye o le binu mi,ki n ma gbayi,ki n ma ri je,ki n ma ri mu,ki ma rina ri lo nigba gbogbo,Ase!!! Ifankaleluya: IFA NI,
Iji ti mo ji mo ba agbe lori igbago
Iji ti mo ji mo ba akalamagbo lori imo
Iji ti mo ji mo ba toro momo lori ope
Toro gege ni iya orunmile nje
Awon olode e mo le binu igun-nu-gun lai-lai
Olorisa kii binu sefun-sefun
Enikan kii binu akan lodo
Aigbori odo pete odo
Aigbaja ka gbimonran ika laja
Enikan kii gun iyan koko ko pode ilu jo
Ojiji enikan ke di mo ni
Ifa o to gege, ma je ki omo araye o le binu mi.
Aboru, Aboye, Abo-sise. |
Culture / Re: .. by wale259(m): 10:56pm On May 14, 2016 |
Amin Ase baba mi ifankaleluya. Ifankaleluya: Ifa ni;
Aronipin(re re re re) eniyan ni funni lagbondo adie je,
A dia fun Orunmila
Baba n fomije sungbere aya
Won ni o sa ki imonle ebo elenini ni ko se,
O gbebo nbe o si sebo,
Nje elenini ile e wa gba,
Eyin aronipin eniyan, e wa gba, Odere ile yi e wa gba,
Asake ile yi e wa gba,
Iya kere ile yi e wa gba,
Eyin aronipin eniyan e wa gba.
Gbogbo ota to ni ti e ko ba de ile oun e o ni se rere,
Pelu ogo-olorun, lowo yin ni won ti mo wa gba. To abala esu.
Aboru, Aboye, Abo-sise. |
Culture / Re: .. by wale259(m): 12:13am On May 04, 2016 |
Ase baba mi Agbalagba,anifanikun.. Ifankaleluya: Ifa ni
Oyeku Baturupon
Mo ri ifa rere ko
Dia fun Ajala
Eyi ti yio ti Oko la wale
Ebo won ni ko se
Ogbebo nbe o si sebo
O geru atu-ka o si tu
Nje e gbo nile ooo
E oo gbo loko
Ajala lo t'oko la wale.
Pelu ogo-olorun, ilekun ola ati ohun rere yio si fun gbogbo wa losu yi.
Aboru, Aboye, Abo-sise! |
Culture / Re: .. by wale259(m): 2:43pm On Apr 25, 2016 |
Ase!!! Ifankaleluya:
Ifa ni;
Iliki lawo iliki,
iliki lawo iliki,
Araba gboju soke mo woye(do re) ilu
Oju-efun kii ri bi,
Oju-osun kii ri bi,
Ifa ma je ki n ri ibi
Eewo ni,
Oko(re mi) kii wonu obo ko farapa,
Oju gbogbo wa ko ni ri ibi o
Aburu ko ni ya si odo wa.
Ase...!!!
Aboru, Aboye. |
Culture / Re: .. by wale259(m): 10:20pm On Apr 19, 2016 |
Ase!ase!!ase!!! Baba.... Ifankaleluya: Won rubo rubo ebo won o fin
Omo Babalawo ni won won fi nba wi
Won se ogun se ogun, ogun won o je
Omo-Onisegun ni won fi n sun lebiran
Ile yin nikan ko wa eegba-awo, omo-olowo ni won fi n ba wi ke eti olowo o le ba gbo ni
Adifa fun Osa ti somo-ologun eru
A ki fun Iwori ti somo-ologbon(re mi do) atiwofa(do do do do)
Nijo won nbe larin Iponju
Ebo Ola(re do) ni won ni ki won o se
Won gbebo nibe won rubo
Won gba-atukan esu o si tu
Nje Osa(do mi) n lowo ooooo
Iwori(do do do) n Loro(mi do)
Eyin O mo pe ile-wa lati jo se ajumo(do do do) jo(re) la(do).
Gbogbo Ori to wa ni fanran yi ni ao jumo jo la oooo. Ase!
E ku Ile..!
Aboru, Aboye, Abo-sise!!
|
Culture / Re: .. by wale259(m): 9:42am On Apr 18, 2016 |
Bawo la se ma se eyele yen leyin ti a ti lo eje re tan ati wipe igbawo ni lilo re marv006: ASINA KEKE KAN NI O
ORI OKETE EGBO TUDE ERU ALAMO EWE EJINRIN ATI EWE EWURO.
ao jo, aolo, aoteni OTURA-OGBE. ao fi eje eyele po, ao su si ona meta, aofi REGAL lofunjo meta. |
Culture / Re: .. by wale259(m): 2:11pm On Apr 13, 2016 |
E se mo dupe sir Ifankaleluya:
@wale259, thank you so much 4 wht you sent to appreciate all wht you av got 4rm m. May GOD continued to bless you!
A ko ni mu owo yen kuro nibe rara, a ma fi Oga yen lo owo yen lori ni a fi ma gbe ose yen le mole. |
Culture / Re: .. by wale259(m): 9:42am On Apr 11, 2016 |
E jo sir,se a ni mu owo(money) yen kuro ninu igba yen ti a fi ma ko ose le Oga lori.[quote author=fxopen post=44432917][/quote] |
Culture / Re: .. by wale259(m): 11:26am On Apr 10, 2016 |
Ase!!! Ifankaleluya: Ifa ni;
Owonrin-wese(do mi) wese
A dia fun Abi-ose
Ti s'omo Ose-lawe(re do re do)
Nijo ti n be larin iponju
Ebo won ni kose
Ogb'ebo nibe o si sebo
Ogb'atuka esu o si tu
Nje ero-ipo, ero-offa
E wa wo ifa awo ki bi ti n se.
Mo gbadura ki Eledumare o ba onikaluku wa we ise(do mi) aye wa nu. Ase!
Aboru, Aboye! |
Culture / Re: .. by wale259(m): 11:25am On Apr 10, 2016 |
Sir,bawo la se ma wa se obi yen to ba ti yan?obi yen ma je mejo(eight pieces) Ifankaleluya: Ifa isegun ota o ni Obara-ika to daju.
Ao lo wa epo igi-iroko, ao lo kunna daadaa, ao sa gbe, ao fi te Obara-ika sinu awo-amo dudu. Ao pa obi-meji fun, ao je die ninu obi na ni ao fi pe ifa re
Ogun ni be mo lori omo-okege
Iroko alu ji ni deru ba agba
Opelope obara-ika
Ngba tomo araiye yo ida
Ti won ni awon o pa mi se bi akaniku,Orunmila lekun
Aja ki ja mo lehin ekun paje
Oso ile to ba nperi mi nibi
Obara-ika o,ka oluwa re sorun
Aje-ile, okunrin, obinrin ti ba n
peri mi nibi, Obara-ika, ko ka
Oluwa re sorun.
Ao da obi yen fun, ti obi yen ba ti yan, ao bu epo pupa si, ao la ti a ba fe sun lale.
Aboru, Aboye. |
Culture / Re: .. by wale259(m): 7:31pm On Mar 28, 2016 |
E sir,bi eniyan to ti ma n ji bi ago meta,merin lati se adua,se ko se nkankan to ba lo ko to bere adua abi o di ti ile ba mo. alexdan1881:
ESE gan Ni baba olohun ama wa pelu yin. kini OKO ATARE? |
Culture / Re: .. by wale259(m): 11:24pm On Mar 25, 2016 |
Sir,ki ni a ma fi Abeere yen se nibe? Ifankaleluya: @wildLife pls i need ur e-mail or line. 1 Like |
Culture / Re: .. by wale259(m): 5:48pm On Mar 24, 2016 |
obara-egun tan,ifa ba emi Wale pa gbogbo egun aye mi. wale259: E bami be Ifa ko pa egun to le wa laye mi. |
Culture / Re: .. by wale259(m): 3:39pm On Mar 24, 2016 |
E bami be Ifa ko pa egun to le wa laye mi. Ifankaleluya: OBARA-OGUNDA NI A N PE NI OBARA-EGUN TAN.
IFA NI;
Obara-egun tan
oni(today) la o pa egun run
adifa fun orunmila nijo ti omo-araye ni awon o fi eegun,epe ba aye baba je
ifa ni iro ni won n pa
egun kii mu ila
egun kii mu ikan
ati egun ati epe kii mu ata
obara-egun tan
ifa ba mi pa gbogbo egun aye mi.
IFA YI NI A MA N FI, ata,ikan,ila ati etu-ibon se. Ti a ba pari re, enu ona ni ao ti te ifa re,ti a ba pe ifa tan. Ao wa fi etu ibon yen si ni aarin,ao wa sa ina si. Ti ina yen ba gbi, ise yen ti dahun niyen.
Ela-boru, ela-boye, elo-bosise.
1 Like |
Culture / Re: .. by wale259(m): 3:18pm On Mar 24, 2016 |
Ako aaya ni baba... Ifankaleluya: Ifa ni; Ogbori ngbiri a tehin dopo Ona(do do) taa ba to ri
Nii se ni siba(do mi) sibo
Ohun rere ni yowo(re mi) obi ninu aso(re re)
ohun buburu(mi re mi) ni yowo ofa(re do) ninu apo(re mi)
Lodifa fun ako(re re) aaya
Lodifa fun abo(re re) aaya
Lojo ti won lo oko iwaje
Ako aaya ni koloko ma ku
Ki igi-Ogunbere ma faya
Ti o ba di iwoyi amodun
Ki a ri bi jo,Gbantete,gbantete
Abo aaya ni boloko ba le ku,ko ku
Bi igi-Ogunbere le ya k'oya
Bi o ba di ni amodun
Ao ri Ibomiran jo,Gbantete,gbantete.
E dakun, e wo lo se ire ninu won?
Ela-boru,Ela-boye,Ela-bosise. |
Culture / Re: .. by wale259(m): 8:38am On Mar 24, 2016 |
Imele ni mo se ti mo fi lowo,Imele ni mo se ti mo laya,Imele ni mo se ti mo fi bimo,Imele ni mo se ti mo fi kole,imele ni mo se ti mo nire gbogbo... Ero(do do) ya, e wa wo ise imele n se,Ero ya! Ifankaleluya: Aje(re mi) bori ogbon(re mi)
Otosi(do do do) so ofo oro
A bu ni lole(mi re) o mo oun ti n se ni
A kunle(mi do) a yan ipin
A dele aye tan oju n kan gbogbo wa
Ipin o se pada lo yanmiran
Aya fi bi a ba tun aye wa.
Ewe le(re) ole(mi re) le alele wure
Dia fun orunmila baba o ma se owo(do do) imele
Imele(do mi mi) ni mo se ti mo fi lowo(mi mi),laya,bimo,nire gbogbo
Ero(do do) ya, e wa wo ise imele n se.
Eledumare yio je aye onikaluku ko rorun(re do) ooo. Ase!
Aboru,Aboye,Abo-sise! |
Culture / Re: .. by wale259(m): 8:27am On Mar 24, 2016 |
Ase!Ase!! Ifankaleluya: Ifa ni; Elefiri-mogun, aja ni aja olofin, agbo lagbo olori, oja-agbala ni ki e fi gbami, oja ti e ba fi gbami ki e ma je ko ja,kike ni ki omo-araye o ma ke mi, gige ni ki omo-araye o ma ge mi, oja ti e ba fi gba mi e ma je ko ja, ewe aje-obale le fi pin ohun lotu-ife nijo n,ogbe-tun-omopon lo ni ke gbe mi pon seyin giri-giri.
Lagbara lowo eledumare awon eleye yio da owo(respect) fun wa.
Ase-orisa lenu mi,eyi mo ba ma ma wi ni irunmole yio gba, ase orisa lenu mi!
Ela-boru, ela-boye, ela-bosise. |
Culture / Re: .. by wale259(m): 8:58am On Mar 23, 2016 |
Se a ma ko ewe ati egbo ajeobale yen le Ega yen lori ninu Ologinni abi a pa ologinni de a si ko ewe ati egbo yen le ni?aso waji yi,se a ma ri lodo anwon elewe omo ati wipe ki ni minrinti Ifankaleluya: IMULE AWON AJE
Odidi Ologinni dudu minrintin kan ti ko ni ami.
Eiye ega kan
Abo adie dudu kan
Ewe-ajeobale pupo
Egbo-Aje-obale
Aso-waji
ko ni ataare kan-kan
ao la adie yen ninu,ao ki ologinni yen bo inu re,olonginni yen na ma wa ni lila(mi do) ninu,ao wa ki eiye-ega yen sinu re, ao wa ko ewe ati egbo aje-obale yen le lori,ao wa fi aso-iwaji yen di papo.
Ao gba sinu agbada, ti a ba ti jo tan ti a si lo,ao wa te ni ifa Osa-meji.
Ifa re:
Mo siju wo apa mi otun mo ri igba eleye,won fori gun rawon igege igege. Mo siju wo apa mi osi mo ri igba eleye,won fori gun rawon igege igege(re do do),dia fun orunmila nijo ti nbe larin eleye,ti won ni awon da ise baba ru,awon o ba ise orunmila je,orunmila ni iro ni won n pa,ati ile atona ni a fi jin olonginni,e ma fi gbogbo oun ti mo ba se jin mi,eiye keye kii fo ko ba sori ajeobale,bi alaso waji ba koja loru oro re a si ru eleye ki eleye loju. Ki oro emi lagbaja omo lagbaja ko ma ru eleyekelye loju.
Ao ma fi fo eko-tutu mu lalaale.
Aboru,Aboye,Abo-sise! 1 Like 1 Share |
Culture / Re: .. by wale259(m): 8:52am On Mar 23, 2016 |
Sir,igba kigba lale we Ose yi abi bawo? Ifankaleluya: OSO KEKE KAN TO GBONA NIYI
Ewe-laali
Eyin adire ororo(do do do) merin
Oga aaye kan
Owo-titun (#500 or 1000)
Igba-olomori
Ose
Oyin
Lofinda bintu meji.
Ao gun ewe-lali yen daadaa, ao gun awon eyin yen mo, ao gun ose yen papo mo, ao fi oyin po ose yen, leyin na ao tun po pelu lofinda bintu kan, ao fi owo(money) yen tele(mi do) igba, ao fi Oga yen le owo yen lori ki o gba awo(do do) owo yen, ao gbe ose yen le lori, ao wa lu ose yen laarin ti yio fi kan Oga yen lara, ao wa tun bintu kan to ku yen si. ao de igba yen pa fun ojo-merindinlogun(16days) ki a to ma we ose na.
Pelu Ogo-Olohun yio si ri be.
NOTE; Akii fi omi si oso yen ti a ba n se lowo oo.
Aboru, Aboye! 1 Like |
Culture / Re: .. by wale259(m): 9:00pm On Mar 22, 2016 |
Sugar melo la ma lomo? Ifankaleluya: EYONU AWON AJE
Elo re wa eso-laara to po daadaa
Odidi-atare kan
Ao jo won papo ni
Ao wa lo(re) sugar mo
Ao ma da senu pelu adura ni alaale ati aro.
Aboru,Aboye. 2 Likes |
Culture / Re: .. by wale259(m): 8:55pm On Mar 22, 2016 |
Ni gba gbogbo ni sise re abi bawo,nitori wipe Ala temi ko clear si mi bi osu melo kan seyin titi di asiko yi,ati wipe se ka to soro si eniyan laro ni mu laro. Ifankaleluya: FUN ENITI N LA ALA-KALA
Ewe-ajeobale mokanlelogun
Omi-agbon to po daa daa.
Omi-agbon yi ni ao fi gbo ewe-ajeobale yen,ao mu die ti a ba fe sun,ao si ji mu iyoku ni aro kutu-kutu.
Bayi ni ao se ma se ti adura wa yio fi gba. |
Culture / Re: .. by wale259(m): 8:49pm On Mar 22, 2016 |
wale259: Sir,e fun mi idi isoye yi... Akii ka owo ki a gbagbe eni Orisa kii gbagbe ati ko ila owo(hand) Omo irunla kii so loko (at farm) ko mala Gbogbo eko ti mo ba ti nko, ki o ma la si mi lokan! Akii ka owo(hand/money)ki a gbagbe eni Se a ma se nigba gbogbo ni abi ekan pere? Se ale se fun omo kekere bi odun meta |
Culture / Re: .. by wale259(m): 1:35pm On Mar 22, 2016 |
WE RENDER OUR CUTTING-EGDE SERVICES TO OUR CLIENTS IN THE FOLLOWING WAYS THEY NEED US: (1)SHIPPING AND PORT SERVICES (2)CLEARING AND FREIGHT FORWARDING (3)AIR FREIGHT FORWARDING PLS:DO CONTACT ME IF U NEED OUR PARTNERSHIP IN ANY OF THE ABOVE SERVICES:08184357512 OR 08038864811...waleadewale2002@yahoo.com THANK U FOR YOUR POSITIVE CONSIDERATION. |
Culture / Re: .. by wale259(m): 9:28am On Mar 22, 2016 |
Sir,e fun mi idi isoye yi... dominicson:
Akii ka owo ki a gbagbe eni Orisa kii gbagbe ati ko ila owo(hand) Omo irunla kii so loko (at farm) ko mala Gbogbo eko ti mo ba ti nko, ki o ma la si mi lokan! 1 Like |
Culture / Re: .. by wale259(m): 12:40am On Mar 20, 2016 |
E se sir,Agba yin o ni baje dominicson:
Eko tutu la a fi lo. Owuro kutukutu la a lo. Aaye ologinni nla la a lo. Ti a ba ti pe gbolohun si ki a to ro sinu ato, o ti daa. |
Culture / Re: .. by wale259(m): 12:25am On Mar 20, 2016 |
Sir,se ale ni lilo ebu yi ati wipe se gbogbo igba ta ba fe lo ni a o ma te ifa eji ogbe si lati pe ohun re si...Aye ologini ni abi Oku re,kini a ma fi lo sir. dominicson: Imule 4:
Olongbo nla kan, owo eyo ogoji(ailu), ewe oriji oojo, atare kan. A o jo papo, ao te ebu yii ni ogbe meji/eji ogbe, a o ro itan/ofo/gbolohun/psalm re si, a o ro sinu ato/seere/ado.
Psalm:
Iweku-ni-iweku, iweja-ni-iweja, a difa fun okanlenirinwo n'ijo ti won lo re yan ipin l'odo Oodua. Won pin aje(wealth) fun Olubini, won pin okun(re do) fun Olurada, won pin ide fun Osun, won pin oje fun Orisa-nla, won pin irin dudu fun ogun, won pin igba omi fun Agbonmeregun, won pin ile(land) fun Oba l'ode Oyo(do mi), won pin isekuse fun Esu Odara. Asotito bo s'ile, o gba aje lowo Olubini, o gba okun lowo Olurada, o gba ide lowo Osun, o gba oje lowo Orisa-nla, o gba irin dudu lowo Ogun, o gba igba omi lowo Agbonmeregun, o gba ile lowo Oba l'ode Oyo. Won wa ni ki Esu o mu isekuse owo re wa, Esu ni ki won o fi ti oun ji oun. Won ni ee ti ri? O ni se bi oba ni eyin, ologinni ni oun. Ati ile, ati ona ni oba fi n ji ologinni, eyin alaye, e wa fi adun aye gbogbo ji mi. Orijin lo ni ki e fi gbogbo ire ti n be ni ode isalaye ji mi. Nitoripe apejin(do do do) ni ti ogoji, e fi ire nla nla ji mi, e fi asise mi gbogbo ji mi o.
|
Culture / Re: .. by wale259(m): 11:36pm On Mar 19, 2016 |
Sir,ki ni a ma fi te ifa Osa meji na,se iyereosun ni abi awon ewe ti agun papo yen. cancioamor: Bawo ni lilo ises yi? esheun
|