Welcome, Guest: Register On Nairaland / LOGIN! / Trending / Recent / New
Stats: 3,167,291 members, 7,867,768 topics. Date: Saturday, 22 June 2024 at 12:09 AM

Wale259's Posts

Nairaland Forum / Wale259's Profile / Wale259's Posts

(1) (2) (3) (of 3 pages)

Culture / Re: .. by wale259(m): 2:11am On Mar 19, 2016
E karo sir,E jo se Eku Asin ati Oga yen,se gbigbe la ma lo ati wipe se lalale ti a ba ti fe lo ebu yi ni a o ma te odu ifa yi si.
dominicson:
Twenty candidates, out of more than two hundred applicants, were sent message to come for interview in a multinational company. These twenty were those who, apart from their academic qualifications, pray and use 'ise aanu/awure'. Only fifteen however could make it there; those that use 'ebe and eyonu' together with their 'awure'. Three of them didn't receive the message sent to them, while two candidates got the message but couldn't make it to the venue for some reasons. Eventually, four of them secured the job after the interview; those that use 'imule'.




Imule 1: Orangun meji

Eku asin meji, oga meji, iwerenjeje igba, eso ido igba, ati igba omo atare. A o jo, a o te ebu yii ni Orangun meji, a o pe gbolohun re si, a o ma fi epo pupa la sun lale.



Psalm/ofo re:

Mo k'eko (learn) k'eko kin to mo ifa da. Mo s'aalo s'aalo kin to mo ibo di. Aalo ni mo se ti mo fi k'eru (load) mi jade kuro n'ile Olofin. Titoro n toro, titoro n toro. O di Oluyonran n yonran. Eyi ona, ona. Eyin ona, afobo s'ona. Eyin ona afobo s'eje. A difa fun Olugbese Ogege, nibi ti won ti n d'ajo esusu, esusu ti won da ni omo won fin nku. Won pa Alara, won pa Ajero, won ni Orangun meji, kini oun kan o. Orangun meji ni nkankan ko kan oun. Emi naa ni aburu aye kankan ko le kan mi. Won ni tori kini o se kan o? O ni ije ti a nje eran gbogbo lenu enikan ki je eku asin be. O ni ije ti a nje eran gbogbo lenu enikan ki je eran oga be. O ni ije ti a nje ohun gbogbo lenu enikan ki je iwerenjeje be. Bee a ki je eso ido bi a ti nje gbogbo eso. Won ni baba, ofo le n pa yii? O ni kii se ofo, o ni oso ile, imule mi le e se, aje ile, imule mi le e se. E ti di imule mi loni. Tori wipe akii bani mule ki a da ise eni ru, akii ba ni mule ki a pon ni loju, a kii bani mule ki a ma le dani l'ola. Eyin eye dudu kekeke ori agbon won yi, se bi eye ile wa le e se, e mu gbogbo aburu kuro lona emi Lagbaja omo Tamado, e wa dami lola, ki e fi adun aye gbogbo fun mi.



Culture / Re: .. by wale259(m): 1:55am On Mar 19, 2016
E karo sir,E jo se ti a ba se obe yi tan la ma pe ohun yi si,nibo la ma te Osa-meji si sir.
dominicson:

Imule 2: Osa Eleye

Igbin apinnu meji, otutu opon, sefunsefun, aluki, ajeobale, iyere.



Psalm:

Alagada nla l'oruko ti a n pe ifa. Araba-tasi l'oruko ti a n pe ile. Ti a ba fi efun fun aye, ara aye a ya gaga. Ti a ba s'epe (curse) so Ogun, ara ogun a le koko. Ogun aseje, awo won lootu Ife, oun l'obi Atepe, Atepe l'obi ile. Nje okunrin l'o ba ni kin ma t'ele yi pe, ki o ku bi aja se n ku ti oun ti ogboro. Agbalagba l'o ba ni ki n ma tele yii pe, ki o ku bi aguntan se ku ti oun ti bolobolo enu re. Ti o ba se pe eyin aje gan ni e wipe ki n ma t'ele yi pe, ki eku bi adire opipi se n ku ti oun ti agada ese re mejeji. Enikeni ti o ba so wipe ki n ma te ile yi pe, ona odi, ona odi ni ki won ma gba lo s'orun. Eye s'eye, o fi apa se eye. Eye s'eye, o fi ese se eye. Eye fo omo owu alagbede pomu. Eye wo(enter) ile Alara, o pa omo Alara. Eye wo ile Ajero, o pa omo Ajero. Eye wo ile Orangun ile Ila, o pa omo Orangun ile Ila. Won ni nibo ni ile awon babalawo to gbo'ju kun si? Won wa k'ori (face) si ile olori Ajangbo-wewe tii se awo ile Alara, eye pa! Bobo-l'aguntan-wo ti se awo ile Ajero, eye pa! Won wa k'ori si ile Aforikori-oke tii se awo Orangun ile Ila, o yan kete, eye pa! Won wa f'abo si ile Orunmila, won ni awon wa wo(pull down) ile re, awon wa pa omo re, awon wa pa aya re, awon wa pa molebi re. Orunmila ni eewo! Orunmila ni oun yoo so oruko yin fun yin nisisiyi. Won ni iro ni, won ni ko si eniti o mo oruko awon laye mo. Orunmila ni sebi Atidisoro l'oruko iya(mother) yin je. Sebi Atedojokan l'oruko ti baba yin je. Sebi Owale-karakara l'oruko ti eyin gan paapa n je. Won ni o di oro imule, won ni ki Orunmila o ke si Otutu-opon, ko kesi Sefunsefun, ki o wa pe Osa meji dani. Won ni ki Orunmila fise Igbin meji yii je. Won ni gbogbo eniti o ba je obe yi ti di eni owo. Won ni ti erin(elephant) ba je oko titi, a fi ewe aluki si le. Bi efon naa ba je oko titi, i fi aluki s'oto ni. Aje kan kii gboju-gboju ko ba sori igi ajeobale, gbogbo ara ni sefunsefun fi sefun aje, ki ile mi o kun fun aje(wealth), ki awon eleye fi owo t'emi wo mi. Oun kohun ti mo ba ti pe ni ko ma je mi.



Culture / Re: .. by wale259(m): 11:48pm On Mar 16, 2016
Baba ifankaleluya,E jo lori ise Asiri bibo yi,mo ni ibere,se leyin ta ti je Aseje tan la ma lo ifa eji ogbe naa ati wipe owo iruwo la ma lo,100,200,500,1000.Se owo yi la ma fi da senu.
Ifankaleluya:
Fun awon ti won bere asiri-bibo lori e-mail.

E lo re wa isu~etiponola, ewe papasan,awom miran n pe ni dedenkude, eyin adire ororo meta,ati ori.

E o lo awon ewe yen papo ni,eo jo eyin yen sibi kan,eo da ewe yen si ti e ba ti lo tan,eo po papo daada.

Eo ju ori yen sinu agbada,ti o ba ti yo,ori yen ni eo fi din eyin yen.

Idi-ikoko yen o gbodo kanle mo oo. Ti o ba ti di ni oru,eo bo ara sile ni ihoho,eo se adura si,eo si ko je.

E o ti wa iyere-osun sile,

iyere-osun yen ni e o fi te eji-ogbe

eo wa pe ifa re si. Mo ti fi ifa yen sile lori fanran yi,e lo re wa nibi ti mo ti ki ifa pe''Oro kan n se mi bi kin ma jo,bi kin ma jo''.

Ti e ba ti pe ifa yen tan,eo fi owo(money) gba iyere osun yen jo,eo da senu. E le mu schnapps tabi seaman kekere si tori ko dara ki eniyan ma mu omi le aseje lori.

Adura yin yio gba ooo.

Ela-boru, Ela-boye, Ela-bosise.

2 Likes

Culture / Re: .. by wale259(m): 11:19pm On Mar 16, 2016
Oguna ni edu(chacol)to ti pon ninu ina(esena)[quote author=zenith329 post=43815028][/quote]
Health / Re: Alafia Logun Oro Itoju Topeye Ogun Ibile Todaju by wale259(m): 1:16pm On Mar 15, 2016
E jo sir,se opolopo eyan lelo.
kadunasouth:

Ododo ori re, flour to wa lori agogo igun, eo ri oun ma te condoro yio gun yio wa kako oun lema ja 99
Health / Re: Alafia Logun Oro Itoju Topeye Ogun Ibile Todaju by wale259(m): 9:23am On Mar 15, 2016
Baba kaduna,e jo e fesi si ibeere mi yi...se inu fitila na lati ma lo kuna abi ale lo lori olo...
wale259:
Sir, e jo se inu fitila na lati ma lo kuna abi ale lo lori olo...
Health / Re: Alafia Logun Oro Itoju Topeye Ogun Ibile Todaju by wale259(m): 5:12pm On Mar 13, 2016
Sir, e jo se inu fitila na lati ma lo kuna abi ale lo lori olo...
kadunasouth:
Asiri Ola (ki ona owo le lakanwa)
Ako ati Abo eye ega owo eyo mesan ewe ola ati ewe sawerepepe odidi atare kan ao ko gbogbore sinu fitila oloju merindinlogun inure lao tijo ao lo ao mafi miliki lo lararo iseyi daju fun owo ati okiki and connection

2 Likes

Culture / Re: .. by wale259(m): 1:23am On Mar 13, 2016
Baba kaduna,ki ni a ma fi sa Ayajo yi,e salaye fun wa.
wale259:
Sir,kini a ma fi sa ayajo yii ati wipe ni gba wo la le ma sa?
Culture / Re: .. by wale259(m): 11:51pm On Mar 12, 2016
Baba health,e jo se gbogbo igba lose na ni wiwe...
healthFirst:
141

IFA IWE ISE ATI OSI DANU
I I
II II
I. II
II. II OBARA DAGISE NU
Egbo akoko ewe re, epo re gbogbo re lara igi kan ao gun pelu ikode kan ao pomo ose dudu ti a ba fe lo ao te nifa OBARA DAGISE NU sori iwon ba ti a fe lo, ap wa pe ofore si.
OFO RE: Mo da sasa awo ile ogbo, mo wewe, mo we osi danu, awo eriki odan. O difa fun Orunmila ni ojo ti awon oso ati aje ngbero wipe awon yio di oran si orunmila lorun orunmila ni e kole di oran simi lorun Woni iwo orunmila jeka wo ohun ti awon kofi ni ledi oran si o lorun, orunmila ni ojo ti omode bati ja ewe pegunrun tosi wa egbo pegunrun ni gbogbo ohun ti o ba n se ni buburu yio pada leyin re emi__omo_moti jawe pegunrun mosi wa egbo re loni gbogbo ohun buruku ti o ba n se mi ko pa da leyin mi....ao wa fi we ao si sun kehikehin
re nina
Health / Re: Alafia Logun Oro Itoju Topeye Ogun Ibile Todaju by wale259(m): 3:20pm On Mar 11, 2016
Baba,e jo kini itumo ki ma gba ogorun eyan lelo oseyi.
kadunasouth:
Ogun Atude Ituwo tiwan bade owo eniyan mejeji
Odidi bara kan ao gesi 16 ao ko tele ape ao wa gbe ori musu tonirun le lori ao fi odidi atare kan si legbe ao jo ao popo ma ose ao mafi we owowa mejeji
Iba akoda iba aseda iba eyin aye ewa tumi nide edi kidi bara ki gbogbo ide owomi kotu danu ki owo mi bere si ya fun owo nlala ki magba
Ogorun eyan lelo oseyi



Moju ba re olodumare

1 Like 3 Shares

Health / Re: Alafia Logun Oro Itoju Topeye Ogun Ibile Todaju by wale259(m): 3:11pm On Mar 11, 2016
Sir,e ku atunse,olorun oba ko ni da ile ati ona yin ru,e jo month fe ki e salaye arin yi ni (toto ikuku to badi aru ao fise sara sita)ati wipe se a ma so igbin yen nu ni.
kadunasouth:
TUDE ASINA
Ekuru funfun, igbin kan ao lu igbin ni idi ao jo omisi ekuru pelu ori(sea butter) toto ikuku to badi aru ao fise sara sita
Culture / Re: .. by wale259(m): 11:48am On Mar 10, 2016
Baba ifankaleluya,ta ba te ni ifa yen tan,se. Ko ni gbolohun kankan,se o ti di wiwe ni yen,nigba gbogbo abi?
wale259:
Baba e jo se ewedu na ni Ewe-ooyo ati wipe se a le fi agbon yen se sara fun onibara tabi awon agbalagba ta ba ri awon omo kekere ni aye lewu baba.wiwe ose yi nigbagbo?
Culture / Re: .. by wale259(m): 11:04pm On Mar 09, 2016
E se baba,Eledumare oni fi yin sile nigba kankan...se mo le lo fun omo mi na bi omo odun meta
Ifankaleluya:


IFA-ISOYE TI O MA N JE GBOGBO OHUN TA BA KA KO DURO SIKUN WA LOKOKAN.


E LO RE WA IGBA-AHUN, ATI IKARA-HUN IGBIN.

AO JO MEJEEJI PAPO, AO LO

KO NI ATAARE NINU OO

AO WA TE NI IFA OFUN-SE (OFUN LOWO-OTUN ATI OSE LOWO-OSI) NI A N PE BAYEN

AO WA PE IFA RE SI BAYI

MO DE IBI WON TI N MUMI OGBON(WISDOM) MO BA WON MU

MO DE IBI WON TI N GBAMON-RAN IMO MO BA WON GBA

ADIFA FUN ORUNMILA NIJO TI N LORE KO MO-IFA, TI N LORE KO OGUN MO-OGUN

WON NI BAWO NI O SE NI GBAGBE

IFA NI EEWO-ORISA IGBIN KII-FA KO GBAGBE IKARA-HUN

BEENI AHUN KIIFA KO GBAGBE IGBA-EYIN RE

WON NI TI O BA GBAGBE BAWO NI O SE NI WO'NU ARA WON

ORUNMILA NI EEWO ORISA IGBIN KII-FA KO WO'NU AHUN

BEENI AHUN KIIFA KO WO'NU IGBIN

OFUN-SE FUN MI NIYE TEMI KI N MU SAWO.

AO MA FI MU EKO-TUTU.

BI WON TI MA N SE NIYEN, E LE TUN BERE LOWO BABALAWO MIRAN TI O BA MO IFA YEN.

ELA-BORU, ELA-BOYE, ELA-BOSISE.
Culture / Re: .. by wale259(m): 9:13am On Mar 09, 2016
Baba ifankaleluya,e ma se be...nitori ta ba ni ka diju keni buruku koja eni rere akoja pelu ati wipe agba o kogbon...emi nife si mo si ti fi email ranse si yin lori e
Ifankaleluya:
Note; If u xtend an handshake 2 a man wit leprosy 2day,next-time he w request 4 a hug. O se bi owe...mo fi ifa imule awon aje yen ranse si ori e-mail enikan,dipo ko dupe o da esi pada wipe emi o fi ami si gbolohun yen ni. E joo se o si leto bayen? N ko ni fisile mo lofe.
Culture / Re: .. by wale259(m): 8:46am On Mar 09, 2016
Baba e ma fun wa ni awon ise tan ki awa na le ma sa wo ko le ri bo se ye kori fun wa ni ti dada.
Ifankaleluya:
OBARA-OGUNDA NI A N PE NI OBARA-EGUN TAN.

IFA NI;

Obara-egun tan

oni(today) la o pa egun run

adifa fun orunmila nijo ti omo-araye ni awon o fi eegun,epe ba aye baba je

ifa ni iro ni won n pa

egun kii mu ila

egun kii mu ikan

ati egun ati epe kii mu ata

obara-egun tan

ifa ba mi pa gbogbo egun aye mi.

IFA YI NI A MA N FI, ata,ikan,ila ati etu-ibon se. Ti a ba pari re, enu ona ni ao ti te ifa re,ti a ba pe ifa tan. Ao wa fi etu ibon yen si ni aarin,ao wa sa ina si. Ti ina yen ba gbi, ise yen ti dahun niyen.

Ela-boru, ela-boye, elo-bosise.

1 Like

Culture / Re: .. by wale259(m): 8:42am On Mar 09, 2016
Baba e jowo e fun mi ni ifa isoye,e fi sanu fun mi....email me re waleadewale2002@yahoo.com
Ifankaleluya:


E seun, Babalawo lo ni isoye,so ifa-isoye po lorisi-risi daadaa,sugbon n ko fe fi ifa sile lori faran yi mo.
A o ma soro lona miran!
Culture / Re: .. by wale259(m): 6:38am On Mar 09, 2016
Eku ise lopolopo,sugbon mofe alaye lori ise yi baba,se iwonba ose ta le lo tan ni a ma fi po omi agbon yi ni a bi ale se ose na sile pupo ati wipe se inu omi agbon ni a ma so oguna na si ka to lo lori olo abi omi lasan.ma dupe te ba dami loun awon ibere wonyi.
Ifankaleluya:
Boya ki e tun lo bere lowo awon agbalagba, OMI-AGBON NI WON N PE NI OMI - APEGUNRUN. EWE-PEREGUN SI DA WA LOTO.

Bayi ni won se ma n lo omi agbon lati fi pa egun, epe, ati ise run.

A o lo wa omi-agbon to po daadaa, ao wa mu oguna to ti pon daadaa ninu ina,ao sare ju si inu omi(owo(hand) ni ao fi mu ogunna yen ninu aro),ao ju si ori-olo,ao lo,ao po mo ose dudu,omi-agbon yen ni ao fi po ose yen. Kanrinkan titun ni ao fi we ose yen ni odo to n san.

Gbolohun yi ni ao ma pe ti a ba ti n we ose yen:

ojo ti ina ba wo inu omi ni egun aye re tan, ki egun aye mi ko tan loni.

Owo(hand) mi ti ba omi-apegunrun lo ni, ki gbogbo egun aye mi ko tan loni,
ati egun, ati epe, ati ise(poverty) aye mi ko ma ba omi lo loni, ko je ki n gbaye se rere.

Ao ju kanrinkan yen si odo,yio ma ba omi lo.
Culture / Re: .. by wale259(m): 6:31am On Mar 09, 2016
Baba e jo se ewedu na ni Ewe-ooyo ati wipe se a le fi agbon yen se sara fun onibara tabi awon agbalagba ta ba ri awon omo kekere ni aye lewu baba.wiwe ose yi nigbagbo?
Ifankaleluya:


Ewe-ooyo ni e o lo re wa ti yio po dada.

Odidi-agbon eyo kan.

Ao sa oyo yen ti yio gbe.

Ao gun po mo ose

Ao pa agbon yen,omi-agbon yen ni ao fi po ose yen

Ao fi ti inu-agbon yen se sara fin awon omo-kekeke,sugbon a ko ni je ninu agbon yen oo.

Ao wa ko ose yen sinu koronfo agbon yen

Ao wa te ni Ogbe-yonu

OGBE-OGUNDA NI A MA N PE NI OGBE-YONU

Culture / Re: .. by wale259(m): 12:50pm On Jan 14, 2016
E jo sir,ba w ni lilo ogun yi...
healthFirst:
27 OGUN TI OWU ALANTAKUN BA N KO ENIYAN LARA
Oku opolo kan ao ki igi bo lati enu ti yoo wole dada ti yoo ha mon ninu dada ao wa mun ao ma fi ko gbogbo jankariwo inu ile titi afi ni leri ara opolo yen mo ti aba ti se bayen tan ao gbodo fi owo kan mon, ao fi ada ge igi yen mo ao wa fi igi gbe sinu agbada ao jo pelu odidi atare kan sugbon ako gbodo fi owo kan ti oba ti jo tan na... ao wa lo epo obo ti yio kuna daada bi atike, ao wa da mo igba yen ni a to le fowo kan.

E joo e je ki ayika wa je mimo...awon kan wa to je wipe nitori idoti ayika won po ni Alantakun se ma n ta okun si ibi ti won n gba ti won le so wipe ise aye ni. Sugbon bi o ba je aarin igboro ni owu alantakun ti ma n ko wa lara nigba gbogbo, Oogun re to daju ni eleyi.
Culture / Re: .. by wale259(m): 12:33pm On Jan 14, 2016
E jo sir,odu osa meji,se o yato si odu osa da si meji?elekeji ni wipe eni to ba se pe eyin ni,ise yi dara lati jo loru ni abi lati lo loru?Agba yin oni baje.
healthFirst:


ha! inkan te beere yi lagbara pupo...ni soki, onitohun ni lati tera mo ise Ebe awon Agba kiakia....gege bi eyin na ti se alaye, ifaseyin nla ni...ayafi ki a be awon agba ki won yonu si wa.

OGUN IMULE TI AJE ATI OSO FIN JAWO LARA ENI TABI TI WON BAN DINI LOWO IRE ENI
Awo'ekun'die, Ewe'afomo'ishana'die, Eyele'dudu kan, Odidin'atare'kan, Ikoride'kan, Iye'agbe'kan, Iye'aluko'kan, Ao mu eyele'dudu yen lai ti ku, Ao ti iye agbe bo eyele yen nidi titi iye'agbe yen yio fi yo jade lenu eyele'dudu yen die , Ao wa ti iye'aluko bo oju'otun eyele yen titi yio fi jade loju'osi eyele'dudu yen die, Ao wa ti ikoride yen bo oju'osi eyele'dudu yen titi yio fi jade loju'otun eyele'dudu yen die, Ao wa jo won papo pelu awo'ekun ati ewe'afomo yen, Ao wa te ifa osa'da'meji si ori'ebu yen, Ao wa pe ofo're si, LILO'RE: Ao bora si ihoho omoluabi ninu iyara wa, Ao wa ta epo'pupa si enu ona inu iyara wa, Ao wada ebu eyele'dudu yen die si ori'epo'pupa yen, Ao wa sun sile, Ao se adura si, Ao wa fi ahon laa epo ati ebu yen, IKILO: Ahon ni ao fila.

OFO'RE
Akin'soro'3xs, Atobo'seje'idi' iya'aje'3xs, Olubeleje'idi' iya'aje'3xs, Awon meteta parapo odi ori'tameta'ele, Won kuro nibe, Odi ile omo olotu'ife, Won dele omo olotu'ife, Won ba gbogb ohun ini omo olotu ife'je, Won kuro nibe, Odi ile omo orunmila, Orunmila kigbe'tooo, Oni rara'ooo, Won ni awon yoo ma ba omo orunmila gbe ile, Orunmila ni ki won'o'bura fun owun, Akin'soro'lo'koko bura, Oni ti owun ba ba inkan ini omo orunmila je, Ki oju'otun owun kio relede owun, Ti owun koba jawo nibe, Ki oju osi owun kio relede owun, Ti owun koba jawo nibe, Ki owun ma po eje lenu titi owun yio fi po gbogbo ifun inu owun jade teje'teje, Atobo'seje idi'iya'aje na bosibe obura be fun orunmila, Olubeleje'idi'iya'aje na bosibe obura be fun orunmila, Emi omo lagbaja omo lagbaja di omo orunmila loni, Toso'taje ilu kie ma bowo fun mi, ki e mase ba ise owo mi je mo, ki e fori jimi, ki e je ki gbogbo idawole mi yori si rere ni tori modi omo orunmila loni'ooo.

NB ODU IFA OSA LOWO OTUN ATI NI OWO OSI. NI WON PENI ODU OSA TOWA LONA MEJI! LAN PENI OSA'DA'SI'MEJI.

2 Likes

Culture / Re: .. by wale259(m): 12:25pm On Jan 14, 2016
E jo sir, se odu osa meji yato si odu osa da si meji? Elekeji ni wipe eni to ba se bi tiyin ni oru ni ise yi dara lati jo ni abi lati ma lo...Agba yin oni baje.
gawab:

E jowo asiko ni enia le lo egbogi yi?
Se enia le lo losan?
Se gbogbo ebu ti a jo ni a o lo lekan na?
Culture / Re: .. by wale259(m): 8:16am On Jan 14, 2016
Ejo sir,se bi a o fo die ninu glass ti won fi n wo oju yen ni,a o si lo mo gbogbo eroja to ku
kadunasouth:
OGUN IFERAN Gbogbo nkan lalelofun
Ewe omisimisi gogoro ati pelebe, gilasi tiwan nfi wo oju dada, koro sugar meta ao lo kuna dada ao teni eji ogbe ao pe ohunre si ao da sinu oyin ao mala
Eleri ikan 3x Aba orisa 3x Amunidele ire 3x Arile rere yasi woni lewu ola 3x,
Awon mererin niwon da ifa fun orunmila nigbati ifa nlo ba olokun sore 3x won ni olokun ma binu siyan ni 3x orunmila ni olokun koni binu si ohun, won ni ibinu omo araye nko, orunmila ni koni binu si omo araye, oni nitoripe oba ilu kibinu oba ilu, oba osin kibinu oba osin, Oba Ajalaye kibinu Oba Ajalawarun, Oba ajalawarun kibinu oba olomerenmere, Oni bi omode bawo digi arerin bi agbalagba bawo digi arerin, nitori adun duntan niti ewe omisimisi ndun kan araWon, Adun denu ni sugar ndun, omode ki fi oyin senu ki opose, Agbalagba kifi oyin senu ki opose, EJIOGBE gbe ife mi si okan............tabi gbogbo araye ki o fi ife aje sin mi

2 Likes

Culture / Re: .. by wale259(m): 1:33pm On Dec 23, 2015
Sir,se lepo niyo ni aseje na?
KolaBELIEVE:
ejowo se ori oka toni iru re lenu ni?
Culture / Re: .. by wale259(m): 1:20pm On Dec 23, 2015
Se a ma lo ewe abamoda yen ati ata ijosi yen papo ati pe se lepo niyo la ma se je..
keyguy59:
¤I HAPPILY GAVE ALL THESE TO PEOPLE WHO HAD BEEN
COMMENTING REGULARLY ON MY UPADATES ONLY
BECAUSE I PAGE WITHOUT COMMENTS IS A "GRAVE
YARD"¤
(1) OGUN BASIRI FUN INAWO¤
Ewe abamoda, ata ijosi, ao ko sinu Isasun titun, ao fi oju Malu(eyes of a cow) mejeeji se laseje. O DAJU !!!
(2) OGUN IRIRAN
Ao be Gbaguda Oojo, ao gun ninu Odo, ao fun omi re.
Ao fipo Efun ile, ao maa kan sinu oju wa mejeeji.
O DAJU!!!
(3) OGUN IDANWO Ojele ewe olosan ati glass, ao waa fi Ewe Olosan na
pa GLASS na loju.
ao maafi glass na wo oju nigba EXAM
Culture / Re: .. by wale259(m): 11:24am On Dec 23, 2015
tundebadmus:
ewo wo ni oni eje ka mon ewoye ki atoda owole,ewe yio maje o
baba,efun wa ni Ewo ise yi...ewe a ma je o
Culture / Re: .. by wale259(m): 11:05pm On Dec 21, 2015
healthFirst:
IFA IBASIRI TI ENIYAN BA FE SE INAWO
TI FI YE ENIYAN
Ao da iyerosun sinu aso funfun ao wa teni
OTUAMEJI.
OFO RE:Amilara, amiloro, iyi ni seru akora
baba yin, orunmila o to gege, kowa fun
emi lagbaja omo lagbaja niyi temi nibi n
kan ti mo fe se yi, ka siri mi o bo, asiri
aso funfun ki tuu, ifa moje kasiri temi
lagbaja omo lagbaja o tu o, otuameji moje
kasiri temi lagbaja omo lagbaja o tu o, kin
gba iyi kin gbeye, aso funfun kisi loju
oloosa.

Baba,e jo se ojo inawo yen ni a ma te ifa na sinu asofun ati wipe ti a ba pe gbolohun na si ifa na ki la ma wa se leyin e,e se alaye na fun wa ko ye....agba yin oni baje

2 Likes

Culture / Re: .. by wale259(m): 1:06pm On Dec 21, 2015
Baba,E jo kini a ma fi lo ogun yi ati wipe igbawo ni lilo re dara ju...
kadunasouth:
Ogun eyonu
Eyin ororo kan ewe ewuro 100 ao fi tele koko ao fi eyin ororo le ao tun ko ewe ewuro 100 le lori ao fi atare kan si ao ma jo to bati jotan dada ao sokale ao wa sadua si ewe ewuro eyokan ao waju si leyin tati sokale ao lo ao pin si ona meje ao bere lilore lojo sunday fun ojo meje
Nb ojo sunday nikan lale jo ise yi odaju
Yio je funyin o+++++++++++++++++++!!!!!!!!!!!!!!!!!!!!!!!!!!!!!!!!!!!!!!!!!!!!!!!!!!!!!!!!!!!!!!!!!!!!!!!!!!!!!!!

2 Likes

Health / Re: Alafia Logun Oro Itoju Topeye Ogun Ibile Todaju by wale259(m): 12:58pm On Dec 21, 2015
Baba,mo ro wipe ogun isoye yi eni Ewe Akoko 16 la ma ko si....
kadunasouth:
Ogun isoye
Ori akuko adie togbo dada ao fi sinu agbada ijo nkan ao ko ewe akoko bomole ao fi odidi atare kan si ao jo ao lo kuna ao da oyin si ao ma fi ika arin ropo ao ma la isoye yi dara otun sise fun awon omo keke tiwan lo ile iwe ao so wipe ki wan ki ika arin bo kiwan la, inu roba ti owo (hand) lewo la dasi ti ao ti mala

2 Likes

Culture / Re: .. by wale259(m): 12:46pm On Dec 21, 2015
Sir,kini a ma fi sa ayajo yii ati wipe ni gba wo la le ma sa?
kadunasouth:
AYAJO AWEBI, AWE-OGUN IDILE AWE-EPE etc
Efun ni baye osun je
Osun ni baye efun je
Atefun Atosun edu ni baye awon mejeji je.
Gbogbo asasi, edi, offa, aisan, epe, idiwo, arun, owo kowo, airi je, airi mu tin be lara oni kaluku wa koba je, kopa ibi da, koso dire, ki ona owo nlala ati arisiki kio la kan mi ati gbogbo ololufe Nairalanders!!! Ase odumare

2 Likes 1 Share

Culture / Re: .. by wale259(m): 10:33am On Dec 21, 2015
Agbelepota ti eni eyan mafi osun pa ori adanripon,a si fi atare mesan si lenu ni mo n so..E se lopolopo
healthFirst:


Agbelepota ewo? Emi o post Osole kankan o, mo de ti ba awon to n post Osole wi. E sora fun Osole o. Eni tio ba ni Ajesara Imunle Agba to gbona gbudo jina si oogun Osole. Igboran san ju ebo riru lo o.

Culture / Re: .. by wale259(m): 12:28am On Dec 21, 2015
E jo sir,se a ma ta epo si etutu na abi ni gberefu na ni a ma gbe lo si orita
Ifadamilola30:


Agba yin a dale baba, e dakun se a ma fi iyo se eran yen??
Culture / Re: .. by wale259(m): 4:08pm On Dec 15, 2015
Ifadamilola30:
cool
Ejo baba,Agbelepota yii ebu to ba ku kini a ma fi se leyin ti ati lo iwonba ti afi pa oju gbere abi opo eniyan le lo.

Osole te so,se ologbo kekere ni abi nila ati wipe nibo la ma ro ogun na si fun lilo diedie. E se

(1) (2) (3) (of 3 pages)

(Go Up)

Sections: politics (1) business autos (1) jobs (1) career education (1) romance computers phones travel sports fashion health
religion celebs tv-movies music-radio literature webmasters programming techmarket

Links: (1) (2) (3) (4) (5) (6) (7) (8) (9) (10)

Nairaland - Copyright © 2005 - 2024 Oluwaseun Osewa. All rights reserved. See How To Advertise. 100
Disclaimer: Every Nairaland member is solely responsible for anything that he/she posts or uploads on Nairaland.