Welcome, Guest: Register On Nairaland / LOGIN! / Trending / Recent / New
Stats: 3,195,554 members, 7,958,704 topics. Date: Wednesday, 25 September 2024 at 09:08 PM

Eye Odidere - Culture - Nairaland

Nairaland Forum / Nairaland / General / Culture / Eye Odidere (6768 Views)

Eye Of God Appears In Sky Above Astana / Late Oba Okunade Sijuwade In The Eye Of History / Itan Eye Odidere (2) (3) (4)

(1) (Reply) (Go Down)

Eye Odidere by gawab: 10:18am On Jun 03, 2015
Eye Odidere naa ni Yoruba npe ni eye Aiye-kooto, eye to rewa ni eye Odidere ko si ilu ti enia le de ni’le Yoruba ti enia o ni ri enikan o kere ju ti yio ni eye yi nile. Sugbon opo awon to ni eye yi nile papa ko kiyesi awon emo to wa lara eye Odidere won kan mo pe o mo nsoro ni atipe Ikode (iye idi) re je eyi ti won mo ri ta, sugbon ti opo ba mo nipa eye ti won gbe sinu ile won o ni fe danwo lasa. Sugbon o eye Odidere kiise enia ni ijanba Kankan nigbati o ba ti de ile koda omode lasan le mo fi sere lai sewu.

AWON EMO TONI LATI MO NIPA EYE ODIDERE NIYI

Eye Odidere ki fi ese kan ile tabi erupe
Inu iho igi lo mo nye eyin si
Ti ogomo ba kan eyin Odidere yio lana
Enia o le fi oju kan eyin Odidere koju naa mo fo
Owo ni ikode Odidere
Owo ni igbe Odidere
Odidere mo nsoro bi enia

Awon emo ara eye Odidere ti un so fun wa niyi, Odidere kii fi ese kanle tabi erupe lojo ti o ba fi ese kanle tabi erupe ni ko tun fo mo laye, inu iho igi lo mo nye eyin si nitori bi enia ba fi oju kan eyin eye Odidere oju naa yio fo lailai ko si ohun to le la oju naa, ti awon ode ba fe mo pe eye Odidere lo nye eyin sinu iho igi kan won o lo mu Ogomo (mariwo ope tuntun to sese yo) won wa te bo inu iho igi naa, bi o ba se nkan eyin Odidere ni yio gba ina lara ti ina naa yio si jo de oke, won o wa mo so igbati yio pamo ti won ba ti mo pe o ti pamo won o so akara kengbe mo ara ogomo ti awon omo eye Odidere ba ti ri akara yi won yio so mo eni to wa ni ita yio wa mo fa bo nita, bi won ba ti mu jade ese re ni won o koko fi lele ko tun le fo mo lailai.

Looto enia le ri eyin Odidere to je ti awon Oibo sugbon ti enia ba wo eye Odidere ti Oibo ati Yoruba dada yio ri pe iyato nla lo wa larin tiwa ati Oibo, nitorina ki enia ma lo ro pe enia le fi oju kan eyin Odidere Yoruba. Ikilo ni fun eni ba fe gbo.

Eyin Odidere ni won mo nfi sinu ade laye atijo idi niyi ti Oba ati enia o gbodo fi si oju wo inu ade. Owo ni ikode Odidere ikode ni iye to je iru re pupa ni ikode Odidere keke lo mo nri kii gun beni si ni igbe Odidere naa tun je owo. Awon Yoruba mo nlo iye ati igbe Odidere fun opo isegun, awon miran ti e mo nlo odidi eye yi. Olori emo eye yi wa ni oro to mo nso, oro da lenu eye yi ti enia yio fi gbo ohun to nso bi igba ti enia ba n sufe ni oro re, bi enia ba wa enia wa nigbati enia ko sini ni ile Odidere yio jise fun oluware to ba de. nkan asiri tabi oro asiri ko se so loju eye yio nitori ko ni se bi enipe ohun ri yin sugbon o ro lorun ko fi wakati kan ro ejo naa fun gbogbo ara ile lati ara oro re ni Yoruba se npe eye Pataki yi ni Aye-Kooto.

Ka itan orisirisi ni: www.itanyoruba.com

Anfani wa fun iwo na lati ko itan ti o ba mo.

Re: Eye Odidere by Maxymilliano(m): 11:09am On Jun 03, 2015
gawab:
Eye Odidere naa ni Yoruba npe ni eye Aiye-kooto,


Are you sure about this ? I know Parrot to be Aye-kooto, and Pigeon to be Eye Odidere.

I don't see how it is the same ...
Re: Eye Odidere by gawab: 11:38am On Jun 03, 2015
Maxymilliano:

Are you sure about this ? I know Parrot to be Aye-kooto, and Pigeon to be Eye Odidere.
I don't see how it is the same ...
Pigeon is not Eye Odidere, Pigeon is Eyele.

Do you know the difference between the two pictures of the birds?
Re: Eye Odidere by Maxymilliano(m): 11:56am On Jun 03, 2015
gawab:

Pigeon is not Eye Odidere, Pigeon is Eyele.

Do you know the difference between the two pictures of the birds?


The first pic you put up is like a Cuckoo, commonly called Odere koko, is it any different from Odidere ?
Re: Eye Odidere by kadunasouth(m): 11:16pm On Oct 25, 2015
ÒKÉTÉ
Okete je ọkan ninu eranko abami to lagbara pupọ.
Amọn gbe ninu iho.
ELEDUMARE fun ni asẹ pupọ.
Okete kii fi ọwọ tabi ẹsẹ gbẹ iho,
iru ni okete ma'nfi gbẹ iho,idi eyi ẹo le ri erupẹ lẹnu isa okete,
bi eniyan ba gbẹ iho okete igbamiran ama se isa mon e'yan lọwọ.
Ti aba gbẹ isa kan okete ti o ba fi ahọn Kan ilẹ gende kan ko faa jade,
okete ni asẹ kan ni ipari Iru rẹ, bi eniyan ba'nle okete lọ toba fi asẹ Iru rẹ nan ilẹ,kosi bi eni nan tile lagbara to yo subu lulẹ,awọn idi eyi lobi owe ''ORO TOKETE BA BALẸ SỌ NI ILẸ GBỌ'' ti eniyan ba pa okete ti eni na ba ge asẹ iru rẹ sinu isa rẹ okete na yo tun da pada wo inu isa na lẹyin ọdun kan eyi lobi owe ''MIO LE FI ILE BABA MI SILẸ LOUN SEKU POKETE LỌDỌỌDUN'' ti okete baa ti bimọ yo yọ yara fun awọn ọmọ rẹ ninu Isa kanan wọn yo yọ palọ sibẹ eyi ni anpe ni agburu okete ibẹ ni gbogbo wọn tiun jẹun, ti okete bati darugbo daadaa ti ẹnu rẹ ko ran onjẹ mọ awọn ọmọ rẹ abo ni wọn o ma fun lọyan mu, eyi lobi owe ''BI OKETE BA DAGBA ỌMUN ỌMỌ RẸ NI MUN'' okete fẹran ekurọ pupọ ẹkurọ ti a ba ri ninu isa okete a kii pe ni ekurọ eese lama npe eyi lobi owe ''KAKA KI OKETE MAJE EESE A FI SAWADANU NI''
okete a ma dide rin bi eniyan lọganjọ oru yo si ko ounjẹ lọwọ tabi ko gberu,ọdẹ tabi ẹnikẹni ko gbọdọ pa okete toba wa ni ipo na.
Orukọ miran fun okete ni ewú,okete Kii jade ni ọsan eyi lobi owe''AKI RI EWU LỌSAN'' ti eniyan ba gbẹ Isa kan okete toba gbe awọn lelẹ ao gbọdọ faa Ju ki iru rẹ ma ba bo,ti okete ba boru mo eniyan lọwọ amunbọ loun fa.
ti eniyan ba pa okete toun sun lọwọ to bu eeru si oju ọnan yo ri oju ẹsẹ okete toti jade pada eyi lomu awọn agba ma pe ni AKUDAAYA' ti aba tu ifun okete ama ri mọlẹ nitori aja,bi aja ba jẹ ifun okete aja na yo ya digbolugi/were.
bi eniyan ba fẹran lati ma jẹ okete ju,o rọrun fun awọn agba lati ma wo ifun ẹni nan.
Eemọ ati iyanu pọ lori ọrọ okete sugbọn kosi aaye. Ao ma tẹ siwaju laipe..

4 Likes 2 Shares

Re: Eye Odidere by tpiah11: 1:13am On Oct 26, 2015
parrot is ayekooto
Re: Eye Odidere by tpiah11: 1:14am On Oct 26, 2015
gawab:



Do you know the difference between the two pictures of the birds?

you can post their scientific names and photos.
Re: Eye Odidere by Lionhearted: 1:31pm On Oct 26, 2015
kadunasouth:
ÒKÉTÉ
Okete je ọkan ninu eranko abami to lagbara pupọ...

Eku ise.

Oro yin mun mi ranti oun ti o sele nigba ewe mi:

Ani ogba ni ehinkule ile wa ti osi je wipe ibe ni a ma n da atan si, okete po ninu ogba na. Ni owuro ojo kan mo losi inu ogba ni mo ba ri Okete ti o nje buredi. Mo mun Igi lati le okete na sugbon se ni Okete na ju buredi na sile ti osi dide duro lori ese re eyin mejeeji toun fi owo re mejeeji rara won bi eniti eniyan n bebe.

Ohun iyalenu loje fun mi.

(1) (Reply)

IGBO What Does Onye Akpu Obi Mean / African Beauty: Cool Girl ! / Our Ancestors - Images From Ancient Egypt

(Go Up)

Sections: politics (1) business autos (1) jobs (1) career education (1) romance computers phones travel sports fashion health
religion celebs tv-movies music-radio literature webmasters programming techmarket

Links: (1) (2) (3) (4) (5) (6) (7) (8) (9) (10)

Nairaland - Copyright © 2005 - 2024 Oluwaseun Osewa. All rights reserved. See How To Advertise. 31
Disclaimer: Every Nairaland member is solely responsible for anything that he/she posts or uploads on Nairaland.