Welcome, Guest: Register On Nairaland / LOGIN! / Trending / Recent / New
Stats: 3,152,815 members, 7,817,364 topics. Date: Saturday, 04 May 2024 at 11:05 AM

Yoruba Hymn - Religion - Nairaland

Nairaland Forum / Nairaland / General / Religion / Yoruba Hymn (8145 Views)

Story Behind The Hymn, "When I Survey The Wondrous Cross" / Which Church Has The Best Hymn Songs / Yoruba Hymn (2) (3) (4)

(1) (2) (Reply) (Go Down)

Yoruba Hymn by obasolape(f): 7:27am On Oct 23, 2015
Ji okan mi dide layo
Korin iyin Olugbala
Ola Re bere orin mi
Seun ife Re ti po to

O ri mo segbe n'isubu
Sibe o fe mi l'afetan
O yo mi ninu osi mi
Seun 'fe Re ti n'ipa to!

Ogun ota dide si mi
Aiye atesu ndena mi
On nmu mi la gbogbo Re ja
SEun 'fe Re ti nipa to

Gba yonu de b'awosanma
To su dudu to nsan ara
O duro ti mi larin re
Seun fe Re ti dara to

Gba gbogbo lokan ese mi
Nfe ya lehin Oluwa mi
Sugbon bi mo ti ngbagbe Re
Iseun ife Re ki ye

Mo fere faiye sile na
Mo fe bo lowo ara iku
A! Kemi kehin mi korin
Iseun ife Re n'iku

Nje ki nfo lo, ki nsi goke
Saiye imole titi lai
Ki nfayo iyanu korin
Iseun ife Re lorun.

4 Likes

Re: Yoruba Hymn by obasolape(f): 5:09am On Apr 01, 2019
Duro, duro fun Jesu,
Enyin om’ogun Krist:
Gbe asia Re soke
A jo’gbodo fe ku;
Lat’isegun de ’segun
Ni y’o ma to ogun Re;
Tit’ao segun gbogb’ota,
Ti krist y’o j’Oluwa

Duro, duro fun Jesu
F’eti s’ohun ipe
Jade s’ohun ipe
L’oni ojo nla Re:
Enyin akin ti nja fun
Larin ainiye ota,
N’nu ewu, e ni ’gboiya
Dojuko agbara.

Duro, duro fun Jesu,
Duro l’agbara Re
Ipa enia ko to
Ma gbekele tire:
F’ihinrere hamora
Ma sona, ma gbadura
B’ise tab’ ewu ba pe
Ma se alai de ’be.

Duro, duro fun Jesu
Ija na ki y’o pe;
Oni, ariwo ogun,
Ola, orin ’segun,
Eni t’o ba si segun,
Y’o gba ade iye
Y’o ma ba Oba Ogo
Joba titi lailai…Amin

2 Likes

Re: Yoruba Hymn by obasolape(f): 5:54am On Sep 06, 2019
Omije oju mi n bere aanu Re... Baba
Omije oju mi n bere aanu Re... Baba
Fi aso oju rere womi Olorun mi
Araye nreti ohun ti mamubo lodo re Baba mimo
Odun yi nlo o Odun yi nlo
Omije oju mi nbere aanu Re o

2 Likes

Re: Yoruba Hymn by obasolape(f): 5:56am On Sep 06, 2019
Krist' ki 'joba Re de,
Ki ase Re bere;
F' opa-rin Re fo
Gbogbo ipa ese.

Ijoba ife da,
Ati t' Alafia?
Gbawo ni irira
Yio tan bi t'orun?

Akoko na ha da,
T' ote yio pari,
Ika at' ireje,
Pelu ifekufe?

Oluwa joo, dide,
Wa n'nu agbara Re;
Fi ayo fun awa
Ti o nsaferi Re

Eda ngan ooko Re,
'Koko nje agbo Re;
Iwa 'tiju pupo
Nfihan pe 'fe tutu.

Ookun bole sibe,
Ni ile keferi:
Dide 'Rawo ooro,
Dide, mase wo mo.
Amin.

1 Like

Re: Yoruba Hymn by obasolape(f): 6:00am On Sep 06, 2019
1 Wa, ma sise,
Tani gbodo s‘ole ninu oko
‘Gbati gbogbo eniyan nkore jo,
Kaluku ni Baba pe fun ise;
“Sise loni”

2 Wa, ma sise,
Gba ‘pe giga ti angeli ko ni
Mu ‘hinrere to t‘agba t‘ewe lo,
Ra ‘gba pada, wawa l‘akoko nlo,
Ile su tan.

3 Wa, ma sise,
Oko po, alagbase ko si to,
Aye titun po fun wa lati kun,
Ohun ona jinjin, at‘itosi
Nkigbe pe; “Wa”

4 Wa, ma sise
Le ‘yemeji on aigbagbo jina,
K‘o s‘alailera ti ko le se nkan,
Ailera f‘Olorun a ma lo ju '
Fun‘se nla Re

5 Wa, ma sise,
‘Simi ko si nigbat‘ ise osan,
Titi orun yio fi WO l‘ale,
Ti awa o si gbo ohun ni pe:
“O seun, omo”

6 Wa, ma sise,
Lala na dun ere re si daju,
‘Bukun f‘awon t‘o fori ti d‘opin
Ayo won, ‘simi won y‘o ti po to!
“Lo d‘ Oluwa”
Amin.

2 Likes 1 Share

Re: Yoruba Hymn by obasolape(f): 5:24am On Nov 12, 2019
Gbat' O ba de, gbat' O ba de
Lati sir' oso Re
Gbogbo oso Re iyebiye
Awon ti o fe

Bi Irawo owuro, nwon nsade Re loso
Ewa won o yo pupo, Ewa f'ade Re

Yio kojo, yio kojo
Oso Ijoba Re
Awon mimo awon didan
Awon ti O fe

Bi Irawo owuro, nwon nsade Re loso
Ewa won o yo pupo, Ewa f'ade Re

Awon ewe, awon ewe
To fe Olugbala
Ni oso Re iyebiye
Awon ti o fe

Bi Irawo owuro, nwon nsade Re loso
Ewa won o yo pupo, Ewa f'ade Re

2 Likes

Re: Yoruba Hymn by obasolape(f): 7:48pm On Nov 26, 2019
AGBARA RE GA JU T'OTA LO OO
IMO RE GA JU T'ESU LO
AGBARA RE GA JU T'OTA LO OO
IMO RE GA JU T'ESU LO -
OLORUN KO SE OUN TI NI O,
OSO AYE KOLE DI O LONA ISE RE,
AGBARA RE GA JU T'OTA LO

1 Like

Re: Yoruba Hymn by obasolape(f): 6:00am On Jun 29, 2021
1. WA k’ a da m’ awon ore wa
Ti nwon ti jere na;
N’ ife k’ a f’ okan ba won lo
S’ ode orun lohun.

2. K’ awon t’ aiye d’ orin won mo,
T’ awon t’ o lo s’ ogo;
Awa l’ aiye, awon l’ orun,
Okan ni gbogbo wa.

3. Idile kan n’nu Krist’ ni wa,
Ajo kan l’a si je;
Isan omi kan l’o yaw a,
Isan omi iku.

4. Egbe ogun kan t’Olorun
Ase Re l’a sin se;
Apakan ti wo ‘do na ja,
Apakan nwo lowo!

5. Emi wa fere dapo na,
Y’o gb’ade bi ti won;
Ao yo s’ami Balogun wa,
Lati gbo ipe Re.

YBH 311

WA k’ a da m’ awon ore wa

6. Jesu, so wa, s’amona wa,
Gbat’oniko ba de;
Oluwo, pin omi meji,
Mu wa gunle l’ayo.

1 Like

Re: Yoruba Hymn by obasolape(f): 6:02am On Jun 29, 2021
A o kọja lọ bi àwọn 'rawọ òórọ̀
T' ìmọ́lẹ̀ wọn n ran n'nu oorun ogo,
Bẹ́ẹ̀ l' a o lọ kúrò l' aye ati 'ṣẹ rẹ̀,
A o maa ranti wa nip' on t' a ti ṣe.

ÈGBÈ:
Wọn yoo ṣe 'ranti, wọn yoo ṣe 'ranti,
A o maa ranti wa nip' on t' a ti ṣe,
Bẹ́ẹ̀ l' a o lọ kúrò l' aye ati 'ṣẹ rẹ̀,
A o maa ranti wa nip' on t' a ti ṣe.

2. A o ha kuro k' àwọn miran rọ́pò wa,
Lati maa kore oko t' a ti gbìn?,
Bẹ́ẹ̀ l' àwọn òṣìṣẹ́ yoo fi 'ṣẹ́ sílẹ̀,
A o maa ranti wa nip' on t' a ti ṣe.

3. Kìkì òótọ́ ti a ba ti sọ láyé,
Pẹ̀lú 'rúgbìn t' a ti gbìn laye yii,
Yoo tẹ̀síwájú t' a ba ti gbàgbé wa,
Eso ikore at' on t' a ti ṣe.

4. 'Gbà t' Olúwa yoo k' àwọn ayanfẹ Rẹ̀,
T'ao jere adé aláyọ̀ t' ó ntàn,
'Gba naa l' ao ranti àwọn olootọ Rẹ̀,
T' àárẹ̀ ti mu nip' on ti wọ́n ti ṣe.

1 Like

Re: Yoruba Hymn by obasolape(f): 4:33am On Oct 14, 2021
GBATI SAMUEL JI

1. GBATI Samueli ji
To gb’ ohun Eleda
Ni gbolohun kokan,
Ayo re ti po to
Ibukun ni f’omo t’ o ri
Olorun nitosi re mbe.

2. B’ Olorun ba pe mi
Pe, ore mi li Oun,
Ayo mi yo ti to
Ngo si f’ eti sile,
Ngo sa f’ ese t’ o kere ju,
B’ Olorun sunmo tosi be.

3. Ko ha mba ni soro?
Be ninu Oro Re?
O npe mi lati wa
Olorun Samuel;
Ninu Iwe na mo ka pe
Olorun Samuel npe mi.

4. Mba f’ ori pamo
S’ abe itoju Re,
Mo mo p’ Olorun nbe
L’ odo mi n’gbagbogbo
O ye k’ eru ese ba mi,
Tor’ Olorun sunmo to si.

5. ‘Gbamba ka oro Re,
Ki nwi bi Samuel pe
Ma wi, Oluwa mi
Emi y’ o gbo Tire;
‘Gba mo ba si wa n’ile Re,
“Ma wi, ‘tori ‘ranse Re ngbo.”

1 Like

Re: Yoruba Hymn by obasolape(f): 4:33am On Oct 14, 2021
Olugbala Gbohun Mi

Olugbala gbohun mi
Gbohun mi, gbohun mi
Mo wa sodo Re gba mi
Nibi agbelebu
Emi se, sugbon O ku
Iwo ku, Iwo ku
Fi anu Re pa mi mo
Nibi agbelebu

Oluwa jo gba mi
Nk'y'o bi O n'inu mo
Alabukun gba mi
Nibi agbelebu

Bi n o ba tile segbe
N o bebe, n o bebe
Iwo ni Ona, iye
Nibi agbelebu
Ore ofe Re ta gba
Lofe ni, lofe ni
Foju anu Re wo mi
Nibi agbelebu

Feje mimo Re we mi
Fi we mi, fi we mi
Ri mi sinu ibu Re
Nibi agbelebu
Gbagbo lo le fun wa ni
Dariji, dariji
Mo figbagbo ro mo O
Nibi agbelebu

Loving Saviour, hear my cry,
Hear my cry, hear my cry;
Trembling to Thine arms I fly:
O save me at the Cross!
I have sinn'd, but Thou hast died,
Thou hast died, Thou hast died;
In Thy mercy let me hide:
O save me at the Cross!

Lord Jesus, receive me,
No more would I grieve Thee,
Now, blessed Redeemer,
O save me at the Cross!

Tho' I perish I will pray,
I will pray, I will pray;
Thou of life the Living Way:
O save me at the Cross!
Thou hast said Thy grace is free,
Grace is free, grace is free:
Have compassion, Lord on me:
O save me at the Cross!

Wash me in Thy cleansing blood,
Cleansing blood, cleansing blood;
Plunge me now beneath the flood:
O save me at the Cross!
Only faith will pardon bring,
Pardon bring, pardon bring:
In that faith to Thee I cling:
O save me at the Cross!

1 Like

Re: Yoruba Hymn by obasolape(f): 4:34am On Oct 14, 2021
WA S'ODO MI, OLUWA MI

Verse 1
WA s'odo mi, Oluwa mi,
Ni kutukutu owuro;
Mu kero rere so jade,
Lat'inu mi soke orun.

Verse 2
Wa s'odo mi, Oluwa mi,
Ni wakati osan gangan;
Ki'yonu ma ba se mi mo,
Won a si s'osan mi d'oru.

Verse 3
Wa s'odo mi, Oluwa mi,
Nigba ti ale ba n lẹ lo;
Bi okan mi ba n sako lo,
Mu pada; f'oju 're wo mi.

Verse 4
Wa s'odo mi, Oluwa mi
Ni oru, nigba ti orun,
Ko woju mi; je k'okan mi
Ri sinmi je ni aya Re.

Verse 5
Wa s'odo mi, Oluwa mi,
Ni gbogbo ojo aye mi;
Nigba ti emi mi ba pin,
Ki n le n'ibugbe lodo Re.

1 Like

Re: Yoruba Hymn by obasolape(f): 4:36am On Oct 14, 2021
(1)Tire titi lai l'awa se,
Oluwa wa orun;
k'ohun at'okan wa wipe
Amen,beni k,o ri

(2) Gbat'ese pelu etan re,
ba fe se wa n'ibi;
k'iro yipe, "Tire l'awa"
Ru etan ese ka

(3) Gbati aiye ban dun mo ni,
To si nfa okan wa
kiro yipe Tire lawa"
Le ma dun leti wa

(4) Gbati Esu ba ntafa re
Sori ailera wa
ki ro yip e Tire lawa
Ma je ki o re wa

(5) Tire nigba wa lawe
Tire nigba ndagba
Tire nigba ba darugbo
Ti aiye wa mbuse

(6) Tire titi lai lawa se
A fara wa fun o
Titi aiye ainipekun
Amin beni kori (AMIN)

1 Like

Re: Yoruba Hymn by obasolape(f): 4:37am On Oct 14, 2021
1. Tan ‘mole Re si wa
Loni yi Oluwa;
Fi ara Re han wa
N’nu oro mimo Re;
Jo m’okan wa gbona,
K’ a ma wo oju Re,
K’ awon ‘mode le ko
Iyanu ore Re.

2. Mi si wa Oluwa,
Ina Emi Mimo,
K’ a le fi okan kan
Gbe oruko Re ga;
Jo fi eti igbo,
At’ okan ironu,
Fun awon ti a nko,
L’ ohun nla t’ O ti se.

3. Ba ni so, Oluwa,
Ohun to ye k’ a so,
Gege bi oro Re,
Ni ki eko wa je;
K’ awon agutan Re,
Le ma mo ohun Re,
Ibit’ O nto won si,
Ki nwon si le ma yo.

4. Gbe ‘nu wa, Oluwa,
K’ife Re je tiwa,
Iwo nikan lao fi
Ipa wa gbogbo sin;
K’ iwa wa je eko,
Fun awon omo Re,
K’o si ma kede Re,
Ninu gbogbo okan. Amin.

1 Like

Re: Yoruba Hymn by obasolape(f): 5:16am On Jun 27, 2023
1. B'eru ese re ba nwo o lorun,
Pe Jesu wole okan re;
B'o nd'aniyan isoji okan re,
Pe Jesu wole okan re,

Le 'yemeji re sonu,
Ba Oluwa re laja;
Si okan re paya fun,
Pe Jesu wole okan re.

2. Bi o ba nwa iwenumo kiri,
Pe Jesu wole okan re;
Omi 'wenumo ko jina si o,
Pe Jesu wole okan re.

3. B'igbi wahala ba ngba o kiri
Pe Jesu wole okan re;
B'afo ba wa ti aye ko le di,
Pe Jesu wole okan re

4. Bi ore t'o gbekele ba da o
Pe Jesu wole okan re;
On nikan ni Olubanidaro,
Pe Jesu wole okan re,

5. B'o nfe korin awon olubukun
Pe Jesu wole okan re,
Bi o nfe wo agbala isimi,
Pe Jesu wole okan re.

'Yemeji mi ti fo lo,
Mo b'Olorun mi laja,
Mo s'okan mi paya fun,
Jesu ti wole okan mi. Amin.

1 Like

Re: Yoruba Hymn by obasolape(f): 6:15am On Jun 29, 2023
1. K’ A to sun, Olugbala wa,
Fun wa n’ ibukun ale;
A jewo ese wa fun O,
Iwo l’o le gba wa la.
Bi ile tile su dudu,
Okun ko le se wa mo;
Iwo Eniti ki s’are
Nso awon enia Re.

2. B’ iparun tile yi wa ka,
Ti ofa nfo wa koja,
Awon angeli yi wa ka,
Awa o wa lailewu.
Sugbon b’ iku ba ji wa pa,
T’ ibusun wa d’ iboji,
Je k’ ile mo wa s’ odo Re
L’ ayo at’ Alafia.

3. Ni irele, a f’ ara wa
Sabe abo Re, Baba;
Jesu, ‘Wo t’o sun bi awa,
Se orun wa bi Tire.
Emi Mimo, rado bow a,
So wa l’ okunkun oru,
Tit’ awa o fi ri ojo
Imole aiyeraiye.

1 Like

Re: Yoruba Hymn by obasolape(f): 11:26am On Jul 08, 2023
Jesu mo wa sodo Re

1. f JESU mo wa sodo Re,
Je ki nle ma to O lehin
Bi 'ni mi gbogbo po si
Ti ero mi gbogbo soji.

Egbe: E yin logo, eyin Mimo
E f'ope fun Baba loke
Da wa si l'egbe Serafu,
Ni kehin gba okan wa la.

2. mf Keferi, Imale, e wa
Onigbagbo, ma kalo
K'a jo yin Olorun wa,
K'a le d'ade ni 'kehin.

Egbe: E yin logo, etc

3. mf A dupe lowo Olorun
T'o fi Jesu Kristi fun wa
Lati ra araiye pada,
Lowo ese at'Esu.

Egbe: E yin logo, etc

4. mf Egbe Serafu damure
Egbe Kerubu kun f'adura
Olugbala yio gba wa la
Oluwosan yio wo wa san.

Egbe: E yin logo, etc

5. Nigbati 'pe kehin ba dun
Jesu y'o ko wa de Kenaani,
Je ka l'ayo lodo Re
Fi wa s'agbala itura.

Egbe: E yin logo, etc

6. E f'ogo fun Baba loke
E f'ofo fun Omo pelu
E f'ogo fun Emi Mimo
Metalokan lope ye fun.
Egbe: E yin logo, etc Amin

1 Like

Re: Yoruba Hymn by orisa37: 11:20pm On Jul 08, 2023
NI PA IFE OLUGBALA KI YO SI NKAN.
BY THE LOVE OF LORD OUR SAVIOUR THERE'S NO FEAR.
Re: Yoruba Hymn by obasolape(f): 11:18pm On Jul 15, 2023
Yin Olorun Abra’am (Yoruba Hymn)
May 5, 2021 by Mayowa Leave a Comment

1. Yin Olorun Abra’am
Ti O njoba l’oke
Enit’o ti wa titi lai
Olorun ‘fe “Jehofa nla l’Emi”
Gbogbo eda jewo
Mo f’ibukun f’Oruko Re
Titi lailai

2. Yin Olorun Abra’am
Nip’ase Eniti
Mo dide, mo si wa ‘tunu
Lowo ‘tun Re Mo ko aiye sile
Ogbon at’ola re
On nikan si ni ipin mi
At’asa mi

3. On na ti seleri
Mo gbekele eyi
Ngo fi iye idi goke
Lo si orun, Ngo ma wo oju Re
Ngo si yin ipa Re
Ngo korin ‘yanu t’or’ofe
Titi lailai

4. B’agbara eda pin
T’aiye at’esu nde
Ngo dojuko ona Kenaan
Nip’ase Re, Ngo re odo koja
Bi Jesu wa lokan
Ngo k’oja n’nu igbo didi
Lo s’ona mi

5. Oba oke orun
Olor’angeli nke
Wipe “Mimo, mimo, mimo”
Oba titi
Eniti ki pada
Ti y’o si wa lailai
Jehofa, Baba, “Emi ni”
Awa nyin O

6. Gbog’ egbe asegun
Nyin Olorun l’oke
Baba, Omo at’Emi ni
Nwon nke titi
Yin Olorun Abra’am
Ngo ba won korin na
Tire l’agbara at’ola, Pelu iyin
Re: Yoruba Hymn by obasolape(f): 4:58am On Jul 26, 2023
ORE WO L’ANI BI JESU
ORE WO L’ANI BI JESU
Ore wo l’ani bi Jesu, ti o ru banuje wa!
Anfani wo lo po bayi lati ma gbadura si!
Alafia pupo l’a nsonu, a si ti je rora po,
Tori a ko fi gbogbo nkan s’adura niwaju re.

Idanwo ha wa fun wa bi? A ha nni wahala bi?
A ko gbodo so ’reti nu; sa gbadura si Oluwa.
Ko s’oloto orebi re ti ole ba wa daro,
Jesu ti mo ailera wa; sa gbadura s’Oluwa.

Eru ha nwo wa l’orun bi, aniyan ha po fun wa?
Olugbala je abo wa, sa gbadura s’Oluwa.
Awon ore ha sa o ti? Sa gbadura s’Oluwa.

Yo gbe o soke lapa re, Iwo yo si ri itunu


WHAT A FRIEND WE HAVE IN JESUS

1. WHAT a friend we have in Jesus,
All our sins and griefs to bear;
What a privilege to carry
Ev’rything to God in prayer.
Oh, what peace we often forfeit,
All because we do not carry
Ev’rything to God in prayer.

2. Have we trials and temptations?
Is there trouble anywhere?
We should never be discouraged,
Take it to the Lord in prayer.
Can we find a Friend so faithful.
Who will all our sorrows share?
Jesus knows our ev’ry weakness,
Take it to the Lord in prayer.

3. Are we weak and heavy laden,
Cumbered with a load of care?
Precious Saviour, still our refuge,-
Take it to the Lord in prayer.
Do thy friend despise , forsake thee?
Take it to the Lord in prayer:
In His arms He’ll take and shield thee,
Thou wilt find a solace there.

1 Like

Re: Yoruba Hymn by obasolape(f): 12:11pm On Jul 29, 2023
ITAN IYANU T’IFE !

1. Itan iyanu t’ife ! So fun mi l’ekan si
Itan iyanu t’ife E gbe orin na ga !
Awon angeli nroyin re Awon oluso si gbagbo
Elese, iwo ki yo gbo Itan iyanu t’ife

Iyanu ! Iyanu ! Iyanu ! Itan iyanu t’ife

2. Itan iyanu t’ife B’iwo tile sako
Itan iyanu t’ife Sibe o npe loni
Lat’ori oke kalfari Lati orisun didun ni
Lati isedale aye Itan iyanu t’ife

3. Itan iyanu t’ife Jesu ni isimi
Itan iyanu t’ife Fun awon oloto
To sun ni ile nla orun Pel’awon to saju wa lo
Won nko orin ayo orun Itan iyanu t’ife. Amin.
Re: Yoruba Hymn by obasolape(f): 3:27am On Aug 10, 2023
1. ISUN kan wa t’o kun f’eje
O yo n’iha jesu,
Elese mokun ninu re,
O bo ninu ebi.

2. ‘Gba mo f’igbagbo r’isun na,
Ti nsan fun ogbe Re,
Irapada d’orin fun mi
Ti ngo ma ko titi.

3. Ninu orin t’odun julo,
L’emi o korin Re:
‘Gbat’ akololo ahon yi
Ba dake n’iboji.

4. Mo gbagbo p’O pese fun mi
(Bi mo tile s,aiye )
Ebun ofe t’a f’eje ra,
Ati duru wura.

5. Duru t’a tow’ Olorun se,
Ti ko ni baje lai;
T’a o ma fi yin Baba wa,
Oruko Re nikan.
Re: Yoruba Hymn by obasolape(f): 3:49am On Aug 10, 2023
ITAN IYANU T’IFE !

1. Itan iyanu t’ife ! So fun mi l’ekan si
Itan iyanu t’ife E gbe orin na ga !
Awon angeli nroyin re Awon oluso si gbagbo
Elese, iwo ki yo gbo Itan iyanu t’ife

Iyanu ! Iyanu ! Iyanu ! Itan iyanu t’ife

2. Itan iyanu t’ife B’iwo tile sako
Itan iyanu t’ife Sibe o npe loni
Lat’ori oke kalfari Lati orisun didun ni
Lati isedale aye Itan iyanu t’ife

3. Itan iyanu t’ife Jesu ni isimi
Itan iyanu t’ife Fun awon oloto
To sun ni ile nla orun Pel’awon to saju wa lo
Won nko orin ayo orun Itan iyanu t’ife.

Iyanu ! Iyanu ! Iyanu ! Itan iyanu t’ife

Amin.

1 Like

Re: Yoruba Hymn by Negroid001(m): 5:11pm On Aug 10, 2023
obasolape:
ITAN IYANU T’IFE !

1. Itan iyanu t’ife ! So fun mi l’ekan si
Itan iyanu t’ife E gbe orin na ga !
Awon angeli nroyin re Awon oluso si gbagbo
Elese, iwo ki yo gbo Itan iyanu t’ife

Iyanu ! Iyanu ! Iyanu ! Itan iyanu t’ife

2. Itan iyanu t’ife B’iwo tile sako
Itan iyanu t’ife Sibe o npe loni
Lat’ori oke kalfari Lati orisun didun ni
Lati isedale aye Itan iyanu t’ife

3. Itan iyanu t’ife Jesu ni isimi
Itan iyanu t’ife Fun awon oloto
To sun ni ile nla orun Pel’awon to saju wa lo
Won nko orin ayo orun Itan iyanu t’ife.

Iyanu ! Iyanu ! Iyanu ! Itan iyanu t’ife

Amin.

I love this song
Re: Yoruba Hymn by obasolape(f): 4:23am On Aug 23, 2023
FI IYIN FUN JESU OLURAPADA WA

1. Fi iyin fun Jesu, Olurapada wa,
Ki aye k’okiki ife Re nla ;
Fi iyin fun ! eyin Angeli ologo,
F’ola at’ogo fun oruko re,
B’olu’agutan, Jesu y’o to omo Re
L’apa Re l’o ngbe won le l’ojojo
Eyin eniyan mimo ti ngb’oke Sion
Fi iyin fun pelu orin ayo

2. Fi iyin fun, Jesu Olurapada wa,
Fun wa, O t’eje Re sile, O ku
On ni apata, ati reti ‘gbala wa,
Yin Jesu ti a kan m’agbelebu;
Olugbala t’O f’ara da irora nla
Ti a fi ade egun de lori
Eniti a pa nitori awa eda
Oba ogo njoba titi laelae.

3. Fi iyin fun, Jesu Olurapada wa
Ki ariwo iyin gba orun kan
Jesu Oluwa njoba lae ati laelae,
Se l’oba gbogb’eyin alagbara
A segun iku; fi ayo royin na ka
Isegun re ha da, isa oku?
Jesu ye ko tun si wahala fun wa mo
‘tori O l’agbara lati gbala. Amin.
Re: Yoruba Hymn by obasolape(f): 7:09am On Aug 24, 2023
B’ORUKO JESU TI DUN TO

1. B’oruko Jesu ti dun to,
ogo ni fun Oruko Re
o tan banuje at’ogbe
ogo ni fun oruko Re

ogo f’oko Re, ogo f’oko Re
ogo f’oruko Oluwa
ogo f’oko Re, ogo f’oko Re
ogo f’oruko Oluwa

2. O wo okan to gb’ogbe san
Ogo ni fun oruko Re
Onje ni f’okan t’ebi npa
Ogo ni fun oruko Re

3. O tan aniyan elese,
Ogo ni fun oruko Re
Ofun alare ni simi
Ogo ni fun oruko Re

4. Nje un o royin na f’elese,
Ogo ni fun oruko re
Pe mo ti ri Olugbala
Ogo ni fun oruka Re.
Re: Yoruba Hymn by obasolape(f): 3:05am On Aug 28, 2023
“lba mase pe Oluwa ti o ti wa ni tiwa”
- Ps. 124:1

1. lBASE p’Oluwa
Ko ti wa ni tiwa
Lo ye k’awa ma wi
Nigbat’ese gbogun tiwa.

Egbe: Ope ni f'Oluwa
Oba wa Olore
A ke kabiyesi
A f'ope fun Jehofa
T'o gba wa Iowo ota,
A dupe Oluwu.

2. Nwon ‘ba bo wa mole
Pelu agbara won,
Ope ni f ’Oluwa,
Ti ko jeki t’esu bori.
Egbe: Ope ni f'Oluwa...

3. Okan wa yo b'eiye
Nin' okun apeiye
Okun ja, awa yo,
E yo Jesu da wa sile.
Egbe: Ope ni f'Oluwa...

4. Tire ni Oluwa
Lati gbe wa leke
Gbogbo awon ota,
T'o wu ko tile yi wa ka.
Egbe: Ope ni f'Oluwa...

5. Ara f ’okan bale
Sodo Olugbala
B’esu ti gbon to ni,
Ko to kini kan fun Jesu.
Egbe: Ope ni f'Oluwa...

6. Iranlowo wa mbe
L'Oruko Oluwa
T’O d’orun on aiye
Oba awon eni Mimo.
Egbe: Ope ni f'Oluwa...

7. Ogo fun Baba wa,
Ogo fun Omo Re,
Ogo f’Emi Mimo
Metalokan jo gbo tiwa.
Egbe: Ope ni f'Oluwa

Oba wa Olore
A ke kabiyesi
A f'ope fun Jehofa
T'o gba wa Iowo ota,
A dupe Oluwu. Amin

1 Like

Re: Yoruba Hymn by obasolape(f): 4:50am On Sep 12, 2023
B’o ti dun lati gba Jesu

Bi iwo ba gbagbo, iwo o ri ogo Olorun. Jn. 11:40

1. B’o ti dun lati gba Jesu
Gbo gegebi oro Re;
K’a simi lor’ ileri Re,
Sa gbagbo l’Oluwa wi

Jesu, Jesu, emi gbagbo,
Mo gbekele n’gbagbogbo,
Jesu, Jesu, Alabukun
Ki nle gbekele O si.

2. B’o ti dun lati gba Jesu,
K’a gb’eje ‘wenumo Re
Igbagbo ni ki a fi bo
Sin ‘eje wenumo na.

3. B’o ti dun lati gba Jesu,
Ki nk’ara ese sile,
Ki ngb’ayo, iye, isimi
Lati odo Jesu mi.

4. Mo yo mo gbeke mi le O,
Jesu mi, Alabukun;
Mo mo pe O wa pelu mi,
Ntoju mi titi dopin.
Amin.

Tis so sweet to trust in Jesus

If thou wouldest believe, thou shouldest see the glory of God. John.11:40

1. 'Tis so sweet to trust in Jesus,
Just to take Him at His word:
Just to rest upon His promise:
Just to know, 'Thus saith the Lord.

Jesus, Jesus, how I trust Him!
How I've proved Him o'er and o'er
Jesus, Jesus, precious Jesus!
O for grace to trust Him more!

2. O how sweet to trust in Jesus,
Just to trust His cleansing blood;
Just in simple faith to plunge me
'Neath the healing, cleansing flood!

3. Yes, ‘tis sweet to trust in Jesus,
Just from sin and self to cease;
Just from Jesus simply taking
Life and rest, and joy and peace.

4. I'm so glad I learn'd to trust Thee
Precious Jesus, Saviour, Friend;
And I know that Thou art with me,
Wilt be with me to the end.

Amen.
Re: Yoruba Hymn by siant: 9:34pm On Sep 17, 2023
'Gbogbo won SI Kun fun Emi-Mimo.' Ise Aposteli 2:4.


Baba wa orun, awa de
Awa alailagbara,
Ran Emi-Mimo Re SI wa
Ko so gbogbo wa d'otun

Wa Emi-Mimo Jare wa,
F'ede titun s'okan wa,
Ebun nla Re n ni la n toro,
T'ojo nla pentecost.

Ranti ileri Re, Jesu,
Tu Emi- Re s'ara wa
Fi alafia Re fun wa
T'aye ko Le fi funii
Wa Emi- Mimo jare wa
Pa ese run l'okan wa
Ebun nla Re n ni la n toro
T'ojo nla pentecost.

Adaba orun, sokale
F'owo ife yi wa ka,
Ki gbogbo orile ede
Teriba f'Olugbala
Ka gburo Re jakejado
Ile okunkun wa yi,
Ebun nla Re la n toro
T'ojo nla pentecost
Re: Yoruba Hymn by obasolape(f): 7:25am On Sep 21, 2023
1. N‘nu gbogbo ayida aye
Ayo on wahala;
Iyin Olorun ni y‘o ma
Wa l‘enu mi titi

2. Gbe Oluwa ga pelu mi,
Ba mi gb‘oko Re ga:
N‘nu wahala, ‘gba mo ke pe
O si yo mi kuro

3. Ogun Olorun wa yika
Ibugbe Oloto;
Eniti o ba gbekele,
Yio ri igbala

4. Sa dan ife Re wo lekan
‘Gba na ‘wo o mo pe,
Awon t‘o di oro Re mu
Nikan l‘eni ‘bukun

5. E beru Re, eyin mimo,
Eru miran ko si;
Sa je ki ‘sin Re j‘ayo yin
On y‘o ma toju yin

Amin.

(1) (2) (Reply)

True Definition Of Sin. / What Would You Do If You Missed The Rapture? / Do You Believe In Fate?

(Go Up)

Sections: politics (1) business autos (1) jobs (1) career education (1) romance computers phones travel sports fashion health
religion celebs tv-movies music-radio literature webmasters programming techmarket

Links: (1) (2) (3) (4) (5) (6) (7) (8) (9) (10)

Nairaland - Copyright © 2005 - 2024 Oluwaseun Osewa. All rights reserved. See How To Advertise. 82
Disclaimer: Every Nairaland member is solely responsible for anything that he/she posts or uploads on Nairaland.