Welcome, Guest: Register On Nairaland / LOGIN! / Trending / Recent / NewStats: 3,162,459 members, 7,850,600 topics. Date: Wednesday, 05 June 2024 at 05:28 AM |
Nairaland Forum / Entertainment / Literature / Ewi Yoruba (4364 Views)
(1) (Reply)
Ewi Yoruba by fatigs88: 4:05pm On Nov 22, 2015 |
AGBA BI OMODE - Ayoola omo Fadeyi Agba bi omode Bi e ri eni to fi opa tele To soro omugo Omode ni Agba kii soro omugo Bi e wa ri abirun funfun lori To n fi ewu ori se bi ajunilo To n fi ese janle kiri ladugbo Omode ni Pelu suru lagba fi n lo Omode bi agba Bi e ri eniyan to soro atata lenu Oro ologbon, onilaakaye Bose omode loju yin Agba ni Bi e ri abirun dudu lori To soro atata Agba ni Ooto ni Owo to fun agba A bere terin pelu opa A fi akamu je moinmoin sun Agba onirun funfun lori Ooto ni Ohun agba ri nikale Bomode garun lori ile oni-peteesi Ko to be kori i Agba ojo ori wa Agba onilaakaye n be Seri awon agba olojo ori Awon ni won n mu emu takiti kiri ilu Awon ni ko le tole won gunrege Agbere o fi won sile nigba kankan Gbogbo ise ibi, owo won lo kun mo Bi a ba dagba, a yee ogun ja Ko ni ti won Won a so agbado modi, adie a si maa le won kiri Wan tu tiri ko lafi n mo agba O le se pataki niha ibi kan Kii se gbogbo ibi Bomode olojo ori bafe dagba onilaakaye O to, ki o bowo fun agba olojo ori O to, ki o bowo fun agba onilaakaye Won a pe aadorin odun Won a tun maa le omoomo won kiri ladugbo Fun fife ko, agbere ponbele ni Won a ni omoataye nile Iya a je iyawo atomo Owo ko lo tan nile Tabi ise lo safeku Oti ati burandi lo n dara Oti ti poju oka won lo Ohun laso fi n pon mo won lara Eyin agba, e se bi agba E huwa agba Ki e le baa ko awon omo yin jen pepepe Enu agba lobi n gbosi Ki awon omode, ma tete mo iyi yin Tani ko fe dagba tooto? Tani ko fe dagba onilaakaye? Agba to mo ojuse Ki n ma dagba iranu, agba iya Ki n ma dagba osi, agba bi omode Mo seba agba Mo juba agba. --------------------------------- #AyF™ ©2015 |
Re: Ewi Yoruba by fatigs88: 12:50pm On Dec 07, 2015 |
OGILINTI - Ayoola omo Fadeyi Ogilinti de, afefe tutu de Orun an lodun, ooru mu Ojo ro lodun, otutu mu Ogilinti n dara, ategun tutu je Orun to ran nibere odun Lomu kii aso gbe labe ooru Oye to n ja nipari odun Lomu ki aso gbe labe otutu Ninu ogilinti, ina ya jo Ninu oye, aso ya gbe Ninu ogilinti, ara ya tutu Ninu oye, tii gbona ya mu Okugbe rise se lasiko Ogilinti loku ti yoo paro mo Akekoo ti o le we l'owuri kutukutu Oye yoo ran lowo d'oba Bi ikoko r'oye, inu ikoko a dun sinkin Oye kii mu ikoko Bi agba r'oye, agba a fojuro Aleyin laya ni oye n se lose Inu oye ni gbogbo ile ti n tutu bi yinyin Gbogbo ile wa di ile oluwere Ti a n ba ni tutututu Omi odo ti wole towo wa lona afefe yeye Adin agbon rise se Bi ko se ete, a se oju Ete gbigbe, oju funfun balau E ba mi gbe adin olororo ki n rihun fi para Bi afefe fe, afefe tutu Bi orun ran, orun tutu Bi osupa tan, osupa tutu Bi irawo yo, irawo tutu Ogilinti gbe kata de Gbogbo ilu lo n fimu Eni mumu tutu ninu ogilinti se'rare pa O digba omi tutu dekun ko to mo 'ki lo n se le' Eyin agbe, e rora fina s'oko papa lasiko ogilinti Oko papa a maa jo, a jo rohin rohin Eyin dereba, e tee jeje lori popo Ara n kan ategun, ara n kan betiro E ba mi m'aso idabora ki oye ma baa gbe mi lo Eruku Osodi kun'le kun'ko Eruku Osodi kun'ko kun'le Oye ogilinti, ogilinti oye #AyF™ ©2015 |
Re: Ewi Yoruba by fatigs88: 9:36am On Dec 14, 2015 |
fatigs88: Ki ogilinti odun yii tuwa lara, t'eru t'omo. |
(1) (Reply)
Impregnate Me Or I Die (episode 9) / Any Poetry Contest Sites 'round : / [teachers Day Dp]™ Happy Teachers Day 2016 Dp, Hd Images, Profile Pic For Fb Cov
(Go Up)
Sections: politics (1) business autos (1) jobs (1) career education (1) romance computers phones travel sports fashion health religion celebs tv-movies music-radio literature webmasters programming techmarket Links: (1) (2) (3) (4) (5) (6) (7) (8) (9) (10) Nairaland - Copyright © 2005 - 2024 Oluwaseun Osewa. All rights reserved. See How To Advertise. 28 |