₦airaland Forum

Welcome, Guest: RegisterLoginWith GoogleTrendingRecentNew

Stats: 3,331,090 members, 8,448,603 topics. Date: Monday, 20 July 2026 at 03:13 PM

Toggle theme

Obasolape's Posts

Nairaland ForumObasolape's ProfileObasolape's Posts

1 2 3 4 5 6 7 (of 7 pages)

Christianity EtcRe: Yoruba Hymn by obasolape(op): 4:02am On Jul 07, 2021
A F’OPE F’OLORUN

1. A f’ope f’olorun
L’okan ati l’ohun wa
Eni s’ohun ‘yanu
N’nu eni t’araye nyo
‘gbat’a wa l’om’owo
On na l’o ntoju wa
O si nf’ebun ife
Se ‘toju wa sibe.

2. Oba Onib’ore
Ma fi w asile laelae
Ayo ti ko l’opin
On ‘bukun y’o je ti wa
Pa wa mo n’nu ore
To wa, gb’a ba damu
Yo wa ninu ibi
L’aye ati l’orun

3. K’a f’iyin on ope
F’Olorun, Baba, Omo
Ati Emi mimo
Ti O ga julo lorun
Olorun kan laelae
T’aye at’orun mbo
Be l’o wa d’isiyi
Beni y’o wa laelae.
Christianity EtcRe: Yoruba Hymn by obasolape(op): 4:02am On Jul 07, 2021
1. Eje k’a f’inu didun
Yin Oluwa Olore
Anu Re O wa titi
Lododo dajudaju

2. On nipa agbara Re
F’imole s’aye titun
Anu Re, O wa titi
Lododo dajudaju

3. O mbo gbogb’eda ‘laye
O npese fun aini won
Anu re, O wa titi
Lododo dajudaju

4. O bukun ayanfe Re
Li aginju iparun
Anu re O wa titi
Lododo dajudaju

5. E je k’a f’inu didun
Yin Oluwa Olore
Anu Re, O wa titi
Lododo dajudaju. Amin.
Christianity EtcRe: Yoruba Hymn by obasolape(op): 4:01am On Jul 07, 2021
Mo ti ni Jesu lore
O j'ohun gbogbo fun mi
Oun nikan larewa ti okan mi fe
Oun nitanna ipado
Oun ni Enikan naa
To le we mi nu kuro nin'ese mi
Olutunu mi lo je ni gbogbo wahala
Oun ni ki n kaniyan mi l'Oun lori
Oun n'Itanna Ipado
Irawo Owuro
Oun nikan l'Arewa ti okan mi fe

Olutunu mi lo je ni gbogbo wahala
Oun ni ki n kaniyan mi l'Oun lori
Oun n'Itanna Ipado
Irawo Owuro
Oun nikan l'Arewa ti okan mi fe

O gbe gbogbo banuje
At'irora mi ru
O j'Odi agbara mi n'gba danwo
Tori Re mo k'ohun gbogbo
Ti mo ti fe sile
O si f'agbara Re gbe okan mi ro
Bi aye tile ko mi
Ti Satan' dan mi wo
Jesu yoo mu mi d'opin irin mi
Oun n'Itanna ipado
Irawo Owuro
Oun nikan l'Arewa ti okan mi fe

Oun ki yo fi mi sile
Be ki yo ko mi nihin
Niwon ti m'ba figbagbo pofin Re mo
O jodi ina yi mi ka
N k'y'o beru-keru
Y'o fi manna Re bokan mi t'ebi npa
Gba m'ba dade n'ikehin
N o roju 'bukun Re
Ti adun Re y'o ma san titi lai
Oun n'Itanna ipado
Irawo Owuro
Oun nikan l'Arewa ti okan mi fe
Christianity EtcRe: Yoruba Hymn by obasolape(op): 6:02am On Jun 29, 2021
A o kọja lọ bi àwọn 'rawọ òórọ̀
T' ìmọ́lẹ̀ wọn n ran n'nu oorun ogo,
Bẹ́ẹ̀ l' a o lọ kúrò l' aye ati 'ṣẹ rẹ̀,
A o maa ranti wa nip' on t' a ti ṣe.

ÈGBÈ:
Wọn yoo ṣe 'ranti, wọn yoo ṣe 'ranti,
A o maa ranti wa nip' on t' a ti ṣe,
Bẹ́ẹ̀ l' a o lọ kúrò l' aye ati 'ṣẹ rẹ̀,
A o maa ranti wa nip' on t' a ti ṣe.

2. A o ha kuro k' àwọn miran rọ́pò wa,
Lati maa kore oko t' a ti gbìn?,
Bẹ́ẹ̀ l' àwọn òṣìṣẹ́ yoo fi 'ṣẹ́ sílẹ̀,
A o maa ranti wa nip' on t' a ti ṣe.

3. Kìkì òótọ́ ti a ba ti sọ láyé,
Pẹ̀lú 'rúgbìn t' a ti gbìn laye yii,
Yoo tẹ̀síwájú t' a ba ti gbàgbé wa,
Eso ikore at' on t' a ti ṣe.

4. 'Gbà t' Olúwa yoo k' àwọn ayanfẹ Rẹ̀,
T'ao jere adé aláyọ̀ t' ó ntàn,
'Gba naa l' ao ranti àwọn olootọ Rẹ̀,
T' àárẹ̀ ti mu nip' on ti wọ́n ti ṣe.
Christianity EtcRe: Yoruba Hymn by obasolape(op): 6:00am On Jun 29, 2021
1. WA k’ a da m’ awon ore wa
Ti nwon ti jere na;
N’ ife k’ a f’ okan ba won lo
S’ ode orun lohun.

2. K’ awon t’ aiye d’ orin won mo,
T’ awon t’ o lo s’ ogo;
Awa l’ aiye, awon l’ orun,
Okan ni gbogbo wa.

3. Idile kan n’nu Krist’ ni wa,
Ajo kan l’a si je;
Isan omi kan l’o yaw a,
Isan omi iku.

4. Egbe ogun kan t’Olorun
Ase Re l’a sin se;
Apakan ti wo ‘do na ja,
Apakan nwo lowo!

5. Emi wa fere dapo na,
Y’o gb’ade bi ti won;
Ao yo s’ami Balogun wa,
Lati gbo ipe Re.

YBH 311

WA k’ a da m’ awon ore wa

6. Jesu, so wa, s’amona wa,
Gbat’oniko ba de;
Oluwo, pin omi meji,
Mu wa gunle l’ayo.
Christianity EtcRe: Post Your Favourite Christian Hymns by obasolape(f): 9:39pm On Jan 26, 2020
Eni Oluwa se l'ore o ko na' wo soke
O semi ooo, O se mi o,
Mo dupe l'owo o, Jesu Olugbala,
Aleluya mo wa dupe
Eniyan lo kole alaja mefa, to jade laiye
Mo dupe lowo o Jesu Olugbala
Christianity EtcRe: Post Your Favourite Christian Hymns by obasolape(f): 9:37pm On Jan 26, 2020
Emi yio Yin Oluwa Oba rere to nseke mi
Emi yio Yin Oluwa Oba rere to nseke mi
Ma fohun mi Yin o
Baba mi
Ma fijo mi Yin
Ma fohun mi Yin o
Baba mi
Ma fijo mi Yin
Ma jo roun roun
Ma jo roun roun
Ma takoto Ori Ile
Ma jo roun roun
Christianity EtcRe: Post Your Favourite Christian Hymns by obasolape(f): 9:36pm On Jan 26, 2020
Olorun to tobi
Olorun Baba Agba
Aye o gba o
O f'orun se ibugbe
Aye o gba o
O f'orun se ibujoko
Olorun to tobi
Olorun Baba Agba
Christianity EtcRe: Post Your Favourite Christian Hymns by obasolape(f): 5:47am On Jan 20, 2020
Mo yo pipo pe Baba wa orun
So t'ife Re ninu 'we t'o fun mi,
Mo r' ohun 'yanu ninu Bibeli,
Eyi sowon ju pe Jesu fe mi,

Egbe
Mo yo pipo pe Jesu fe mi,
Jesu fe mi, Jesu fe mi,
Mo yo pipo pe Jesu fe mi,
Jesu fe an' emi.

Gba mo gbagbe Re, ti emi salo
O fe mi sibe, O wa mi kiri,
Mo yara pada s' apa anu Re,
'Gbati mo ranti pe Jesu fe mi.
Bi o se orin kan l' emi le o,

'Gba mo r' oba nla ninu ewa Re,
Eyi yio ma j'orin mi titii,
A! iyanu nip e Jesu fe mi.
Jesu fe mi mo si mo pe mo fe E,

Ife l'o mu wa r' okan mi pada,
Ife lo m' U ko ku l' ori igi,
O da mi loju pe Jesu fe mi.
Emi o ti se dahun b' a bi mi

Ohun ti Ogo Oluwa mi je?
Emi Mimo njeri nin' okan mi,
Ni igbagbo pe Jesu fe mi.
Ni gbekele yi mo r' isimi,

Ni gbekele Krist, mo d' alabukun,
Satan damu sa kuro l' okan mi,
Nigba mo so fun pe Jesu fe mi.
Source: Yoruba Baptist Hymnal #335
Christianity EtcRe: Post Your Favourite Christian Hymns by obasolape(f): 5:43am On Jan 20, 2020
Ore bi jesu kosi laye yi
Oun nikan l'ore otito
Ore aye yi le fi wa sile
Sugbon Jesu ko je gbagbe wa

Ah! Ko je gbagbe wa/ 2ce
Sugbon Jesu ko je gbagbe wa

Akoko nkoja lo laifotape
A f ojo kan sunmole wa si
Onidajo mbo gongo yio so
Awawi kan kosi l ojo na

Duro d'Oluwa, ma siyemeji
Ohunkohun t' o wu ko le de
Gbat o ro p'o pin ranwo Re y'o de
Eni yanu l oba Oluwa
Christianity EtcRe: Post Your Favourite Christian Hymns by obasolape(f): 5:27am On Jan 19, 2020
1. Jeovah onibuore, rojo ibukun Mana re
sori awa ayanfe re larin wakati yi
Ibukun taye kole fifun ni
Ire to so okun di ona fun awon omo Israel
wa la ona ibukun rere fun wa wa se tiwa nire.

2. Ire to pase fun awon eye iwo lati wa fi
akara ateran didun bo woli Elijah
Leba odo Jordan jowo ranti
awa ti nkepe o
ki o si fi jije ati mimu
Lona awamaridi bo awatire
Oba onibuore

3. Oba togbo ekun Elizabeth
awa omo re nwoju re
Fomo rere se'ranti wa Oba Olupese
Jesu Oba oluwosan mimo
Wa wo awa tire san
Kawa le fi Orin ayo sin o
Ninu ijo mimo re latorun wa
Olufayo fun ni. Amin.
Christianity EtcRe: Post Yoruba Christian Hymns Here by obasolape(f): 4:55am On Dec 11, 2019
Keresimesi
keresimesi de
keresimesi de
a bi Olugbala kan fun wa
nilu Bethlehem
a bi Olugbala kan fun wa
eni ti o joba aye (ayeraye)
awa si ti ri irawo re lawo sanmo
awa si wa lati mu ebun
f'oba taabi loni

Mo mu ore wa fun Oba taabi
Mo mu ore wa fun Jesu
Mo mu wura wa la t’ona jinjin rere
Ohun ti mo ni mo mu wa fun o
Jowo ma s’alai gbo pe mi

Keresimesi
keresimesi de
keresimesi de
a bi Olugbala kan fun wa
nilu Bethlehem
a bi Olugbala kan fun wa
eni ti o joba aye (ayeraye)
awa si ti ri irawo re lawo sanmo
awa si wa lati mu ebun
f'oba taabi loni

Mo mu ojia wa fun Oba taabi
Mo mu ojia wa fun Jesu
Mo mu ojia wa la t’ona jinjin rere
Ohun ti mo ni mo mu wa fun o
Jowo ma s’alai gbo pe mi

Keresimesi
keresimesi de
keresimesi de
a bi Olugbala kan fun wa
nilu Bethlehem
a bi Olugbala kan fun wa
eni ti o joba aye (ayeraye)
awa si ti ri irawo re lawo sanmo
awa si wa lati mu ebun
f'oba taabi loni

Mo mu Turari wa fun Oba taabi
Mo mu Turari wa fun Jesu
Mo mu Turari wa la t’ona jinjin rere
Ohun ti mo ni mo mu wa fun o
Jowo ma s’alai gbo pe mi

Keresimesi
keresimesi de
keresimesi de
a bi Olugbala kan fun wa
nilu Bethlehem
a bi Olugbala kan fun wa
eni ti o joba aye (ayeraye)
awa si ti ri irawo re lawo sanmo
awa si wa lati mu ebun
f'oba taabi loni
Christianity EtcRe: Yoruba Hymn by obasolape(op):
AGBARA RE GA JU T'OTA LO OO
IMO RE GA JU T'ESU LO
AGBARA RE GA JU T'OTA LO OO
IMO RE GA JU T'ESU LO -
OLORUN KO SE OUN TI NI O,
OSO AYE KOLE DI O LONA ISE RE,
AGBARA RE GA JU T'OTA LO
Christianity EtcRe: Yoruba Hymn by obasolape(op): 5:24am On Nov 12, 2019
Gbat' O ba de, gbat' O ba de
Lati sir' oso Re
Gbogbo oso Re iyebiye
Awon ti o fe

Bi Irawo owuro, nwon nsade Re loso
Ewa won o yo pupo, Ewa f'ade Re

Yio kojo, yio kojo
Oso Ijoba Re
Awon mimo awon didan
Awon ti O fe

Bi Irawo owuro, nwon nsade Re loso
Ewa won o yo pupo, Ewa f'ade Re

Awon ewe, awon ewe
To fe Olugbala
Ni oso Re iyebiye
Awon ti o fe

Bi Irawo owuro, nwon nsade Re loso
Ewa won o yo pupo, Ewa f'ade Re
Christianity EtcRe: Post Yoruba Christian Hymns Here by obasolape(f): 3:13am On Nov 05, 2019
'WO Imole! larin okun aiye,
Ma sin mi lo,
Okunkun su, mo si jina s'ile
Ma sin mi lo,
To ‘sise mi: ohun ehin ola
Emi ko bere, ‘sise Kan to fun mi.

2. Nigbakan ri, emi ko be O, pe
Ma sin mi lo,
Beni nko fe O, sugbon nigbayi,
Ma sin mi lo,
Afe aiye ni mo ti nto lehin,
Sugbon Jesu, ma ranti igbani.

3. lpa Re l'o ti ndi mi mu y‘o si
Ma sin mi lo,
Ninu ere ati yangi aiye,
Ma sin mi lo,
Titi em‘o fi ri awon won ni,
Ti mo fe, ti nwon ti f'aiye sile.

4. K'o to di ‘gba na, l'ona aiye yi
T’iwo ti rin Ma sin mi lo,
Jesu Olugbala S’ile Baba
Ki nle simi lehin ija aiye
Ninu imole ti ko nipekun. Amin
CultureRe: A Yoruba Poem- Ise Logun Ise (work Is The Antidote For Poverty) by obasolape(f): 11:53am On Oct 10, 2019
Ise ni ogun `se
Mura si ise ore mi
Ise ni afi ndeni giga
Bi ako ba reni fehinti
Bi ole la a ri
Bi a ko ba reni gbekele
A tera mose eni
Iya re le lowo lowo
Baba re si le leshin le kan
Bi o ba gboju le won
O te tan ni mo so fun o
Ohun ti a ko ba jiya fun
Se kii le tojo
Ohun ti a ba fara sise fun
Ni npe lowo eni
Apa lara
Igunpa ni iye kan
Bi aiye ba nfe o loni
Ti o balowo lowo
Won a ma fe o lola
Jeki o wa ni ipo atata
Aiye a ma ye o si terin-terin
Jeki o deni rago
Ko o ri bi aiye ti nyinmu si o
Eko si tun seni doga
Mura ki o ko dara-dara
Iya nbo fomo ti ko gbon
Ekun mbe fomo ti o nsa kiri
Ma fowuro sere ore mi
Mura si ise ojo nlo.
Christianity EtcRe: Post Yoruba Christian Hymns Here by obasolape(f):
1. Kini ni n o fole se laye timo wa
Kini ni n o fole se laye timo wa
Laye ti mo wa kaka kin jale
Kaka kin jale makuku deru.
Kini ni n o fole se laye timo wa.

2. Eni ba jale adele ejo
Eni ba jale adele ejo
Adajo awa fewon si lese
Fewon si lese bi olugbe
Eni to jale Adele ejo

3. Aye ema fole s'omo ti mo bi
Aye ema fole s'omo ti mo bi
Omo ti mo bi ewon ko sun won
Ewon ko sun won f'omoluwabi
Aye ema fole s'omo ti mobi.

4. Oluwa ma fole segbe ti mo ni
Oluwa ma fole segbe ti mo ni
Egbe ti mo ni kaka kin jale
Kaka kojale bo ba ku o to
Aye ema fole s’gbe ti mo ni.

5. Beni to jale ba Lola laye
Beni to jale ba Lola laye
Bo lola laye kole rorun wo
Kole rorun wo bolojo bade
Beni to jale Balola laye.
Christianity EtcRe: Post Yoruba Christian Hymns Here by obasolape(f): 5:46am On Sep 30, 2019
Bami gberu mi o Baba
Bami gberu mi dori
Ma se dami da bukatami o
Jesu oba iye.
Eru aye mi to wuwo bi irin
Baba wa bami gbe
Eru aye mi to n bami leru
Jesu wa fopin si
Satani lo n di kuta
Lo n dikuta seru eni to fuye
Jesu Kristi nikan la banise
To n bani gberu to wuwo
Wa so banuje mi dayo
Mama je n dero eyin
Odi Jericho ninu aye mi Baba wo wan bale
Ati mo no eda laye ko soro f'Oluwa
T 'Oluwa bati meda mono Ibanuje mati pari patapata
Wa bami gberu mi o Baba
Bami gberu mi dori
Mase da mi da bukatami o
Jesu Oba iye
Christianity EtcRe: Post Yoruba Christian Hymns Here by obasolape(f): 3:49am On Sep 26, 2019
IOM 291.
Jesu, oro Re ye
1. Jesu, oro Re ye,
O si nto ‘sise wa;
Enit’ o ba gbagbo,
Y’o l’ayo on ‘mole.
2. Nigb’ota sunmo wa,
Oro Re l’odi wa;
Oro itunu ni,
Iko igbala ni.
3. B’igbi at’okunkun
Tile bo wa mole;
‘mole re y’o o wa,
Y’o si dabobo wa.
4. Tani le so ayo,
T’o le ka isura,
Ti oro re nfi fun
Okan onirele?
5. Oro anu, o nfi
‘lera fun alaye,
Oro iye, o nfi
Itunu f’eni nku.
6. Awa iba le mo
Eko ti o nkoni,
Ki a ba le fe O,
K’ a si le sunmo O. Amin.
Christianity EtcRe: Yoruba Hymn by obasolape(op): 6:00am On Sep 06, 2019
1 Wa, ma sise,
Tani gbodo s‘ole ninu oko
‘Gbati gbogbo eniyan nkore jo,
Kaluku ni Baba pe fun ise;
“Sise loni”

2 Wa, ma sise,
Gba ‘pe giga ti angeli ko ni
Mu ‘hinrere to t‘agba t‘ewe lo,
Ra ‘gba pada, wawa l‘akoko nlo,
Ile su tan.

3 Wa, ma sise,
Oko po, alagbase ko si to,
Aye titun po fun wa lati kun,
Ohun ona jinjin, at‘itosi
Nkigbe pe; “Wa”

4 Wa, ma sise
Le ‘yemeji on aigbagbo jina,
K‘o s‘alailera ti ko le se nkan,
Ailera f‘Olorun a ma lo ju '
Fun‘se nla Re

5 Wa, ma sise,
‘Simi ko si nigbat‘ ise osan,
Titi orun yio fi WO l‘ale,
Ti awa o si gbo ohun ni pe:
“O seun, omo”

6 Wa, ma sise,
Lala na dun ere re si daju,
‘Bukun f‘awon t‘o fori ti d‘opin
Ayo won, ‘simi won y‘o ti po to!
“Lo d‘ Oluwa”
Amin.
Christianity EtcRe: Yoruba Hymn by obasolape(op): 5:56am On Sep 06, 2019
Krist' ki 'joba Re de,
Ki ase Re bere;
F' opa-rin Re fo
Gbogbo ipa ese.

Ijoba ife da,
Ati t' Alafia?
Gbawo ni irira
Yio tan bi t'orun?

Akoko na ha da,
T' ote yio pari,
Ika at' ireje,
Pelu ifekufe?

Oluwa joo, dide,
Wa n'nu agbara Re;
Fi ayo fun awa
Ti o nsaferi Re

Eda ngan ooko Re,
'Koko nje agbo Re;
Iwa 'tiju pupo
Nfihan pe 'fe tutu.

Ookun bole sibe,
Ni ile keferi:
Dide 'Rawo ooro,
Dide, mase wo mo.
Amin.
Christianity EtcRe: Yoruba Hymn by obasolape(op): 5:54am On Sep 06, 2019
Omije oju mi n bere aanu Re... Baba
Omije oju mi n bere aanu Re... Baba
Fi aso oju rere womi Olorun mi
Araye nreti ohun ti mamubo lodo re Baba mimo
Odun yi nlo o Odun yi nlo
Omije oju mi nbere aanu Re o
Christianity EtcRe: Share Your Best Hymns by obasolape(f): 5:23am On Jul 06, 2019
"Iwo ki ise eru mo, Iwo di arole Olorun nipase Kristi" - Gal. 4:7

1. EWE ti Oba orun,
Korin didun be ti nlo
Korin ‘yin Olugbala
Ologo ‘nu ise Re.

Egbe: A nlo ‘le sodo Olorun
Lona t'awon Baba rin
Nwon si nyo: nisisiyi
Ayo won l'awa o ri.

2. A nlo sodo Olorun
Lona t'awon Baba rin
Nwon si nyo: nisisiyi,
Ayo won l'awa o ri.

Egbe: A nlo ‘le sodo...

3. Korin agbo kekere
E o simi n'ite Re,
‘Bit'a pese 'joko nyin
Ibe si n'ijoba nyin.
Egbe: A nlo ‘le sodo...

4. W'Oke, omo imole
Ilu Sion wa lokan
Ibe n‘ile wa titi;
Ibe l'ao r'Oluwa.

Egbe: A nlo ‘le sodo...

5. Kerubu, tesiwaju
Serafu, ma jafara
Kristi Omo Baba nwi
Pe laifoiya ka ma lo.

Egbe: A nlo ‘le sodo...

6. Jesu, a nlo l'ase Re,
A ko‘hun gbogbo sile
Iwo ma j‘ amona wa,
A o si ma ba o lo.

Egbe: A nlo ‘le sodo...

7. A f’ogo fun Baba wa,
A f'ogo fun Omo Re;
Ogo ni f’Emi Mimo,
Mu wa de ‘le ayo na.

Egbe: A nlo ‘le sodo Olorun
Lona t'awon Baba rin
Nwon si nyo: nisisiyi
Ayo won l'awa o ri. Amen
Christianity EtcRe: Post Your Favourite Christian Hymns by obasolape(f): 3:58am On May 18, 2019
Oluwa iwo ni apata a mi
Eru kan ki yio ba mi
Igba ti emi ba ke pe o
Ye o dami lohun
Oluwa mi ma se ko mi sile
Ma se je kota yo mi
Igba ti imole Re ba tan sona mi
Ayo mi o ti po to

Ogo ni fun Baba
Ogo ni fun omo
Oga ni fun emi mimo
Metalokan ijinle ife

Baba mi ti soro mi fayo
Jesu Kristi modupe o seun
Gbogbo oke isoro mi ti di petele
Ha halleluyah
Christianity EtcRe: Yoruba Hymn by obasolape(op): 5:09am On Apr 01, 2019
Duro, duro fun Jesu,
Enyin om’ogun Krist:
Gbe asia Re soke
A jo’gbodo fe ku;
Lat’isegun de ’segun
Ni y’o ma to ogun Re;
Tit’ao segun gbogb’ota,
Ti krist y’o j’Oluwa

Duro, duro fun Jesu
F’eti s’ohun ipe
Jade s’ohun ipe
L’oni ojo nla Re:
Enyin akin ti nja fun
Larin ainiye ota,
N’nu ewu, e ni ’gboiya
Dojuko agbara.

Duro, duro fun Jesu,
Duro l’agbara Re
Ipa enia ko to
Ma gbekele tire:
F’ihinrere hamora
Ma sona, ma gbadura
B’ise tab’ ewu ba pe
Ma se alai de ’be.

Duro, duro fun Jesu
Ija na ki y’o pe;
Oni, ariwo ogun,
Ola, orin ’segun,
Eni t’o ba si segun,
Y’o gba ade iye
Y’o ma ba Oba Ogo
Joba titi lailai…Amin
Christianity EtcRe: Yoruba Hymn by obasolape(op): 9:20am On Mar 05, 2019
TAL'ENI naa ti n kan 'lekun okan mi(2ce)
Jesu Kristi Omo Olorun ni,
Silekun je' ko wole' lo

Tal'eni naa ti n kan 'lekun
Okan mi? (2ce)
Emi Mimo adaba orun ni,
Silekun je' ko wole lo

Tal'eni naa ti n kan 'lekun
Okan mi? (2ce)
Olupese Oba awon Oba,
Silekun je ko wole lo

Tal'eni naa ti n kan 'lekun
Okan mi? (2ce)
Olugbala Oba ayeraye,
Silekun je ko wole lo

Tal'eni naa ti n kan 'lekun
Okan mi? (2ce)
Olusegun alabo mi ni,
Silekun je ko wole lo
Christianity EtcRe: Share Your Best Hymns by obasolape(f): 4:45am On Jan 31, 2019
WA S'ADURA OORO
Verse 1
WA s'adura ooro,
Kunle k'a gbadura;
Adura ni opa Kristiani,
Lati b'Olorun rin.

Verse 2
Losan, wole labe,
Apat' ayeraye;
Itura ojiji Re dun,
Nigba t'orun ba mu.

Verse 3
Jẹ ki gbogbo ile,
Wa gbadura l'ale;
Ki ile wa di t'Olorun,
Ati 'bode orun.

Verse 4
Nigbat' od'oganjo,
Je k'a wi l'emi, pe,
Mo sun, sugbon okan mi ji
Lati ba O sona.
Christianity EtcRe: Post Yoruba Christian Hymns Here by obasolape(f): 4:23am On Dec 21, 2018
1. Tire titi lai, l’awa ‘se
Oluwa wa orun,
Tire l’ omode, tire l’ agba,
‘W’ Olorun Ife o.

Chorus:
Di wa mu, Oba Iye (2)
Si jek’a yin ‘fe Re,
K’ ohun at’ iwa wa k’o j’okan,
Amin, be ni k’o ri.

2. Tire, titi lai, l’awa ‘se
Balogun wa orun,
Pelu wa n’ b’ere at’ oju- ‘ja,
K’a ma se te s’ Ibi.

3. Tire l’ ojo t’ idamu mbe
Oluwa wa orun;
Tire nigb’ ekun ati l’ayo
Olorun ajito.

4. Tire l’ ojo t’ ireti mbe,
T’a nri je, t’o nye wa;
Tire b’ ebi de ati n’nu ‘ya,
Olorun ‘tunu yi.

5. Tire titi lai, yan fun ‘ni
Alase wa orun;
Tire l’ enu ‘se ati l’ ero,
Olorun Isegun.

6. Tire l’ ojo t’ aisan bam be
T’ a nsu won l’ agbole;
Tire bi Iku npe wa s’ Orun,
Olorun aiku yi.
Christianity EtcRe: Post Yoruba Christian Hymns Here by obasolape(f): 4:59am On Oct 10, 2018
"Lo sise loni l’ogba ajara mi" - Matt.21:28

1. WA, ma sise
Tani gbodo sole ninu oko
Gbati gbogbo enia nkore jo
'Kaluku ni Baba pase fun pe
“Sise Ioni"

2. Wa, ma sise
Gba' pe giga ti angeli ko ni
Mu hinrere to t‘agba t’ewe lo
Ra gba pada, wawa l’a akoko nlo
Ile su tan.

3. Wa, ma sise
Oko po, alagbase ko si to
A n’ibi titun gba, a ni’po‘ro
Ohun ona jijin, at’itosi
Nkigbe pe, ‘Wa.

4. Wa ma sise
Le ‘yemeji on aigbagbo jinna
Ko s'alailera ti ko le se nkan
Ailera l’Olorun a ma lo ju
Fun ‘se nla Re.

5. Wa, ma sise
‘Simi ko si, nigbat'ise osan
Titi orun yio fi wo l'ale
Ti awa o si gbo ohun ni pe
O seun omo.

6. Wa, ma sise
Laala ni dun, ere re si daju
‘Bukun f’awon t’o f’ori ti d’opin
Ayo won, ‘simi won, y'o ti po to
Lod' Oluwa! Amin
Christianity EtcRe: Post Yoruba Christian Hymns Here by obasolape(f): 4:02am On Oct 10, 2018
Okan are, ile kan mbe,
L’ona jinjin s’aiye ise ;
Ile t’ ayida ko le de,
Tani ko fe simi nibe?
Duro…roju duro, mase kun!
Duro…duro, sa roju, mase kun!

Bi wahala bo o mole,
B’ ipin re laiye ba buru,
W’ oke s’ ile ibukun na;
Sa roju duro, mase kun!

Bi egun ba wa lona re,
Ranti ori t’a f’ egun de;
B’ ibanuje bo okan re,
O ti ri bee f’ Olugbala.

Ma sise lo, mase ro pe,
A ko gb’ adura edun re;
Ojo isimi mbo kankan:
Sa roju duro, mase kun!
Duro…roju duro, mase kun!
Duro…duro, sa roju, mase kun!
Christianity EtcRe: Post Yoruba Christian Hymns Here by obasolape(f): 4:00am On Oct 10, 2018
1. A segun ati ajogun ni a je,
Nipa eje Kristi a ni isegun
B’Oluwa je tiwa, a ki yo subu
Ko s’ohun to le bori agbara re
Asegun ni wa, nipa eje Jesu
Baba fun wa ni ‘segun, nipa eje Jesu
Eni t’a pa f’elese
Sibe, O wa, O njoba
Awa ju asegun lo
Awa ju asegun lo

2. A nlo l’oruko Olorun Isreal
Lati segun ese at’aisododo
Kise fun wa, sugbon Tire ni iyin
Fun ‘gbala at’isegun ta f’eje ra

3. Eni t’O ba si segun li ao fi fun
Lati je manna to t’orun wa nihin
L’orun yo sig be imo ‘pe asegun
Yo wo ‘so funfun, yo si dade wura. Amin

1 2 3 4 5 6 7 (of 7 pages)