Welcome, Guest: Register On Nairaland / LOGIN! / Trending / Recent / NewStats: 3,194,355 members, 7,954,440 topics. Date: Friday, 20 September 2024 at 06:57 PM |
Nairaland Forum / Nairaland / General / Religion / Yoruba Hymn (9034 Views)
Story Behind The Hymn, "When I Survey The Wondrous Cross" / Which Church Has The Best Hymn Songs / Yoruba Hymn (2) (3) (4)
Yoruba Hymn by obasolape(f): 7:27am On Oct 23, 2015 |
Ji okan mi dide layo Korin iyin Olugbala Ola Re bere orin mi Seun ife Re ti po to O ri mo segbe n'isubu Sibe o fe mi l'afetan O yo mi ninu osi mi Seun 'fe Re ti n'ipa to! Ogun ota dide si mi Aiye atesu ndena mi On nmu mi la gbogbo Re ja SEun 'fe Re ti nipa to Gba yonu de b'awosanma To su dudu to nsan ara O duro ti mi larin re Seun fe Re ti dara to Gba gbogbo lokan ese mi Nfe ya lehin Oluwa mi Sugbon bi mo ti ngbagbe Re Iseun ife Re ki ye Mo fere faiye sile na Mo fe bo lowo ara iku A! Kemi kehin mi korin Iseun ife Re n'iku Nje ki nfo lo, ki nsi goke Saiye imole titi lai Ki nfayo iyanu korin Iseun ife Re lorun. 4 Likes |
Re: Yoruba Hymn by obasolape(f): 5:09am On Apr 01, 2019 |
Duro, duro fun Jesu, Enyin om’ogun Krist: Gbe asia Re soke A jo’gbodo fe ku; Lat’isegun de ’segun Ni y’o ma to ogun Re; Tit’ao segun gbogb’ota, Ti krist y’o j’Oluwa Duro, duro fun Jesu F’eti s’ohun ipe Jade s’ohun ipe L’oni ojo nla Re: Enyin akin ti nja fun Larin ainiye ota, N’nu ewu, e ni ’gboiya Dojuko agbara. Duro, duro fun Jesu, Duro l’agbara Re Ipa enia ko to Ma gbekele tire: F’ihinrere hamora Ma sona, ma gbadura B’ise tab’ ewu ba pe Ma se alai de ’be. Duro, duro fun Jesu Ija na ki y’o pe; Oni, ariwo ogun, Ola, orin ’segun, Eni t’o ba si segun, Y’o gba ade iye Y’o ma ba Oba Ogo Joba titi lailai…Amin 2 Likes |
Re: Yoruba Hymn by obasolape(f): 5:54am On Sep 06, 2019 |
Omije oju mi n bere aanu Re... Baba Omije oju mi n bere aanu Re... Baba Fi aso oju rere womi Olorun mi Araye nreti ohun ti mamubo lodo re Baba mimo Odun yi nlo o Odun yi nlo Omije oju mi nbere aanu Re o 2 Likes |
Re: Yoruba Hymn by obasolape(f): 5:56am On Sep 06, 2019 |
Krist' ki 'joba Re de, Ki ase Re bere; F' opa-rin Re fo Gbogbo ipa ese. Ijoba ife da, Ati t' Alafia? Gbawo ni irira Yio tan bi t'orun? Akoko na ha da, T' ote yio pari, Ika at' ireje, Pelu ifekufe? Oluwa joo, dide, Wa n'nu agbara Re; Fi ayo fun awa Ti o nsaferi Re Eda ngan ooko Re, 'Koko nje agbo Re; Iwa 'tiju pupo Nfihan pe 'fe tutu. Ookun bole sibe, Ni ile keferi: Dide 'Rawo ooro, Dide, mase wo mo. Amin. 1 Like |
Re: Yoruba Hymn by obasolape(f): 6:00am On Sep 06, 2019 |
1 Wa, ma sise, Tani gbodo s‘ole ninu oko ‘Gbati gbogbo eniyan nkore jo, Kaluku ni Baba pe fun ise; “Sise loni” 2 Wa, ma sise, Gba ‘pe giga ti angeli ko ni Mu ‘hinrere to t‘agba t‘ewe lo, Ra ‘gba pada, wawa l‘akoko nlo, Ile su tan. 3 Wa, ma sise, Oko po, alagbase ko si to, Aye titun po fun wa lati kun, Ohun ona jinjin, at‘itosi Nkigbe pe; “Wa” 4 Wa, ma sise Le ‘yemeji on aigbagbo jina, K‘o s‘alailera ti ko le se nkan, Ailera f‘Olorun a ma lo ju ' Fun‘se nla Re 5 Wa, ma sise, ‘Simi ko si nigbat‘ ise osan, Titi orun yio fi WO l‘ale, Ti awa o si gbo ohun ni pe: “O seun, omo” 6 Wa, ma sise, Lala na dun ere re si daju, ‘Bukun f‘awon t‘o fori ti d‘opin Ayo won, ‘simi won y‘o ti po to! “Lo d‘ Oluwa” Amin. 2 Likes 1 Share |
Re: Yoruba Hymn by obasolape(f): 5:24am On Nov 12, 2019 |
Gbat' O ba de, gbat' O ba de Lati sir' oso Re Gbogbo oso Re iyebiye Awon ti o fe Bi Irawo owuro, nwon nsade Re loso Ewa won o yo pupo, Ewa f'ade Re Yio kojo, yio kojo Oso Ijoba Re Awon mimo awon didan Awon ti O fe Bi Irawo owuro, nwon nsade Re loso Ewa won o yo pupo, Ewa f'ade Re Awon ewe, awon ewe To fe Olugbala Ni oso Re iyebiye Awon ti o fe Bi Irawo owuro, nwon nsade Re loso Ewa won o yo pupo, Ewa f'ade Re 2 Likes |
Re: Yoruba Hymn by obasolape(f): 7:48pm On Nov 26, 2019 |
AGBARA RE GA JU T'OTA LO OO IMO RE GA JU T'ESU LO AGBARA RE GA JU T'OTA LO OO IMO RE GA JU T'ESU LO - OLORUN KO SE OUN TI NI O, OSO AYE KOLE DI O LONA ISE RE, AGBARA RE GA JU T'OTA LO 1 Like |
Re: Yoruba Hymn by obasolape(f): 6:00am On Jun 29, 2021 |
1. WA k’ a da m’ awon ore wa Ti nwon ti jere na; N’ ife k’ a f’ okan ba won lo S’ ode orun lohun. 2. K’ awon t’ aiye d’ orin won mo, T’ awon t’ o lo s’ ogo; Awa l’ aiye, awon l’ orun, Okan ni gbogbo wa. 3. Idile kan n’nu Krist’ ni wa, Ajo kan l’a si je; Isan omi kan l’o yaw a, Isan omi iku. 4. Egbe ogun kan t’Olorun Ase Re l’a sin se; Apakan ti wo ‘do na ja, Apakan nwo lowo! 5. Emi wa fere dapo na, Y’o gb’ade bi ti won; Ao yo s’ami Balogun wa, Lati gbo ipe Re. YBH 311 WA k’ a da m’ awon ore wa 6. Jesu, so wa, s’amona wa, Gbat’oniko ba de; Oluwo, pin omi meji, Mu wa gunle l’ayo. 1 Like |
Re: Yoruba Hymn by obasolape(f): 6:02am On Jun 29, 2021 |
A o kọja lọ bi àwọn 'rawọ òórọ̀ T' ìmọ́lẹ̀ wọn n ran n'nu oorun ogo, Bẹ́ẹ̀ l' a o lọ kúrò l' aye ati 'ṣẹ rẹ̀, A o maa ranti wa nip' on t' a ti ṣe. ÈGBÈ: Wọn yoo ṣe 'ranti, wọn yoo ṣe 'ranti, A o maa ranti wa nip' on t' a ti ṣe, Bẹ́ẹ̀ l' a o lọ kúrò l' aye ati 'ṣẹ rẹ̀, A o maa ranti wa nip' on t' a ti ṣe. 2. A o ha kuro k' àwọn miran rọ́pò wa, Lati maa kore oko t' a ti gbìn?, Bẹ́ẹ̀ l' àwọn òṣìṣẹ́ yoo fi 'ṣẹ́ sílẹ̀, A o maa ranti wa nip' on t' a ti ṣe. 3. Kìkì òótọ́ ti a ba ti sọ láyé, Pẹ̀lú 'rúgbìn t' a ti gbìn laye yii, Yoo tẹ̀síwájú t' a ba ti gbàgbé wa, Eso ikore at' on t' a ti ṣe. 4. 'Gbà t' Olúwa yoo k' àwọn ayanfẹ Rẹ̀, T'ao jere adé aláyọ̀ t' ó ntàn, 'Gba naa l' ao ranti àwọn olootọ Rẹ̀, T' àárẹ̀ ti mu nip' on ti wọ́n ti ṣe. 1 Like |
Re: Yoruba Hymn by obasolape(f): 4:33am On Oct 14, 2021 |
GBATI SAMUEL JI 1. GBATI Samueli ji To gb’ ohun Eleda Ni gbolohun kokan, Ayo re ti po to Ibukun ni f’omo t’ o ri Olorun nitosi re mbe. 2. B’ Olorun ba pe mi Pe, ore mi li Oun, Ayo mi yo ti to Ngo si f’ eti sile, Ngo sa f’ ese t’ o kere ju, B’ Olorun sunmo tosi be. 3. Ko ha mba ni soro? Be ninu Oro Re? O npe mi lati wa Olorun Samuel; Ninu Iwe na mo ka pe Olorun Samuel npe mi. 4. Mba f’ ori pamo S’ abe itoju Re, Mo mo p’ Olorun nbe L’ odo mi n’gbagbogbo O ye k’ eru ese ba mi, Tor’ Olorun sunmo to si. 5. ‘Gbamba ka oro Re, Ki nwi bi Samuel pe Ma wi, Oluwa mi Emi y’ o gbo Tire; ‘Gba mo ba si wa n’ile Re, “Ma wi, ‘tori ‘ranse Re ngbo.” 1 Like |
Re: Yoruba Hymn by obasolape(f): 4:33am On Oct 14, 2021 |
Olugbala Gbohun Mi Olugbala gbohun mi Gbohun mi, gbohun mi Mo wa sodo Re gba mi Nibi agbelebu Emi se, sugbon O ku Iwo ku, Iwo ku Fi anu Re pa mi mo Nibi agbelebu Oluwa jo gba mi Nk'y'o bi O n'inu mo Alabukun gba mi Nibi agbelebu Bi n o ba tile segbe N o bebe, n o bebe Iwo ni Ona, iye Nibi agbelebu Ore ofe Re ta gba Lofe ni, lofe ni Foju anu Re wo mi Nibi agbelebu Feje mimo Re we mi Fi we mi, fi we mi Ri mi sinu ibu Re Nibi agbelebu Gbagbo lo le fun wa ni Dariji, dariji Mo figbagbo ro mo O Nibi agbelebu Loving Saviour, hear my cry, Hear my cry, hear my cry; Trembling to Thine arms I fly: O save me at the Cross! I have sinn'd, but Thou hast died, Thou hast died, Thou hast died; In Thy mercy let me hide: O save me at the Cross! Lord Jesus, receive me, No more would I grieve Thee, Now, blessed Redeemer, O save me at the Cross! Tho' I perish I will pray, I will pray, I will pray; Thou of life the Living Way: O save me at the Cross! Thou hast said Thy grace is free, Grace is free, grace is free: Have compassion, Lord on me: O save me at the Cross! Wash me in Thy cleansing blood, Cleansing blood, cleansing blood; Plunge me now beneath the flood: O save me at the Cross! Only faith will pardon bring, Pardon bring, pardon bring: In that faith to Thee I cling: O save me at the Cross! 1 Like |
Re: Yoruba Hymn by obasolape(f): 4:34am On Oct 14, 2021 |
WA S'ODO MI, OLUWA MI Verse 1 WA s'odo mi, Oluwa mi, Ni kutukutu owuro; Mu kero rere so jade, Lat'inu mi soke orun. Verse 2 Wa s'odo mi, Oluwa mi, Ni wakati osan gangan; Ki'yonu ma ba se mi mo, Won a si s'osan mi d'oru. Verse 3 Wa s'odo mi, Oluwa mi, Nigba ti ale ba n lẹ lo; Bi okan mi ba n sako lo, Mu pada; f'oju 're wo mi. Verse 4 Wa s'odo mi, Oluwa mi Ni oru, nigba ti orun, Ko woju mi; je k'okan mi Ri sinmi je ni aya Re. Verse 5 Wa s'odo mi, Oluwa mi, Ni gbogbo ojo aye mi; Nigba ti emi mi ba pin, Ki n le n'ibugbe lodo Re. 1 Like |
Re: Yoruba Hymn by obasolape(f): 4:36am On Oct 14, 2021 |
(1)Tire titi lai l'awa se, Oluwa wa orun; k'ohun at'okan wa wipe Amen,beni k,o ri (2) Gbat'ese pelu etan re, ba fe se wa n'ibi; k'iro yipe, "Tire l'awa" Ru etan ese ka (3) Gbati aiye ban dun mo ni, To si nfa okan wa kiro yipe Tire lawa" Le ma dun leti wa (4) Gbati Esu ba ntafa re Sori ailera wa ki ro yip e Tire lawa Ma je ki o re wa (5) Tire nigba wa lawe Tire nigba ndagba Tire nigba ba darugbo Ti aiye wa mbuse (6) Tire titi lai lawa se A fara wa fun o Titi aiye ainipekun Amin beni kori (AMIN) 1 Like |
Re: Yoruba Hymn by obasolape(f): 4:37am On Oct 14, 2021 |
1. Tan ‘mole Re si wa Loni yi Oluwa; Fi ara Re han wa N’nu oro mimo Re; Jo m’okan wa gbona, K’ a ma wo oju Re, K’ awon ‘mode le ko Iyanu ore Re. 2. Mi si wa Oluwa, Ina Emi Mimo, K’ a le fi okan kan Gbe oruko Re ga; Jo fi eti igbo, At’ okan ironu, Fun awon ti a nko, L’ ohun nla t’ O ti se. 3. Ba ni so, Oluwa, Ohun to ye k’ a so, Gege bi oro Re, Ni ki eko wa je; K’ awon agutan Re, Le ma mo ohun Re, Ibit’ O nto won si, Ki nwon si le ma yo. 4. Gbe ‘nu wa, Oluwa, K’ife Re je tiwa, Iwo nikan lao fi Ipa wa gbogbo sin; K’ iwa wa je eko, Fun awon omo Re, K’o si ma kede Re, Ninu gbogbo okan. Amin. 1 Like |
Re: Yoruba Hymn by obasolape(f): 5:16am On Jun 27, 2023 |
1. B'eru ese re ba nwo o lorun, Pe Jesu wole okan re; B'o nd'aniyan isoji okan re, Pe Jesu wole okan re, Le 'yemeji re sonu, Ba Oluwa re laja; Si okan re paya fun, Pe Jesu wole okan re. 2. Bi o ba nwa iwenumo kiri, Pe Jesu wole okan re; Omi 'wenumo ko jina si o, Pe Jesu wole okan re. 3. B'igbi wahala ba ngba o kiri Pe Jesu wole okan re; B'afo ba wa ti aye ko le di, Pe Jesu wole okan re 4. Bi ore t'o gbekele ba da o Pe Jesu wole okan re; On nikan ni Olubanidaro, Pe Jesu wole okan re, 5. B'o nfe korin awon olubukun Pe Jesu wole okan re, Bi o nfe wo agbala isimi, Pe Jesu wole okan re. 'Yemeji mi ti fo lo, Mo b'Olorun mi laja, Mo s'okan mi paya fun, Jesu ti wole okan mi. Amin. 1 Like |
Re: Yoruba Hymn by obasolape(f): 6:15am On Jun 29, 2023 |
1. K’ A to sun, Olugbala wa, Fun wa n’ ibukun ale; A jewo ese wa fun O, Iwo l’o le gba wa la. Bi ile tile su dudu, Okun ko le se wa mo; Iwo Eniti ki s’are Nso awon enia Re. 2. B’ iparun tile yi wa ka, Ti ofa nfo wa koja, Awon angeli yi wa ka, Awa o wa lailewu. Sugbon b’ iku ba ji wa pa, T’ ibusun wa d’ iboji, Je k’ ile mo wa s’ odo Re L’ ayo at’ Alafia. 3. Ni irele, a f’ ara wa Sabe abo Re, Baba; Jesu, ‘Wo t’o sun bi awa, Se orun wa bi Tire. Emi Mimo, rado bow a, So wa l’ okunkun oru, Tit’ awa o fi ri ojo Imole aiyeraiye. 1 Like |
Re: Yoruba Hymn by obasolape(f): 11:26am On Jul 08, 2023 |
Jesu mo wa sodo Re 1. f JESU mo wa sodo Re, Je ki nle ma to O lehin Bi 'ni mi gbogbo po si Ti ero mi gbogbo soji. Egbe: E yin logo, eyin Mimo E f'ope fun Baba loke Da wa si l'egbe Serafu, Ni kehin gba okan wa la. 2. mf Keferi, Imale, e wa Onigbagbo, ma kalo K'a jo yin Olorun wa, K'a le d'ade ni 'kehin. Egbe: E yin logo, etc 3. mf A dupe lowo Olorun T'o fi Jesu Kristi fun wa Lati ra araiye pada, Lowo ese at'Esu. Egbe: E yin logo, etc 4. mf Egbe Serafu damure Egbe Kerubu kun f'adura Olugbala yio gba wa la Oluwosan yio wo wa san. Egbe: E yin logo, etc 5. Nigbati 'pe kehin ba dun Jesu y'o ko wa de Kenaani, Je ka l'ayo lodo Re Fi wa s'agbala itura. Egbe: E yin logo, etc 6. E f'ogo fun Baba loke E f'ofo fun Omo pelu E f'ogo fun Emi Mimo Metalokan lope ye fun. Egbe: E yin logo, etc Amin 1 Like |
Re: Yoruba Hymn by orisa37: 11:20pm On Jul 08, 2023 |
NI PA IFE OLUGBALA KI YO SI NKAN. BY THE LOVE OF LORD OUR SAVIOUR THERE'S NO FEAR. |
Re: Yoruba Hymn by obasolape(f): 11:18pm On Jul 15, 2023 |
Yin Olorun Abra’am (Yoruba Hymn) May 5, 2021 by Mayowa Leave a Comment 1. Yin Olorun Abra’am Ti O njoba l’oke Enit’o ti wa titi lai Olorun ‘fe “Jehofa nla l’Emi” Gbogbo eda jewo Mo f’ibukun f’Oruko Re Titi lailai 2. Yin Olorun Abra’am Nip’ase Eniti Mo dide, mo si wa ‘tunu Lowo ‘tun Re Mo ko aiye sile Ogbon at’ola re On nikan si ni ipin mi At’asa mi 3. On na ti seleri Mo gbekele eyi Ngo fi iye idi goke Lo si orun, Ngo ma wo oju Re Ngo si yin ipa Re Ngo korin ‘yanu t’or’ofe Titi lailai 4. B’agbara eda pin T’aiye at’esu nde Ngo dojuko ona Kenaan Nip’ase Re, Ngo re odo koja Bi Jesu wa lokan Ngo k’oja n’nu igbo didi Lo s’ona mi 5. Oba oke orun Olor’angeli nke Wipe “Mimo, mimo, mimo” Oba titi Eniti ki pada Ti y’o si wa lailai Jehofa, Baba, “Emi ni” Awa nyin O 6. Gbog’ egbe asegun Nyin Olorun l’oke Baba, Omo at’Emi ni Nwon nke titi Yin Olorun Abra’am Ngo ba won korin na Tire l’agbara at’ola, Pelu iyin |
Re: Yoruba Hymn by obasolape(f): 4:58am On Jul 26, 2023 |
ORE WO L’ANI BI JESU ORE WO L’ANI BI JESU Ore wo l’ani bi Jesu, ti o ru banuje wa! Anfani wo lo po bayi lati ma gbadura si! Alafia pupo l’a nsonu, a si ti je rora po, Tori a ko fi gbogbo nkan s’adura niwaju re. Idanwo ha wa fun wa bi? A ha nni wahala bi? A ko gbodo so ’reti nu; sa gbadura si Oluwa. Ko s’oloto orebi re ti ole ba wa daro, Jesu ti mo ailera wa; sa gbadura s’Oluwa. Eru ha nwo wa l’orun bi, aniyan ha po fun wa? Olugbala je abo wa, sa gbadura s’Oluwa. Awon ore ha sa o ti? Sa gbadura s’Oluwa. Yo gbe o soke lapa re, Iwo yo si ri itunu WHAT A FRIEND WE HAVE IN JESUS 1. WHAT a friend we have in Jesus, All our sins and griefs to bear; What a privilege to carry Ev’rything to God in prayer. Oh, what peace we often forfeit, All because we do not carry Ev’rything to God in prayer. 2. Have we trials and temptations? Is there trouble anywhere? We should never be discouraged, Take it to the Lord in prayer. Can we find a Friend so faithful. Who will all our sorrows share? Jesus knows our ev’ry weakness, Take it to the Lord in prayer. 3. Are we weak and heavy laden, Cumbered with a load of care? Precious Saviour, still our refuge,- Take it to the Lord in prayer. Do thy friend despise , forsake thee? Take it to the Lord in prayer: In His arms He’ll take and shield thee, Thou wilt find a solace there. 1 Like |
Re: Yoruba Hymn by obasolape(f): 12:11pm On Jul 29, 2023 |
ITAN IYANU T’IFE ! 1. Itan iyanu t’ife ! So fun mi l’ekan si Itan iyanu t’ife E gbe orin na ga ! Awon angeli nroyin re Awon oluso si gbagbo Elese, iwo ki yo gbo Itan iyanu t’ife Iyanu ! Iyanu ! Iyanu ! Itan iyanu t’ife 2. Itan iyanu t’ife B’iwo tile sako Itan iyanu t’ife Sibe o npe loni Lat’ori oke kalfari Lati orisun didun ni Lati isedale aye Itan iyanu t’ife 3. Itan iyanu t’ife Jesu ni isimi Itan iyanu t’ife Fun awon oloto To sun ni ile nla orun Pel’awon to saju wa lo Won nko orin ayo orun Itan iyanu t’ife. Amin. |
Re: Yoruba Hymn by obasolape(f): 3:27am On Aug 10, 2023 |
1. ISUN kan wa t’o kun f’eje O yo n’iha jesu, Elese mokun ninu re, O bo ninu ebi. 2. ‘Gba mo f’igbagbo r’isun na, Ti nsan fun ogbe Re, Irapada d’orin fun mi Ti ngo ma ko titi. 3. Ninu orin t’odun julo, L’emi o korin Re: ‘Gbat’ akololo ahon yi Ba dake n’iboji. 4. Mo gbagbo p’O pese fun mi (Bi mo tile s,aiye ) Ebun ofe t’a f’eje ra, Ati duru wura. 5. Duru t’a tow’ Olorun se, Ti ko ni baje lai; T’a o ma fi yin Baba wa, Oruko Re nikan. |
Re: Yoruba Hymn by obasolape(f): 3:49am On Aug 10, 2023 |
ITAN IYANU T’IFE ! 1. Itan iyanu t’ife ! So fun mi l’ekan si Itan iyanu t’ife E gbe orin na ga ! Awon angeli nroyin re Awon oluso si gbagbo Elese, iwo ki yo gbo Itan iyanu t’ife Iyanu ! Iyanu ! Iyanu ! Itan iyanu t’ife 2. Itan iyanu t’ife B’iwo tile sako Itan iyanu t’ife Sibe o npe loni Lat’ori oke kalfari Lati orisun didun ni Lati isedale aye Itan iyanu t’ife 3. Itan iyanu t’ife Jesu ni isimi Itan iyanu t’ife Fun awon oloto To sun ni ile nla orun Pel’awon to saju wa lo Won nko orin ayo orun Itan iyanu t’ife. Iyanu ! Iyanu ! Iyanu ! Itan iyanu t’ife Amin. 1 Like |
Re: Yoruba Hymn by Negroid001(m): 5:11pm On Aug 10, 2023 |
obasolape: I love this song |
Re: Yoruba Hymn by obasolape(f): 4:23am On Aug 23, 2023 |
FI IYIN FUN JESU OLURAPADA WA 1. Fi iyin fun Jesu, Olurapada wa, Ki aye k’okiki ife Re nla ; Fi iyin fun ! eyin Angeli ologo, F’ola at’ogo fun oruko re, B’olu’agutan, Jesu y’o to omo Re L’apa Re l’o ngbe won le l’ojojo Eyin eniyan mimo ti ngb’oke Sion Fi iyin fun pelu orin ayo 2. Fi iyin fun, Jesu Olurapada wa, Fun wa, O t’eje Re sile, O ku On ni apata, ati reti ‘gbala wa, Yin Jesu ti a kan m’agbelebu; Olugbala t’O f’ara da irora nla Ti a fi ade egun de lori Eniti a pa nitori awa eda Oba ogo njoba titi laelae. 3. Fi iyin fun, Jesu Olurapada wa Ki ariwo iyin gba orun kan Jesu Oluwa njoba lae ati laelae, Se l’oba gbogb’eyin alagbara A segun iku; fi ayo royin na ka Isegun re ha da, isa oku? Jesu ye ko tun si wahala fun wa mo ‘tori O l’agbara lati gbala. Amin. |
Re: Yoruba Hymn by obasolape(f): 7:09am On Aug 24, 2023 |
B’ORUKO JESU TI DUN TO 1. B’oruko Jesu ti dun to, ogo ni fun Oruko Re o tan banuje at’ogbe ogo ni fun oruko Re ogo f’oko Re, ogo f’oko Re ogo f’oruko Oluwa ogo f’oko Re, ogo f’oko Re ogo f’oruko Oluwa 2. O wo okan to gb’ogbe san Ogo ni fun oruko Re Onje ni f’okan t’ebi npa Ogo ni fun oruko Re 3. O tan aniyan elese, Ogo ni fun oruko Re Ofun alare ni simi Ogo ni fun oruko Re 4. Nje un o royin na f’elese, Ogo ni fun oruko re Pe mo ti ri Olugbala Ogo ni fun oruka Re. |
Re: Yoruba Hymn by obasolape(f): 3:05am On Aug 28, 2023 |
“lba mase pe Oluwa ti o ti wa ni tiwa” - Ps. 124:1 1. lBASE p’Oluwa Ko ti wa ni tiwa Lo ye k’awa ma wi Nigbat’ese gbogun tiwa. Egbe: Ope ni f'Oluwa Oba wa Olore A ke kabiyesi A f'ope fun Jehofa T'o gba wa Iowo ota, A dupe Oluwu. 2. Nwon ‘ba bo wa mole Pelu agbara won, Ope ni f ’Oluwa, Ti ko jeki t’esu bori. Egbe: Ope ni f'Oluwa... 3. Okan wa yo b'eiye Nin' okun apeiye Okun ja, awa yo, E yo Jesu da wa sile. Egbe: Ope ni f'Oluwa... 4. Tire ni Oluwa Lati gbe wa leke Gbogbo awon ota, T'o wu ko tile yi wa ka. Egbe: Ope ni f'Oluwa... 5. Ara f ’okan bale Sodo Olugbala B’esu ti gbon to ni, Ko to kini kan fun Jesu. Egbe: Ope ni f'Oluwa... 6. Iranlowo wa mbe L'Oruko Oluwa T’O d’orun on aiye Oba awon eni Mimo. Egbe: Ope ni f'Oluwa... 7. Ogo fun Baba wa, Ogo fun Omo Re, Ogo f’Emi Mimo Metalokan jo gbo tiwa. Egbe: Ope ni f'Oluwa Oba wa Olore A ke kabiyesi A f'ope fun Jehofa T'o gba wa Iowo ota, A dupe Oluwu. Amin 1 Like |
Re: Yoruba Hymn by obasolape(f): 4:50am On Sep 12, 2023 |
B’o ti dun lati gba Jesu Bi iwo ba gbagbo, iwo o ri ogo Olorun. Jn. 11:40 1. B’o ti dun lati gba Jesu Gbo gegebi oro Re; K’a simi lor’ ileri Re, Sa gbagbo l’Oluwa wi Jesu, Jesu, emi gbagbo, Mo gbekele n’gbagbogbo, Jesu, Jesu, Alabukun Ki nle gbekele O si. 2. B’o ti dun lati gba Jesu, K’a gb’eje ‘wenumo Re Igbagbo ni ki a fi bo Sin ‘eje wenumo na. 3. B’o ti dun lati gba Jesu, Ki nk’ara ese sile, Ki ngb’ayo, iye, isimi Lati odo Jesu mi. 4. Mo yo mo gbeke mi le O, Jesu mi, Alabukun; Mo mo pe O wa pelu mi, Ntoju mi titi dopin. Amin. Tis so sweet to trust in Jesus If thou wouldest believe, thou shouldest see the glory of God. John.11:40 1. 'Tis so sweet to trust in Jesus, Just to take Him at His word: Just to rest upon His promise: Just to know, 'Thus saith the Lord. Jesus, Jesus, how I trust Him! How I've proved Him o'er and o'er Jesus, Jesus, precious Jesus! O for grace to trust Him more! 2. O how sweet to trust in Jesus, Just to trust His cleansing blood; Just in simple faith to plunge me 'Neath the healing, cleansing flood! 3. Yes, ‘tis sweet to trust in Jesus, Just from sin and self to cease; Just from Jesus simply taking Life and rest, and joy and peace. 4. I'm so glad I learn'd to trust Thee Precious Jesus, Saviour, Friend; And I know that Thou art with me, Wilt be with me to the end. Amen. |
Re: Yoruba Hymn by siant: 9:34pm On Sep 17, 2023 |
'Gbogbo won SI Kun fun Emi-Mimo.' Ise Aposteli 2:4. Baba wa orun, awa de Awa alailagbara, Ran Emi-Mimo Re SI wa Ko so gbogbo wa d'otun Wa Emi-Mimo Jare wa, F'ede titun s'okan wa, Ebun nla Re n ni la n toro, T'ojo nla pentecost. Ranti ileri Re, Jesu, Tu Emi- Re s'ara wa Fi alafia Re fun wa T'aye ko Le fi funii Wa Emi- Mimo jare wa Pa ese run l'okan wa Ebun nla Re n ni la n toro T'ojo nla pentecost. Adaba orun, sokale F'owo ife yi wa ka, Ki gbogbo orile ede Teriba f'Olugbala Ka gburo Re jakejado Ile okunkun wa yi, Ebun nla Re la n toro T'ojo nla pentecost |
Re: Yoruba Hymn by obasolape(f): 7:25am On Sep 21, 2023 |
1. N‘nu gbogbo ayida aye Ayo on wahala; Iyin Olorun ni y‘o ma Wa l‘enu mi titi 2. Gbe Oluwa ga pelu mi, Ba mi gb‘oko Re ga: N‘nu wahala, ‘gba mo ke pe O si yo mi kuro 3. Ogun Olorun wa yika Ibugbe Oloto; Eniti o ba gbekele, Yio ri igbala 4. Sa dan ife Re wo lekan ‘Gba na ‘wo o mo pe, Awon t‘o di oro Re mu Nikan l‘eni ‘bukun 5. E beru Re, eyin mimo, Eru miran ko si; Sa je ki ‘sin Re j‘ayo yin On y‘o ma toju yin Amin. |
How To Be The Apostle Paul Of Our Generation / Interested In Moderating This Section? / How Can Man Be Sinless?
(Go Up)
Sections: politics (1) business autos (1) jobs (1) career education (1) romance computers phones travel sports fashion health religion celebs tv-movies music-radio literature webmasters programming techmarket Links: (1) (2) (3) (4) (5) (6) (7) (8) (9) (10) Nairaland - Copyright © 2005 - 2024 Oluwaseun Osewa. All rights reserved. See How To Advertise. 89 |