Obasolape's Posts
Nairaland Forum › Obasolape's Profile › Obasolape's Posts
Ẹ jẹ ka jumọ f'ọpẹ f'Ọlọrun Orin iyin atọpẹ lo yẹ wa Iyanu n'ifẹ rẹ si gbogbo wa Ẹ kọrin iyin s'ọba olore wa. Chorus: Halleluya ogo ni f'Ọlọrun A f'ijo ilu yin Ọlọrun wa Alaaye ni o yin ọ bo ti yẹ Halleluya ogo ni f'Ọlọrun Ki l'a fi san j'awọn t'iku ti pa Iwọ l'o f'ọwọ wọ wa di oni Iwọ l'o nṣọ wa t'on gba wa lọw'ewu Oba wa aiku Onibu ọrẹ Chorus: Halleluya ogo ni f'Ọlọrun A f'ijo ilu yin Ọlọrun wa Alaaye ni o yin ọ bo ti yẹ Halleluya ogo ni f'Ọlọrun |
Jesu onirele Omo Olorun Alanu Olufe Gbo gbe omo Re Fi ese wa ji wa Si da wa n'ide Fo gbogbo orisa Ti mbe lokan wa Fun wa ni ominira F'ife s'okan wa Fa wa Jesu mimo S'i bugbe l'oke To wa l'ona ajo Si je Ona wa La okun aiye ja S'imole orun Jesu onirele Omo Olorun Alanu Olufe Gbo gbe omo Re. Amin |
Jesu onirele Omo Olorun Alanu Olufe Gbo gbe omo Re Fi ese wa ji wa Si da wa nide Do gbogbo orisa Ti me lokan wa Fun wa ni ominira F'ife s'okan wa Fa wa Jesu mimo S'i bugbe l'oke To wa l'ona ajo Si je Ona wa La okun aiye ja S'imole orun Jesu onirele Omo Olorun Alanu Olufe Gbo gbe omo Re. Amin |
Bi osun gbegbe eti do Tutu minimini Bi igbo dudu eti omi B' Itanna ipado Bi igbo dudu eti omi Itana ipado Be lomo naa yio dagba Ti nrin lona Baba Tokan re nfa si Olorun Lati Igba ewe re Tokan re nfa si Olorun Lati Igba ewe re Ewe tutu l'eba odo B'o pe, a re danu Be n'itanna ipa omi Si are l'akoko re Be n'itanna ipa omi Si are l'akoko re Ibukun ni fun omo na Ti nrin l'ona Baba Oba ti ki pa ipo da Emi mimo lailai Oba ti ki pa ipo da Emi mimo lailai Oluwa, 'Wo l'a gbekele Fun wa l' ore-ofe L'ewe, l’agba, ati n'iku Pa wa mo b'omo Re L'ewe, l’agba, ati n'iku Pa wa mo b'omo Re |
Bi Osun gbe gbe etido Tutu minimini Bi igbo dudu eti omi Ita na ipado Bi igbo dudu eti omi Itana ipado Be lomo naa yio dagba Ti nrin lona Baba Tokan re fa si Olorun Lati Igba ewe re Tokan re fa si Olorun Lati Igba ewe re |
Eyin Oba ogo, On ni Olorun Yin fun 'se 'yanu ti o ti fihan O wa pelu awon ero mimo l'ona O si je imole won l'osan l'oru. E yin Angel 'didan, lu duru wura Ki gbogbo yin juba, t'e now oju re Ni gbogbo 'joba re, b'aye ti nyi lo Ise re y'o ma yin Ise re y'o ma yin Fi ibukun fun Oluwa okan mi. E yin fun 'rapada ti gbogbo okan E yin fun orisun imularada Fun inu rere ati itoju re Fun 'daniloju pe O ngbo adura, E yin fun idanwo bi okun ife, T'o nso wa po moa won ohun orun Fun 'gbagbo ti n|”segun , 'reti ti ki sa Fun ile ogo t'O ti pese fun wa. |
Baba mi, GBA MBA nsako lo Kuro l'ona Re laiye yi Ko mi ki nle wi bayi pe Se fe Tire B'ipin mi l'aiye ba buru Ko mi ki ngba, ki nmase kun Ki ngbadura to ko mi wipe Se fe Tire B'o ku emi nikansoso Ti ara on ore ko sii Ni'teriba ngo ma wipe Se 'fe Tire B'o fe gba ohun owo mi Ohun t'o se owon fun mi Ngo fi fun O se Tire ni? Se fe Tire Sa fi Emi Re tu mi n'nu Ki On k'o si ma ba mi gbe; Eyi to Ku, o dowo Re Se fe Tire Tun fe mi se lojojumo Ko si mu ohun na kuro Ti ko je kemi le wipe Se fe Tire Gbat' emi mi ba pin late Nilu to dara ju aiye Lemo ma korin na titi Se fe Tire. |
Baba mi, GBA MBA nsako lo Kuro l'ona Re laiye yi Ko mi ki nle wi bayi pe Se fe Tire B'ipin mi l'aiye ba buru Ko mi ki ngba, ki nmase kun Ki ngbadura to ko mi wipe Se fe Tire B'o ku emi nikansoso Ti ara on ore ko sii Ni'teriba ngo ma wipe Se 'fe Tire B'o fe gba ohun owo mi Ohun t'o se owon fun mi Ngo fi fun O se Tire ni? Se fe Tire Sa fi Emi Re tu mi n'nu Ki On k'o si ma ba mi gbe; Eyi to Ku, o dowo Re Se fe Tire Tun fe mi se lojojumo Ko si mu ohun na kuro Ti ko je kemi le wipe Se fe Tire Gbat' emi mi ba pin late Nilu to dara ju aiye Lemo ma korin na titi Se fe Tire. Amin ziinee: |
. K ‘ore ofe Krist‘ Oluwa, Ife Baba ail‘opin, Oju rere Emi mimo, K‘o t‘oke ba s‘ori wa; Bayi l‘a le wa n‘irepo Awa ati Oluwa; K‘a si le ni ‘dapo didun, At‘ayo t‘aye ko ni. Amin. |
Ona ara l' Olorun wa Ngba sise Re l' aiye; A nri 'pase Re lor' okun, O ngun igbi l' esin. Ona Re enikan ko mo, Awamaridi ni; O pa ise ijinle mo, O sin se bi Oba. Ma beru mo, enyin mimo, Orun t' o su be ni, O kun fun anu: y'o rojo Ibukun sori nyin. Mase da Oluwa l' ejo, Sugbon gbeke re le; 'Gbat o ro pe O binu, Inu Re dun si . Ise Re fere ye wan a, Y'o ma tan siwaju; Bi o tile koro loni, O mbo wa dun lola. Afoju ni alaigbagbo, Ko mo 'se Olorun; Olorun ni Olutumo, Y'o m' ona Re ye ni. |
Eyin ero, nibo l'e nlo T' enyin t' opa lowo nyin? A nrin ajo mimo kan lo, Nipa ase Oba wa, Lori oke on petele, A nlo s' afin Oba rere, A nlo s' afin Oba rere, A nlo s' ile t' o dara, A nlo s' afin Oba rere, A nlo s' ile t' o dara. Eyin ero, e so fun ni, T' ireti ti enyin ni? Aso mimo, ade ogo Ni Jesu y'o fi fun wa; Omi iye l' a o ma mu; A o si b' Olorun wa gbe, A o si b' Olorun wa gbe, N' ile mimo didara A o si b' Olorun wa gbe, N' ile mimo didara. E ko beru ona t' e nrin, Eyin ero kekere? Ore airi npelu wa lo, Awon Angeli yi wa ka, Jesu Kristi l' amona wa; Y'o ma so wa, y'o ma to wa, Y'o ma so wa, y'o ma to wa, Ninu ona ajo wa; Y'o ma so wa, y'o ma to wa, Ninu ona ajo wa. Ero, a le ba yin kegbe, L' ona ajo s' ile na? Wa ma kalo, wa ma kalo, Wa si egbe ero wa, Wa, e ma se fi wa sile, Jesu nduro, O nreti wa, Jesu nduro, O nreti wa, N' ile mimo t' o dara; Jesu nduro, O nreti wa, N' ile mimo t' o dara. |
Fe enikeji re, ase Oluwa ni O sa f'ara Re s' apere ni fi fe t'O fe wa. Fe enikeji re N'ire tabi n'ija O ko wa pe k'a f'ota wa k'a f'ore san uni Fe enikeji re Oluwa nke tantan O ye ki gbogbo wa mura Ka fenikeji we Fe enikeji re At'aladugbo 're Pelu gbogb' eni yi o ka At'ota re pelu K'a f'enikeji wa Bi Jesu ti fe wa Jesu sa f'awon ota 're O si sure fun won. Amin |
The correct lyrics Fun anu to po bi'yanrin Ti mo ngba lojumo Lat'odo Jesu Oluwa Kil' emi o fi fun? Kini ngo fi fun Oluwa Lat'inu okan mi Ese ti ba gbogbo re je Ko tile jamo nkan Eyi l'ohun t'emi o se F'ohun t'O se fun mi Em'o mu ago igbala Ngo kepe Oluwa Eyi l'ope ti mo le da Emi osi, are; Em'o ma soro ebun 're Ngo si ma bere si Emi ko le sin b 'o ti to Nko n'ise kan to pe Sugbon e'mo sogo yi pe Gbese ope mi po. Amin |
Yin yin lohun elo ati duru Yin o yin yin o Yin yin lohun elo ati duru Yin o yin yin o Emi yio korin iyin sOlugbala Emi yio pokiki Re ka gbogbo aye Yin yin lohun elo ati duru Yin o yin yin o |
Ko tun si ore bi Jesu, Eniti o ru gbogbo ese wa, T’o ku iku Oro fun wa ni aikanra. Ore Nla Ife nla alailegbe (2ce) Ni ti Jesu, Olugbala rere Ife l'O fi ku f'aw'elese Eni t'O farada irora Taraiye pa, n'irira l'aide ri, Ore nla? Ani'ku reyi j'Ebo fese Etu t'O se tun je ailegbe O to k'awa k'o feran Jesu jojo; Ore nla! Ileri Re nfun okan layo Eni to far a gba iya wa T'O je k'awa k'o gba Ifiji t'Oba; Ore nla! Ko siru aini to nje ni n'ya Baba l'o run kappa 're jojo O to k'awa wa do 're Fun isinmi, Ore nla! Ko to kawa ko ko ife 're Oba t'o j'oba lo ma ni o Dupe pe ina fe Re yi Ki jo ku; Ore nla |
Mo ti gba Jesu loba temi Jesu loba to gba mi la Okam mi si nile Jesu o Ko ni je koju ti mi |
Jesu l'Olusagutan mi Ore eniti ki ye Ko s'ewu bi mo je tire T' On so je temi titi Nib' odo omi iye nsan Nibe l'o nm' okan mi lo Nibiti oko tutu nhu L'o nfoje orun bo mi Mo ti fi were sako lo N'ife O si wa mi ri L'ejika Re l'o gbe mi si O fayo mu mi Wale Nko beru ojiji iku Bi wo ba wa lodo mi Ogo Re ati opa Re Awon l'o ntu mi ninu Iwo te tabili fun mi Wo d' ororo sori mi A! Ayo na ha ti po to Ti nt'odo Re wa ba mi Be lojo aye mi gbogbo Ore Re ki o ye lai Olusaguntan ngo yin O Ninu Ile Re titi. |
Ji okan mi dide layo Korin iyin Olugbala Ola Re bere orin mi Seun ife Re ti po to O ri mo segbe n'isubu Sibe o fe mi l'afetan O yo mi ninu osi mi Seun 'fe Re ti n'ipa to! Ogun ota dide si mi Aiye atesu ndena mi On nmu mi la gbogbo Re ja SEun 'fe Re ti nipa to Gba yonu de b'awosanma To su dudu to nsan ara O duro ti mi larin re Seun fe Re ti dara to Gba gbogbo lokan ese mi Nfe ya lehin Oluwa mi Sugbon bi mo ti ngbagbe Re Iseun ife Re ki ye Mo fere faiye sile na Mo fe bo lowo ara iku A! Kemi kehin mi korin Iseun ife Re n'iku Nje ki nfo lo, ki nsi goke Saiye imole titi lai Ki nfayo iyanu korin Iseun ife Re lorun. |
Love this Yoruba hymn and I'm posting it here Gbat' O ba de, gbat' O ba de Lati sir' oso Re Gbogbo oso Re iyebiye Awon ti o fe Bi Irawo owuro, nwon nsade Re loso Ewa won o yo pupo, Ewa f'ade Re Yio kojo, yio kojo Oso Ijoba Re Awon mimo awon didan Awon ti O fe Bi Irawo owuro, nwon nsade Re loso Ewa won o yo pupo, Ewa f'ade Re Awon ewe, awon ewe To fe Olugbala Ni oso Re iyebiye Awon ti o fe Bi Irawo owuro, nwon nsade Re loso Ewa won o yo pupo, Ewa f'ade Re |