Obasolape's Posts
Nairaland Forum › Obasolape's Profile › Obasolape's Posts
1. Bi mo ti ri, lai s'awawi, Sugbon nitori eje Re B'o si ti pe mi pe ki nwa; Olugbala, mo de. 2. Bi mo ti ri, laiduro pe, Mo fe k' okan mi mo toto, S'odo Re to le we mi mo, Olugbala, mo de. 3. Bi mo ti ri, b'o tile je Ija l'ode, ija ninu Eru l'ode, eru ninu, Olugbala, mo de. 4. Bi mo ti ri, osi are; Mo si nwa imularada, Iwo le s'awotan mi, Olugbala, mo de. 5. Bi mo ti ri 'wo o gba mi, 'Wo o gba mi, t'owo t'ese; 'Tori mo gba 'leri Re gbo; Olugbala, mo de. 6. Bi mo ti ri ife Tire, L'o sete mi patapata, Mo di Tire, Tire nikan; Olugbala, mo de. 7. Bi mo ti ri, n'nu fe nla ni T'o fi titobi Re han mi; Nihin yi ati ni oke; Olugbala, mo de. Amin |
Ninu irin ajo mi, beni mo nkorin Mo n toka si kalfari, N’ibi eje na Idanwo lode ninu, l’ota gbe dide Jesu lo nto mi lo, isegun daju Egbe: A! mo fe ri Jesu kin ma w’oju re, Ki nma korin titi nipa ore re Ni ilu ogo ni ki ngbohun soke Pe mo bo, ija tan, mo de ile mi. Stanza 2 Ninu ise isin mi, b’okunkun basu Un o tubo sunmo Jesu, y’o tan imole Esu le gb’ogun ti mi, kin le sa pada Jesu lo nto mi lo, ko se’wu fun mi. Egbe: A! mo fe ri Jesu kin ma w’oju re, Ki nma korin titi nipa ore re Ni ilu ogo ni ki ngbohun soke Pe mo bo, ija tan, mo de ile mi. Stanza 3 Bi mo tile bo sinu afonifoji Imole itoni Re, Yio Mole simi Yio na owo re simi, Yio gbe mi soke Un o ma tesiwaju, b’o ti nto mi lo Egbe: A! mo fe ri Jesu kin ma w’oju re, Ki nma korin titi nipa ore re Ni ilu ogo ni ki ngbohun soke Pe mo bo, ija tan, mo de ile mi. Stanza 4. Nigbati iji aye yi ba yi lu mi Mo ni abo t’o daju, labe apa re Y’o ma f’owo re to mi titi de opin Ore ododo ni, A! mo ti f’e to. Egbe: A! mo fe ri Jesu kin ma w’oju re, Ki nma korin titi nipa ore re Ni ilu ogo ni ki ngbohun soke Pe mo bo, ija tan, mo de ile mi. |
1. Oba ogo, alafia, Un o feran Re; Ife na ki y'o dekun, Un o sunmo O; N'tori O ti gbebe mi, O ti gb'ohun mi; O ka iwe aya mi, O da mi n'de. 2. Fun idasile yi ni Uno korin Re; Gbogb'ayo okan mi ni Uno mu fun O; 'Gba t'ese mi nke kikan, O da mi lare: 'Gba mo pe O nikoko, O gbebe mi. 3. Gbogb'ojo aye mi ni Uno fi yin O; Mo le gbe O ga ninu Okan mi yi: Aye wa n'nu okan mi T'Iwo y'o ma gbe! Ayeraye kuru ju Lati yin O. Amin. |
Isun kan wa to kun feje, O yo niha Jesu. Elese mokun ninu re, O bo ninu ebi. Gba mo figbagbo risun naa, Ti n san fun ogbe Re, Irapada dorin fun mi Ti n o ma ko titi. Ninu orin to dun ju lo, Lemi o korin Re: 'Gba t'akololo ahon yii Ba dake niboji. Mo gbagbo p'O pese fun mi (Bi mo tile saiye) Ebun ofe ta feje ra, Ati duru wura. Duru ta towo'Olorun se, Ti ko ni baje lai: T'a o ma fi yin Baba wa, Oruko Re nikan. |
1. Si O Olutunu Orun Fun ore at'agbara Re, A nko, Aleluya. 2. Si O, ife eni t'O wa Ninu Majemu Olorun A nko, Aleluya. 3. Si O, agbara Eni ti O nwe ni mo, t'o d' opin A nko, Aleluya. 4. Si O, Oluko at'ore. Amona wa toto d'opin, A nko, Aleluya. 5. Si O, Eniti Kristi ran, Ade on gbogbo ebun Re, A nko, Aleluya. Amin. |
1. Ki l'o le w'ese mi nu, Ko si lehin eje Jesu; Ki l'o tun le wo mi san, Ko si lehin eje Jesu. A! eje 'yebiye, To mu mi fun bi sno Ko s'isun miran mo. Ko si lehin eje Jesu 2. Fun wenumo mi, nko ri 'Kan mi, lehin eje Jesu; Ohun ti mo gbekele Fun 'dariji, l'eje Jesu 3. Etutu f'ese ko si, Ko si lehin eje Jesu, lse rere kan ko si, Ko si lehin eje Jesu. 4. Gbogbo igbekele mi, Ireti mi l'eje Jesu; Gbogbo ododo mi ni, Eje, kiki eje Jesu. Amin. |
ONIBU ORE HYMN LYRICS Verse 1 Oluwa orun on aye Wo Niyin atope ye fun Bawo la ba ti fe o to Onibu ore Verse 2 Orun ti nran atefefe Gbogbo eweko nso fe re Wo lo nmu irugbin dara Onibu ore Verse 3 Fun ara lile wa gbogbo fun gbogbo ibukun aye Awa yin o, a si dupe a onibu ore Verse 4 O ko du wa li omo re o fi fun aye ese wa o si f'ebun gbogbo pelu onibu ore Verse 5 O fun wa l'Eni Mimo re Emi iye atagbara O rojo ekun ibukun re Le wa lori Verse 6 Fun idariji ese wa, ati fun ireti orun Ki lohun ta fin fun o O je isura ti taye Onibu ore Verse 7 Owo ti anna, ofo ni Sugbon eyi tafin fun o O je isura ti taye Onibu ore Verse 8 Ohun ta bun o Oluwa Wo o an le pada fun wa Layo la ta o lore Onibu ore Verse 9 Ni odo re lati san wa olorun olodumare Je ka le ba O gbe titi Onibu ore |
1. “Tori Mi at’ Ihinrere, E lo so t’ Irapada; Awon onse Re nke, ‘Amin’ ! Tire ni gbogbo ogo; Nwon snso tibi, tiya, t’iku, Ife etutu nla Re; Nwon ka ohun aiye s’ ofo, T’ajinde on ‘joba Re. 2. Gbo, gbo ipe ti jubili, O ndun yi gbogb’aiye ka; N’ile ati loju okun, A ntaqn ihin igbala, Bi ojo na ti nsunmole, T’ Ogun si ngbona janjan, Imole Ila – orun na Y’o mo larin okunkun. 3. Siwaju ati siwaju Lao ma gbo Halleluya, Ijo ajagun y’o ma yo, Pel’ awon oku mimo; A fo aso won n’nu eje, Duru wura won sin dun; Aiye at’orun d’ohun po, Nwon nko orin isegun. 4. O de, Enit’ a nw’ona Re, Eni ikehin na de, Immanueli to d’ade, Oluwa awon mimo, Iye, Imole at’ Ife, Metalokan titi lai; Tire ni Ite Olorun Ati t’ Odo-agutan. Amin. |
1. OLORUN aiye mi Emi ni yo si O Ore Re l'o da mi L'o da mi si sibe Ayajo ibi mi tun de Ngo sure f’ojo t’a bi mi. 2. Ni gbogbo ojo mi Ki nwa laye fun O Ki gbogbo emi mi F‘ope, iyin fun O Gbogbo ini at’iwa mi Y’o yin Eleda mi logo. 3. Gbogbo pa emi mi Y’o je Tire nikan Gbogbo akoko mi Mo ya soto fun O Jo tun mi bi l'aworan Re Ngo si ma yin O titi aiye. 4. Mo nfe se ife Re B’angel‘ ti nse l’orun Ki ndatunbi n'nu Krist’ Ki nri ‘dariji gba Mo nfe mu ‘fe pipe Re se K'ife Re ya mi si Mimo. 5. Gba ‘se na ba pari L’agbara igbagbo Tewogb’ ayanfe Re Li akoko iku Pe mi sodo bi ti Mose Gbe emi mi s‘afefe 're. Amin |
C.M.S 371 H.C 536, 8s 6 (FE 596) “Tani eyi ti ngoke Iati aginju wa, ti o fi ara ti Olufe re?" - Orin Solo: 8:5 1. JESU mimo, Ore airi Oluranlowo alaini N’nu ayida aiye, ko mi K’emi le romo O. 2. Ki nsa n’idapo mimo yi Gba ohun t’O fe ngo kun bi? B’okan mi, b’eka ajara Ba sa le romo O. 3. Are ti m‘okan mi pupo Sugbon o wa r’ibi ‘simi Ibukun si de s'okan mi Tori t’o romo O. 4. B'aiye d'ofo mo mi loju B’a gba ore at’ara lo Ni suru ati laibohun L’emi o romo O. 5. Gbat’ o k’emi nikansoso L'arin idamu aiye yi Mo gb’ohun ife jeje na Wipe, ‘Sa romo Mi‘. 6. B'are ba fe mu igbagbo T'ireti ba si fe saki Ko si ewu fun okan na T'o ba romo O. 7. Ko beru irumi aiye Nitori ‘Wo wa nitosi Ki O si gbon b’iku ba de, Tori o romo O. 8. Ire sa ni l’ohun gbogbo Wo agbara at’asa mi Olugbala, ki y’o si nkan Bi mba ti romo O. Amin |
IWO TO FE WA LA O MA SIN TITI 1. I wo to fe wa la o ma sin titi Oluwa Olore wa Iwo to n so wa n’nu idanwo aye Mimo, logo ola re Baba, iwo l’a o ma sin Baba, iwo l’a o ma bo Iwo to fe wa l’a o ma sin titi Mimo l’ogo ola re. 2. Iwo to nsure s’ohun t’a gbin s’aye T’aye fi nrohun je o Awon to mura lati ma s’oto Won tun nyo n’nu ise re. 3. Iwo to nf’agan lomo to npe ranse Ninu ola re to ga Eni t’o ti s’alaileso si dupe Fun ‘se ogo ola re 4. Eni t’ebi npa le ri ayo ninu Agbara nla re to ga Awon to ti nwoju re fun anu Won tun nyo n’nu ise re. 5. F’alafia re fun ijo re l’aye K’ore-ofe re ma ga; k’awon eni tire ko ma yo titi ninu ogo ise re. Amin. |
E FUNPE NA KIKAN 1. E funpe na kikan, Ipe ihinrere K' o dun jake jado L' eti gbogbo eda; Odun idasile ti de; Pada elese, e pada. 2. Fun 'pe t' Odagutan T' a ti pa s' etutu; Je ki agbaiye mo Agbara eje Re. Odun idasile &c. 3. Enyin eru ese E so 'ra nyin d' omo Lowo Kristi Jesu E gba omnira nyin. Odun idasile &c. 4. Olori alufa L' Olugbala ise; O fi 'ra Re rubo Arukun, aruda. Odun idasile &c. 5. Okan alare, wa, Simi lara Jesu: Onirobinuje Tujuka, si ma yo. Odun idasile tide e.t.c BLOW YE THE TRUMPET, BLOW! 1. Blow ye the trumpet, blow! The gladly solemn sound Let all the nations know, To earth’s remotest bound: Refrain The year of jubilee is come! The year of jubilee is come! Return, ye ransomed sinners, home. 2. Jesus, our great high priest, Hath full atonement made, Ye weary spirits, rest; Ye mournful souls, be glad: 3. Extol the Lamb of God, The sin atoning Lamb; Redemption by His blood Throughout the lands proclaim: 4. Ye slaves of sin and hell, Your liberty receive, And safe in Jesus dwell, And blest in Jesus live: 5. Ye who have sold for naught Your heritage above Shall have it back unbought, The gift of Jesus’ love: 6. The Gospel trumpet hear, The news of heavenly grace; And saved from earth, appear Before your Savior’s face: |
Tune:- Peace be still 1 Oluwa, iji nja kikan, Igbi omi nru s‘oke; Oju orun pelu su dudu, ‘Ranlowo ko si n‘tosi; ‘WO ko bere, bi a segbe? ‘WO y‘o ha se le sun ‘Gbati ‘seju kokan d‘eru ba wa Pe omi n‘iboji wa Egbe :- Afefe at‘igbi y‘o se fe mi; Dakeje: Ibase ‘binu riru okun, Ibase esu tabi ohunkohun, Ko si omi t‘ole ri oko na, Ti Oluwa orun at‘aye wa; Won y‘o finu didun se fe mi, Dake je, Dake Je Won y‘o finu didun se ‘fe Mi Dake je. 2. Oluwa, pel‘edun emi, Mo teriba n‘ironu; Inu okan mi ko ni 'simi, A! ji k‘O gba mi, mo be; Igbi ese on binuje Bo okan mi mole; Mo segbe, Oluwa mi mo segbe A! yara k‘O si gba mi 3 Oluwa, eru ti koju Idakeje si ti de, Orun f‘oju han nin‘ adagun Orun si wa l‘aya mi; Duro Olurapada mi, Ma fi mi sile mo; Pe l‘ayo, un o d‘ebute ibukun Un o simi l‘ebute na Amin. Master, the tempest is raging! Author: Mary Ann Baker 1 Master, the tempest is raging! The billows are tossing high! The sky is o'ershadowed with blackness, No shelter or help is nigh; Carest thou not that we perish?" How canst thou lie asleep, When each moment so madly is threat'ning A grave in the angry deep? Refrain: The winds and the waves shall obey thy will. "Peace, be still!" Whether the wrath of the storm-tossed sea, Or struggles or evil, whatever it be, No water can swallow the ship where lies the Master of ocean and earth and skies: They all shall sweetly obey thy will. "Peace, be still! Peace, be still!" They all shall sweetly obey thy will. "Peace, peace, be still!" 2 Master, with anguish of spirit I bow in my grief today; The depths of my sad heart are troubled, Oh, waken and save, I pray; Torrents of sin and of anguish Sweep o’er my sinking soul! And I perish! I perish, dear Master: Oh, hasten and take control. [Refrain] 3 Master, the terror is over, The elements sweetly rest; Earth’s sun in the calm lake is mirrored, And heaven’s within my breast. Linger, O blessed Redeemer, Leave me alone no more; And with joy I shall make the blest harbor, And rest on the blissful shore. [Refrain] -- |
Yoruba Methodist Hymn Book - 366 (Tune: Petition) 1. ’Gba ’mole yo lojiji Si Kristian’ ti nkorin ; Oluwa ni o ndide Pelu ’mularada : ’Gbati irora ndinku, On a tun fun okan N’ imole ti ntan sansan, Lati mu lara-ya. 2. Pelu ironu mimo L’ a nfi ayo lepa Oro ’gbala Olorun Ti mbe l’ otun titi. B’ a bo n’nu aro n’siyi, A le f’ ayo wipe K’ ojo ola t’ a koi ri Mu ohun t’ o wu wa. 3. Ohun to wu k’ o mu wa On y’ o mu wa la ja ; Eni daso bo koko Y’o da bo enia Re ; Labe orun t’ o teju, Ko s’ eda ti ki bo ; Eni mbo awon iwo Y’o f’ omo Re l’ onje. 4. B’ ajara tab’ opoto Ko tile so eso, Bi gbogb’ oko tile ro, T’ agbo eran segbe, Olorun mbe bakanna, Ngo korin iyin Re ; Niwon ti mo gbokanle Nko le se ki nma yo. |
Bibeli mimo torun Owon isura temi! 'Wo ti n wi bi mo ti ri, 'Wo ti n so bi mo ti wa. 'Wo nko mi, bi mo sina, 'Wo n f'ife Oluwa han; 'Wo lo si n to ese mi, 'Wo lo n dare at'ebi. 'Wo ni ma tu wa ninu, Ninu wahala aye, 'Wo n ko ni, nipa 'gbagbo Pe a le segun iku. 'Wo lo n so tayo ti n bo, Ati 'parun elese; Bibeli mimo torun, Owon isura temi. |
MO fi gbogbo re fun Jesu, MO fi gbogbo re fun Jesu, Patapata l'aiku kan, Ngó ma fe, ngó si gbekele, Ngó wa lodo re titi. CHORUS Mo fi gbogbo re (2ce) Fun o, Olugbala mi, ni Mo fi won sile. Mo fi gbogbo re fun Jesu, Mo fi rele wole fun; Mo fi gbadun ayé sile; Gbami Jesu si gba mi Mo fi gbogbo re fun Jesu, se mi ni Tire nikan Jeki kun fun Ki nmo pe 'wo je temi' Mo fi gbogbo re fun Jesu Mo fi ara mi fun o F'ife at'agbara kun mi, Ki ibukun re ba le mi. Mo fi gbogbo re fun Jesu, Mo mo p'emi ba le mi A! ayo igbala kikun! Ogo, ogo, f'ogo re. AMIN All to Jesus I surrender, All to Him I freely give, I will ever love and trust Him, In His presence daily live. I surrender all, I surrender all; All to thee, my blessed saviour, I surrender all. All to Jesus I surrender, Humbly at His feet I bow; Worldly pleasures all forsaken, Take me, Jesus, take me now All to Jesus I surrender, Lord, I give myself to Thee; Fill me with Thy love and power, Let Thy blessings fall on me. All to Jesus I surrender, Now I feel the sacred flame, O the joy of full salvation! Glory, glory to His name. |
“Iba mase pe Oluwa ti o ti wa ni tiwa” - Ps. 124:1 1. mf IBA SE p'Oluwa Ko ti wa ni tiwa, Lo yẹ k'awa ma wi, Nigba t'esu gbogun tiwa. ff Egbe: Ọpẹ ni f'Oluwa, Ọba wa Olore, A ke Kabiyesi, A f'ọpẹ fun jehofa, T'o gba wa lọwọ ọta, A dupẹ Oluwa. 2. f Wọn 'ba bo wa mọlẹ, Pẹlu agbara wọn, Ọpẹ ni f'Oluwa, Ti ko jẹ ki t'esu bori. ff Egbe: Ọpẹ ni f'Oluwa,..........etc. 3. f Ọkan wa yọ b'ẹyẹ, Nin' okun apẹyẹ, Okun ja, awa yọ, Ẹ yọ Jesu da wa silẹ. ff Egbe: Ọpẹ ni f'Oluwa,..........etc. 4. cr Tirẹ ni Oluwa, Lati gbe wa leke, Gbogbo awọn ọta, T'o wu ko tilẹ yi wa ka. ff Egbe: Ọpẹ ni f'Oluwa,..........etc. 5. cr Ara f'ọkan balẹ, S'ọdọ Olugbala, B'esu ti gbọn to ni, Ko to kini kan fun Jesu. ff Egbe: Ọpẹ ni f'Oluwa,..........etc. 6. f Iranlọwọ wa mbẹ, L'orukọ Oluwa, T'O da ọrun oun ayé, Ọba awọn ẹni mimọ. ff Egbe: Ọpẹ ni f'Oluwa,..........etc. 7. cr Ogo fun Baba wa, Ogo fun Ọmọ Rẹ, Ogo f'Ẹmi Mimọ , Mẹtalọkan jọ gbọ tiwa, ff Egbe: Ọpẹ ni f'Oluwa,..........etc. Ọba wa Olore, A ke Kabiyesi, A f'ọpẹ fun jehofa, T'o gba wa lọwọ ọta, A dupẹ Oluwa. AMIN |
Onigbagbo e bu sayo! Onigbagbo e bu sayo! 1. Onigbagbo e bu sayo! Ojo nla loni fun wa Korun fayo korin kikan, Kigbo atodan gberin E ho! E yo! Okun atodo gbogbo. 2. E jumo yo, gbogbo eda, Laye yi ati lorun, Ki gbogbo ohun alaaye Nile, loke, yin Jesu E fogo fun Oba nla ta bi loni. 3. Gbohun yin ga, "Om'Afrika" Eyin iran Yoruba; Ke "Hosanna" lohun gooro Jake jado ile wa. Koba gbogbo, Juba Jesu Oba wa. 4. E damuso! E damuso! E ho ye! Ke si ma yo, Itegun Esu fo wayi, "Iru-omobinrin" de. Halleluyah! Olurapada, Oba. 5. E gbohun yin ga, Serafu, Kerubu, leba ite; Angeli ateniyan mimo, Pelu gbogbo ogun orun. E ba wa yo! Odun idasile de. 6. Metalokan, Eni Mimo Baba Olodumare Emi Mimo, Olutunnu, Jesu, Olurapada, Gba iyin wa 'Wo nikan logo ye fun. |
1. “MO mo p’Oludande mi mbe;” Itunu nla l’eyi fun mi! O mbe, Enit’ o ku lekan; O mbe, Ori iye mi lai. 2. O mbe, lati ma bukun mi, O si mbebe fun mi loke; O mbe, lati ji mi n’boji, Lati gba mi la titi lai. 3. O mbe, Ore korikosun. Ti y’o pa mi mo de opinl; O mbe, emi o ma korin, Woli, Alufa, Oba mi. 4. O mbe, lati pese aye, Y’o si mu mi de ‘be l’ayo; O mbe, ogo l’ oruko Re; Jesu, okanna titi lai. 5. O mbe, mo bo low’ aniyan; O mbe, mo bo lowo ewu; A! ayo l’ oro yi fun mi, “Mo mo p’ Oludande mi mbe!” |
Krist' Oluwa ji loni, - Halleluyah, Eda at' Angeli nwi - Hal. Gb' ayo at' isegun ga - Hal. K' orun at' aiye gberin! - Hal. Ise ti idande tan; - Hal. O jija, O ti segun; - Hal. Wo, 'ponju orun koja - Hal. Ko wo sinu eje mo - Hal. Lasan n' iso at' ami, - Hal. Krist' woo run apadi; - Hal Lasan l' agbara iku, - Hal. Krist, si Paradise. - Hal. O tun wa, Oba ogo: - Hal. "Iku itani re wa?" - Hal. Lekan l' O ku k' O gba wa, - Hal. "'Boji, isegun re wa?" - Hal. E je k' awa goke lo, - Hal. Sodo Kristi Ori wa, - Hal. A sa jinde pelu Re, - Hal. Bi a ti ku pelu Re. - Hal. Oluwa t' aiye t' orun, - Hal. Tire ni gbogbo iyin, - Hal. A wole niwaju Re - Hal. 'Wo Ajinde at' Iye. - Hal. Source: Baptist Hymnal #118 |
O fun mi l'edidi O fun mi l'edidi, 'Gbese nla ti mo je, B'o ti fun mi, o si rerin, Pe, “Mase gbagbe mi!” O fun mi l'edidi, o san igbese na; B'o ti fun mi, o si rerin, Wi pé, “Ma ranti mi!” N ó p'edidi na mo, B'igbese tile tan; o n so ife eni t'o san, Igbese naa fun mi. Mo wo, mo si rerin Mo tun wo, mo sokun; eri ife Re si mi ni, N ó toju re titi. Ki tun s'edidi mo, Sugbon iranti ni! Pe gbogbo igbese mi ni, Emmanueli san. Amin |
1. JESU oluf’ okan mi, Je ki nsala s’ aiya Re; Sa t’ irumi sunmo mi, Sa ti iji fe s’ oke; Pa mi mo, Olugbala, Tit’ iji aiye y’o pin, To mi lo s’ ebute Re, Nikehin gb’ okan mi la. 2. Abo mi, emi ko ni, Iwo l’ okan mi ro mo; Ma f’ emi nikan sile, Gba mi, si tu mi ninu. Iwo ni mo gbekele, Iwo n’iranlowo mi, Ma sai f’iye apa Re D’abo b’ori aibo mi. 3. Krist’,’wo nikan ni mo fe, N’nu Re, mo r’ohun gbogbo; Gb’emi t’o subu dide, W’alaisan, to afoju; Ododo l’oruko Re, Alaisododo l’emi, Mo kun fun ese pupo, Iwo kun fun ododo. 4. ‘Wo l’opo ore-ofe Lati fib o ese mi: Je ki omi iwosan We inu okan mi mo; Iwo l’orisun iye, Je ki mbu n’nu Re l’ofe, Ru jade n’nu okan mi, Si iye ainipekun. 1 Jesus, lover of my soul, Let me to Thy bosom fly, While the nearer waters roll, While the tempest still is high: Hide me, O my Savior, hide, Till the storm of life is past; Safe into the haven guide; O receive my soul at last. 2 Other refuge have I none, Hangs my helpless soul on Thee; Leave, oh, leave me not alone, Still support and comfort me. All my trust on Thee is stayed, All my help from Thee I bring; Cover my defenseless head With the shadow of Thy wing. 3 Thou, O Christ, art all I want; More than all in Thee I find; Raise the fallen, cheer the faint, Heal the sick and lead the blind. Just and holy is Thy name, I am all unrighteousness; Vile and full of sin I am, Thou art full of truth and grace. 4 Plenteous grace with Thee is found, Grace to cover all my sin; Let the healing streams abound; Make and keep me pure within. Thou of life the fountain art, Freely let me take of Thee; Spring Thou up within my heart, Rise to all eternity. |
Jesu lolubaso okan mi Ore ti ko le ko mi sile Oba ti nso Ekun dayo Olutunnu okan mi Larin ota larin idamu E ko fi mi fun iji aye A Oluwa mi mo dupe Modupe modupe |
Oluwa, awa omo re de, Lati gbohun ebe wa soke, Gebebi o ti gbo adura Elijah, Jowo gbo adura wa. O gbadura k'ojo mase ro, Fun odun meta, osu mefa, Gebebi o ti gbo adura Elijah, Jowo gbo adura wa. O si tun gbadura lekeji, Ojo ro, ile si meso wa, Gebebi o ti gbo adura Elijah, Jowo gbo adura wa. Adura lo silekun anu, Adura lo si Anna ninu, Gebebi o ti gbo adura Elijah, Jowo gbo adura wa. Amin |
Laifoya lapa Jesu, Laifoya laya Re Labe ojiji 'fe Re Lokan mi yo sinmi. Gbo ohun angeli ni, Orin won deti mi, Lati papa ogo wa, Lati okun Jaspi. Refrain: Laifoya lapa Jesu Laifoya laya Re Labe ojiji 'fe Re Lokan mi yo sinmi. Laifoya lapa Jesu Mo bo low'aniyan, Mo bo lowo idanwo, Ese ko nipa mo, Mo bo lowo 'banuje, Mo bo lowo eru O ku idanwo die! O k'omije die! Jesu abo okan mi, Jesu ti ku fun mi, Apata ayeraye Lemi o gbekele, Nihin lemi o duro Tit'oru yo koja, Titi n o fi rimole Ni ebute ogo. Source: Yoruba Baptist Hymnal #254 Safe in the arms of Jesus, Safe on His gentle breast; There by His love o’ershaded, Sweetly my soul shall rest. Hark! ’tis the voice of angels Borne in a song to me, Over the fields of glory, Over the jasper sea. Refrain: Safe in the arms of Jesus, Safe on His gentle breast; There by His love o’ershaded, Sweetly my soul shall rest. Safe in the arms of Jesus, Safe from corroding care, Safe from the world’s temptations; Sin cannot harm me there. Free from the blight of sorrow, Free from my doubts and fears; Only a few more trials, Only a few more tears! Jesus, my heart’s dear Refuge, Jesus has died for me; Firm on the Rock of Ages Ever my trust shall be. Here let me wait with patience, Wait till the night is o’er; Wait till I see the morning Break on the golden shore. |
1. MO gbohun Jesu t’ o wipe, “Wa simi lodo Mi; Gbe ori re, ‘wo alare, Le okan aiya Mi.” Ninu are on ‘banuje, Ni mo to Jesu wa; O je ib’ isimi fun mi, O si mu ‘nu mi dun. 2. Mo gbohun Jesu t’ o wipe “Iwo ti ongbe ngbe, Ngo f’ omi ‘ye fun o lofe, Bere, mu k’ o si ye.” Mo to Jesu wa, mo si mu Ninu omi ‘ye na; Okan mi tutu, o soji, Mo d’ eni alaye. 3. Mo gbohun Jesu t’ o wipe, ” ‘Mole aiye l’ emi; Wo Mi, Emi ni Orun re, Ojo re yio dara.” Mo wo Jesu, emi si ri B’ Orun ododo mi, Ninu ‘mole yi l’ emi o rin Tit’ ajo mi yio pin. |
Emi orun, gbadura wa, Wa gbenu ile yi Sokale pel'agbara Re, Wa, Emi Mimo wa. Wa b'imole, si fihan wa Baini wa ti po to; Wa, to wa si ona iye, Ti olododo n rin. Wa bi ina ebo mimo: Sokan wa di mimo; Je ki okan wa je ore, Foruko Oluwa. Wa bi iri, si wa bukun Akoko mimo yi: Ki okan alaileso wa Le yo l'agbara Re. Wa bi adaba, n'apa Re, Apa ife mimo; Wa je ki ijo Re laye Dabi ijo torun. Emi orun, gbadura wa, Saye yi dile Re; Sokale pel'agbara Re, Wa, Emi Mimo wa. |
*Ore Wo L’ani Bi Jesu* Ore wo l’ani bi Jesu, ti o ru banuje wa! Anfani wo lo po bayi lati ma gbadura si! Alafia pupo l’a nsonu, a si ti je rora po, Tori a ko fi gbogbo nkan s’adura niwaju re. Idanwo ha wa fun wa bi? A ha nni wahala bi? A ko gbodo so ’reti nu; sa gbadura s' Oluwa. Ko s’oloto ore bi re ti ole ba wa daro, Jesu ti mo ailera wa; sa gbadura s’Oluwa. Eru ha nwo wa l’orun bi, aniyan ha po fun wa? Olugbala je abo wa, sa gbadura s’Oluwa. Awon ore ha sa o ti? Sa gbadura s’Oluwa. Yo gbe o soke lapa re, Iwo yo si ri itunu. Amin |
Bi mo ti ri laisawawi, Sugbon nitori eje Re; B’o si ti pe mi pe ki mwa Olugbala, mo de. Bi mo ti ri laiduro pe, Mo fe k’okan mi mo toto, S’odo Re t’o le we mi mo, Olugbala, mo de. Bi mo ti ri b’o tile je Ija l’ode, ija ninu, Eru l’ode eru ninu, Olugbala, mo de. Bi mo ti ri osi, are, Mo si nwa imularada; Iwo l’o le s’awotan mi, Olugbala, mo de. Bi mo ti ri ’Wo o gba mi, Wo o gba mi t’owo t’ese; ’Tori mo gba ’leri Re gbo, Olugbala, mo de. Bi mo ti ri ife Tire, L’o sete mi patapata; Mo di tire, tire nikan, Olugbala, mo de. Amin. |
1. Are mu O, okan re poruru So fun Jesu, so fun Jesu; Ibanuje dipo ayo fun O? So fun Jesu nikan. So fun Jesu, So fun Jesu, On l'ore ti o mo; Ko si ore tabi 'yekan bi Re So fun Jesu nikan. 2. Asun-dekun omije lo nsun bi? So fun Jesu, So fun Jesu, Iwo l'ese ti enikan ko mo? So fun Jesu nikan. 3. Iwo nfoya 'banuje ti mbe bi? So fun Jesu, So fun Jesu: Iwo ns'aniyan ojo ola bi? So fun Jesu nikan. 4. Ironu iku nda o lamu bi? So fun Jesu, So fun Jesu: O nsaferi ijoba Jesu bi? So fun Jesu nikan. Amin. |
O fun mi l'edidi O fun mi l'edidi, 'Gbese nla ti mo je, B'o ti fun mi, o si rerin, Pe, “Mase gbagbe mi!” O fun mi l'edidi, o san igbese na; B'o ti fun mi, o si rerin, Wi pé, “Ma ranti mi!” N ó p'edidi na mo, B'igbese tile tan; o n so ife eni t'o san, Igbese naa fun mi. Mo wo, mo si rerin Mo tun wo, mo sokun; eri ife Re si mi ni, N ó toju re titi. Ki tun s'edidi mo, Sugbon iranti ni! Pe gbogbo igbese mi ni, Emmanueli san. Amin |
The name the name of Jesus Is greater and higher than all names It is not an ordinary name It's the name that full of power and grace. At the name all sickness will bow Demons tremble at the sound of the name It is not an ordinary name It's a name that full of power and grace..... |