Welcome, Guest: Register On Nairaland / LOGIN! / Trending / Recent / New
Stats: 3,152,318 members, 7,815,607 topics. Date: Thursday, 02 May 2024 at 03:12 PM

Obasolape's Posts

Nairaland Forum / Obasolape's Profile / Obasolape's Posts

(1) (2) (3) (4) (5) (6) (7) (of 7 pages)

Religion / Re: Share Your Best Hymns by obasolape(f): 7:25am On Apr 30
1. Iyin f'Eni mimo julo
L'oke ati ni 'le;
Oro Re gbogbo je 'yanu,
Gbogb' ona Re daju.

2. Ogbon Olorun ti po to
Gbat' eniyan subu;
Adam' keji wa s'oju 'ja .
Ati lati gbala.

3. Ogbon ife! p'eran ara
T'o gbe Adam' subu
Tun b'ota ja ija otun
K'o ja, k'o si s'egun.

4. Ati p'ebun t'o j' or-ofe
So ara di otun
Olorun Papa tikare
J'Olorun ninu wa.

5. Ife 'yanu! ti Eni ti
O pa ota en'yan
Ninu awo awa en'yan
Je irora F'en'yan.

6. Nikoko, ninu ogba ni
Ati l'ori igi
T'o si ko wa lati jiya
T'o ko wa lati ku.

7. Iyin f'Eni mimo julo
L'oke ati nile
Oro Re gbogbo je 'yanu
Gbogb' ona Re daju.
Amin
Religion / Re: Share Your Best Hymns by obasolape(f): 1:06am On Apr 12
Omode, e sunm’ Olorun,
Pelu irele at’ eru;
Ki ekun gbogbo wole fun
Olugbala at’ Ore wa.

Oluwa, je k’ anu Re nla,
Mu wa kun fun ope si O;
Ati b’ a ti nrin lo l’ aiye,
K’ a ma ri opo anu gba.

Oluwa! m’ ero buburu,
Jinna rere si okan wa;
L’ ojojumo fun wa l’ ogbon,
Lati yan ona toro ni.

Igba aisan, at’ ilera
Igba aini tabi oro;
Ati l’ akoko iku wa,
Fi agbara Tire gba wa.

Amin.
Religion / Re: Share Your Best Hymns by obasolape(f): 12:07pm On Apr 11
1. OLORUN aiye mi
Emi ni yo si O
Ore Re l'o da mi
L'o da mi si sibe
Ayajo ibi mi tun de
Ngo sure f’ojo t’a bi mi.

2. Ni gbogbo ojo mi
Ki nwa laye fun O
Ki gbogbo emi mi
F‘ope, iyin fun O
Gbogbo ini at’iwa mi
Y’o yin Eleda mi logo.

3. Gbogbo pa emi mi
Y’o je Tire nikan
Gbogbo akoko mi
Mo ya soto fun O
Jo tun mi bi l'aworan Re
Ngo si ma yin O titi aiye.

4. Mo nfe se ife Re
B’angel‘ ti nse l’orun
Ki ndatunbi n'nu Krist’
Ki nri ‘dariji gba
Mo nfe mu ‘fe pipe Re se
K'ife Re ya mi si Mimo.

5. Gba ‘se na ba pari
L’agbara igbagbo
Tewogb’ ayanfe Re
Li akoko iku
Pe mi sodo bi ti Mose
Gbe emi mi s‘afefe 're. Amin
Religion / Re: Share Your Best Hymns by obasolape(f): 3:27am On Apr 07
Alabukun n’nu Jesu
Ni awon om’ Olorun,
Ti a fi eje Re ra
Lat’ inu iku s’iye;

Egbe:
A ba je ka wa mo won,
L’aiye yi, ati l’orun.

Awon ti a da l’are
Nipa ore-ofe Re;
A we gbogbo ese won,
Nwon o bo l’ojo ’dajo;

Egbe:
A ba je ka wa...

Nwon ns’eso ore-ofe;
Ninu ise ododo,
Irira l’ese si won,
Or’ Olorun ngbe ’nu won;

Egbe:
A ba je ka wa...

Nipa ej’ Odagutan,
Nwon mba Olorun kegbe,
Pelu Ola-nla Jesu,
A wo won l’aso ogo;

Egbe:
A ba je ka wa...

Amin.
Religion / Re: Share Your Best Hymns by obasolape(f): 6:28am On Mar 30
Tune name: #st. Agnes
m:m:m:r:-m:f:-t:d:-:-
s:s:s:m:-r:r:-:-
f:f:m:r:-d:t:-l:s:-:-
s:l:d:m:-r:d:-:-

1. Okan mi, sunmo ’te anu,
Nibi Jesu ngb’ ebe,
F’ irele wole l’ese Re,
’Wo ko le gbe nibe.

2. Ileri Re, ni ebe mi,
Eyi ni mo mu wa;
Iwo npe okan t’ eru npa,
Bi emi, Oluwa.

3. Eru ese wo mi l’orun,
Esu nse mi n’ ise;
Ogun l’ode, eru ninu,
Mo wa isimi mi.

4. Se Apata at’ Asa mi,
Ki nfi O se abo;
Ki ndoju ti Olufisun,
Kin so pe Kristi ku.

5. Ife iyanu ! Iwo ku,
Iwo ru itiju;
Ki elese b’ iru emi,
Le be l’ oruko Re. Amin.
Religion / Re: Share Your Best Hymns by obasolape(f): 4:36am On Mar 24
Oluwa gunwa lori’te
Akobi awon t’o sun
On nikan l’Onigbeja wa
To ngbe wa leke ota
Aleluya, Aleluya
Jesu li Onje Iye.

Awa njuba, awa nsape
Kabiyesi Oba wa,
Busi igbagbo wa loni
K’a le tubo mo O si,
Aleluya, Aleluya
Iwo njoba larin wa.

Bi a ko tile ri O
Bi t’awon ti igbani,
A wa at’awon Angeli
Nyin iru-omo Jese
Aleluya, Aleluya
Tewo gba ijosin wa.

Od’agutan t’a fi rubo
Ti s’etutu f’ese wa
Ko tun si ebo miran mo
Eje Re ti to fun wa.
Aleluya, Aleluya
Eje na lo we wa mo.

O nfi onje iye bo wa
Manna didun lat’orun
K’orun at’aye korin na
Orin ‘yin s’Od’agutan.
Aleluya, Aleluya
O jinde, O si goke

Amin.
Religion / Re: Share Your Best Hymns by obasolape(f): 4:28am On Mar 24
Hosanna s'omo Dafidi
Hosanna, e korin
Olubukun l'Eniti mbo
L'oruko Oluwa.

Hosanna s'omo Dafidi
L'egbe Angeli nke
Gbogbo eda jumo gberin
Hosanna s'Oba wa

Hosanna awon Heberu
Ja imo ope s'ona
Hosanna e mu ebun wa
Fi tun ona Re se.

T'agba t'ewe nke Hosanna
Ki ijiya Re to de
Loni a si nko Hosanna
B'O ti njoba loke

B'O ti gba'yin won nigbanaa
Jo gba ebe wa yi
Lorun k'a le ba Angeli korin
Hosanna s'Oba wa.

Amin.

Happy Palm Sunday.
Religion / Re: Share Your Best Hymns by obasolape(f): 4:26am On Mar 24
Ma gesin lo l’olanla Re;
Gbo ! gbobg’ aiye nke “Hosanna”;
Olugbala, ma lo pele
Lori im’ ope at’ aso.

Ma gesin lo l’olanla Re;
Ma f’ irele gesin lo ku:
Kristi, ’segun Re bere na,
Lori ese ati iku.

Ma gesin lo l’olanla Re;
Ogun angeli lat’ orun
Nf’iyanu pelu ikanu
Wo ebo to sunmole yi.

Ma gesin lo l’olanla Re;
Ija ikehin na de tan;
Baba, lor’ ite Re lorun,
Nreti ayanfe Omo Re.

Ma gesin lo l’olanla Re;
Ma f’irele gesin lo ku:
F’ara da irora f’eda:
Lehin na, nde, k’o ma joba.

Amin.
Religion / Re: Share Your Best Hymns by obasolape(f): 4:24am On Mar 24
Hosanna s'omo Dafidi
Hosanna, e korin
Olubukun l'Eniti mbo
L'oruko Oluwa.

Hosanna s'omo Dafidi
L'egbe Angeli nke
Gbogbo eda jumo gberin
Hosanna s'Oba wa

Hosanna awon Heberu
Ja imo ope s'ona
Hosanna e mu ebun wa
Fi tun ona Re se.

T'agba t'ewe nke Hosanna
Ki ijiya Re to de
Loni a si nko Hosanna
B'O ti njoba loke

B'O ti gba'yin won nigbanaa
Jo gba ebe wa yi
Lorun k'a le ba Angeli korin
Hosanna s'Oba wa.

Amin.
Religion / Re: Share Your Best Hymns by obasolape(f): 4:24am On Mar 22
Are mu O, okan re poruru?
So o fun Jesu:
Ibanuje dipo ayo fun o?
So o fun Jesu nikan.

Egbe:
So o fun Jesu; so o fun Jesu
Oun lore ti yoo mo
Ko tun sore
Ati'yekan bi Re
So o fun Jesu nikan

Asun-dakun omije lo nsun bi?
So o fun Jesu, so o fun Jesu,
O l'ese to farasin f'eniyan
So o fun Jesu nikan

Egbe:

'Banuje teri okan re ba bi?
So o fun Jesu, so o fun Jesu
O ha nsaniyan ojo ola bi?
So o fun Jesu nikan

Egbe:

Ironu iku mu o damu bi?
So o fun Jesu, so o fun Jesu
Okan re nfe ijoba Jesu bi!
So o fun Jesu nikan

Egbe:

Amin.
Religion / Re: Share Your Best Hymns by obasolape(f): 4:30am On Mar 17
Jesu, a fe pade,
Lojo Re mimo yi;
A si yite Re ka,
Lojo Re mimo yi:
'Wo Ore wa orun,
Adura wa n bo wa,
Boju wo emi wa
Lojo Re mimo yi.

A ko gbodo lora,
Lojo Re mimo yi
Li eru a kunle
Lojo Re mimo yi;
Ma taro ise wa,
K'Iwo ko si ko wa,
Ka sin O bo ti ye
Lojo Re mimo yi

A teti soro Re
Lojo Re mimo yi;
Bukun oro ta gbo,
Lojo Re mimo yi;
Ba wa lo 'gbat'a lo,
Fore igbala Re
Si aya wa gbogbo,
Lojo Re mimo yi.

Amin.
Religion / Re: Share Your Best Hymns by obasolape(f): 11:27am On Mar 15
BI mo ti ri – laisawawi,
Sugbon nitori eje Re,
B’O si ti pe mi pe ki nwa –
Olugbala, mo de.

Bi mo ti ri – laiduro pe,
Mo fe k’okan mi mo toto,
Sodo Re t’o le we mi mo.
Olugbala, mo de.

Bi mo ti ri -b’o tile je
Ija l’ode, ija ninu;
Eru l’ode, eru ninu –
Olugbala, mo de.

Bi mo ti ri -osi, are,
Mo si nwa imularada;
Iwo l’o le s’awotan mi –
Olugbala, mo de.

Bi mo ti ri -‘wo o gba mi,
‘wo o gba mi t’owo t’ese
‘Tori mo gba ‘leri Re gbo –
Olugbala, mo de.

Bi mo ti ri – ife Tire
L’ o sele mi patapata;
Mo di Tire, Tire nikan –
Olugbala, mo de.

Amin.
Religion / Re: Yoruba Hymn by obasolape(f): 7:53am On Mar 09
GBO OHUN JÉSÙ TO NKE PE

1 Gbo ohun Jesu ti nke pe,
Tani yio sise loni?
Oko pon pupo sise loni?
Tani yio lo ka a?
Kikankikan l' Oluwa npe,
Ebun nla l' O fi fun o,
Tani yio f' ayo dahun pe,
"Emi ni; ran mi, ran mi.

2 B' iwo ko le la okun lo,
Lati wa 'won keferi,
O le ri nwon nitosi re,
Nwon wa l' enu-ona re;
B' o ko le fi wura tore,
O le fi baba ore,
Die t' o si se fun Jesu,
'Yebiye ni l' oju Re.

3 B' o ko le s' oro b' angeli,
B' o ko le wasu bi Paul',
Iwo le so t'ife Jesu,
Iwo le so ti iku Re;
B' iwo ko le ji elese
Ninu ewu idajo,
'Wo le ko awon omode
Li ona t' Olugbala.

4 B' iwo ko le k' agbalagba,
Krist' Olusagutan ni,
"Bo awon od'-agutan Mi,
Gbe onje ti won lodo:"
O le je pea won 'mode
T' o ti fi owo re to,
Ni yio wa larin oso re
Gbat'o ba de 'le rere.

5 Ma jek' enia gbo wipe,
"Ko si nkan t' emi le se,"
Nigbat' awon keferi nku,
Ti Oluwa si npe o,
F' ayo gba ise t' O ran o,
K' ise Re je ayo re;
F' ayo dahun gbat' O pe o
Pe, "Emi ni yi, ran mi."
Religion / Re: Yoruba Hymn by obasolape(f): 8:21am On Mar 07
A O PADE LETI ODO

1 A o pa de leti odo,
T’ese angeli ti te;
T’o mo gara bi kristali;
Leba ite olorun?

Egbe:
A o pade leti odo
Odo didan, odo didan na
Pel’ awon mimo leba odo
T’o nsan leba ite ni.

2 Leti bebe odo na yi
Pel’ Olusaguntan wa,
A o ma rin a o ma sin
B’a ti ntele ’pase Re. [Egbe]

3 K’a to de odo didan naa,
A o s’eru wa kale
Jesu y’o gba eru ese
Awon ti y’o de l’ade. [Egbe]

4 Nje l’eba odo tutu na,
A o r’oju Olugbala;
Emi wa ki o pinya mo
Yi o korin ogo Re. [Egbe]
Religion / Re: Yoruba Hymn by obasolape(f): 4:24am On Mar 07
OLORUN mi! Olorun mi!
Mo f’ ara mi fun O;
Dari aisedede ji mi,
Ma je ki nsako mo,

Egbe:
F’ oju anu wo mi,
Ma je ki ndese mo,
Se mi l’ oniwa rere;
Bi awon angeli.

Olorun mi! Olorun mi!
We mi n’nu eje Re;
Fi hisopu fo mi Baba,
Emi yio si mo.

Egbe:

Olorun mi! Olorun mi!
Mu ese mi duro;
Ki nma siyemeji l’ ona,
Ti O dari mi si.

Egbe:

Olorun mi! Olorun mi!
Jo, ranti, mi loni,
Ka mi m’ awon ayanfe Re,
Ke mi, k’ o si ge mi.

Egbe:

Olorun mi! Olorun mi!
Aiye nfe rerin mi,
Esu nin’ agbara re nla
Gbe tosi re si mi,

Egbe:

Olorun mi! Olorun mi!
Mo kanu ese mi,
Ese l’ o ti gbe mi subu,
Ti nko fi le sin O.

Egbe:

Se ‘gba mi ni tire,
Ma jeki nw’ ehin mo,
Ki mba o rin l’ aiye yi,
Ki nle gb’ adun orun.

Egbe:

Amin.
Religion / Re: Yoruba Hymn by obasolape(f): 1:00am On Mar 07
3rd Wednesday in Lent

IOM 147

1. Iwo low’ enit’ ire nsan,
Mo gb’ okan mi si O;
N’ ibanuje at’ ise mi,
Oluwa, ranti mi.

2. ’Gba mo nkerora l’ okan mi,
T’ese wo mi lorun:
Dari gbogbo ese ji mi,
Ni ife ranti mi.

3. Gba ’danwo kikan yi mi ka,
Ti ibi le mi ba;
Oluwa, fun mi l’ agbara,
Fun rere, ranti mi.

4. Bi ’tiju at’ egan ba de,
’Tori Oruko Re;
Ngo yo s’egan, ngo gba ’tiju,
B’ iwo bar anti mi.

5. Oluwa, ’gba iku ba de,
Em’ o sa ku dandan;
K’ eyi j’ adura gbehin mi,
Oluwa, ranti mi. Amin.

1. Iwo low’ enit’ ire nsan,
Mo gb’ okan mi si O;
N’ ibanuje at’ ise mi,
Oluwa, ranti mi.

2. ’Gba mo nkerora l’ okan mi,
T’ese wo mi lorun:
Dari gbogbo ese ji mi,
Ni ife ranti mi.

3. Gba ’danwo kikan yi mi ka,
Ti ibi le mi ba;
Oluwa, fun mi l’ agbara,
Fun rere, ranti mi.

4. Bi ’tiju at’ egan ba de,
’Tori Oruko Re;
Ngo yo s’egan, ngo gba ’tiju,
B’ iwo bar anti mi.

5. Oluwa, ’gba iku ba de,
Em’ o sa ku dandan;
K’ eyi j’ adura gbehin mi,
Oluwa, ranti mi. Amin.
Religion / Re: Yoruba Hymn by obasolape(f): 3:14pm On Mar 06
ISUN kan wa t’o kun f’eje
1. ISUN kan wa t’o kun f’eje
O yo n’iha jesu,
Elese mokun ninu re,
O bo ninu ebi.

2. ‘Gba mo f’igbagbo r’isun na,
Ti nsan fun ogbe Re,
Irapada d’orin fun mi
Ti ngo ma ko titi.

3. Ninu orin t’odun julo,
L’emi o korin Re:
‘Gbat’ akololo ahon yi
Ba dake n’iboji.

4. Mo gbagbo p’O pese fun mi
(Bi mo tile s,aiye )
Ebun ofe t’a f’eje ra,
Ati duru wura.

5. Duru t’a tow’ Olorun se,
Ti ko ni baje lai;
T’a o ma fi yin Baba wa,
Oruko Re nikan.

DOWNLOAD FROM PLAYSTORE
Religion / Re: Yoruba Hymn by obasolape(f): 6:44pm On Mar 03
Christ is our cornerstone

N'nu Krist' nikan nireti mi,
O'n n'imọlẹ, agbara, orin mi;
Igun-ile yii, Apata yii,
Wa sibẹ nin' ọda 'ti'ji.
Ifẹ giga, ibalẹ okan,
'Gbati 'bẹru, idamu pin!
Olutunu, Oun ni mo ni,
Ninu 'fẹ Kristi mo duro.

N'nu Krist' nikan, t'O wa leeyan
Ọlọrun to wa bí ìkókó!
Ẹbun 'fẹ yii at' ododo
T'awọn t'O wa gbala kẹgan:
Lori igi ti Jesu ku,
Irunu Ọlọrun walẹ-
Tori pẹ'ṣẹ wa lo gberu;
Ninu 'ku Kristi ni mo ye.

Nibẹ 'nu 'lẹ l'oku Rẹ wa
Imọlẹ aye t'ookun pa:
Lẹyin eyi lọjọ ologo
O ji dide kuro 'nu oku!
B'O si ti duro n'iṣẹgun
Mo bọ lọwọ egun ẹṣẹ,
Mo jẹ Tirẹ, Oun temi-
Emi ta fẹjẹ Kristi ra.

Niye, niku, ko si 'foya,
Agbara Kristi 'nu mi ni;
Lati 'bẹrẹ titi dopin,
Jesu gba ayanmo mi mu.
Ogun eṣu, ete aye
Ki yoo le gba mi lowo Rẹ,
'Ti y' O fi de, tabi pe mi
N o duro 'nu agbara Kristi.

Amin.
Religion / Re: Yoruba Hymn by obasolape(f): 7:09am On Mar 03
Idapo didun, ayo atoke wa
’Sinmi le apa ayeraye
Ibukun pupo, ifokanbale
’Sinmi le apa ayeraye

Egbe:
Sinmi, sinmi
Eru ko ba mi, aya ko fo mi
Sinmi, sinmi
Sinmi le apa ayeraye

Bo ti dun to lati rin ajo yii
’Sinmi le apa ayeraye
B'ona na ti n’mole sii lo'jumo
’Sinmi le apa ayeraye

Egbe:

N o se wa foya, n o se wa beru,
’Sinmi le apa ayeraye
Okan mi bale, Jesu sunmo mi
’Sinmi le apa ayeraye

Egbe:
Religion / Re: Yoruba Hymn by obasolape(f): 12:28am On Feb 25
Yin Oluwa, orun wole
1. Yin Oluwa, orun wole
Yin enyin mimo l’ oke
K’ orun at’ osupa ko,
K’ awon ‘rawo f’ iyin fun.

2. Yin Oluwa, O ti s’ oro,
Awon aiye gb’ ohun Re,
Fun nwon O fi ofin le’le,
T’ a ko le baje titi.

3. Yin, nitoriti O l’ ola,
Ileri Re ko le yi;
O ti mu awon enia Re
Bori iku on ese.

4. Yin Olorun igbala wa,
Ogun orun, so pa Re,
Orun, aiye, gbogbo eda,
Yin, k’ e gb’ oruko Re ga.
Religion / Re: Yoruba Hymn by obasolape(f): 12:26am On Feb 25
Jesus, the Sun of Righteousness

1. Jesu, Orun ododo,
Iwo imole ife;
Gbat’ imole owuro
Ba nt’ ila orun tan wa,
Tan'mole ododo Re
Yi wa ka.

2 Gege bi iri tin se
S'ori eweko gbogbo,
K’ Emi ore-ofe Re
So okan wa di otun;
Ro ojo ibukun Re
Sori wa.

3 B’ imole orun tin ran,
K’ imole ife Tire,
Si ma gbona l’okan wa;
K’o si mu wa l’ara ya,
K’a le ma f’ayo sin O
L’aiye wa.

4 Amona, Ireti wa,
Ma fi wa sile titi;
Fi wa sabe iso Re
Titi opin emi wa,
Sin wa la ajo wa ja
S’ ile wa.

5. Pa wa mo n’nu ife Re
Lojo aiye wa gbogbo,
Si mu wa bori iku,
Mu wa de ‘le ayo na,
K’a le b’ awon mimo gba
Isimi. Amin.
Religion / Re: Yoruba Hymn by obasolape(f): 9:24pm On Feb 23
Ka to sun Olugbala wa
Fun wa nibukun ale
A jewo ese wa fun O
Iwo lo le gba wa la
Bi ile tile su dudu
Okun ko le se wa mo
Iwo eni ti kii saare
So awon eniyan Re

Ni irele a fara wa
Sabe abo Re Baba
Jesu 'Wo to sun bi awa
Se orun wa bi tire
Emi mimo rado bo wa
So wa lokunkun oru
Tit'awa yo fi ri ojo
Imole ayeraye

B'iparun tile yi wa ka
Ti ofa n fo wa koja
Awon angeli yi wa ka
Awa o wa lailewu
Sugbon biku ba ji wa pa
T'ibusun wa diboji
Je kile mo wa sodo Re
Layo atalafia.

Amin.
Religion / Re: Yoruba Hymn by obasolape(f): 10:02pm On Feb 18
Hymn Title: Ogo ni f'Oluwa (To God be the glory)
Language: Yoruba (Subtitled in English)

lyrics
1. Ogo ni f'Oluwa to se ohun nla
Ife lo mu k'O fun wa ni OmO Re,
Enit'O f'emi Re lele f'ese wa
To si silekun iye sile fun wa.

Yin Oluwa, Yin Oluwa,
F'iyin fun Oluwa,
Yin Oluwa, Yin Oluwa,
E yo niwaju Re,
Ka to Baba wa lo l'Oruko Jesu,
Je k'a jo f'ogo fun Onise-yanu.

2. Irapada kikun ti eje Re ra
F'enikeni t'o gba ileri Re gbo,
Enit'o buruju b'o ba le gbagbo,
Lojukanna y'o ri idariji gba.

3. O s'ohun nla fun wa, O da wa l'ola
Ayo wa di kikun ninu Omo Re
Ogo ati ewa irapada yi
Y'o ya wa lenu 'gbat' a ba ri Jesu

#hymn #HymnSinging #yorubahymn

1 Like

Religion / Re: Yoruba Hymn by obasolape(f): 3:48pm On Feb 18
Ninu irin ajo mi, beni mo nkorin
Mo n toka si Kalfari n’ibi eje na
Idanwo lode ninu l’ota gbe dide
Jesu lo nto mi lo, isegun daju

Egbe:
A! mo fe ri Jesu kin ma w’oju Re
Kin ma korin titi nipa ore Re
Ni ilu ogo ni ki ngbohun soke
Pe mo bo, ija tan, mo de ile mi.

Ninu ise isin mi, b’okunkun basu
Un o tubo sunmo Jesu, y’o tan imole
Esu le gb’ogun ti mi, kin le sa pada
Jesu lo nto mi lo, ko se’wu fun mi.

Egbe:

Bi mo tile bo sinu afonifoji
Imole itoni Re yio mole simi
Yio na owo re simi, Yio gbe mi soke
Un o ma tesiwaju, b’o ti nto mi lo.

Egbe:

Nigbati iji aye yi ba yi lu mi
Mo ni abo t’o daju, labe apa re
Yio ma f’owo Re to mi titi de opin
Ore ododo ni, A! mo ti f’e to.

Egbe:

Amin.
Religion / Re: Yoruba Hymn by obasolape(f): 5:04am On Feb 17
Jesus keep me near the cross

1. Fa mi sun m'agbelebu
Orisun iwosan
Itunnu fun else
Iye f'eni nku lo
Agbelebu Jesu
Ni y'o je ogo mi
Titi ngo fi goke lo
S'ibi isimi mi

2. Nib'agbelebu mo ri
Anu, ife Jesu
N'ibe l'Orun ododo
Ti ran si okan mi

3. Nib'agbelebu mo ri
Odagutan t'a pa
'Jojumo ran mi leti
Ijiya kalfari

4. Kin gbadura kin sora
Nibi agbelebu
Ki iranti ife Re
Ma fi mi 'le titi
Religion / Re: Yoruba Hymn by obasolape(f): 8:42am On Feb 09
Emi o ma korin anu Oluwa laelae. OD. 89:1.

1. mf Olorun ‘gba’okan mi wo
Gbogbo anu Re nla,
Iran na mu ki emi kun
Fun ‘yanu, ‘fe iyin.

2. f Itoju Re fi aimoye
Itunu f’okan mi,
K’okan omode mi to mo
‘Bi ti ‘re na ti nsan.

3. mf L’ona yiyo odomode
Mo sare laiwoye:
Owo anu Re l’o to mi
Titi mo fi dagba.

4. Larin ewu, ati iku,
O nto isise mi;
Ati n’nu ikekun ese
T’o li eru julo.

5. mp Nigbat’aisan je mi l’ara,
‘Wo tun fun mi l’okun
‘Wo f’or’-ofe mu mi soji
Gbat’ese bori mi.

6. mf Fun egbegberun ebun Re,
Mo nsope lojojo;
Ati f’okan t’o m’ore Re,
Ti ngba won pel’ayo.

7. Ni gbogbo igba aye mi
Un o lepa ore Re;
di Leyin iku, l’aye ti mbo,
cr Un o tun ore Re so.

8. f Un o ma korin ope si O,
Titi ayeraye;
ff Sugbon ayeraye ko to
So gbogbo iyin Re!

Amin.
Religion / Re: Yoruba Hymn by obasolape(f): 6:02am On Feb 09
Wa sodo Jesu, ma se duro
N'nu oro Re lo ti fona han wa
O duro ni arin wa loni
O n wi jeje pe, "Wa"

Egbe:
Ipade wa yio je ayo
Gb'okan wa ba bo lowo ese
A o si wa pelu Re Jesu
Ni ile wa lailai

Je k'omode wa
A! Gb'ohun Re
Je kokan gbogbo fo fun ayo
Ki a si yan A layanfe wa
Ma duro, sugbon wa

Egbe:

Tun ro, O wa pelu wa loni
F'eti s'ofin Re ko si gboran
Gbo b'ohun Re ti n wi pele pe,
"Wa, omo mi, e wa!"

Egbe:

Amin.
Religion / Re: Yoruba Hymn by obasolape(f): 8:55am On Feb 06
EMI o kokiki Rẹ, Oluwa,
Iwọ ni o da mi n'ide,
Iwọ ni ko jẹ ki ọta yọ mi,
Ogo ni f'orukọ Rẹ.

Egbe: Iyin, Ọla, Ogo ni fun Ọ,
Agbara ati ipa jẹ Tirẹ,
Ẹgbẹrun ahọn ko to yin Ọ,
A wolẹ, a juba Rẹ.

Oluwa mi, emi kigbe pe Ọ,
Iwọ si mu mi lara da;
O yọ ọkan mi ninu 'sa oku,
O si pa mi mọ l'aye.

Egbe:
Iyin, Ọla, Ogo...

Kọrin s'Oluwa ẹyin Séráfù,
K'ẹ si dupẹ n'iwa mimọ Rẹ,
Ibinu Rẹ ki pẹ ju 'sẹju kan,
Iye l'oju rere Rẹ.

Egbe:
Iyin, Ọla, Ogo…

Bi ẹkun tilẹ pẹ di alẹ kan,
Sibẹ ayọ de l'Owurọ;
Alafia si de ni ọsan gangan;
Mo tun di ipo mi mu.

Egbe:
Iyin, Ọla, Ogo...

Nigba t'Oluwa pa oju rẹ mọ,
Ẹnu ya mi mo si kigbe;
A! Ki l'ere ẹjẹ mi, Oluwa,
Gba mba koju s'isa oku?

Egbe:
Iyin, Ọla, Ogo...

Bayi l'Oluwa mi gbọ igbe mi,
O si sọ kanu mi d'ijo;
O bọ asọ ọfọ kuro l'ọrun mi,
O f'amure ayọ di mi.

Egbe:
Iyin, Ọla, Ogo…

A! Ogo mi dide si ma kọrin
Ma fi ayọ kọrin s'oke;
Oluwa n ó fi ọpẹ fun Ọ,
N ó si ma yin Ọ lailai.

Egbe:
Iyin, Ọla, Ogo…

Amin.
Religion / Re: Yoruba Hymn by obasolape(f): 9:54am On Feb 03
1. Mo f’ emi mi sabe
Itoju Re Jesu;
‘Wo ko jo mi l’ ainireti,
‘Wo l’ Olorun Ife.

2. ‘Wo ni mo gbekele
‘Wo ni mo f’ara ti:
Rere at’ Otitio ni O,
Eyi t’ O se l’ o to.

3. Ohun t’o wu k’o de,
Ife re ni nwon nse:
Mo f’ ori pamo saiya Re,
Nko foiya iji yi.

4. B’ ibi tab’ ire de,
Y’o dara fun mi sa!
Ki nsa ni O l’ ohun gbogbo,
Ohun gbogbo n’nu Re. Amin.
Religion / Re: Yoruba Hymn by obasolape(f): 2:47pm On Jan 30
Yin Olorun Abra’am (Yoruba Hymn)
1. Yin Olorun Abra’am
Ti O njoba l’oke
Enit’o ti wa titi lai
Olorun ‘fe “Jehofa nla l’Emi”
Gbogbo eda jewo
Mo f’ibukun f’Oruko Re
Titi lailai

2. Yin Olorun Abra’am
Nip’ase Eniti
Mo dide, mo si wa ‘tunu
Lowo ‘tun Re Mo ko aiye sile
Ogbon at’ola re
On nikan si ni ipin mi
At’asa mi

3. On na ti seleri
Mo gbekele eyi
Ngo fi iye idi goke
Lo si orun, Ngo ma wo oju Re
Ngo si yin ipa Re
Ngo korin ‘yanu t’or’ofe
Titi lailai

4. B’agbara eda pin
T’aiye at’esu nde
Ngo dojuko ona Kenaan
Nip’ase Re, Ngo re odo koja
Bi Jesu wa lokan
Ngo k’oja n’nu igbo didi
Lo s’ona mi

5. Oba oke orun
Olor’angeli nke
Wipe “Mimo, mimo, mimo”
Oba titi
Eniti ki pada
Ti y’o si wa lailai
Jehofa, Baba, “Emi ni”
Awa nyin O

6. Gbog’ egbe asegun
Nyin Olorun l’oke
Baba, Omo at’Emi ni
Nwon nke titi
Yin Olorun Abra’am
Ngo ba won korin na
Tire l’agbara at’ola, Pelu iyin
Religion / Re: Yoruba Hymn by obasolape(f): 5:54pm On Jan 24
BABA IWO LA O MA SIN

Verse 1
Iwo to fe wa la o ma sin titi
Oluwa Olore wa
Iwo to n so wa n’nu idanwo aye
Mimo, logo ola re

Chorus:
Baba, iwo l’a o ma sin
Baba, iwo l’a o ma bo
Iwo to fe wa l’a o ma sin titiMimo l’ogo ola re.

Verse 2
Iwo to nsure s’ohun t’a gbin s’aye
T’aye fi nrohun je o
Awon to mura lati ma s’oto
Won tun nyo n’nu ise re.

Verse 3
Iwo to nf’agan lomo to npe ranse
Ninu ola re to ga
Eni t’o ti s’alaileso si dupe
Fun ‘se ogo ola re

Verse 4
Eni t’ebi npa le ri ayo ninu
Agbara nla re to ga
Awon to ti nwoju re fun anu
Won tun nyo n’nu ise re.

Verse 5
F’alafia re fun ijo re l’aye
K’ore-ofe re ma ga;
k’awon eni tire ko ma yo titi
ninu ogo ise re.
Religion / Re: Yoruba Hymn by obasolape(f): 10:01am On Jan 23
GBEKE RE LE OLORUN

YORUBA 1
Gbẹkẹl'Ọlọrun n'gba to ku'wo nikan
O ri, O mọ ọnà t'iwọ ti tọ
Ọkan ninu ọmọ rẹ kì yóò dáwà
Gbẹ kẹ rẹ lè Gbe kẹ rẹ le

Egbe
Gbẹ kẹ rẹ le o mbẹ lor'itẹ
Gbe kẹ rẹ le o nṣọ awọn tirẹ
Ko le kùnà, oun yo bori
Gbẹ kẹ rẹ lè Gbe kẹ rẹ le

YORUBA 2
Gbẹ kẹ rẹ le gbat'adua ko n'idahun
Ẹbẹ rẹ ni, oun kì yóò gbàgbé
Gbẹ kẹ l'Olu, n'igbagbọ pẹlu sùúrù
Gbẹ kẹ rẹ lè ,yóò dáhùn laipẹ

YORUBA 3
Gbẹ kẹ l'Ọlọrun n'nu 'rora oun 'ṣoro
Ọkan rẹ gbẹ fún 'banujẹ ẹ rẹ
Gbe 'banuje oun ajaga rẹ fún
Si fi sílẹ, fi wọn sílẹ

YORUBA 4
Gbẹ kẹ l'Ọlọrun gba ti ko s'ireti
Gbe kẹ rẹ le, o'n pèsè f'awon tirẹ
Ko le kùnà, gbogbo 'joba yóò ṣegbe
O wa njọba lor'itẹ rẹ

(1) (2) (3) (4) (5) (6) (7) (of 7 pages)

(Go Up)

Sections: politics (1) business autos (1) jobs (1) career education (1) romance computers phones travel sports fashion health
religion celebs tv-movies music-radio literature webmasters programming techmarket

Links: (1) (2) (3) (4) (5) (6) (7) (8) (9) (10)

Nairaland - Copyright © 2005 - 2024 Oluwaseun Osewa. All rights reserved. See How To Advertise. 65
Disclaimer: Every Nairaland member is solely responsible for anything that he/she posts or uploads on Nairaland.