Welcome, Guest: Register On Nairaland / LOGIN! / Trending / Recent / New
Stats: 3,150,635 members, 7,809,391 topics. Date: Friday, 26 April 2024 at 08:39 AM

Ore Odaju - Literature - Nairaland

Nairaland Forum / Entertainment / Literature / Ore Odaju (1300 Views)

A Yoruba Poem: Mura Si Ise Ore Mi. / Ore Ti Ko Common (2) (3) (4)

(1) (Reply)

Ore Odaju by oloriireomo(m): 3:24pm On Sep 11, 2013
ORE ODAJU

"Olorun yoo pese Jiipu fun o,sungbon koni fimi se dereba re.
Ase looto ni wipe bi iya nla ba gbe'ni sanle kekere asi tun gori eni.
Ore timo timo ni Olatide ati Ayo ola lati igba ewe wa.

Ile iwe kan naa ni awon mejeeji lo.yooba bo won wipe ogun omode ko le sere f'ogun odun.
Leyin ti olatide ati ayoola ti pari iwe mefa ni egbon iya ayoola ti mu ayoola kuro labule losi abuja.aso ni egbon iya re yi n ta .odo re naa ni ayoola ngbe.

"Olatide je oniwa irele,osi je olooto si ore re ayoola.kii fi asiri kankan pamo fun.koda bi wonba bun-un ni tooro yoo sofun ayoola ore re yoosi fun ni eto tire naa.egan lotun ku,ore daada ni olatide.

Leyin ti ayoola ti kuro labule,olatide ko gboro ore re mo,opo igba ni olatide ma n wa ekun mun bii gaari ijebu ni akoko ti aaro ore re ayoola ba n so.niigbami ewe,bii koma danikan soro tabi ko ma sebi alaaganaa. kii jeun,afi ekun saa.kole se deede mo lenu eko re bii ti ateyin wa.
Igba ko lo bi orere ojo ko to o lo bi opa iban.
leyin ti olatide ti pari iwe mefa loti sinmi.idi si ni pe koni oluran lowo,awon obiire sini yii aje ko bawon d'ore rara.oko agbaro ni olatide nse labule...o tun ma n ba awon oni biriki pon omi kobo tabi ko se'gi ta.humm!aa sa buta.

Ni irole ojokan,idi ayo olopon ni olatide ati awon elegbe re wa,ti oko ayokele mesidiisi bobinni kan gunle,awon okunrin gende to san-angun merin sare jade ninu oko,won sare siilekun oko. ayoola sokole ninu oko ninu ola-n-la,o f'owo geresi aso re daada.agbada lo wo lojo naa.ikan lara awon gende merin to tele sare gba potifolio owo re.
Tani mo n woyi ?lo jade lenu Olatide.o f'owo bo'ju e daada boya oju oun n ri dobu.Olatide f'ayo pade ore re,o dimo....ayo kun inu re,erin si pa eke re.
Olatide mun Ore re losi ibugbe re.nigba ti wonde ibugbe re,awon ibeere gbankogbi t'ole yo ile aye lemi eeyan lo n jade lenu ayoola.
Ayoola:se ibi to n gbe niyi?
Olatide:beeni o,koda mo sese kun-un loda ni.ayoola wole bee lo n wo yan-an-yan-yan bi eni tofe d'oogun le,o f'owo bo'mu....,olatide fi yara re han.ibeere mii lotun beere"
Ayoola:se yara to n sun naa lori bi yara eku yii?iya ma n je iwo iwo arakunrin yii gan
Olatide:hun!iwolo n wo bee,okele gbigbe pelu ifokanbale............mo dupe emi ati ilera pipe ti olorun funmi.

Ni gbogbo akoko yii Olatide ti n s'akiesi asesa ore re,inu re siti n baje.okan re gb'ogbe,omije gbigbona bo loju re.Ayoola Gbowo le lejika,o tuu pe koma ba okunrin je,osi se ileri lati ran-an-lowo.o sofun Olatide pe oun yoo fisi aaye kan niibi se oun ti yoosi ma gba owo osu niipari osu.o fun ni kaadi ile ise re nii eyi ti adiresi re wa ninu re,pe kowa ri oun ni ile ise oun kosi nii lokan lati bere ise lojo kan naa.inu Olatide dun debi pe bi wonba g'esin ninu re koni ko'se.Ayoola seju si arakunrin t'ogbe potifolio dani,kia,iyen naa timo nkan ti ayoola n fe.o gbe bondu owo kan jade.egberun naira ni won we papo.Ayoola fa eyo egberun kan yoo ninu owo naa o naa si Olatide.olatidegba,inu olatide dun de'badi.o jowo loti gb'orun owo mo.ayoola dagbere osi pada si abuja.
Leyin ojo keta,Olatide gbera odi abuja.ko se wahala jina lojo naa.enu ona ile ise Ayoola gangan ni oko jasi.o wole,o si loore ofe lati ba ayoola niibise lojona.se awon oni bisinesi kii ku duro s'oju kan.amerika loni,katangua ni lola.
Ayoola n ki ore re.

Ayoola:pele o arakunrin

Olatidesadtiyan-tiyanu)o o!

Ayoola:se e mo oko wa daada?

Olatide:Oko?

Ayoola:beeni,oko!

Olatide:mo mo oko wa

Ayoola:yooto bi odun melo ti eti n wa oko bo?ati pe iru awon oko wo ni eti ni ore ofe lati wa?manua tabi otomatiiki?
Olatide:mo mo oko wa daada kosi si eyi ti n ko lewa.bose ajagbe,jagi tabi tipa deede ara lose

Ayoola:inu mi dun bii bi eti dami lohun.a o bere pelu egberun mewa funyin.leyin odun kan,ti aba ri bi eti se daada si alekun yoo ba owo osu yin.

Olatide:E se!oko wo lefe kin wa?ati pe ile ise wo ni mofe wa?

Ayoola:Mo sese fera oko jiipu kan ni,iwo sini mofe koo mo wami niile ise yii.
Olatidesadoun sunkun)e mi naa?biiya n la ba gbeni sanle keke re asi tun g'ori eni.ayoola agh!iwo.laduru bi moti feran re to.o se o,mo dupe pupo.Olorun yoo pese jiipu fun o,amo koni fimi se dereba re.(Olatide sunkun bosita osi n wa oko lati pada s'abule)ibi ti oti n se eyi.....oko ayokele kan gba,oko yii si salo.won gbe Olatide digbadigba lati doola emi re, odi ile iwosan,sungbon ki wonto de'le iwosan. "Olatide Ku"
Re: Ore Odaju by wizb: 3:49pm On Sep 15, 2013
Hmmmn.

(1) (Reply)

Kelvin's Dilemma(a Short Story) / The Strange Woman In My Matrimonial Bed / Adventures Of Ayodeji

(Go Up)

Sections: politics (1) business autos (1) jobs (1) career education (1) romance computers phones travel sports fashion health
religion celebs tv-movies music-radio literature webmasters programming techmarket

Links: (1) (2) (3) (4) (5) (6) (7) (8) (9) (10)

Nairaland - Copyright © 2005 - 2024 Oluwaseun Osewa. All rights reserved. See How To Advertise. 20
Disclaimer: Every Nairaland member is solely responsible for anything that he/she posts or uploads on Nairaland.