Welcome, Guest: Register On Nairaland / LOGIN! / Trending / Recent / New
Stats: 3,150,832 members, 7,810,201 topics. Date: Friday, 26 April 2024 at 11:25 PM

African Poetry: Ise Loogun Ise - J.F Odunjo - Culture - Nairaland

Nairaland Forum / Nairaland / General / Culture / African Poetry: Ise Loogun Ise - J.F Odunjo (7423 Views)

British Tottenham Choir Singing Yoruba song - Ise Oluwa / A Yoruba Poem- Ise Logun Ise (work Is The Antidote For Poverty) / Timeless Yoruba Poem By J.f Odunjo (2) (3) (4)

(1) (Reply)

African Poetry: Ise Loogun Ise - J.F Odunjo by obaede: 6:22pm On Oct 04, 2014
Awon Yoruba ni bi onirefin ko ba fingba mo, eyi
to ti fin ko le parun laelae. Okan lara awon
gbajugbaja ewi akosori ile iwe alakobere nigba
kan ri ni yii, eleyii ti opolopo awon agbalagba aye
ode oni ka ninu iwe Alawiye ti won koko te jade
lodun 1943.
Nje eyin si ranti bi?
Ise l'ogun ise
Mura s'ise ore mi
Ise la fi n'deni giga
Bi a ko ba reni feyin ti
Bi ole la'nri
Bi a ko ba reni gbekele
A tera mo'se eni
Iya re le lowo lowo
Baba re le lesin lekan
Bi o ba gbo'ju lewon
O te tan ni mo so fun o
Ohun ti a ko ba ji'ya fun
Se kii le pe lowo
Ohun ti a ba fara sise fun
Nii pe lowo eni
Apa lara
Egunpa niyekan
B'aye ba n'fe o loni
Bi o ba lowo lowo
Aye a ma fe o lola
Tabi ki o wa ni'po atata
Aye a ma ye o si terinterin
Je k'o de'ni tin rago
Aye a ma yinmu si o
Eko si'nso ni d'oga
Mura ki o ko dara dara
Bi o si r'opo eniyan
Ti won f'eko s'erin rinrin
Dakun ma f'ara we won
Iya n'bo fun'omo ti ko gbon
Ekun n'be fun'omo to nsa kiri
Ma f'owuro sere ore mi
Mura si'se ojo'nlo.
www.olayemioniroyin.com/2014/09/ewi-ise-loogun-ise-jf-odunjo.html?m=1

3 Likes

Re: African Poetry: Ise Loogun Ise - J.F Odunjo by 2prexios: 10:26pm On Oct 08, 2014
b'omode ba k'oyan ale, awon aga a f'itan b'ale.

G.F. Odunjo, bi o tile je wipe baba ti ku, sugbon ise rere ti won fi sile ko ni parun laelae. Ile Akoko latii gbedo. Baba lo kowa labidi, won kowa labidi olowe, baba kowa bi a ti maa ko moo ka, baba kowa ni 'tan Mojisola Alaso Oke. Awaye iku osi. Boba se pe aiku laye, aba ba Awolowo, baba ninu Oloselu, Ababa Asikiwe, aba ba Muritala, ti won nfi orin ki lojoun ana. Owu ni ka jeran pe lenu, ounfa onafun o je.

Bi mo ba wo rere ile aye, ti mo ranti baba to bi mi, okan mi a si maa ranmi leti pe baa ba bini, oye ka tunra eni bi, ka se oun to to nitori, iku o dojo arun o dosu, ojo a ba ku laa dere. Iku o mara beeni ko menikan. Iku o kuku mo majesin beeni ko meni oosa. Ise rere loye ki koowa o maa se nitori pe, ojo atisun lebo. Eledua nii ku soni ni gbogbo ojumo tii mo, rere ni koju wa o ri l'otu ife rere, nibi oju tii mo wale aye.

Laini deena penu, Alawiye laba maa pe ni akomolede, alawiye naa tun loye ka maa pe ni sagbade, oun naa lore ewe. Eyin ewe iwoyi eye elo ni suuru, ogbon ni baba nfi'tan igba atijo koni. Onisuuru nii fun wara Kiniun, Omo atata, kaka kin bi egba obun, ma kuku bi okansoso oga, ma roun yan araye loju, ma roun gberaga: se okansoso araba, kii segbe egba osunsun, omo to jafafa kan soso, kii segbe egba irunbi omo.

To, akewi nrele na, o tan lenu, o ku nikun.

O digba,
Ori rere lakuro nlo nibu omi.
Re: African Poetry: Ise Loogun Ise - J.F Odunjo by Cathyla: 11:53am On Sep 24, 2018
One of the great men time will never be able to represent... Rest on baba J.F ODUNJO

(1) (Reply)

You Know You're Nigerian If: / Tale Of Joromi Bini/edo / Ibadan Omo Ajorosun: Ohun To Ye Ke E Mo Nipa Ilu Ibadan

(Go Up)

Sections: politics (1) business autos (1) jobs (1) career education (1) romance computers phones travel sports fashion health
religion celebs tv-movies music-radio literature webmasters programming techmarket

Links: (1) (2) (3) (4) (5) (6) (7) (8) (9) (10)

Nairaland - Copyright © 2005 - 2024 Oluwaseun Osewa. All rights reserved. See How To Advertise. 13
Disclaimer: Every Nairaland member is solely responsible for anything that he/she posts or uploads on Nairaland.