Welcome, Guest: Register On Nairaland / LOGIN! / Trending / Recent / New
Stats: 3,150,853 members, 7,810,283 topics. Date: Saturday, 27 April 2024 at 05:22 AM

Laarin Ooni Ife Ati Alaafin Oyo, Ija Sese Bere Ni O - Culture - Nairaland

Nairaland Forum / Nairaland / General / Culture / Laarin Ooni Ife Ati Alaafin Oyo, Ija Sese Bere Ni O (2727 Views)

Wives Of Alaafin Of Oyo Take A Selfie Together / Adeyeye Ogunwusi Visits Alaafin Of Oyo / Alaafin Of OYO With Yoruba Descendants In Brazil (pictures) (2) (3) (4)

(1) (Reply)

Laarin Ooni Ife Ati Alaafin Oyo, Ija Sese Bere Ni O by obaede: 10:05pm On Dec 28, 2014
Laarin Ooni Ife ati Alaafin Oyo, Ija Sese Bere Ni o
http://www.olayemioniroyin.com/2014/12/laarin-ooni-ife-ati-alaafin-oyo-ija.html

Bi o tile je wi pe aimoye awon agbalagba ma-je-o-baje ni won ti gbiyanju lati pari ija agba to wa laarin Alaafin Oyo, Oba Lamide Adeyemi ati Ooni ti ile Ife, Oba Okunade Sijuwade sibesibe won gbo ni ko si eyi to gba ninu awon mejeeji.

Ohun to faja naa ni bi Alaafin se n wi pe oun ni ojulowo Omo Odua kii se Ooni, ati wi pe ohun ni asaaju gbogbo Yoruba ni tile-toko. Ooni Ile Ife ni Ife ni orirun gbogbo Yoruba pata, ati wi pe ibi taa ba pe lori a kii fibe tele laelae. Ife ni iran Yoruba ti se wa, ibe naa si ni ade Odudua wa titi di oni.

Lara awon to ti da si oro naa ni Ogbeni Rauf Aregbesola. Bi o tile je wi pe ko si awuyewuye kankan to jeyo mo nipa rugudu aarin won, sugbon o ye gbogbo wa wi pe kaka ki kinihun se akapo ekun, onikaluku o se ode re lotooto ni. Nigba ti awon agba ile Yoruba meji to ye ki won je opomulero ba n ba ara won takangbon kini yoo sele si okiki iyi ati eye Yoruba to ti kari aye?

Sugbon pelu bi nnkan se n lo lagbo oselu bayii, oseese ki wahala tun sele laaarin awon oba mejeeji yii eleyii to le mu ifaseyin tabi tabuku Yoruba.

Omo egbe A.P.C ni Alaafin Oyo, sebi gbogbo yin le mo igba ti baba lo fi oruko sile. Bi Ooni ko ti le fi oruko sile bi omo egbe PDP, kosi eni ti oro ko ye wi pe imule egbe alaburada ni Ooni ti ile Ife je. Ooni yii kan naa lo lewaju awon agbaagba Yoruba ti won fi onte lu Aare Goodluck Jonathan gege bi eni to pegede lati di Aare lodun 2015.

Oro oselu to fe pin, tabi ki n so wi pe to ti pin awon asaaju ile Yoruba si meji yii, se ko ni se akogba fun iran Yoruba?

Ohun to daju ni wi pe egbe PDP ko ni wonkun, A.P.C naa ko ni gba laabo. Kaka ki eku ma je sese, gbogbo wọn o fi sawadanu ni oro ibo odun 2015 je. To ba wa ri bee, se ajosepo to wa laarin Alaafin ati Ooni yoo dan moran ni tabi yoo tun bo buru jai.

http://www.olayemioniroyin.com/2014/12/laarin-ooni-ife-ati-alaafin-oyo-ija.html

1 Like

(1) (Reply)

Oba Of Benin Coronation Speech / 5 Reasons Why Racism Will Never Stop / See The Witch That Fell And Crash Landed In An Environ In Benin.

(Go Up)

Sections: politics (1) business autos (1) jobs (1) career education (1) romance computers phones travel sports fashion health
religion celebs tv-movies music-radio literature webmasters programming techmarket

Links: (1) (2) (3) (4) (5) (6) (7) (8) (9) (10)

Nairaland - Copyright © 2005 - 2024 Oluwaseun Osewa. All rights reserved. See How To Advertise. 8
Disclaimer: Every Nairaland member is solely responsible for anything that he/she posts or uploads on Nairaland.