Welcome, Guest: Register On Nairaland / LOGIN! / Trending / Recent / New
Stats: 3,155,869 members, 7,828,098 topics. Date: Wednesday, 15 May 2024 at 12:30 AM

Asa Ibile (a Yoruba Drama) - Culture - Nairaland

Nairaland Forum / Nairaland / General / Culture / Asa Ibile (a Yoruba Drama) (771 Views)

The Oba Of Benin Is A Yoruba Man. / Benin Was A Yoruba speaking Empire. / Yara Iwosan Ibile Yoruba (2) (3) (4)

(1) (Reply)

Asa Ibile (a Yoruba Drama) by TemmyT002(m): 8:27am On Jul 19, 2019
This is mostly in the Yoruba language

Asa Ibile is a drama about a Yoruba man who travelled out of the country and returns later believing that witches do not exist, completely losing belief in the Yoruba culture.

Itan yi da le ori odomokunrin kan, ti oruko re n je Alao, ti o lo si ilu oyinbo lati lo sise.

Enjoy Asa Ibile


SCENE ONE OF ASA IBILE


Alao mura lati lo sir irinajo na.

Iya Alao: Omo mi, bi o se n lo yi, jowo se jeje o. Ki o ranti iru omo ti o je; ki o ranti ile ti o ti jade wa. Ki o si sunmo Olorun ti o da o

Alao: Ese iya mi. Gbogbo oun ti e so ni ma se. Eyin na sa mo pe omo daada ni mi.

Iya Alao: Ose omo mi. Ma ma gbadura fun e. Ki iwo na si maa gbadura. Oko ofurufu re ko ni jabo

Alao: Ese iya mi. Mo wa se ipinu bayi wipe mo ma ko ile ti o tobi ju ti oba ilu wa lo; ilu wa yi na ni ma ko ile na si

Iya Alao: Ose omo mi. Eledumare a fun e se.


SCENE TWO OF ASA IBILE


LEYIN ODUN MEJE
Alao de lati ilu oyinbo. O ti di olowo. O fi igo dudu soju. O gbe jeep dudu wa si odo iya re. O wo aso alarabara.

Alao: Eku ile o. Ta lo wa n le. I am back mehn. Who is here?

Iya Alao: Ta ni o?

Alao: Maami, omo yin lo n soro. I am back from London. I come bearing gifts.

Iya Alao: Ha, omo mi, kaabo. Adura mi ti gba. Eledumare o ma se o.

Alao: Maami, moti ra nkan to po wa fun yin lati ilu oyinbo.

Alao ra aso ti o po fun iya re. O ra ero ibanisoro ti awon oyinbo sese se, ati nkan orisirisi

Iya Alao: Ha, omo mi, Eledumare a san fun e. Olodumare, o ma se o, ti o fun mi ni omo gidi, omoluabi, ti o mo iyi iya re.

Alao: Iya mi, bi mo se de yi, maa ko ile nla fun yin

Iya Alao: Ose omo mi. Mo kan fe so fun e pe ki o ma roar se ni ilu yi o. Awon agba powe pe, ti o ba wa ni oja, mase ju okuta, nitoripe o le lo ba eniyan re. Omo mi, ilu yi dabi oja na. Oun ti o ba se ni okuta. Ronu ti oba fe se oun kan, nitoripe awon aje po ni ilu yi.

Alao rerin nigbati o gbo eyi

Alao: Maami ko si oun kan ti o n je aje. Iron la ni gbogbo re. Won ko fe fi da eru baa won eniyan ni. Superstition ni gbogbo re.

Iya Alao: Ha, ori iya mi o. Alao, ni ilu wa yi nikan, awon aje po. Ma to ija won o.

Alao: Maami, ani iro no ni gbogbo re. Ni ilu oyinbo, ko si nkan ti o n je aje

Iya Alao: Alao, ile Yoruba ni owa yi. Awon Yoruba ma n lo ogun, ti o si ma n je. Se o ko gbo itan awon bi ologun awon Oyo se ma n lo ogun ni? Tabi itan awon eniyan bi Ogedengbe ati Fabunmi Okemesi. Won be ori Ogedengbe, o si da ori na pada. Won yibon mo Fabunmi Okemesi, ibon na ko sise

Alao: Won o lo AK47 ni ko je ki ibon na sise. Iro ni gbogbo re maami, inu film nikan le ti ma gbo. Ko si nkan to n je aje.

Iya Alao: Sa ma rora omo mi

Alao: Mo ti gbo

Iya Alao: Maabo, wa lo je amala


SCENE THREE


Alao sese san owo ile kan ni ilu na. O w aba iya re lati so fun

Alao: Maami, mo ti ra ile ti mo ma kole si fun yin

Iya Alao: Ose omo mi. Nibo ni o ri ile na si?

Alao: Ile to wa ni egbe ile Otun ilu.

Iya Alao: Ori ya mi o. Alao, o tis i ile ra. Tete lo da owo na pada

Alao: Maami, ki lo de? Se e ko fe ki n koi le fun yin ni?

Iya Alao: Omo mi, ile na ni iya onigi fe ra

Alao: Eniti o ta igi na so fun mi, sugbon emi ni mo koko gbe owo wa. Emi ni mo ni

Iya Alao: Ogbologbo Aje ni iya onigI. Gbogbo eniyan lo mo

Alao: Maami, mo ti so fun yin pe ko si nkan to n je aje. Iro ni gbogbo re. Emi ni mo ni ile na. Eniti o ba disturb mi, tabi ti o fun mi ni wahala, ma fi olopa gbe. Ma sue anybody. Ewon lo ma sun

Iya Alao: Jowo da owo na pada

Alao: Lailai


SCENE FOUR


Alao lo si church rascaboge kan

Pastor Mike: Somebody shout Halleluya

Congregation: Halleluya

Pastor Mike: Today, we are gonna be talking about money. Somebody tell your neighbour Money

Congregation: Money

Pastor Mike: Somebody say I am gonna be rich

Congregation: I am gonna be rich

Pastor Mike: You can get rich anyhow. Nothing can stop you. The local Yoruba people blame their problems and shortcomings on witches and wizards. There is nothing like witches; there is nothing like wizards; everything is a lie, a superstition. There are no witches in London, Germany, USA, it is only in Nigeria you will find witches. I am tired of all the superstition; they give me headaches. You grab your opportunity.

Congregation: Ride on pastor

Pastor Mike: There are no witches

Congregation: Ride on Pastor

Pastor Mike: When you have problem, call on me and I will answer. Let us pray.


SCENE FIVE


Iya onigi ati awon ore re wa ba Alao nile.

Alao: Yes, yes, who are you people?

Iya Onigi: Omo mi, mi o gbo ede re. So ede mi fun mi, ki n gbo

Alao: Itumo mi pe, Ki le fe?

Iya Onigi: Mo fe ki o da owo ile pada. Mo nilo ile na

Alao rerin

Alao: Iru nonsense wo niyen? E o ti e beru, e wa bami nile. E kan la enu gbalaja, e ni kin da owo pada. Oya e jade, mo ti binu. I am angry.

Iya Onigi: Omo mi, mo n be o, da owo na pada

Alao: Mo ni ki e get out. E jade kuro ninu ile mi.

Awon iya na na owo si Alao, inu bere si ni run Alao.

Alao: Ha. Ha. Ki le n se si mi? E stop e. Ma pe olopa siyin o. This is assault and battery without aggravation. Ma fi olopa gbe yin. Ma sue yin lo court. Ewon le ma sun si.

Nigbati Alao ri pe awon iya na ko fe dawo duro, o pe awon olopa ninu phone re.

Alao: Se DPO niyen? Okay sir, yeeeeeee, awon iya buruku kan lo n se nkan simi nibi o. E ran awon boys wa, ki won wa gbe won. Yeeeeeeeee
Laipe, awon olopa meji de.

Olopa 1: Awon iya na da?

Nini irora, Alao na owo si won

Alao: Awon niyen.

Awon olopa ko le ri awon iya na

Olopa 2: Awon da?

Alao: Se oju yin fo ni? Sebi okan ninu won lo n feyin siyin yen

Olopa 1: O da bi wipe awon aye n tele yin. E pa wa lati wa waste time abi? E ni isoro. Awe, je ka ma lo

Olopa 2: Oga, e fun wa ni owo epo

Alao: Nnkan n se yin. E o mu awo iya, e wa fe gba owo epo. Ti mo ba fun yin ni blow..

Awon olopa binu, won na Alao, won si ba tiwon lo

Iya Onigi: A ma fi aye han e, afi ti o ba da owo ile na pada

Alao pe Pastor Mike lori ero ibanisoro re

Laipe, Pastor Mike sare de

Pastor Mike: Bro Alao, what happened? Where are the wicked women?

Alao: Look at them behind you

Continued in the source....

Source: https://opinionsandstories.com/asa-ibile/

(1) (Reply)

Brief History Of Yagba, Okun Speaking Most Populated Group / Largest Man Made Structure On The Planet. / Oludofian, One Of Nigeria’s Longest Ruling Monarchs Is Dead

(Go Up)

Sections: politics (1) business autos (1) jobs (1) career education (1) romance computers phones travel sports fashion health
religion celebs tv-movies music-radio literature webmasters programming techmarket

Links: (1) (2) (3) (4) (5) (6) (7) (8) (9) (10)

Nairaland - Copyright © 2005 - 2024 Oluwaseun Osewa. All rights reserved. See How To Advertise. 27
Disclaimer: Every Nairaland member is solely responsible for anything that he/she posts or uploads on Nairaland.