Welcome, Guest: Register On Nairaland / LOGIN! / Trending / Recent / New
Stats: 3,162,597 members, 7,851,014 topics. Date: Wednesday, 05 June 2024 at 12:14 PM

If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! - Culture (160) - Nairaland

Nairaland Forum / Nairaland / General / Culture / If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! (377435 Views)

If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here. Everybody Is Invited! / If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! / Do You Speak Yoruba? (2) (3) (4)

(1) (2) (3) ... (157) (158) (159) (160) (161) (162) (163) ... (167) (Go Down)

Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by tkb417(m): 8:25am On Jan 08, 2009
Nature as a noun has a lotta meanings
il try here
Nature (natural scenery or the universe with all its phenomena) = ayika in yoruba

Nature (the particular combination of qualities belonging to a person, animal, thing, or class by birth, origin, or constitution; native or inherent character: human nature.) =iru. for example, iru alakoso wo ni won fe gbe wa si kilaasi wa. the tone on the iru is (re re)

itumo nature fun emi ni yen o
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by farotika(m): 8:42am On Jan 08, 2009
chamotex:

ewo bi awon agbalagba yi se npa ofo nitori obinrin

Fadeyi oloro ati kukute grin grin

Pele o buroda Aworo.  Se gbogbo eniyan lo ro pe o ri bi tie to je pe gbogbo obirin adugbo ni o nfowo ba kiri. Onisekuse ati oniranu gbaa ni mo ka e si. Shioo

Nitemi, oju kan bayii ni ada ni, nitorina emi le ja, mo si le pofo nitori onitemi, adamaradan, ejiwumi, iyunade temi nikan kiss kiss kiss Eyin pegan pegan kan nse lasan ni. tongue tongue tongue
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by dayokanu(m): 8:54am On Jan 08, 2009
@farotika,
ma da shamotessi lohun jare. Ko ti mo odo ti o fe da orunla si.

Ta tun ni Iyunade Booda Onishina?

Mo yonda adumaran fun oh sugbon ki o toju re daada o. Ki o ma ba dija larin wa.
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by farotika(m): 9:00am On Jan 08, 2009
tkb417:

Nature as a noun has a lotta meanings
il try here
Nature (natural scenery or the universe with all its phenomena) = ayika in yoruba

Nature (the particular combination of qualities belonging to a person, animal, thing, or class by birth, origin, or constitution; native or inherent character: human nature.) =iru. for example, iru alakoso wo ni won fe gbe wa si kilaasi wa. the tone on the iru is (re re)

itumo nature fun emi ni yen o

Mo kan sara si e Ogbeni 419. O fihan pe omo yooba gidi ni e. Gbosa!!! meta fun e.

Atun le pe nature ni: ihuwasi. Fun apeere: It is in the nature of dayokanu to covet another man's wife. Itumo: O wa ninu ihuwasi dayokanu lati maa se ojukokoro si iyawo oniyawo tongue tongue tongue
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by farotika(m): 9:04am On Jan 08, 2009
dayokanu:

@farotika,
ma da shamotessi lohun jare. Ko ti mo odo ti o fe da orunla si.

Ta tun ni Iyunade Booda Onishina?

Mo yonda adumaran fun oh sugbon ki o toju re daada o. Ki o ma ba dija larin wa.

O se jare Dayo ore mi tooto. Ko si ija laarin wa mo o.

E gbo oooooo eyin ika eniyan to wa ninu tireedi yi, ti inu yin ndun si bi emi ati dayo se nja; ko si ija mo o, aso ija wa ti ya patapata.

Iwo ma seyonu, ma toju toyin daaaaaaa daaaaaaaaaa ohun gan ma royin fun o. Lai se aini aini, mo ti fe lo maa ko bi mo se ma se e ti o ma fi le loyun iberin grin grin grin grin Iwo sa ti daa da mi.
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by Remii(m): 10:49am On Jan 11, 2009
Enu o ni pawa ooooooooh!!!!!!

Agbongbon awo ode Ilore
Agbayangidi awo ile Ijesa
A difa fun Oloyimefun ti o bu'le Olowu r'oko
Won ni ko bo eegun ile, ebo re ko ru,
O bo oosa oja ebo re ko da
O bori, ori pa
O bo ile, ile lu
Won wa ni ko bo olubobotiribo baba ebo
O ni oun ma baba eni leegun ile,
Oun mo iya eni loosa oja
Oun mo ori l'ori,
Oun si mo ile n'ile
Sugobon oun ko mo olubobotiribo baba ebo
Won wa so fun wipe Enu ni, Enu l'olubobotiribo baba ebo
Nje ki lanbo ni Ife, Enu won la nbo n'Ife Enu won

Gbogbo eni b'agbo e sora fun enu o,

Enu won la nbo n'Ife.
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by smurf1(f): 7:23am On Jan 12, 2009
Happy New year to all my yoruba tutors oh, cheesy cheesy

Mr Faritika

Pls i ask u include teaching moi, yoruba this year as ur new years resolution tongue

E jo wo, grin grin grin
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by farotika(m): 7:35am On Jan 12, 2009
Remii:

Enu o ni pawa ooooooooh!!!!!!

Agbongbon awo ode Ilore
Agbayangidi awo ile Ijesa
A difa fun Oloyimefun ti o bu'le Olowu r'oko
Won ni ko bo eegun ile, ebo re ko ru,
O bo oosa oja ebo re ko da
O bori, ori pa
O bo ile, ile lu
Won wa ni ko bo olubobotiribo baba ebo
O ni oun ma baba eni leegun ile,
Oun mo iya eni loosa oja
Oun mo ori l'ori,
Oun si mo ile n'ile
Sugobon oun ko mo olubobotiribo baba ebo
Won wa so fun wipe Enu ni, Enu l'olubobotiribo baba ebo
Nje ki lanbo ni Ife, Enu won la nbo n'Ife Enu won

Gbogbo eni b'agbo e sora fun enu o,

Enu won la nbo n'Ife.

Si Remii,

Ninu enu ati ori, ewo lo ye ki a maa bo gan an , nitoripe yooba bo won ni, ori la ba bo ti a ba forisha sile, nitori nigba ti ori ngbeni, nibo ni orisha wa cool
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by farotika(m): 7:37am On Jan 12, 2009
~smurf:

Happy New year to all my yoruba tutors oh, cheesy cheesy

Mr Faritika

please i ask u include teaching moi, yoruba this year as ur new years resolution tongue

E jo wo, grin grin grin

Emi o gbo eebo ti o nso o. Jowo so yooba ki nba le da e lohun daadaa grin grin grin
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by dayokanu(m): 8:00am On Jan 12, 2009
Ogbeni farotika,

Ma fi owo kan omo eleyi oh mo ti fun e ni adumaradan Toyin.

Ki o ma lo je wipe Agbonrin eesin lon je lobe. Abo oro ni an so fun omoluwabi
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by TOYOSI20(f): 8:01am On Jan 12, 2009
dayokanu:

Ogbeni farotika,

Ma fi owo kan omo eleyi oh mo ti fun e ni adumaradan Toyin.

Ki o ma lo je wipe Agbonrin eesin lon je lobe. Abo oro ni an so fun omoluwabi

LOL!!!!!!!!!!!!! grin
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by Remii(m): 9:36am On Jan 12, 2009
farotika:

Si Remii,

Ninu enu ati ori, ewo lo ye ki a maa bo gan an , nitoripe yooba bo won ni, ori la ba bo ti a ba forisha sile, nitori nigba ti ori ngbeni, nibo ni orisha wa cool

Farotika:

Enu l'ebo, a ki je ogede kowu lereke enu lebo. Baa f'ese ko yoo san sugbon eni f'enu ko le gbabe lo. O gbagbe itan inu alawiye nipa okunrin to se igun ati adie, Oun je adie o fun awon alejo re ni igun je sugon o so fun won wipe ounje igun. Oun ni oku awon to je igun si wa laaye. Bi aye bani koo bori ti o ko b'ori sugbon too so fun won pe oti b'ori ori a gbe eo, beena ni too ba bori ti o f'enu saa ta wipe oo b'ori fun won aye ni yoo fi jamba owo ara won se eni naa. Enu l'ebo enu koni re ba wa l'ese oooo. Abo mi ree oo.
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by farotika(m): 10:15am On Jan 12, 2009
dayokanu:

Ogbeni farotika,

Ma fi owo kan omo eleyi oh mo ti fun e ni adumaradan Toyin.

Ki o ma lo je wipe Agbonrin eesin lon je lobe. Abo oro ni an so fun omoluwabi

dayokanu ore miiiiiiii,

Haba shocked shocked shocked se o gberi mi je ni Emi o le gba iyawo e o; o pe ti mo ti mo pe iwo ni o ni Smoofu. Niwon igbati iwo si ti jawo loro iyawo mi, emi o tun le fi obe eyin je e nisu o.

Ti e gbo, won ni omo yen fe maa sa fun e toripe eru kini abe e nba shocked shocked shocked Se ooto ni
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by farotika(m): 10:20am On Jan 12, 2009
TOYOSI20:

LOL!!!!!!!!!!!!! grin

Ki lo npa iwo lerin grin grin grin grin Penumo joo. Olodo nla tongue
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by farotika(m): 10:24am On Jan 12, 2009
Remii:

Farotika:

Enu l'ebo, a ki je ogede kowu lereke enu lebo. Baa f'ese ko yoo san sugbon eni f'enu ko le gbabe lo. O gbagbe itan inu alawiye nipa okunrin to se igun ati adie, Oun je adie o fun awon alejo re ni igun je sugon o so fun won wipe ounje igun. Oun ni oku awon to je igun si wa laaye. Bi aye bani koo bori ti o ko b'ori sugbon too so fun won pe oti b'ori ori a gbe eo, beena ni too ba bori ti o f'enu saa ta wipe oo b'ori fun won aye ni yoo fi jamba owo ara won se eni naa. Enu l'ebo enu koni re ba wa l'ese oooo. Abo mi ree oo.

Ooto lo pa ore mi. Hmn, hm arojinle oro lo so hun. Eni to je adie to ni iye igun ni o je se be o ku. Enu le bo o. Enu ni olubobokiribo baba ebo; enu wa o ni pa wa oo. Amin, Ase ademare.
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by Muza(m): 1:28pm On Jan 12, 2009
Ma fu e leti,
ori o da,
omo buruku. . . grin
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by tkb417(m): 6:16pm On Jan 12, 2009
Ma fu e leti,
ori o da,
omo buruku
ori e kope rara. se eebu nikan ni womo ni?
olodo

farotika
se iwo ni o fun Dayo ni sumoofu?
metala yin kotobe. abi ogbon ori yin ti jabo sile ni? aye yi leju bi ese ngbe yi lo
nkan to le mu emi dani ni efe rawole yi. ema je kin gbo be lenuyin mo laye at lailai
emi ni mo ni summofu.
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by TOYOSI20(f): 6:52pm On Jan 12, 2009
farotika:

Ki lo npa iwo lerin grin grin grin grin Penumo joo. Olodo nla tongue

E fi mi sille jare, oni yeye ni yin oo tongue

Boda agbaya, shebi emi ni mo neyimi grin grin
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by Jarus(m): 8:48pm On Jan 12, 2009
kai, atijo ti mo ti manri tiredi yii, unho ti si ri. Oni ni mo koko si. Sugbon ose ni laanu pe gbogbo ohun ti eko ni mi o le ka dada.
Dayokanu, asoo ti egbo Yoruba bayi. MRS grin(lol, Mo Rerin Soke)

Ede Yoruba Kuara leminso o, nitoripe araalu oke leemi.
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by Jarus(m): 8:51pm On Jan 12, 2009
Muza:

Ma fu e leti,
ori o da,
omo buruku. . . grin
Ogbeni Muza, sannu, yaya aiki
ose wa jepe eebu lekoko ninu Yoruba. MRS grin
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by SisiJinx: 8:54pm On Jan 12, 2009
Lmao!! First thing ti gbogbo eyan ma koko ko ni any ede ni yen.

Boya, ni toripe eebu dun so dada! cheesy
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by Nobody: 10:43pm On Jan 12, 2009
Dayo!! Dayo!! Oga fun e o.
Na me u dey give away like this? cry cry

O se jare Dayo ore mi tooto. Ko si ija laarin wa mo o.

E gbo oooooo eyin ika eniyan to wa ninu tireedi yi, ti inu yin ndun si bi emi ati dayo se nja; ko si ija mo o, aso ija wa ti ya patapata.

Iwo ma seyonu, ma toju toyin daaaaaaa daaaaaaaaaa ohun gan ma royin fun o. Lai se aini aini, mo ti fe lo maa ko bi mo se ma se e ti o ma fi le loyun iberin Grin Grin Grin Grin Iwo sa ti daa da mi.

You no fit o. I'm a very hard person to please o
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by dayokanu(m): 10:48pm On Jan 12, 2009
Farotika,
Je ki nla ye o. Won ni ela loro.
Awon agba bo, won ni: Ai se alaye oro ni o pa elenpe akoko ti o ni igba wuwo ju awo lo.

Sumofu(eyinfunjowo Ibadi aran) ti o ri yen. Iyawo Tkb ni, ati wipe ana temi ni.
Toyosi (Opelenge subu lu awo, awo ko fo), Aburo mi ni.
Toyin(Adumaradan omoge rumurumu) ni mo yonda fun o.
Se o ti ye o.

@Jarusi,
Awon agba so wipe: Ki a ro aso mo idi, ki a ro idi mo aso, Ki di sa ma ti gbofo.
Awon na ni won so wipe, Itakun ti o so igba se ohun na ni o so elegede

Ati Yoruba Kwara ati yoruba Oyo nkan kan na ni gbogbo re( seemu ni)
Ti ko ba tin se ede larubawa

Ti e gbo, won ni omo yen fe maa sa fun e toripe eru kini abe e nba Se ooto ni

oro ti ko ni ese nile ni yen. Paapa Tani ko mo pe ori oko ko to ori omo?
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by dayokanu(m): 10:50pm On Jan 12, 2009
Dayo!! Dayo!! Oga fun e o.
Na me u dey give away like this?
You no fit o. I'm a very hard person to please o

Kini itumo gbogbo firinfitin yi?
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by Nobody: 11:18pm On Jan 12, 2009
dayokanu:

Kini itumo gbogbo firinfitin yi?
Lol, kini firinfitin?
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by kushi1: 11:20pm On Jan 12, 2009
Bawo ni everybodi?
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by bluespice(f): 12:24am On Jan 13, 2009
mo ki gbogboyin o
bawo lara?
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by kushi1: 2:36am On Jan 13, 2009
bluespice:

mo ki gbogboyin o
bawo lara?

Saka lara da. . . .
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by farotika(m): 7:04am On Jan 13, 2009
tkb417:

ori e kope rara. se eebu nikan ni womo ni?
olodo

farotika
se iwo ni o fun Dayo ni sumoofu?
metala yin kotobe. abi ogbon ori yin ti jabo sile ni? aye yi leju bi ese ngbe yi lo
nkan to le mu emi dani ni efe rawole yi. ema je kin gbo be lenuyin mo laye at lailai
emi ni mo ni summofu.

Ema binu booda 419, igbagbe lo se mi ati wipe owo ti Dayo yo simi nigbati mo daruko Sumoofu lo je ki nro pe ohun lo nse aye ibe ni. E jowo e dariji mi eyin agba naa le so wipe: omode o le mo eko je ki o ma ra lowo. embarassed

grin grin grin Yeepa, olodo lomo yi o. Inu re ti ndun pe mo nbe ni ebe iya. Aa o ma se o sad sad Se bi won se ma nba agbalagba soro labule yin niyen. Ofutu feete, aasa ti o ni konu angry angry Ode nla, olodo, oponu, orobirin dori. Edumare ni o ni je ki o ba ibi ti o bawa lo. Shiooooooooooooooooo grin grin grin
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by dayokanu(m): 7:11am On Jan 13, 2009
Farotika,

Gboro mi di eleru, Ajinido fe di oko eni.
Ewo ni o kan o pelu TKB,

Tkb lo ni sumofu. Ekuro ni alabaku ewa.
Ati wipe iro ni pepe npa, Aja lo leru!!!
Iro ni gbogbo awon odomokunri Nairaland npa, TKB lo ni Sumofu.
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by farotika(m): 7:13am On Jan 13, 2009
HeatFusion:

Dayo!! Dayo!! Oga fun e o.
Na me u dey give away like this? cry cry

You no fit o. I'm a very hard person to please o

Igbagbe lo se o. Kaka ko re mi, ma fi elewe ofe gbere. Turaya lomo, ko re mi ri. Maa fi sun e
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by Jarus(m): 9:40am On Jan 13, 2009
Edakun ebaami pe Funmi atimama wa ko wa ko mi lede Ijesa

(1) (2) (3) ... (157) (158) (159) (160) (161) (162) (163) ... (167)

Pictures Of Nigeria Traditional Attire / Igbo Names & Their Meanings / Igbo Kwenu ! Kwenu Kwezo Nu ! Join Us If You Proud To Be An Igbo Guy/lady

(Go Up)

Sections: politics (1) business autos (1) jobs (1) career education (1) romance computers phones travel sports fashion health
religion celebs tv-movies music-radio literature webmasters programming techmarket

Links: (1) (2) (3) (4) (5) (6) (7) (8) (9) (10)

Nairaland - Copyright © 2005 - 2024 Oluwaseun Osewa. All rights reserved. See How To Advertise. 56
Disclaimer: Every Nairaland member is solely responsible for anything that he/she posts or uploads on Nairaland.