Welcome, Guest: Register On Nairaland / LOGIN! / Trending / Recent / NewStats: 3,195,453 members, 7,958,364 topics. Date: Wednesday, 25 September 2024 at 01:10 PM |
Nairaland Forum / Nairaland / General / Religion / Post Yoruba Christian Hymns Here (226890 Views)
Post Your Favourite Christian Hymns / Share Your Best Hymns / Christian Hymns/songs And Copyrights (2) (3) (4)
(1) (2) (3) ... (6) (7) (8) (9) (10) (Reply) (Go Down)
Re: Post Yoruba Christian Hymns Here by siant: 10:20pm On Nov 17, 2021 |
Laifoya l'apa Jesu Laifoya l'aya Re Labe ojiji Ife Re L'okan mi yo Simi Gbo Orin Angeli ni Orin won d'eti mi Lati Papa ogo wa, Lati okun jaspi Laifoya l'apa Jesu Mo bo low'aniyan Mo bo lowo 'banuje Ese ko nipa Mo Mo bo lowo idanwo Mo bo lowo eru O ku idanwo die O k'omije die. Jesu abo okan mi Jesu ti ku fun mi Apata ayeraye Lemi yio gbekele Nihin l'emi yo duro Tit'oru yo koja Titi un o fi ri 'mole Ni ebute ogo |
Re: Post Yoruba Christian Hymns Here by siant: 2:08pm On Nov 18, 2021 |
Orin yi wa fun omo lehin Kristi tooto, to se tan lati gbe agbelebu re ki o si tele Jesu tokantokan, lati fi ori ti gbogbo iponju nla aye, ki o si de orun nikeyin. 'Nitorina isinmi kan ku fun awon eniyan Olorun'. Heberu 4:9 Isinmi wa l' orun, ko si l'aye Emi yio se kun gbati 'yonu ba de? Sinmi okan mi, eyikeyi to de O din ajo mi ku, o mu k' ile ya Ko to fun mi, kin ma sinmi nihinyi, Ki n si ma ko 'le mi ninu aye yi, Oungbe ilu t' ako fowo ko n gbe mi, Mo n reti aye ti ese ko baje Egun esusu le ma hu yi mi ka, Sugbon emi ko le gbara le aye Emi ko wa isinmi kan ni aye, Ti t'emi o fi sinmi laya Jesu mi 'Yonu le damu, sugbon ko le pa mi Oju 'fe Jesu le so 'yonu d'erin Erin Re le so ekun wa di ayo Bi 'gba t' efufu fe ojo sisu lo Je ki 'danwo at'ewu wa lona mi Won mu k'orun tubo dun nigb' aye pin Ibanuje tab'okunkun le de Wakati kan lodo Jesu to fun mi Amin |
Re: Post Yoruba Christian Hymns Here by obasolape(f): 6:52am On Dec 02, 2021 |
Ko to k’ awon mimo beru, Ki nwon so ’reti nu: ’Gba nwon ko reti ranwo Re, Olugbala y’o de. Nigbati Abram mu obe, Olorun ni, “Duro” ; Agbo ti o wa lohun ni, Y’o dipo omo na.” ’Gba Jona ri sinu omi, Ko ro lati yo mo; Sugbon Olorun ran eja, T’ o gbe lo s’ ebute. B’ iru ipa at’ ife yi Ti po l’ oro Re to ! Emi ba ma k’ aniyan mi, Le Oluwa lowo ! E duro de iranwo Re, B’ o tile pe, Duro, B’ ileri na tile fale, Sugbon ko le pe de. Amin. |
Re: Post Yoruba Christian Hymns Here by obasolape(f): 6:09pm On Dec 23, 2021 |
“Nipase Re li a ti da ohun gbogbo.” Johan1:3 1. Fun aiye t’o l’ewa yi Fun ewa awosanma Fun fife t’Iwo fe wa Lati igba ewe wa Kristi awa y’o yin O Jo, tewogba ope wa 2. Fun anu t’a ngba l’osan At’eyit’angba l’oru Igi ati eso re Orun ati osupa Kristi awa y’o yin O Jo, tewogba ope wa 3. Fun oju ati eti Okan ti a fi nronu Owo, ese, ti a nlo Iwo da wa ni pipe Kristi awa y’o yin O Jo, tewogba ope wa 4. Fun ife ninu Kristi Ife t’o se wa l’okan Ife baba si omo Ati t’omo si baba Kristi awa y’o yin O Jo, tewogba ope wa 5. Fun gbogbo ebun ofe T’Iwo da le wa lori Aileso ore-ofe T’o se wa ni omo Re Kristi awa y’o yin O Jo, tewogba ope wa |
Re: Post Yoruba Christian Hymns Here by sholay2011(m): 10:57pm On Dec 23, 2021 |
Emi a duroti Oluwa 'Tori O mo ibere aye mi, 'Tor'Ohun lo le gbami, Lo le gbani, lo le lani, 'Tor'Ohun lo le gbami, Ki ese mi ma se ye! |
Re: Post Yoruba Christian Hymns Here by siant: 12:40am On Dec 27, 2021 |
Onigbagbo e bu s'ayo Ojo nla l'eyi fun wa E gbo bi awon angeli Ti nfi ogo f'Olorun Alafia, Alafia, Ni fun gbogbo eniyan. Gbogbo aye e ho f'ayo K'afi ogo f'Olorun, Omo bibi Re L'ofun wa T'abi ninu wundia Eni 'yanu, eni 'yanu Ni Omo t'abi loni Ninu gbogbo rudurudu Ohun ibi t'okun aye Ninu idamu nla ese L'omo Olorun wa gba wa. Olugbimo, Olugbimo Alade Alafia Olorun Olodumare L'abi bi omo titun Baba Eni ayeraye L' odi alakoso wa E bu s'ayo, E bu s'ayo Omo Dafidi j'oba. O wa gba wa l'owo ese O wa d'oni gbowo wa Lati fo itegun ese A se ni Oga Ogo, E ku ayo, E ku ayo A gba wa l'owo iku. Amin |
Re: Post Yoruba Christian Hymns Here by obasolape(f): 7:55pm On Dec 28, 2021 |
HYMN 138 “lba mase pe Oluwa ti o ti wa ni tiwa” - Ps. 124:1 1. lBASE p’Oluwa Ko ti wa ni tiwa Lo ye k’awa ma wi Nigbat’ese gbogun tiwa. Egbe: Ope ni f'Oluwa Oba wa Olore A ke kabiyesi 2. Nwon ‘ba bo wa mole Pelu agbara won, Ope ni f ’Oluwa, Ti ko jeki t’esu bori. Egbe: Ope ni f'Oluwa... 3. Okan wa yo b'eiye Nin' okun apeiye Okun ja, awa yo, E yo Jesu da wa sile. Egbe: Ope ni f'Oluwa... A f'ope fun Jehofa T'o gba wa Iowo ota, A dupe Oluwu. 4. Tire ni Oluwa Lati gbe wa leke Gbogbo awon ota, T'o wu ko tile yi wa ka. Egbe: Ope ni f'Oluwa... 5. Ara f ’okan bale Sodo Olugbala B’esu ti gbon to ni, Ko to kini kan fun Jesu. Egbe: Ope ni f'Oluwa... 6. Iranlowo wa mbe L'Oruko Oluwa T’O d’orun on aiye Oba awon eni Mimo. Egbe: Ope ni f'Oluwa... 7. Ogo fun Baba wa, Ogo fun Omo Re, Ogo f’Emi Mimo Metalokan jo gbo tiwa. Egbe: Ope ni f'Oluwa Oba wa Olore A ke kabiyesi A f'ope fun Jehofa T'o gba wa Iowo ota, A dupe Oluwu. Amin |
Re: Post Yoruba Christian Hymns Here by obasolape(f): 7:56pm On Dec 28, 2021 |
Wi jade larin Keferi p’ Oluwa l’ Oba, Wi jade ! Wi Jade ! Wi jade f’ orile-ede, mu ki nwon korin, Wi jade ! Wi jade ! Wi jade tiyintiyin pe, On o ma po si, Pe, Oba nla Ologo l’ Oba Alafia; Wi jade tayotayo, bi iji tile nja, Pe, O joko lor’ isan omi, Oba wa titi lai. Wi jade larin Keferi pe, Jesu njoba, Wi jade ! Wi Jade ! Wi jade f’ orile-ede, mu k’ ide won ja, Wi jade ! Wi jade ! Wi jade fun awon ti nsokun, pe Jesu ye; Wi jade f’ alare pe, O nfun ni nisimi; Wi jade f’ elese pe, O wa lati gbala; Wi jade fun awon ti nku pe, O ti segun iku. Wi jade larin Keferi, Krist njoba loke, Wi jade ! Wi jade ! Wi jade fun keferi, Ife n’ ijoba Re. Wi jade ! Wi jade ! Wi jade lona opopo, l’ abuja ona, Je k’o dun jakejado ni gbogbo agbaiye: B’ iro omi pupo ni k’ iho ayo wa je, titi gbohun-gbohun y’o fi gbe iron a de ’kangun aiye. Amin. |
Re: Post Yoruba Christian Hymns Here by obasolape(f): 7:52pm On Jan 07, 2022 |
1. ISUN kan wa t’o kun f’eje O yo n’iha jesu, Elese mokun ninu re, O bo ninu ebi. 2. ‘Gba mo f’igbagbo r’isun na, Ti nsan fun ogbe Re, Irapada d’orin fun mi Ti ngo ma ko titi. 3. Ninu orin t’odun julo, L’emi o korin Re: ‘Gbat’ akololo ahon yi Ba dake n’iboji. 4. Mo gbagbo p’O pese fun mi (Bi mo tile s,aiye ) Ebun ofe t’a f’eje ra, Ati duru wura. 5. Duru t’a tow’ Olorun se, Ti ko ni baje lai; T’a o ma fi yin Baba wa, Oruko Re nikan. |
Re: Post Yoruba Christian Hymns Here by obasolape(f): 8:14pm On Jan 07, 2022 |
Bi mo ti ri, lai s’awawi Bi mo ti ri, lai s’awawi 1. Bi mo ti ri, lai s’awawi Sugbon nitori eje Re B’o si ti pe mi pe ki nwa Olugbala, mo de. 2. Bi mo ti ri, laiduro pe Mo fe k ‘okan mi mo toto S’odo Re to le we mi mo Olugbala, mo de 3. Bi mo ti ri, b’o tile je Ija l’ode, ija ninu Eru l’ode, eru ninu Olugbala, mo de 4. Bi mo ti ri, osi are Mo si nwa imularada Iwo le s’awotan mi Olugbala, mo de. 5. Bi mo ti ri ‘wo o gba mi ‘wo o gba mi, t’owo t’ese ‘tori mo gba ‘leri Re gbo Olugbala, mo de. 6. Bi mo ti ri ife Tire L’o sete mi patapata Mo di Tire, Tire nikan Olugbala, mo de. 7. Bi mo ti ri, n’nu ‘fe nla ni T’o fi titobi Re han mi Nihin yi ati ni oke Olugbala, mo de. Amin. Just as I am—without one plea 1. Just as I am—without one plea, But that Thy blood was shed for me, And that Thou bidst me come to Thee— O Lamb of God, I come, I come. 2. Just as I am—and waiting not To rid my soul of one dark blot, To Thee whose blood can cleanse each spot— O Lamb of God, I come, I come. 3. Just as I am—though tossed about With many a conflict, many a doubt, Fightings and fears within, without— O Lamb of God, I come, I come. 4. Just as I am—poor, wretched, blind; Sight, riches, healing of the mind, Yea, all I need in Thee to find— O Lamb of God, I come, I come. 5. Just as I am—Thou wilt receive, Wilt welcome, pardon, cleanse, relieve; Because Thy promise I believe— O Lamb of God, I come, I come. 6. Just as I am—Thy love unknown Hath broken every barrier down; Now, to be Thine, yea, Thine alone— O Lamb of God, I come, I come. 7. Just as I am—of that free love The breadth, length, depth, and height to prove, Here for a season, then above— O Lamb of God, I come, I come! |
Re: Post Yoruba Christian Hymns Here by siant: 12:10am On Jan 21, 2022 |
K' ise lai n'ireti Ni mo to O wa K' ise lai n'igbagbo Ni mo kunle Ese ti g'ori mi Eyi sa l' ebe mi Eyi sa l'ebe mi Jesu ti ku A! Ese mi po ju O pon Koko Adale, adale Ni mo n'dese Ese aiferan re Ese aigba O gbo Ese aigba O gbo Ese nlanla Oluwa mo jewo Ese nla mi O mo bi mo ti ri Bi mo ti wa Jo we ese mi nu K'okan mi mo loni K'okan mi mo loni Ki n di mimo Olododo ni O O n dariji L'ese agbelebu Ni mo wole Je k'eje iwenu Eje Od'aguntan Eje Od'aguntan We okan mi Gbana alafia Yo o d'okan mi Gbana n o ba O rin Ore airi Emi o f' ara ti O Jo ma to mi s'ona Jo ma to mi s'ona Titi aye |
Re: Post Yoruba Christian Hymns Here by obasolape(f): 4:30am On Jan 27, 2022 |
1. WA k’ a da m’ awon ore wa Ti nwon ti jere na; N’ ife k’ a f’ okan ba won lo S’ ode orun lohun. 2. K’ awon t’ aiye d’ orin won mo, T’ awon t’ o lo s’ ogo; Awa l’ aiye, awon l’ orun, Okan ni gbogbo wa. 3. Idile kan n’nu Krist’ ni wa, Ajo kan l’a si je; Isan omi kan l’o yaw a, Isan omi iku. 4. Egbe ogun kan t’Olorun Ase Re l’a sin se; Apakan ti wo ‘do na ja, Apakan nwo lowo! 5. Emi wa fere dapo na, Y’o gb’ade bi ti won; Ao yo s’ami Balogun wa, Lati gbo ipe Re. 6. Jesu, so wa, s’amona wa, Gbat’oniko ba de; Oluwo, pin omi meji, Mu wa gunle l’ayo. |
Re: Post Yoruba Christian Hymns Here by obasolape(f): 11:03am On Feb 09, 2022 |
1. TAN ihin na kale, jakejado aiye K'awon ti eru npa Mo pe igbala de K‘awon t’ise ti Krist’ So ihin ayo na. Egbe: Olutunu ti de, Olutunu ti de Emi Iat’ oke wa, ileri Baba wa Tan ihin na kale, jakejado aiye Olutunu ti de. 2. Oba awon oba, wa f 'iwosan fun wa O wa ja ide wa, O mu igbala wa K‘olukuluku wa, korin isegun pe. Egbe: Olutunu ti de... 3. lfe iyanu nla, a! mba rohin na Fun gbogbo enia, ehun or‘ofe Re Emi omo egbe, di omo igbala. Egbe: Olutunu ti de... 4. Gbe orin ‘yin soke s'olurapada wa K‘awon mimo l‘oke Jumo ba wa gberin Yin ife re titi, ife ti ko le ku. Egbe: Olutunu ti de, Olutunu ti de Emi Iat’ oke wa, ileri Baba wa Tan ihin na kale, jakejado aiye Olutunu ti de. Amin 1 Like |
Re: Post Yoruba Christian Hymns Here by obasolape(f): 6:19am On Feb 26, 2022 |
1. Baba mi, ‘gba mba / nsako lo Kuro l’ ona Re / l’ aiye yi; Ko mi kin le wi / bayi pe, Se ‘fe Tire. 2. B’ ipin mi l’ aiye / ba buru, Ko mi ki ngba, ki / nmase kun! Ki ngbadura t’ o ko / mi, wipe, Se ‘fe Tire. 3. B’ o ku emi ni/kansoso, Ti ara on o/re ko si; Ni’ teriba ngo / ma wipe, Se ‘fe Tire. 4. B’ o fe gba ohun / owo mi, Ohun t’ o se o/won fun mi; Ngo fi fun O, se / Tire ni? Se ‘fe Tire. 5. Sa fi Emi Re / tu mi n’nu, Ki On k’ o si ma / ba mi gbe; Eyi t’ o ku, o / d’ owo Re. Se ‘fe Tire. 6. Tun ‘fe mi se lo/jojumo K’ O si mu ohun / na kuro, Ti ko je k’ emi / le wipe, Se ‘fe Tire. 7. ‘Gbat’ emi mi ba / pin l’ aiye, N’ ilu t’ o dara / ju aiye, L’ emi o ma korin / na titi. Se ‘fe Tire. Amin. |
Re: Post Yoruba Christian Hymns Here by obasolape(f): 6:49am On Feb 26, 2022 |
1. Jesu mimo Ore airi Oluranlowo alaini N'nu ayida aiye, ko mi K'emi le romo O. 2.Ki nsa n‘idapo mimo yi, Gba ohun t‘O fe ugo kun bi? B‘okan mi b‘eka ajara Ba sa le ro mo O. 3. Are ti m'okan mi pupo Sugbon o wa r'ibi simi T'ori t'o room O 4. B'aiye d'ofo mo mi loju Ba gba ore at'ara lo Ni Suri ati laibohun L'emi o romo O 5 ‘Gba t‘o k‘emi nikan soso, Larin idamu aye yi, Mo gb‘ohun ife jeje na Wipe, “Sa ro mo Mi 6 B‘are ba fe mu igbagbo, T‘ireti ba si fe saki, Ko si ewu fun okan na Ti o ba ro mo O. 7 Won ko beru ‘rumi aye Nitori ‘Wo wa nitosi; Won ko si gbon b‘iku ba de ‘Tori won ro mo O. 8 Ire sa ni l‘ohun gbogbo, Ko s‘eni le daya fo mi ‘Gba mo fi O s‘Olugbala, Ti mo si ro mo O. |
Re: Post Yoruba Christian Hymns Here by obasolape(f): 3:29am On Mar 09, 2022 |
Ma gbadura; Emi mbebe n’nu re Ma gbadura; Emi mbebe n’nu re Fun gbogbo aini re igagbogbo. Ma gbadura; labe eru ese, Adura nri eje Jesu ti nsan. Ma gbadura; b’ are tile mu o, Adura ngbe wa s’eba ‘te Baba. Ma gbadura; n’nu wahala aiye, Adura l’o nfun okan n’ isimi. Ma gbadura; b’ ayo ba yi o ka, Adura nlu harp, o nkorin angel’. Ma gbadura; b’awon t’o feran ku, Adura mba won mu omi iye. Gbogb’ ohun aiye y’o b’aiye koja, Adura wa titi: ma gbadura. Amin. |
Re: Post Yoruba Christian Hymns Here by obasolape(f): 3:43am On Mar 09, 2022 |
The name the name of Jesus Is greater and higher than all names It is not an ordinary name It's the name that full of power and grace. At the name all sickness will bow Demons tremble at the sound of the name It is not an ordinary name It's a name that full of power and grace..... |
Re: Post Yoruba Christian Hymns Here by obasolape(f): 2:28am On Mar 10, 2022 |
O fun mi l'edidi O fun mi l'edidi, 'Gbese nla ti mo je, B'o ti fun mi, o si rerin, Pe, “Mase gbagbe mi!” O fun mi l'edidi, o san igbese na; B'o ti fun mi, o si rerin, Wi pé, “Ma ranti mi!” N ó p'edidi na mo, B'igbese tile tan; o n so ife eni t'o san, Igbese naa fun mi. Mo wo, mo si rerin Mo tun wo, mo sokun; eri ife Re si mi ni, N ó toju re titi. Ki tun s'edidi mo, Sugbon iranti ni! Pe gbogbo igbese mi ni, Emmanueli san. Amin |
Re: Post Yoruba Christian Hymns Here by obasolape(f): 2:31am On Mar 10, 2022 |
1. Are mu O, okan re poruru So fun Jesu, so fun Jesu; Ibanuje dipo ayo fun O? So fun Jesu nikan. So fun Jesu, So fun Jesu, On l'ore ti o mo; Ko si ore tabi 'yekan bi Re So fun Jesu nikan. 2. Asun-dekun omije lo nsun bi? So fun Jesu, So fun Jesu, Iwo l'ese ti enikan ko mo? So fun Jesu nikan. 3. Iwo nfoya 'banuje ti mbe bi? So fun Jesu, So fun Jesu: Iwo ns'aniyan ojo ola bi? So fun Jesu nikan. 4. Ironu iku nda o lamu bi? So fun Jesu, So fun Jesu: O nsaferi ijoba Jesu bi? So fun Jesu nikan. Amin. |
Re: Post Yoruba Christian Hymns Here by obasolape(f): 2:39am On Mar 10, 2022 |
Bi mo ti ri laisawawi, Sugbon nitori eje Re; B’o si ti pe mi pe ki mwa Olugbala, mo de. Bi mo ti ri laiduro pe, Mo fe k’okan mi mo toto, S’odo Re t’o le we mi mo, Olugbala, mo de. Bi mo ti ri b’o tile je Ija l’ode, ija ninu, Eru l’ode eru ninu, Olugbala, mo de. Bi mo ti ri osi, are, Mo si nwa imularada; Iwo l’o le s’awotan mi, Olugbala, mo de. Bi mo ti ri ’Wo o gba mi, Wo o gba mi t’owo t’ese; ’Tori mo gba ’leri Re gbo, Olugbala, mo de. Bi mo ti ri ife Tire, L’o sete mi patapata; Mo di tire, tire nikan, Olugbala, mo de. Amin. |
Re: Post Yoruba Christian Hymns Here by obasolape(f): 2:41am On Mar 10, 2022 |
*Ore Wo L’ani Bi Jesu* Ore wo l’ani bi Jesu, ti o ru banuje wa! Anfani wo lo po bayi lati ma gbadura si! Alafia pupo l’a nsonu, a si ti je rora po, Tori a ko fi gbogbo nkan s’adura niwaju re. Idanwo ha wa fun wa bi? A ha nni wahala bi? A ko gbodo so ’reti nu; sa gbadura s' Oluwa. Ko s’oloto ore bi re ti ole ba wa daro, Jesu ti mo ailera wa; sa gbadura s’Oluwa. Eru ha nwo wa l’orun bi, aniyan ha po fun wa? Olugbala je abo wa, sa gbadura s’Oluwa. Awon ore ha sa o ti? Sa gbadura s’Oluwa. Yo gbe o soke lapa re, Iwo yo si ri itunu. Amin |
Re: Post Yoruba Christian Hymns Here by obasolape(f): 5:34am On Mar 16, 2022 |
Emi orun, gbadura wa, Wa gbenu ile yi Sokale pel'agbara Re, Wa, Emi Mimo wa. Wa b'imole, si fihan wa Baini wa ti po to; Wa, to wa si ona iye, Ti olododo n rin. Wa bi ina ebo mimo: Sokan wa di mimo; Je ki okan wa je ore, Foruko Oluwa. Wa bi iri, si wa bukun Akoko mimo yi: Ki okan alaileso wa Le yo l'agbara Re. Wa bi adaba, n'apa Re, Apa ife mimo; Wa je ki ijo Re laye Dabi ijo torun. Emi orun, gbadura wa, Saye yi dile Re; Sokale pel'agbara Re, Wa, Emi Mimo wa. |
Re: Post Yoruba Christian Hymns Here by obasolape(f): 5:34am On Mar 16, 2022 |
1. MO gbohun Jesu t’ o wipe, “Wa simi lodo Mi; Gbe ori re, ‘wo alare, Le okan aiya Mi.” Ninu are on ‘banuje, Ni mo to Jesu wa; O je ib’ isimi fun mi, O si mu ‘nu mi dun. 2. Mo gbohun Jesu t’ o wipe “Iwo ti ongbe ngbe, Ngo f’ omi ‘ye fun o lofe, Bere, mu k’ o si ye.” Mo to Jesu wa, mo si mu Ninu omi ‘ye na; Okan mi tutu, o soji, Mo d’ eni alaye. 3. Mo gbohun Jesu t’ o wipe, ” ‘Mole aiye l’ emi; Wo Mi, Emi ni Orun re, Ojo re yio dara.” Mo wo Jesu, emi si ri B’ Orun ododo mi, Ninu ‘mole yi l’ emi o rin Tit’ ajo mi yio pin. |
Re: Post Yoruba Christian Hymns Here by obasolape(f): 5:35am On Mar 16, 2022 |
Laifoya lapa Jesu, Laifoya laya Re Labe ojiji 'fe Re Lokan mi yo sinmi. Gbo ohun angeli ni, Orin won deti mi, Lati papa ogo wa, Lati okun Jaspi. Refrain: Laifoya lapa Jesu Laifoya laya Re Labe ojiji 'fe Re Lokan mi yo sinmi. Laifoya lapa Jesu Mo bo low'aniyan, Mo bo lowo idanwo, Ese ko nipa mo, Mo bo lowo 'banuje, Mo bo lowo eru O ku idanwo die! O k'omije die! Jesu abo okan mi, Jesu ti ku fun mi, Apata ayeraye Lemi o gbekele, Nihin lemi o duro Tit'oru yo koja, Titi n o fi rimole Ni ebute ogo. Source: Yoruba Baptist Hymnal #254 Safe in the arms of Jesus, Safe on His gentle breast; There by His love o’ershaded, Sweetly my soul shall rest. Hark! ’tis the voice of angels Borne in a song to me, Over the fields of glory, Over the jasper sea. Refrain: Safe in the arms of Jesus, Safe on His gentle breast; There by His love o’ershaded, Sweetly my soul shall rest. Safe in the arms of Jesus, Safe from corroding care, Safe from the world’s temptations; Sin cannot harm me there. Free from the blight of sorrow, Free from my doubts and fears; Only a few more trials, Only a few more tears! Jesus, my heart’s dear Refuge, Jesus has died for me; Firm on the Rock of Ages Ever my trust shall be. Here let me wait with patience, Wait till the night is o’er; Wait till I see the morning Break on the golden shore. |
Re: Post Yoruba Christian Hymns Here by Deejaygold(m): 11:07pm On Apr 02, 2022 |
Jesu, a fe pade L’ojo Re mimo yi, A si y’Ite Re ka L’ojo Re mimo yi Wo ore wa orun, Adura wa mbo wa, Bojuwa emi wa, L’ojo Re mimo yi. This is by Methodist Church Nigeria |
Re: Post Yoruba Christian Hymns Here by obasolape(f): 5:05am On Apr 03, 2022 |
Oluwa, awa omo re de, Lati gbohun ebe wa soke, Gebebi o ti gbo adura Elijah, Jowo gbo adura wa. O gbadura k'ojo mase ro, Fun odun meta, osu mefa, Gebebi o ti gbo adura Elijah, Jowo gbo adura wa. O si tun gbadura lekeji, Ojo ro, ile si meso wa, Gebebi o ti gbo adura Elijah, Jowo gbo adura wa. Adura lo silekun anu, Adura lo si Anna ninu, Gebebi o ti gbo adura Elijah, Jowo gbo adura wa. Amin |
Re: Post Yoruba Christian Hymns Here by obasolape(f): 5:11am On Apr 03, 2022 |
Jesu lolubaso okan mi Ore ti ko le ko mi sile Oba ti nso Ekun dayo Olutunnu okan mi Larin ota larin idamu E ko fi mi fun iji aye A Oluwa mi mo dupe Modupe modupe |
Re: Post Yoruba Christian Hymns Here by obasolape(f): 2:55am On Apr 18, 2022 |
1. JESU oluf’ okan mi, Je ki nsala s’ aiya Re; Sa t’ irumi sunmo mi, Sa ti iji fe s’ oke; Pa mi mo, Olugbala, Tit’ iji aiye y’o pin, To mi lo s’ ebute Re, Nikehin gb’ okan mi la. 2. Abo mi, emi ko ni, Iwo l’ okan mi ro mo; Ma f’ emi nikan sile, Gba mi, si tu mi ninu. Iwo ni mo gbekele, Iwo n’iranlowo mi, Ma sai f’iye apa Re D’abo b’ori aibo mi. 3. Krist’,’wo nikan ni mo fe, N’nu Re, mo r’ohun gbogbo; Gb’emi t’o subu dide, W’alaisan, to afoju; Ododo l’oruko Re, Alaisododo l’emi, Mo kun fun ese pupo, Iwo kun fun ododo. 4. ‘Wo l’opo ore-ofe Lati fib o ese mi: Je ki omi iwosan We inu okan mi mo; Iwo l’orisun iye, Je ki mbu n’nu Re l’ofe, Ru jade n’nu okan mi, Si iye ainipekun. 1 Jesus, lover of my soul, Let me to Thy bosom fly, While the nearer waters roll, While the tempest still is high: Hide me, O my Savior, hide, Till the storm of life is past; Safe into the haven guide; O receive my soul at last. 2 Other refuge have I none, Hangs my helpless soul on Thee; Leave, oh, leave me not alone, Still support and comfort me. All my trust on Thee is stayed, All my help from Thee I bring; Cover my defenseless head With the shadow of Thy wing. 3 Thou, O Christ, art all I want; More than all in Thee I find; Raise the fallen, cheer the faint, Heal the sick and lead the blind. Just and holy is Thy name, I am all unrighteousness; Vile and full of sin I am, Thou art full of truth and grace. 4 Plenteous grace with Thee is found, Grace to cover all my sin; Let the healing streams abound; Make and keep me pure within. Thou of life the fountain art, Freely let me take of Thee; Spring Thou up within my heart, Rise to all eternity. |
Re: Post Yoruba Christian Hymns Here by obasolape(f): 2:56am On Apr 18, 2022 |
O fun mi l'edidi O fun mi l'edidi, 'Gbese nla ti mo je, B'o ti fun mi, o si rerin, Pe, “Mase gbagbe mi!” O fun mi l'edidi, o san igbese na; B'o ti fun mi, o si rerin, Wi pé, “Ma ranti mi!” N ó p'edidi na mo, B'igbese tile tan; o n so ife eni t'o san, Igbese naa fun mi. Mo wo, mo si rerin Mo tun wo, mo sokun; eri ife Re si mi ni, N ó toju re titi. Ki tun s'edidi mo, Sugbon iranti ni! Pe gbogbo igbese mi ni, Emmanueli san. Amin |
Re: Post Yoruba Christian Hymns Here by obasolape(f): 2:56am On Apr 18, 2022 |
Krist' Oluwa ji loni, - Halleluyah, Eda at' Angeli nwi - Hal. Gb' ayo at' isegun ga - Hal. K' orun at' aiye gberin! - Hal. Ise ti idande tan; - Hal. O jija, O ti segun; - Hal. Wo, 'ponju orun koja - Hal. Ko wo sinu eje mo - Hal. Lasan n' iso at' ami, - Hal. Krist' woo run apadi; - Hal Lasan l' agbara iku, - Hal. Krist, si Paradise. - Hal. O tun wa, Oba ogo: - Hal. "Iku itani re wa?" - Hal. Lekan l' O ku k' O gba wa, - Hal. "'Boji, isegun re wa?" - Hal. E je k' awa goke lo, - Hal. Sodo Kristi Ori wa, - Hal. A sa jinde pelu Re, - Hal. Bi a ti ku pelu Re. - Hal. Oluwa t' aiye t' orun, - Hal. Tire ni gbogbo iyin, - Hal. A wole niwaju Re - Hal. 'Wo Ajinde at' Iye. - Hal. Source: Baptist Hymnal #118 |
Re: Post Yoruba Christian Hymns Here by obasolape(f): 2:57am On Apr 18, 2022 |
1. “MO mo p’Oludande mi mbe;” Itunu nla l’eyi fun mi! O mbe, Enit’ o ku lekan; O mbe, Ori iye mi lai. 2. O mbe, lati ma bukun mi, O si mbebe fun mi loke; O mbe, lati ji mi n’boji, Lati gba mi la titi lai. 3. O mbe, Ore korikosun. Ti y’o pa mi mo de opinl; O mbe, emi o ma korin, Woli, Alufa, Oba mi. 4. O mbe, lati pese aye, Y’o si mu mi de ‘be l’ayo; O mbe, ogo l’ oruko Re; Jesu, okanna titi lai. 5. O mbe, mo bo low’ aniyan; O mbe, mo bo lowo ewu; A! ayo l’ oro yi fun mi, “Mo mo p’ Oludande mi mbe!” |
Re: Post Yoruba Christian Hymns Here by obasolape(f): 2:58am On Apr 18, 2022 |
Onigbagbo e bu sayo! Onigbagbo e bu sayo! 1. Onigbagbo e bu sayo! Ojo nla loni fun wa Korun fayo korin kikan, Kigbo atodan gberin E ho! E yo! Okun atodo gbogbo. 2. E jumo yo, gbogbo eda, Laye yi ati lorun, Ki gbogbo ohun alaaye Nile, loke, yin Jesu E fogo fun Oba nla ta bi loni. 3. Gbohun yin ga, "Om'Afrika" Eyin iran Yoruba; Ke "Hosanna" lohun gooro Jake jado ile wa. Koba gbogbo, Juba Jesu Oba wa. 4. E damuso! E damuso! E ho ye! Ke si ma yo, Itegun Esu fo wayi, "Iru-omobinrin" de. Halleluyah! Olurapada, Oba. 5. E gbohun yin ga, Serafu, Kerubu, leba ite; Angeli ateniyan mimo, Pelu gbogbo ogun orun. E ba wa yo! Odun idasile de. 6. Metalokan, Eni Mimo Baba Olodumare Emi Mimo, Olutunnu, Jesu, Olurapada, Gba iyin wa 'Wo nikan logo ye fun. |
(1) (2) (3) ... (6) (7) (8) (9) (10) (Reply)
The First Britsh Slave Ship To Reach The Americas Was Called The Good Jesus! / Cultism, The Spiritual Consequences And Deliverance Through Christ / Gospel Hymns And Songs — ♫ Praise & Worship || All-Sufficient Jesus ♫
(Go Up)
Sections: politics (1) business autos (1) jobs (1) career education (1) romance computers phones travel sports fashion health religion celebs tv-movies music-radio literature webmasters programming techmarket Links: (1) (2) (3) (4) (5) (6) (7) (8) (9) (10) Nairaland - Copyright © 2005 - 2024 Oluwaseun Osewa. All rights reserved. See How To Advertise. 74 |