Welcome, Guest: Register On Nairaland / LOGIN! / Trending / Recent / New
Stats: 3,153,016 members, 7,817,994 topics. Date: Sunday, 05 May 2024 at 02:39 AM

Post Yoruba Christian Hymns Here - Religion (10) - Nairaland

Nairaland Forum / Nairaland / General / Religion / Post Yoruba Christian Hymns Here (224556 Views)

Post Your Favourite Christian Hymns / Share Your Best Hymns / Christian Hymns/songs And Copyrights (2) (3) (4)

(1) (2) (3) ... (7) (8) (9) (10) (Reply) (Go Down)

Re: Post Yoruba Christian Hymns Here by obasolape(f): 2:34am On Apr 30, 2022
“Iba mase pe Oluwa ti o ti wa ni tiwa”
- Ps. 124:1

1. mf IBA SE p'Oluwa
Ko ti wa ni tiwa,
Lo yẹ k'awa ma wi,
Nigba t'esu gbogun tiwa.

ff Egbe: Ọpẹ ni f'Oluwa,
Ọba wa Olore,
A ke Kabiyesi,
A f'ọpẹ fun jehofa,
T'o gba wa lọwọ ọta,
A dupẹ Oluwa.

2. f Wọn 'ba bo wa mọlẹ,
Pẹlu agbara wọn,
Ọpẹ ni f'Oluwa,
Ti ko jẹ ki t'esu bori.

ff Egbe: Ọpẹ ni f'Oluwa,..........etc.

3. f Ọkan wa yọ b'ẹyẹ,
Nin' okun apẹyẹ,
Okun ja, awa yọ,
Ẹ yọ Jesu da wa silẹ.

ff Egbe: Ọpẹ ni f'Oluwa,..........etc.

4. cr Tirẹ ni Oluwa,
Lati gbe wa leke,
Gbogbo awọn ọta,
T'o wu ko tilẹ yi wa ka.

ff Egbe: Ọpẹ ni f'Oluwa,..........etc.

5. cr Ara f'ọkan balẹ,
S'ọdọ Olugbala,
B'esu ti gbọn to ni,
Ko to kini kan fun Jesu.

ff Egbe: Ọpẹ ni f'Oluwa,..........etc.

6. f Iranlọwọ wa mbẹ,
L'orukọ Oluwa,
T'O da ọrun oun ayé,
Ọba awọn ẹni mimọ.

ff Egbe: Ọpẹ ni f'Oluwa,..........etc.

7. cr Ogo fun Baba wa,
Ogo fun Ọmọ Rẹ,
Ogo f'Ẹmi Mimọ ,
Mẹtalọkan jọ gbọ tiwa,

ff Egbe: Ọpẹ ni f'Oluwa,..........etc.
Ọba wa Olore,
A ke Kabiyesi,
A f'ọpẹ fun jehofa,
T'o gba wa lọwọ ọta,
A dupẹ Oluwa.
AMIN
Re: Post Yoruba Christian Hymns Here by obasolape(f): 2:53am On May 07, 2022
MO fi gbogbo re fun Jesu,

MO fi gbogbo re fun Jesu,
Patapata l'aiku kan,
Ngó ma fe, ngó si gbekele,
Ngó wa lodo re titi.

CHORUS

Mo fi gbogbo re (2ce)
Fun o, Olugbala mi, ni
Mo fi won sile.

Mo fi gbogbo re fun Jesu,
Mo fi rele wole fun;
Mo fi gbadun ayé sile;
Gbami Jesu si gba mi

Mo fi gbogbo re fun Jesu,
se mi ni Tire nikan
Jeki kun fun
Ki nmo pe 'wo je temi'

Mo fi gbogbo re fun Jesu
Mo fi ara mi fun o
F'ife at'agbara kun mi,
Ki ibukun re ba le mi.

Mo fi gbogbo re fun Jesu,
Mo mo p'emi ba le mi
A! ayo igbala kikun!
Ogo, ogo, f'ogo re.

AMIN

All to Jesus I surrender,
All to Him I freely give,
I will ever love and trust Him,
In His presence daily live.

I surrender all,
I surrender all;
All to thee, my blessed saviour,
I surrender all.

All to Jesus I surrender,
Humbly at His feet I bow;
Worldly pleasures all forsaken,
Take me, Jesus, take me now

All to Jesus I surrender,
Lord, I give myself to Thee;
Fill me with Thy love and power,
Let Thy blessings fall on me.

All to Jesus I surrender,
Now I feel the sacred flame,
O the joy of full salvation!
Glory, glory to His name.
Re: Post Yoruba Christian Hymns Here by obasolape(f): 6:11am On May 11, 2022
Bibeli mimo torun
Owon isura temi!
'Wo ti n wi bi mo ti ri,
'Wo ti n so bi mo ti wa.

'Wo nko mi, bi mo sina,
'Wo n f'ife Oluwa han;
'Wo lo si n to ese mi,
'Wo lo n dare at'ebi.

'Wo ni ma tu wa ninu,
Ninu wahala aye,
'Wo n ko ni, nipa 'gbagbo
Pe a le segun iku.

'Wo lo n so tayo ti n bo,
Ati 'parun elese;
Bibeli mimo torun,
Owon isura temi.
Re: Post Yoruba Christian Hymns Here by RexTramadol1: 10:56pm On Sep 18, 2022
Idrizz:
Mo ti wa la ti ma ko orin ti igbani



Lmao, which version is this

(1) (2) (3) ... (7) (8) (9) (10) (Reply)

Pastor Chris And T.b Joshua Are Satanic. (pst Chris Is A White Demon) / The First Britsh Slave Ship To Reach The Americas Was Called The Good Jesus! / Gospel Hymns And Songs — ♫Praise & Worship || Prevailing Prayers ♫

(Go Up)

Sections: politics (1) business autos (1) jobs (1) career education (1) romance computers phones travel sports fashion health
religion celebs tv-movies music-radio literature webmasters programming techmarket

Links: (1) (2) (3) (4) (5) (6) (7) (8) (9) (10)

Nairaland - Copyright © 2005 - 2024 Oluwaseun Osewa. All rights reserved. See How To Advertise. 15
Disclaimer: Every Nairaland member is solely responsible for anything that he/she posts or uploads on Nairaland.