Welcome, Guest: Register On Nairaland / LOGIN! / Trending / Recent / New
Stats: 3,153,755 members, 7,820,623 topics. Date: Tuesday, 07 May 2024 at 06:24 PM

Itan Sebi Otimo - Literature - Nairaland

Nairaland Forum / Entertainment / Literature / Itan Sebi Otimo (2747 Views)

Itan Alajo Somolu / Itan Akonilogbon (2) (3) (4)

(1) (Reply) (Go Down)

Itan Sebi Otimo by oloriireomo(m): 5:54pm On Sep 11, 2013
SE BI O TI MO, ELEWA SAPON,OWE NI TABI OWE KO?KA ITAN YI

Idalasa yii kiise owe tabi asayan rara.
,iya kan nii dasa be laye igbakan .

asa yii ti di ka'leka'ko ni ilẹ Yoruba titi d'oni yii.

Oja kan wa ni Abeokuta ni ipinle Ogun,o gbayi pupo laiye atijo, oja naa ni gbogbo awon ti ko laya n'le tabi apon ti ma n fatapase(jeun) ajeyo si ni won ma n je. idi rè niyen ti won fi npe ọja naa ni Saponloore.

Oja Sapọn ni iya kan ti oruko re nje Odesola ti nta ewa sise, oun naa lo si maa n daasa Sebootimo.

Ewa iya yi dun to beege to fi jẹ pe kia lo gb’ori l’owo gbogbo awon ẹlẹwa yooju ni agbegbe re.

Ikoko ẹwa jabete kan lo fi bẹrẹ owo yii sugbon ko pẹ pupọ ti isẹ yi fi kuro ni keremi, o deni tii se odindi apo ẹwa kan tan l’ọjọ kan soso.

Ikoko ẹwa a wa lo bii rẹrẹ ni isọ re pẹlu ogunlọgọ awon ọmọ isẹ. Se ni ọgọọrọ ero a pe le lori pitimu,biigba teegun ba n jo tero sii n woran. ti won a to lọ bẹẹrẹ lati ra ẹwa, afi bii pe o se awure .

Bi awon kan ti nj’oko jẹ ẹ ni isọ rẹ l’awon miin a ra a lọ s’ile won.
Ninu ita arigbo pe, eja n’iya yi nta niigba kan ri. Eja panla lo n kiri lọ l’ọjọ kan ló ni k’oun ra ẹwa jẹ l’adugbo kan ni Abeokuta. Obẹ ata ti won bù lé ori ewa fún un buru jai kosi te l’ọrun idi niyi ti oun naa fi pinnu lati bẹrẹ ẹwa tita.ose atunse si ewa tie ki oun naa ma baa se iru asise eyi ti elewa ibi ti oti ra se.

Agbo ninu itan pe iya yii ka iwe mefa aye igba naa,iyen Standard 6.

Asa sebootimọ yi lo maa nda nigba ti owo ẹwa re yi bureke tan.

O ma n sofun awon onibara re pe ki won sebi wonti mo(sebootimo), ki won ma je ju iwon owo to wa l’apo wọn lọ, ki wọn ma si ra ẹwa ju iwọn ti ikun wọn le gba lọ bi won ti e jeun sapo daadaa.

Otun ma n dasa yii k'ewa re ma baa tete tan .

Niigba mii t'ewa ba ti tan ti awon kan ba beere pe kilode ti ko se ewa si a ni ‘'n o le se ju agbara mi lo, se bo o ti mo l’aye gba’.

Iya elewa sopon yii siwa lori eepe titi doni yii.sungbon agba tide,kosi le sa kijo kijo kiri bii tatehinwa mo.
Ko ta ewa mo,ara n fe isinmi fakafiki lojoojumo.orin baba wa kan nun-un.

odun marunlelogoji ni iya yii fi tewa koto sinmi sile(retire)ni odun 1996.

Ninu itan,a gbo pe iya yii ti ta ewa fun oba ilu kan ri.koda ni aimoye igba ti oba yii bani awon alejo nla jankan-jankan ti ti wonsi nipe ewa lowun awon,iya yii ni won o gbe kontirati yi fun.

Kinnikan lowa yani lenu o.

Ni bayi,iya yii ti di ayalegbe, koda ati san'wo ile ti d'ogundode.kama wule menu ba oro ounje rara.Ipo ti iya yii wa bayi yato si aye igbaani.niigba ti ara se kosakosa.

O dami loju pe e o gbagbe itan baba alajo somolu?ara awon eniire niyen.itan iya alajo elewa saponloore niyi o.a o le gbagbe awon eniire mo ,oniirese ti fingba bi won o fingba mo eyi ti wonfi kole pare mo laelae. B'aye gbagbe ijoye tabi gbagbe olowo won o le gbagbe awon eni ire wonyi niiwon igba ti ina ede Yoruba ba ti n jo geerege.oun re o.

Kinni ipa tire ninu igbelaruge asa ati ede yoruba?

Kinni ise takuntakun re lati je o se'ranti re boo ba lo laye?


Hun!amo a o ni tori awijare kiito otan lenu.

A n gbadura pe k'oba adaniwaye o b'oju aanu wo iya elewa sapon lati aye dorun,ko boju aanu wo emi ejiworo,ebi mi,ati eyin ore mi lapapo.
Re: Itan Sebi Otimo by Nobody: 7:00pm On Sep 11, 2013
Ki Eledumare ran o lowo
Re: Itan Sebi Otimo by oloriireomo(m): 10:04am On Sep 12, 2013
Amin
Re: Itan Sebi Otimo by Thomanad(m): 1:26pm On Jan 05, 2021
Amin o.
Ese gan lopolopo fun itan yi. Ma a ri daju wipe emi na sa gbogbo ipa mi lati gbe asa ati ede Yoruba laruge nigba ku igba to anfani ati aye re ba wa.

(1) (Reply)

Dean koontz, Stephen King / Origins (A Poem On Yoruba Cultural Heritage) / Without A Silver Spoon

(Go Up)

Sections: politics (1) business autos (1) jobs (1) career education (1) romance computers phones travel sports fashion health
religion celebs tv-movies music-radio literature webmasters programming techmarket

Links: (1) (2) (3) (4) (5) (6) (7) (8) (9) (10)

Nairaland - Copyright © 2005 - 2024 Oluwaseun Osewa. All rights reserved. See How To Advertise. 14
Disclaimer: Every Nairaland member is solely responsible for anything that he/she posts or uploads on Nairaland.