Welcome, Guest: Register On Nairaland / LOGIN! / Trending / Recent / New
Stats: 3,153,536 members, 7,819,919 topics. Date: Tuesday, 07 May 2024 at 06:44 AM

.. - Culture (77) - Nairaland

Nairaland Forum / Nairaland / General / Culture / .. (1829291 Views)

"We The Ewe People Of Ghana Are The Same As Yoruba"- Yewe2011.ewe Guy From Ghana / How Do U Spell (weed) In Yoruba, Is It Igbo? Or Egbo? / Yoruba Idioms: Owe Yoruba, Itunmo Re Ati Lilo Re (2) (3) (4)

(1) (2) (3) ... (74) (75) (76) (77) (78) (79) (80) ... (99) (Reply) (Go Down)

Re: .. by Hadeyeancah(m): 6:50pm On May 15, 2016
Ifankaleluya:

Iyato wa dara-dara larin awon nkan ti e daruko yen. Ati wipe orisi-risi re lo wa.
Asiri-Owo da bi Ako-Osole, Nigbati a si le pe Asiri-bibo ni Awure.

Nipa disadvantages won, Awon nkan ti won ba fi se ni yio so iru alebu to wa nibe. Kiiise. Gbogbo iru-ogun bayen na ni o ni alebu, o wa lowo Babalawo ti o ba se fun yin. Idi niyi to fi je wipe eniyan o kan le sa dede ma se awon ogun kan to ka ninu iwe kan, bi kose. Ko to awon to ni imo(knowledge) nipa Ogun lo.
E se gan ni sir, Oba oke a ma fun yin se
Re: .. by wale259(m): 9:01pm On May 15, 2016
Ifa o to gege,ma je ki omo araye o le binu mi,ki n ma gbayi,ki n ma ri je,ki n ma ri mu,ki ma rina ri lo nigba gbogbo,Ase!!!
Ifankaleluya:
IFA NI,

Iji ti mo ji mo ba agbe lori igbago

Iji ti mo ji mo ba akalamagbo lori imo

Iji ti mo ji mo ba toro momo lori ope

Toro gege ni iya orunmile nje

Awon olode e mo le binu igun-nu-gun lai-lai

Olorisa kii binu sefun-sefun

Enikan kii binu akan lodo

Aigbori odo pete odo

Aigbaja ka gbimonran ika laja

Enikan kii gun iyan koko ko pode ilu jo

Ojiji enikan ke di mo ni

Ifa o to gege, ma je ki omo araye o le binu mi.

Aboru, Aboye, Abo-sise.
Re: .. by Tevez83839: 9:10pm On May 15, 2016
Baba Ejo o
Re: .. by Lero70: 6:56am On May 17, 2016
Ifankaleluya:
Ose Awure

E lo re wa ewe-marugbo-sanyan ati eru, ao gun po mo ose,ao ma we nigba to ba wu wa.

Aboru, Aboye, Abo-sise..!

edakun baba, se eeru(ashes) ni tabi eeru alamo abi eeru awonka? Eseun eweomaaje o.

1 Like

Re: .. by zenith329: 10:47am On May 17, 2016
Ekaro gbogbo ile, e jo, ki lo je ekiri eran, oronro malu ati onlo adie?
Re: .. by dominicson: 11:15pm On May 17, 2016
Ifa sings in Oyekuturupon:
Olowo f'owo jin mi Oyeku baturupon Alaya f'aya jin mi Oyeku-baturupon Olomo f'omo jin mi Oyeku-baturupon Onile f'ile jin mi Oyeku baturupon Oloko f'oko jin mi Oyeku baturupon
Ela boru, Ela boye, Ela bosise

2 Likes

1 Like 1 Share

Re: .. by PrinceAloBB: 6:59am On May 18, 2016
Ese pupo
Re: .. by Ifankaleluya: 3:22pm On May 18, 2016
AWURE OJA TITA ATI FUN ENI TI WA ISE
Ori--Langba, Oyin die, Omi-Omu, Ewe sawerepepe, Ewe-
afomo ajade, ao gun won po mo ose, ao ko sinu igba-
olomori, omi-omu yen ni ao fi po ose yen oo.
Ao te ose yen ni eji-ogbe, ao ma fi we.
Aboru, Aboye, Abo-sise!

2 Likes 2 Shares

Re: .. by Ifankaleluya: 3:23pm On May 18, 2016
Lero70:

edakun baba, se eeru(ashes) ni tabi eeru alamo abi eeru awonka? Eseun eweomaaje o.

Eru(do do) alamo(re re re)

1 Like

Re: .. by dominicson: 3:42pm On May 18, 2016
Ifa in Irete-Sa says:

Awo Ajiki l'awo Ajiki
Awo Ajiki l'awo Ajiki
Awo Ajiki l'a pe awo Aja-ale-gbuun
A dia fun Iki t'o ni oun yoo bo Ori-Elu, yoo gba ibo lowo oun
Iki ji o wewo fini, o wese fini, o wa mu obi o naa si Ori-Elu
Ori-Elu gba lowo re, o ni iwo Iki eleyinjuege l'o to mi bo.
Igbanaa ni Iki m'ekun s'ekun igbe, o m'ohun so'hun yere, nkorin wipe:
Gb'obi pa o, Awo aye! Gb'obi pa o, Awo Aye!

Ela boru, Ela boye, Ela bosise!

1 Like

Re: .. by Ifankaleluya: 3:43pm On May 18, 2016
Ifa ni;
Kundi ni mo sun
Kundi ni mo ji
Awon ni won se ifa fun Orunmila
Baba nlo si ilu awon apani je
Won ni baba ilu awon apani le n lo yi
Orunmila ni kin ni won fi n pa ara won nibe
Won ni won n fi Oso pa ni
Won n fi Aje pa ni
Won n fi Aasan pa ni
Won n fi Ase pa ni
Won fi Ifa pa ni
Won n fi Woli pa ni
Won n fi Alfa pa ni
Be ni won n pe eniyan pa lori Esu
Orunmila ni gbogbo awon ti won sise ibi yi
Sebi bibi la bi won
Won ni bibi la bi won
Orunmila ni sebi igbati a bi won
Sebi won bi Ibi mo won
Won ni be ni, won bi ibi mo won
Gbogbo eni won ba bi Ibi mo to ro ibi simi
Ibi ni yio pa won
Won ni baba bawo leyin se mo
O ni egbesi ni yio ma sin won lo sorun
Won ni baba nibo ni eyin ati awon omo yin yio wa
O atare ni yio ma tari won lo sode orun
O ni sebi Iku Babalawo la gbo, enikan kii gbo iku Ifa
Emi ni mo gburo iku awon ota mi, won o ni gbo iku mi
Odi-meji ni o ba mi di Ibi won mo won laya.

Aboru, Aboye, Abo-sise!

2 Likes

Re: .. by Ifankaleluya: 3:43pm On May 18, 2016
Lofinda Awure

Erupe oju-ona ti ese n to dada, ewe-sawerepepe, ati ewe-ominsinminsin mejeji, ao lo kunna dada, ao da sinu lofinda
Lo ba tan!

Aboru, Aboye, Abo-sise!

3 Likes

Re: .. by Ifankaleluya: 3:43pm On May 18, 2016
Ose Eyonu Awn Agba

Imi-ewure, Imi-agutan, Ewe-orijin pupo, ewe-eko ti won sonu

Ao gun papo mo ose, ao ko sinu igba onikoko,

Ao te ni eji-ogbe, ao ma fi we.

Aboru, Aboye, Abo-sise!

4 Likes

Re: .. by Ifankaleluya: 4:02pm On May 18, 2016
zenith329:
Ekaro gbogbo ile, e jo, ki lo je ekiri eran, oronro malu ati onlo adie?

Ekiri-eran malu ni, onlo adire yen, a le pe ni Ajesi Adire, o ma n saba wa ni ibi aya adire, e bere oronro malu lowo awon alapata ko soro lati ri rara.

1 Like

Re: .. by dominicson: 10:48pm On May 18, 2016
Ifa sings in Iworiturupon:
Oyigiyigi ota omi
Oyigiyigi ota omi
Iwori tutu n ko ku mo
Oyigiyigi ota omi

Ela boru, Ela boye, Ela bosise!

1 Like

Re: .. by orunmila76(m): 6:53pm On May 19, 2016
Eyonu to daju.

Erupe ona oja die,Erupe ona church,Erupe ona mosque,Erupe oritameta,Ose aipo,atare aija,. Aa gun gbogbo re papo pelu omi agbon,aa ko sinu Ike fun fun olomori.
LILO; waa maa we ose naa pelu omi gbigbona(Hot water) ni Ale monday ati Thursday .
Ofo re; oju tii nsun losan, oju to nsun loru,e waa maa pe Temi lagbaja omo lagbaja nire.

Tested trusted and certain

1 Like

Re: .. by orunmila76(m): 6:59pm On May 19, 2016
Ayajo Eyonu to daju fun OJO monday.

Ogundabede awo ile olokun,lo ni ki gbogbo Aiye maa fi oju ire womi loni
Afena lobirin nfena
Amomo ni eniyan moro
Tomode tagba lo mo Afin loja
A kii tori obo ka yobe
Nire nire la nsoro atare
Eniti o dami mo ati eniti ko dami mo e maa sooro mi nire loni.
Pelu atare meje lenu

1 Like

Re: .. by Morounofolu: 2:10pm On May 21, 2016
E jowo baba, kini a lee lo fun nkan omokunrin to kere ju ojo ori lo ?
Ifankaleluya:
Ifa ni;

Kundi ni mo sun

Kundi ni mo ji

Awon ni won se ifa fun Orunmila

Baba nlo si ilu awon apani je

Won ni baba ilu awon apani le n lo yi

Orunmila ni kin ni won fi n pa ara won nibe

Won ni won n fi Oso pa ni

Won n fi Aje pa ni

Won n fi Aasan pa ni

Won n fi Ase pa ni

Won fi Ifa pa ni

Won n fi Woli pa ni

Won n fi Alfa pa ni

Be ni won n pe eniyan pa lori Esu

Orunmila ni gbogbo awon ti won sise ibi yi

Sebi bibi la bi won

Won ni bibi la bi won

Orunmila ni sebi igbati a bi won

Sebi won bi Ibi mo won

Won ni be ni, won bi ibi mo won

Gbogbo eni won ba bi Ibi mo to ro ibi simi

Ibi ni yio pa won

Won ni baba bawo leyin se mo

O ni egbesi ni yio ma sin won lo sorun

Won ni baba nibo ni eyin ati awon omo yin yio wa

O atare ni yio ma tari won lo sode orun

O ni sebi Iku Babalawo la gbo, enikan kii gbo iku Ifa

Emi ni mo gburo iku awon ota mi, won o ni gbo iku mi

Odi-meji ni o ba mi di Ibi won mo won laya.

Aboru, Aboye, Abo-sise!
Re: .. by jophins(m): 5:09am On May 22, 2016
ifankaleluyah eku ojo meta sir email mi no jophinsinluv@yahoo.com e jowo sir e kan so mi.
Re: .. by jophins(m): 5:15am On May 22, 2016
Ifankaleluya:
AWURE OJA TITA ATI FUN ENI TI WA ISE
Ori--Langba, Oyin die, Omi-Omu, Ewe sawerepepe, Ewe-
afomo ajade, ao gun won po mo ose, ao ko sinu igba-
olomori, omi-omu yen ni ao fi po ose yen oo.
Ao te ose yen ni eji-ogbe, ao ma fi we.
Aboru, Aboye, Abo-sise!
e jowo sir shey omi inu amu(muld) pot ti awon baba wan lon ni tabi omi yen yato

1 Like

Re: .. by bernarddada2010: 11:26am On May 22, 2016
Kini oruko miran fun 'AFOMO AJADE'?
Re: .. by Zalam5: 2:39pm On May 22, 2016
Ifankaleluya:
EBE AWON AGBA

A o lo epo-obo, a da senu ona,a po mo ose, a wa fi iyo fon inu-isasun tuntun kekere kan,ao gbe ose yen sinu re, ao wa fi odidi igbin kan bo inu ose yen. O di wiwe leyin ojo keje ti a se ose yi.

Abori, Aboye, Abo-sise!
Alaye tie se lori ogun yii ko BA arawon mun rarara,e gbiyonju kir tun alaye yi se leekan sii@ifa kaleluya!!!

Re: .. by skamoh74: 4:17pm On May 22, 2016
baba wa Ifankaleluya Eledua a jeki e pe fun. Apada saburu ko ni bayin tomotomo.
e jowo mofe Ogun ERO fun gbogbo asasi.
e seun
stay blessed sir
Re: .. by Ifankaleluya: 7:07pm On May 22, 2016
Zalam5:

Alaye tie se lori ogun yii ko BA arawon mun rarara,e gbiyonju kir tun alaye yi se leekan sii@ifa kaleluya!!!
Alaye tie se lori ogun yii ko BA arawon mun rarara,e gbiyonju kir tun alaye yi se leekan sii@ifa kaleluya!!!

Alaye tie se lori ogun yii ko BA arawon mun rarara,e gbiyonju kir tun alaye yi se leekan sii@ifa kaleluya!!!

Oponu ni e ee.....boya ko lo bere iyoku lodo baba awo re!!!

Ti won ba ran e nise kiise iru mi wa ma je iru ise yen fun ti o ko ba fe ki awon eeyan e fi oju sunkun eee!
Se alaye yoku to ku lodo re babalawo awn oku, kin ni ifa ori-keji din ni adota ese keji so??
Re: .. by Ifankaleluya: 7:09pm On May 22, 2016
skamoh74:
baba wa Ifankaleluya Eledua a jeki e pe fun. Apada saburu ko ni bayin tomotomo.
e jowo mofe Ogun ERO fun gbogbo asasi.
e seun
stay blessed sir
Ero-ifa ni e le se, sugbon esu re ti e o ma bo ni o dara ju!

1 Like

Re: .. by Ifankaleluya: 7:12pm On May 22, 2016
[quote author=bernarddada2010 post=45858133]Kini oruko miran fun 'AFOMO AJADE'?[/quote

E gbiyanju ki e bere re lowo awon elewe-omo, won da month dara-dara!
Re: .. by jophins(m): 11:28pm On May 22, 2016
e Jooor sir omi omu koye mi AWURE OJA TITA ATI FUN ENI TI WA ISE
Ori--Langba, Oyin die, Omi-Omu, Ewe sawerepepe, Ewe-
afomo ajade, ao gun won po mo ose, ao ko sinu igba-
olomori, omi-omu yen ni ao fi po ose yen oo.
Ao te ose yen ni eji-ogbe, ao ma fi we.
Aboru, Aboye, Abo-sise![/quote]
Re: .. by skamoh74: 7:21am On May 23, 2016
Ifankaleluya:

Ero-ifa ni e le se, sugbon esu re ti e o ma bo ni o dara ju!

e seun sir. may live long sir in peace and prosperity
Re: .. by dominicson: 5:36pm On May 23, 2016
Ifa, in Oturagbe, sings:
Kini mo mu m'ase ida
Oyin mo mu m'ase ida o oyin
Agbe s'awo o gb'aso dudu
Oyin mo mu m'ase ida o oyin
Aluko s'awo o gb'aso osu
Oyin mo mu m'ase ida o Oyin
Ori s'awo o gb'ade
Oyin mo mu m'ase ida o Oyin
Orun s'awo o gb'ejigbara okun
Oyin mo mu m'ase ida o Oyin
Atewo s'awo o gb'eru
Oyin mo mu m'ase ida o Oyin
Idi s'awo o gb'aso gb'owo
Oyin mo mu m'ase ida o Oyin
Alade oloja
Oyin mo mu m'ase ida o Oyin
O n se mi sese
Oyin mo mu m'ase ida o Oyin
O n se mi sese
Oyin mo mu m'ase ida o Oyin.

Ela boru, Ela boye, Ela bosise.

Re: .. by jophins(m): 11:35pm On May 23, 2016
[quote author=Ifankaleluya post=45740370]Lofinda Awure

Erupe oju-ona ti ese n to dada, ewe-sawerepepe, ati ewe-ominsinminsin mejeji, ao lo kunna dada, ao da sinu lofinda.

Iru lofinda WO lale lo tabi eyi keyi,bi St Michael,grace 777

(1) (2) (3) ... (74) (75) (76) (77) (78) (79) (80) ... (99) (Reply)

(Go Up)

Sections: politics (1) business autos (1) jobs (1) career education (1) romance computers phones travel sports fashion health
religion celebs tv-movies music-radio literature webmasters programming techmarket

Links: (1) (2) (3) (4) (5) (6) (7) (8) (9) (10)

Nairaland - Copyright © 2005 - 2024 Oluwaseun Osewa. All rights reserved. See How To Advertise. 47
Disclaimer: Every Nairaland member is solely responsible for anything that he/she posts or uploads on Nairaland.