Welcome, Guest: Register On Nairaland / LOGIN! / Trending / Recent / NewStats: 3,152,747 members, 7,817,063 topics. Date: Saturday, 04 May 2024 at 02:29 AM |
Nairaland Forum / Nairaland / General / Religion / Share Your Best Hymns (41841 Views)
Post Your Favourite Christian Hymns / I Need Deeper Life Bible -gospel Hymns CD / Post Yoruba Christian Hymns Here (2) (3) (4)
(1) (2) (3) ... (10) (11) (12) (13) (Reply) (Go Down)
Re: Share Your Best Hymns by obasolape(f): 4:26am On Mar 24 |
Ma gesin lo l’olanla Re; Gbo ! gbobg’ aiye nke “Hosanna”; Olugbala, ma lo pele Lori im’ ope at’ aso. Ma gesin lo l’olanla Re; Ma f’ irele gesin lo ku: Kristi, ’segun Re bere na, Lori ese ati iku. Ma gesin lo l’olanla Re; Ogun angeli lat’ orun Nf’iyanu pelu ikanu Wo ebo to sunmole yi. Ma gesin lo l’olanla Re; Ija ikehin na de tan; Baba, lor’ ite Re lorun, Nreti ayanfe Omo Re. Ma gesin lo l’olanla Re; Ma f’irele gesin lo ku: F’ara da irora f’eda: Lehin na, nde, k’o ma joba. Amin. |
Re: Share Your Best Hymns by obasolape(f): 4:28am On Mar 24 |
Hosanna s'omo Dafidi Hosanna, e korin Olubukun l'Eniti mbo L'oruko Oluwa. Hosanna s'omo Dafidi L'egbe Angeli nke Gbogbo eda jumo gberin Hosanna s'Oba wa Hosanna awon Heberu Ja imo ope s'ona Hosanna e mu ebun wa Fi tun ona Re se. T'agba t'ewe nke Hosanna Ki ijiya Re to de Loni a si nko Hosanna B'O ti njoba loke B'O ti gba'yin won nigbanaa Jo gba ebe wa yi Lorun k'a le ba Angeli korin Hosanna s'Oba wa. Amin. Happy Palm Sunday. |
Re: Share Your Best Hymns by obasolape(f): 4:36am On Mar 24 |
Oluwa gunwa lori’te Akobi awon t’o sun On nikan l’Onigbeja wa To ngbe wa leke ota Aleluya, Aleluya Jesu li Onje Iye. Awa njuba, awa nsape Kabiyesi Oba wa, Busi igbagbo wa loni K’a le tubo mo O si, Aleluya, Aleluya Iwo njoba larin wa. Bi a ko tile ri O Bi t’awon ti igbani, A wa at’awon Angeli Nyin iru-omo Jese Aleluya, Aleluya Tewo gba ijosin wa. Od’agutan t’a fi rubo Ti s’etutu f’ese wa Ko tun si ebo miran mo Eje Re ti to fun wa. Aleluya, Aleluya Eje na lo we wa mo. O nfi onje iye bo wa Manna didun lat’orun K’orun at’aye korin na Orin ‘yin s’Od’agutan. Aleluya, Aleluya O jinde, O si goke Amin. |
Re: Share Your Best Hymns by obasolape(f): 6:28am On Mar 30 |
Tune name: #st. Agnes m:m:m:r:-m:f:-t:d:-:- s:s:s:m:-r:r:-:- f:f:m:r:-d:t:-l:s:-:- s:l:d:m:-r:d:-:- 1. Okan mi, sunmo ’te anu, Nibi Jesu ngb’ ebe, F’ irele wole l’ese Re, ’Wo ko le gbe nibe. 2. Ileri Re, ni ebe mi, Eyi ni mo mu wa; Iwo npe okan t’ eru npa, Bi emi, Oluwa. 3. Eru ese wo mi l’orun, Esu nse mi n’ ise; Ogun l’ode, eru ninu, Mo wa isimi mi. 4. Se Apata at’ Asa mi, Ki nfi O se abo; Ki ndoju ti Olufisun, Kin so pe Kristi ku. 5. Ife iyanu ! Iwo ku, Iwo ru itiju; Ki elese b’ iru emi, Le be l’ oruko Re. Amin. |
Re: Share Your Best Hymns by obasolape(f): 3:27am On Apr 07 |
Alabukun n’nu Jesu Ni awon om’ Olorun, Ti a fi eje Re ra Lat’ inu iku s’iye; Egbe: A ba je ka wa mo won, L’aiye yi, ati l’orun. Awon ti a da l’are Nipa ore-ofe Re; A we gbogbo ese won, Nwon o bo l’ojo ’dajo; Egbe: A ba je ka wa... Nwon ns’eso ore-ofe; Ninu ise ododo, Irira l’ese si won, Or’ Olorun ngbe ’nu won; Egbe: A ba je ka wa... Nipa ej’ Odagutan, Nwon mba Olorun kegbe, Pelu Ola-nla Jesu, A wo won l’aso ogo; Egbe: A ba je ka wa... Amin. |
Re: Share Your Best Hymns by obasolape(f): 12:07pm On Apr 11 |
1. OLORUN aiye mi Emi ni yo si O Ore Re l'o da mi L'o da mi si sibe Ayajo ibi mi tun de Ngo sure f’ojo t’a bi mi. 2. Ni gbogbo ojo mi Ki nwa laye fun O Ki gbogbo emi mi F‘ope, iyin fun O Gbogbo ini at’iwa mi Y’o yin Eleda mi logo. 3. Gbogbo pa emi mi Y’o je Tire nikan Gbogbo akoko mi Mo ya soto fun O Jo tun mi bi l'aworan Re Ngo si ma yin O titi aiye. 4. Mo nfe se ife Re B’angel‘ ti nse l’orun Ki ndatunbi n'nu Krist’ Ki nri ‘dariji gba Mo nfe mu ‘fe pipe Re se K'ife Re ya mi si Mimo. 5. Gba ‘se na ba pari L’agbara igbagbo Tewogb’ ayanfe Re Li akoko iku Pe mi sodo bi ti Mose Gbe emi mi s‘afefe 're. Amin |
Re: Share Your Best Hymns by obasolape(f): 1:06am On Apr 12 |
Omode, e sunm’ Olorun, Pelu irele at’ eru; Ki ekun gbogbo wole fun Olugbala at’ Ore wa. Oluwa, je k’ anu Re nla, Mu wa kun fun ope si O; Ati b’ a ti nrin lo l’ aiye, K’ a ma ri opo anu gba. Oluwa! m’ ero buburu, Jinna rere si okan wa; L’ ojojumo fun wa l’ ogbon, Lati yan ona toro ni. Igba aisan, at’ ilera Igba aini tabi oro; Ati l’ akoko iku wa, Fi agbara Tire gba wa. Amin. |
Re: Share Your Best Hymns by Sapasenator: 3:00am On Apr 12 |
Nimota, Nomota, oo ro e sun mi! Nimota, Nimota, oo ro e sun mi! Nigba ti a jo sun lo katan le mi.... Nimota, Nimota, ooooro e sun mi! |
Re: Share Your Best Hymns by obasolape(f): 7:25am On Apr 30 |
1. Iyin f'Eni mimo julo L'oke ati ni 'le; Oro Re gbogbo je 'yanu, Gbogb' ona Re daju. 2. Ogbon Olorun ti po to Gbat' eniyan subu; Adam' keji wa s'oju 'ja . Ati lati gbala. 3. Ogbon ife! p'eran ara T'o gbe Adam' subu Tun b'ota ja ija otun K'o ja, k'o si s'egun. 4. Ati p'ebun t'o j' or-ofe So ara di otun Olorun Papa tikare J'Olorun ninu wa. 5. Ife 'yanu! ti Eni ti O pa ota en'yan Ninu awo awa en'yan Je irora F'en'yan. 6. Nikoko, ninu ogba ni Ati l'ori igi T'o si ko wa lati jiya T'o ko wa lati ku. 7. Iyin f'Eni mimo julo L'oke ati nile Oro Re gbogbo je 'yanu Gbogb' ona Re daju. Amin |
(1) (2) (3) ... (10) (11) (12) (13) (Reply)
Chris Oyakhilome: Black Is Evil, Africans Must Stop Saying They Are Blacks / Prophet T O Obadare Is Dead / Bishop Daniel Obinim Trying To Fly Like A Bird On Air (Video)
(Go Up)
Sections: politics (1) business autos (1) jobs (1) career education (1) romance computers phones travel sports fashion health religion celebs tv-movies music-radio literature webmasters programming techmarket Links: (1) (2) (3) (4) (5) (6) (7) (8) (9) (10) Nairaland - Copyright © 2005 - 2024 Oluwaseun Osewa. All rights reserved. See How To Advertise. 22 |