Welcome, Guest: Register On Nairaland / LOGIN! / Trending / Recent / New
Stats: 3,150,849 members, 7,810,273 topics. Date: Saturday, 27 April 2024 at 04:17 AM

.. - Culture (83) - Nairaland

Nairaland Forum / Nairaland / General / Culture / .. (1827430 Views)

"We The Ewe People Of Ghana Are The Same As Yoruba"- Yewe2011.ewe Guy From Ghana / How Do U Spell (weed) In Yoruba, Is It Igbo? Or Egbo? / Yoruba Idioms: Owe Yoruba, Itunmo Re Ati Lilo Re (2) (3) (4)

(1) (2) (3) ... (80) (81) (82) (83) (84) (85) (86) ... (99) (Reply) (Go Down)

Re: .. by emtar(m): 9:28pm On Aug 02, 2016
zenith329:

E jo sir, e ba wa te odu obara ika si ta
baba ejowo se obi meji alawe merin merin ni a ma pa si obara-ika.
Re: .. by dominicson: 8:48am On Aug 03, 2016
Imule-Ebe-Eyonu(Owonrinmiki)


Ako Okete aye kan, eepo erun(eepo obo), imi ojo, odidi atare meta, a o jo, a o te ni odu oworinmiki, a o ro itan/ifa/psalm re si, a o ma fi ahon la ninu awo taasa lale ki a to sun ni ihoho pelu epo pupa.


Itan/psalm/Ofo

Orunmila lo ji ni owuro yii, lo gba ojude awon aje lo. Nigbati o de be, o joko, o da ifa owonrinmiki nitori awon alaboyun ti won de mole lori ikunle ti won kole bi omo, tori ki won o le bi omo. O tun da ifa owonrinmiki nitori agan ti won ko loyun, ki won o le ti owo ala bo osun, ki won o ba le di olomo laye. Orunmila tun da ifa owonrinmiki nitori awon okunrin iduro ti won n rin kiri ti won ko gbadun ara won, ki won o le gbadun ara won. Orunmila tun da ifa oworinmiki nitori okunrin idubule, ti won kole sun, ti won ko le wo, ti won ko le je, ti won ko le mu, ki won ki o le rije-rimu. Orunmila tun da ifa owonrinmiki nitori awon alaseiri, ti won n fi osan(noon) won n sise, ti won n fi oru(night) won n sise, ti won ko ni akojo. Nibe ni awon iyami aje ba n bi Orunmila, won ni iwo orunmila, se o mo wipe agan ti ko ni oyun, se o mo wipe ounje wa ni? Orunmila ni oun mo, a ma oun wa sipe fun won ni. Se iwo ko mo wipe alaboyun ti o de ori ikunle ti ko le bi mo, se o mo pe ounje wa ni? Orunmila ni wipe oun mo, a ma mo wa sipe fun won ni. Se iwo ko mo wipe awon okunrin iduro ti won n rin kiri, ti won ko gbadun aye won, se iwo ko mo wipe ounje wa ni won ni? Orunmila ni wipe oun mo, a ma mo wa sipe fun won ni. Se iwo o mo wipe okunrin idubule ti won ko le sun, ti won ko le wo, ti won ko le je, ti won ko si le mu, se iwo ko mo wipe ounje wa ni gbogbo won ni? Orunmila ni wipe oun mo, a ma mo wa sipe fun won ni. Se iwo ko mo wipe awon alaseiri ti won fi osan won sise, ti won n fi oru won sise, ti won ko ri je, ti won ko ri mu, ti won ko ri na, ti won ko ri lo, bee won ko ni akojo, se iwo ko mo wipe ounje wa ni? Orunmila ni wipe oun mo, a ma mo wa sipe fun won ni. Awon iyami ni gbogbo ipe ti Orunmila ba ri ko se, awon ko ni gba ipe naa. Orunmila ni e ba ko ti e ko ba gba ipe, oun yoo p'itan fun yin nisinsinyi. Won ni gbogbo itan ti Orunmila ba mo ko ma pa. Orunmila ni se bi Olupowo ni yeye eyin aje, se bi eyin ni Owewelakasa, se bi eyin naa ni Arinhohojedun. Won ki orunmila dakun(please) ki o duro ni be yen. Orunmila ni ki e ranti adehun ti a jo se ni ijokinni ana, ki e ranti pe aje kii je imi ojo, won ni enikan ki i di ojo lowo koma yo. Se e ranti wipe aje kii roro ki o je eepo eerun. Oro ti okete ba ba ile so ni ile n gbo. Nibe ni awon iyami aje ni awon ti gbo, awon si ti gba. Won ni ti alaboyun ba lo ninu ogun yii, yoo bi tibi-tire. Agan ti o ba lo nibe yoo ti owo ala bo osun, yoo si bi ni alaafia. Okunrin iduro ti o ba lo nibe yoo ri iwosan. Okunrin idubule ti o ba lo nibe yoo ni alaafia. Alaaseiri ti o ba lo nibe, yoo ri se tosan-toru. Ona ire gbogbo yoo si ma a la fun lati odo gbogbo omo araye patapata. Ona ire gbogbo yoo ma la fun emi Lagbaja omo Lamorin naa lati odo gbogbo omo araye patapata. (A o se adura si).

2 Likes

Re: .. by AbroadBabe(f): 12:40pm On Aug 03, 2016
Bosville:
baba e tun no pe fun wa....Ejowo iru ogun wo la ma lo fun eniti o n mu amuju oti(ogogoro)...Eseun
Sir, good afternoon, I need your help now nd I know you can can do it for me.
with due respect Ma, the 2016 Mr nairaland election is ongoing, nd I need you to please help us with the dream of winning the elections.

the voting thread is

https://www.nairaland.com/3265483/mr-nairaland-contest-2016-semi-final

just type" I vote falconey Cc: NLjega"



the voting continues tomorrow and the grand finale will be held on Wednesday.

I am trusting you for this sir
Re: .. by olorymusty: 8:41am On Aug 04, 2016
moki gbogbo ojogbon lori ikani yi. mogba ladura wipe ogbon, imon ati oye wa konidi ibaje amin.imoran mi ni wipe nu abale gbiyanju lati se awon ogun wonyi jade ni (pdf) file jobadara pupoju. olohun abukun oore ati aanu gbogbo wa. amin
Re: .. by zenith329: 10:01am On Aug 04, 2016
E ka aro gbogbo ile. E jo, e ba wa te odu owonrinmiki sita.
Re: .. by Ousmaf(m): 2:29pm On Aug 04, 2016
Ifankaleluya:
ATOSI

Imi-orun, etu-ibon, a lo po, ao da sinu oyin igan, ao ma fi mu eko gbigbona
eku ise takuntakun baba Ifankaleluya, keepe fun wa lase Edumare, ejoo baba eba wa te odu Ologbon meji sita, ko ni tan nibi te ti mu ooo pelu ase Edumare

2 Likes

Re: .. by jentusoul: 7:15pm On Aug 04, 2016
Hmmmnn eku ise @baba domonicson. Olodumare yoo ma bukun yin o ase. Ejowo bawo ni a se ma te odu owonrinmiki
Re: .. by jentusoul: 7:21pm On Aug 04, 2016
BABA IFANKALELUYA ESEUN GAN MOTIRI NUMBER YIN LORI EMAIL ME MOSEBA FUNYINOO, DOMINICSON IBARE OOO
Re: .. by ogboliagba: 2:28pm On Aug 05, 2016
@ifankaleluya, number mi niyi ooo, baba ejowo e Funmi ni ise naa tan 08066161217. Aboru boye oo.
Re: .. by ogboliagba: 2:58pm On Aug 05, 2016
baba ejowo e fun mi ni agadagodo yi pe, isese a gbewa oooo ooo number miree 08066161217. tabi olugbogiy@yahoo.com.
Re: .. by Nudewhenu31(m): 1:26pm On Aug 06, 2016
Please baba, add me to Isese Lagba whatsap group 07030420960, adupe sir
Re: .. by OmoOsanyin: 2:30pm On Aug 06, 2016
ORUKA ALUWO

Aworoko Etu,
Adigbonanku 7,
Ewe ...............
Efo gbure,
Ewe Aluko,
Ewe ...............
Obuko toyo,

Ao .......ao re si ako ajapa
Ao ko ni ojo 7.


Ero Re:
Awo etu, ewe ........, ori, Aolopo.
Ao fi pawo....


08092320195

Alaafia
Re: .. by OmoOsanyin: 2:42pm On Aug 06, 2016
OOGUN ASUNKUN

Egbo Igba,
Isu alubosa,
Oko ............,
Abere...........
Ao ko si owu otutu,
Ao pa awori won,
Ao ro eje re si,
Ao k o ni ojo 7,
...... ni ao fi ko si apo

Ao mafi gun enia lese tabi ito.

Odaju!


08092320195
Re: .. by OmoOsanyin: 2:47pm On Aug 06, 2016
KI OBINRIN MALE KO ENIA SILE

Iyimi yimi,
Ewe ...........
Iye igun,
Eyo Atare 7,

Aolopo
Ao fi sin gbere meta si iwaju ori.


Confirm!

1 Like

Re: .. by mondaylyno(m): 2:47pm On Aug 06, 2016
Add me to ur whatsapp group 09038148236
Re: .. by OmoOsanyin: 2:51pm On Aug 06, 2016
BI OMODE BA NRU

Egbo peregun
Epo ose
Kerewu
Eru 9

Ao da ni agbo tutu.
Ao mafi we fun omo na.

Ko gbodo kan lori o.


Opari.
Re: .. by dominicson: 3:53pm On Aug 06, 2016
jentusoul:
Hmmmnn eku ise @baba domonicson. Olodumare yoo ma bukun yin o ase. Ejowo bawo ni a se ma te odu owonrinmiki



Oworinmiki/owonrinirete/oworin-irete


Two-two-one-one at the first side, and one-one-two-one at the second side. But remember, odu ifa, just like arabic, starts from the right side.


So, two-two-one-one is at the right side, the first ese. And then one-one-two-one at the left side. Ese kan owonrin and ese kan irete is Owonrinmiki or Owonrinnirete.

Regards.

2 Likes

Re: .. by nikky2012(f): 7:44pm On Aug 06, 2016
Aboru boye o ejowo kini eniyon lelo Fun idi omode tounyo
Re: .. by zenith329: 8:17pm On Aug 06, 2016
Eka ale, gbogbo ile. E jo oruko miran wo ni ewe kasan je?
Re: .. by OmoOsanyin: 9:30pm On Aug 06, 2016
dominicson:




Oworinmiki/owonrinirete/oworin-irete


Two-two-one-one at the first side, and one-one-two-one at the second side. But remember, odu ifa, just like arabic, starts from the right side.


So, two-two-one-one is at the right side, the first ese. And then one-one-two-one at the left side. Ese kan owonrin and ese kan irete is Owonrinmiki or Owonrinnirete.

Regards.

Hmmm,
Won't It be easier and clearer for him if done with strokes like to tefa?
Re: .. by jentusoul: 9:57pm On Aug 06, 2016
@Baba domonicson ejowo e funmi ni number ati email yin
Re: .. by jentusoul: 11:45pm On Aug 06, 2016
Baba domonicson number mi niyi please add me on isese lagba, 08074522156
Re: .. by basanbo6: 6:15pm On Aug 08, 2016
@healthfirst.elo lalee ri iwe yi ra.
Re: .. by basanbo6: 6:39pm On Aug 08, 2016
Opo a won ole, onijibi lowa Lori ikan yi tiwon perawon Ni ologun, sugbon ogbon ati lu jibiti Ni. Eniti o da ikani yisile oni kafi asiri todaju fi ran arawa lowo Ni.ewoni Ogun tiko pe tikoni itumo,elomi yoni kepe ohun fun asiri oto ni ohun ti won o man so. To bani Ogun to fe ta, sowipe o fe ta,ma tan awon eniyan.eberu olohun toda ewe ati egbo fun lilo omo araye.Iwo tosepe onisegun nio polowo oja re,Alfa nio Iwo na polowo,ewo Ni iro, Ogun tikoo da elomi loju yoni ohun fe ta seyin Leda ewe ni.
Re: .. by degreatking: 6:07am On Aug 10, 2016
Oruko Mi Ni Degreatking. E Jowo Gbogbo Ile, Emi Sese Fe Darapo Mo Eyin Agba Ni. E Jowo, E Gba Mi Tokantara.

1 Like

Re: .. by bababdul(m): 4:44pm On Aug 10, 2016
Eku ISE O........ Edakun AYA man tami mosi fe ke ranmilowo lori ogun Aya Tita. Eseun
Re: .. by dominicson: 10:42am On Aug 11, 2016
Arobi/Aseta/hunt-the-hunters

Ori aparo mokanla, orogbo mokanla, obi ipa oloju-merin mokanla, obi ifin olojumerin mokanla. Atare mokanla. A o jo papo. A o te ejiogbe si. A o ro sinu seere. Ko gbodo kan'le mo. A o ma fi fo eko tutu mu, a si tun le fi omi tutu lo.


Psalm:
Egun ni ti Onimulu, 3ce. Igede ni ti Ikamesan, 3ce. Ekaebiti lo ni ase lenu. Oro-meji, iwo lo lo difa fun won lode-orun. Nigbati won gbe ifa de ile aye tan, won wa fe fi ba ti Oro-meji je. Won ni Oro-meji ko mo o se mo o. Oro-meji ni ti o ba se bi ise temi ni won ba n wi, o ni egun Onimulu nii pa Onimulu, igede enu Ikamesan nii se iku pa Ikamesan, ase ti n be lenu Ekaebiti naa ni se iku pa Ekaebiti. Gbogbo eniti nba pe ori mi nibi, iwo(do mi) ni ki o lo re wo ile oluwa re. Gbogbo otakota, enikeni, eyankeyan, adahunse, onisegun, oso, aje, ni n ro ibi ro mi, iwo ni ki o lo re wo ile oluwa re. Obi ni ki won fi bi oran si oluwa re lorun. Orogbo ni ki won fi gbo oju oluwa re mo le. Atare ni ki won fi ta oluwa re latapa. Ota po lorun mi yeeye. Egbesi oko, ee si ba mi s'ikan kuro lorun mi; e s'ikan kuro lorun mi. Igbo onigbo ni aparo nku si o. Gbogbo eyin ota mi ni ki e ku iku oro, iku aimodi, iku esin. Oro ti e o mowo, ti e o mese ni ki won o pa yin le lori. Ki n segun ota, ki n reyin odi.

4 Likes

Re: .. by horlakunmy: 11:11am On Aug 13, 2016
ejowo,nje lapa pupa ni abi funfun.
Re: .. by horlakunmy: 11:21am On Aug 13, 2016
ejowo,mo need Ogun obe(knife) todaju,akiyesi,koise okigbe ada ni Monso oo,nitoripe opolopo okigbe ada koisise fun obe,nitorina ejowo Ogun obe Toni onde tabi ikunpa,tabi ikobere todaju ,edakun eranmi lowo.
Re: .. by Wolad(m): 12:34am On Aug 15, 2016
Ejowo isu wo ni wo'n pe ni "isu efuru"? Ati pelu.. Eiye wo ni "Eiye Atata" Isese a gbewa o!
Re: .. by Wolad(m): 12:47am On Aug 15, 2016
horlakunmy:
ejowo,mo need Ogun obe(knife) todaju,akiyesi,koise okigbe ada ni Monso oo,nitoripe opolopo okigbe ada koisise fun obe,nitorina ejowo Ogun obe Toni onde tabi ikunpa,tabi ikobere todaju ,edakun eranmi lowo.

E gbinyanju eleyi wo.

Suku owu(Koro owu) , Suku agbado, Ipe Aika, odidi atare kan, Jijo papo, fifoko mu, tabi Lila.

(1) (2) (3) ... (80) (81) (82) (83) (84) (85) (86) ... (99) (Reply)

(Go Up)

Sections: politics (1) business autos (1) jobs (1) career education (1) romance computers phones travel sports fashion health
religion celebs tv-movies music-radio literature webmasters programming techmarket

Links: (1) (2) (3) (4) (5) (6) (7) (8) (9) (10)

Nairaland - Copyright © 2005 - 2024 Oluwaseun Osewa. All rights reserved. See How To Advertise. 50
Disclaimer: Every Nairaland member is solely responsible for anything that he/she posts or uploads on Nairaland.