Welcome, Guest: Register On Nairaland / LOGIN! / Trending / Recent / New
Stats: 3,160,688 members, 7,844,260 topics. Date: Wednesday, 29 May 2024 at 05:20 PM

Ifankaleluya's Posts

Nairaland Forum / Ifankaleluya's Profile / Ifankaleluya's Posts

(1) (2) (3) (4) (5) (6) (7) (8) (9) (10) (of 10 pages)

Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 7:58pm On Jun 21, 2016
zenith329:

E jo sir, e ba wa te irete meta si ta

Eyi ni Irete-meta

! ! !

! ! !

!! !! !!

! ! !


Aboru, Aboye, Abosise.

1 Like

Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 5:06pm On Jun 18, 2016
IFA TI A MA FI N SI IPA BURUKU KURO LARA ENIYAN ONI IRETE-META




Ao lo efun loto, osun loto ati edu loto.

Ao wa te ni irete-meta loju opan-kan na

Ao wa ro itan-ifa re si

Ao wa po mo ose. O di wiwe lale-lale

Ifa re; Aku-mo-nisepe loruko ta pe ina

Agbi-mo-letu loruko tape omi

Ara-mo-sindin loruko ta pe ori eni

Nijo ti eyin meteta n tode orun bo wa ile-aye

E ni, eniti ori re ba buru

Tori re ko sunwon

Ti ko ni aje

Ti ko ni ire gbogbo

E ni e o ma ba bi gbogbo e danu

O wa to gege, ke wa bi gbogbo ibi ara lagbaja omo lagbaja danu lati oni lo

Efun ni biwa osun je

Osun ni biwa efun je

Atefun-atosun, edu ni biwa won je

E wa ba gbogbo ogun buruku ti n be lara lagbaja omo lagbaja je lati oni lo

Irete-meta ni e fi ba te gbogbo olubi ara re mole lati oni lo

Ela-boru, Ela-boye, Ela-bosise!

3 Likes

Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 8:35pm On Jun 07, 2016
Tevez83839:
Edakun eranmilowo baba Ifakanlelluyah tabi healthfirst tabi kadunasouth....artist nimi pelu paintersugbon ise daagun funmi .kosise,kosowo eramilowo ,mo fe ma gba contract nlla nla .ise kekeere owo nla,ki emi naa je eyan lawujo ati olowo laarin egbe painter ati ore ilu mi.toori Oorun ni mo ma n sunkale ni shop mi .edakun e seeto awure tabi osole tutu koda kii ba se eyi ti maa rimole ni shop mi .kin sati lowo lowo ,kin jeeyan laipe edakun08162736520

Ore wa, mo le ran e lowo. Sugbon kosi nkan ti a le se ti e ko ba ni owo lowo, ati wipe ifa ti a ma fi n da oja sile, ile-iwe, ile-kewu, ile-epo ati be be lo ni e le ri mo shop yin yen ti e o si yin olohun logo laipe lai jina.

Ti a ba fe se ifa yen....eroja re po die

Lara re ni eiye-logeesa meji, eiye kowe meji, eiye olongo meji, eku-egungun ti o n jade ni every year, esun olubongaga, iyepe oja nla to wa ni ilu nla merin, ati be be lo. E ko le da se.

Awon miran na wa, ti e ba ri odidi abo elede, ewe-kunkun, egbo-opoto, ewe adurosusu ti be be lo.
Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 11:13pm On Jun 06, 2016
wale259:
Ase bami Agbalagba!

Thank you very much for the gift you sent this morning bro, GOD bless you real good. Amen!

E seun modupe, owo yin o ni kan isale apo, e o ni wa owo ti

Nile aye yin.

Ifa ni;

Ajikore, Arinkore, oji-kutukutu ko okun ola(wealth) lowo

Ajikore loruko ti a pe ifa

Arinkore loruko ti a pe esu-odara

Oji-kutukutu ko okun ola lowo loruko ti a pe eyin iyami eleye

Eyin meteta ni kin ni mo pe yin fun

Mo ni nitori okun-ola ti e ko lowo ni

Ki e ko fun wale259

To ba se bi ise ti wale259 ba ni

E ni yio la laye

Afaila ojo, bi ojo ba la ki wale259 o la

Eewo, aje ki pe aje ti fi ri taje se

Sawerepepe ni ko ma pe ohun rere fun wa

Ogunda-bede oooo, wa lo re ma jale owo nla nla fun wale259. Ase oo!
Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 10:39am On Jun 06, 2016
Awure nla ti a ma fi n para
Omi ti won ba fi we omo-titun ti oojo,
Irun ori-afin
Alakan were
Ao lo gbogbo re paop, ao da sinu omi yen
Ao wa ro sinu igo funfun, ao tu lofinda six-flower tabi bintu si
Ao ma fi para ti a ba we tan
Aboru, Aboye!

3 Likes

Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 10:26am On Jun 06, 2016
I I

I II

II II

I II

Obara-Irete

Ifa ni;

Ponusesere Awo Ile Agbonmiregun

O difa fun Agbonmiregun Oloja Oribojo

Nijo ti won ji

Ti won n foribale fun Ikin won

Eni ba foribale a jogbo

Eni ba foribale a jato

Eni ba foribale laa ni ire gbogbo

Pelu ogo-olohun, gbogbo wa la j'gbo, j'ato, ti ao si ni ire gbogbo.

Aboru-Aboye-Abo-sise!

3 Likes

Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 10:21am On Jun 06, 2016
Ifa ti a da fun OKE-ITASE 2016/2017 ni OBARA lotun
IRETE lowo osi, awon babalawo pe papo, won pe ni Obara-rete.
Ifa ni;
Abere nii fi toju- timu sise
A difa fun Foribale koo rire
Ebo ni won ni ko se
O si gbebo nbe o rubo
Awa wa foribale a o ku mo
Obara- rete , Ori gbo ke!
IFA ori mi re oooo
Mo foribale mo rire
Ifa o jire loni oooo.
Mo gbadura wipe ori gbogbo wa ni yio gbare lodun yi oooo
Aboru, Aboye, Abo-sise!

1 Like

Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 10:07am On Jun 06, 2016
Ifa ni;

Ope segi-segi awo odo

Awonrin mogun

Adifa fun oye ti n lo re subu lu otua

Igba ti oye subu lu otua

Igba ti oye wole otua

Aye wa wa di wo bi ti ilasa.

Gbogbo awa ti a peju se odun yi, odun irorun ni ao ma se oooo, aye wa yio si rorun pelu ogo-eledumare.

Aboru-Aboye-Abo-sise!
Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 9:59am On Jun 06, 2016
Mo ki gbogbo awa elesin ibile fun ayeye- odun OKE-ITASE ti a

ma n se ni ilu ILE-IFE ti, ti odun yi wa si ipari ni ana. Mecca ati

Jerusalem ti wa niyen, mo gbadura wipe emi wa yio se

opolopo re laye. Ase!

Ifa ni;

Isu ni fi ibi gbigbo sodun

Koko gbo ohun arira lale

Akere ni ikeyo, o gbo kuku ojo

O fo rere, fo rere si olohun

Adifa fun oye ti n rele ofun re sodun

Igba oye re ile ofun re sodun

A o jo-jo-jo(dance)

A o yo yo yo

A o feja san iyan

Ao si rera kebe.

Gbogbo awa ti a peju se odun yi, odun ayo ni ao ma se o!

Aboru, Aboye, Abo-sise!
Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 7:24pm On Jun 02, 2016
IFa ni

Akere finu sogbon

Ni oruko ti an pe ifa

iran Ija gidigidi ko kan agba

Eniti olorun ba pe ni agba

Baba la ma pe

Adifa fun osetura ti o ma ti kere

Gba agba lowo olodunmerinlogun

Ebo won ni kose

Ogbe'bo nbe o si sebo

Ko pe, ko jinna

Ka wa bani ni jebutu ire

Ijebutu ire la ba ni lese oba-orisa.

Mo toro fun gbogbo wa losu titun yi, ti won ba gba ire ni ile ti won gba ni ita, odo gbogbo wa ni won o dari re si. Ase!!!

Aboru, Aboye, Abo-sise.

Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 11:22am On May 29, 2016
[quote author=jophins post=45910061][/quote]

Lofinda eyikeyi to ba wu yin dada, sugbon o gbodo je eyi to ni oorun dada!

Awon agbalagba bo, won ni ojo ti lofinda ba wole, ojo na ni oga re ma n mu ile....ati be be lo!
Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 11:18am On May 29, 2016
jophins:


e jowo sir shey omi inu amu(muld) pot ti awon baba wan lon ni tabi omi yen yato

Omi-oyan aya obinrin

1 Like

Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 11:14am On May 29, 2016
viperVIP:
If you are using a juju and you are told not to near a woman (sexually) for somedays. If you masturbated within the period, is it same thing as woman sex

It does not good enough, it is more or less you're reducing the potency of the JUJU.

3 Likes

Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 11:10am On May 29, 2016
zenith329:
Ejo sir, se ori ako alangba loje ori langba abi won yato?

Ori Ako-alangba

1 Like

Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 11:09am On May 29, 2016
wale259:
Baba,Ako Langba abi Abo?
Ori. Ako-alangba ni ooo
Ojumo kiimo ki alangba ma su imi-aje!

1 Like

Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 7:12pm On May 22, 2016
[quote author=bernarddada2010 post=45858133]Kini oruko miran fun 'AFOMO AJADE'?[/quote


E gbiyanju ki e bere re lowo awon elewe-omo, won da month dara-dara!
Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 7:09pm On May 22, 2016
skamoh74:
baba wa Ifankaleluya Eledua a jeki e pe fun. Apada saburu ko ni bayin tomotomo.
e jowo mofe Ogun ERO fun gbogbo asasi.
e seun
stay blessed sir
Ero-ifa ni e le se, sugbon esu re ti e o ma bo ni o dara ju!

1 Like

Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 7:07pm On May 22, 2016
Zalam5:

Alaye tie se lori ogun yii ko BA arawon mun rarara,e gbiyonju kir tun alaye yi se leekan sii@ifa kaleluya!!!
Alaye tie se lori ogun yii ko BA arawon mun rarara,e gbiyonju kir tun alaye yi se leekan sii@ifa kaleluya!!!

Alaye tie se lori ogun yii ko BA arawon mun rarara,e gbiyonju kir tun alaye yi se leekan sii@ifa kaleluya!!!

Oponu ni e ee.....boya ko lo bere iyoku lodo baba awo re!!!

Ti won ba ran e nise kiise iru mi wa ma je iru ise yen fun ti o ko ba fe ki awon eeyan e fi oju sunkun eee!
Se alaye yoku to ku lodo re babalawo awn oku, kin ni ifa ori-keji din ni adota ese keji so??
Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 4:02pm On May 18, 2016
zenith329:
Ekaro gbogbo ile, e jo, ki lo je ekiri eran, oronro malu ati onlo adie?

Ekiri-eran malu ni, onlo adire yen, a le pe ni Ajesi Adire, o ma n saba wa ni ibi aya adire, e bere oronro malu lowo awon alapata ko soro lati ri rara.

1 Like

Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 3:43pm On May 18, 2016
Ose Eyonu Awn Agba


Imi-ewure, Imi-agutan, Ewe-orijin pupo, ewe-eko ti won sonu

Ao gun papo mo ose, ao ko sinu igba onikoko,

Ao te ni eji-ogbe, ao ma fi we.


Aboru, Aboye, Abo-sise!

4 Likes

Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 3:43pm On May 18, 2016
Lofinda Awure


Erupe oju-ona ti ese n to dada, ewe-sawerepepe, ati ewe-ominsinminsin mejeji, ao lo kunna dada, ao da sinu lofinda
Lo ba tan!


Aboru, Aboye, Abo-sise!

3 Likes

Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 3:43pm On May 18, 2016
Ifa ni;
Kundi ni mo sun
Kundi ni mo ji
Awon ni won se ifa fun Orunmila
Baba nlo si ilu awon apani je
Won ni baba ilu awon apani le n lo yi
Orunmila ni kin ni won fi n pa ara won nibe
Won ni won n fi Oso pa ni
Won n fi Aje pa ni
Won n fi Aasan pa ni
Won n fi Ase pa ni
Won fi Ifa pa ni
Won n fi Woli pa ni
Won n fi Alfa pa ni
Be ni won n pe eniyan pa lori Esu
Orunmila ni gbogbo awon ti won sise ibi yi
Sebi bibi la bi won
Won ni bibi la bi won
Orunmila ni sebi igbati a bi won
Sebi won bi Ibi mo won
Won ni be ni, won bi ibi mo won
Gbogbo eni won ba bi Ibi mo to ro ibi simi
Ibi ni yio pa won
Won ni baba bawo leyin se mo
O ni egbesi ni yio ma sin won lo sorun
Won ni baba nibo ni eyin ati awon omo yin yio wa
O atare ni yio ma tari won lo sode orun
O ni sebi Iku Babalawo la gbo, enikan kii gbo iku Ifa
Emi ni mo gburo iku awon ota mi, won o ni gbo iku mi
Odi-meji ni o ba mi di Ibi won mo won laya.

Aboru, Aboye, Abo-sise!

2 Likes

Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 3:23pm On May 18, 2016
Lero70:


edakun baba, se eeru(ashes) ni tabi eeru alamo abi eeru awonka? Eseun eweomaaje o.

Eru(do do) alamo(re re re)

1 Like

Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 3:22pm On May 18, 2016
AWURE OJA TITA ATI FUN ENI TI WA ISE
Ori--Langba, Oyin die, Omi-Omu, Ewe sawerepepe, Ewe-
afomo ajade, ao gun won po mo ose, ao ko sinu igba-
olomori, omi-omu yen ni ao fi po ose yen oo.
Ao te ose yen ni eji-ogbe, ao ma fi we.
Aboru, Aboye, Abo-sise!

2 Likes 2 Shares

Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 3:00pm On May 15, 2016
IFA NI,

Iji ti mo ji mo ba agbe lori igbago

Iji ti mo ji mo ba akalamagbo lori imo

Iji ti mo ji mo ba toro momo lori ope

Toro gege ni iya orunmile nje

Awon olode e mo le binu igun-nu-gun lai-lai

Olorisa kii binu sefun-sefun

Enikan kii binu akan lodo

Aigbori odo pete odo

Aigbaja ka gbimonran ika laja

Enikan kii gun iyan koko ko pode ilu jo

Ojiji enikan ke di mo ni

Ifa o to gege, ma je ki omo araye o le binu mi.

Aboru, Aboye, Abo-sise.

2 Likes

Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 2:37pm On May 15, 2016
Hadeyeancah:
Ara iwaju iba o!!!

E Jo sir, kini awon agba npe ni ogun asiri owo ati ogun asiri bibo.

Iyato wo lo wa larin won ati wi pe kinni implications ati disadvantages won..
E se sir, ewe a ma je ooo

Iyato wa dara-dara larin awon nkan ti e daruko yen. Ati wipe orisi-risi re lo wa.
Asiri-Owo da bi Ako-Osole, Nigbati a si le pe Asiri-bibo ni Awure.

Nipa disadvantages won, Awon nkan ti won ba fi se ni yio so iru alebu to wa nibe. Kiiise. Gbogbo iru-ogun bayen na ni o ni alebu, o wa lowo Babalawo ti o ba se fun yin. Idi niyi to fi je wipe eniyan o kan le sa dede ma se awon ogun kan to ka ninu iwe kan, bi kose. Ko to awon to ni imo(knowledge) nipa Ogun lo.

1 Like

Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 2:28pm On May 15, 2016
Tevez83839:
Edakun eyin babawa
monife arabinrin kan ni mosi fee fe sile sugbon oni ohun ko le femi edakun mo mo oruko re ati ti baba re .ko ki se omo timo le fun ni afunje .,sugbon iru ise wo nimole sasi

Imonran temi ni wipe ki e koko lo wadi boya iyawo yin ni na. Lotito Ife se fi agbara wa, sugbon ko dara to nitori ojo-iwaju.

1 Like

Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 5:57pm On May 13, 2016
Ifa ni;
Aronipin(re re re re) eniyan ni funni lagbondo adie je,
A dia fun Orunmila
Baba n fomije sungbere aya
Won ni o sa ki imonle ebo elenini ni ko se,
O gbebo nbe o si sebo,
Nje elenini ile e wa gba,
Eyin aronipin eniyan, e wa gba,
Odere ile yi e wa gba,
Asake ile yi e wa gba,
Iya kere ile yi e wa gba,
Eyin aronipin eniyan e wa gba.
Gbogbo ota to ni ti e ko ba de ile oun e o ni se rere,
Pelu ogo-olorun, lowo yin ni won ti mo wa gba. To abala esu.
Aboru, Aboye, Abo-sise.

1 Like

Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 9:14pm On May 12, 2016
Ifa ni;
Bikun ba jẹ loju oloko,
Eku ẹ sagada lẹhin ebe
A difa fun Ogbe eyi ti o gbe apo iwa ko Iwori ọmọ iya rẹ lọrun.
O ni ọjọ ta a ri Iwori la rahun aje mọ.
A rira, mama jẹ ki a rahun a rira.
Ojọ ta ri Iwori la rahun owo mọ.
Ojo ta ri Iwori la rahun ire gbogbo mo. A rira, Ifa mama je ki a rahun, a rira.
Eledumare ko ni je ki a rahun ire-gbogbo nile aye...Ase!

1 Like

Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 10:23pm On May 11, 2016
Ifa ni;
Tipa-tipa ni Babalawo fi fewure bo-ifa
Agbe eeti ni maro
Aluko kii ti ni ibu kosun
Odidere kii ti ni ibu tepo
Ojulumo e je ki ahun o sun gbe
Alo, alo, alo ese lori alabahun jafa
Ora loni kin ma rahun owo
Ihoho-dodo lagbado roko
To ba dajodun a do nigba ire gbogbo
Sinkinminni mi de
Afaimoni ko ni mora
Iyere-osun loni ki ire-aje temi o ma sun na
Eji-ogbe, a gbe la ni ko gbe mi.
Eledumare ko ni je ki gbogbo wa o rahun ire gbogbo. Ase!
Aboru, Aboye, Abo-sise..!

1 Like

Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 7:23pm On May 09, 2016
consato009:
E joo baba efun nise yi tan nitori mo need e gan ni, gbogbo Awon babalawo timo ma nlo sodore tiwon ba dafa lo tiwon dafa bo won ani ogun Awon agbalagba ni kinma tera mo lati loo, e tori olorun efi iseyi saanu mi, 08062090143.........or shoyinkaismail@gmail.com




Se eti se awon etutu ti won ni ki e se?

Ati wipe, se awon babalawo yen o se ifa awon agbalagba fun yin ni?

Ifa awon agbalagba po dada, melo ni e se?....sugbon ko ba wu mi lati mo ODU-IFA e da last.
Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 7:18pm On May 09, 2016
Lero70:

,
baba awo Ifankaleluya, edakun orisi panumo meji lowa, panumo abo ni abi panumo abafe? Eseepupo ewe amaaje o.

Panumo Abo ni baba..!

1 Like

(1) (2) (3) (4) (5) (6) (7) (8) (9) (10) (of 10 pages)

(Go Up)

Sections: politics (1) business autos (1) jobs (1) career education (1) romance computers phones travel sports fashion health
religion celebs tv-movies music-radio literature webmasters programming techmarket

Links: (1) (2) (3) (4) (5) (6) (7) (8) (9) (10)

Nairaland - Copyright © 2005 - 2024 Oluwaseun Osewa. All rights reserved. See How To Advertise. 57
Disclaimer: Every Nairaland member is solely responsible for anything that he/she posts or uploads on Nairaland.