Welcome, Guest: Register On Nairaland / LOGIN! / Trending / Recent / New
Stats: 3,163,411 members, 7,853,810 topics. Date: Saturday, 08 June 2024 at 03:16 AM

Ifankaleluya's Posts

Nairaland Forum / Ifankaleluya's Profile / Ifankaleluya's Posts

(1) (2) (3) (4) (5) (6) (7) (8) (9) (10) (of 10 pages)

Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 2:52pm On Mar 02, 2016
Adupe lowo eledumare to mu ki oju wa ko ri osu titun,mo gbadura wipe emi wa ni yio reyin re...Ase!

Ifa ni modupe awo-oba,lo difa fun oba lalede oyo,ti a ba seni loore,ope laadu,ogunda-irosun ifa modupe.

Ela-boru, ela-boye, ela-bosise.

2 Likes

Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 2:48pm On Mar 02, 2016
ONILEIFA:
¤HAPPY NEW MONTH GREAT FANS¤
<OSA-OLOYAN>
! !!
! !
!! !
! !
Bi ara eni ba n laje, bao ba laje,
oju amaa yan ni.
Bi ara eni ba n kole, bao ba koo,
Oju amaa yan ni.
Bi ara eni ba n laya bao ba ni,
Oju amaa yan ni.
Bi ara eni ba sere gbogbo bao ba seekan, oju amaa yan ni.
Adiafun Osa oloyan,
Ekun ire gbogbo niisun.
Ebo niwon nio see,
O rubo tan, ire wole re wa.
Nje kini Oloyan gbewa fawo?
Jingbinjigbin ileke, ola nla loloyan gbewa fawo,
Jingbinjingbin ileke.
Kini Oloyan je lere o?
Jingbinjingbin Ileke, Ere nla loloyan je,
Jingbinjingbin ileke.
Gbogbo ohun to n dun awa FANS egbe yi lokan ni Olodumare aa see fun o(ase).
Aa je ere ninu osu tuntun yi o,
Gbogbo ire ti egbe awa FANS page yi nse lawa naa amaa bawon gbele aye se.
OLODUMARE KO NII SE AWA FANS PAGE YI LASINNIWAYE O(ASE).
Wishing you a joyful MONTH!!!.
O TUN TI BERE IWO OKUNRIN YI?
TA NI BABALAWO RE TO NI OSA-OLOYAN LO FI SILE YI?
ATI ODU ATI OFO IRO TO PA YEN,KOSI ELEYI TO CORRECT NIBE. KO BA DARA KO FE KAN LO RE KO IFA,TI ISE BABALAWO BA WU O LATI SE. ODU TI O FI SILE YEN NI A N PE NI '' OFUN-NA'GBE''.

SE PELE PELE OOO

ela-boru,ela-boye,ela-bosise.
Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 2:42pm On Mar 02, 2016
healthFirst:


Ifa a gbe yin fun esi te fun mi. Mio kuku binu sugbon ko le da na mo gbiyanju. Ko si eni kan to le so wipe oun mon gbogbo inkan tan sugbon ta ba ri ayederu, o ye ki a mon wipe ayederu ni.

Eni tio ba ti fe ko ara re nijanu lori ikilo ti mo fi sita, ko lo da ikanni tire sile. ki won ma se ba ibi je fun mi ati fun gbogbo awon ti won se ogun lori ikanni yi.

E seun leekan si, ogbeni OnileIfa.

IWO ATI TANI KI KEKE PA MO LENU? O MA TI E G*(D*FT),NIBO LO TI RI BABALAWO GIDI KAN TI N TA IWE-OGUN? SE EMI WA NINU OLOOGUN TI E JO NSE OGUN EWE-OYO,ISU DAN-DAN ATI ATA IJOSI NI? SE BI MO TI E CHALLENGE E NI WHTSAPP PE KO KI(CITE) ESE IFA KAN PERE FUN MI SUGBON TI O KO RI ESI KANKAN FO? ABI OTI GBAGBE WIPE O JEWO(CONFESSED) FUN MI WIPE O KIN N SE BABALAWO? IWO ATI AWON WO NI YIO GBA ALEJO ESU? NJE O TI E MO N TI WON NPE NI ESU GAN? NJE O TI E NI EPE KAN TI N SISE LOWO NI? MO SE TAN LATI BA O GBE PEREGI IJA KA NA,TI N O SI FI EJO RE SUN IJO-ERIWO WIPE O N FI ORUKO AWON BABALAWO LU JIBITI LORI ERO AYE LUJARA. EMI TI TAYO ENI TI YIO SESE MA SA IFA LORI-ESU KIN TO BA ENIYAN JA, TI MO BA FI GBOLOHUN IFA LASAN RANSE SI OO,OO TO BE KO KA KI ORUN(N*CK) O MA WO EE.
SE PELE-PELE OO BABALAWO NI EMI,KIISE BABA-ALARIWO.

1 Like

Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 2:40pm On Mar 02, 2016
ONILEIFA:


Baba Ema binu ogbeni Ifankaleluya lo ni a mo ju lara... ologun eke ti on pe ra re ni aroni lati eni lo mi ko ni fi ise sita lai gba ase lowo yin

IWO ATI TANI KI KEKE PA MO LENU? O MA TI E G*(D*FT),NIBO LO TI RI BABALAWO GIDI KAN TI N TA IWE-OGUN? SE EMI WA NINU OLOOGUN TI E JO NSE OGUN EWE-OYO,ISU DAN-DAN ATI ATA IJOSI NI? SE BI MO TI E CHALLENGE E NI WHTSAPP PE KO KI(CITE) ESE IFA KAN PERE FUN MI SUGBON TI O KO RI ESI KANKAN FO? ABI OTI GBAGBE WIPE O JEWO(CONFESSED) FUN MI WIPE O KIN N SE BABALAWO? IWO ATI AWON WO NI YIO GBA ALEJO ESU? NJE O TI E MO N TI WON NPE NI ESU GAN? NJE O TI E NI EPE KAN TI N SISE LOWO NI? MO SE TAN LATI BA O GBE PEREGI IJA KA NA,TI N O SI FI EJO RE SUN IJO-ERIWO WIPE O N FI ORUKO AWON BABALAWO LU JIBITI LORI ERO AYE LUJARA. EMI TI TAYO ENI TI YIO SESE MA SA IFA LORI-ESU KIN TO BA ENIYAN JA, TI MO BA FI GBOLOHUN IFA LASAN RANSE SI OO,OO TO BE KO KA KI ORUN(N*CK) O MA WO EE.
SE PELE-PELE OO BABALAWO NI EMI,KIISE BABA-ALARIWO.

1 Like

Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 2:39pm On Mar 02, 2016
healthFirst:
Ogbeni Ifankaleluya ati OnileIfa, ki keke pa mo yin lenu, eyin obileje awo eke. ki le ri ninu obe te fi waro owo bayi? A gbe eto yi sita lati ran awon ti aye n fiya je lowo ati lati gba won sile lowo eyin Awo eke gbogbo. lehin gbogbo ikilo ta kin yin, e tun wa n paro orisirisi. Mo fe fi dayin loju, teo ba dawo ibi duro, eo gba Esu lalejo laipe. Egbinrin ote loro yin, ba se n pa kan nikan n ru jade. E ki owo omo yin sinu aso ni kiakia te ba fe ka fi Epe ranse si yin.

Ikilo leekan si fun gbogbo awon ti won fe se ogun kan tabi meji lori ikanni yi; yato si oogun ti mo fi sita ati awon eyi ti ogbeni kadunasouth fi sita, iro funfun ni gbogbo eyi to ku. E kiyesara o! Bi enikeni ba ko eti didi si awon ikilo wonyi, o ku si lowo ati Eleda re o. oogun eke ma n ba kadara eeyan je lehin igba ti won ba fi owo yin sofo. Ao ni ri ogun agbana lati owo awon Awo eke o!.

IWO ATI TANI KI KEKE PA MO LENU? O MA TI E G*(D*FT),NIBO LO TI RI BABALAWO GIDI KAN TI N TA IWE-OGUN? SE EMI WA NINU OLOOGUN TI E JO NSE OGUN EWE-OYO,ISU DAN-DAN ATI ATA IJOSI NI? SE BI MO TI E CHALLENGE E NI WHTSAPP PE KO KI(CITE) ESE IFA KAN PERE FUN MI SUGBON TI O KO RI ESI KANKAN FO? ABI OTI GBAGBE WIPE O JEWO(CONFESSED) FUN MI WIPE O KIN N SE BABALAWO? IWO ATI AWON WO NI YIO GBA ALEJO ESU? NJE O TI E MO N TI WON NPE NI ESU GAN? NJE O TI E NI EPE KAN TI N SISE LOWO NI? MO SE TAN LATI BA O GBE PEREGI IJA KA NA,TI N O SI FI EJO RE SUN IJO-ERIWO WIPE O N FI ORUKO AWON BABALAWO LU JIBITI LORI ERO AYE LUJARA. EMI TI TAYO ENI TI YIO SESE MA SA IFA LORI-ESU KIN TO BA ENIYAN JA, TI MO BA FI GBOLOHUN IFA LASAN RANSE SI OO,OO TO BE KO KA KI ORUN(N*CK) O MA WO EE.
SE PELE-PELE OO BABALAWO NI EMI,KIISE BABA-ALARIWO.
Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 11:23pm On Feb 28, 2016
ONILEIFA:
#1

EBO AYE TODAJU*
Eyin meje,
Odidi Okete,
Orogbo meje,
Eyin Open meje,
Oti ati epo,
Awo sobi kan,
Ao fi Ifa osa meji koru,
Otan.


#2
OOgun Atepa
ESE pepeye mejeeji, ao pelu odidi atare kan, ao wafi sin ESE mejeeji yika.

#3

Owo(respect) fun ole:-
Igi Abo, ao fi nu idi, ao fi aso funfun di ni ikobere, ao wafiko ibi ti aba nso.
Ole koni wo ibi ile ti aba fiko laelae.
NB:- (for vengeance) Atun leefi gba esan, eni to fe fi GBA esan korimi

gbe enu re dake joorr...iwo mo ohun ti won npe ni aye?igi-abo re wo lo fi n nu idi? Din-dinrin,dakun bawo lo se fi ifa osa-meji ko ebo ru jare?
ONIJIBITI!
Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 11:13pm On Feb 28, 2016
ONILEIFA:
Ìbà o, Obatala, Oba taasa, Oba patapata lode Iranje, Ìbà Iranje’le Iba Iranje oko, Ìbà Ifon-Osun, Ìbà Igbin, Iba Igbin-Oosa, Ìbà Alágemo-téérekangé, Je a gbo Je a to; Ìbà Abamoda omo Oosa-Agbowujin, Mo daba ire aje, ire aya/oko, ire omo, ire gbogbo, Aba ti Alagemo bada lOosa-Oke n gba, Ìbà Gunyan gunyan ile Ido, Ìbà rokaroka obinrin Ibadan, Ìbà Aje tii n somo Olu-Ibini, Ìbà Okun tii n somo Ode-Irada, Ìbà Orò, òròpòtò pómùpómù, Tobi ‘mo léweléwe ti kan kan o sofun, Ìbà Osanyin –mògbòráyè, To gba opa lowo olókùnrùn sanu. Aye mo juba é jé ki o ju mi sé
Dake enu re joorr...Iba iro re wo? Ifon-osun ko....Ifon-oyo ni. Onijibiti..!
Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 11:08pm On Feb 28, 2016
ONILEIFA:





BABA IFAKALELUYA EJO WO KI NI MO RA NI IGBA YIN ONIKON KO JABELE KALUKU N SE TI RE O DAMI LOJU GBAN GBA PE ODU IFA YEN NI OGBE IRETE TI AN PE NI OGBE ATE TI KO BA RI BE E FI TI YIN SI TA KA RI EDA TO NWO SE OKUNKUN KO MA SE DO SUPA LORO.


Ogbeni..ko wu mi lati da o lohun oro re tori mo ti se ipinnu lati ma so oro lori thread yi mo,sugbon mi o ni la oju mi sile ki o ma fi ifa paro fun awon eniyan. Emi o kin n se baba-alariwo, babalawo ni emi,fun idi eyi mo ni lati fo esi si oro re.
LO BA BABALAWO RE PE IFA IRE-N-TEGBE LOPE FUN O NI OGBE-ATE. ONIJIBITI NI OOO,INU-IWE ALAWIYE LO TI WO,O KIN NSE BABALAWO.

ifa ni ogbe wa te ki ara o ro won,eni wa iwakuwa,a ri irikuri lodifa fun apon to sai laya nile to n toro omo lowo-orisa.
Arakunrin se pele-pele,mo ri ibinu awon awo. Ma wa iwakuwa loruko awon babalawo!
Dakun ki ese ifa kan ninu ogbe-ate to so yen gan?
Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 10:55pm On Feb 28, 2016
ONILEIFA:



Eyi owun e wi mi o ni lo lati ba yin jiyan rara to ri wipe eyin ni aroni lale odo





arunkunrin o le bami jiyan tori onijibiti ni ooooo. Nibo loti ri gbogbo odu-ifa iro re yen? Dakun nje o ti e mo odu to bi o gan? Pelepele re ooo...ko ye ki e mo fi oruko babalawo gba awon eniyan,ti o ba wu o lo ona miran.
Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 6:13pm On Feb 28, 2016
ONILEIFA:
[AGADAGODO TI KIIJE KENU ENU ENIYAN KO

Iye igun, iye agbe, ...Ekan si mi ..., etu ibon die[not original one], atare odindin kan, ao jo po, ao waabu sinu efe owu. ao fi owu dudu ati funfun we. ao waa so mo agadagodo.
*OFORE*
Moda ofa meta mo mu ikan mofita igun, igun ni enu won koni gun, modafa meta mo mu ...efi number sile fun iyoku....., modafa meta mo mu ikan mofita agbe lenu, agbe loni odi igbo rere, etu loni kiwon tuka.


WONYI NI ONIRURU ORUKO TI NWON FI NPE AWON ODU OWO ENRINDILOGUN¤
1. OKANRAN
2. EJIOKO
3. OGUNDA
4. IROSUN
5. OGBESE
6. OBARA
7. ODI
8. EJIOGBE
9. OTURA
10. OFUN
11. Owonrin
12. Ejila Sebora
13. Odu pariwo
14. Oyeku
15. Igara
16. Adakete



Aye wa fun ibere tabi so unkan ti oba ru yin ni oju.

Nibo lo ti ri gbogbo awon odu-ifa iro re yi okunrin yi? Haaaaaaa.....erin re pa mi.

1 Like

Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 6:11pm On Feb 28, 2016
skypeme:
eejo wo kini mo le se ti mo fi le da irawo
ati ayan mo mi pada lowo awon eni keni ti won ji lo ?

ke si awon babalawo ki won bo da-ifa ki won o bo oo bi eleda re ohun ti o ba fe lati pada si odo re.

O digba kan na..!
Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 5:57pm On Feb 28, 2016
O se mi ni aanu wipe nko ni ni anfani lati wa si ori-ate yi mo rara. Nitori awon onijibiti ni o po ti won nfi oogun sile lori ate yi. O si di eewo...babalawo o gbodo lu jubiti tori ifa nbe lorun.

Fun enikeni to ba fe bere ohunkohun...e-mail yi ifankaleluya@gmail.com.
Odigba kan na....!

Ela-boru, Ela-boye, Ela-bosise.
Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 5:48pm On Feb 28, 2016
ONILEIFA:
Ogbe ate
| |
| |
| ||
| |
Kadiju kase bii eni ku,

BABA...SE IFA OGBE-ATE TI YIN NU?
TA NI BABA-AWO YIN TO SOWIPE OGBE-ATE NU? HNNMMM BABA-ALARIWO NI YIN OOOO...E O KIN N SE BABALAWO. KO DARA KE DE YIN LATI LU AWON ENIYAN NI JIBITI KI OLODUMARE O MA BA BINU SI YIN.
Kawo eni tio sunkun eni....
Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 2:16pm On Feb 28, 2016
Note; If u xtend an handshake 2 a man wit leprosy 2day,next-time he w request 4 a hug. O se bi owe...mo fi ifa imule awon aje yen ranse si ori e-mail enikan,dipo ko dupe o da esi pada wipe emi o fi ami si gbolohun yen ni. E joo se o si leto bayen? N ko ni fisile mo lofe.
Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 2:10pm On Feb 28, 2016
Ifa ni Oka nigbenubu yori ola, ere nigbe abata yorun ewa dadada, agba dudu abe iti abara weyiweyi bi eji, adifafun olu lojo ti nlore wewe oye, ebo won ni ose, iwe kan iwe kan ti olu weni gba n ni oba lofi je. Lagbara lowo Olodumare gbogbo wa lao di olu omo nile baba ati iya wa o, ao ni di ero eyin o. Ase o
Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 12:16pm On Feb 28, 2016
Fun awon ti won nilo Ifa imule awon aje yen ni pipe. E kan si mi lori e-mail yi; ifankaleluya@gmail.com. A si fi ranse si yin. Nko fe fi ifa yi si ori-afefe tan fun awon idi-kan. Ati wipe ifa yi ko se fi sere rara oooo. Iwo ti o ko bale dase fun ra re,ko ba dara ki o kan siwa ki a si bayin se.
NOTE
FUN IWADI LORI ORO AIYE RE, O LE KAN SIWA KI A SI BA O BI IFA(ELERI IPIN,ATUN ORI ENI TIO SUNHAN SE) LERE. ELEDUMARE YIO BA WA TO AYE WA OOO. To abala-esu!
Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 12:07pm On Feb 28, 2016
Ifa ni: Aridigi ni ti eegun,ako-tagiri ni ti ejo, ojo ti owu alahun-takun ba ja, agbaagba meta won kii roju so, adifa fun orunmila nijo ti baba n lo soju-ogun to le,won ni ki orunmila o ma lo,orunmila ni nitori kin ni,won ni awon to n yin ni nibon,awon to n sa ni lada,awon to na eni loogun ati awon to n se ni ni ajogun gbogbo wa nibe, orunmila ni ohun o lo,orunmila ni ti won ti fi oju kan ohun gbogbo ohun buruku ti n be ninu won yio si ma ra si won ninu, iwo won ka sai sun si won lapo iwo won.

NOTE
ifa ti o wa loke yi ni kiije ki ogun ti won ba fi na eeyan ati ibon,ati ohun buruku ti won ba fe se si wa ko sise. Aso eegun,owu-alahuntakun,ori-ejo,ewe aruso oko ati be-be-be loooo. Aso-eegun yen ni ao fi di ni ikobere.

Ela-boru, ela-boye, ela-bosise.

1 Like

Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 2:39pm On Feb 27, 2016
IFA-ISOYE

ODIDI OROGBO KAN, ODIDI ATAARE KAN, OBI-ABATA OLOJU MERIN KAN, EJA-ABORI KAN, EWE-ONIYEMIYE,EWE-EERAN ATI EWE ATORI. AO GUN PAPO TI YIO KUN NA DADA BI AGUNMU,AO WA TE NI ODU-IFA OLOGBON-MEJI,AO WA PE IFA RE SI

IFA RE: sabe lawo sade, asa lawo asagede,arara abori patoki awo ile orunmila, lodifa fun orunmila nigba ti baba nsawo ti ko ni iye ninu, ifa ni to ba bi ise tohun(to ba se bi ise temi lagbaja omo lagbaja ba ni. Ni e ma lo larin yen) ba ni, ifa ni iye-orogbo kiiku mo orogbo ninu ka je ko ma le koro,iye obi kiiku mo obi ninu ka so ko ma le yan,iye ataare kiiku mo ataare ninu ka je ko mo le ta ni lenu, eyi ti mo jaja gbagbe eja loni ko ja simi ninu,eeran loni kin ma ranti, atori loni ko to nikun mi worowo,ipanan merindinlogun ni ewe-oniyemiye ma n ni,gbogbo ara ni fi so. Ologbon-meji fun mi ni iye temi kin gbon sara-sara. AO MA FI MU EKO-TUN DIE-DIE.
NOTE
mo fi ifa yi sile fun iwulo awon eniyan ni. Ti iwo ti o n ta iwe ba ko sori iwe-re,lagbara lowo eledumare wa ri ija awon eleye. Mo fi odu-mererindinlogun bura.

FUN IMONRAN TABI OHUNKOHUN, E KAN SI WA LARI ifankaleluya@gmail.com
Ela boru, Ela boye, Ela bo sise.

2 Likes

Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 2:14pm On Feb 27, 2016
Nudewhenu31:
Eku agba o, Baba health. Ejoo mo nilo ogun oyun nini, fun obinrin to un wa oyun ti gbogbo ayewo fihan pe koni abu ara kankan (no any health problems)

Baba ko kin n se Ogun ni e nilo,O ye ki e se ayewo daadaa ni. Ki e kesi awon Babalawo to gbo ifa yanran-yaran ki won o ba yin so ifa-kale. Pelu ogo olorun gbogbo ohun to n fa idiwo ni ifa yio fi han kedere.
NOTE
Ifa-dida ati etutu sise lagbara ju ogun lo.
Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 9:34pm On Feb 26, 2016
Ifa ni oro kan n semi bi kin ma jo, kin ma jo. Oro kan mama nse mi bi kin ma yo bi kin ma yo. Mo wo apa mi otun n o ma ri alasiri mi, mo wo apa mi osi n o ma ri alasiri mi, owo mi wa ba iyere-osun, ifa mo lo to gege ki o wa bo asiri mi, Eji-Ogbe oo wa lo re gbe eni rere ko mi, mo ni o to gege ki o je ki gbogbo eniti o ba fojukan mi ma fi owo nla-nla bo asiri mi. Lagbara Eledumare, Asiri gbogbo wa ni yio bo oooo. Ase orisa lenu mi, eyi ti mo ba wi ni irunmole yio gba, ase orisa lenu mi. Ase..!

Ela boru, ela boye, ela bo-sise.
Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 9:24pm On Feb 26, 2016
Zalam5:

Hmmm ,e se gan ,Iya lenun nla lo je funmi bi etisesowipe ko wopo ni Africa ,katomawaso nigeria,iyen tunmo siwipe mio le ri eegbo igi yen ra niyen baun
O de dun min sha undecided undecided
[color=#000099][/color] shocked

Igi-Asorin wa ni Nigeria,O wa ni apa-iwo orun ti a mo si south-west. Sugbon n ko mo boya omiran tun wa,sugbon eyo-kan soso ni emi mo pe o wa Nigeria. Olorun fun wa ni ore-ofe to po gbaaa. So, epo-igi nla wa. E le ri ra ni owo awon elewe-omo. Sugbon,o se se ki won o fun yin ni ayederu re ooo. Tori ko wopo.
Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 6:44pm On Feb 26, 2016
Zalam5:

Oruko miran wo latunle PR(epo igi Nla) ?

kosi ibi won o ti mo igi-nla. Sugbon oruke miran re epo-igi-Asorin.
Igi yi ko wo po ni africa. A ko si gbodo mu anything irin(iron) de ibi ti igi yi ba wa.
Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 1:16pm On Feb 26, 2016
ALIUDAVID:
@ Ifankaleluya efi email yin sita ki alekansi yin lori email..
ejowo efunmi ni ifa
yen ni pipe, number mi ni.. 09030116480 OR 08097212426. Email mi re: aliudavidodunayo@gmail.com.

E-mail wa ni...; ifankaleluya@gmaol.com

Eniti o ba ni oro lati ba wa so,ko kan si wa lori e-mail yen.
Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 11:28am On Feb 26, 2016
belatoxx:
Baba Ifankaleluya Ati babawa Healthfirst....... Ose mi lanu pe oni ni igba ikeyin ti mo ma was si ori ikan ni yi to ri wipe e so wipe e fe fun awa eniyan ni ogun ilera ofe baba healthfirst gbiyanju sugbon baba wa Ifankaleluya ko kin fi sita tan se ikanni yi ti di ti olowo ni ki a mo e se pupo.

ALAGBA...O SE MI NI AANU PE MO TI GBIYANJU LATI PE NUMBER YIN SUGBON TI KO LO. MO TI FI NUMBER MI RANSE SI ORI-E-MAIL YIN. BOYA KI E PE KI A FI SORO AWON IFA YEN. IFA KO SE FI SERE LATI MA FI SI ORI-ATE BAYEN TORI AWON TO WON N TA IWE-OGUN NI OOOO. ATI WIPE AWON IFA KAN WA TI A KO LE FI SITA KI AWON ENIYAN MA BA SI WON SE ATI LO.
Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 9:55am On Feb 26, 2016
OGUN AWORO ITAJA.

EWE-AWOYOYO TUTU TI A JA NI OOJO, EWE ETIPON-OLA TUTU TI A JA NI OOJO, IMI OJO, YEPE OJA TI O BA MA NKUN DADA. OJU-OJA NI KA TI BU YEPE YEN OOO. ATI OSE IYETI O BA WU WA. AO KOKO GUN EWE MEJEJI YEN PAPO , AO FI IMI-OJO SI, LEYIN NA NI AO DA YEPE OJA YEN SI TI AO SI GUN PAPO. TI A BA GUN TAN,AO KO SINU IGBA-FUNFUN TABI IKE-FUNFUN,AO TE NI IFA EJI-OGBE AO WA PE IFA RE SI.

IFA RE; OJUMO KIIMO KI ORUN O MO LA,KI O MU IRE OLA KAN EMI LAGBAJA LONI, OJA KIIPE ENIYAN TI WON FI MA NSARE LO SOJA,KII TERUTOMO O MA SARE WA BA MI RA OJA TEMI ATI.......... BE-BE-BE-BE-BE LOOOOOOOO. TORI AWON TI WON NTA IWE OGUN.

KAN SI WA TI O BA FE ISE YI.

TI O BA WA JE WIPE SHOP RE TOBI DADA,KAN SI WA,AO RAN O LOWO LATI SE OSO-AWORO TI WON MA FI N DA OJA-SILE.

ABORU, ABOYE, ABO-SISE.

1 Like

Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 9:40am On Feb 26, 2016
IFA NI ASO FUNFUN NISAWO WON NILE'TE, APA NI SAWO WON NILU APA, OGERERE NISAWO WON NILU OGERERE, ADIFA FUN OGUNLENIRINWO OKO, ABUFUN OTALE-LEGBEJE ADA TI WON GBARIJO TI WON N BOKE SE OTA, WON GBARIJO WON N BOKE SE OTE, OKO O JE, OKE O MU, BEEBI OKE O BEWE, OKE O BEGBA, OKE NI YIO REYIN OGUNLE-NIRINWO OKO, OTALE-LEGBEJE ADA O, ADIFA FUN ORUNMILA NIJO TI OMO ARAYE NI YIO SO OHUN BURUKU SILE IFA, IFA NI IRO NI WON N PA, EKE NI WON N SE, IFA NI EWE-ARUSO OKO KO NI JE KI IBI O SO. OLODUMARE KO NI JE KI IBI O SO SILE GBOGBO WA OO. EWE ARUSO-OKO KO NI JE KI IBI O SO. ASE ORISA LENU MI, EYI TI MO BA WI NI IRUNMOLEYIO GBA, ASE ORISA LENU MI.
IFA TI A FI SILE JE IFA ISEGUN-OTA TI AWON BABALAWO MA NFI EWE-ARUSO-OKO, OMO-OWU ATI BE-BE LO SE KI WON O TO PE IFA YEN SI. TI WON BA SA SI WA, ORI NI YIO FO ENI NA PA.

ABORU, ABOYE, ABO-SISE.

Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 2:20pm On Feb 25, 2016
FUN ENITI KO BA SE ASEYORI LORI GBOGBO IDAWOLE RE TABI TI AWON AGBALAGBA KO JE KO RI ONA ABAYO.

IFA NI AWA NI TI A LE FUN YIN,KO KIN NSE OGUN LASAN.

IFA YI JE AKO ATI ABO.

AKOKO NI IWE(BATH) ASEYORI TI GBOGBO OGUN ATI OHUN TI O BA DAWOLE YIO FI MA SESE
EKEJI NI IMULE AJE TI WON FI MA N YOJU SI ENIYAN LOJU ORUN TI WON YIO SI FI ASIRI OGUN AYE RE HAN E.
IFA ELEKEJI YI, TI O BA SE BI WON TI MA N SE,OKUNRIN YIO LO FUN OJO MESAN,OBINRIN YIO LO FUN OJO MEJE. LEYIN TI O BA LO IFA YI TAN,TI ENIYAN BA LO YA X-RAY NI HOSPITAL,WON A RI IGBA NI AYA WA,IGBA(CALABASH) YEN NI AMI TI AWON AJE YIO FI SI WA LARA TO TUMO SI WIPE AWON AJE KO GBODO FI OWO KAN WA MO.

SUGBON NKO NI NI ANFANI LATI FI IFA KEJI YEN SILE LORI IKANNI YI,NITORI AWON KAN TO JE WIPE IWE OGUN NI WON N TA. AWA SI MO ASIRI WON.TORI AWON IWE KAN NI WON N DAKO FUN YIN,WON KIISE BABALAWO. IRO LASAN NI WON N PA FUN YIN.

1.
IWE ASEYORI.

EWE-IYALODE TI KO JA TI KO LU 201, AKO-OKUTA MESAN, ATI EPO-OBO NI AO FI SE AGBO YEN. OMUNU EWE-IYALODE MESAN ATI EPO-OBO DIE NI AO GUN PAPO,TI AO PO MO OSE DUDU DIE TI AO FI SE OSE RE.AO KO AKO-OKUTA YEN TELE IKOKO,AO FI EPO-OBO YEN LE LORI,AO WA KO GBOGBO EWE YEN LE LORI. AO BU OMI TO PO DADA SI,AO GBEKA INA NI DEDE AGOGO-MEFA IROLE. TI AGBO YEN BA TI JINNA,A KO GBODO FI IDI RE KAN ILE OO. A LE WA AKO-OKUTA TI O TOBI DADA KI A GBELE LORI. AO WA KO GBOGBO EWE YEN KURO,AO LO DA SI ORI-AKIITAN. SUGBON,A KO NI KO AKO-OKUTA YEN KURO.
FUN ENITI KO BA NI AGBARA LATI PA ODIDI ERAN,AO TI RA(BUY) ORI ORUKO ATI ESE RE MERERIN SILE,AO KO SINU AWO ABOKADELE DUDU,AO BU EPO PUPA SI LORI. TI O BA DI NI AGOGO-MOKANLA ALE,AO SE ADURA SI,AO LO GBE SI ORITA-META,A KO GBODO WEYIN TI A BA TI GBE KA LE OO.
AO NI SUUURU KI O FI DI AGO-KAN ORU,TI AGO-KAN ORU BA TI LU NI AO FI AGBO YEN WE PELU KENKEHIN TITUN. TI A BA TI WE TAN,AO RI KENKENHIN YEN MOLE,AO KO AKO-OKUTA YEN LO DA SI ORITA-META LORU YEN,A KO SI GBODO WO EYIN TI AO FI WOLE PADA.

GBERE IFA YEN; ESO-LOWEREJENJE MESAN ATI OMO-IRULA MESAN NI AO LO PAPO TI AO FI SIN GBERE MERIN NI AYA APA-OTUN,META NI EYIN APA-OTUN ATI GBERE META NI AYA APA-OSI,MERIN NI EYIN APA OSI. LO BA TAN.

IKILO RE OOO
OBINRIN KO GBODO WE IWE YEN OOO. TI OBINRIN BA WE,AWON IYAMI MA FUN NI EIYE NI OOO.

2
IMULE AWON AJE TO DAJU
ABO ADIE TO DUDU TIKO NI AMI KANKAN, IKODE KAN,OBI-IFIN,OBI-IPA,TEWE-TEGBO AJEOBALE,IGBA OLOMORI ATI ........., AO LO WA EGBO AJEOBALE YEN NI ARO KUTU-KUTU,AO WA FI EGBO YEN WON IKA-ARIN WA,AO GE SI META,AO YA AWE-KAN NIBI OBI-IPA,AO GE SI MARUN,AO YA AWE KAN NIBI OBI-IFIN AO GE SI MERIN. AO KO EGBO TI A GE SI META YEN TELE IGBA,AO DA AWON OBI TI A GE YEN SI,AO FI IKODE YEN ATI EWE........,AO WA KO GBOGBO IFUN ADIE YEN TI A YO LATI IDI,TORI A KO GBODO PA ADIE YEN LORI,LATI IDI(OBO) NI AO TI GE,TI AO SI TIKO GBOGBO IFUN RE JADE. TI A BA TI KO TAN. AO KO SINU IGBA(CALABASH) YEN,AO WA KO EWE AJE-OBALE TO PO DADA SI LORI. AO WA DE IGBE YEN PA. AO GBE SINU IKOKO,AO GBE KA INA. AO DE KOKO YEN,A KO GBO RO PAPO TI YIO FI JO TAN. TI O BAJO TAN TI ATI LO,AO WA TE NI ODU-IFA OSA-MEJI. AO WA PE IFA RE SI. SUGBON N KO NI FI IFA YI SILE TAN TORI AWON TI WON N TA IWE-OGUN.

NOTE;;
TI O BA NILO GBOGBO IFA YI TAN,FI NUMBER RE SILE LABE KIN NI YI. PELU OGO OLORUN,MA SI FI SILE FUN OOO.

ABORU,ABOYE,ABO-SISE.

4 Likes 1 Share

Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 11:45am On Feb 25, 2016
IFA NI AKARA WOWOWO IDI-ESU, ADIFA FUN ETI-GBORE TI SE IYA-OSETUA, TI WON N SE YI O GB'ORE, KA SAI GB'ORE, ETI AKAPO YIO GBORE. LAGBARA LOWO ELEDUMARE ETI GBOGBO WA NI YIO GBO'RE OOOOO. ASE ORISA LENU MI, EYI TI MO BA WI NI IRUNMOLE YIO GBA, ASE ORISA LENU MI. ABORU, ABOYE, ABO SISE.
Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 11:38am On Feb 25, 2016
belatoxx:
@ Ifankaleluya ... se eni ti o ni atosi ojo pipe le lo

Beeni baba.
Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 11:04pm On Feb 24, 2016
belatoxx:
Baba ejowo ki ni a le lo si atosi ojo pipe mo ti lo orisirisi ogun e jowo e sa nu fun mi.

Ogun-Atosi
Epa ikun, odidi bara kan,eru,ako kanhun,ewe baba die,emu ni ao fi da agbo re,ao gbe pamo di oko-keta. Leying ojo-keta ao ma mu die-die. Odaju oo!!

1 Like

Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 10:54pm On Feb 24, 2016
Ifankaleluya:

Ewe-Rekureku Apeje re tabi oruko miran ti won n pe ni Ewe-Balekale

(1) (2) (3) (4) (5) (6) (7) (8) (9) (10) (of 10 pages)

(Go Up)

Sections: politics (1) business autos (1) jobs (1) career education (1) romance computers phones travel sports fashion health
religion celebs tv-movies music-radio literature webmasters programming techmarket

Links: (1) (2) (3) (4) (5) (6) (7) (8) (9) (10)

Nairaland - Copyright © 2005 - 2024 Oluwaseun Osewa. All rights reserved. See How To Advertise. 82
Disclaimer: Every Nairaland member is solely responsible for anything that he/she posts or uploads on Nairaland.