Welcome, Guest: Register On Nairaland / LOGIN! / Trending / Recent / New
Stats: 3,155,543 members, 7,827,032 topics. Date: Tuesday, 14 May 2024 at 05:02 AM

Ifankaleluya's Posts

Nairaland Forum / Ifankaleluya's Profile / Ifankaleluya's Posts

(1) (2) (3) (4) (5) (6) (7) (8) (9) (10) (of 10 pages)

Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 1:24pm On Jan 06, 2017
ademotech:
ejor kini molese

E lo re wa EWE-AJABO(eku gogoro ni a n pe bayen). e gbo ninu omi ti e le fi we ni e kan soso ni aro kutukutu, ki e wa ju epo igi-nla di e sinu omi yen ki e gba omi yen si ibi ti o tile ri sanmo lati aro yen di ale. ki e wa ra AJAPE eran oruko, ki e ko sinu awo-abokadale, ki e bu epo pupa si lori, ki e wa se adura si wipe Oso lo ba fe bayin ja ni, aje lo ba fe ba yin ja ni gbogbo ajogun kajogun to ba fe koju ija si yin lati de yin mole lona kan tabi lona miran, odidi eran ni e ti pa fun won yi, ki won jowo ki won yonda yin. eo ti wa efun ati osun sile, eo lo papo, eo fi omi di e po, eo wa fi pa ese yin lati orunkun da atelese, eo wa lo gbe ipese yi si orita-meta lale ti gbogbo eniyan ba wole sun tan. pi pada ti e ba pada wo inu ile ni eo wa fi omi ti e ti gbo ewe-ajabo ninu re yen sin gbogbo ara yin ti eo si wole sun.

NB; Ti ile ba mo laro ojo-keji, e gbiyanju lati se saara fun afoju meje.

Pelu ogo-olohun, eo si ja Ajabo ninu odun yi, e ki yio ri ohun ti yio da yin gunle tabi ogun atimo(do do mi). Ase!

1 Like

Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 11:56pm On Jan 05, 2017
EBE AWON AGBA TO DAJU

1. EPO-OBO TI IGI RE KU FUN RA RE

2. ASO-AGBA MOKANLELOGUN(21)

3. EWE-AJE-OBALE TUTU TO JE TOOJO

4. EPO-IGI NLA

5. EWE-EGELE TUTU TO JE TOOJO

ao gun awon eroja yi papo mo ose, lai si aso-agba ati epo-nla yen nibe. ao ko ose yen sinu isasun titun kan to ni ideri, ao wa lo epo-igi nla yen,ao ku si ose yen lori bi elubo, ao wa fi aso-agba yen gun ose yen lori ni eyo kookan. ao de isasun yen pa. ao gbe sinu ora kan, ao so, ao lo bo mole lorita meta fun ojo meje. ao lo wu leyin ojo keje, ao ma fiwe ki a to sun lale.

ABORU, ABOYE, ABO-SISE.

1 Like 1 Share

Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 11:42pm On Jan 05, 2017
CallmePROF:
Baba ejowo... ose awure wo lonje " awure dalute ". Ejowo kini iwulo re atipe bawo lose ma n sise.

Inu mi Ma dun ti e ba dahun ibeere mi. cool

Baba, e ma je ka tan ara wa je. EMI o gbagbo ninu Awure ti e n toka si yen. Gege bi Apere, ki eniyan kan ni ohun fe ma lo awure dalute ni ilu eko, e dakun nibo ni alujonnu awon to se alujonnu owo ma lo? E dakun, nibo ni alujonnu awon to n lo OSOLE-GBIGBONA ma lo? E ma je ka tan ara wa je, ALUJONNU ju ara won lo. won si ma n da ara won lona gege bi ole ti ma n da eniyan lona! Won da pe fun yin ni, o ni loruko miran, gbogbo n kan to ba je mo bayen gbodo ni owo awon iyami(AJE) ninu,

4 Likes

Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 11:32pm On Jan 05, 2017
ademotech:
. baba ejor ebami tunmo ala MI ,,mo LA ala pe mo joko ti owo (money) to PO ni gbangba ti eyan PO ti wan yi MI ka ti wan SI WO mi

Hnmmmmmmm.........!

Baba, emi o mo bi a ti n tan(deceives) ni. Ala ti e la ko dara rara. Iseda yin o ni gba abode pelu ogo-olohun......Amin! N o ni so ju bayen lo.....!
Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 1:35pm On Dec 29, 2016
Ayomidegbenga1:
Baba ifankaleluya pls kindly give me Odu ifa that works for boldness"ikiya" and how to use it.isese a gbe wa ooooo...

IFA ILAYA OLODI-MEJI

1. Yangi Oju-ona

2. Ikujebu

3. Eresile ewe-idi

4. Yangi esu

Ao lo papo, ao wa te ni odu-ifa odi-meji.

ifa re; Olukimolaya, ayamudindi kimolaya, ayamu didi ni ti kujebu, ayamu didi ni tesu, yangi oju-ona kiije ji aya ona o ja, ewe-idi ni ko di emi lagbaja omo lagbaja laya. odi-meji iwo ni ko di emi lagbaja omo lagbaja laya. eewo ni, aya esu liija nigba kookan. ao ma fi fo eko tutu mu.

Aboru, Aboye, Abo-sise.

2 Likes 2 Shares

Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 10:26pm On Dec 01, 2016
Zenlife:


You see, that's why your style isn't admirable.
Can someone who has Esu as asked be an alaimokan to ma si lo?
Dude, if you aren't posting complete, best you don't post at all. Why post it? Obviously to be contacted behind the scene or 'abe aso' as you're prone to call it, for money gains. If giving, just give. Quit teasing.

You're quick to post "Ifa ni..." But not when you really should.

Stop this practice of giving the goat and holding on to the rope, it's not honorable.

Go take a look at kadunasouth posts as an example.

May God open your heart.


I've comprehend your problem. You've always wants, needs, and admires my attention. but mind you, i'll never grant it again.
Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 12:40am On Dec 01, 2016
seanjizzyayo:




motiri ewe ireke sir kini a won nkan Erija toku sir?
ejowo efiranse so ori email yii seanjizzyayo@gmail.com tabi ero ibanisoro mi 08100713615
ewe a maje oop

Kiise ewe-Ireke. Ewe-ire ni mo n so!
Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 12:37am On Dec 01, 2016
Ogunleti01:
e jowo baba, ogun wo la le se lati tu asiri ole i.e boya enikan jale ninu ile ti ero po si ti ko si eni ti o fe jewo. kini a le se lati tu asiri eni to jale yii

Nje e ni Esu ti n gba ebo, tabi eyi ti e fi n sa abilu?

Ti e ba ni, Akuko-adie kan ni eo mu lo sidi Esu yi, Iyere-osun, Edun-ara number one, ati Aso-were.

Iyere-osun yen ni e o fi te eji-ogbe sori esu yen, eo wa pe ifa re si, ti e ba pe ifa si iyere-osun tan, eo fi edun-ara yen le lori, eo wa pa akuko adie yen sori esu pelu aniyan yin, eo wa fi aso were yen bo mole.
Pelu ogo-olohun eni na yio ya were ni ti ko ba tete jewo.

N o ni fi ifa re sile lori ikanni yi, ki awon alaimokan mo ba ma si lo. Were dun wo, sugbon ko se bi lomo!

1 Like

Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 12:30am On Dec 01, 2016
Nostradamus:
edakun baami arabinrin mi kan ni abiku maa n damu,obinrin yi ti pada nu omo marun already,ejowo baba e sanu,e yonda ogun kan sile ti mo le fun arabinrin yi,mo nife arabinrin yi pupo gan ni.

E ma je ki a ma fi opa poolo-poolo pa ejo,ki ejo na ma ba lo ma wa lowo. Oro arabinrin yen kiise ogun sise, o gba akiyesi ni, ti oro ba ri bayen o ni ibi ti awon agbalagba ma n gbe ka. E je ko to awon agbalagba lo, ko mo idi ti nkan yen fi n sele si, ko gbo ikilo, kosi se awon etutu to ba ye. Adura re yio gba pelu ogo-olohun!
Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 11:19pm On Nov 19, 2016
seanjizzyayo:
Baba ejowo she omo Yahoo le malo Ogun eyonu tabi awure lati fi ma ri owo GBA lowo client?

Atipe iru Ogun eyonu or awure tabi Ogun WO ni omo Yahoo le ma lo ti yo si mari owo gba?

Ewe amaje oooo

Ti e ba ti ri ewe-Ire ki e kan si wa. o tun ni eroja kan ti ko se daruko lori afefe.

1 Like

Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 11:18pm On Nov 19, 2016
zenith329:


Ekasan sir, e jor sir, oruko miran wo ni yaya je?


Ile-ikan funfun ni a n pe ni yaya. fun idi eyi, ti e ba ti ri ile-ikan yen , ki e gbiyanju lati tu ka eo si ri awon koriko kan ninu re to je wipe awon ikan yi lo gbe wole tabi ko ile le lori. ohun ni a n pe ni koriko inu yaya!
Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 11:14pm On Nov 19, 2016
08101646045atwp:
Eseun oremi ifankaleluyah, mosi tun Ki eniti Oro Ti odo re bere na wipe:- AKU'ETO'ILU'O,
Akoni sasise!
Sugbon Oro ti mofe soyi, moti so Tele Ni ibere pepe wipe:- ohun'kohun ti ao base tabi ti ao baso molero wipe oye Ki amaro leemeji wipe:- bi obadun Ni eti temi, nje oledun Ni eti elomi, atipelu ti emibayin arami, nje moleri eni yin mi bi. Itumon Ni wipe:- Akiesi gbodo mawa ninu Oro ti yio ma ti enu wa bo si ori afefe, nitori Oro ori afefe eyin Ni nse, boba ti fo bai amasoro lati Ko pada!
Nitori na kosi enikan ti koni ntogbojiule ninu Ile tabi tiko Ni akoya!
Debi Ki awama soro alu'fansa si arawa!
Moti titori be dawo duro Ni igba kan, mosi ri pe ikan niyi ntun wa itesiwaju jubai lo, nloje Ki nma wole leekokan!
Nitori na oremi ifankaleluyah ema Te siwaju!
Ki oremi keji na'o Te siwaju
Sugbon:-IFA NI KOKO IGI NI O BERE OJO,ADIFA FUN EJO N BE LORUN TI SE OMO-AWISUNKUN,IFA NI IRE LO BA MO SE. MA SE LOO,IKA LO BA MO SE, MA SE LO,AT'ORE AT'KA OKAN KAN KIIGBE.
Gbogbo eleyi to ba se ni wa je ere re...!
ela-boru, ela-boye, ela-bosise.

Ori a gbo, Ori a to ore mi. ododo-oro, ko ni reyin pelu ogo-olohun!

2 Likes

Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 10:33pm On Nov 18, 2016
08101646045atwp:
ISEYI NI AFI NSAN GBESE ODAJU
Ewe ata epo obo ao lo kuna dada ao gun po mon ose dudu ao ma fi epo pupa para kato lore we oseyi asiri obo latima san owo yi pelu ase oloun

OGUN ISANGBESE¤ Ao waa iyo ati suger ao lo papo ao waa lo pelu Imi ojo ao po mo ose dudu.... Ao tee ose yen ni Ifa Ogunda ao maa se adua bi oba ti wuwa si, ao maa fi ose yen we lararo ati alale.
Ajuwase'o


Ore mi Oni-majemu lai-lai, e ku ise, E dakun se eo ni ogun ti zenlife n soro re yen lowo labe aso?

1 Like

Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 10:30pm On Nov 18, 2016
Zenlife:


Was the original post for femi?
When posted initially did you know femi?
Truth is it was posted as an advertisement to solicit clients for sake of money hence it's incomplete. To be further discussed off this forum..

My grammars ain't spoken for your approval.
Others will confirm that the only user who claims to know and gives complete remedies is Baba kadunasouth and probably healthfirst whom you drove away insensitively.
And haven't since been able to fill the void he left behind after derailing his thread, marked by your infrequency/ absence.

If you can't do what good others do, let it be.

Go tell your tale to a sucker dude.

@Zenlife, I'm glad to tell you that "I shall not all die" on this thread. Dozens of users of this thread have got the said medicine you clamored not to completed through e-mail & other means. Due to conformity of your mind to the facts, you've opted to always speaks against the sun. One thing in life is that When you are steeped in little things, you shall safely attempt great things. @least I put some things there that were completed and appreciated by some users of this thread, so what are you talking about? I don't know when I become a driver and drove those people name you mentioned off this thread, hence am not the owner of the site. Anyway, by excessive laughter one can recognise the fool. I am a busy type, so don't expect me to always come there and put something online as if i got some biro in stock to sell. the spirit spreads wherever it wants!

Nkan ti ko ye e ni wipe, ti ogun kan ba ti poju to n je sise ni gbogbo igba, awon agbalagba a gbe owo le iru ogun yen ni. kiise ogun yen nikan lo wa now, idi ti mo fi so pe ki FEMI je ka soro labe aso niyen.

The times are changing, and we change in them!!!
Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 10:42pm On Nov 17, 2016
Daxruss:



Aboru aboye o.. Babaa,

E jo ki ni itumo ala yi, pe ki eniyan ma 'je eniyan ni oju ala. Bi kan gbe aseje fun eyan je, ki o wa je pe eran eniyan no fi se aseje na. Ki oni to un si mo pe eran eniyan loun je, sugbon o si n ro ju lati je na. Baba e jo e so itumo ala yi fun mi.

O gbo, O to ooo,

Kiise ala to dara rara. n o gbodo so oro awon agbalagba lori afefe, sugbon to ba ri bayi lojo miran e gbiyanju ki e mu ito(Urine) yin ni afejumo ojo yen lai ti soro si eni kankan.
Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 10:36pm On Nov 17, 2016
Zenlife:


@ Ifakanleluya

" IFANKALELUYAH, ELA BORU -ELA BOYE.... OLUFEMI NI ORUKO MI (OGBE-SE LODU TO BI MI) ABI MI SILE IFA, NI IPERU REMO/ILE IFE,OSUN...MA FE KI E FI PHONE NUMBER YIN RANSE SORI EMAIL : oqualitii@gmail.com...IFA A GBE WA
-----------------------------------------------------------------------------------------------------------
2
IMULE AWON AJE TO DAJU
ABO ADIE TO DUDU TIKO NI AMI KANKAN, IKODE KAN,OBI-IFIN,OBI-IPA,TEWE-TEGBO AJEOBALE,IGBA OLOMORI ATI ........., AO LO WA EGBO AJEOBALE YEN NI ARO KUTU-KUTU,AO WA FI EGBO YEN WON IKA-ARIN WA,AO GE SI META,AO YA AWE-KAN NIBI OBI-IPA,AO GE SI MARUN,AO YA AWE KAN NIBI OBI-IFIN AO GE SI MERIN. AO KO EGBO TI A GE SI META YEN TELE IGBA,AO DA AWON OBI TI A GE YEN SI,AO FI IKODE YEN ATI EWE........,AO WA KO GBOGBO IFUN ADIE YEN TI A YO LATI IDI,TORI A KO GBODO PA ADIE YEN LORI,LATI IDI(OBO) NI AO TI GE,TI AO SI TIKO GBOGBO IFUN RE JADE. TI A BA TI KO TAN. AO KO SINU IGBA(CALABASH) YEN,AO WA KO EWE AJE-OBALE TO PO DADA SI LORI. AO WA DE IGBE YEN PA. AO GBE SINU IKOKO,AO GBE KA INA. AO DE KOKO YEN,A KO GBO RO PAPO TI YIO FI JO TAN. TI O BAJO TAN TI ATI LO,AO WA TE NI ODU-IFA OSA-MEJI. AO WA PE IFA RE SI. SUGBON N KO NI FI IFA YI SILE TAN TORI AWON TI WON N TA IWE-OGUN.




ORI A GBO, ORI A TO FEMI. IFA DARA-DARA NI IFA TO BI O, SUGBON NINU GBOGBO OHUN TO BA N SE MA GBIYANJU LATI MA BO ORI RE DARA-DARA, BI OGBE-SE SE SO NIYEN. AO MA SO IYOKU LOJO LABE ASO.

Aboru, Aboye, Abosise.


Incomplete gibberish nonsensical rubbish!!!
You wanna help?
Just do it!!

Hissssssssssss

@Zenlife, I do not value your grammars but only see your reaction as "ab irato" & i've learnt to always "audi, vide, tace". the person in question(FEMI) is an initiate(Babalawo) from what he wrote, so don't expect some or most of our conversation to be here online. You're not an ifa-priest! what Femi requested for is not the only confirmed Imule Awon Aje that I learnt on the course of learning "dida-owo, etiti-ile ati okara-ebo ni hiha", so i may decide to give him something better. I concur that there is freedom of speech but freedom after speech, no-one can guarrantee.
Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 10:09pm On Nov 16, 2016
kenismusic:
IFANKALELUYAH, ELA BORU -ELA BOYE.... OLUFEMI NI ORUKO MI (OGBE-SE LODU TO BI MI) ABI MI SILE IFA, NI IPERU REMO/ILE IFE,OSUN...MA FE KI E FI PHONE NUMBER YIN RANSE SORI EMAIL : oqualitii@gmail.com...IFA A GBE WA
-----------------------------------------------------------------------------------------------------------
2
IMULE AWON AJE TO DAJU
ABO ADIE TO DUDU TIKO NI AMI KANKAN, IKODE KAN,OBI-IFIN,OBI-IPA,TEWE-TEGBO AJEOBALE,IGBA OLOMORI ATI ........., AO LO WA EGBO AJEOBALE YEN NI ARO KUTU-KUTU,AO WA FI EGBO YEN WON IKA-ARIN WA,AO GE SI META,AO YA AWE-KAN NIBI OBI-IPA,AO GE SI MARUN,AO YA AWE KAN NIBI OBI-IFIN AO GE SI MERIN. AO KO EGBO TI A GE SI META YEN TELE IGBA,AO DA AWON OBI TI A GE YEN SI,AO FI IKODE YEN ATI EWE........,AO WA KO GBOGBO IFUN ADIE YEN TI A YO LATI IDI,TORI A KO GBODO PA ADIE YEN LORI,LATI IDI(OBO) NI AO TI GE,TI AO SI TIKO GBOGBO IFUN RE JADE. TI A BA TI KO TAN. AO KO SINU IGBA(CALABASH) YEN,AO WA KO EWE AJE-OBALE TO PO DADA SI LORI. AO WA DE IGBE YEN PA. AO GBE SINU IKOKO,AO GBE KA INA. AO DE KOKO YEN,A KO GBO RO PAPO TI YIO FI JO TAN. TI O BAJO TAN TI ATI LO,AO WA TE NI ODU-IFA OSA-MEJI. AO WA PE IFA RE SI. SUGBON N KO NI FI IFA YI SILE TAN TORI AWON TI WON N TA IWE-OGUN.




ORI A GBO, ORI A TO FEMI. IFA DARA-DARA NI IFA TO BI O, SUGBON NINU GBOGBO OHUN TO BA N SE MA GBIYANJU LATI MA BO ORI RE DARA-DARA, BI OGBE-SE SE SO NIYEN. AO MA SO IYOKU LOJO LABE ASO.

Aboru, Aboye, Abosise.
Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 5:49pm On Nov 14, 2016
beware16:
Moki Gbogbo Awo Patapata Ewe Amaje O, Ejowo Ise Wo Ni Alelo Ti Won Ba Ran Ofa Sini Lati Oju Orun. Oju Oni Tiwa O.

Iru-ofa wo ni

se oju-oro yen han lara eni yen?
Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 5:47pm On Nov 14, 2016
ONMO

Eiye-opere to ye eyin-meji sori ite re

ati eyin, ati ite yen ni ao ko

atare kan

Kowe dudu kan

Esuru funfun ati Pupa

koriko inu-yaya

ao jo awon nkan yen papo ni, ao ma fi mu eko-tutu ninu igba-funfun ni ago-kan oru.

Aboru, Aboye, Abosise.

1 Like

Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 5:34pm On Nov 14, 2016
IFA NI;

Mo sa pamo

Sa pamo

Ori mi ni o fi mi pamo

Mo rin koro rin koro

Iseda mi ni o rin koro

A dia fun apata gbangba

Eyi ti yio joko ojude gba n gba

Nje eni gbangba ni mi

Ifa ma ma je n di eni koro.


Pelu ogo-eledumare, gbogbo wa o ni di eni koro.

Aboru, Aboye, Abosise.

3 Likes

Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 9:51pm On Jul 27, 2016
ifasheun:



Aboru, Aboye, Abo sise.
Baba Ifankaleluya mo ki yin fun ise takuntakun ti e n se oo,
Oba Adaniwaye a je ki epe fun wa o, ao si ma ri yin ba.
Edakun iranlowoyin ni mo ntoro o
Otipe ti mo ti ma nri arami(myself) ni atimole(cage) ni oju ala mi, koda ni igbami, mo ma nsun gidigan ni oju ala, ni igbami mo si ma nri arami ni ori akitan ti maa ti sun lo ni oju ala mi kan na,
mo ti kirikiri, mo si ti gbinyanju titi sugbon ti mo ba fi owo(hand) mi tun nkan se, nise ni ma tun fi ese(leg) ba nkan na je. Ejowo nitori ti Olodumare se ele komi ni nkan ti mase lati fi bo ninu panmpe aye yi? Edakun mofe ki eran mi lowo, inu mi ibadun ti eba le ko mi ni oun ti mase nitori omo ikofa ni mo nse, osi damiloju wipe eminikan ko ni nbe ninu iru igbekun bayi lori feranyi. Ebe ni mo nbe yin o baba wa ifankaleluya.

Email mi ni yi ; ifasheun11@gmail.com

Pelu ogo-olohun, ifa o tena si o ninu.

Ifa ni; Ahere nla aboju yau

Giri-giri ese leyin kule

Ona aboju tiun

Awon ni won sefa fun orunmila

Nijo ti baba n lore kofa-mofa,ko ogun mo ogun

Ko atenuso mora won

Won ni bawo ni o se ma gbo

O ni ogbo loni ki oun ma gbo gbogbo oun ti won ba n ko oun

Imo loni ki oun ma mo sikun

Iye ataa kiiku mo ata ninu

Iye obi kiiku mo obi ninu

Iye orogbo kiiku mo orogbo ninu

Iye o ni ku mo ninu

Gbogbo ifa ti o ba ko ni yio ma wo sikun re.
Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 9:45pm On Jul 27, 2016
AdebisiTim2:
Ejowo, kini ogun ti oma nje ki oni ise owo ma ri se

Iru ise wo ni e n se?
Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 9:43pm On Jul 27, 2016
ifasheun:




Eji Ogbe kan na lo ni;

Otoototo baba alawo olowo lo difa fun olowo(the rich)
otoototo baba alawo oloro lo se ifa ijokan nni fun oloro(the wealthy)
ka'je epa(groundnut) tan, ka' gbon owo s'awo poroporo OR
kajepa tan, ka da epo re si igbo
baba alawo olomo lo difa fun olomo
olowo ku(die), owo e gbe
oloro ku, oko oro e lo si orun(heaven)
ero ipo, ero ofa
aye olomo ni ko ni parun.

O kare, be ni, bi ifa ti wi niyen. Awon akomonifa oju-ala o tena si o ninu. O di ase, oro kan, oro kan ti awo ba so di eegun!
Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 9:39pm On Jul 27, 2016
ifasheun:



Eji Ogbe ni:
Otoototo, Oroororo Oto oto la njepa, oto oto la nje imumu loto loto la nfi olu esunsun senu oun ti ori ni ti ori, oun ti oori ni ti oori oun tori ntori la fi nf'oba ma'kin lode nranje k'oba le fi oun t'ori toori tani l'ore egbesan a dia fun ogoterere, ti nse awo re ilu gbendugbendu l'oke ehinwonran ogoteerere loruko a npe okunrin/oko ilu gbendugbendu la npe obirin/obo eyi amubo ibe, ire omo(child) loo je.
Ki ori gbo omo oni-babalawo..!!!
Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 10:41pm On Jul 20, 2016
Nostradamus:
baba eseun pupo,eledua a maa fun yin se,ejoor e fun wa ni ogun ti a fi le ba aye eni ti o gbo gun ti wa je.

Se e da awon yen mo dara-dara with their details? Ati wipe iru ogun wo ni e fe fi ja won? Se o si dayin loju wipe eo jebi awon yen? Ti o ba je wipe won re yin je ni, lotito Eledumare lo ni Esan lodo, sugbon a le ran yin lowo lati fi iya di e je awon yen. Boya ka so labe aso!!

1 Like

Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 12:43pm On Jul 17, 2016
IPESE TI A FI N TORO NKAN LOWO AWON AJE(OSA-MEJI)



Abodie dudu kan, ao pa eje re sinu awo abokadale, ao tu huhu re, ibose re ati tenu, ifun re ao jo papo. Ao te ebu yi ni osa-meji, ao fi iyere-osun pe ifa re ni ihoho loru, ao fi ebu yi fo eko-tutu mu, iyoku ebu yen ni ao da si iyoku adie yen ti a fi epo-pupa din lai fi omi kan adire yi lara ti ao si lo gbe si orita-meta

Ifa re: ipingun aje, Asanmimi ogun, obe ide lefi gun omo-olomo je, eje-eniyan lefi da omi-obe, nilawe odo le gbe pe, Adurogesin ni somobinrin ikej, aje mesan ti n be lalede orun, ori igi-gogoro orun leti ro waye, eni ta lo mo oruko yin bayi, mo ni emi lagbaja omo lagbaja ni, eni kin lode, mo ni nitori nkan bayi ni mo se pe yin ni ihoho ke wa siju anu yin wo mi, ke wa faso asiri yin bo mi lara, eni omode ki ridi osan ti fi pon, eni agbalagba ki ridi oru ti fi gan dudu, eewo ni, epo-gbigbona ki roju sun lailai, osa-meji sure tete ko lo sa ire ola bayi fun mi.

Fun imonran kan si ifankaleluya@gmail.com

Aboru, Aboye, Abo-sise

2 Likes

Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 12:28pm On Jul 17, 2016
ERO-OKUTA(do do do)
Iseta, Atare 1, ao gun po mo ose, ao ma fi we, ao si tun ma fi fo shop yen.

2 Likes

Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 12:26pm On Jul 17, 2016
ATOSI
Imi-orun, etu-ibon, a lo po, ao da sinu oyin igan, ao ma fi mu eko gbigbona

2 Likes 1 Share

Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 12:23pm On Jul 17, 2016
Ti ara eniyan ba wu

Epo-Amuje, oko atare kan, Egbo igbon, epo-amuje, ao lo papo, ao ma fi pa ibi to ba wu.

2 Likes

Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 11:07am On Jun 25, 2016
Awure

Iha epo,

Ejinrin were,

Aso Eegun,

Odidi atare kan

Ao jo po, a o ma fi sa ori

Ofo re: iha ni sariya ina, ejinrin ni sariya iti, tomode-tagba ni se aariya egun, tewe-tagba ni ko ma fi owo sariya mi.

Aboru, Aboye, Abosise.

3 Likes

Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 11:02am On Jun 25, 2016
Agunmu Inarun

Egbo-ipeta, egbo-ifon, iru, egbo-inobiri, ide-osa, egbo-tude, alubosa elewe, ata dudu, ao gun po ao ma fi mu eko-gbigbona.

1 Like

Culture / Re: .. by Ifankaleluya: 10:41pm On Jun 21, 2016
Ogun ta fi wo egbo jina

Epo jebo, epo ira, egbo jasoke, ao fi omi se, ao ma fi we egbo na yo si jina kiakia

2 Likes

(1) (2) (3) (4) (5) (6) (7) (8) (9) (10) (of 10 pages)

(Go Up)

Sections: politics (1) business autos (1) jobs (1) career education (1) romance computers phones travel sports fashion health
religion celebs tv-movies music-radio literature webmasters programming techmarket

Links: (1) (2) (3) (4) (5) (6) (7) (8) (9) (10)

Nairaland - Copyright © 2005 - 2024 Oluwaseun Osewa. All rights reserved. See How To Advertise. 81
Disclaimer: Every Nairaland member is solely responsible for anything that he/she posts or uploads on Nairaland.