Welcome, Guest: Register On Nairaland / LOGIN! / Trending / Recent / New
Stats: 3,194,394 members, 7,954,574 topics. Date: Friday, 20 September 2024 at 11:01 PM

If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! - Culture (16) - Nairaland

Nairaland Forum / Nairaland / General / Culture / If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! (380926 Views)

If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here. Everybody Is Invited! / If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! / Do You Speak Yoruba? (2) (3) (4)

(1) (2) (3) ... (13) (14) (15) (16) (17) (18) (19) ... (167) (Go Down)

Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by mishoo(m): 12:29pm On May 28, 2007
ronnie-slimz:

ewo ni gbogbo isokuso yi gan na?
ewo ni isokuso ninu owe? A dara ti o ba yan oo!!
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 12:32pm On May 28, 2007
Segooye,
Lati apa odo temi, ire nifa wi o. Iwo ko nilo etutu pupo. Sugbon o di dandan ki o de Aso rock o. Ti o ba n lo ki o gbe igan aso "satini" meje dani ati garawa epo meta, akuko ti ko i ti gun abo meje ati awon nkan kan ti o o gba dani lati owo iya chalie. Ti o ba de ibe awon iyere ti o o ma sun re:

'KE-KE-KE NI NWON NKAN KOSO;
GUDUGUDU NI NWON NLU F' AWON ORISA:
BI BABALAWO MEJI BA RI ARA WON,
NWON A SE IRUKERE WON YETURU YETURU.
A DIFA FUN ORI, NIGBATI 0 NTI ISALU ORUN BO WA ILE AIYE.
NWON NI KI ORI SETUTU, NlTORI Kl O LE BA DI ENI APESIN;
O RUBO, O DI ENI APESIN.
NJE, ORI RERE NI TI IRERE;
IRERE KO NI ORI A GB'ERU LE,
ORI RERE NI TI IRERE."

ma beru awon godogodo ti o wa ni aso rock o, won yio o lu o , eyi ti di dandan, sugbon bi iya re ba se po si ni , imukumu re yio se din ku si, bee na ni awon orobo ti o n wa yio se ma po si.
Nipa ti omo ti o ni aarunkurugbe (AIDS) ti o ba ni n kan po, uhn uhn uhn  grin grin grin grin grin, a n ja ewe ise re lowo o. grin
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by Dapo4u(m): 12:37pm On May 28, 2007
Richylaw, o ka re o,omo yoruba atata ni iwo,walahi inu midun pelu oye atti ogbon ti o fi gbe yoruba re kale.Se bi omo ti ekun babi,ekun naa ni yoo jo,be gele loro re ri ore mi.Omoge kan ti oruko re nje Ngozi ti o fi ilu Amerika se ibudo ni o so wipe,paape julo awon oyinbo alawo funfun ni won so wipe awon kii gbe orinyin fun eni ti ko ba le so ede ilu baba re.Eyin omo yoruba,e jowo e je ki agbe ede baba wa laruga.Bole Ige orun re o, abi e gbagbe ni?ogbona gbongbo ti o le so orisirisi ede gege bi faranse,laatin, ko da yoruba re muno doko.Yoruba re ki si se amulumola,rara o.
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 12:40pm On May 28, 2007
ronnie-slimz:

ewo ni gbogbo isokuso yi gan na?

Arabinrin ronnie-slimz, ma binu wipe mi o ki o kaabo si ori eto, Ki olofin Ajalaye ati ajalorun ki o gba ni ni lowo segooye2  ati arabinrin kan ti o pe oruko ara re ni o---
( bi o ba tu inu okun ijiroro yi daadaa, iwo yio ri nibe) . Sugbon ogbeni segooye san die nitori o gbo ibawi awon agba grin. Ma binu si ohun ti won ba n so, se ipa tire lati so oro ti o ba n dun o lokan lori iran yoruba ,ere idaraya, irohin agbaye tabi oselu. Ko je bo ti je , ire o
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by Dapo4u(m): 12:46pm On May 28, 2007
ara ijaye niwaju ile ogunmola?
Penkelemesi?
oju ona sonanbole?
osomaalo?


Tani o le se alaye awon gbolohun won yi?
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 12:47pm On May 28, 2007
Dapo4u:

Richylaw, o ka re o,omo yoruba atata ni iwo,walahi inu midun pelu oye atti ogbon ti o fi gbe yoruba re kale.Se bi omo ti ekun babi,ekun naa ni yoo jo,be gele loro re ri ore mi.Omoge kan ti oruko re nje Ngozi ti o fi ilu Amerika se ibudo ni o so wipe,paape julo awon oyinbo alawo funfun ni won so wipe awon kii gbe orinyin fun eni ti ko ba le so ede ilu baba re.Eyin omo yoruba,e jowo e je ki agbe ede baba wa laruga.Bole Ige orun re o, abi e gbagbe ni?ogbona gbongbo ti o le so orisirisi ede gege bi faranse,laatin, ko da yoruba re muno doko.Yoruba re ki si se amulumola,rara o.

o seun o, o ku agbekale ayesi mi. Ile aye a san e sowo , a san somo, a san e si aiku baale oro ASE WA.
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by ronnieslimz(f): 12:52pm On May 28, 2007
segedo nimo nba wi, anyhw sha ama ma rira later. . odabo!!
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by Dapo4u(m): 12:53pm On May 28, 2007
O se o[i] Richylaw[/i],gbogbo ohun to so,aro a ro mo. Inu mii dun nitori wipe o da be eni wipe mo wa lodo awon ebi mi nio.Eleyi n fun ni mi anfani lati ma se iranti ile ni.
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by mishoo(m): 12:55pm On May 28, 2007
arabinrin roonie-slimz, ko to ibinu rara oo. Omo eni ko le buru ka le fun ekun paje. Alaye !richylaw ni ki o gba, ki osi bu omi suuru mu. agba to ba ni suuru ni omo re npo joojoo.
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by mishoo(m): 1:04pm On May 28, 2007
Dapo4u:

ara ijaye niwaju ile ogunmola?
Penkelemesi?
oju ona sonanbole?
osomaalo?


Tani o le se alaye awon gbolohun won yi?
Okookan la ma mun. Osomaalo seyo lati awon eya yoruba kan. ti won ba ya ra won lowo, ati gba ma n nira, o si gbudo je alagidi eniyan ki owo re ma ba lo gbe raurau. ti won ba ti wa gba owo won, ti won ko ba ba o nile, won o ni joko rara. won a so pe "oso ni maalo" (meaning i'll prefer to squat) ki eni na ma ba sope won ti joko, nitori na won nilo lati sanwo ijoko. Bi ose ye mi re oo !!
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by Dapo4u(m): 1:09pm On May 28, 2007
kaabo arakunrin Mishoo, ori re ko ni daru o(amin). Mo wa se iranti wa yi,ninu ere "ogbori Eelemoso" lati owo Eda onile ola .
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by mishoo(m): 1:14pm On May 28, 2007
Ekeji ti mo le soro re ni Penkelemesi.eyi wa lati oro awon eniyan wa. Ikan lara awon Oloselu atijo (Ade___ Adegoke) ti o ma so geesi to po ni o ma nso "peculiar mess" ni gbogbo igba. Ni awon eeyan wa ba soo ni penkelemesi.
Nibi ni o ye mi mo!
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by mishoo(m): 1:17pm On May 28, 2007
Dapo4u:

kaabo arakunrin Mishoo, ori re ko ni daru o(amin). Mo wa se iranti wa yi,ninu ere "ogbori Eelemoso" lati owo Eda onile ola .
Ase oo. Omo tiyin na o ni sanku oo!! iwonba ti a le se ni a nse oo.
Mo gbe bi igba oti fun ogidi omo yoruba bi @richylaw & @haywhy, ki won ba mi pari eyi toku.
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 1:26pm On May 28, 2007
Dapo4u:

ara ijaye niwaju ile ogunmola?
Penkelemesi?
oju ona sonanbole?
osomaalo?


Tani o le se alaye awon gbolohun won yi?

ara ijaye niwaju ile ogunmola?
Bi o ba wo abala okun oro yi sehin mo ti pa owe yi ri wipe:
akini tan n je aki ni tan ,
A fini han n je afini han
Ewo ni pele ara ijaye n'iwajude ogunmola

Ijaye je ilu kan ni e ba ikoyi ti ko jina si Ilu Ogbomoso  , Kurumi si ni Aare ogun fun won nibe
Ogunmola ni Basorun  iko ogun ti i ibadan. Awon mejeeji fi igbakan  je ore ara won , ninu ogun Gbanamu lati gbe Baale Maye pada gegebi Baale Ibadan. Sugbon ko pe pupo ti won fi di ota ara won ti ogun si se yo laarin Ibadan ati Ijaye (1859-1861). Kunrumi tile fi igba kan segun  Ogunmola, sugbon Ogunmola ri alaanu o si mura bi obinrin, o sa lo. Lehin eyi ni won pada wa ko ogun ja ilu ijaye ti won si paarun. Ota nI yoruba gba wipe Ijaye je si Ibadan inu re si ni won ti mu owe yi jade

Penkelemesi.
Bi o tile je wipe a ko tii bi mi ni odun 1950, mo ba aroba ti i se baba itan, Adegoke Adelabu ni o pe ewa ede yi jade, lati inu ede geesi- PECULIAR MESS. E dakun e gba mi laaye fun asiko yi nikan lati yan na na e ni ede geesi fun gbogbo ile lati mo itan yi dara dara. Fun anfani awon ti yoruba won ku die kaato

Even when I can ascertain that I was not born in the 50s, history has made me realise the impact and political might of Honourable Adegoke Adelabu,  yes Nigerians of the 60s and 70s call him "PENKELEMESI" , King Sunny Ade never overlooked the necessity to sing a praise song for him too
, Penkele o o o
Penkele
Adegoke mi o o
Penkele ,
But how many of us  have delved into the core of this funny nickname , yes "PENKELEMESI".
It is worth noting that up till this moment, Adegoke Adelabu is often mentioned in Yoruba and Nigerian history, almost nearly in parenthesis as the author of that expression: "penkelemesi", a Yorubanisation of the phrase, "peculiar mess" which Adelabu, who had an excessive gift of the garb, who revelled in his mastery of the English language, and who spoke English in a manner that fascinated and confounded his audience, had used on an occasion to describe the opposition in the Western House of Assembly. Not understanding what he meant, the non-literate section of his audience translated the phrase into vernacular as "penkelemesi".

N o ma tumo eyi ni kikun ni ojo iwaju.

oju ona sonanbole?

O da mi loju wipe Sinabole ni o fe so.
Ede yoruba alafetiya ni eyi lati inu oruko ile ise akun titi laro ti a n pe ni SOLEL BONEH ti won se ise ona ni ilu Ibadan ni Igba kan ri.


osomaalo?[/i]

Se Ujesa ni o re ni.
Itumo osomaalo ni wipe ma a loso (squat) duro gba owo mi. A ma n fi eyi bu awon ijesa, nitori iwa ahun tabi ife owo ni idi owo sise. Won k i i fi owo ba eniyan sere rara.Ra ki n ta ni oja ti won, won ko si ko iku ati aawo pelu onigbese won.
Akoko mu oro yii jade ninu itan Soun Ogunlola ti i ilu ogbomoso ti o lu arakunkunrin ijesa ti o ta aso fun iyawo re  kan  pa, lori wipe o wa sin owo o si so wipe dandan lohun ma duro gba owo ohun ki ohun to lo.

ITAN YI PO DIE , SUGBON EYI TI O NILO NINU WON NI MO TI SO FUN O YI.
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by Dapo4u(m): 1:31pm On May 28, 2007
Gbogbo yin eku ise opolo o. E duro naa eyin ara,ki lo fa ti a ki fi so ede yoruba si awon omo wa?Igbagbo wa ni wipe omo wa ko ni mo iwe ti a ba n so yoruba si,nje bee lo ri?
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by Dapo4u(m): 1:39pm On May 28, 2007
Baale Richlaw, eku ise opolo o,oluwa a je ki a ma ri yin ba o.(Wao i am impressed!,that was fantastic!)
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 1:41pm On May 28, 2007
Dapo4u:

Baale Richlaw, eku ise opolo o,oluwa a je ki a ma ri yin ba o.(Wao i am impressed!,that was fantastic!)
grin grin grin grin hen hen hen hen E se o , ki oluwa ma fun wa se o.
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by mishoo(m): 1:46pm On May 28, 2007
@richylaw, o ku ogbon, ku laakaye, abudi ni todo, opolo re o ni gbe ooo!!
@dapo4u, ti o ba wa ni ilu wa, o nilo lati so oyinbo fun awon omo re nitori yoruba ni won a kuku gbo ni ita.o si dara pupo ki won le mo ede mejeeji nso. Sugbon to ba se pe oke okun lowa, a dara ki o fi Yoruba ko omo re ooo. Eyi dara pupo ki won ma ba sonu ninu ede elede!!
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by Dapo4u(m): 1:58pm On May 28, 2007
Mishoo, otito ku ni oro re,sugbon mo gbe ilu eko niigba kan ri, gbogbo awon omo egbon mi,ko si eleyi ti o gbo yoruba ninu won, won kii so yoruba ni suuku won,ti won ba si ti dele,mama won ati egbon mi kii so yoruba si won nitori wipe ki won ma ba ya olodo gege bi egbon mi ti so.Eleyi loo fa ti mo fi bere ibere yi.
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 2:07pm On May 28, 2007
Mishoo ati Dapo,
Ko si iro ninu oro yin, eyi je ohun to o ba ni lokan je gidi gan ni. Ironu wipe omo yio ya olodo yi si buru pupo. Awon obi a ma so oyinbo si mi ni kekere, ni gba ti mo dagba die won bere si ni so yoruba simi ni nu ile (eyi ti ki i se ogidi rara- yoruba Eko grin) , won a si so geesi simi ni ta. Emi o ro wipe mo ya olodo ni ibi ti mo de ninu aye mi ni ojo oni. Awon obi ti won ko lati ma so ede ilu won si omo won yi ni olodo funra ra won nitori awon gan ko gbo ede yi.
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by mishoo(m): 2:19pm On May 28, 2007
otito ponbele. Ore mi kan wa ti abi si ilu oba - maryland, US. ibe ni won dagba si, bi o tile jepe kole so yoruba daradara, o ma ngbo daradara nitori mama won man fi yoruba bawon soro, baba won a si ma fi geesi bawon soro. nitori na kini a le se si oro to wa nile yi
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 2:40pm On May 28, 2007
Aye ti di aye olaju, wahala nla ni lati koju isoro yi. Nipapa julo ti yoruba ki ise ede akoko ni orile ede Naijiria. Awon eya Yoruba ti o wa ni amerika, Kuba ati Brasili, n se igbelaruge ede yii ju awa ti a n gbe ni ibi ti a ti pilese re gan lo. Amoran temi ni wipe ki awa ti a mo ewa re ki a ko omo wa,boya nipa be omo wa yio ko omo re, omo re yi o si ko omo-omo re ati beebee lo grin
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by Dapo4u(m): 2:43pm On May 28, 2007
Ohun ti emi ro ni wipe ani lati gbe ede ati asa wa laruge.wahala ti o wa ni ile yi  ni  wipe ani igbabgo wipe ede ati asa awon geesi dara ju ti walo.Ti eniyan ba sii ede geesi so,gbogbo wa ni a o ma fi eni  naa se eleya sugbon eni  ti ko ba le so ede abinibi re, igbagbo wa ni pe eni be lati je omo alakowe.E mi ro wipe eni ti ko ba le so ede abinibi re,ti a ba fi irufe eni naa se eleya,eyi yoo gbe ede ni aruge.
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 2:56pm On May 28, 2007
Dapo4u:

Ohun ti emi ro ni wipe ani lati gbe ede ati asa wa laruge.wahala ti o wa ni ile yi ni wipe ani igbabgo wipe ede ati asa awon geesi dara ju ti walo.Ti eniyan ba sii ede geesi so,gbogbo wa ni a o ma fi eni naa se eleya sugbon eni ti ko ba le so ede abinibi re, igbagbo wa ni pe eni be lati je omo alakowe.E mi ro wipe eni ti ko ba le so ede abinibi re,ti a ba fi irufe eni naa se eleya,eyi yoo gbe ede ni aruge.

Bawo ni eniyan perete se fe gbe ede ati asa laruge?Melo ni igbin ninu eranko oniwo. O dun so ju ka se lo. Eni melo ninu omo yoruba to mo ede ti o si dangajia ninu ogbufo ni oni asiko tabi emi lati ma se ohun ti o ko soke yii. Gbogbo oohun ti a n se lojojumo ni oni owo geesi ninu. So ojo na fun mi ti iwo ko so geesi ni odindi tabi ni asorege si inu ede yoruba. E ma je ki a tan ara wa. Oro yi soro die. Pepese bi o ba so ogidi yoruba ju won a ni babalawo ni o grin
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by hotchic1(f): 3:24pm On May 28, 2007
Eku le oooooooo
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by segoye2(m): 3:46pm On May 28, 2007
Babalawo oo, E seun pupopupo ooo, ani awon yeye ti e n pe ko ni pada lehin yin ooo,
oda na, Mo seba eyin yeye ti o wa ni ori threadi yi ooo, mo seba awon agbagba, mo seba awon ati fun jedo, eti everywhere je ororo, eje ki iba mi se oo, ki oro ti nu mi ti mo den so yi ma ba temi jee oo Ase.

Ehnnn, nnnn kan be. Bi mo se fi bi sile, ti mo ni kin jade lo we, ni mo ri sisi olomi loyan, ni se lon be mi, Ha!, what is left next to do, ni o jade ni enu mi, ani mi o le fi ara gbaa moo, iwo fun mi ni omi omu ti o ti kan mu, owan wa bami ni oni ojo mondi, youuu mustt be madd ni mo pariwo si lori!.

Ni deedee agogo meta osan oni ni mo ranti ohun ti osele si mi ni ilu Asaba ni nkan bi odun meta sehin bayi, o de ma n pa mi ni erin ni ni ojo jumo, Ha haha, ati wipe, omo orobo ti mo gbanigi ni gbayen, ha!, ni se lo sere si ni bariwo wipe fan me abeg, abeg abeg, erin omo yen a de ma pa mi ni sin ati wipe, eni ti mo je ni 400 hundiredi naira ti o ri mi ni azene avenuee, bi mo se ri, mo de mo pe a ma fe se yeye eni, ni mo ba sebe si ni sha paperrr ni ile, ni mo n se bi were kekere, nise ni were obinrin yin wo mi, o wa n mi orie, mo mo pe ani  bobo daadaa yi ti n were, ni se ni mo wo korodo kan bayi, mo da paper owo mi sile, ni mo sare, mo gbagi ginagina.  grin

si awe oborryunnmmii,
Se ki i sa n se pe, won ti ko e ni owun ti yio pa oo oo, ani se ki i se pe oti fi IDI e ti nu omi to tutu daadaa (ice blocku).  grin

Meanwhile, ko i ti si omo to sanra lori threadi yi abi

Babalawo, mo n gbadu opolo tire, ani original olo ogun ni yin, Sugbon se dan dan ni won ma na mi ni? se ko si remedy si oro yi ni? emi fe se awon nkan bi, kin gbe ofe lo si ibe, kin, se etutu mi, kin de pada wa sibi, e mi o ni owo flighti ticketi ooo, ebamise kee!

Aha!, eti ni ogun AIDS, oda ni yen ooo, ele di olowo lati ibe yen kee, ele taa fun owon omo jamajama ti o wa ni aroudi mi wonyi.
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 4:32pm On May 28, 2007
hot chic:

Eku le oooooooo

Arabinrin hot chic, gbogbo ile lo n ki o ku abo o. Ara o le bi? Ise nko loni? Emi si wa lenu ise ni temi o. Ma gbadun ara re

Segoye2
Ina ti jo de ori koko wayi o, ewe re ti n je bo die die, kekere bayi na loku.Bi o ti le je wipe ogun Eedi ni iwonba eyin ore mi ti e ti na si ibi ti ko ye ni a se fun o. Nipa ti ofe lati gbe o lo si aso rock , ona abayo ti wa fun o lai na owo rara. Ohun re lo si iwaju odo Thames ni ilu Oba ti o n gbe yi. ki o si ma wipe:


“Gbogbo orí àfín ewú

Abuké ló rerú òòsà mósò

Lààlààgbàjà ló ti isé è de

Adíá fún òrúnmìlà

Níjó ti ńlo rèmu omo olódùmarè sóbìnrin

Eri ńlá níí sunkún ibú

Agbara giri nii sunkun ògbun

Adíá fun Aadelówo nífè

Nwón ní ó ká a kío mó

Bi o ba ti so tan , iwo fo si inu odo Thames, IYALENU NLA NI YIO JE FUN O WIPE IWAJU ASO ROCK NI O O TI BA ARA RE NI ABUJA! grin
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by DisGuy: 4:39pm On May 28, 2007
shocked
ogbeni richylaw
ba wa lo shi shey awon amin yen?
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 4:44pm On May 28, 2007
Don't be shocked.
Awon ape itewe ti o fi aaye sile lati fi ami si ori oro ti wa fun tita. Bi beko , lo si inu "microsoft word" o le e se ni be
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by mishoo(m): 4:46pm On May 28, 2007
@segoye, ooto ni @richylaw pa oo, sugbon ile iwosan ni oo ti ba ara re ti awon irunmole ba ko e yo ninu eleyi na
richylaw:

Don't be shocked.
Awon ape itewe ti o fi aaye sile lati fi ami si ori oro ti wa fun tita. Bi beko , lo si inu "microsoft word" o le e se ni be
microsoft word ma gba asiko ti opo. So fun wa nipa awon ape itewe ti o wa fun tita.
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 4:53pm On May 28, 2007
mishoo:

@segoye, ooto ni @richylaw pa oo, sugbon ile iwosan ni oo ti ba ara re ti awon irunmole ba ko e yo ninu eleyi na microsoft word ma gba asiko ti opo. So fun wa nipa awon ape itewe ti o wa fun tita.


Ko lee gba asiko rara bi o ba je akowe ayarabiasa , sugbon ma beere ni owo ore mi ti o wa eyi ti mo n lo yi fun mi ibi ti o ti ra. O da mi loju wipe naijiria ni sa

Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by mishoo(m): 4:58pm On May 28, 2007
o see gan fun idahun re. A ye o kale oo!!

(1) (2) (3) ... (13) (14) (15) (16) (17) (18) (19) ... (167)

Pictures Of Nigeria Traditional Attire / Igbo Names & Their Meanings / Igbo Kwenu ! Kwenu Kwezo Nu ! Join Us If You Proud To Be An Igbo Guy/lady

(Go Up)

Sections: politics (1) business autos (1) jobs (1) career education (1) romance computers phones travel sports fashion health
religion celebs tv-movies music-radio literature webmasters programming techmarket

Links: (1) (2) (3) (4) (5) (6) (7) (8) (9) (10)

Nairaland - Copyright © 2005 - 2024 Oluwaseun Osewa. All rights reserved. See How To Advertise. 70
Disclaimer: Every Nairaland member is solely responsible for anything that he/she posts or uploads on Nairaland.