₦airaland Forum

Welcome, Guest: Join Nairaland / LOGIN! / Trending / Recent / New
Stats: 2,007,488 members, 4,254,997 topics. Date: Wednesday, 23 May 2018 at 05:59 AM

If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! - Culture (16) - Nairaland

Nairaland Forum / Nairaland / General / Culture / If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! (246055 Views)

If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here. Everybody Is Invited! / If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! / Do You Speak Yoruba? (1) (2) (3) (4)

(0) (1) (2) ... (13) (14) (15) (16) (17) (18) (19) ... (166) (Go Down)

Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by tiwantiwa: 5:10pm On May 28, 2007
Inu mi dun lati ri wipe ede yoruba yii ko ni baje
E jowo , iwe yoruba igba lode wo lo wa nita bayi ,

o seni laanu wipe awon akowe be Baba ishola, Akinwunmi , babalola ko si wopo mo
kini a le se lati fi fa okan awon omo yoruba nile loko si kiko ati ,momo ede yoruba lekun rere

ire o
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 5:14pm On May 28, 2007
E o ri bi e se le se e ni inu awon adiressi alantakun yin, yala ki e ra ape itewe (keyboard)yi , tabi ki e fi gogo fa (download) amori sise (installation drivers) ero ayara bi asa fun ape eyi ti e n lo lowolowo la ti le se ise yi. Eleyi yi fi awon alifabeti yoruba si agbari Ero ayara bi asa yin.  

http://www.konyin.com/
http://www.learnyoruba.com/keyboard.htm
http://www.thisdayonline.com/archive/2003/06/23/20030623art01.html

Se agbeyewo foto yi

Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 5:26pm On May 28, 2007
tiwantiwa:

Inu mi dun lati ri wipe ede yoruba yii ko ni baje
E jowo , iwe yoruba igba lode wo lo wa nita bayi ,

o seni laanu wipe awon akowe be Baba ishola, Akinwunmi , babalola ko si wopo mo
kini a le se lati fi fa okan awon omo yoruba nile loko si kiko ati ,momo ede yoruba lekun rere

ire oNje bi onkowe ba ti le wa, se onkawe ede yoruba si wopo bi. Gbese ni yio je fun onkowe ati ontewe o
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by israelite(m): 9:06pm On May 28, 2007
Eyin Elegbe mi,
mo ki gbogbo yin kabo pada.ejo motoro aforiji lowo eyin, eje ka ni suru toripe ose pataki.nigbati akin se majesi,
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by israelite(m): 9:10pm On May 28, 2007
eje kasoro lori awon iwe yoruba eyi ti awon oloyinbo peni NOVEL eyan melo ninu yin loti ka iwe ALAGBA JERIMAYA
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by DisGuy: 2:10am On May 29, 2007
jerimaya wo ni yen, shey eyi to wa ninu bibeli abi ako nofeli ni?

eyin ogbeni yoruba ibele yin fo me lori ejeka so modern yoruba

eshe je je o e ma ja o

wani omo ti ko ba ko ewa ni ile, ita ni ati ko tabi o ma di odaron tongue
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by omoge(f): 2:12am On May 29, 2007
Dis guy, ki lon she ni be bayi

ki lo shele? ta lo wa gbe word doc ati komputer keyboard wa si be yi? ni to ri kini?
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by DisGuy: 2:13am On May 29, 2007
mon tojo lol

abi kin di enumi mu ni? moni ominira speech abi?
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by omogenaija(f): 2:13am On May 29, 2007
ewo le se ?
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by omoge(f): 2:14am On May 29, 2007
e pe mi lerin sha grin
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by DisGuy: 2:14am On May 29, 2007
ako wa ni ko si mushh men, mo kon gentle si bi biyini
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by omoge(f): 2:16am On May 29, 2007
she tani le kilo fu?
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by DisGuy: 2:18am On May 29, 2007
mi ko gbo ye o. a mi ko get e
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by omoge(f): 2:20am On May 29, 2007
ta lo mo orin yi?

Mary lo mo agutan funfun kekere kan
To ke igbe alafiya
Wura fun Mary
Wura fun agutan
Wura fun oluko wa to ko wa le ko

Nibitibi ti mary lo agutan tele
To ke igbe alafiya
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by ayefele200(m): 5:26am On May 29, 2007
ta lo wa ni ile ooooooooooooo
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 10:17am On May 29, 2007
israelite:

eje kasoro lori awon iwe yoruba eyi ti awon oloyinbo peni NOVEL eyan melo ninu yin loti ka iwe ALAGBA JERIMAYA

Bi o tile je wipe mo se alaye siwaju si lori oriki re ti mo bere, o  o ti da mi lohun ibeere ti mo beere lowo re o, sugbon sa nipa ti Alagba Jeremiah bi mo ba niran daadaa o dabi e ni wipe Oyetunde Awoyele ni o ko iwe yi gege bii iwe fun ere ori itage, Alagba Jerimaya, da le lori iwa awon wooli eke ti won n ti inu ese kan bo si omiran. Arakunrin na a ma fi afose soro ninu soosi , o weju lati riran, o si tun fun arabinrin ti ki se iyawo re loyun ni abe aabo, oju window lo gba fo jade ninu soosi ni ojo ti awo ya grin
Mo si n duro de idahun ibeere temi sa

omoge:

Dis guy, ki lon she ni be bayi

ki lo shele? ta lo wa gbe word doc ati komputer keyboard wa si be yi? ni to ri kini?

N je iwo ka awon iwe ti awon olusoro bii marun sehin ti ko ki o to ri "word doc ati komputer keyboard"gege bi o se ko o? Won n se iwadii boya o wa ati atoka ibi ti won ti le ri ape itewe (keyboard) ti a le lo la ti te oro yoruba ti o ni ami 'do' 're' 'mi' lori. Aunty wa e ma fi suuru ka odu  ti owa loju opon ki e to ma beere ibeere o.
omoge:

ta lo mo orin yi?

Mary lo mo agutan funfun kekere kan
To ke igbe alafiya
Wura fun Mary
Wura fun agutan
Wura fun oluko wa to ko wa le ko

Nibitibi ti mary lo agutan tele
To ke igbe alafiya


mo feran orin yi ni kekere, n je o mo wipe o tun lee ko bayi

Mary lo mo agutan funfun kekere kan
To n ke igbe alafia
Patewo fun Mary
Patewo fun agutan
Patewo fun oluko wa to ko wa le ko

Nibikibi ti mary lo l'agutan n tele e
To n ke igbe alafia.
Good to see someone like you aggravating a youthful nostalgic scene in my mneme . cheers

Dis Guy,
Ma je ki yoruba yi fo e lori o, iyi pataki ni fun o nitori wipe o tile ni aya lati da si oro lori abala yi, ogunlogo ni omo bibi ile yoruba ti o wa ni Nairaland ti o ti ri akole yi sugbon nitori wipe ko si bi won yio se ko ede yi sile , won ko le kopa rara. Alagba Jeremiah ti Israelite beere kii se ti inu bibeli o, bi o ba ka idahun mi si Israelite iwo yio mo nipa iwe yi daadaa , a ko gegebi iwe itan yoruba fun ere ori itage ni odun 1983.

Si gbogbo akopa lori abala yii  E MA A GBADUN .ire
IRE KAN KA
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by Dapo4u(m): 11:24am On May 29, 2007
Alagba Richlaw, ewo ni tire gan? gbogbo ejo jije ? o fe se wipe ko si nkankan ti o ko lee so nipa itan yoruba.O ku ise opolo o.Duro naa,ki lo fa ti a ki fi pe eniyan ni ogbeni ni ile yoruba? Ore mi kan ni mo pe ni ogbeni,lo ba fara ya,ki ini idi re gann ni pato?
Ma binu wipe mi o ki ara ile o.
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by omoge(f): 11:43am On May 29, 2007
Dapo4u, daku, eba mi beere undecided grin. omo guy yin Jerry Springer abi Jerrymania wa fe fi yoruba fo wa lori cheesy

thanks for redoing it but u know awa omo kekere loves doing it our own ways, so we changed the song be mo ko (the way i wrote it)
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 12:11pm On May 29, 2007
omoge:

Dapo4u, daku, eba mi beere undecided grin. omo guy yin Jerry Springer abi Jerrymania wa fe fi yoruba fo wa lori cheesy

thanks for redoing it but u know awa omo kekere loves doing it our own ways, so we changed the song be mo ko (the way i wrote it)

he he he, thanks for thanking me , I must say with courtesy that you are welcome.
Atunko orin re yen kii se lati fihan wipe mo gbo yoruba o , bi o ba ka ipari oro mi si o nipa orin yi , mo fi ye o ni be wipe o wumi lori lati ri orin yi lori afefe ni o. Se o mo wipe bi o ba se wu ni la n se imole eni. Mo kan ko o si lati fi han o bi emi gegebi enikan se feran lati ma a ko ati wipe ki i se lati so fun o wipe ki o yi bi o se ko tire pada. By the way if you refer to yourself as kekere then I will see myself as a milking child. I'm still young meen!


Dapo4u:

Alagba Richlaw, ewo ni tire gan? gbogbo ejo jije ? o fe se wipe ko si nkankan ti o ko lee so nipa itan yoruba.O ku ise opolo o.Duro naa,ki lo fa ti a ki fi pe eniyan ni ogbeni ni ile yoruba? Ore mi kan ni mo pe ni ogbeni,lo ba fara ya,ki ini idi re gann ni pato?
Ma binu wipe mi o ki ara ile o.

O dami loju wipe o mo wipe IMO NI AGBARA PUPO knowledge is power. Ki i se itan yoruba nikan ni emi n se ofintoto si o, ohun gbogbo ti o ba le se anfani fun mi ni orile aye ni o, koda ninu ede ati igbe aye awon eya  miran as I am presently a French student at Alliance Francaise right here in the UK/sup]. Ko si eko kankan to mo ko tabi ti mo fi n sise loni ti o si ba ede yoruba lo. Ayojuran lo fun mi ni ominira ede. Wa asiko fun ara re lorekore lati wa agbara imo kun agbara o .
[sup]empower yourself with knowledgeable things
.
Nipa ti oro "ogbeni" ti o bere. Emi ko ni le se alaye ni kikun fun o ni ori abala oro yi, nitori afojudi si awon ti o ni agbara iwase lowo. Sugbon lerefe , mo fe ki o mo wipe apejuwe "ogbeni" je inagije ti awon elegbe awo /tabi 'ogboni' ( IBA EYIN AGBA O) ma n lo lati fi iyato oye han laarin ara won. Ki i se ogbufo fun Mr. rara gegebi opo eniyan ti se ro. Sugbon aye ti di olaju, o ti di o n a n pe ti a si gba towo tese lawujo.Ore re mo ipilese inagije yi lo mu ki o fara ya o.
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by Dapo4u(m): 12:15pm On May 29, 2007
Omidan Omoge,,emi ko ma ti le mo orin yen.Sugbon sa a ko fe amulumola ni ibi o.Ti a be fe so ede geesi,e je ki a so geesi,ti a be fe so yoruba,e je ki a so yoruba,ki a ma da iru po mo ila, hun hun o,o ku die ka to grin grin.
Dakun jehun soke!
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 12:21pm On May 29, 2007
Dapo , bi o ba fe alaye kikun ju eyi ti mo se yi koleta si mi.
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by Dapo4u(m): 12:28pm On May 29, 2007
Mo kuku gbe idi fun e grin grin; ma ma da mi lohun o ja re, ko si asa danu ninu gbogbo oro re,sugbon bukata taye yato si ti kehinde.A lo suuku laro,suuku lagba de ibi ise, o si di ale patapata ki ato wole.Gbogbo ebi ti a fi sile si ilu wa lohun,a gbodo se to fun won.Gbogbo eleyi ni ko fun ma mi laye lati wa imo ,paapa julo imo ayara bi asa tabi imo ede.
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by israelite(m): 10:35pm On May 29, 2007
Richlaw,
o sha fe mo oriki idile me,
oda naa, eyi ni oriki idile wa ni oke imesi, ADEMOLA OMO AJE OMO ORUJO OMO AFI OJOGBOGBO DARA OMO TO DE ODO TO PONMI WALE ,MO DELE TAPA WON NI KIN WO E NI ORITA BALE,MO DE ORITA BALE WON KIN WO NI AGBOLE IYALODE MODE ODE IYALODE,IYALODE NI ONJEUN LOWO NI YARA MI SE RI BI OMO NAA SE DARA TO.MO GBA FUN E TOO.KARE OMO AJE, molerope mo ti tefe ninu mi si e nibayi, grin wink
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 11:19pm On May 29, 2007
israelite:

Richlaw,
o sha fe mo oriki idile me,
oda naa, eyi ni oriki idile wa ni oke imesi, ADEMOLA OMO AJE OMO ORUJO OMO AFI OJOGBOGBO DARA OMO TO DE ODO TO PONMI WALE ,MO DELE TAPA WON NI KIN WO E NI ORITA BALE,MO DE ORITA BALE WON KIN WO NI AGBOLE IYALODE MODE ODE IYALODE,IYALODE NI ONJEUN LOWO NI YARA MI SE RI BI OMO NAA SE DARA TO.MO GBA FUN E TOO.KARE OMO AJE, molerope mo ti tefe ninu mi si e nibayi, grin wink

ehen, ki wa lode ti o n tadi sehin tele, bi o tile je wipe oriki idile ni o ki fun mi , nigbaa ti o je wipe ti orile ni mo beere fun , eyi na te mi lorun . O ti te ife inu mi o. Mo si lero wipe emi na dahun ibeere  re nipa alagba Jeremiah daadaa?
Ka sun layo. O digba kan na.
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by lalaboi(m): 1:10am On May 30, 2007
bikO! mi o mo pe eleyi wa nibi yi! ki lo apin?
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by nana(f): 1:14am On May 30, 2007
lala o,lala
bawo ni, kilon she online ni time yi?
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by lalaboi(m): 1:24am On May 30, 2007
ko si notin o! awon demdem nko?
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by nana(f): 1:27am On May 30, 2007
O wa o, iwo na nko o?
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by ayefele200(m): 1:30am On May 30, 2007
mo wa pa, omo to dun
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by nana(f): 1:36am On May 30, 2007
hope u aint talking to me dude?
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by ayefele200(m): 1:38am On May 30, 2007
yes u, u u u u u u u , nana nana nanananannananananan
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by nana(f): 1:40am On May 30, 2007
who're u anyways,
and wot business have i got wiv u to deserve such a rubbish comment

(0) (1) (2) ... (13) (14) (15) (16) (17) (18) (19) ... (166)

Pictures Of African Traditional Clothing! / Post Pictures Of Traditional Weddings. / Nairaland Official Igbo, Hausa and Yoruba Dictionary

(Go Up)

Sections: politics (1) business autos (1) jobs (1) career education (1) romance computers phones travel sports fashion health
religion celebs tv-movies music-radio literature webmasters programming techmarket

Links: (0) (1) (2) (3) (4) (5) (6) (7) (8) (9)

Nairaland - Copyright © 2005 - 2018 Oluwaseun Osewa. All rights reserved. See How To Advertise. 118
Disclaimer: Every Nairaland member is solely responsible for anything that he/she posts or uploads on Nairaland.