Welcome, Guest: Register On Nairaland / LOGIN! / Trending / Recent / New
Stats: 3,162,432 members, 7,850,522 topics. Date: Wednesday, 05 June 2024 at 12:15 AM

Richylaw's Posts

Nairaland Forum / Richylaw's Profile / Richylaw's Posts

(1) (2) (3) (4) (5) (6) (7) (8) (9) (10) (11) (of 17 pages)

Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 11:11am On Jul 30, 2007
E pele o gbogbo ara ile, se mo ba gbogbo yin lalaafia ara. Se opin ose yin gbinmirin? Mo ri owo gbogbo omo adarihurun lori okun yi o , paapaa julo awon orin alarinrin atijo ti Wunmi tun gbe si ori afefe pada yi, koda mo ju Akon, Mary J Bleige ati awon akegbere nu lati sare jo si orin yi ni! gege bi Mishoo ti so, omo buruku ni ojo tire.
A mo sa, o da mi loju wipe o ye ki a ma pe gbon ni , a kii pe go. Ka sise die ka si tun se ere die ni idagbandagba laye fi n gun rege. Sugbon bi gbogbo omo ara aye ti n s'apa wipe ki gbogbo wa gbon, ka le maa fi laakaye se ohun gbogbo, ika ti ko dogba ko je! O mu mi ranti owe iyekan mi kan; a ni 'Edumare oke mo je ni to go o gbon, kale mo rohun tuje bi  isu'. Ta lo n dagba mo labe laye, awaye ma gbo aja o si, arigbere ma kan agbo kan o wopo. Ki oluwa ma se wa l'akiriboto. Ohun ti 'ako' n fe n be labe 'abo', ohun ti 'abo' si n fe n be labe 'ako', sugbon yoruba mo oruko ti awon nkan yi je ki ato ma a pe ni 'abe' .
Omo yoruba e je ki a bowo fun iwase,
e je ki awari fun isese
Ohun gbogbo loni iwon tunwonsi, bi 'atilawi' ba ti e n hun ni labe, o ni bi a se n se ti ara fi n tu ni, Wunmi emi kii se onija re rara, onimoran lasanlasan ni mo je fun o. Aso ibora ti mo si ni, ni mo ma n fun o lo lorekoore ti o ba ye ki n fun o. Bi o tile je wipe okun yoruba yii gba ole (thief) osi gba ole(lazy), eyi ko tumo si wipe ki a si iwa hu. Looto awon aworan re ti o n fi sowo jade , a ma derin pani ni igba miran , sibe ko ba oju mu rara fun okun yi , o lee fi sowo si ori okun 'romance' tabi ki o ti e si okun kan ti o le pe ni 'Bleep Pics' . O da mi loju wipe oja re yi o ta gidi gan nibe. Ko si eni ti o ni ki o ma ko ohun ti o ba wu o sile lori okun yi, iwofa sa lenu, ohun ti o ba wu elenu ni fenu e so, eniti o ba si wu ni yio fun o lesi. Sugbon iru awon aworan  wonwonyi ko ba oju mu fun ori okun yoruba. Ti o ba ti e wo akole okun yi , ohun ti o wi ni wipe, 'If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here!' ko so wipe ,' if you have porn pictures send it here'. Roo  re o, mo fe ki o mo wipe emi kii se mojesin ninu gbogbo ohun ti o n fi ranse yi, bi oro ti e na ni, "kini fi n seni".
O lee ro wipe enikeni ko le fi o se nkan lori ile yi, beeni
Ko da opolo re le yan fandafanda loju elegusi , beeni
Sebi won o mo mi , won o si ri oju mi, beeni .
Sugbon ranti o, ori okere koko lawo, baa wi fomo eni a gbo, baa wi fomo eni agba .
Ogodo ti o ba fini sesin, gongo ori imu ni tii mu ni, igba ti o su yo sita , enikan kii mo, irora ti yo si fun ni pelu enikan kii mo o.
Search your conscience
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 3:02pm On Jul 27, 2007
Awon oruko kan wa to ni ami ju bi a se fi owo yepere mu lo. Arakunrin Jagunlabi, mo ni lati jewo fun o wipe mo gbadun oruko inagije  re yi kii i se kekere. Oruko akikanju ni aye atijo ni o je, bi o tile je wipe awa ti ode oni ti so di yeye. JAGUNLABI.
koda ti o ba fe mo, itan kekere kan tii mo n ko lowo nisisiyi fun ere sinima alarinrin kan ti mo n gbimo lati se laipe da lori Jagunlabi ( jagunjagun ni omo ti abi). Mo lero wipe jagunlabi ni o nitooto. grin ekun!

Preview:
Muni muni de
Ara Ibadan de
Ekun  lanu gbe ni mi!
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 3:45pm On Jul 26, 2007
Mishoo
A dupe o jare , Odu kii se a i mo fun oloko o, ati igbo irunmole, igbo odaju, igbo oju olomo o to, Igbo olomo n gbesan, igbo elegbeje, igbo eledumare, gbogbo re arese pa ni o. Ki oluwa ma to ipa ese wa ki o ma je ki a sin rin laye o.

Nana
cOME BACK HOME YOU ARE NOT YET LOST . egun is 'thorn' LOL
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 3:07pm On Jul 26, 2007
Hello grin !
ati eni ti n gbe inu igbo ati eni ti won sese fe mu wo igbo lo, imoran temi ni wipe ki e wo bata to ba ni itele to nipon nitori egun o. O da mi loju wipe eyin mejeeji mo wipe egun tun yato si egun o. Mo gbo wipe ise ni awon egun inu igbo irunmole lo se photocopy ara won ni sa! grin
Mishoo and Nana, how una dey?
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 12:31pm On Jul 25, 2007
champredd:

ibo ni mo tile ri keyboard(mi omo oyinbo e) ti o le te leta ti oni awon aami lori.

A ti so oro nipa eleyi sehin ni oju ewe ketadinlogun okun oro yi , sugbon fun anfani eni ti o ba ni ife si, e o ri bi e se le se e ni inu awon adiressi alantakun yin, yala ki e ra ape itewe (keyboard) yi , tabi ki e fi gogo fa (download) amori sise (installation drivers) ero ayara bi asa fun ape eyi ti e n lo lowolowo la ti le se ise yi. Eleyi yi fi awon alifabeti yoruba si agbari Ero ayara bi asa yin.

http://www.konyin.com/
http://www.learnyoruba.com/keyboard.htm
http://www.thisdayonline.com/archive/2003/06/23/20030623art01.html

Se agbeyewo foto yi

1 Like

Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 11:20am On Jul 25, 2007
Ija fun omoniyan!
Gbogbo wa la fe ohun to dara, sugbon ta lo fe ki won fi ori ohun fo agbon. Naijiria je orile ede kan pato ti eleyi si ku die kaato fun, bi o tile je wipe a n
tiraka nipa ifokanbale ti o n yo jade lati owo ijoba tiwantiwa, ti o wa fun wa, lati owo wa, si awa funrara wa. Ki Oluwa ki o ma fun wa lokun , ki o si gbe ori ati owo wa soke ki a le goke sori afara bi awon ilu oke okun.
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 4:56pm On Jul 24, 2007
o da nigbana hello! grin
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 2:09pm On Jul 24, 2007
e gbona, o dabi eni wipe afefe 'hello! grin' n fe kiri nisisiyi o, abi ibo tun ni desorlah ti tun  gbe ti e wa.

Mishoo, owo tun ti te ole kan ni o,sugbon irohin yi sese n fese mule ni , e je ki a woye die si, ki o fi suru de ori afefe daadaa ki a to da sile o
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 9:55am On Jul 24, 2007
Segoye , a bo ri nkan ! bi Oluwa yio se maa tu asiri gbogbo won niyen. Apani lekun asiwaju gbogbo.
Mo ki gbogbo ile o
E ku oro ilu wa o.
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 5:01pm On Jul 23, 2007
nana:

Hello! grin
grin grin grin
I can't but laugh o.
O dabi eni wipe 'hello!' lo tun fe gba ode kan bayi. Arabinrin Nana, ewo le ri gbo loni o? 'hello!' grin
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 4:44pm On Jul 23, 2007
omoge:

grin grin grin grin grin grin @ richylaw. it's kind of funny they all come back with funny names too  grin

the way it started too was hilarious ''Hello  !''


Tot I was d only one thinking that way.

Asin de oorun de!
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 3:02pm On Jul 23, 2007
satan:

Hello ! grin
This guy makes me laugh anytime he comes up. Of course I know him to have multiple pseudonyms on nairaland.He gets banned and comes with another one. Sugbon ka ti e pa ti oruko ti si egbe kan , bi o tun se rora yo wo ile ti o si so wipe 'hello'yi ni o da erin pa mi. Oro re ri bi oro awon ti won n soro ore won kan lehin la i mo wipe o wa lehin awon ,ni gba ti ara re ko gba mo , lo ba so wipe 'hello', jinijini bo awon meji ti o n soro re yi , laibesubegba atorin ni o wa ni ibi ti o da, ana sare ni o si na won. Sugbon lori ti arakunrin satan yi, idakeji ni yio je. Bi o ba fara mo ile o gbadun ara re, a i je be!
Oloye segoye , e ku boju ojo se ri o.
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 2:30pm On Jul 23, 2007
Mishoo, o seun o gbogbo wa lawa lalaafia ara.
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 12:28pm On Jul 23, 2007
E pele o gbogbo mutumuwa
Mo ki gbogbo ologbon ori ti n mu togbon se
mo ki gbogbo onimo ti n lo t'imo se iwa hu
mo ki gbogbo olopolo pipe ti n wa baye a se da
mo ki aroni pele afinju oge obinrin ti n fi bebe d’ako lorun lojogbogbo
mo ki oniwatutu okunrin, arowo so ileke si idi omo elomiran
Iba f’awon ara iwaju ti n lo ti o ni fese ko
Iba f’awon iko ta jo n gbimo lati jo di onifuja lawujo
Iba fawonsin ,kekere ile ti n bo wa dagba lola
Iba f’won ti ya mopo to dorikodo ti o d’omi nu
Ikorita meta ona ara aruniloju peregede, Ko ni ru wa loju o
Imo ede Yoruba o ni tuka o
Awujo wa o ni poruuru o
Ka maa ri baa ti se
Ka ma rona gbegba
Ka rowo sola o
Ka riyi se gbajumo lawujo
Ola eyin agba ti n be lode ile yi
K’Olu o je ke e pe laye
Kee mu erigi jobi
Ka le ma r’ohun de ba nile
Ka le maa re ni seba fun nigba gbogbo
Aroye nise ibaka, Igbe kike nise eye
Mo de l’ose yi lakotun o
Mo tun fe ma jise ori ran mi lo
Pakoyi loni ile, oba loni sese efun
Oluwaseun Osewa, O jire abo o jiire?
Bi emo ba ti jire lopo ile
T’okete si jiire nii sa re
Won a ni bi gbogbo ohun to ku o tile ji , abuse ti bu se
Seun o, o ni kose awon agba o.
Gbogbo ara aba Yoruba patapata , e n le be n o , Oloye segoye, Iyalode Ika, Nite Angel, Mishoo, gbogbo omo kaaro ojiire ti n be lode ile yi mo ki gbogbo yin, eledua o ni je ki n seyin o. Mo si tun ki ara mi na pelu, sebi alara ni gbaraaga.
Nite angel, ile l’apoti n joko si de idi o, mi o yise, bi e ba ti de wa l’alejo, o didan ki ase alejo o un ni o. Ki eledua je ki awa odo ode oni ka pe laye ka si gbe ori eepe se oun rere o
ASE WA
IRE.
Computers / Re: She Spilled Hot Coffee On My Laptop: Now What? by richylaw(m): 12:30am On Jul 21, 2007
Shall we then say this is another antique to drop at the nearest museum. Why not try the Russian style
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 10:50pm On Jul 20, 2007
Hi Folks, thanks for the compliments, e seun gan ni, opolo gbogbo wa ko ni jo ba o. Ogbon ti olodumare si fun gbogbgo wa ko ni di obu o.
Wunmi, I wish you a tight weekend as well
Segoye, what a great gesture! I am actually looking forward to a few days break to Florida around November but I may still look into your offer. Fi nomba ero ibanisoro re sowo simi ninu adiresi ori alantakun mi. Je ki a soro, we may even be able to see before you go to Nigeria ( I was around in London all through last weekend).
Desorlah, e ku faaji alaale friday o, n je oni ko ni ti Lagbaja grin common dig it
Mishoo, se ara n le daadaa o, bawo lola se ma ri o, abi ko si ode kankan lati lo
Ferlie, you are really welcome
cheers all.
Romance / Re: If Your Lover Kicks the Bucket in Your House? by richylaw(m): 3:01pm On Jul 20, 2007
Walahi dead man will wake dead woman. Professor Peller will have to come from his grave to perform the magic . She must wake by force. Ah ah which kain 'yaponyanrin' scene be that.
Nairaland / General / Re: Server Maintenance This Month by richylaw(m): 1:51pm On Jul 20, 2007
TayoD:

richylaw,
This is just between me and you o. No let anybody hear this. I hear it is more like the "M-word" and not the "B-word"! 
Really? thanks for the handy info, Seun go get visitor soon grin LOL
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 11:56am On Jul 20, 2007
Yoruba bo won ni "Obinrin sekete ye oko re ni ojo ajo ati lojo ere, eyi firigbon ye oko lojo ija to le fe doju ti oko" O dabi eni wipe otito ni eyi sugbon mo tun ri eleyi mo si fe fi lo gbogbo eyin ti o loye nile yi, gbogbo e ni ti n fi ogbon se ori e ba mi da si , oro bi ase n so awon lepa di orobo ni orile ede wa . Nje eleyi mu ogbon dani? E ba mi kalo http://news.bbc.co.uk/2/hi/africa/6904640.stm
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 11:50am On Jul 20, 2007
Desorlah Friday indeed, but sooner it will be the snoobish monday grin Eku ariya o.

Ferlie ati arakunrin Wunmi Inu mi dun lati ri owo awon agba ninu agbara ipede yin o, sugbon e je ki a tii ibi saakun wo oro yi. Gegebi mo se ma n so , oro lo n yo obi lapo(pocket), o n na lo si n yo ida ni apo(scabbard)owe yoruba. Remember the existence of your soul has links to your personality and is never disconnected from your pseudonyms on nairaland.
Niwon igba ti mo mo wipe omo yoruba tooto ni yin mo ni lati gba yin ni imoran wipe ki e fi owo omo yin bonu aso  die o. O da mi loju wipe e mo ohun ti o n je 'ARO'( clinger in the simplest translation) . Olubobotiribo baba ebo enu ma pa mi, enu mo ko ba mi. Ko di igba ti a ba la enu soro ki a to so wipe a so oro o. Ohun ti o ro ninu, ti o si ko sile na je oro enu re, ori ahon inu okan re ni o si gba jade , o di dandan ki ARO o ro mo o, bi ase ba si ti gun, uhn.
Eje ki a ma fi agbara inu ijinle ipede wa  'wure , ki a si jina si epe. Se eyin ti gbagbe ni  wipe "aja ti o bu ni je kii gbo, aparo ti o je oko oloko ko ni dun"owe yoruba. Bi e tile mo ara yin loju aye tabi boya enikan gba iyawo elomiran , o ye ki e mo wipe "eso pele lagbalagba  fi n pa efon ti o ba ba le ni lori abe!"owe yoruba.
Looto "otokunlu kii sin'mole to ba ro, ebora to le koko ni ya won lara"owe yoruba sugbon yio dara ki e tun ro ni idakeji wipe "eni to ba weju leru n ba o" owe yoruba
E rora o , erora o, e ranti wipe ere a maa di otito o. Bi o tile je wipe ere ni gbogbo wa n se lori alantakun ,inu wa ati irori wa yato o. A o me eni to fe ni,
omo araye o ni pa wa da si aida o
aye o ni ti  digi wa bo omi o
oniyangi o ni da wa lepo nu o
alabata o ni de idi ala wa o
A mo sa "owo ara eni ni a fin n tun iwa eni se o"owe yoruba "enu eni ni a si n fi ko me je"owe yoruba e dekun epe , iwure lo to . E ma je ki apara ati yeye di otito mo yin lowo, e mo je ki aibikita ede ni nairaland so igbe aye di eti ni ojo ola.
Mo n so gbogbo eleyi gegebi imoran fun "eni ti ko l'ogun arindo to n je aayan"owe yoruba
Fun eniti ko l'okigbe ti n ba won rode olobe ati ada
Fun eniti ko ni ayeta ti n ba won roko onibon agbede
Apete ati gbetugbetu ko si e wa n leri si ra yin.
"Awodi gbomo agbebo, agbebo n mura ija, se iran baba re pa asa ri ni, a mo sa asa ohun gan kan n tiraka ni akikanju ode ti ke bon sile  fun"owe yoruba
Erora o, erora o, "abati alapa arelumo bi owu, ako ta giri ejo, agba to rejo ti o sa ara iku lo n ya."owe yoruba

"Iyoku ito , o di inu bante."owe yoruba
GRACE TO THE SUPREME BEING 'ELEDUA' , THE CREATOR AND CURATOR OF MY SOUL (ORI INU), SHALL I WALK NEVER TO STUMBLE INTO THY WRATH  iba,iba,iba
IRE
Nairaland / General / Re: Server Maintenance This Month by richylaw(m): 10:17am On Jul 20, 2007
Seun, look to be more serious we want the best for/on nairaland, but 24hours during a weekend , that is cry please don't do that, how do you want people like me who are "single, lonely but may not be searching" who hides under work consolation during the week and spices their weekend with nairaland to cope? If there is a technological magic like RAID or Hard drive mirror,then kindly adopt that and keep this blood flowing without much interruption.
Forum Games / Re: Look Up Your Birthday And See What You Are by richylaw(m): 4:09pm On Jul 19, 2007
February 06 - 14 ~ Dove
Still trying to fault this , the more I try , the more it becomes true grin
Art, Graphics & Video / Re: How About These Wonderful Books On Animation by richylaw(m): 3:57pm On Jul 19, 2007
I'm not sure now if I still have this stuffs with me , but pretty certain that a pdf copy of Illusion of life is available. If you need it holla me.
Nairaland / General / Re: Server Maintenance This Month by richylaw(m): 2:49pm On Jul 19, 2007
Just a direct meaning of selfless service, good works Seun keep it moving.
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 2:44pm On Jul 19, 2007
Gbogbo re ti wa n dun bo bayi, emi o wa joko woran die bayi. Abule Yoruba ti n kun si, asodun oro si ti n posi loniruru, lelekajeka  pelu.
Omo Oodua e gbera nile e dide. Okete afiru na le bo ba ti di oloro ase. Ise ya e je ki a mu ise se, owuro lojo.
Enikan beere ibeere yi lowo mi , n ko si fe ki o je oro emi nikan e ba mi da si o.
'' Nje Balogun Owu, Baba Alaremu Obasanjo yio fun Aare orile ede Naijiria arakunrin Yaradua ni aaye lati se ijoba ni ona ti o to bi? Eda si oro yi
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 4:08pm On Jul 18, 2007
mo kuku wa lalaafia ara.
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 3:13pm On Jul 18, 2007
MISHOO ARA IGBO IRUNMOLE, AWON ARA OHUN NKO, AWON IWIN , EBORA , EGBERE ATI ORO SE E NTOJU ARA YIN. grin
CHEERS PAL
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 11:47am On Jul 18, 2007
mo wa daadaa o Desorlah, Gbogbo ara aba to ku e ku ikale o.
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 9:46am On Jul 17, 2007
Iyalaje mo n ri owo re o, gegebi Iyalode Ikamefa ti se so wipe oke Sapati ni ko je ka ri ti aro, tihin ni ko je ka ri tohun o. Ki oluwa ki o ma so eni ni. Awon oro ti o nii se pelu emi eniyan, iyannije ati arankan kan ni awon ara ilu kan gbewa sii iwaju mi , o si gba pelekutu lati petu sii ninu. Ki oluwa ki o ma fun wa loye ati ogbon lati ba omo araye lo po o.
Ase.
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 4:33pm On Jul 16, 2007
Mo ki gbogbo wa ku faaji ni gbagede oro o
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 11:05am On Jul 14, 2007
kanakan ti na omo re o di esin , ija n bo ija ko i de.
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 1:16am On Jul 13, 2007
When you are in a group and others seems to go on well, yet you can't fit in, CHECK YOURSELF
When you take an action but every other people around you reacts negatively , CHECK YOUR BRAIN
When your conscience asks you question about the societal moral acceptance of yourself , CHECK YOUR STEPS
it is evident that someone here is wallowing in agony of sexual starvation, but I feel this may not be the right avenue for you to solve your problem, to be candid you don't need to stop  being anti-moral, all I will appreciate in you is to take a quiet moment to observe yourself, I'm sure you know that you are simply being depressed by "arousal lunatism" and I strongly beleive this is the right time for you to consult your parents if only they are not the cause of all this your short comings.
Why must someone always believe that he /she should destroy any good thing. Youth of today , leader of tommorow you call yourself right? I can bet it with you , the course of fate cannot allow one like you to move on to destroy the already mutilated body of Nigeria again.
Note that all your activities are noted and the multiple personality you are managing on nairaland will not help your situation when eventually you are axed, I guess you don't use an ip address , right?.
You may say nairaland is no man's land , yet it came on and runs with someone's sweat. If only he was stupid and daft like you he would have wasted his thoughts and brain doing some other things.
To be honest this is a share exhibition of how you were brought up.
Go ahead if only you can not differentiate a cultural thread from Romance

(1) (2) (3) (4) (5) (6) (7) (8) (9) (10) (11) (of 17 pages)

(Go Up)

Sections: politics (1) business autos (1) jobs (1) career education (1) romance computers phones travel sports fashion health
religion celebs tv-movies music-radio literature webmasters programming techmarket

Links: (1) (2) (3) (4) (5) (6) (7) (8) (9) (10)

Nairaland - Copyright © 2005 - 2024 Oluwaseun Osewa. All rights reserved. See How To Advertise. 65
Disclaimer: Every Nairaland member is solely responsible for anything that he/she posts or uploads on Nairaland.