Welcome, Guest: Register On Nairaland / LOGIN! / Trending / Recent / New
Stats: 3,164,235 members, 7,856,938 topics. Date: Tuesday, 11 June 2024 at 09:23 AM

Richylaw's Posts

Nairaland Forum / Richylaw's Profile / Richylaw's Posts

(1) (2) (3) (4) (5) (6) (7) (8) (9) (10) (of 17 pages)

Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 6:27pm On Feb 21, 2008
E gba mi o, Baale ti ni bi omo to le l'aadota e tun wa n soro ibeta, n je agbara fileeki ka bayi.

Mukina2 je okan ninu awon Olori, sugbon awon marun toku ko yoju si awon ara ilu. Se eyin na kuku mo wipe iyawo ti oko feran loko lo n gbe.
Ko da Mukina2 gan ko fi igba kan gbe aafin, iya n yo wa lo n se, Nitorina , Ile ni ile re o fileeki,Iwo nikan ni o wa pelu mi laafin bayi , laisi ani-ani iwo na ni olori ti yio ma ba mi se wole-wode o.
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 11:36am On Feb 21, 2008
Fileeki, O ku abo si afin o,

Arude arude
aponjinijini a le nu ma ro
loruko ti a npe ibaka
A le fonfo dori omi mu
ni oruko ti a npe iwo oju oro
Idandan awo molubi
E ba mi se Olori Fileeki ni majomajo o
E ba mi gba si afin iwase ni belejebeleje
Omo were laa ba lagbo ogede
Igba ewe lewe iyeye o
Inu a gbe oyun dani o
E hin a gbomo pon
A logbo n'igba n lo ope
ASE

singing: Ta lo so pe ru eyi o ye ni/2x
Fileeki d'aya Kabiesi
Ta lo so pe ru eyi o ye ni.

Arabinrin Lamide, inu mi dun si ilosiwaju ilu wa yi ti o je o loogun, o o ni pare maye lara o. Iwaju bayi lopa ebiti re yi o ma re si.
Oye Erelu je oye ti o lagbara pupo, orisirisi idanwo ni a si ma n gbeyewo lara awon ti o ba to si. Mo si nu , mo si ikun awo enu ni. Nje o le yanana ohun ti o ro wipe awon erelu ma n je laarin ilu. Ki tile ni ise won, Nje eyin ti ni oko bi?, omo melo ni e ti bii
Asiwaju Ferlie , E je ki fileeki fun yin ni idahun si ibeere wonwonyi, ki a le jiroro lori re ni tanmo-oko
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 6:19pm On Feb 20, 2008
To o bi a se pe a waye ri na laa ri,

Fileki,  sebi omode gbon agba gbon la fi da ile ife, ogbon ologbon ni ko si je ki a pe agba ni were. Ko si afojudi ninu oro yi rara. Mo tooro aforiji fun aifiyesi ati afoju foda ipo re laarin ilu yi o. Mo ki o ku abo ni ekan si o.

Asiwaju Dr Ferlie , bi o ba  wo saakun oro yi daradara, Fileki kan beere awon Olori ni, ko so wipe ohun fe di okan, a mo sa o fe je oye iyalode,  Ikamefa si n be laye ara re, a o le si lese pada.
Oye kan soso ti o wa nile nisisiyi fun obinrin ni , ' Yeye Oge Amogbonjoye of Nairaland' iyen tun nko.

Fileeki, won ni ohun ti n dun ni ni i po loro eni, okan mi n so fun mi wipe aafin mi n wu o gbe, sugbon o lee joye ilu  ki o tun di olori o, ' a pe laye , oju mi o ni ribi, okan loo fowo mu ninu re' -iyen owe awon agba.

Awon igbimo ilu n fun o laye lati lo ro wo daadaa ki o si fi owo di ikan mu ninu mejeeji- sugbon laisi ani-ani, Oba ti gbese le o wayi titi ti awon igbimo yio fi pari ipade lori re, Mukina2 ti gba iyawo na nu. Oloye Ferlie e ba wa pari eto bi yio se de afin ni ojo-ro
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 3:45pm On Feb 19, 2008
Ko ku rara, oke o hun ni ko je ki a ri ti ibi, a o se odun ilu wa laipe , iwo yio si ri gbogbo awon eni atijo ni ori okun yi!
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 1:52pm On Feb 19, 2008
Dr Ferlie, se oju ojo so ire loni o,okiki re o ni di ibaje o
Segoye, aworerin eledumare, aridinu loju iyawo, o o ni pose, o ni fojusunkun o
Tafari nko, e ba mi so fun wipe o jina simi o, ki lode?  Agbala owo re, ko ni hu koriko aini ati osi o
Ayanjide, ore Oba, ahere ni kehin oko, akitan ni yio kehin ile, iwo lo ma bori gbogbo ota ati abinu eni o
Desorlah, aya oloye, e ku itoju baale o.Isale lowo atoroje n wa, o ma fun ni ni o, o ni i toro laye o
Disguy, bi opolo se n yan niwaju elegusi ni o ma yan fanda loju awon elenini eniyan
Minute nko? Iyalode Ikamefa ni bo lo wa?
mukina2,haywhy,nana olufidu, nite angel,omoge, omogenaija, thiefofheart, debosky
gbogbo olori ire ti n be n'ilu yi e ba mi gbaruku ti akitiyan kii Kaaro-o-jiire o le gboro si,

Odua a gbe wa o

Baale Richylaw
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 1:40pm On Feb 19, 2008
Ojumo to mo wa loni , ojumo owo ni o
Ojumo alaafia ati aiku baale oro
Bi ojo ba yo a kari aye, alakanle bayi ni ti osumare
enikan kii fi owo b'oju ojo ko ma yo
enikan kii f'owo b'ogo orun ko ma ran
Irawo gbogbo wa o ni ku o
Ki a ma ri ba ti se o
ki a ma rona gbegba o
Lola awon onile a o ni d'obu o
Idere loni ki awon adeni ma le ri wa de mo le o
Okakatirika ko ni je ki aye ka wa ribiti o
Akun sinu ni tegbin, a kun sikun ni teera
Eti ayan ki gbo igbe , eti eera ki gbo ibosi
Awa la o ma leke ota wa o. ASE

Libational Prayers from the Palace of Baale of Yoruba Thread
Richylaw
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 4:07pm On Feb 18, 2008
top_kin:

E'nle ni bee o! grin
E ku abo si ori eto yi o, Baale Richylaw lo se yin ni pele pele o
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 4:05pm On Feb 18, 2008
Ara ile se ba o ni de , a n bo o
Ire taa ko lona lo je a pe.

Mo ki kekere ile o
Mo ki gbogbo agbagba beleje o, Gbogbo odo-langba ode iwoyi mo ki yin o
Omidan ilu mo ki yin o
Adelebo ilu, mo ki yin o
Mojesin ilu moki yin o
borokini ilu , mo ki yin o
Mekunnu ilu, mo ki yin o
Mo ki gbogbo eso
mo ki gbogbo ologun
mo ki gbogbo oloye,
mo ki oselu
mo ki ojelu

Ki akoda aye  je ko ma ju wa a se o, a o ni ta wo na o, a o si ni taraka o. Nibi won ba  gbe n lu ilu ayo, ese wa o ni ko ijo nibe o.
Gudugudu l’oba  awon omele, wonsi-wonsi l’oba awon sekere, Ilu kan bayi ti o ba ni saworo kii se ilu rara. Okun Yoruba a ma layo ni o. Ilu o ni t u mo wa lori o. Ase.
Dr Ferlie , Asiwaju Okun Oro Yoruba ti Ile Nairaland, e ku a mu le dani o. Inu mi dun si akitiyan re o, wa a ma ri ba ti se o Ase, (ran mi leti o ye ki n le ba o wa isare ile lona Ogun gege bii ebun ranpe lati owo bale o),
Laisi ani-ani Stranger 26 ti n fi ara mo ile lehin ti Dr Ferlie ti yanana asa ati ise awa ti Okun oro Yoruba ti Nairaland fun.
Ayanjide, ore mi pataki Pataki, bi gbogbo nairaland ba rin ninu mi won o ni kose nitori re. O ku ayesi mi lojo ibi mi  ti o koja, ipe re jo mi loju , o bu iyi kun  mi, o si tun  se apehan oriki ti ORE nje. A o pe fun ara wa o, ire bayi na ni a o ma ba ara wa se.
Segoye, abobajiro mi , se eku n dun bi eku o, se eye na si n dun bi eye. Ki Eledua ki o ba wa fun egbon re ni alaafia ti o peye o. O tobi gigigidi ni owo mi o , a o si ni te lowo  ara. Adiresi ayara bi asa mi n be loju ewe idanimo mi (profile), Inu mi yio si dun lati ri iwe re o.
Gbogbo oju titun, Stranger26,Fileki ati awon bebe lo, aaya ti bee le o fe sare o, e gbaradi fun ekunrere ede abinibi baba nla baba wa ti ko ni amulumola Kankan ninu, inu eyin na yio si dun wipe e darapo mowa.
Kanakan ti na omo re o desin , ija nbo , ija ko i de, sebi awifunni koto dani iyen gangan lagba ijakadi.
Awodi Baale lo re ye, won sebi eye ti ku, o sewo a kii gba abata lowo akiti, a kii gba ile baba eni lowo eni
Ope o ku o, e wo moriwo ope to n tu turu yeye turu yeye lorun ope
IRE. IRE KABITI

Richylaw
Baale Okun Oro Yoruba
TV/Movies / Re: Voltron Defender Of The Universe by richylaw(m): 8:32pm On Jan 17, 2008
cute9jaguy and Jairzinho, I don't have a problem sending the 72 episode to you , but like i mentioned, it is about 8gb(in fact i jst checked now and it's exactly 12gb), so the net is out of the option. If you live in the Uk that may mean the problem is half solved as I can post the DVD to you.
TV/Movies / Re: Voltron Defender Of The Universe by richylaw(m): 6:23pm On Jan 17, 2008
Yeah, if i don't show up here then I will be an ingrate to childhood. Voltron was really DA BOMB, I really love it. It's funny though that after a couple of cartoon discussions,  a good number of this british guys here don't know voltron ( maybe because it's an asian stuff). Voltron and Thundersub were my favourites then. Just of recent I met a guy who has all the voltron episode!!!  Gbam I couldn't wait, he he he he
, and now I am a proud custodian of an 8gb size volume of all voltron episodes.
Romance / Re: Who Sits In Front: Your Girlfriend Or Bestfriend? by richylaw(m): 6:06pm On Jan 14, 2008
The lady , if not abnormally possesive should give regards to my friend. If she sits at the back, that does not mean she is an outcast, I know an understanding lady will always reason along this way. I think the only ideal time the so-called friend may be obliged to sit at the back is when she is also a lady!
Religion / Re: Lovemaking After Traditional Wedding Only: Is This Fornication? by richylaw(m): 3:30pm On Jan 14, 2008
I still continue to wonder when certain Nigerians will be able to differentiate between culture and religion.
Though it is clear that they both seems now twained together, albeit they are two different things. Each tribes of the world always have their original culture before any foreigner comes around to contaminate it, so is the case in Nigeria. Marriages happens many years before the invasion and overnight transformation of our great-grand-father's belief by the colonial masters ( Arabs and the illusioned white skinned). The act of marriage in  any tribe in Nigeria is submerged into such tribe's culture. By standard most marriages today take this trend: Introduction, Traditional, Engagement, Registry or Nikai(Mosque) or Church ( refered as white wedding). I am not sure of the hausas,but I am sure yorubas do introduction , engagement and then the wedding of their choice based on religion. Igbos do traditional wedding after introduction and may move on to the next as it also relates to the yorubas. From this view it is noted that an engagement and traditional wedding is valued to Nigerians before the church , registry or Mosque. This in common cultural sense means we know our culture and must not be thrown off because of a white man induced culture.

Now to the main topic


By religious understanding, if you accept the christian faith devotedly, you will understand that the church is for the blessings on a marriage of consent between the couple, their parents and made openly known to the public. The church has no biblical right to join two that are yet to seek and accept the agreement of their parents.

A pronounced white wedding attracts the usage of a white wedding gown  which apparently is not any of the nigerian tribe attire, neither was christianity or islamic part of us some 150 years ago.

Conclusion: So far the two parents agrees to your relationship in a formal way (engagement or traditional) through bride price and it is declared to the general public by any form of the legal media method, you are married and the pear can be peeled.

Note : However if after your traditional and/or  engagement, you plan, intend, aspire or believe you need a church wedding then tarry till you do it, for the white wedding gown is a symbolic attire of virginity from the whiteman. Ask yourself; am I qualified to wear it (as woman)  or am I qualified to do it
( as a man) based on the religious value of this attire placed by those who brought it to us, your conscience will answer you. Two people don't fall ignorant of lies, if the liar does not know he/she is lying the person lied to will know.
If you need a traditional wedding alone go ahead for the sacred valley after then, but if you need to take blessings from the church then HOLD IT to fulfil all righteousness.
As for me, after introduction, I know I will proceed to engagement then church wedding when the time comes and these last two will be done in 1 weekend, I will now wait to see the gateman who will close doors!
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 12:44pm On Jan 03, 2008
ADURA ODUN TUNTUN 2008
(Singing)
Oun ti mo wi aaro a ro mo, hen a hen /2x
Ka l’owo l’owo
Ka kole mole
Hen a hen ,

Mo ki kekere ile o
Mo ki eyin agba popo ti n be ninu imo oro
Mo ki ologbon ti n mu ogbon se ohun ogbon
Mo ki onimo to n mu imo se ohun imo
Mo ki ara iwa ti n lo geregere ti o ni f’ese ko
Mo ki ero eyin ti n bo ginigini ti o si ni d’eni awa ti
Mo ki gbogbo oloye (the wise) ti a jo la odun to koja ja
Ani mo ki gbogbo eniyan loke erupe ti a jo ri odun titun
Ninu odun yi a o ni ta wo na o
A o ni taraka o
Ile o ni gbona mo wa o
Ona o ni na wa
Ka ro wo s’aye
A o ni je eegun gbehin eran o
Odun ayo , odun idunu
Odun owo, odun omo
Omoge to n w’oko ari , odomokunrin to n w’aya a ri o
Awon to ti ni ko ni fi oju sunkun o
Iwaju lopa ebiti n re si o
Ilu yi o ni daru o
Nairaland o ni di ohun igbagbe o
Orile ede Naijiria a gun rege o
Omori igba kii ri idi joko
Gbogbo ojelu , alaparutu, afarannu ba ohun to dun je, eletekete, onisekuse,ole, abinu eni
Ati gbogbo oniyangi to fe d‘oju ti elepo, ati elepo paapaa to fe d’oju ti alala
Awon alale a se won m’ose fun gbogbo wa ninu odun yi o.
ASEEEEEEEE!!!!
Segoye o ku ojo meta, lo ba di firifiri, a dara ki n gba nomba ibanisoro re wayi o nitori wipe eni ti a o fe ni ile re njinna
Dr Ferlie, mo ri bi o se n se aayun mi,sugbon bi a ba mu ipin kuro loju, a ma n fi han oju ni o, gbogbo ohun ti o n wi kiri laarin ilu ni mo kuku n gbo , sugbon ninu re o mo wipe otito kan ko si ni be. Baale o gba iyawo oloye kankan o, Desorlah n be,Oloye Segoye na n be o, Baale Richylaw o si lo si ewon rara o.Mo wa ni alaafia ara mi l’aafin o. Koko lara ota n le, bi a ba pe a o mu oni ola la n mu o.
Tafari , Disguy, Ikamefa, Mishoo,Iya aje ati ojiji re ‘Wunmi! , Nana,Minutes, Omoge ati gbogbo oju titun ti n be ni lu mo ki yin o.
B’ojo ba yo a kari aye , a la kanle ni t’osumare , oto logo orun , oto logo osupa o. Aye o ni ri Irawo wa ju si omi o
ASEEEEEEE!!!
Richylaw
Baale Yoruba Thread
Romance / Re: My Wife Is Discussing Marriage With Another Man by richylaw(m): 5:10pm On Dec 17, 2007
The same full gist you hid from 'her' until she got to know herself and she decided to start discussing marriage with another man is also the same one you are hiding from us . Grow up and be a man , then you can have a mature counselling from us.
Family / Re: My Brother-In-Law And I by richylaw(m): 1:51pm On Dec 05, 2007
Stop this nonsense,
- The fact that he is your  Husband's brother does not mean your husband will not KILL him if he gets to know
- Your own case is an easy  one, he will only batter you, broadcast to the whole world on what you have done  and then you will be thrown out of your marital home with a domestic/ global shame!
-It is only a form of exonoration for you to say that he has always been the instigator, afterall you were not raped by him.
- As you have attached it all to perfume , I hope that bottle does not contain one of those  concocted " DAN MARIYA" , confess to us  where did you get it?

All in all, be aware that if you tell your husband it will be 'wahala' and if you don't it will be 'bilisi'
If you believe in God , pray to Him for forgiveness with true repentance and forgive yourself as well,  then cross your fingers through the path of life. You will eventually have the liver to confess to him when you clock 70
Art, Graphics & Video / Re: Autocad Designer by richylaw(m): 4:10pm On Nov 12, 2007
Can this guys script or rescript the VB in autocad?
Are these guys architect or have the skills to cope with basic architectural rudiments in terms of details?
How comfortable are they to pull stunts in 3d via autocad (2008 preferable)?
Do you have a copy registered to AUTODESK to facilitate an online interactive design work force

If sincerely you can say bold yes to the four above, kindly send a pdf copy of any detail drafting you have to my email, it's on the profile.
NOTE: PDF copies only please.
Art, Graphics & Video / Re: Re: What Is The Best Software for CD Covers Design Photoshop Or Coreldraw by richylaw(m): 3:58pm On Nov 12, 2007
Gamine said it all, you can only compare photoshop to corel photo paint , corel draw is only comparable to Adobe illusrator. I being a photoshop person will not even venture into photopaint ( even though I use it and corel draw very well) for any just course. Try your hands on the new Photoshop CS3 and you will know the answer without asking. Think the professional way man.
Romance / Re: Should I Marry For Love Or Stability? by richylaw(m): 3:31pm On Nov 12, 2007
IMHO, I can see that the plain truth of this issue lies in you but you don't want to trust your personal judgement.

-What guarantees an assurance that he will continue to shower all those affections after the marriage day?
-What gives an assurance he is not sparing the time to care for you now simply to woo you  and and get you in as his wife, and then a phase II will start   contrary to phase 1?

In the actual sense , you have confessed that you are not attracted to him physically, do you think he is not aware of this?
My own philosophy indicates that a good relationship  grows from the physical into the mind where it will thrust it's roots. This is contra-phenomena to your case as I am strongly trying to see how you developed an inward affection for his inner man and not the external.
You getting layed by him surely is not the solution as you may even end up getting dissapointed by what he may have to offer.

Seach yourself and don't be kconfused as far as your mind is questionable in this relationship.Take a toll to decide whether to go on or not.
In this situation, I can assure you that as far as you still don't get attracted to his physical man, you are still playing poker, don't force yourself on what you don't believe. Age counts though, but this sun high up may still dry your wet clothes.
Culture / Re: Are Nigerian Men Lazy Or Just Completely Insensitive? by richylaw(m): 2:02pm On Nov 12, 2007
It is sad to still realise that some fellas here still generalize personal issues or individual behaviour, when it is actually meant to be separated. First and foremost I stand to say that it is an understatement to say Nigerian men are insensitive. The fact that only one has behaved like a monkey does not make all others the same. Even in Nigeria we see a lot of men who help their wives in the day to day activity.

londoner:

I remember staying with one of my Aunts in the states, they have three small children. My aunt was at work and the daughters hair needed combing, instead of just combing the hair, it was left by her husband, simply because it wasn't appropriate for a man to do. I thought it was so silly, why not just comb your own daughters hair if it needed it? Instead he would rather go out with her hair unkempt. Why should that be a measure of manhood? What about fatherhood?

I just don't get it, lol

From this I beleive you know it deep in you that not all Nigerian fathers will behave like your inlaw. As for me I am a guy, though not married but I weave hair for my little nieces because I am good in the art, in fact a couple of my inlaws learnt how to make different hair-do through me, DO YOU EXPECT ME TO NOW WAIT FOR MY WIFE TO COME AND DO SIMPLE COMBING ON A CHILDS HAIR LATER IN FUTURE?

In summary this has to do with individual differences , it should not be generalised. pppplllllzzzzzzzz
Business / Re: The Naira Is Gaining Back Its Value? by richylaw(m): 1:42pm On Nov 12, 2007
sniperwolf:

Let's keep our fingers crossed till 2020 and see if the Naira wouldn't appreciate or not.

I'm quite sure it will

That's for sure, the young shall grow, but then they grow when they are well nutured , like you said finger crossed
Sports / Re: :( We Lost The Bid To Host The Commonwealth Games! :( by richylaw(m): 7:06am On Nov 10, 2007
scientist:

@ richlaw:
I'm sure every one in that office must have laughed you to scorn and ridicule grin grin Poor Nigeria, Poor Preparation, angry angry angry and ultimately POOR RESULTS shocked angry shocked angry shockedwhat a shame; Good riddance to bad rubbish indeed grin

it was indeed another show of shame , I just walked out of the Tv room.
Sports / Re: :( We Lost The Bid To Host The Commonwealth Games! :( by richylaw(m): 5:46pm On Nov 09, 2007
You only need to see my face and attitude today ( as I am the only Nigerian in my office, a scottish, glawegian  firm) while everyone held their breath to hear the announcement on the news. They were so eager and particular about it that an extra 15minutes was added earlier to the lunch break which normally starts at 1.00pm so that we could all view the bid result at 12.45pm. Glasgow got 47  out of 71 votes. You only need to read this [/http://canadianpress.google.com/article/ALeqM5iyiwJiyixrZPSoh8JTzUhWMvBVRA]   and see our face of shame in terms of preparation. Poor Nigeria.
Romance / Re: Is 4 Years Too Long For Courtship? by richylaw(m): 4:11pm On Nov 07, 2007
However a clear difference should be shown between dating and courting, dating may take as long as you may wish to study each other, but courtship is just that last step to the real thing, at that point you are digesting and knowing what you have STUDIED. Then we might talk of courtship.
Nonetheless, ''when will the long rehearsed game of madness be staged in the market'' the earlier the better
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 2:55pm On Oct 17, 2007
mishooo:

Richylaw, e ku iwaju oo
o jare , se alafia la ri yin o?
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 1:55pm On Oct 17, 2007
Iya Aje Niwon igba ti o dabi eni wipe afojufoda ati amoworekoja ko je ki n ranti se e n lebeun si Mr 'Wunmi (iya aje), mo fi asiko yi parowa wipe ki o fiyedenu ki o ma si se binu o. Iku ati arun logbagbe re o. Oro lo n yo obi lapo(pocket) , o n na lo n yo ida lapo (scabbard).Imo ede wa , asa wa ati isesi wa ko ni poora mo wa loju o.
Tafari o mo to ojo meta, se gbogbo re n se deedee. Awon aafa wa n ko lode Kuwait. Gbona Ondo abi kini mo ri grin. Looto ni o, koda won ni iwo ni oye oba kan nibe!!! grin grin grin.

wed123:

wakoro wakoro ijah omo etiabai denke hilaro ati?
semife lala hin toni jakala refutiko abik
Beni ati gkoro ti o tomi daburo nkem in si ya me
ndatu ife mmega!!!

Beni. Odabo.

Lati ibo sii ibo, erin n gbe mi n ko si lee da rin. A se iru awon eniyan bayin si tun ku lori ile aye grin grin grin
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 1:50pm On Oct 12, 2007
Minute, kii ja kii ja, omo ale lo n je be, sugbon agbaniloju gunni lobe ko fomo odo lu ni se die ninu iwa janduku. Jowo ma je ki ibinu re ma po to ba yi o. Se wa pele ni mu ni niyi lawujo o. LOL.
ati Aiyefele ati Excel ore ni gbogbo wa o mo ba ara wa se o a o ni di ota.
Mishoo , o to ojo meta kan, se alaafia ni. Oko okun yi ti n worin lenu lowolowo yi osi ye o be lo ye mi, ohun gbogbo ti di foyegbe. Ayan n ko ati Segoye , desorlah nko pelu bolorunfem, dis guy nko ati bebe lo , eni to ba ti ri won ema ba mi ki won o.
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 2:55pm On Oct 02, 2007
buttyelele:

apere temi ko ni o se pataki, ti ko ba se opolopo awon eniyan ti ko le so ede abinibi won, papa ju lo, ede yoruba. A le so yoruba di ola, oto oro ni pe opolopo awon eniyan ni gbogbo nkan ti a ko si nairalandi yi ko ye, ko se nipa kiko orin shina peters tabi sunny ade ni afin gbo yoruba. iwo na mu akole gidi wa ka si jiroro lori re.

Ohun ti mo n so ni wipe ki o ye ra fun ede geesi ni ori okun yi gegebi eyi ti o koko fi gbe eronu re kale ninu oro ti o fi sowo si ori okun ni akoko.
Nipa akole ti o d'amoran ko buru rara gege bi aba sugbon mo mo wipe asiko le e ma si fun o lati ka ohun gbogbo to wa lori okun yi lati oju ewe kini, iwo o ba ti ri akitiyan lati se bi o se n fe ( bo tile je wipe ara n fu mi wipe awodi re kan pa aso esin da ni). Opo igba ni a ti daba akole, opo igba ni awon ti o ni arojinle na ti gbe koko yi yewo , sugbon niwon igba ti oronro ba ti n fo po mo eran adun re a ma soro ri.
Opo eniyan ni abara meji lori okun yoruba yi, won ni oruko ti won fi n hu iwa buburu, won si ni eyi ti won fi n fi oye inu won han. Sugbon niwon igba ti nomba idanimo(IP Address) wa fun ero ayarabiasa ti onikaluku, awon aseto n je ki a da iru won mo.
Emi gegebi enikan , yala ni igba kan tabi omiran mo ti mu aba akole orisirisi wa , ko si si eyi ti o mu ogbon dani ti enikeni da laba ti n ko da si. Opon oro ni o wa ni iwaju iwo na yi, da ifa tire na sile ko je ki a gbo ohun to ba wi nipa akole.

Gbogbo ile, eku ojo meta e si tun ku ko le da o. Bolorunfem e seun o eku ibeere mi. Emi na o ti gburo Segoye2 o, o da mi loju wipe ko le e wa larowoto ki o ma kan si ori okun ti o fi owo ara re da sile. E je ki a mu suuru ka si ma woye titi ti yio fi de.
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 1:42pm On Sep 24, 2007
buttyelele:

i studied linguistics in You.I and mother tongue was really promoted, am always impressed when our laguage is being promoted, some think the language is endangered, because it has not been passed from one generation to another, all the alo apagbe, the folklores, games we used to play in yoruba when we were younger is all gone, all the bat somi were were, the poems i.e adiye mi eyi ti mo ra, all that is gone, we are losing out big time on our heritage, your child will never speak as good as u can, and they will pass on their substandard yoruba to the next generation until theres is no yoruba left, what can we do please bring suggestions.

Suggestion: Bi o tile je wipe oro isiri ati onilaakaye ni o ti ko sile, iba dara ki o tumo gbogbo ohun ti o ko si oke yi si ede yoruba, bi iwo na ba bere pelu apere rere ko ti buru ju.Oyinbo tabi ede geesi ko ni aagbon okun oro yi wa fun
Religion / Re: Are Expensive Church Buildings Really Necessary? by richylaw(m): 11:59pm On Sep 14, 2007
Well, if this enormous and gigantic worship places will make more people submit themselves to God why then won't it be?fterall Nigerians will then fear God the more and obey him. But you only need to take a case study of Europe, most especially UK,most church buildings are now turning to pubs and some renovated for dwellings.( where are the old worshipers?)
The heart is the believe but the building is not the CHURCH.
Computers / Re: Help: Someone Sat On My Laptop And Broke The Screen by richylaw(m): 11:30pm On Sep 14, 2007
A fairly used screen ranges between 20-30k but be watchful of some funny bad hands at computer village
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 11:13pm On Sep 14, 2007
Hello ! grin.
O to ojo meta kan ti mo jade lati inu afin si ojugbara, ayo nla nla ni o si je nigba ti mo ri wipe iri alekun to ku dede ti da si ori eweko okun oro yi , oju tuntun ti po yantirere, awon eja tuntun ti n fi ori la ibu. E ku aayan gbogbo omo yoruba atata. Okankan wa o ni te lawujo awon omo adari-hu-irun o.
Ayanjide, mo wa lalaafia ara, ise ilu lo gbomi mu o. K'Oluwa je ki gbogbo wa kere de ile o.Ori to si mu opo de igberi okun a je ki a bu abutoro, ajiwele omi afowuro pon pada sile o. ASE.
Iya Bolorunfem,mishoo, debosky, haywhy,nana, minute,iya aje,aloib,dis guy,segoye gbogbo eekan oro ti n be lode ile yii pata mo se iba yin o.A o ni te lowo ara wa o
Gbogbo ogunna gbongbo akomonamona waiwai ti n da ito lenu igbin, to fi ojude yoruba sele mo sipe fun yin o.
iba ta pebe owo
iba apebe ese
iba akoda
iba aseda
Iba ojiji ateleni mo dehin ti o se mu so
Ile ogere afoko yeri , alapooka je kaye o tu wa, ka gbe ori re se rere o
Ero ni tigbin
ero ni ti koko lagbala
Ero pese ni ajo aye gbogbo wa yio je o
KO TU 'BA, KO TU 'SE
IRE
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 2:57pm On Sep 09, 2007
Bolorunfem, mo wa bi ewa,
Gbogbo ile , a ku imura ose titun o.

(1) (2) (3) (4) (5) (6) (7) (8) (9) (10) (of 17 pages)

(Go Up)

Sections: politics (1) business autos (1) jobs (1) career education (1) romance computers phones travel sports fashion health
religion celebs tv-movies music-radio literature webmasters programming techmarket

Links: (1) (2) (3) (4) (5) (6) (7) (8) (9) (10)

Nairaland - Copyright © 2005 - 2024 Oluwaseun Osewa. All rights reserved. See How To Advertise. 109
Disclaimer: Every Nairaland member is solely responsible for anything that he/she posts or uploads on Nairaland.