Welcome, Guest: Register On Nairaland / LOGIN! / Trending / Recent / New
Stats: 3,162,397 members, 7,850,417 topics. Date: Tuesday, 04 June 2024 at 08:55 PM

Richylaw's Posts

Nairaland Forum / Richylaw's Profile / Richylaw's Posts

(1) (2) (3) (4) (5) (6) (7) (8) (9) (10) (of 17 pages)

Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 8:08pm On Sep 06, 2007
Penfold,

To , moti ka idahun si awon ibeere re o, niwon igba ti o si le fi oju Olodumare se eri wipe otito ni gbogbo ohun ti o ko yi , o di dandan ki emi fun o ni iwonba imoran ti mo ni
Ona meta ni o pin si:
1. Ma  suja omobinrin na mo , bi o ba pe o tabi fiwe sowo ranse si o, ma se fun ni esi
2. Niwon igba ti e ko tii fi oju kan ara yin ri , ko si iyonu niyen, o lee fi ejo ara re sun, ki o si so bi okan re se ri fun. Se o mo wipe awi fun ni ko to da ni , iyen gangan lagba ijakadi
3. [s]Ona keta ni ki o fi owo ile to , a o gba ese re jade  la i wehin pelu igbale, a o si fe eru re danu si inu afefe!  [/s]
Koko lo se meji ti akoko na , bi ko ba wa gba lero, o di dandan ka mu lele. Sugbon je ki o ye o  o, gbogbo imoran yi lo ti ka, bi o  ba fi le je wipe eleketa ni oro yi gbehin si, mo daju wipe otito ni gbogbo ohun ti o ti so nipa arabinrin na o, aijebe, eni da eeru l'eru to! grin
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 2:10pm On Sep 06, 2007
Segoye se alaafia ni , maa gbadun ile baba re o
segoye2:


Baale, nje e mo nkan kan nipa igi ti ara kunrin yin so bi?


Oro nla ni eyi ti o beere yi, mo ma n sa ipa mi lati yonda ara mi kuro lori  ijiroro kankan ti o ba je mo  iru awon oro bayi .
Idi si ni wipe gbogbo wa o koju si ibi kan na, eyi wu mi , ko wu o ni ko je ki a pa oruko  po ka ma je Ogidan-Odo.
Olaju, aibikita fun isedale, a i ri aye lati gbo aroba tii se baba itan, eja dida ( under-estimation), a i ni laakaye to lati so imo ijinle , eko opolo ati arojinle (psychology and philosophy) papo mo ara won ti se okunfa fun orisirisi ifasehin omo eniyan ni oni. Paapaa julo l'awujo awa omo kaaro ojiire, ni ibi ti o je wipe a ti n so asa ati ise nu. Mo mo wipe ti mo ba ko awon otito oro gegebi idahun si ibeere re tan, opolopo alainigbagbo ni yio bu enu ate lu.
Sugbon e je ki ologbon, ko mu ogbon se ogbon, ko o si ma fi gbe aye pelu ogbon
Bi ohun ti mo ti ko soke ko ba ye o to jowo wo ohun ti awon eniyan fi n fesi ni oju ewe yi   (https://www.nairaland.com/nigeria/topic-75388.0.html)
Nitorina eniti ko ba ni igbagbo ninu asa ati ise ile yoruba tabi awon eya to ku ni orile ede adulawo ki o dakun ki o fi iye denu , ki o ma wule beere ohun ti ko ba ba oro yi mu lowo mi.
[b]Segoye idahun si ibeere re, [/b]
Lotito  ni, ko si si iro ninu wipe igi yi wa. Awa yoruba a ma n pe ni 'IGI NLA'.
Fun eni ti o ba ti gbagbo wipe Alagbara lori aye ti a n pe ni Eledumare wa , o didan ki eni na ni iran wipe imo ijinle nikan ko ni oro aye yi, o kun fun awamaridi awon oro ati isele  jankanjankan yala lori ile, ninu ile , ninu afefe ati ni ode orun. Eledua fi ase ati agbara fun ohun gbogbo ti o da.
Isalu aye je ibi ti o pin si ona meji IRE ATI IBI, a si gba wipe esu tabi asetani ninu esin igbagbo tabi imole ni o n da buburu sile.
Mo fe ki o mo wipe 'nunu - ebe' tabi igi nla wa ni ori ile aye yi, sugbon ko wopo pupo rara be si ni kii hu si oko etile, aginju rere ni o fi n se ile!, gbogbo ohun ti a si ko nipa re ni o je otito, igbagbo awa yoruba ni wipe 'oro'(spirit)  ti o ma n fi inu iru igi bayi se ile ni agabra tie ni ara oto.
Enikan kii ge 'igi nla' o s'ewo, o si ma n soro fun awon agba ti o mo ibi ti o hu si lati toka re fun mojesin tabi ogberi.
N je o mo owe yi  ' BI SANGO N P'ARABA , TO N PA IROKO, BI I TI IGI NLA KO'. Abami igi gbaa ni igi yii.
Awon ode ama sora lati sinmi tabi lati sunmo igi na ti won ba n s'ode lo nigbo laarin oru.
N ko ni le ko pupo nipa igi yi nitori oro po ninu iwe kobo
Bi o ba mo awon eranko abami yi: ofafa ati Wonnsia ( emi ko mo oruko oyinbo won) ati awon ewo ti o so mo won be gele na ni oro 'igi nla' je o. Bi o ba fe ki n tun laa ye o si , a o soro lojo iwaju lori ero ibanisoro fun ilaloye si ni ori oro yi.

Fun gbogbo ile: E mi kii se Akolawole Irinkerindo ( RIP) o, mo ba aroba ni , mo se akitiyan  iwadi , mo si farabale ko bi a se n ba awon agba jeun. Emi kii i si se olorisa rara.
Odua a gbe wa o
IRE.
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 5:25pm On Sep 05, 2007
bolorunfem:

Inu mi dun, ori mi si wu lati ri pe awon eniyan ti o to gbangba a sun l'oye nipa ede Yoruba kiko wa lori owu yi. E ma a bafaaji bo, eni to ba lo lo ba ku.

E jowo talo le bami pari owe yi , "babalawo to se afeeri fun aayan (cockroach), ?

O N NA LO SE TI ARINKO FADIYE!
ju imi si afefe , a jo wa lenu e.
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 1:37pm On Sep 05, 2007
[quote author Penfold]
E j'owo, Alagba Richylaw, mo ri wipe e gbowo die ni mo se ni ki n wa ba yin fun imoran ni o!!
O ni omodebirin kan ti o n fooro emi mi ni ile wa yi (ipinle nairaland), mo si fe da seria fun,
E dakun dabo, e jowo, e fun mi ni imoran bi mo se le lee kuro l'eyin mi nitoripe o ti fe di isolenu bayi o!!
won ni abeere ona ki sina rara, e dakun e to mi si ona bi ma se le omo yii danu leyin mi o!!
e seeeee gan ni
[quote][/quote]

Lotito ni wipe abeere ona kii sina. Adura to sa tun ye ki a ma gba ni wipe ibi ti ori ba n gbe ni re ki ese ma mu ni lo ni.
Penfold, o ya mi lenu lati ri ohun ti o n sele si o yi

Arugbo n sunkun eyin
Agan n sunkun aibimo
iya abiku n sunkun omo re
Eyin ojogbon aye , e ba ni wa ibi osupa ale ana lo.
Obinrin ti awon kan n wa lojumejeeji ti won si n gba awe le loori ni iwo n sa fun. Ki oba oke ki o dakun ki o mo fi ipo obinrin ninu aye wa won wa o.
Mo mo wipe o n ti o n dun o ni, o si di dandan ki a wa ojutu oro yi, ki a si ri wipe a ba o le danu. Sugbon o ni lati dahun awon ibeere perete wonyi.
1. Kini o pa iwo ati omobinrin yi po?
2. N je o ti da enu ife ko o ri lori Nairaland?
3. Nje e ti jo ni ede aiyede oro tabi aigboye kan pato lori okun nairaland kankan ri?
4. Yala , ni firi , nikoko tabi ni gbangba, n je e tile ti pade ri loju koroju?

Nipa didahun si awon ibeere yi , emi yio lee tii ibi saakun wo oro na. Agbejo apakan da kan si , agba osika laa pe!
Ko je bo tije, mo n reti idahun.
IRE.
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 1:20pm On Sep 05, 2007
Bolorunfem: Oro nla leleyi fun eni ti o ba le fi se ogbon.
Segoye: Ki wa lo tii ri, to jo e loju, a i de jinna rere aginju ni ko je ko ri abuke okere, bi o ba kan le isale odo , o didan ki o ri eja to n lo awo oju!(sun shade)
Ki Oluwa ki o so igba dero fun wa, ki o si yan olori rere ti o ni otito lenu.
Celebrities / Re: Denrele Of Soundcity by richylaw(m): 3:37pm On Sep 04, 2007
Just another emblem of stage originality - that's what he is. Let him be.
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 3:22pm On Sep 04, 2007
lalaboi:

kokoko!!

ta ni n be nile oh!
Ero po laba, gbogbo wa la si ki o ku abo
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 10:44am On Sep 03, 2007
o ye ki o le e ri gba nigba ti yio ba fi di owo ale
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 9:38am On Sep 03, 2007
Ojumo ire ni lotito o. Ayanjide ati Replenish e ku oju momo o. Ara o le bi. Ki oba oke ko se alatilehin wa ki a ma ri arin fese si o ase.
Ayan, jowo ma binu simi o, mo sese pada de lati irin ajo ranpe kan ti ko je ki n le kan si o ninu opin ose ti a lo tan yi ni o.
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 2:33pm On Aug 31, 2007
Joge , o ku laakaye ati imoran ti o tun mu ogbon dani. Opo eniyan ni gbagede oro yi ni won ti n mo ara won ti won si ma n te ara won laago lehin itage. Ko da bi o ba fe mo , eni ti o n wa ise ti se alabapade ise nipa alanu kan ni ori gbagede oro yoruba yi. Mo si ti ko firi awon ti won jo se apero lati jo da owo po. Ibase ore laarin ako ati abo , ti mo lero wipe o le di idile olorire ni ojo ola kan na si n lo lowo bayi. Mo mo wipe iwo yio ma beere wipe bawo ni mo se mo. Ipo baale ti mo wa lo je ki n le se apero pelu awon ti o ni oro ologbon lenu ati imo onilaakaye  lori okun yi.
Dara po mo wa , iwo yio bere si i ni ore, won o si ma pe aago re, ranti wipe bi oju ba fi ara bale daadaa yio ri imu o.
Gbo naa okunrin ni o abi obinrin? O sa ye ki a mo eni ta fe ba se ore.
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 11:30am On Aug 31, 2007
Replenish, O di dandan o, oni a da lola eledumare.
Ayanjide o ye ki n kan si e ki ile to su loni, ma binu wipe mi o le se bi mo se so mo lana.
Segoye, ma gbadun o baba re loni le.
Gbogbo ile e ku yotomi opin ose.
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 10:17pm On Aug 29, 2007
nana:

E kale o

E ma wole o. Se ko re ra?
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 9:49pm On Aug 29, 2007
segoye, o to ojo meta o. se ilee n dun
omoge , continue hummmmmmmmmmmmmmmmiiiing o, oun to n dun ni ni i po loro eni.
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 1:46pm On Aug 29, 2007
Nite angel , ko nomba ero ibanisoro eni ti o de si lodo ranse si ori addresi alantakun mi gegebi o se wa ni oju iwe idanimo mi (profile) n pe , a o si se eto lati ri ara wa.
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 9:03am On Aug 28, 2007
Ayanjide , ma je ki ireti ojo pipe mu okan re saare rara o. Oke o un  ni ko fe ja ka ri tihin. N o sa gbogbo ipa mi lati ba o soro ni asale oni.
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 11:12pm On Aug 24, 2007
I can't help but laugh whenever I see omoge humming her songs
This time around eye lo de kan.

Bi mi o ba ni be rara o dabi orin ti o fe ko niyi:
ko s'oloko ( farm owner) loko eye bere ma jeka (eat the guinea corn) eye
Minute se nkan n se muremure. A a kuu opin ose o.
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 11:07am On Aug 24, 2007
replenish:

ta wa gan ni ewuro, ta l'eso weewe

ati pe awon wo ni onigba.

idahun si ibere mi ni mo fe o jare

Erofo ni oro, bi a ba fi papa lu a ma ta ba ni, eni oro ta ba ni ko fi oye gbe, ki o si ye ara re wo.
Bi Oba oke se n be , ti orun o si jabo, emi RICHYLAW NI BAALE OKUN YORUBA YII
Niwon igba ti emi ko si yaju si ara iwaju o di dandan ko ju mi se.
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 10:26am On Aug 24, 2007
IBEERE MEJE PERE!

1. Nibo ni akere wa nigba ti opolo n gba ara re lowo elegusi?
2. Nibo ni eera wa nigba ti ikan n mo ile nla, to tun hu iye lapa di esunsun?
3. Okin joba eye, Ogongo je baba eye, Owiwi je amoye lawujo eye, awoko joba orin nipekun oke lawujo abiye fo. Nibo ni ega ati eliri wa nigba ti
   gbogbo awon wonyi  n yan ase laayo?
4. Nigba ti olokun n se ogun okiki nibo ni gbogbo awon odo pepepe wa?
5. Nibo ni iran okobo wa , nibi olomokunrin ti n ku aya e mole lori eni?
6. Nibo ni akiriboto lo lojo gbogbo alabe aye  n fi ti won se omo?
7. Yerepe gbara e la loko, gbogbo igi oko wa n pa ariwo enu, e ba mi bere lowo won wipe nibo ni won wa , nigba ti ewe ajonilara n sebo igbara la?


Ewuro ti dagba igi , eso wewe igi kerejee e faaye owo sile
Tafojudi ko, tete sonbo si ko.
Bo nigba ba se pe igba re , laa ba pe.
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 9:45am On Aug 24, 2007
Ayanjide mo ti ri owo re, a o soro laipe. Ki Oba Oke ki o ma gba opolo ati ohun lenu eni kooka wa.
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 7:30pm On Aug 23, 2007
ayanjide:

richy, o see pupo, mo gbadun oriki naa
sugbon mo ni idojuko die ninu itumo
awon oro die ninu e
awon oro bii :

AKORAYE AKEJI OMO-1st to see d world, d 1 that second a child

OJU MI YESO, OJU RABESA- beauty adorns my face, my face ran away from(avoids)knife

LEMBEBE- wots d meanin ASODUN EDE NI LEMBEBE JE LATI SE ATENUMO IPO TI IFE DURO SI LAARIN AWON ILU YORUBA TI O KU
BI O BA TORI ONI KEKE KU E PE KU AREWA LO POGO- if i die because of a bicycle owner, say it is d death of a beautiful 1 that kills GLORY. THIS IS KEKE (ami:is 'mimi')and not 'keke'-bicycle. KEKE IS REGARDED AS ONE OF THE MOST BEAUTIFYING FACIAL ADORNMENT ( SCARIFICATION!) OTHERWISE KNOWN AS TRIBAL MARK. NOTE THAT SOMBORO IS ALSO ANOTHER TYPE.THIS ARE TYPICAL OF OMO OLUFE.

Yoruba pa owe: Tita riro laa kola , to ba doju tan a di oge.
it is believed that tribal marks makes you more beautiful grin

PERENSE- wots d meanin[b]. PERENSE IS A FACIAL SCARIFICATION USED AS MARKS ON SLAVES[/b]

e ma ni wahala mi po o , e o ko wa je pe, e o ri un amufiboju ati amusagba

The first two phrases are right by your translation

[s]if you truely need it , give me your number , I will call you and recite it for you.[/s]
ODUA A GBE WA O
Ko ju be lo.
IRE
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 5:23pm On Aug 23, 2007
Ase o, opolo ti e na o ni joba - sterile ( put mi:do on it)
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 4:59pm On Aug 23, 2007
O se o jare, lotito ni mo n re ju, even though it's ironical , you can imagine what it may look like working with this  oyinbos

Oriki Olufe niyi ni soki, o gun gbonanagbonana sugbon jeki ki a mu ni iwonba.

Ife o daye, ibi oju ti n mo wa
akoraye akeji omo
oju mi yeso, ojurabesa
A i duro ki won n'Ife Oni
bi o ba duro ki won nife ooni , eru ni baba won n mu ni se
a i bere kin won n'ife lembebe
bi o ba bere ki won n'ife lembebe ebo ni baba won n fini se
Bi mo ba tori oni keke ku, e pe ku arewa lopogo
bi mo ba tori onisomboro ku , e pe ku arewa lo pogo
Emi o ni tori oni perense ku , abila logido
erukeru abi lala lenu
aso funfun ni mu le yin wu mi duro si
Ori a fa kodoro nii  mule baba won su mi loo.


kii dun po , soki lobe oge grin
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 3:49pm On Aug 23, 2007
Alagba Tafari, e kaa bo si ori eto yi.
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 3:07pm On Aug 23, 2007
ayanjide:

RICHY, omo ogbomosho gan ni mo je ni oyo st8
ise ilu lilu si ni ise awon baba nlaa mi
sugbon ai f'oju f'okan si lo je ko yi mi
legbiri. ki olorun ki o ran mi lowo

Ogbomoso, ajilete, ogbomojugun
omo oreposuyi
nibi won gbe n jeka ki won to mu eko yangan.

Ara e lara e , okun sokoto. Ko ti pe ju fun o, wa woroko se ada ki o je ki oruko re ba ise owo re lo.


Mishoo, mi o mo bi o se n pe ami yen jade , sugbon ti o ba je wipe bi gongo yio se pee jade ni, be ni ami ti mo yan le lori yio se ri lowo onilu, se iwadi re daadaa.
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 2:14pm On Aug 23, 2007
Ayanjide , o dabi eni wipe o ni lo lati lo ja gbere alayan meje si ehin eti re o , ki o le ma gbo ilu daadaa gege bi ayan tooto. La ise ani ani , ti o ba je omo Oyo, bi o ko ba ti le mo nkan kan nipa ilu, o di dandan ki o wa ninu eje re o. Nitori wipe iran Onirese niyin , eyin ni a si mo ni olori afingba, eyin na si ni n gbegi ilu.
Trace your root man grin
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 1:56pm On Aug 23, 2007
ile won na nu ni
ile won na nu ni
ile abere wo bi i le ekute
ile won na nu ni.


Ayanjide, Ode-Omu, ko jo rara bo tile je Osun ni mo ti wa.
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 1:27pm On Aug 23, 2007
Ayanjide, bo ti ye ko mo ri na nu. A bo ti e ri nkan ni?
Mo lo si ode abosi kan lana ni , lawujo awon loba loba
ni okan ninu awon ayan ba bere si ni fi ilu so oro alufansa si arakunrin kan ti ko mo bi ase n ko ara eni ni ijanu lori okun yi.
o pe bo o lo se wi grin?

re mi rere mi do mi re
re mi rere mi do mi re
re mi dododo
mi re mi do mimi re mi
re mi rere mi do mi re.
( fun eni ti o ba mo ami yoruba to kun oju owo , ti o si gbo ilu bii ayanjide , o didan ki e le tu eleyi o grin)
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 1:21pm On Aug 23, 2007
Mo ki onile mo ki alejo o. Mo ki gbogbo mutumuwa ti n be ni ha hin.
Otokunlu e ku ko le da
Borokini ilu  e ku oro aje o
Se gbogbo re n lo dede o.
Mishoo,minutes, ayanjide, awon omoge mejeeji, nana, desorlah , ogbeni oloti dblock ati aloib oni shikin periperi! E wo le se

Nipa ti ilu ti olukuluku wa ti wa;
Omo asoni okeke ni mi , omo olodo ide
opopo meta lo la ilu temi ja
ibi aperin si ni won n pe nita iperin
ibi a pa gbo si ni won n pe l'okejigbo
ibi a pa elede si ni won n pe ni oke ede
omo amowo ila ra eru
amowo ikan ya iwofa
( bi o ba je ogidi omo yoruba to mo oriki orile , iwo yio mo ilu mi pelu oriki yi!  e ma a gbe yewo)
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 1:11pm On Aug 23, 2007
Ayanjide , alabajo re.
oyo alaafin , ojo pasekere omo atiba!
Beru ba n ba yin e wi o
eru o ba omo oyo o
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 8:47pm On Aug 22, 2007
ibikan lati n bere.
Culture / Re: Yoruba Proverb Competition by richylaw(m): 8:43pm On Aug 22, 2007
Nite Angel, you found me here! cool.
Lets get moving then.

Ejo to ba moo je nii to itan,  a i rin po ejo ni i se iku pa won.

A snake that is cautious in it's daily plight will grow to be as thick as the human thigh, but unfortunately snakes don't move en-mass so they are easily killed as an individual.

Can you wait to fight six black mambas charging at you at the same time?
Culture / Re: Yoruba Proverb Competition by richylaw(m): 7:42pm On Aug 22, 2007
orisa oke mo je ni to go o gbon ka le ma ro n tu je bi isu

oh Lord prevent the foolish from being wise so that the world will always have someone to cheat !

(1) (2) (3) (4) (5) (6) (7) (8) (9) (10) (of 17 pages)

(Go Up)

Sections: politics (1) business autos (1) jobs (1) career education (1) romance computers phones travel sports fashion health
religion celebs tv-movies music-radio literature webmasters programming techmarket

Links: (1) (2) (3) (4) (5) (6) (7) (8) (9) (10)

Nairaland - Copyright © 2005 - 2024 Oluwaseun Osewa. All rights reserved. See How To Advertise. 65
Disclaimer: Every Nairaland member is solely responsible for anything that he/she posts or uploads on Nairaland.